Monday, February 13, 2012

EGUN IDILE (CAB)

EGUN IDILE
ORO AKOSO:                        

Opo awon ebi ni won wa labe ijegaba egun idile nitori awon isopo ti o wa laarin won ati awon emi esu. Opolopo ni won njiya ninu egun loni, nitori awon ohun ti awon baba won ti se, ti esan re si  nke   lori awon omo. Awon baba je eso ajara aipon, eyin awon omo kan

Oro ti a pe  ni Egun tumosi oro tabi gbolohun kan ti onpe fun ijiya, ipalara, tabi iparun enikan. Egun ni ohun ti o nfa ori   buruku tabi iparun. Egun ni oro tabi awon oro ti a lo pelu ohun ti o lagbara pelu ibinu.

KINNI A PE NI EGUN IDILE?
Ijo Olorun ti nwo inu akoko titun miran; akoko itusile ati biba awon mejemu idile je.

O je igbagbo awon eniyan wipe awon egun idile je abajade awon ese ti awon baba won tabi ti enikan da, ti o je abajade awon oriburuku, awon aisan, iyagan, osi ati bee bee lo. Awon wonyi ni o koja sori awon omo won lati iran. Eleyi da lori oro ti o wa ninu awon iwe wonyi: Eksodu 20:5; Deut. 7:9, 10; Num. 14:17-19; Ekun Jere. 5:7

Awon miran di erongba yi mu wipe, bi eniyan tile di atunbi, ti o si ni eda titun, ti a o si baptisti re ninu Emi Mimo ati pelu ti o tun le fi ede titun soro, o si tun le ni awon egun ti o jogun. A gbodo doju ko egun ni ona ti o yato, yato si igbala ati awon iriri ti Emi Mimo. Eleyi ntoka si wipe gboogbo omo Olorun ti o ba di atunbi ni won gbodo se iwadi ati ayewo won ati ipile won ki won si tun ye aiye won wo nitori awon egun iran de iran.

Fun apeere: Opo awon oruko ni won ni ibasepo pelu awon Emi esu. Awon ebi nibi ti  won tin sin orisa  gbodo kiyesara. O je igbagbo wipe awon egun idile maa ntele awon eniyan wonyi ati wipe ti a ko ba wa awon egun wonyi jade, ki a si dojuko won gidigidi, bi o tile je wipe awon iru eni bee ti di atunbi [kristieni], sibe awon egun idile wonyi yio si maa lepa won. Awon ara[brethren]  ti oro naa kan gbodo se awon egun idile wonyi ki won si ko sile, bakanna, ki won si jowo ara won fun itusile.

Egun idile ni a le salaye re gegebi adura kan tabi ase orun  lati pani lara tabi lati mu ki ipalara wa sori ebi kan tabi eniyan kan;

Egun je idakeji ibukun, sugbon ranti wipe laisi idikan egun kii deede wa …Owe 26:2

AWON NKAN WONYI NI AWON ABAJADE AWON EGUN NINU AYE ENIYAN.
1.    Isinwin ti o ntesiwaju, itara ati iwopale ti ara
2.   Aisan, ailera, ati awon arun ti ko gboogun oyinbo
3.   Awon aisan iran de iran
4.   Iwopale  igbeyawo ati ipinya ebi
5.   Osi olojo gbooro  ati ailaseyori
6.   Nini ijanba oko tabi ijanba miran nigba gbogbo
7.   Agan olojo pipe ati ki oyun  maa baje nigba gbogbo
8.   Awon iku igba gbogbo ninu awon ebi paapaa julo awon iku aitojo
9.   Awon ijakule ti o yi nika ati awon ikuna ti otesiwaju
10. Igbe aiye odo’kunrin ati odo’binrin olojo pipe
11.  Awon iriri ailepari awon idawole, ti o tun farahan leralera bii [ile    
      kiko, oko, okowo etc]
12.    Ki eegun maa leni loju oorun nigbagbogbo, awon ejo, awon maalu ati afefe ti o yanilenu loju oorun
13.    Osi nla  ti o tesiwaju
14.    Iku ti kii  se lasan tabi ipa, tabi iku ojiji ninu ebi
15.    Ki won maa bori eniyan nigba gbogbo. Num. 14:36-45, I Sam. 14: 1-48
16.    Aisan ti o le koko tabi awon arun ti ko sewosan. Lef. 13:1-46,Num. 12:1-16, Mk. 2:3, Matt.9:2, Deut. 28:15-44, Jn. 9:1-15, II COr.12:1 -10

KINNI OHUN TI O NMU EGUN WA ?
Gege bi iwe Owe 26:3 ti so wipe ‘Egun ti ko ba to sini, ko le wa sori eniyan’. Ni oro miran, bi o ti wu  ki oro egun ti a npele  eniyan lori ti le lagbara to, ko le munadoko [ko se iru eni bee ni nkankna] ti ko ba nidi. Lati je ki o ye wa si, a le so wipe bi enikan ba wa ninu Kristi. Iyen ni wipe, iru eni be je kristieni, tio si ngbe igbe aye re gege bi oro Olorun ti o si korira iwa ibi, iru eni bee ko ni ohun  tabi awon ohun ti o le fa egun wa ninu aiye re, sugbon bi ese ba wa ninu aye re tabi ohun kan ti o le mu egun wa, egun yiio wa sori iru eni bee.

Ni ipele yi, a nilo lati jiroro lori koko ohun ti o fa egun-ESE. Gbogbo ise aigboran ni ese si Olorun. Eniyan ninu isubu re, dese si Olorun, a si fi iseda eniyan sabe egun ninu Adamu. Eleyi sele nigbati Adamu dese ninu ogba Edeni. Nitooto Bibeli daruko awon ise ese ti o je wipe nigba ti eniyan ba da iru ese bee, o maa nfi eniyan sabe egun.

AWON WONYI NI AKOSILE AWON OKUNFA EGUN;

1.        IBORISA:      Eksodu.20:2-5, Iborisa maa nwa ni awon ona ti o po. Gbogbo ona ti eniiyan ban gba nfowosowopo pelu emi aimo ni iborisa, iyen ni wipe, awon ona ti a nba awon emi inu aiye  soro nipa eyi ti eniyan ri wipe o dara lati gba awon oro, idaabobo, ati isipaya

2.       ISE AJE:       Eleyi je agbara awon emi esu, ti o maa nni [possesses] eniyan ti o si le mu ki ohun kan sele

3.       AWON ABOKUSORO TABI EMI IBOKUSORO:      Awon wonyi je awon ti emi oku maa nsoro nipase won, ti won si so wipe o fun awon ni idari fun iwulo awon miran.  I Sam. 28: 5-16

4.       TITU OHUN IRUBO DA SILE:      eleyi ni ise nipa titu oti tabi awon nkan olomi miran sori ile lati bere lowo awon baba nla won, ki won le se iranlowo, tabi lati so won di oloro tabi lati  daabobo

5.       BIBO ERE TABI SIGIDI:       Eleyi je sinsin emi ti awon orisa nsoju tabi awon ere tabi awon ohun miran. Awon eranko ni won maa lo lati fi se irubo lati bebe si awon ohun elo wonyi

6.       BIBA OKU SORO:  O je igbiyanju lati baa won emi awon oku soro ati lati jo jiroro.[Heb. 9:27] awon  emi ti won farahan kii se awon emi oku gangan, sugbon awon emi aimo ti o sunmo won ti o je ti ebi

7.       ISE OSO TABI ALAGBARA AJE:  Eleyi je igbiyanju lati lo emi esu tabi agbara lati fi ipa yi eniyan pada tabi awon isele. Awon ti won nse iru nkan wonyi, maa nlo oogun, idan pipa, agbara, ogun-oyinbo ati ogun dudu, tewetegbo lati fi mu ilepa won se. [Lev. 20:6]

8.       ALAFOSE:      O je igbiyanju lati fi ogbon ikoko mo ojo iwaju tabi lati mo awon isele. O je ona ti esu maa ngba lati so asotele ibi. Deut. 18:9, 10; I Sam. 28:7-16; I Kron. 10: 13-14, Lev. 20:27. Isa. 47:12-13, I Sam. 15:23, Acts 8:11-23.

9.       ESIN EKE:     Eleyi je igbiyanju lati sin ati lati josin si Olorun nipase ogbon ati ayinike ona ti eniyan. Gal.1:8. Gbogbo awon esin ti ko tejumo Kristi ni won pada di esin eke, ti emi esu si ngbe inu won. Nitori naa, enikeni ti o   ba jowo ara re fun awon esin miran, yato si eyi ti Olorun palase ninu Kristi, iru eni bee ti fi ara re sabe egun. Eph. 1:12-13, Jh. 14:6

10.    AWON WOLI EKE:        Woli eke ni enikan ti o so asotele tabi ti o so itoni ti ko ti odo Olorun wa. Oniruru woli eke ni o wa:

      i.        Awon ti won mo wipe awon je onigbowo satani, sugbon ti won yirawon pada lati di wooli Olorun lati tan awon eniyan je sugbon ti won dogbon agabagebe wipe awon ni ebun yi, ti  won si se bee tan awon eniyan je.

     ii.        Awon miran wa ti Olorun tin lo ninu ise iranse isoltele sugbon ti won se aigboran si Olorun, ti won si dese ti won ko si ronupiwada.

Ti iru awon eniyan wonyi ko ba dekun lati so asotele, awon emi emere, ogbanje yi wole to iru eni bee. Iru eni bee yio maa sise bi o ti se tele, sugbon nipa emi emere tabi ogbaje ni eyi ti o mo bi won ti se sise tele. Awon naa yio pada di wooli eke. Won yio si mu iparun wa sori ara won iyen ni  wooli eke. Won yio si mu egan wa sori ara won [2Pet. 2:1-3]

11. ESE IBALOPO: Oniruru awon eya ese ibalopo ni o wa ti o si mu egun wa sori eniyan, gegebi iwe Lefitiku ori kejindinlogun ti so; opo awon ise ailofin nipa ibalopo ni o wa. Deut. 27:20-23

AWON APERE ENIYAN TI WON WA LABE EGUN IBALOPO NI WONYI
a)   Judah ninu iwe Genesis 38:1-26, Judah wo inu ibalopo buruku nipa ifekufe pelu iyawo omo re, Tamari. Nitori eleyi  ni egun se wa sori idile eya Judah.

b)  Dafidi ninu iwe 2Sam. 11:1-5, 2 Sam. 12:1-4. Dafidi se ifekufe pelu Batseba, iyawo Uriah. Dafidi ba obinrin naa sun.Dafidi si se aseyori nipa Uriah eniti o wa loju ogun. Dafidi  se ojukokoro iyawo arakunrin re, o se pansaga,o jeri  eke lodi si Uriah, ni ipari  Dafidi  pa Uriah.

c)   Ammoni: 2Sam. 13:1-21 Ammoni je omo Dafidi ti o ba omo baba re Tamari dapo, Tamari aburo Absalomu
·        Ammoni ni iporuru okan titi ti o fi se aisan
·        Tamari je omo baba  re, ti won ko si gbodo fe ra won
·        Ammoni korira re ju ife ti o ni si lo
·        Emi aimo kan ni owa lehin isele yi

d) Solomoni:  I King 11:1-8  Solomoni je omo Dafidi, oun si ni o gba ipo Dafidi gegebi Oba Israeli. Oluwa ti so   fun awon omo Israeli wipe won ko gbodo gbeyawo pelu awon ajeji, sibe, Solomoni gbojufo awon nkan yi o si fe awon ajeji obinrin. Deut.17:17, I Kings11:3

AWON OHUN MIRAN TI O NFA EGUN

1)       IPANIYAN: Deut. 27:24-25., Apeere eleyi ni Kaini. Gen.4:10-12 a fi Kaini sabe  egun nigba ti o pa Abeli aburo re

2)      IROPIPA:       Deut. 27:17. Gehazi iranse    Elisha  ko bo sabe egun nitori o se ojukokoro nikan, sugbon nitoripe o pa iro fun wooli Elisha. 2 Kings 5:22-27

3)      RIRE ALEJO JE, ALAINIBABA ATI AWON OPO:        Deut. 27:19 Olorun kii se ojusaju enikeni. nigbakugba ti eniyan ba lo anfani ailoye, o si ti wa nipa aini iranlowo fun eniyan, ti a si se lodi si iru eni be ti ko ni iranlowo, iru eni bee ti fi ara  re sabe egun

Judah paapa bo sinu idekun nipase Tamari nitori o yi idajo po lori opo ninu iwe Genesisi 18. Hamani fi owo ara re fa idajo re nipa gbigbeko sori igi nigbati o se lodi si Modekai ara Juu, eniti o je ajeji

4)      IWA IKA:      Deut. 27:1, Gen. 49:7
Mimu awon afoju sina je ise iwa ika. Iru ise ailaanu tabi iwa ika, bi nina omo ti ko dese tabi ki a se awon arugbo ni isekuse je ohun ti o le fa egun. Gen. 49:7

5)      FIFI IBI SAN RERE:     Fifi ibi san rere pada je ese ti o maa nfi eniyan sabe egun. Pro. 17:3, I Sam. 25: 1-38
Awon iranse Dafidi ran awon darandaran Nabali lowo lati boju to awon aguntan won. Won wa ni ayika won ni gbogbo igba. Ko si ohunkohun ti o je ti Nabali ti o sonu. Lehin naa ni Dafidi ran awon iranse re si Nabali ni akoko ikore fun iranlowo, sugbon Nabali ko jale. Iru ise be maa mu ibi wa sori eniyan. Ni kete lehin isele yi, Nabali si ku [I Sam. 25:1-38

6)      IWA ERAN ARA:   Eleyi tumosi gbigbekele eran ara lasan, sisinmi le eniyan fun iranlowo Jer.17:5

7)      JIJA OLORUN LOLE, JIJALE, IBURA EKE: Olorun nfe ki gbogbo wa je olooto ninu  ohun gbogbo ti a ban se, bee ni wa ki o je bee ni, ki beeko  si je beeko. Ohunkohun ti o ba yato si eleyi, ko se itewogba rara nitori ibi ni o nmu wa. Sugbon kiko lati mu idamewa wa, wa sinu Olorun, kii se wipe o buru nikan, sugbon o je jija Olorun lole.[ Malaki 3:8-9]

8)      SISE AIGBORAN SI AWON TI O WA NI IPO ASE:    Eksodu 16:6-8, Rom 13:1-2
Fun apeere:     Miriamu soro lodi si Mose ti o si  mu arun ete wa sori re, eyi ti o je ami ese ikoko tabi egun ninu aiye eniyan ninu majemu laelae[ Num. 12:1-16]. Korah, Abiramu, Datani ati pelu awon eniyan bii Aadotalenigba [250] ti won je adari, won si dide lodi si Mose ati Aaroni[Nim.16] sise aigboran si awon ti o wa ni ipo ase je ese, o si nfi eniyan sabe egun.


ORISI AWON EGUN
Orisi awon egun bi marun ni a daruko, awon naa si ni wonyi:
     i.        Awon egun ti o wa nipa sise aigboran si ofin Olorun. Eks. 20:3-4, Deut. 28:15-68, Deut 27:16; Josh. 6:20, Deut. 27:15-26
   ii.        Awon egun ti awon iranse Satani fi le eniyan lori[apeere awon aje, babalawo, awon alawo tabi elegbe okunkun]
  iii.        Awon egun awon iranse Olorun, Asoju Olorun, awon iko Olodumare ba pe sori eniyan.2 Kings 5:27, 2Kings 2:23-24
  iv.        Awon egun afowofa. Matt. 27:24-25, Gen.27:12-13
    v.        Awon egun ti o wa lati owo awon ibatan ti o ni ase lori eniyan [awon obi lori omo] [oga lori omo ise]


NIGBAWO NI EGUN MAA NDOPIN?

A nilo lati yara wo akoko ti egun maa nlo lori eniyan gege bi iwe Eks.20:5-6,34:6-7 Deut.7:9-10. a kiyesi wipe egun maa nsise lati iran keta titi de iran kerin.

KRISTI TI RAWA PADA KURO NINU EGUN
Ipele yi ni a ti kiyesi awon ohun nla ti Olorun ti se fun wa nipa Jesu Kristi. Opolopo awon oro ni o wa ninu majemu titun ti o nsalaye ohun ti Oluwa ti se fun wa ninu Kristi. Okan lara awon oro yi ‘ Irapada’. Gal. 3:13-14,   IKor. 15:47, Jesu Kristi Oluwa se eleyi nipa tita eje re sile ati fifi ara Re lele fun gbogbo iran eniyan. Mk 10:34, Eph.1:7, I Kor. 6:19-20

Abajade ise Kristi ti o munadoko ni wipe ati so wa di ominira kuro lowo awon egun ofin gbogbo. Jesu ti gbawa lowo ijoba satani, idalebi ati kuro lowo ebi ati agbara ese. Gal.3:13-14, Acts26:18, Rom. 8:1, 6:6-7

Ati wa di omo Olorun bayi, ati wipe a ti gba eto ati ase lekunrere lati je omo Olorun. Gal.4:4-7

NI IPARI
Nitooto, o nilo lati ye aiye re wo, ti awon itokasi egun ba nfarahan ninu aiye re, nigbana, o nilo lati beere fun eje Jesu lati ba gbogbo agbara egun idile je ninu aiye re. ki Oluwa  ran o lowo lati je olooto ati olododo si ara re ki o ba le da isoro aiye re mo

Boya awon obi re je ijoye, Oba, ode jagunjagun, babalawo, onisegun tewetegbo tabi o tile jade lati inu ebi oniyawo pupo tabi awon obi re je omo egbe okunkun, alaawo tabi wooli eke, tabi awon obi re tabi iwo fun rare nbe babalawo wo, tabi oruko re tabi oruko awon obi re je ti awon orisa. Boya awon olorun keekeekee, tabi eni ojubo tabi pepe orisa. Boya  awon obi re ko fara mo awon ounje kan, tabi e tile nbowo fun awon itumo buburu ti o dabi wipe o ni emi esu. Jowo ye ara re wo, ki o si bere fun eje Jesu fun itusile nla

No comments: