IRETI FUN IDILE ONIGBAGBO
AFIHAN
Ipo ti opo idile wa loni, je egbo okan fun Olorun, beeni o si tun je edun okan fun awon iranse ati omo Olorun tooto. Ipo ti ko dara to ti opolopo ebi wa, ti wa di igi idabu fun opo awon odo ni iran wa yi. Opo idile ni o nse aisan ti o ni agbara lowolowo bayi, koda, o dabi eni pe ko tile si ireti fun won mo. Omo Olorun ti o ti padanu igbala re ati iranse Olorun ti o ti di apeyinda nikan, ni o le ni inu didun si ohun ti o je egbo okan fun Olorun
“Owo Oluwa wa ni ara mi, o si mu mi jade ninu emi Oluwa, o si gbe mi kale laarin afonifoji ti o kun fun egungun. O si mu mi rin yi won ka: si woo, opolopo ni nbe ni gbangba afonifoji, si kiyesii, won ti gbe pupopupo” (Esikieli 37:1-2)
Bi o tile je wipe awon ese Bibeli yi je gbaju-gbaja fun opo wa, ti opolopo si ti wa awon oniruuru iwasu jade lati ibe wa, sibe, Olorun yoo lo o lati ba wa soro nipa idile wa.
Lotito ni awon ese Bibeli yi soro nipa egungun gbigbe, sugbon won ko sadede di egungun gbigbe, awon ohun kan ti sele si won, ni asiko kan, ninu eyi ti o so won di egungun gbigbe.
AKOKO AIKIYESARA
Opo aisan ti o so idile si ipo aini ireti loni, ni kii se isele pajawiri, opo re ni o mun akoko aikiyesara dani. Opo aisan ti o so awon eniyan si ipo aini ireti ni aye ode oni, ni o sele leyin opo oniruru ikilo.
Gbogbo wa la mo wipe ikilo wa fun arun ko’gboogun (HIV) bakanna ni ikilo wa fun amusiga, koda ikilo wa fun awon awako lati mase sare ju bi o se ye lo. Sugbon o seni laanu wipe, opo ma nranti awon ikilo wonyi nigba ti o ba ti pe ju.
Opo idile ni won ti la eko oniruru koja nipa sise abojuto iyawo tabi oko won, opo tile ni iwe akosile nipa bib’ojuto awon ebi oko tabi iyawo won, sugbon sibe, won papa bo sinu wahala igbeyawo ki won to ranti. Boya ipo ti ebi tire wa loni niyi, iba dara bi o ba le se akiyesi awon ohun ti Olorun ti ba o so seyin, ki o si pada sinu ojuse ti o ye.
AKOKO AISAN
Ohun ti o maa ntele aikiyesara nipa ilera, naa ni aisan; bakanna l’omo s’ori nipa oro idile. Opo idile ni o ti wa ni ipo aisan-ebi lowolowo bayi.
Kini aisan ebi?
1. Aini alafia tabi ayo okan ninu ebi
2. Aile fi ara daa fun ara wa
3. Aini igbekele mo ninu enikeji wa ati beebee lo.
Nigbati ebi kan ba de iru ipo yi, a je wipe won ti wa ninu aisan nla, sugbon eyi ti o buru ju, ni ki won bo iru aisan be mo’ra, ki won ma si kigbe pe eni ti o le ran won lowo, tabi ki won ma lo oogun ti a yan fun won.
AWON IBEERE IFISISE
1. Awon ona wo ni a le gba bo aisan ebi mora?
2. Awon wo ni onisegun ti a le to lo?
3. Irufe awon oogun wo ni won le fun wa?
4. Awon ona wo ni a le gba bo lowo aisan ebi?
AKOKO IKU
Leyin ti awon onisegun ba ti gbiyanju titi, ti aisan naa ko si lo, boya nitori pe aisan naa ti ba awon eya kan je ninu ara, tabi nitori aitete kigbe sita ni asiko, nigba naa ni yoo yori si iku.
AWON IBEERE IFISISE
1. Kini iku nipa ti ara ati ti emi?
2. Kini iku ninu ebi?
3. Kini awon isoro ti iku ma nmu lowo?
4. Awon ona wo ni a le gba fi dena iku yi?
Awon ti won nla akoko aikiyesara koja je ida ogun (20), nigbati awon ti won wa ni akoko aisan je ida ogoji (40), ida ogbon (30) ni awon ti o wa ni ipele akoko iku, nigba ti awon ti idile won duro sinsin je idamewa (10) pere. Eyi ni ipo ibanuje ati ogbe okan ti Olorun ati awon ojulowo omo Re wa loni.
EGUNGUN GBIGBE
A mu Esikieli lo sinu afonifoji egungun gbigbe, lati ri ipo ti awon aye kan wa, leyin oniruru ipele isoro ti won ti la koja, won papa pari re si ipo aini ireti, won ti jera tan patapata, koda, awon egungun naa tile ti fonka kaakiri.
Olorun wa beere lowo Wolii Esikieli wipe, se awon egungun gbigbe yi si tun le wa laaye?
“O si wi fun mi pe, “omo eniyan, egungun wonyi le ye?” (Esikieli 37: 3) Gege bi eniyan, o je ibeere ti o soro lati dahun, boya nitori awon ipo ti egungun gbigbe wonyi yi ti la koja ti o si dabi enipe oro won ko ni ojutuu titi ti o fi wa pada hasi pe won di egungun gbigbe, sugbon Olorun ninu aanu Re fi idahun si i: “sotele”. Lati sotele tumo si lati so okan Olorun tabi lati koni ni okan Olorun, tabi gbadura.
Opo idile ni o wa ni ipo ti awon egungun wonyi wa loni, won ti pinya, olukuluku si ti fonka si ona tire, osi dabi enipe ko le si iwalaaye fun iru ebi be, sugbon ohun ti Olorun nso fun awon iranse re naa ni wipe “e sotele si awon idile wonyi” eemi iye yoo wo ibe lo. Nitori wipe Olorun korira ikosile. Edun okan loje fun Olorun lati ri idile kan ni ipo ikosile tabi ituka.
“Sugbon eyin wi pe, Nitori kinni? Nitori Oluwa ti se eleri laarin iwo ati laarin aya ewe re, eni ti iwo ti nhuwa etan si: bee ni elegbe re ni oun je, ati aya majemu (Igbeyawo) re. Nitori Oluwa Olorun Isreli wipe “Emi korira ikosile ati eni ti o fi iwa ipa bo aso re mole ni Oluwa awon omo ogun wi: Nitori naa e so emi yin, ki e mase huwa etan.” (Malaki 2:14,16)
Awon ewu ti ikosile ma nmu wa po ju idi ti ikosile fi nwaye lo. Ipokipo ti o wu ki idile ki o wa, ninu awon ohun ti a ti gbe yewo wonyi, mo layo lati so fun o pe, ireti si wa, ati wipe Olorun ti da si oro naa lati iseju yi lo.
Leyin asotele yi ariwo lo telee, ati leyin naa, nse ni a ri egbe ogun nla ti won dide, eyi fi han wipe opo ohun nla ti Olorun iba lo opo idile fun, ni o wa ninu afonifoji ituka ati ikosile, bi Oluwa yoo ba tun ma gbo adura re, ti yoo si ma gba ore re, o gbodo fi aye gba asotele Olorun yi, lati mu ki idile yin pada di okan. Ireti si wa fun gbogbo igi ti a ge, nitori ni ojo ti o ba gboorun omi yoo tun hu jade.
E je ki a gbadura!
No comments:
Post a Comment