GROUND
OF TRUTH BIBLE INSTITUTE
G.P.O
BOX.17171 IBADAN NIGERIA
ILANA
FUN JIJE ADARI KRISTIENI
IDAKORO
ENI IDUROSINSIN
Ni
gbogbo igba ti Olorun ba fe se ohun kan, Olorun nilo eniyan ti o duro sinsin ti
yoo lo latu gbe ete ati erongba okan Re jade nitori laisi eni idurosinsin yii
ti Olorun yio lo, ko si Ohun ti Olorun lee se (Ezek 22:30)
Eni Idurosinsin yii je adari fun Ise
ti Olorun fe se naa.
Yoo duro gege bi apa Iran naa mo,
eyi ti a si gbe ojuse ati mu ise naa se le lowo.
Ninu awon ohun ti Emi, adari ni eni
naa ti o duro ni Ipo Olorun lati se ise Re, pelu igbekele tabi ifowosoya pe ko
ni se ohun miran, yato si ohun ti Olorun fi le e Lowo lati se (Jn 9:4; 4:34)
Jesu gegebi aduro sinsin ati Oludari ti a gbe le lowo ati ise ti a ran-an ati
lati pari ise naa.
Nitorina eni idakuro (aduro sinsin)
yii ni awon ojuse kan ati awon eronga kan ti a nreti lati owo re. Awon ohun ti
o ye ki ose, ati awon Irin ise ni idari nbeerre fun.
Sugbon ohun ti a npe ni adari maa n
ni orisirisi itumo si awon eniyan, nitori naa, Jesu fun wa ni apeere ohun ti o
tumo si lati je adari nipa ti Emi.
“Nigba
ti awon mewa yoku gboo, won binu si awon arakunrin won mejeeji sugbon Jesu pe
won sodo re o si wipe, Eyin mo pe awon oba keferi a maa lo agbara lori won, ati
awon eni nla ninu won, a maa fi ola teriwon ba, Sugbon ki yoo ri bee laarin
yin, sugbon enikeni ti o ba fe po ninu yin, E je ki o se Iranse yin, ati
enikeni ti o ba fe se olori ninu yin, E je ki maa se omo odo yin” (Matt
20:24-27).
“Ija
kan si nbe laarin won niti eni ti a ka si Olori ninu won, O si wi fun won pe
“Awon oba keferi a maa fela lori won, a si maa pe awon alase ninu won ni
oloore, sugbon eyin ki yoo ri bee, Sugbon eni ti o ba po ju ninu yin ki o je
bii aburo, eni ti o si se Olori, bi eni ti o nse Iranse”.
Adari nipa ti igbekele Jesu ko ni
ohun kohun lati se nipa ijegaba, lilo ipa tabi agabre, tabi gbigba awon oye
kanka-kanka etc. ni kukuru, jije adari tumo si sise iranse fun awon ti o kere
si ni ni Ojugba, tabi sise Iranse fun awon eniyan.
Ninu abala bibele ti a toka si yii,
Jesu je ki o di mimo pe Orisi adari meji lo wa.
1. Adari awon keferi tabi Ara
2. Adari Kristeni tabi Emi.
Nipa
ero ti Jesu Oluwa, adari ti Emi je idakeji awon eyi ti ari ninu aye laarin awon
keferi tabi awon alaiwa bi Olorun.
BI A
SE NMO AWON ADARI NINU AGBO
Awon
orisiris eniyan meta ni o ma nwa ninu agbo. Awon naa ni:
1
Awon
Oluse
2
Awon
Oluworan
3
Awon
Koseese

5% Awon Oluse
25% Awon Oluworan
70% Awon Koseese
OLUSE
: Awon egbe yii maa
nto meta ninu mewa. awon egbe akoko yii ni awon to gbagbo pe o seese, awon yio
si je ki isele sele. Awon wonyi ni awon Oluse ninu agbo. Awon ki iju ida marun
ninu ogorun. Lati inu idamarun yi ni
awon adari ti maa njade wa. (Numeri 13:30, Owe 29:2).
OLUWORAN: Awon egbe keji ni awon ti o gbagbo pe
o seese ki nkan sele, o si le ma sele, eyi ti o ba wu ki o ri, e je ki a lo
woran. E je ki a lo wo bi yio ba se sele.
KOLESEESE: Awon ebge ti o keyin yi ni awon ti
won gbagbo pe ko si ohun ti o le sele, won gbagbo pe ko le seese. Awon egbe yi
lo ma nsaaba po ju ninu gbogbo apejopo.
ADARI TI ARA ADARI
TI EMI
1. A maa debe nipase awon eniyan Je ebun lati odo Olorun
2. A maa ja
lati taku sori oye Maa
nri ipo gege bi anfaani lati sise
3. A maa bo ese re mole A maa sipaya
asise re, a si bebe fun idariji
4. Nilo ogbon alumo-nkoroyi Kan nilo Emi Mimo nikan
5. A maa wipe ese ohun ti mo wi A maa wipe, “E ma se afarawe
mi ni apeere Jesu
6. Ranju mo owo Tejumo awon okan ti yio
jeere
8. Feran iyin awon eniyan Feran ise ti o
dake, ti o si farasin
9. Feran oruko oye ati apele A maa duro de ifororo
yan ati afihan Olorun
10 A maa se ohun ti o wu eniyan A maa gbase lowo Olorun lati
se ohunkohun
A kii mo adari ti Emi nipa ase (apase
waa) tabi agbara ti won nlo lori awon eniyan nitori ipo won gege bi asa awon
alaigbagbo, a ko gbodo mo adari nipa awon “apele re” tabi awon oye kanka-kanka,
sugbon a gbodo mko (adari) pelu amin sise ise iranse.
Iru adari ti Jesu kii se olominira kuro
lodo Olorun sugbon o ma nse ohun gbogbo gege bi asoju fun Olorun (Kii se ohun
timo wu u, bikose ohun ti Olorun ba fe ki o se)
AWON
IDI FUN ADARI NIPA TI EMI
a)
Olorun ko lee se ohunkohun laisi won:-
Ekso 3:7-10
Olorun si wipe “Nitooto, Emi ti ri
iponju awon eniyan mi ti o wa ni Egipti mo si gbo igbe won nitori awon
akonisise won, mo mo ibanuje won, Emi si sokale wa lati gba won lowo awon ara
Egipti, ati lati mu won goke ti ile naa wa, wa si ile rere ati nla, si ile ti o
nsan fun wara ati fun oyin si ibi ti awon ara Kenaani, ara Hitti, aawon Amori,
awon Perisi, awon Hiffi ati aawon Jebusi wa.
Nje nisinsinyi, kiyesi igbe awon omo
Israeli de odo mi, Mo si ti ri pelu wahala ti awon oba Egipti nwahala won,
nitori naa wa nisinsinyi, Emi o si ran o si Farao, ki iwo le mu eniyan mi, awon
omo Israeli lati Egipti jade wa”
Bi o tile je pe Olorun so pe oun ti
sokale wa lati gba awon eniyan Oun, sibe Olorun nwa eniyan ti yio ran, sisokale
Olorun iba je ohun ti ko wulo ti ko ba ri eni ti yio ran.
Eyi tumo si pe adari ti Emi je ohun
elo Pataki ti Olorun yio lo nibikibi fun ise Re. Mose yio wa di eni Pataki ni
owo Olorun ti erongba Olorun fun aye re ba wa si imuse.
Bi o ti wu ki iran ijo gbooro to,
ohun kohun ti Olorun lee so nipa ijo, orile-ede tabi ebi, ti ko ba si ohun elo
Pataki ti Olorun lee lo, ko si ohun ti Olorun lee se, a fi gba ti Olorun ba ri
eni ti O lee lo fun ipo naa, gbogbo erongba Olorun tabi ete Re ko lee wa si
imuse.
b)
Olorun nilo iboju fun ara Re: - Gen.
1:26; 2: 1-7
Lati igba iseda, Olorun ri idi lati
mu imole wa si aye ki isudede ohunkohun ti o subo aye ninu Gen 1:2 maa ba ni
ipa lori aye, ki o maa baa ba aye je, ati lati mu aye sofo.
Nitorinaa, Olorun pinnu lati da
aworan ara Re si aye, aworan Re yii ni o fi pamo sinu amo, ohun ti ari ni ita
ni amo, (ile ti a ko fun Olorun ) sugbon ninu amo yii ni Olorun wa, lati igba
yii ni Olorun ko ti fi ara Re han mo gegebi Olorun lati se awon ise kan ni aye.
Ohunkohun ti Olorun ba fe se, nipase
eniyan lo maa ngba nse, o fi ohun gbogbo ti o wa laye fun omo eniyan, ti Orun
je aafin Re (Ps. 115:16)
c)
OLORUN NILO OHUN ELO IYASOTO: - Is. 6:
6-8; Jer. 1:5,7
Ohun ti Olorun mba wo iya ija nigba
aye woli Isaiah kii se eni ti Olorun yoo ran, “Sugbon tani yoo lo fun wa”.
Opolopo awon adari ti a ti ran tele
ri lo ti lo fun ara re, won dibon bi eni pe won ni idunnu si ohun ti Oluwa ti
ran won lo se, sugbon, nigba ti a ran won, ohun ti a ra won ko ni won lo nse.
Opolopo oloselu, ti won npolongo ibo pelu orisirisi ileri ni won maa ngbagbe,
awon ti o dibo yan won, ni gere ti a ba ti se ibura fun won.
Sugbon adari nipa ti emi ni o nilo
lati se ohun gbogbo gege bi ilana ti Olorun ati fun Olorun.
Olorun so fun Jeremiah ni Jer. 1:5,7
“Ki Emi ki o to da o ni inu, Emi ti mo o, ki o si to ti inu jade wa ni Emi ti
so o di mimo, Emi si ya o soto se wolii
fun awon orile-ede, subgon Oluwa wi fun mi pe, ma wipe Omode ni emi, sugbon iwo
o lo sodo enikeni ti Emi o ran o si, ati ohunkohun ti Emi o pase fun o ni iwo o
so”
Oro “Iyasimimo” tumo si iyasoto”
Olorun maa nfe ki iranse re je ti Oun nikan.
Ko soro lati ri awon ti won npe ara
won ni “Iranse Olorun” lonii lati ri ohun ti won nsin. Opolopo awon ti won pe
ara won ni iranse Olorun ni won nsin ohun miran, idi niyii ti Olorun se nilo
Iranse ti yoo lo si ibi ti Olorun ran won nikan ati se ohun ti Olorun fe ki won
se, ki won si so ohun ti Olorun ni ki won so.
Odi igba ti Olorun ba ri aduro
sinsin kan ki o to lee fi idakoro ise adari ti emi le iru eni bee lowo, awon
eni ti won sin ni otito ni aye igbaani ni awon iwa amuye naa.
IMURA
SILE ADARI TI EMI. Lk 1:80, 2: 40,52.
A kii bini bi adari, sugbon a maa n
pese (mura sile) eniyan bi adari ni. Ipaya nla ba Mose nigba ti arakunrin
Israeli naa bii leere wipe talo fi o je Olori ati onidajo lori won (Eks. 2:13,
14,Ise apos. 7:25)
Ko si enikan ti o le je adari ohun
ti Emi lai je pe ati mu la awon ona iyiri wok an koja. Gbogbo awon eniyan ti o
ti keru, keru fun Olorun ninu Bibeli ni won ti la awon akoko imurasile kan tabi
omiran koja ki won to je ohun ti won je. Olorun kii se eni ti ko ni osuwon tabi
gbedeke, awon ohun Pataki kan gbodo wa ninu aye awon eni ti a npe ni adari ti
Emi, lati kun oju osuwon naa.
Johanu onitebomi je apeere adari ti
Emi, eniti a ti yiri wo ki a to fi opa ase Irinse Iranse le lowo, lehin gbogbgo
asotele ti a ti so saaju ibi re, “Omo naa si ndagba, o si le ni okan, o si wa
ni iju titi o fi di ojo afihan re fun Israeli” (Lk. 1:80)
(a)
IBI RE: Ohun akoko duro lori ibi adari ti
Emi. Bi o tile je wipe Olorun ti mo Jeremiah ki a to da sinu Iya re, ti a si ti
yaa soto, (fi ororo yan-an) gegebi wolii fun awon orile-ede ki a to bi lati inu
Iya re wa, ohunkohun yowu ti eniyan lee fe je tabi da gbodo duro de igba ti a
ba bii.
Ibi nipa ti ara se Pataki, sibe ibi
nipa ti Emi se Pataki pupo pupo ninu idari ohun ti Emi. A ko lee pe enikeni ni
adari nipa ti emi nigba ti igbala re ba si nmu ifura lowo ti a ko tii ri
idaniloju igbala re.
(b)
IDAGBA SOKE NIPA TI ARA ATI TI OPOLO: “Omo naa si ndagba …………….” ohunkohun
ti Olorun le so nipa aye eniyan, ti idagbasoke nipa ti ara ko ba si, Iran naa
ko lee tii jo. Omo ti ko ba dagba soke nipa ti ara, ti ko lee rin, ti ko lee riran, ti ko si lee soro, bawo lo
se le je nnkan ninu aye? Adari nipa ti emi kii se ohun ti Emi nikan lo ti gbodo
maa dagba. Gbogbo ogbon ile Egipti ni a fi kom Mose (Ise Apos. 7:20-22).
Jesu fun ara re dagba nipa ti ara,
Bibeli so nipa Re pe nigba ti Jesu pe odun mejila, enu si ya gbogbo awon ti won
ngbo oro Re fun oye ati idahun re.(Lk. 2:47)
Agbara oye nbo nipa ti idagbasoke,
nitori naa, adari ohun ti Emi ko gbodo je eni ti ko loye lati moye awon isele
lekunrere.
Idagba soke nipa ti ara ati ti opolo
se Pataki ninu mimura adari ti Emi sile, adari nipa ti Emi gbodo ni ironu nti o
mo gaara, Obi gbodo le ni ero to dangajia, ko gbodo je eni titun (ope) (1Tim. 3:6) omugo kii se ebun Emi.
Oye tabi opolo adari ti Emi gbodo pe perepere.
(c)
IDAGBASOKE NIPA TI EMI
“Omo
naa si ndagba, o si le ni okan...” (LK 1:80).
Oro
“Osi” ti a lo fihan pe idagbasoke nipa ti ara/ opolo gbodo lo papo nipa ti Emi.
Isoro Mose ni pe Mose ndagba nipa ti ara/Opolo, sugbon ko dagba nipa ti Emi.
Nitori,
isepataki Idagbasoke nipa ti Emi, Mose lo afikun Ogoji odun lodo alufa ni
Midiani, ki o to lee kun oju osuwon adari.
O je
ohun isele ti ko mu oriire wa ninu awon Ijo lonii pe awon amuye nipa ti ara
tabi imo iwe nikan ni won nwo gegebi ohun pataki lati yan awon adari. Nitori
naa, ki enikeni to je adari ti o muna doko idagbasoke nipa ti emi gbodo je ara
Imurasile re.
(d)
IRIRI INU AGINJU: LK1 :80; 4:1-14;
DEUT 8:2-3
Inu
aginju je ibi ti a ti njo (se) awon ohun inu okan. O je ibi ti a ti nyi ri
adari emi ti a mimura sile wo, ibi ti a
ti nre sile, fi ebi pa ki a le mo Ohun ti o wa ni ookan aya re. O je ibi ti a
ti nyiri Igboran eniyan ti o ba fe je
adari wo.
Ko da,
ada ri Jesu si iju lati danwo.
Johanu
Onitebomi wa ninu iju “afigba” fihan wa pe ko wa ninu iju titi lae.
Alufa
lo bi Johanu Onitebomi ti tumo si pe ninu Tempili ni o ti ye ki a ko nise
alufaa, ti a ba lo ko ninu Tempili lasan, Iba
ma le gbe eko ti o ye kooro to nilo fun irufe ise agbara ti yoo se fun
Olorun.
Adari ti ko ba ti gba inu iju koja
ko see gbekele. Iru adari bee yoo gba ojege nigba ti ebi tabi Iyan ba de Iru
adari beee ni ewa asan aye yii maa ntan won je.
Iru
adari bee ni gbogbo ohun tire maa nduro lori awon ohun aye.
Adari
ti ko ba ti la iju kija, kii le fi owo to danmoran mu oro Olorun nigba ti ebi
ba de.
(e)
SAFIHAN FUN IGBELEWON AWON ENIYAN (LK
1:80, ISA 41:1)
“...
titi di Ojo afihan re fun Isreali”.
Akoko
kan wa ti Olorun ma se afihan Iranse Re ti o ti nmura sile ki awon eniyan le se
igbelewon re. Olorun so ni Isa42:1 “Won Iranse mi...”
Gbogbo
Iranse Olorun ti awon eniyan yoo gbo tire gbodo je eyiti ti awon eniyan yoo wo.
“Wiwo”
yii tumo si wiwo, fifowo kan, gbigbamu ati kiko ni papa mora, gbogbo eyi ni ki
ale mo Iru eniyan ti o je.
ENITI AWON ADARI ISE
1.
Adari a ma pa iran ati Afojusun kan
mo: Adari gbodo je
eni ti o ni ilepa. O gbodo yago fun awon ayaba, eyi ni ohunkohun ti o le di eni
lowo lati ma de ibi ilepa eni. Adari a maa teju re mo ilepa a si maa ko awon to
ku sodi titi owo won yio fit e ilepa na.
2.
Adari Dabi Amuseya: Kaun ti a fi se onje je amuseya fun
iru onje ti o le, bee ni adari je. Gbogbo agbo ni o rorun fun lati ma se ohun
ti ko to, ni iru akoko be ni adari ni ojuse lati toka agbo naa si ilepa won
nipa sise koriya fun won. Adari a maa so iran agbo ji.
3.
Lati fi Apeere Igbe aye Lele: Adari a maa fi apeere lele fun awon
to ku lati tele. Adari gbodo je awokose fun agbo ti o ndari. Adari gbodo dari
pelu apeere rere.
4.
Lati fi Igbese lele: Adari je eni ti o maa nfi igbse lele.
Akoko kukuru lowa laarin awon eniyan ati ilepa won. Ti a ko ba fi igbesc lele,
o seese ki a ma de ibi ilepa laarin akoko ti o si sile.
5.
Lati Bojuto Ilana Tabi Eto Nipa
fifunni ni Ojuse ati ibawi ninu Agbo:
Gbogbo agbo ni o le daru nipa ija jija. Ojuse adari ni lati tun iru agbo bee
to. Ija tabi ede aiyede laarin agbo ma ndi eniyan lowo ise. A ko le sa fun ede
aiyede patapata, sugbon a le din ede aiyede ku. Jesu ma nyanju ede aiyede nipa
eko, adari ko gbodo fi ete sile ki o maa pa lapalapa.
6.
Oun ni Agba Ironu: Adari gbodo le ronu daradara, o gbodo
ni ore ofe lati ronu jinle. Ilepa ati afojusun ma nfarahan nipa aini awon
eniyan, aini awon eniyan ko si see yipada. Adari gbodo le fimu finle nipa awon
eniyan ti o ko sodi ki o si mo aini won ki o to gbe ilepa re kale.
AWON IWA AMUYE ADARI TI EMI Isa 42:1-4
a)
ENI TI O SEE WO. 1Sam 12:1-3
Ki enikeni
to lee je Iranse tabi adari ti Emi ti yoo le dari awon eniyan Olorun de idi ete
tabi erongba kan pato, o gbodo je eni to “seewo”. Eyi tumosi pe ogbodo je eni
ti a lee gbamu, eni Ojulowo kii se Ifeefe ko gbodo je eni yiyo, o gbodo je eni ti
a le gbamu ki o si duro fun awon ohun ti o ba se.
Adari nipa
ti Emi gbodo je eni ti o see gbelewon fun awon ti O dari. O gbodo je eni ti
nduro fun apeere rere.
Eni ti o see
sunmo, ale ni imolara re, bakan naa lo si le ni imoran ailera awon eniyan
nitori oun naa je eniyan eleran-ara (Heb 5:1-2).
Opolopo
adari ni ko jej ojulowo, ti won je ifeefe iwaasu won ko je bi aye won. Samueli
so wipe “... Emi ti rin niwaju yin lati igba ewe mi wa titi o fi di oni yii,
woo, emi niii, Jeri simi niwaju Oluwa ati niwaju eni ami-ororo re” Malu tani mo gba ri ? tabi
ketekete tani mo gba ri ? tani mo re je ri? Tani mo je ni iya ri? Tabi lowo
tani mo gba owo abetele kan ri lati fi bo ara mi loju? Emi o si san-an pada fun
yin”.
Samueli ko
rin leyin awon omo Isreali, ko se ohunkohun ni ikoko, ohun gbogbo ti o se
niwaju won ni, eyi ti o tumo si nigba ti awon eniyan naa wa nibe, Igbe aye re
ko farasin fun awon eniyan Isreali.
Adari emi ti
o je ojulowo gbodo gbe iru igbe aye Samueli yi ko gbodo je onigbe aye ikoko, o
gbodo je eni ti o see ri fun gbogbo eniyan. Eni ti Igba aye tabi aye re ko
farasin fun awon eniyan.
b)
IRANSE MII. Jer 1:5,7, Jn 4:34; 9:4
Adari nipa
ti emi gbodo je eni ti o nsin Olorun ko ni ohunkohun ti o fe se, ati aye ti
Olorun fi ran ti ko lee se ohun miran yato si ife Olorun. Kii sse ife are re
afi ife Olorun.
Adari nipa
ti emi maa nni Idunnu ninu sise ife Olorun.
Jesu je
apeere pe nipa adari ti emi fun-un lati se ise.
Je dandan,
ise naa si gbodo je ise Olorun ti o ran –An (Jesu) Jesu ko ni ise tire.
c)
ENI TI OLORUN GBERO Jn 5:19-20
Adari ti emi ti o je ojulowo gbodo je
ni ti ko duro fun raare bikose fun Olorun, eyi ti o tumo si pe Olorun ni koko
ninu aye re. Ti a ba ti yo Olorun kuro, ko je nnkankan. Kii se ohunkohun nipa
ilakaka re, ko si je Olominira.
Adari
ti emi ko gbodo duro lori imo, ogbon, iriri etc. ara re; bee na ni ko ni ohun
aseyori tabi amuyangan ayafi Olorun.
Eni
ti mo pe ki si ohhun ti o gbe oun ro afi Olorun, ko gbodo gberaga. “Eniti mo
gbero” ti aba ya Olorun kuro, ko sohun to gbero, Laisi Oloru, adari rere ti emi
mo pe eni ile lasan lasan ni Oun.
d)
ENI TI INU OLORUN DUN SI Lk 3:22; Jn 5:20
Adari ti emi
gbodo je eni ti Inu Olorun dun si ogbodo ni aye (kii se Iwaasu lasan) ti o ba
ife Olorun mu.
Ti Olorun ko
ba ni ife si aye adari ti Emi bawo lo se fe maa fi ise agbara tabi asiri ran?
Eyi tumosi pe adari ti Olorun gbodo ni idi lati dun nu si igba aye adari bee.
Ohun ti
adari emi rere gbodo lakaka lati ni ni igbe aye ti inu Olorun dun si.
Ibasepo ti o
gunrege laarin adari bee ati Olorun gbodo se dandan sii ogbodo ri daju wipe
ohun kankan ko ba ibasepo to gunrege laarin oun ati Olorun je, nitori nini
Ibasepo ti o dara lo le mu ki o maa loye awon asiri Ijinle.
e)
ENI TI O NI EMI-OLORUN Isa 11:1-2
Bi o tile je
pe Opolopo nnkan ni oye ki a ko nipa Emi-Mimo, sigbon nipa ififun ni emi mimo
nibi yii, kii se lati mu ki Iranse fi emi soro nikan, sugbon lati sa fihan bi
Olorun se je fun raa re ninu aye Iranse naa.
Nigba ti Elisha ri ohun ti o beere
Elijah gba tan, bi o tile je pe enikeni ko.
Mo nipa
ibeere yii, sibe awon omo wolii ti won wa ni idakeji odo Jordani nigba ti
Elisha nbeere ohun ti o fe so pe “Emi Elijah be le Elisha” ohun ti o mu oro yii
wa nipe iru ohun gan-an ti Elijah se naa ni Elisha se. O tumo sipe nigba tie mi
Olorun ba wa lori aye eniyan. Iru Olorun tabi iseda Olorun gbodo di mimo ninu
re.
Nitori naa,
o tumo si pe adari nipa ti Emi ni eni naa ti o ni iru Olorun ninu re eni ti o
gbe ohun ti Olorun nfe laruge, ti o si le korira ohun ti Olorun korira.
f)
ENI TI KII SE ALARIWO
Adari nipa
ti Emi kii se eni ti o nfon rere ara re tabi si ohun ti o ban se.
“On ki yoo
kigbe, bee ni ki yoo gbe ohun soke, bee ni ki a gbo ohun oun ni igboro” (Isa
42:2).
Jesu ko
polongo tabi fonrere ise Re tabi ara Re.
Opolopo awon
eniyan lo kilo fun pe ki won mase polongo awon Ise agbara Re. Jesu je idakeji
awon ohun ti a nri loni, nibi ti awon eniyan Olorun tin lo opolopo owo ati ara
fun ipolongo.
g)
ENI TI KII SU TABI RE (Isa 42:3)
“Iye fifo ni
oun ki yoo se, owu ti nru eefin ni oun ki yoo pa; yoo si mu idajo wa si otito”
Adari nipa
ti Emi ma nni Ipamora, o maa nfarada ohun pupo, nnkan kii tete su.
Jesu ko je
kik oro Peteru ati Tomasi O su oun. Oro marku ko su Barnaba titi di igba ti o
fi eni ti o wulo gidigidi ninu ise iranse Paulu.
AWON
OHUN TI O LE PA IDARI RUN
1.
AIJAFAFA NINU EMI: Aijafafa ni emi maa nsele nigba ti
adari ko ba le gbo itoni mo lati orun. Ira adari be ni eni ti a so pe o ti kuro
niwaju Olorun ni iru akoko bee, ko ni le gba oro lati odo Olorun, eni ti o yan
si ipo adari.
2.
IGBERAGA: Igberaga ni nsiwaju iparun. Nigba ti
adari ba jo ara re loju, ti o siro pe, koseemani ni oun je, nigba naa ni ijoba
re nsubu. Nigba ti adari ba fi ara re si ipo Olorun ki nipe subu ni ipo adari
ti o wa.
3.
IFI-AGA-AGA-GA: Eleyi ma sele latari owu jije, tabi
nagba ti idagbasoke enikan ninu agbo ba nderu ba adri. Adari ti ma nfi igba
gbogbo baa won eniyan re ja ko le kese jari.
4.
SISO OPOMULERO TI EMI NU: Adura, kika oro Olorun ati aawe je
awon opo lori eyi ti igbe aye adari sinmile. Ti adari ba ti so awon wonyi nu,
ko nipe ko ni jina ti yoo fi bere si ni ni isoro pelu ojuse re. (Ise 6:1-4) Ni
gba ti awon opo wonyi ba ye, ko to ki iru adari bee maa se bojuboju pelu
orisirisi eto fun ijo. O ye ki o tete sa to Olorun lo fun ina otun.
EKO
NIPA IHUWASI EDA
Eko nipa
ihuwasi eda da lori nini oye iwe eniyan. O je ona lati mo nipa are eni ati awon
elomiran. Ki eniyan to le mo nipa iwaa re, o ni lati se ofin toto nipa ipile
eni naa. Opolopo adari ni o je isoro fun lati ni ajose po pelu awon eni ti won
ndari, nitoripe won se alailoye nipa awon otito Pataki kan nipa awon ti won
ndari.
Idi wa fun
bi awon eniyan ti maa nhuwa, a silee so awon idiwon yi mo ipile mefa ti eniyan
maa nri. Lk3:10-14
1.
IPILE EBI: Ipile ebi eni kookan ma nko nipa ipa
Pataki ninu bi eni ti o tie bi naa jade wa semaa huwa ni awujo. (Est 3:2;6:13)
Ebi Modekai lo nso iru iwa ti Modekai nhu ni ita. Si Hammani, Modekai je
agberega, sugbon si Modekai, oun kan hu ohun tie bi re gbagbo ni iwa ni.
(Jer35:1-10) Awon omo Rekabu kii mu oti waini beeni won ki kole. Eyi je iwa ebi
won, Olorun pelu si moo fun won. (Gen 46:31-34;47).
2.
IPILE ADUGBO/AYIKA: Ipile adugbo a maa nipa lori ihuwasi
eniyan. Omo ti o dagba ni kotasi ki yoo huwa bi omo ti o dagba laarin gbungbun
ilu. Mose dagba laafin nitori naa oungbe lati je olori lo sun lati hu iru iwa
ti o hu. (Ek 2:11-14) Isowo kowe Mateu fi han pe ju ni ise.
3.
IPILE EKO/ISE: Eko je ifitonileti tabi ise ti a
kojopo nipa opolopo ifitonileti. Ti eniyan ba ka ihinrere ti a ti owo Luku ko
sile too ri daju pe ni tooto onisegun ni Luku un se. O tenu mo ise iyanu to da
lori iwosan pupo ju awon miiran lo. Johanu so oro pupo nipa igbe aye Jesu niti
emi ju awon to ku lo.
4.
IPILE ASA: Asa Sedraki, Mesaki ati Abednigo ni
ko gba won laaye lati teriba fun orisa-korisa won si satan lati ye ese kuro
ninu ipile yi, bi o tile mu iku dani. Awon ara ile Ibo kii dabale ki agbalagb,
nitori naa, adari ti o ba je Yoruba yoo ro pe Ibo naa ngberaga si oun nitori ko
doable lati kii.
5.
IPILE ESIN: Esin je ohun ti okman, o si je ohun to
se Pataki pupo ninu igbe aye eniyan. Gen 46:33-34. Nipa esin Egipiti kii pa
maalu, won si maa n wo enikeni ti o ba nsin eran bi maalu gegebi eni irira.
Ipile esin awon ara Egipiti ko gba aye fun Isreali lati maa gbe pelu won.
6.
IPILE ITAARA: Laarin gbogbo ipile mefa wonyi, ti
itara nikan ni o da yato. Marun akoko ma nwa nipa kigbe po pelu awon eniyan,
sugbon ipile itara je eyi ti a bi mo ni. O je ohun anutorun wa. Eleyi ko se ko
nibikibi, ni ona kan itara ma ni ipa lori iwaa wa.
AWON
ITARA ENIYAN
1.
Oloyaya: Oloyaya je eni ti rorun lati ba rin.
O ma adore pupo, a maa nse ipinnu kiakia lopo igba lairorun ki o to see. Kii ni
arojinle. O turaka a si maa ba gbogbo eniyan sere.
2.
Onironu: Oniro ki se ipinu kiakia ironu. A maa
lo asiko pupo lati fi ronu lori oro kansoso ki o to se ipinu. O je eni ti o maa
nwo nkan finifini. A maa ko ohon re ni ijanu. Kii saba soro, o je eni ti kii so
ti inu re sita. Ki nsaba se yeye kaakiri. Nitoripe o maa nlo akoko pupo lati fi
ronu, opolopo anfani lo ma nbo sonu moo lowo.
3.
Apase: Apase ko iwa oloyaya pupo mo ti re
nitori pe oun a maa sare se ohunkohun, o le gbe laarin awon eniyan o ko eniyan
mora, sugbon ko gba iwosi lati odo enikeni. O je onise, O nko awon eniyan sise,
kii si tete ree.
4.
Olofintoto: Olofintoto je enikan ti o ma n wo
nkan ni finifini. O je olusiro to moyan lari. A maa pa ilana ati asa mo.
Kogbodo ninu asise o le pupo a maa se ohun gbogbo gegebi ilana ti a fi lele.
Kii saba yi awon eto ati ilana atijo.
Gegebi
adari, o ye ki o ye wape gbogbo koko oro wonyi ni a maa ni ipa nla ninu bi
eniyan se nhuwa ati bi o se nronu.
Gege bi
adari, eniyan gbodo no iru iwa ara re papa itara re kio si gbiyanju lati yanju
awon isoro ti o ndoju koo pelu Gal 5:22-23.
OJUSE
AWON ADARI NIPA TI EMI
Awon aguntan
ninu ese oro Olorun yi ni awon eniyan (Onigbagbo) ti won je ti Jesu.
Aguntan ki
dabii ti awon ewure. Idi niyi ti won se nilo eni ti yio maa to won sona.
Bakan naa ni
onigbagbo gbodo dabi aguntan ti o si ni adari lati maa dari won; eyi tumo si pe
gbogbo egbe onigbagbo kookan ni Olusoaguntan (adari) ttt yio maa dari won.
Adari t Emi
bi ti Olusoaguntan ti o boju t oagbo aguntan, yio maa gbadurafun won nigba ti o
ba ye.
O nseso lori
awon eniyan. O nbo won. Kii bo ara re lati ara won (Jn21:15).
Ki Olorun ki
o ri o bi adari rere. (Amin).
No comments:
Post a Comment