GROUND
OF TRUTH BIBLE INSTITUTE
G.P.O.
BOX 17171,
DUGBE, IBADAN.
ITOPASE ATI SISONI DI OMOLEHIN
AFIHAN: Gbogbo igbese ati so eniyan di omolehin
bere pelu iran.
A ni lati koko se agbeyewo, kini omolehin tumo si ? Iru igbe aye ti Olorun
beere lowo wa gege bi Kristieni. A pew a lati je atele Kristi- omolehin: sugbon
bakanna ni a paa lase fun was lati “lo
ki a si so awon eniyan di omolehin,” ti o tumo si isodipupo omolehin. O se
Pataki ki a ni iran ti yoo
mu wa wo inu re ni igboran si ase Kristi “Lo
ki e si so orile ede
gbogbo di omolehin mi.” (Matt. 28:19).
Siso ni di
omolehin bere pelu ilepa ijere okan. Gege bi enikan ti so, ilepa Kristieni ti o
ye ki o gaju ni wipe, ki o mu ijoba Orun gbooro si, ki orun apaadi si maa din
ku. Bi igbese akoko ninu sisoni di omolehin ba je ijere okan, igbese keji ni
lati je itopase. Ohun kan ni lati woya ija
pelu ota ki o si awon eniyan di ominira, ohun miran tun ni lati wa aaye fun
asesegbagbo lati rii wipe o dagba, ki o si de ekun Kristi.
Ninu ebi Olorun,
awon ipele eniyan meta ni o wa bi o ti wa ninu aye. (I John. 2: 12-14). O gba itoju to kun lati mu ki omode di okunrin,
o si gba okunrin alagbara ati okunrin ti iriri pelu ikoni ti o ye lati di obi
ti o ni ojuse. (se agbeyewo Titu 2:1-4).
ALAYE ITUMO ITOPASE
O je ise ti emi
lati fie se asese gbagbo mule ninu igbagbo aaye. Kol. 1:28-29; Ise. 14:21-22.
O je ibasepo obi
si omo pelu asese gbagbo. I Tessa.
2:7-12.
OHUN TI ITOPASE KO JE
1.
Itopase kii se biba asese
gbagbo nikan soro ninu Bibeli kika.
2.
Kii se ki a kan maa deru iwe kika pa won ninu itoni.
3.
Kii se ki a kan mu asese gbagbo gbo iwaasu ojo oluwa
nikan tabi darapo mo ile-eko ojo Oluwa.
4.
O ju ki a kan maa gbiyanju lati fun asese gbagbo ni
ojuse tabi fun ni ise se ninu ijo.
Gbogbo awon
akitiyan wonyi lo niye lori, sibe won ko ba aini asese gbagbo pade tabi kun oju
osuwon iwe Mimo; nitori gbogbo itopase ninu Majemu tuntun ni o toka si aini
olukuluku.
NIGBAWO L’OYE KI A BERE ITOPASE
Ajere okan ti o
dangajia gbodo bere itopase asese gbagbo ni kete ti o ba ti jere okan iru eni
be fun Jesu. Eyi ni pe itoju emi omo kookan gbodo bere ni kete ti a bii.
KINI IDI
1.
Ikoko nilo itoju oju ese
2.
Odo Kristieni je kogbo-kogbo.
3.
Odo Kristieni nilo ounje temi,
aabo ati ikoni
4.
Gbogbo odo Kristieni nilo obi
tie mi (I Korin. 4: 15)
5.
Olorun fi itoju awon asese
gbagbo sowo obi won tie mi.
6.
Idagba awon asese gbagbo duro
lori boya awon obi tie mi mu ojuse won lokunkundun tabi beko.
7.
Itoju emi oju ese se Pataki
nitori Satani a ma doju ko asese gbagbo lesekese pelu idanwo ati iporuru okan.
ITOPASE TO MUNADOKO
1.
Riran asese gbagbo lowo lati ni
idaniloju igbala re ati itewogba pelu Olorun. I Jh. 2:12-13, Gal. 3: 26-29.
2.
Riran asese gbagbo lowo lati ni
akoko idakeje pelu Olorun.
3.
Riran asese gbagbo lowo lati ni
oye igbe aye Kristieni lekunrere. II
Timo. 3:16-17; Matt. 4:4; I Pet. 2:2 eyi yoo ran asese gbagbo lowo lati
gbekele awon ileri Olorun funrare, yoo mo bi a ti nmu Olorun nipa oro re. Joh. 1:8; Matt. 24:35.
4.
Lati ran asese gbagbo lowo lati
te ara re si ikoni iwe mimo ati lati loye agbara ti o wa fun gbogbo Kristieni
gege bi abajade eni ti o kun fun agbara Emi Mimo. Joh. 8:47; Orin 9:11; Ef. 5:18; I Joh. 4:4.
5.
Ki a ran asese gbagbo lowo lati
ni idapo pelu awon Kristieni miran (lati ni ore) ki a si fese re mule sinu ijo
agbegbe ti o wa laaye fun idagba re ti emi. Heb. 10:25.
6.
Ki a ran asese gbagbo lowo lati
ko bi a ti npin eri igbagbo eni pelu elomiran (Mak. 16:15; Ise. 1:8).
A. KINNI
IDI ITOPASE
Ijere-okan lai
si ise itopase to tona dabi igba ti a bi omo tuntun ti a ko si fun ni itoju ti
o ye. Ko tile nilo ki a so wipe omo naa yo ku ni. Itopase wa se Pataki nitori
oniruru ipele akoko ti awon asese gbagbo yoo la iriri re koja ninu igbe aye
kristieni.
i. AKOKO IGBADUN: Ni akoko
yi, a ngba sinu ebi Olorun (ebi tuntun) pelu idunnu. A gbodo ko ni awon ilana
igbagbo kristieni lati ni idaniloju igbala, ati awon ilana ti eniyan fin pa ayo
jije kristieni re mo titi de opin. (Fillipi.
4:47).
ii. AKOKO IJAKADI: Lehin igba die, o
seese ki o beere sini kiyesi awon iwoya’ja ninu ara re. Ni akoko yi gan, a o ko
bi a ti ngbe igbe aye isegun lori eran ara. (Gal. 5:16-17, Rom.
8:12-14). Je ki a mo wipe kristieni
maa nba esu jagun emi. (Efesu.
6:10-12).
iii. AKOKO IYEMEJI: O seese fun asese
gbagbo lati siyemeji igbala re (paapaa nigba miran awon ti o ti dagba ninu
igbagbo) boya nipase awon wahala kan
to de ba won laye. A nilo lati mu asese gbagbo lokan le lati duro sinsin ninu
Oro Olorun ti ko labuku ti o si le mu eniyan duro ninu igbagbo (se ayewo Matt. 7:24-27).
Nibi lati maa nje ki asese gbagbo loye wipe wahala ko mu wa kuro ninu
ebi Olorun, ati wipe jije omo Olorun ko so wipe a o le ni wahala kankan ti a o
maa dojuko bi o ti wu ki o ri. (Se ayewo Joh.
16:33; Matt. 8:23-26).
iv. AKOKO WIWA OTITO PELU IBERU: Nitori oniruuru
igbekale eko ninu awon ti nbe laye loni,
opo awon asese gbagbo ti wo ko i tii fese mule ninu Bibeli ni won o wo inu
iporuru eko, eyi ti yoo mu won maa ti inu ijo agbegbe kan de ekeji lati maa wa
otito. Nipa bee o se Pataki ki a to asese gbagbo ki a si mu won dagba de ipele
ekunrere. (Matt. 24: 11, Fillipi.1:-11).
v. AKOKO IDAKEJE: Opolopo
awon aese gbagbo, nitori pe won ko ri eni ko won lati pin eri igbagbo won pelu
elomiran nigba ti won sese gbagbo, mu ki won je alaileso. Nitori idi eyi, o wa
se Pataki ki a ko asese gbagbo lati so eso ati bi a ti nje ajere okan. (Matt. 28:9-10). Eyi le munadoko nipa
mimu sise II Timo. 2:1-2; I Tessa. 1:6;
II Timo. 3:10-11).
LAKOTAN: Olorun maa npese
obi fun awon omo nipa tara. Bibi omo kan je ibeere mu ojuse obi se ni.
Omo ti ko ni
itoju obi ati aabo le di alaisan omo. A gbodo to omo na dagba ki a si fun ni
awon eko ati ohun ti o ye fun lati ni ki o ba le je omo orile-ede rere ati omo
rere lawujo ibi tin won ngbe.
B. AWON
IDI FUN ITOPASE
1.
Won o ni oye oro Olorun.
2.
Won je ope si otito t’emi.
3.
A le yara tan won je.
4.
Nitori idewo ati isubu pada
sinu ese.
5.
Idojuko le dide.
Olorun maa nyiri
eniyan wo lati gbee ga, sugbon esu n dan eniyan wo lati bii subu.
AWON ISORO INU ISE ITOPASE: Bibojuto awon asese gbagbo maa ngba akoko. A ngbe ninu aye ti o kun
fun ise ti akoko ti an lo si se iyebiye ati pelu awon wakati wa kuru pupo, fun
awon kristeni miran, yoo je irubo lati lo wakati kan tabi meji laarin ose pelu awon asese
gbagbo.
Boya didari awon
akeko omolehin, tabi mimu asese gbagbo kan
la eko ja, ilepa naa le ni ijakule. Awon miran lora lati loye awon ohun ti emi.
Awon kan ko
tile pongbe ati dagba ati wipe idagba tie mi ko ni tete wa. Awon ijakule yi yoo
mu irewesi wa fun osise bi o ban se ni oun nikan.
O seese ki isoro
ti o gaju je wiwa kristieni ti o nife ati se iranwo fun ise naa. Paulu Aposteli
dojuko iru isoro bee. O (Paulu) nfe lati ran enikan lo si odo awon ti o jere
fun Kristi ni Fillipi lati mo bi o ti wa, sugbon ko ri enikankan lati ran
ayaafi Timotiu. “Mo ni ireti ninu Jesu
Oluwa lati ran Timotiu si yin laipe, ki emi pelu le kun fun ayo nigba ti mo ba
gbo irohin yin. Nko ni elomiran bii re, ti o ni ife niti eni ti alaafia yin je logun. Nitori
olukuluku nwa ife inu ara re, kii se ti awon ti Jesu Kristi.” (Fillipi 2:
19-20).
Wahala nbe lori
bi a o ti se le mu awon ti o wa lode, ti won ti to Kristi wa, ati lati fi ife mu won wa sinu
ile-ijosin? Ko tii mo nipa ilana ijosin wa. Eto isin agbegbe yoo se ajeji sii.
Eyi je wahala ti o maa nwopo laarin awon ti won sese njowo aye won fun Kristi
nipase ijosin wa to logo. Awon isin wa gbogbo yoo yato gedegede si ohun ti o ti
nri tele rii, paapaa ko tile ni mu yanyan loju re.
APAPO ITOPASE: Oniruuru ona ati ogbon ni a fi nse itopase
sugbon ete kan
naa ni gbogbo won ni:
APAPO
ITOPASE
A. Itopase eniyan pupo B. Itopase
enikan si enikan D. Itopase Ara eni
ALAYE:
-
A. ITOPASE ENIYAN PUPO: Itopase eniyan pupo ni mimu awon asese gbagbo ti ijo agbegbe tabi
ipejopo awon omo Olorun jere fun Kristi dagba. Iru itopase yi ni agbekale itoni
ti o duro lori igbekale eko Bibeli nipase lilo iyara ikeko awon asese gbagbo.
Yoo je ki asese gbagbo le da ara re mo, pelu ara Kristi nipase ijo agbegbe.
B. ITOPASE ENIKAN SI ENIKAN: Itopase enikan si enikan je igbese onigbagbo kan ti o ti dagba lati ni ajosepo pelu asese
gbagbo pelu ete iranlowo lati mu dagba. Ijere okan enikan si enikan ati itopase
enikan si enikan je awon ona kanna ti o muna doko lati fi otito han ati lati
fie se otito mule. Ilana igbekale Bibeli nbe ninu II Timotiu 2:2.
Eyi je ohun ti ko le pupo ninu ijo agbegbe,
yoo je ohun ti o dara lati ri iru ibasepo Paulu ati Timotiu ti awon iranse
Olorun tabi awon alagba gbero bi awon kristieni kan yoo ti maa ni oju ese obi
lati toju awon miran.
C. ITOPASE ARA ENI: Itopase ara eni ni ki asese gbagbo kan funrare ni awon ojuse te’mi ti yoo maa
se funrare. Eyi ni se pelu kika awon iwe tabi ki o ni akoko sise asaro ninu
Bibeli, nigba miran ki o maa se eko agbeleka fu idagba ara re ninu Emi.
AWON
IDI ITOPASE ENIKAN SI ENIKAN: Bi o tile je wipe awon ogbon itopase miran
dara ti a si nilo won fun idagba awon asese gbagbo, bi a ba gbojufo itopase
enikan si enikan, won o le muna doko to gege bi iriri. Itopase enikan si enikan
ni o si dara ti o si munadoko ju ninu itopase ti a si ri. Awon idi fun eyi ko
si jina rara.
AWON
ISORO TI AWON ASESE GBAGBO MAA NDOJUKO: Lara
awon ohun ti o je iranlowo fun awon odo ninu igbagbo ni ibeere ti won maa
nbeere, bi awon omo wa ti a bi nipa t’ara ti maa ni ibeere ti kii lopin, beeni
o ri nipa t’emi.
Lakoko,
opolopo suuru ni a nilo. O le ri wipe ibeere kanna ni won maa nbeere
loorekoore, bi o tile je wipe o ti dahun won daradara bi o ti to ati bi o ti
ye, sibe won a tun beere si. O seese ko je wipe o o ti so ni ede ti yoo ye won. Gege bi odomobinrin ti o
nkeko lori ELEDA TABI ASEDA TI O GAJU, ti
o maa nso lehin oluko re: N o bikita
ohun ti o so, sugbon mo gbagbo pe Olorun wa.
Leekeji, o nilo ife aisetan ti kii mi ati eyi ti o dan moran
si awon elomiran. Awon wahala miran yoo dabi ti ara eni, nitori a o ni akoko to
ye lati feti bale gbo ohun ti won nso (bi o tile je wipe kii se leekan naa) eyi
si beere fun ife tooto – ife Olorun.
Ni ona keta O o nilo ogbon – iru eyi ti
Olorun nfun ni. Nipase iru ogbon yi gan ni a fi le mo iyato irusoke eniti o
nsoro. Lopo igba isoro ti a gbo nipa re lakoko fi isoro nikan han awon idi
miran si wa ti a nilati se imoyato re.
Ni ona kerin a gbodo je eni ti yoo le gbani
nimoran lati inu iwe Mimo dipo ki a ma so iriri ti ogbon ori. Opo awon
oluranlowo maa nse asise nipa imoran eyi ti o nmu iporuuru ba asese gbagbo ti o
nbere iru ibere kanna loorekoore ti imoran ti a sin fun yato si ara won.
Maa lo sinu Bibeli bi o ba seese fun idahun
awon ibeere.
Nibi ni ati ri oniruuru isoro ti itopase
ndojuko:
1. A I FE BA E PADE
FUN ITOPASE: Eyi ni nigbati o mo wipe asese gbagbo ko fe
lati ba e pade fun itopase.
2. AI SI IDANILOJU IGBALA.
3. RIRI ARA RE BI ELEBI NIPA ESE TI O KOJA.
4.
BIBERU LATI FI ARA RE HAN BI
KRISTIENI.
5. DIDOJUKO EBI TI O LE.
6. NINI ABASEPO PELU IJO TI KO JE IRANWO
FUN.
7. AWON IBEERE TI ALAIGBAGBO MAA N BEERE.
Awon ibeere ti alaigbagbo maa nbeere maa
nwa loorekoore, ti o si je afiyesi ni wonyi:
1.
Bawo
ni o se mo wipe Olorun wa?
2.
Bawo
l’o se mo pe otito ni Bibeli?
3.
Bawo
ni Olorun ife
se le gbaaye fun alaise lati jiya?
4.
Kilode
ti Olorun fi gbaaye fun ese ninu aye?
5.
ki
l’ese tumo si?
6.
Bawo
lo se mo wipe orun apaadi nbe?
7.
Nje
Adamu ati Efa je eniyan gidi?
8.
Nibo
ni Kaini ti ri iyawo re fe?
9.
Ki lo
maa sele si awon ti won ko gbo nipa Kristi ri?
10.
Bawo
lo se mo wipe Kristi jinde kuro ninu oku?
11.
Bawo
ni eniyan se le di Kristieni tooto?
O se Pataki wipe ki o se agbeyewo awon
ibeere wonyi ninu ipade re pelu asese gbagbo ki o ran an lowo lati ri ojulowo
idahun fun ibeere wonyi funrare.
AWON
ILEPA ITOPASE
1. Ilepa akoko si asese gbagbo ninu itopase ni
IDANILOJU IGBALA.
2. Ilepa keji ni RINRIN DEEDE ti o tumo si jijosin papo pelu awon ayanfe.
Ifara-enijin
fun OLUWA, kiko eko oro Olorun.
3. DIDURO
SINSIN: Ikoni niti
ojulowo eko to duro, eyi ti kii ye.
Diduro sinsin ninu:
a. Ikoni – Kika Bibeli.
b. Lorekoore – Wiwa deede.
c. Nigba gbogbo – Wiwa nigba gbogbo.
4.
IRI KRISTI:
Igbe aye Kristieni
asegun, iwa mimo ati siso eso tie mi. gbogbo eyi ni yoo mu eniyan dabi Kristi.
5.
OMINIRA:
Lati gbekele oro
Olorun nikan. Paapaa nigba ti ko ba si enikeni; boya oluko ile eko ojo Oluwa,
Oluso aguntan tabi awon ara nitosi, ti yoo si le duro ni oun nikan.
6.
BIBI:
Bibi omo tuntun, eyi
ni bibi elomiran ninu Kristi ki o si fese won mule.


IDANILOJU
IGBALA
IBI TABI IBI
Ti
o fi han wipe eniyan ti Mimu awon miran wa sodo
Atunbi
tabi eda tuntun. Kristi, ki a si tun so won di
omolehin tooto.


RINRIN
DEEDE OMINIRA
Igbe aye ifara-eni-jin ti Jije anfani ominira ninu kika
kikeko
oro Olorun ati pipe- ILEPA
Bibeli lakaye, laisi oluranlowo
jopo
pelu awon ayanfe. ITOPASE bikose Emi Olorun.


DIDURO
SINSIN IRI KRISTI
Duro
sinsin, lorekoore, nigba Igbe aye Kristieni asegun,
gbogbo
ati sise deede. Igbe aye mimo, siso eso ti
Efesu
4:4. Emi.
AWON AKOJADE EKO ITOPASE: Ipele yi ni se pelu awon ohun elo ti a o lo fun ise itopase. Awon ohun
elo ti a nilo yoo je iranwo ti o ye fun eko Bibeli ati akosori ti o le ba aini
awon asese gbagbo pade.
Nipase eko Bibeli yoo le ni anfaani lati ri idahun si
gbogbo aini ati ibeere re. Nigba naa o le di alagbara ati asegun ninu gbogbo
idojuko ti o ba wa si oju ona re nipase akosori Bibeli
Awon akojade itopase ni awon akori ti a o ko nigba ti
a ba nlo nko eniyan boya itopase enikan si enikan tabi itopase ologooro eniyan
tabi itopase ara eni. Awon akojade eko yi pin si ipa meta:
IPA IFARAENI JIN AKOJADE
IGBEKALE EKO
ITOPASE
SISONI DI
OMO LEHIN
1. ABALA IFARA ENI JIN
Abala yi nii se pelu oniruuru eko lati inu
Iwe Mimo ti nso bi kristieni se ndagba (I
Pet. 2:2). Eyi yoo mu dagba ninu igbe aye kristieni re lati maa gbe igbe
aye re fun Kristi.
Die niyi ninu awon akori eko naa:
1. Igbala
2. Idaniloju
Igbala
3. Adura
4. Akosori
5. Igboran
6. Itoni
7. Sise
deede ni ile Ijosin
8. Ififunni
9. Ijere
Okan (a.b.b.l).
2. ABALA IGBEKALE EKO
Eyi nii se pelu igbekale eko Bibeli. Nibi
ti awon onigbagbo ti ng ni imo ti won si nduro ninu igbagbo aaye ti a sin ran
lowo lati gbe igbe aye sise deede. II
Timotiu 3:16-17.
Awon eko naa niwonyi:
1. Olorun
2. Igbala
3. Isodi
Mimo
4. Ese
5. Kristi
6. Ijo
7. Satani
9. Eko
nipa ohun/isele ikehin (a.b.b.l.).
3. ABALA OMOLEHIN
1. Ijere
Okan
2. Itopase
3. Igbanimoran
4. Gbigbadura
fun elomiran
5. Sisakoso
akoko a. b. b. l.
Niwon igba ti o je wipe ilepa itopase ni
lati so gbogbo olukuluku eniyan di omo lehin Kristi, o wa se Pataki fun awon
asese gbagbo lati mo bi o ti ye lati maa rin deede ninu ile ijosin fun itoni
tabi idanileko fun ijadelo, pelu ete bibi elomiran tabi lati di pupo si.
Omolehin tumo si Kristieni ti o ndagba gege
bi iri Kristi, ti o njere okan fun Kristi, ti o si nko awon asese gbagbo lati
dabi Kristi. Fillipi 3:3-10; 9:16;
Kolose 1:28-29.
No comments:
Post a Comment