Wednesday, June 6, 2012

PASTORIAL THEOLOGY YORUBA


  
 GROUND OF TRUTH BIBLE INSTITUTE
     G.P.O BOX 17171, DUGBE, IBADAN, OYO STATE, NIGERIA, WEST AFRICA.
TEL. NO: - 0805 600 8526
E mail: groundoftruth2@ yahoo.comHAND OUT
PASTORAL THEOLOGY
               
                                                    
 

  ADVANCED CHRISTIAN LEADERSHIP 100 LEVEL
GROUND OF TRUTH BIBLE INSTITUTE

G.P.O. BOX 17171 DUGBE IBADAN


IMO IJINLE NIPA SISE OLUSOAGUTAN

           
ITOKASI     oro yi “Oluso agutan” ni a fi npe eniti nbojuto ijo agbegbe kan. Awon oro Greeki kan ni a lo ninu majemu titun lati fi sapejuwe ipo yi. Awon ni eyi:-
1. POIMEN -eyiti   o tumosi daran-daran tabi Olusoagutan.
2. EPISPOKOS -eyiti o tumosi Alagba.
Oro Olorun fi ye wa pe awon oro yi tumosi ipo kan na, se akiyesi [Ise awon Aposteli 20 vs17, 28 ati fillipi 1vs1] lotito, Oluso agutan ni Bisobu tabi alabojuto, alagba tabi Oluso agutan to setan lati bo awon agutan.

   KINI IPE?


Nigbati a ba nsoro nipa ipe Oluso agutan a nso nipa idaniloju ti inu okan pe a ti gba ojuse lati oke fun wiwasu oro Olorun ati awon ojuse miran ti o lo pelu re, ipe si ise iranse je ipe ore-ofe. Jesu nipa ore ofe pe awon apeja bi omolehin re o so fun won pe” E tele mi ngo si so yin di apeja eniyan [matt. 4 vs 18-19]. Aposteli Paulu mu daju pe oun di iranse Olorun nitori ebun ore ofe Olorun (Efesu 3 vs 7, ise A.A. 20 vs 24b) o si fi ogo fun Olorun fun ipe ore ofe yi. [Timotiu kini ori kini ese kejila]

         SE OLUSO AGUTAN NIKAN NI OLORUN PE?


Rara.  Olorun pe gbogbo onigbagbo lati wasu ihinrere.
1.      Ni ona kan gbogbo onigbagbo la pe lati wasu ihinrere [Matt. 9 vs 38, I Kor.12vs13, Johannu 15 vs 1-8]
2.      Gbogbo onigbagbo ni a ti fun ni agbara lati tesiwaju ninu ise Kristi, eyi ni idi fun Emi Mimo [Johannu 17:20; 14:20]
3.      Esin kristiani ni akoko je ti gbogbo enia [Ise A.A. 8 vs 1, 4; 11vs 19-22] kii se awon Aposteli nikan ni o wasu oro naa kiri. Sugbon gbogbo awon omo ijo Aposteli naa jade lati kede oro igbala naa [Romu 10 vs18]. Bi o ti wu ki o ri, gbogbo omo ijo la pe lati wasu ihinrere, bakanna ni ipe kan wa ni pato fun. Olorun ni o ma ngbe ninu ipe si ojuse lati oke wa sinu ise iranse.[Amoos 7 vs14,15, Esek 34vs 23, ise A.A 9 vs3-6,15-16, Efesu 4 vs7] Aye kan wa fun gbogbo eniyan, aye pataki si wa fun awon kan ninu ise iranse ijo ti Kristi. Ojuse pupo ni yio na eniyan lati pari ise ile kiko [I kor.3 vs9]
                        IDI TI AWON KAN FI GBAGBO PE A PE AWON

  Awon idi ayederu kan wa fun ipe:
i.          Iyolenu awon obi [I Sam.1: 20-28]
ii.         Ise to wuni [Ise A.A. 19:13-17]
iii.       Ipongbe ti ara eni [Ise A.A.8: 18-19]
Gbogbo kristiani nilati wa itoni Olorun, bi o ba si si okan ati Emi re si Olorun, yio mo boya Olorun pe oun tabi ko pe oun si ise iranse ti ihinrere.
Nje awon eniyan kan wa ninu ise Oluso agutan ti Olorun kope? Beni, laise iyemeji ale tete da won mo nipa awon ami wonyi.
1)     Won ma nri ise olusoagutan bi ise asela ki se bi ipe oto lati odo Olorun, won a ma yan ise Oluso agutan bi igba ti eniyan ba yan ise dokita tabi agbejoro.
2)     Won ki iri ijere okan bi ojuse akoko ati ojuse pakati. Opolopo won ko tile gbagbo ninu pe o nilo ki eniyan o yipada si Oluwa lati je kristiani.
3)     Won je awon eniyan ti o maa nse ase, iwa omoluabi ati imisi oro Olorun.
4)     Won je awon ti won ma ngbe iwasu won le ohun ti won ka ninu oro elomiran, won a si fi Bibeli ti lehin bi ese oro Olorun fun iwasu na.
5)     Iru awon eniiyan be lo ma nsa kuro ninu ise iranse bi o ba ti su won nitori bi ise na tiri, ati iru owo ti won ngba.

Kini a o so lakotan? Ise olusoagutan je ise Olorun ni owo eniyan, awon ti Olorun pe ni a ma nse, ise Oluso agutan pelu gbogbo ise otito kriatiani, bakanna ni o je ise ti o tobi ju lagbaye. Ise Oluso agutan yio mu ere aiyeraye wa.
O je ohun to lewu lati gba ipe eke, lati sare nigbati a ko ran wa, Ezek 13:3, 6:8-9. o ye ki a ko eko ninu Ahimasi ti o ro wipe  enia daradara ni oun ti o si ni itara sugbon ko ni oro [2 Sam 18:22,27-30]. Oba pasae ki o ya segbe kan. Ohun itiju ni eyi!, Olorun lodi si eni to pe ara re lati wasu.
  OLUSO AGUTAN ATI IDAGBASOKE IJO
Kini idagba soke ijo tumo si?  Idagba soke ijo tumo si iposi ti o dogba ni pipo yanturu,
 ni pipeye ati ni eto eto ti ijo agbegbe kan.                                                                 

IPA META IDAGBASOKE IJO                                                             Gbogbo
1)     Pipo ni yanturu       Ise A.A.2:4,4:5-14                                    Idagbasoke Ijo         
2)     Pipeye tabi idagba ti Emi Ise A.A 2:42-47; Efesu 4  
Aiko si idagba ti emi ma nse idiwo fun pipo yanturu, awon mejeji wo inu ara won ni
     3)   Idagba soke ninu eto ijo [ise A.A. 6:1-6; 14 : 23

                ONA MEJE LATI KO LATI BOJUTO IDAGBASOKEOluso agutan ni lati duro bi asoju. Nitori na ki o to le dari ijo ni ona ti o muna doko
fun iyipada, o nilati ni eto fun idari awon eniyan.
Igbese merin ototo la nilati gbe fun iyipada yi
        i.            Se alaye iran re
     ii.            Fi aye gba fifesi
   iii.            Gbe isokan  laruge ninu ara[ijo]
A ni awon eniyan ti won je onitesiwaju, adakeja, eleto
 iv.      Seto biboju to akoko
   E JE KI A SE AYEWO ONA MEJE TI YIO MU IDAGBASOKE IJO JA GERE
1.      Oluso agutan nilati gbadura fun ise si.[luku 17:5]
Igbagbo ti a nilo ni eyiti o le gbekele Olorun fun iyanu gbogbo [Mk16: 17-18;Jn 14:12]
2.     Oluso agutan nilati setan fun iyanju isoro gbogbo
Idagbasoke igbagbo re yio je ki o ri isoro bi anfani fun o dola, dojuko lesekese ki o to di nla
3.     Oluso agutan nilati se eto ijadelo iwasu
Lo ogbon ti o dara lati mu oro Kristi to awon ti kii lo si inu ijo kankan ni agbegbe re.         
bawo ni o sele ni idaniloju pe o se eyi?

              i.      Keko Ninu Iriri: Bawo ni awon ona ti o gba nsee tele se le so eso si?
           ii.      Mo Aini Awon ti kii lo Josin ni Agbegbe re?           Mu ile bi ogorun ni adugbo ijo re,
Ki o si beere ibeere, eyi ni awon ibere marun ti o le bi won:-

1)     Nje omo ijo kankan ni o lagbegbe yi? Bi idahun re ba je beni, fi sile ki Oluwa ki o pelu iru eni be
2)     Kini ohun ti o je Pataki aini adugbo yi
3)     Kilo fa ti awon eniyan kii fi lo josin ni adugbo yi? Eyi je koko ibere.
4)     Bi o ba nwa   ijo ni agbegbe yi iru awon ohun wo lo fe ri nibe?
5)     Iru amoran wo lo le gba mi gegebi   Oluso agutan ijo kan ladugbo yi fun apeere, kini mo le fun o? fun iru eniyan be ni iwe ti o njuwe ijo re.
 iii.   Fojusin ijadelo re fun awon to setan
1)      So akoko ati ibi ti o to [Jn.4:34-35]
2)     Gbin eso si ile olora [Mk4]
Awon eniyan wonyi ni yio nife si irohin rere tabi iwasu ana
                                i.            Ore ati ojulumo omo ijo, papa ti awon ti asese gbagbo
                             ii.            Awon alejo tuntun ni   agbegbe
                           iii.            Awon alejo ti o wa si inu ijo re
                           iv.            Awon eniyan ti o le ba aini won pade
                             v.            Awon eniyan to nla isoro koja lakoko na ti won si nilo ife ati iranlowo.

4.            Oluso agutan nilati se eto to peye fun gbigbe eko sara fun    
    awon omo ijo tuntun
Kini idi ti awon ijo to nsakitiyan fun ijade lo ko fi dagba sibe? Eyi je apere irewesi
ati aile gba oro na, ona meji pakati la le fi ri daju pe omo ijo gba eko wole sara
        i.            Wa ojuse fun
     ii.            Da ipejopo tabi ijosin ifojukoju sile

5.    Oluso agutan gbodo tu awon abenugan ti nda ijo sile ka
Awon akoko omo ijo bi ipinle ti won ti ni ojuse kan to si ti di eto liana bi ati nse nkan tiwa, awon eniyan yi ni awon to de nigbati Oluso agutan tuntun gba ipo. Isoro yi ma nwopo ninu ijo tiwa ntiwa
6.   Oluso agutan nilati fi kun osise to nilo
Opo ijo ni ko ni osise ti o to fun idagba. Sugbon pipeye ati pipo awon osise se Pataki fun idagbasoke ijo

ABA MEJI FUN IPEYE OSISE
        i.            Gba awon osise titun nipa ebun emi ti won ni
     ii.            Gba osise   nipa ifara eni jin ti won ni si ijo ati Oluso agutan agba

7.   Oluso agutan nilati wasu fun idagbasoke
        i.            Je ki iwasu re ba eko nipa ise iranse re mu
     ii.            Lo agbara ori pepe lati ru awon eniyan soke fun idagbasoke
   iii.            O gbodo ma se ohun ti o dara laisi iyemeji ki o si ma duro sinsin, ma so otito ati
      oro irunisoke
   iv.            Ma ya  fun awon akori  to le fa ariyanjiyan
     v.            Wasu si aini enikookan
                       Oluso agutan ati awon ebun emI

Oluso agutan nilati sakoso awon ebun emi ninu ijo. O nilati loye nipa ifarahan ati ojuse awon ebun yi
  Idagbasoke ijo ati ebun emi          
Ki lo ma nsele nigbati ijo   ko ba ka Pataki ebun emi si
1.         Isoro aimokan yio sele [2 Kor.10 :12
2.         Isoro afirawera yio wa [2 Kor 10:12
3.         Isoro ki a dojuko eto yio wa dipo ki a doju ko enia
4.         Isoro ijia yio wa [I Kor. 3:3-6]

Ojuse merin ti Oluso agutan ni sisakoso awon ebun emi
1.         Kii se talenti lasan [I Kor 2:4-14]
2.         Kii se ojuse ti kriatiani [Luke 24: 48]
3.         Kii se eso ti Emi [Gal. 5: 22-23
4.         Kii se ayederu ebun [Matt 24:24, 7:22-23]

OJUSE PATAKI MEJI TI EBUN NIISE NINU IJO
1.         Awon ebun emi nilati bi idagbasoke  [I Kor12 :7 ,14:12,26]
2.         Awon ebun emi nilati bi isokan [I Kor 12:22]
a.         Ebun yato bi omo ijo se sototo [I Kor 12:28,17,18; Rom 12:6-8]
b.         Liloye to jinle nipa ebun emi nilati mu emi itiju ati aidogba kuro. [I Kor12:14-17]
d,         Liloye ebun emi ko ni fi aye  fun gbigbe ara eni gesin aayan. [ IKor. 12:21,
           Rom 12:3, I Kor 4:7]

 Ipele  meta ti ebun emi

1.         Ebun iruni soke[Rom 12:6-8;I Pet.4:9-11]
2.         Ebun ifarahan [I Kor 12:8-10, 21]
3.         Ebun ise iranse[ Efesu 4:11]

Text Box: Bi a ti ngba ebun emi

A nri ebun emi gba nipa ibale re lori eniyan kii se nipa ase tabi eko
1.    Agbara ni O se nse ohun ti o wu:- Olorun  le fi  ebun, ise oranse ati ipo funni
   bi o ti wuu [Ise A.A.2:14, 4:31;10:44]
2.           Nipa igbowoleni [Deut. 34:19,Ise A.A 13.3; ITim 4:14
Baawo ni o sele da ebun ti Olorun fun o mo?

1.         Sise iwadi re[Lk 11:9,13; I Pet.4:10
2.         Danwo pelu iyekiye[ I Kor 14;12]
3.         Ye imolara re wo, kini o nife lati ma se [O.D.100: 2, Matt. 11:30]
4.         Siro imunadoko re [I Kor.12: 7]
5.         Reti ifidimule   re lati ara [Ise A.A 9:36-39,11; 24:2]
Olusoagutan   ati isakoso ijo
Isakoso ijo:-            ise iranse ti o nfi  irinse funni
Alaye itumo isakoso ijo:      Fun ijo lati ni idurosiinisiin to kun oju osuwon, o ye fun adari ati olutoni ki o lo ohun elo ti won ni fun ise iranse. O se Pataki lati je ki ijo se awari ki won si pinnu idi ti won fi wa ati ilepa   won. A nilati  da awon aini eniyan mo, ki a si wa  ojutu si awon aini yi. O ye dandan ki ijo o ma pese awon ohun elo ti o ye ni akoko re

Nitorina ohun tio papo je isakoso ijo ni ojuse adari bi o tin se deede ninu awon ise iranse yi. Charles A. Didweh fun wa ni itumo isakoso ijo.
Isakoso ijo ni idari to nfun ijo ni agbara ti o nilo lati je ijo ati lati se ojuse ijo. O je   idari ti ijo npese nipase adari lati lo awon ohun elo ti emi, omoniyan, ti ara ati ti eto isuna owo ni ona eyi ti yio mu ijo de ibi imuse erongba re. o ma  nran awon omo Olorun ti won je ijo lowo lati di ohun ti won fe da ati ki won le se ohun ti won fe se nipa ore offe Olorun.

A nilo lai se alaye eyi  ju ki a ma teju mo alaye   itumo nipa ohun ti isakoso ijo  je
1.         Isakoso ijo ni adari
2.         Isakoso ijo nfi ohun elo  fun ni ki ijo o le je ijo ati ki o le se ise ijo
3.         Isakoso ijo je itoni ti awon adari npese bi won ti ndari ijo
a.         Lati lo awon elo ti emi
b.         Lati lo awon elo ti omoniyan
d.         Lati lo awon elo ti ara
e.         Lati lo ohun elo ti isuna owo
4.         Isakoso ijo nje ki awon omo Olorun tin se ijo ba le di ohun ti won fe di nipa
           ore ofe Olorun
5.         Isakoso ijo  ni mimu ijo lo si ipele imuse ifojusun won
5.      Isakoso ijo ni jije ki awon eniyan Olorun le se ohun ti won fe se nipa ore ofe Olorun
     Isakoso ijo Je idari

Kini idari je?

Adari wa lati inu oro yi idari. Adari ni eniti o mo ona, ti o si nfi ona han ni, ti o si nrin oju ona na, idari ni titoni loju ona kan .
Adari le lo saju awon ti o fi nmona, nigba miran, adari le nilo lati mu awon eniyan re wa labe ase ati idaduro, olutona nilati ni imo to daju nipa ona ati gbogbo isoro ati ewu oju ona yi. Awon amuye fun adari yi ran wa leti oro Jesu Oluwa, nigbati oo nfesi si ilodi awon adari Israeli. Jesu wipe”Fi won sile afoju adari fun  afoju bi afoju ba si nto afoju gbogbo won yio subu sinu koto.

Oro Jesu yii fi ye wa  daju  pe adari nilati je eniti o ni imo paapaa funrare. Idari ijo wa labe Kristi, nitori oun ni ori ijo re ko si si enikan ninu awon adari ti o jjulo. Nitori na  o ko gbodo saju oluko, sugbon tele oluko, awon ti o nsaju oluko a ma fi ara won han, won kii gba amoran sugbon won ma nje gaba lori eniyam. Idari ninu ijo ni  lati waye  lati owo eniti o se tan lati tele idari Kristi, ti se ori ijo. Kristi funrare ni eniti o ma ran awon eniiyan lowo lati mo ona nipa itoni Emi Mimo

Idari ijo wa lati fi irinsefun ni
Idari ati itoni wa ninu ijo fun ete lati fi irinse fun ijo. Kini o tumo si ki a fi irinse fun ni? Ijo gba irinse nigbati a se lowo fun ise isin tabi fun igbese. Ifirinse fun ni je lati mura sile, lati wa leto, lati farahan nita ni ona ti o dara. Oro yi ni a lo nigba atijo ti o tumo  si titun nkan to ni oju ibi ti o ti ye, fi ohun kan si eto. Iru oro yi fi ara han ninu [Matt.4: 21 ati efesu 4:20] lati fi irinse fun ijo ni lati fun wa ni gbogbo ohun elo iyebiye ti a nilo lati gbe ohun kan se; ti ara, iwa, ise ti o se pataki nipa idari ijo na ni lati fi agbara kun ijo.Ise iranse olusakoso wa lati fi irnse fun ni
Gbogbo itumo oro yi “Isakoso Ijo” fi ara mo ero wipe o wa lati fi irinse fun ijo lati fi se ise iranse. Oro ti o wipe “Lati se  akoso” wa lati inu ede Latin ti o tumosi si iranse, iranse Olorun nsise iranse re ninu ijo.
Isakoso ijo nsalaye bi iranse yio se bojuto ise iranse nipa pe ki o lo awon oro tabi ipa eniyan lati le ete re ba titi yio fi de oju osuwon ati imuse.

Oluso agutan gege bi oludasakoso ni ojuse pipese idari ti o le mu wa ri, ti o si le fun wa ni awon opin, itoni pelu je ona ati le iru opin be ba.

Ise iranse isakoso je eyiti o pese ohun elo gbogbo ti a nilo funni, isakoso ni bi awon enia se ndagba, isakoso nran adari ati awon alabasisepo re lowo lati fi awon eniyan to to si ojuse to to nigba ti o to, pelu ise ti o to, imo, ati akitiyan lati se ise to to

Isakoso ijo ati awon eniyan

Isakoso ijo ko eniyan ati ohun gbogbo po, iyato pataki ti o wa laarin isakoso rere ati buburu ni a ri ninu bi adari se je ki awon eniyan se pataki ju ohun elo lo.

Adari to dara yio ma dari awon eniyan lati dagba ninu imo, ise, ati ojuse gbogbo ninu eyiti  oun gegebi adari ati alajosisepo yio mu ijo tesiwaju ninu ifojusun ijo.

Adari to dara nilati mo bi ati nsise po pelu eniyan. Adari yi nilati ran awon to je ijo lowoo lati dagba ninu ayo ati itelorun ninu abajade eso ise won bi won tin jade lo wasu fun awon elomiran. Adari nilati ni ife si awon eniyan lati se ti won nse ninu ijoba Kristi. IFi irinse funni to ba bibeli mu
Jetro: apejuwe ti Mose [Eks. 18:13-27] bi a ba ka iwe yi daradara a o jere awon ohun ti yio ran wa lowo ninu isakoso. Jetro fi idajo to dara han nipa ise re si Mose, o koko bere ibeere o si da lohun, o bi Mose leere ohun ti o nse fun awon eniyan ati bi o se ndaase ni oun nikan. Mose fun ni idahun ti ko le ni ese kini “Awon eniyan to mi wa”. awon alabojuto ni lati gbiyanju ki o salaye awon idojuko won bayi.
                         Jetro ko mose ni ise iranse to fi irinse fun ni
1.         Gbadura fun won ati isoro won[ 19b]
2.         Ko won ni awon eto ilana [20a]
3.         Fi ona han won, ilana aiye won [20b]
4.         Fi ise ti won o se han won ki won le di orile ede ti Olorun yio lo fun ise irapada
5.         Se eto awon eniyan yi si egbegbe ti o se sakoso [21a]
6.         Yan awon okunrin to kun oju osunwon lati dari egbe kookan [21a]
7.         Fun awon adari ti o yan yi ni ase atigba de igba
8.         Je ki awon adari o pinni ojuse gbogbo igba
9.         Gbe awon oro to lagbara to adari agba wa.
Imoran Jetro yi ran Mose lowo lati kuro ni ipo jiju adari to nsise takuntakun pelu
awon omoleyin di alabojuto ti ise re pe  nigba tire  
   Amuye Oluso agutan

Itokasi
Labe akori yi a o wo amuye Oluso agutan lona meta.
1.     Amuye amutorunwa

2.         Amuye ti eko
3.         Amuye ti Emi

Amuye amutorun wa
1.       Isirasi aati ero opolo:   Opolopo iriri ni Oluso agutan yio la kojoa nitori na o gbodo mu aiya le nigbati ijakule ba de I Sam. 30:1-8
2.       Nini eda ikanu:             O gbodo    lanu awon eniyan ki o le pin ninu ayo ati ibanuje won. Rom. 12:15. o le se isin ininku ati igbeyawwo ojo kanna.
3.       Nini ife si eniyan: Bi o ba se mo awon eniyan yi to ni yio se loye nipa won si nitori o nilati mo awon nkan nipa ebi, ise ojo won ati isoro kisoro ti won ba ni.
4.       Mimo riri ojuse eniyan:        Ohun ti o ba so ni ipa lori awon eniyan si ibi tabi ire
5.       Fife lati sise kara:  Oluso agutan nilati le sise kara:
a.  Lori ibasoropo pelu Olorun      b.  Nipa omo ijo
d. Nipa ikole Olorun     e.  Nipa agbegbe

          Amuye ti eko

Itokasi   Bawo ni Oluso agutan sele kawe to, eyi ni se pelu kini ojo ori re nigbati o gba ipe Olorun. Bi o ba je odo, gbiyanju lati ni eko bi o ba ti dagba ju o le lo ile iwe agba
Siwaju si Oluso agutan ni lati je akeko ni gbogbo ojo aye re., je ki a se ayewo iru awon iwe to le ka, ka so pe o ti jade iwe mewa.
(i)        Ile iwe bibeli to dara         (ii)       Ile eko ise owo
(iii)     Idanileko orisirisi             Amuye ti emi

Itokasi        Bi a ti nmura sile fun ise iranse awon nkan kan wa to se pataki ju talenti, eko iwe, ayika ti o wu ni, ipa lati wasu lo. Bi enikeni ba kuna ninu ti emi gbogbo amuye ti o wu ki o ni ko le mu se aseyori inu ise Oluso agutan.

1.         O nilati je kristiani
2.         O nilati kun fun emi
3.         O nilati ni ipe Olorun, ki o si je ipe Olorun to ran
4.         O nilati fi ara re fun awe ati adura
       Pataki ifami ororoyan [ifinijoye] 

Itokasi      Opo ijo lo je pe awon ti a fi ororo yan lo ndari won, eyi ni awon ti a ya soto fun ise iranse ihinrere, nipa ohun ti a npe ni “Isin Ifijoye”. Itumo oro yi kii je iranlowo fun awon Akoni ninu igbagbo nitori o tumosi ifijoye yi bi fifi  ase mimo le ni lowo eyi nipe  a ti gbe ase lati sise bi  Oluso agutan le lowo

Se ifijoye yi nilo bi?    Nje o nilo ki a yan eniyan ki o to le wasu ihinrere bi? Beko bi o ba je pe o se pataki ki  a se iribo fun ni ki a to le ni igbala, a je wipe kii a fi ororo yan ni fun iwasu ihinrere se pataki, kini idi ti awon akoni ninu igbagbo  fi gbagbo ninu re ti won si nse? kini ifijoye  tumosi ati itumo kan wipe ki a le gba bi a se nse awon ise isin mimo kan lati muni wo inu ise iranse kristieni.

Asa ti o wipe yiyan yi ma nfi agbara ati eto fun iranse, eyi nipe awon ojuse kan wa ti o je pe awon ti a yan lo to si lati se bi iribomi, sise eto ounje ale Oluwa pe yio ni awon ami ti emi nitori eniti ondari re. Awon akoni ninu igbagbo wonyi, yato si awon Anglican ni ko gbagbo ninu iru asa be sugbon awon gbagbo ninu ki a ya enikan soto fun ise kristiani. Eyi mu ye   lati se awon ojuse re ninu ipo ojise ti a fi si, kii ise igba ti a ba se isin ifinjoye ni ase to ba lowo.

Awon anfani kan wa labe ofin ijoba ti o nfifun awon eniyan ti a ba fi joye yi, anfani be ni lati fi  ara han nibi igbeyawo ti ijoba ipinle nse; kii se kakiri agbaye, bi eniyan ba je Oluso agutan iyen ti to fun ojise igbeyawo nibomiran
Nje ifesemule oro iyanni yi wa ninu bibeli
A gbagbo pe o wa, a ri awon oro gbolohun ti a ti lo  “yiyan” ninu bibeli

2.           Jesu yan awon mejila ki o to ran won ko wasu[Mk 3:14.] Jesu fi won se aposteli nipa  yiyan  won si ipo yi
2.     Paul wipe a “yan” oun bi oniwasu [I Tim 2:7]. Paulu ni lokan re pe Olorun yan oun si
              ipo yi
     3.   Paulu ati Barnaba ni oju ona irinajo ise iranse ijadelo’yan’ awon alagba ninu ijo [Ise      
           A.A/ 14:23]. A lo oro yi fun ninawo jade fun igbesoke eyi ni pe a yan won nipa
           gbigbe won soke.
    4.   Paulu pa Titu lase lati yan awon alagba [Titu 1:5] Oro Griki yi tumo si “lati mu, ya soto,                                
          yan. Ninu awon oro wonyi, ko si ibi ti lo pelu ase kan-kan.
A le ri awon ero die mu jade ninu ese yi.
    1.     Olorun ma nyan awon iranse re yio si fi won si enu ise
    2.     Awon oniwasu wa laiseyemeji pelu iyonda ijo ati ise le da ipe Olorun mo
    3.     Ninu eyi a ripe eni  ti a yan gbodo la won iyiriwo koja lati owo eni ti o fe fi won joye   
           fun ipeye  ati yiye.

O ti di asa ni ijo akoko lati ya eniyan soto fun ise iwasu ati ise Oluso agutan nipa gbigbe owo le ni [Ise A.A 13:3,I Tim4: 14,5:22; 2Tim 1:6 bakanna Ise A.A. Aposteli 6:6, eyi ni awon Diakoni] a gbagbo pe yiyanni ba bibeli mu a si nfisi ise ni igba gbogbo.                                
                                  AMUYE FUN AWON TI A FE YAN 
Nje o ye ki ijo yan enikeni to ba fe ki a yan oun ? Rara, ni oplopo ipejopo ni ari awon enia ti won rope o ye ki awon  o ma wasu, won nfe ki a yan won, yio je asise nla fun ijo lati fi owo si iru ibere be.
  Opo ona ni o wa ti ale fi mo eniyan ti o peye fun iru ipo ifinijoye be.

Eni ti afe yan yi ni lati ni idaniloju pe Olorun pe oun si ise iranse. Pulu Aposteli wipe “Bi moti  nwasu ihinrere emi ko li ohun ti emi o fi sogo nitoripe  aigbodo mase wa lori mi ani  mo gbe bi emi ko ba wasu ihinrere [IKor.9:16]

Je ki a mo pe iyanni pelu ororo yi ko so enikeni di Oluso agutan tabi iranse tabi pe eyi ti agbara kan tabi amuye kan fun lati sise na. O nilati koko ni idaniloju pe Olorun ti koko pe oun eyi si ma nfarahan ninu bi won ti nwasu. Eleyi duro pe Olorun ko ni pe enikeni lati wasu lodi si Bibeli. Aini idaniloju yi lo ma nfa ti opolopo fi ma sa kuro ninu ise iranse nitori ise yi a wa poju ohun ti won lero, owo ti o nsi wole ko to nkan, won a wa fi ise ise iransae sile won a si wa ise osu miran ti yio ma mowo wole fun won.
   Eri ipe Olorun
Eni ti a fe yan yi nilati ni eri to daju pe Olorun pe oun. Orisirisi ona ni a le gba se eyi:

1.  Nipa sisalaye idaniloju re:  [I Kor. 6:16; I Tim 1:12]. Idi niyi ti awon igbimo idanwo fun iyanni fi ma nbere pe ki eni yi se alaye bi a ti pe sinu ise iranse, awon igbimo igbalode ma kuna lakoko yi bi o ba kawe dada a ki yewo finni-finni, ipe ati nini eko ijo re.

3.     Nipa bi o se le wasu:  Nipa awon amuye oye Bisobu [Oluso agutan] Paulu wipe o nilati mo bi a ti nkoni [I Tim.3:221] Si Timoteu o pasé fun lati wasu oro naa [II Tim4:2]. Iyato wa laarin ikoni ati iwasu, awon ti a pe si ise iranse nilati je ol;uso agutan ati olukoni[ Efesu 4:11] kikoni je fifi imo si aiye eni, idi ti a fi nkoni ni fun akeko lati le ni imo si lehin to ba jade ile iwe tan yato si igba ti o wo ile iwe, kii ise ona ti a gba nkoni lo se pataki bikose idi ati abajade eko naa. Iwasu je pipolongo ihinrere lati wasu, lati gbani niyanju, idi ti a fi nwasu ni lati fi ohun kan si ise, a mu oro yi ‘Ikoni’ jade ninu oro Griki kan [Gal 5:11] ti o tumosi pe ohun kan ni lati di sise. Opolopo Oluso agutan ni won je ojogbon ninu kikoni ni Bibeli sugbon sibe won ki jere okan, beni awon oniwasu wa ti won je ajihinrere to njere okan sugbon awon omo ijo won kii fi’dimule ninu igbe aiye  kristiani nitoripe  awon ajihinrere yi ko ni imo eko Bibeli lati koni. Ohun ti o bojumu ni ki Oluso agutan ko gbogbo re po.

      Idanwo siwaju ki a to yanni sipo.

Ko si eyiti ari ninu majemu tuntun, sibe ninu ase re si Titu nipa amuye Bisobu tabi alagba Paulu so wipe ki o je eniti o dimu sinsiin oro otito naa bi a ti ko ko oun na le gbani niyanju be [Titun 1:9] ‘ti o ndi oro otito mu sinsiin eyiti ise gege bi eko, ki oun ki o le ma gbani niyanju ninu eko ti o ye koro ki o si le ma da awon asoro odi lebi.

Sise olusoagutan ki a to Yanni sipo
Ko si eko kan ninu Bibeli lori eyi awon ijo kan tin se tele ri, awon miran si nse sibe, bi o ti le je wipe a o jiyan nitori re sibe a gbagbo pe o ni idi daradara tire.

1.         Yio fihan boya eni na ni ebun fun iwasu ati ise Oluso agutan
2.         Yio fihan bi o ti ni imo nipa ise Olorun naa
3.         Yio fi han ohun ti o gbagbo
4.         Yio se laafani pupo bi o ba je ki o ni iriri ninu sise Oluso agutan dara dara

A gbagbo pe ki o koko sise po pelu enikan ninu ijo fun Oluso agutan dara pupo, bi onisegun ba jade eko tan yio koko lo sise fun ijoba lati ni iriri, be gege lo dara fun Oluso agutan ti o ba jade ile eko Bibeli lati se be ki won to yan si ipo Oluso agutan.
     Oluso agutan bi adari
Adari ni eniti o mo ona, ti o nfi ona han ni, ti o sin rin ni ona na. Olusoaguntan ni adari agba fun ijo. Oun si ni o ndari awon olori egbe gbogbo to ku ninu ijo ati awon igbimo gbogbo, Oluso agutan ni awon ojuse wonyi lati se:-
1.         Ile eko ojo isinmi
2.         Isin ojo isinmi [ojo Oluwa]
3.         Eto orin ninu ijo
4.         Eto ijere okan
5.         Igbani ni moran
6.         Didari awon isin dandan
7.         Eto isomoloruko
8.         Eto isinku
9.         Eto igbeyawo
10.       Ibaniwi ninu ijo
   Isi ojo isinmi:

Oluso agutan bi adari ni ojuse ti o po lati se ni ojo isinmi
1.         O nilati se eto adura akoko fun awon osise laaro saju isin
2.         O nilati se itoni fun ile eko ojo isinmi
3.         Yio se kokari eto isin lojo naa
4.         Yio ko awon ifilo sile
5.         Yio ti pese iwasu sile
6.         Yio pari isin nipa sise ore-ofe
   Eto ile eko ojo isinmi

Oluso agutan bi adari ni ojuse nla lati se ni ile eko ojo isinmi
Kini ile eko ojo isinmi?    O je ile iwe eko bibeli ti ojojo isinmoi.  Nitori naa o kun
fun nkan yi
A     Ile iwe Bibeli ojo isinmi
1.         Eko nipa bibeli
2.         Eko ti o duro lori igbagbo ijo
3.         Eko ti o ngeb ijo duro
4.         Eko ti o ba ihinreere lo fun awon elese

B          Awon asoju ile eko bibeli
1.         Awon adari ti o kun fun emi bi alabojuto
a.         Alabojuto fun ile eko bibeli ojo isinmi
b.         Awon oluko fun ile eko ojo isinmi
2.         Ikeko ti imura eni sile
3.         Iwe ilewo fun eko yi
4.         Pinpin awon akeko lgbegbe.
Awon nkan wonyi ni ojuse oluso autan nitori nibi ti ko ba si awon osise to Oluso agutan ni lati pese awon eko ki o kun fun isinmi li o si sakoso eko imuraemi sile, nigbamiran we o le koni ni kilasi.


 Eto orin ninu IJO 
O dara fun Oluso agutan lati mo nipa orin, sugbon bi Oluso agutan ko bani imo orin o le gba oga akorin ti o le mojuto eto orin ojo isinmi ninu orin to ni imisi, Oluso agutan gege bi adari ni o ni ojuse lati fi awon eniyan si ipo niha orin.

1.         Oga akorin
2.         Aluduru
3.         Awon omo rgbe akorin
4.         Ipade akorin
Nibiti ko ba ti si eniyan to, Oluso agutan nilati di ipo yi

           Ijadelo fun ihinrere  
Oluso agutan bi adari nilati fi apeere rere leele fun awon omo ijo, bi Oluso agutan ba se ri ni oro ijo yio se ri Oluso agutan to ni itara yio se eto fun ijere okan lati ni awon omo ijo to ni itara Oluso agutan ni o oye ki o je agbateru eto yi nipa
1.         Pipese ati gbigba awon omo ijo niyanju fun
2.         Nini afojusin ati wiwa agbegebe ti ijo lo fun ijere okan
3.         Reran won lo pelu adura tabi biba won lo
4.         Pipese awon ohun elo isoro, iwe ilewo, tabi owo nigbati o ba ye
5.         Yiyan adari ti okan fun eni Olorun lati saju won lo legbegbe tabi lapapo
Ojuse Oluso agutan po pupo ninu ise ijadelo fun ijere okan

OLUSOAGUNTAN ATI IGBANIMORAN  
Olusoaguntan gege bi baba ninu ijo ni ojuse ti o po latise ninu aye omo ijo, nitorina won a ma so fun-un opolopo ohun ti won nla koja, nitori:
1.                  Gbigba adura si
2.                  Imoran agba
3.                  Imoran Olorun
4.                  Ominira ninu okan tabi eri okan
5.                  Fifi asiri pamo fun ojo iwaju.
Nitorina Oluso agutan nilati ri ara re bi agbani niyanju ju olubani daba lo.
Iyanju tumo si wiwadi oro daju titi a o fi mo otito ibe ti a o si wa ojutu fun. Nitori na Oluso agutan ni ojuse  ti o po gege bi agbani niyanju.e.g.

1.         O nilati mo bi a ti nwa oju Oluwa
2.         O nilati mo bi  a ti nlora lati fesi oro
3.         Ko gbodo ma sise pelu itara oro
4.         Ko gbodo se dajo lairi eni ti a fi esun kan
5.         O nilati mo pe olufisun yi na eniyan ni oun na
6.         O gbodo setan lati bere nipa gbogbo oro to ba sokunkun
7.         Ko gbodo fi ojutu pata si oro na.
Nitori ojuse nla ti Oluso agutan ni ninu igbani nimoran, o nilati mu awon iwa wonyi
a.         Ko gbodo je asoro ju
b.         O nilati mo ohun to nse
d.         O gbodo ko ara re ni ijanu, eyi nipe ki o le fi asiri pamo
Oluso agutan bi adari papa ni ibeere, oun ni yioo ma se ojuse igbamoran.                Bibojuto eto isin dandan

Olusoi agutan gegebi olori nko ipa nla ninu ijo ninu eyi ti isin  dan-dan wa, ti osi se Pataki

Kini isin dandan? ‘Ase ati liana’ ninu Bibeli awon ohun meji ni Jesu palase
Ounje ale Oluwa ati iribomi
Ojuse Oluso agutan ni lati se awon eto yi leyin iyiriwo , awon nkan wonyi:
            Iribomi
1.         Se eni yi ti gbo ihinrere
2.         Se o ti gbagbo
3.         Se o ti ni iriri aiye titun ninu Kristi [2Kor. 5: 17]
4.         Se o ti dominira lowo agbara ese ati esu
5.         Se o ti fi aiye re fun Jesu tori ijoba Olorun tabi tori ohun miran
6.         Igbe aiye   igbeyawo
7.         Iru ise wo lo nse
     Ounje ale Oluwa
1.         Se eni na wa niha ti Olorun i.e. se kristiani ni?
2.         Se eni yi ti bo lowo ese gbogbo
3.         Se o ti bo lowo odi yiyan se o si ti setan lati dariji awon to se
4.         Se o setan lati polongo iku Jesu titi yio fi de [I Kor.21:23-24]

Oluso agutan nilati ri daju pe gbogbo nkan yi ni oun nse pelu mimo ati owo pelu ola
       Sise eto ISIN isomoloruko

Isomoloruko je isin pataki to nsele ninu aiye omo leekan soso. Idi niyi ti o fi se pataki lati yewo finifini.
A fun Jesu loruko ni ojo kejo, bakanna ni Johannu Onitebomi ati awon miran. Nitorina ojuse Oluso aguntan ni lati dari eto isomoloruko, lara awon ohun ti a o yewo niyi;
1.         Adura ibere ati oniruru adura
2.         Orin iyin ati isin, orin inu iwe ati psalmu
3.         Pipe oruko tele baba omo
4.         Gbigba baba omo laye lati gbadura fun omo
5.         Wiwasu oro na
6.         Fifi ebun fun omo na

Oluso agutan le pe awon eniyan si ojuse kookan, bi ko ba si eniti o le se, Oluso agutan gbodo se funrare, ki o si ri pe ohunkohun ko wole
      Sise isin isinku             

Isinku je eye ikehin fun eniyan, o ma nsele nigbati eniyan ba ku tan eyi si ni nkan ti o sele gbehin si eniyan siwaju idajo, ki o to gba idajo. Bi Olorun se nfikun ijo ni awon agbalagba yio ma ku ni okookan. Oluso agutan bi adari ni ohun pipo lati se ninu isinku, a nilati ye awon nkan kan wo ti o ma nsele si eniyan ki o to dipe o ku, ani bi o ti nku lo.

  Ki o to ku    A so wipe kise gbogbo iku lo ma sele nipa ijanba moto opo yio tile ku nipase aisan. Nitorina ojuse Oluso agutan ni lati se toju alaisan ninu ijo re botiwu ki aisan yi buru to, Oluso agutan bi baba nilati :

1.         Lo ki eni to saisan yi ni kete to ba gbo
2.         Se eto adura fun nibiti o ngbe  tabi  ile iwosan
3.         Ma lodi si itoju ti ile iwosan ti awon ebi re fowosi
4.         Jeki gbogbo ijo lowo si adura ati ibewo
                 Bi emi re ti nlo                         

Awon nkan mii ma nba ni lojiji bi ijamba motor tabi bi iku ojiji ba pa omo ijo, bi Oluso agutan ba gbo ipe ojiji yi o gbodo koko:
1.         Fi ohun gbogbo tio nse sile ki o si sare lo si ibi isele na tabi ibi ti eni na wa
2.         Je ki   gbogbo awon omo tabi awon enia ti o kere kuro ni yara ibiti o wa
3.         Sare to Olorun lo ninu adura kikan-kikan
4.         Je ki o bo aso lara eni na ki awon ti o wa nitosi ranlowo
5.         Seto ti o mu ko rorun lati gbe eni ti o ku na si inu posi
6.         Bo enu, imu, oju ara, iho idi pelu owu
7.         Bo oju ati gbogbo ara re pelu aso e. t. c.

Awon nkan wonyi ati opolopo ni o se Pataki fun Oluso agutan lati se ni kete ti o ba de ile oku na. Olusoaguntan ko gbodo sa fun awon idile eniti o ku yi, o nilati  ba  won se eto isinku, o gbodo le fun ni gbogbo ifitomileti ti o ba ye boya  won fe sin oku na ni kiakia tabi bi o baya

Isinku
Bi isomoloruko se je akoko ninu aiye enia be ni isinku je asekehin nitorina a gbodo sse towotowo pelu ikanu, awon ihuwasi Oluso agutan niyi nibi isin na.

1.         O gbodo mu aiya le
2.         O gbodo ni ikanu
3.         Ko gbodo soro  lati mu ki awon eniyan ma sokun
4.         Ko gbodo sukun lori pepe            Lev.10:1-7
5.         Ko gbodo se alai ma wasu ihinrere fun awon olubanikedun
6.         Ko gbodo gbagbe lati so ohun ti o mo nipa oku yi  fun awon enia[pelu ogbon Olorun]
       Leti iboji
Olusoaguntan lo ndari eto isinku o si nilati sakiyesi nkan wonyi:-
a.         Lati gbadura fun oku [bi otile je wipe  ko ni tumo]
b.         Kika ese bibeli to ba asiko be mu
d.         Gbigba omo oku tabi ebi laye lati koko bu iyepe le oku lori leti iboji
e.         Igbani niyaju ranpe gbodo tele ki a to gbe oku si koto, ki a si je ki akobi o soro
e.         Oluso agutan yio si tun pada lo si ile eniti oku na lati lo gbadura ati awon oro iyanju.
Oluso agutan je baba o si ni ojuse  pupo  lati se ninu isin isinku.          Eto isin IGBEYAWO     
Oluso agutan gege bi adari nilati se eto isin igbeyawo fun awon omo ijo re papa awon odo, se asi mo pe odo se pataki ninu ijo, Olusoagutan ni lati se ise lori won ki won tile to de ipele igbeyawo, lara won ni.
1.         Riri daju pe won ti di atunbi
2.         Kiko won lati gbekele Olorun fun yiyan afesona
3.         Jije ki won mo ewu to wa ninu asise igbeyawo
4.         Jije ki won mo pe akoko iba dorepo je akoko ise atunse

Lehin awon nkan wonyi o dara ki Olusoagutan pe ajo ti o nbojuto igbeyawo ti yio ma bojuto awon nkan wonyi:-
1.         Igbe aiye ti won ti gbe tele ri
2.         Riri daju pe  ile na ko ni doju de lehin igbeyawo
3.         Wadi daju pe won ko fi oyun se igbeyawo nitori meji ni yio di ara kan ki se meta

Bi gbogbo eyi ba ti yanju Oluso agutan le wa so won po ninu igbeyawo yi pelu okan ayo, sugbon awon nkan wonyi nilati farahan ninu eto na;

1.         Opo adura ati orin ayo
2.         Sise iwadi fini-fini nipa isopo yi niwaju awon eniyan
3.         Isopo ati ibukun
4.         Wiwasu oro Olorun

Akiyesi: Olusoagutan nilati mo pe lilo si kotu fun igbeyawo ki se ese tabi lilo oruka igbeyawo.

              Ibaniwi ti ijo    
Oluso agutan gege bi adari wa ni ipo lati ba awon omo ijo re wi bi won ba se, awon ohun wonyi  la o kiyesi ni sise be:-
1.         A gbodo pe Emi Mimo si oro na ki o to di ibawi
2.         Iwadi fini-fini nilati wa
3.         Awon oloye ninu ijo le mo nipa re bi o tile je wipe ki se nigbogbo igba

A tun le kiyesi awon wonyi:-

1.         Ibaniwi ki pani sugbon fun itoni
2.         A o gbodo baniwi ntori ikorira
3.         Ibawi wa fun ki okan le fuye pelu idalare
4.         Ibawi nilati yo enia kuro ninu ide
5.         Ibawi wa fun fifi opin si oro ehin
6.         Ibawi yio fi aye  fun iberu Olorun ati igbe aye iwa mimo
Nitorina a nilati se labe ase ati imisi Emi Mimo pelu adura.
Oluso agutan si gbodo ri daju pe eniti a nbawi na:-
1)     Nwa sile isin lojojumo ti sin bati wa
2.         A ko gbodo fi se yeye  sugbon ki a jeki ijo ma gbadura fun
3.         Ki a mu pada bo sipo, nigbakugba ti eso ironupiwada ba ti farahan ninu aye re, Oluso agutan gege bi baba ati adari gbodo ba ni wi pelu owo ife
4.         Ki a mu wa si ironupiwada toto

Nitori idi eyi Oluso agutan ni ohun pupo lati se ninu ijo gegebi olori. Ole ri eko yi bi wipe ko kun to, ati wipe awon akiyesi wa ko ni o dara ju lo, sugbon a sa ipa wa lati wa eyi ti a ro wipe o dara, a si fi ori ero tiwa ti sinu iwe mimo.

A gbagbo wipe awon eko wonyi yio je iranlowo ati ibukun fun o

No comments: