Wednesday, March 26, 2014

DIDAGBA ATI BIBOJUTO IBASEPO TO MUNA DOKO PELU AWON AKEKO



DIDAGBA ATI BIBOJUTO IBASEPO TO MUNA DOKO PELU AWON AKEKO
IRANJADE
Ibasepo tumosi “ipo sisopo pelu awon eniyan. Eyi ni ohunkan to so timotimo laarin awon eniyan, egbe, tabi orile ede”
Apeere, aja kan le wa laaye lai ri tabi ba ja miran se titi ojo aye re, sugbon eyi ko ri bee fun eniyan! Yio nira fun eniyan lati wa laaye ni oun nikan. Lati ojo akoko ibi re titi di igba iku re lai ba elomiran se.
Eyi ni yio mu wa lo si igba atetekose, Olorun rii wipe bi oti dara ati lewa to eniyan ti o da. Fun okunrin yi lati dawa ni Olorun ri wipe ko dara! Olorun ri wipe Okunrin yii nilo ibasepo, eyi mu ki Olorun da Obinrin fun (Gen.2:18).
Jesu fun oro yi ni okun nigbati o ran awonomo eyin re jade lo si awon ilu ti koni se alaibewo Bibeli wipe:
“Leyin nkan wonyi, Oluwa si yan adorin omo-ehin miran pelu, o si ran won ni mejimeji lo saaju re, si gbogbo ilu ati ibi ti on tikarare yio gbe de. O si wi fun won pe, ikore po, sugbon awon alagbase ko to nkan. Nitorina e be Oluwa ikore, ki o le ran awon alagbase sinu ikore re.
Emu ona yin pon, sa wo o  Emi ran yin lo bi odo-agutan sarin ikoko. E mase mu asuwon, e mase mu apo tabi bata, e ma si se ki enikeni ni ona”. Luke 10:1-4 (kjv).
Botile sse je wipe Jesu ko gbawon laaye lati mu apo, eyi ti nse owo, ayi ti nse bata fun irin ajo won. Oun kan nbe ti Jesu fi dawon loju pe won ni bi won ti nlo eyi naa ni Alabasisepo! Kosi eyikeyi ninu awon omo eyin ti o se alaini alabasisepo. Jesu, nipa eyi nje ki oye wa wipe eniyan lese aseyori ninu ise iranse laisi owo ninu apo wa. Jesu nso wipe alese aseyori ninu ise iranse bi o ba ti e je wipe kosi nkankan ninu apo wa bi awon oun  wiwo, aso ati awon ohun miran ti ale nilo alase se laisi awon nkan wonyi, eyi ti opo eniyan kasi nkan pataki fun aye wa ati ise iranse, sugbon otito ni wipe ako le se laisi alabasisepo tabi ibasepo!
Jesu nso wipe eniyan le se aseyori ninu ise iranse bi o ba le ni ona taara si ibasepo o le mani anfani si owo repete.
O se pataki fun wa lati mo awon akeko wa le manilo opo owo wa bi won se nilo wa! Otito ni wipe awon eniyan ko fe mo bi o ti se mo to sugbon iye ife ti o fi nhan. Bi o tile je wipe ako ni owo tabi aso lati fifun awon akeko wa, won si le je ohun ti Olorun fe ki won ki o je bi a ba fi ojulowo ibasepo fun won!
Otito ni wipe ibasepo rere ati eyi to munadoko pelu awon akeko wa ni o se pataki bi won yio ba de ipele ti o ga ati ti iwabi Olorun.
IMUDAGBA ATI SISE ABOJUTO IBASEPO TO YE KOORO
Bibeli gbawa niyanju:
“Eje ki a ye ara wa wo
lati ru ara wa si ife ati si ise rere: ki a ma ko ipejopo ara wa sile gege bi asa awon elomiran; sugbon ki a ma gba ara eni niyanju: pelupelu bi enyin ti ri pe ojo ni nsunmo etile”. Hebrews.10:24-25 (Amp).
IFISISE ORO AJOSOPO
·        Kini itumo oro wonyi: Eje ki, Kikiyesi; Bibojuto nigba gbogbo
·        Kini itumo gbolohun yi: Ye ara wa wo lati ru ara wa soke si ife ati ise rere.
·        Kini otumo si lati ma so ara wa?
·        Iru agbegbe tabi ayika wo lati le se eleyi? (Heb.10:24-25)
Bibeli pa lase fun wa lati fi ara wa fun iso loni enikeji abojuto to dara ati bibojuto nigbagbogbo. Ni or miran, bi ati joko lati wo awon eko ti ama ko awon akeko nigba gbogbo, eni lati jeki O kun opolo wa lati ma bojuto won nigba gbogbo. O ye ki awa pelu ise sisse nipa bawo ni ase le ma so eso lori won. Eyi duro lori ayika ati awon okunfa miran. Bi ojo ori, eya ipo igbeyawo, ise ile ti won ngbe etc. Bi apeere koni dara ki odo binrin ti o je oluko ile eko ojo isinmi, lati ni ibasepo pelu odo kunrin ti ko ti gbeyawo lati ma seso lori re.
IBASEPO ELENIKAN SI ENIKAN (Gen.18:17-19)
Ni iwon igba ti oje wipe ibasepo ni isopo laarin eniyan meji, eyi tumosipe kole si ibara-eni-sepo laisi ibadore. A kole se aseyori nipa irunisoke tabi mimu ki enikeji ni ife tabi lati ranni lowo lati se awon ise rere bi alafo bawa nini ibasepo wa tabi bi ko ba si ibasepo timotimo. Kosi omo ekose ti o le dabi oga re laisi ibasepo timotimo pelu oga re lati ri oun gbogbo ti oga re nse. Ko si ona ti ale fi mu ki awon akeko wa fi oun ti a nko won si ise bi won ko ba ri anfani lati ri wa ti awa naa nse bee.
Ibasepo ti o dara pelu awon akeko ni ise pelu siso ara wa di ore won ati ni igba miran, pipe won wa si ile wa, ki won le ri bi atise nfi nkan naa si ise,  o tun nise pelu lilo ma bewon wo lati ye mu okan won le nipa oun ti a nko won, eyi yio ranwalowo lati ri ibi ti won kusi ati ibi ti won ti nilo iranlowo, yio si ranwolowo ninu adura wa fun won ninu eko ti a nko won.
Owo ibadore tabi ibasepo ti Olorun naa si Abrahamu so di olusipe tabi sodi aladura isipe. Abrahamu dagba de ipele ti o fi ni igboya lati Olorun leere nitori Olorun fe ara re han fun bi ore. Awon akeko ni won yio se ohun ti o to bi aba fi ara wa han fun won bi ofe.
AYE OLUKO (Acts.1:1; Judges.7:16-18)
Kinse nkan gbefe lati je oluko. Oluko je oluse (Acts.1:1). Okunrin tabi obinrin, ti o nkoni, nilati koko gbagbo ninu oun ti o nkoni aati irufe Oluko be nilati ma rin ninu ohun ti o nkoni.
Ikoni ni sisoni domoleyin. Awon akeko ni a ngbe niyanju nigbati won ba ri eniti o nfi oun ti awon eko ti ako ni yara ikeko  si ise. Eyi ni yio fun akeko ni anfani lati sunmo oluko bee ati lati ni ibasepo ti yio pe titi. Awon eniyan bi Nicodemu Zakeu ati awon bee rii wipe ororun lati wa sodo Jesu nitori igba aye eko ti o nkoni ti won ri ninu re (Johanu.3:1-2; LK.19:2-9).
JIJEKAN PELU AKEKOO (Johanu.11:1-4, 33-36)
O se pataki fun wa lati mo wipe idi wa fun ati so arawa po mo akeko ninu aini won tabi ni akoko iyiriwo won, bi aba ni ife si imudagbasoke ati ibasepo ti o ye kooro pelu won Jesu sokun lati wa ni okan pelu awon  ore re ninu isoro won. A ko le fa ar wa seyin kuro lodo awon akeko wa sibe ki a si tun ma reti wipe won yio keko lati odo wa.

No comments: