IGBE AYE OLUKO
ILE EKO OJO ISINMI
AFIHAN: Ohunkohun ti o ba pinu lati je fun
Olorun bere pelu igbe aye re gan, eyi ri be nitori pe o ko le fun ni ni nnkan
ti wo gan ko ni, eyi ri be nitori pe igbe aye kan lo bi igbe aye kan.
Agbara eni
ti o ju okuta ni yio so nipa ibi ti okuta na yo rinde. Bi o tile je wipe opo
ohun kan ni okuta yii le se, sugbon ki yio le se lai si agbara lati inu; enikan
gbodo juu ki o to kolu ohun ti a foju sun. Bakan naa ni ori pelu oro Olorun, bi
igbe aye eni ti o fe lo oro Olorun ba ti ri yoo so nipa ohun ti o le sele ninu
aye awon Ologbon. Eleyi ni o so nipa boya ipa oro naa yoo duro pe titi ninu
okan won tabi beeko. Ti o ba ni aye to dara, eko re yoo wa ni okan awon akeeko ni
ona ti o muna doko, yio si se awon atunse ninu aye won.
Ninu gbogbo ise asela, ise Olorun nikan soso ni o n pe fun
igbe aye to dara ki eniyan to le se aseyori ninu re. Sugbon ninu awon ise
miran, kiisi atejumo ti o po nipa igbe aye niwon igba ti eni na ba je
akose-mose ninu ise re. Sugbon ise ti Emi ko ri be rara; igbe aye re le mu
ibujade tabi atuka ba ohun ti Olorun ran
e.
IGBE
AYE KORO ATI IGBANGBA TI OLUKO ILE EKO OJO ISINMI
A.
KINI A NPE NI IGBE AYE KORO?
Koro
ni a le se apejuwe re gege bi adani, ikoko ati asiri. Lati inu alaye itumo ti o
wa ni oke yi, ale so wipe igbe aye koro je igbe aye ti a gbe nigba ti awon
eniyan ko si nibe.
Oje
ohun ti o dun lati gbo wipe igbe aye yi ni inu Olorun ma ndun si, eyi ri be
nitoripe gbogbo eniyan ni o ma nse looto nigba ti o ba ku ohun nikan. Nitori
na, nigba ti Olorun ba nwa eni ti yio lo tabi gbe ga, igbe aye koro eni na ni
ibi akoko ti yio koko wo.
B.
KINI A NPE NI IGBE AYE GBANGBA?
Igbe
aye gbangba ni igbe aye ti a gbe niwaju opo eniyan, eyi ni awon ohun ti a se ni
ojutaye ti gbogbo eniyan le ri ki won si f’owo kan.
OLUKO
ILE EKO OJO ISINMI ATI IGBE AYE KORO
Gege
bi a ti so siwaju, bi okuko ile eko ojo isinmi kan ba kuna ninu igbe aye
re
ikoko, iru eni na ti kuna ninu ise iranse re ni ita gbangba. Ikuna ati ailere opo
awon iranse Olorun loni ni a le topase re de ibi aibojuto igbe aye ati ihuwasi
won ni ikoko.
AWON
EROJA IGBE AYE KORO TI O DARA
1. Gigbe igbe aye mimo
2. Sise asaro ninu oro Olorun
3. Nini igbe aye adura ti o dara
4. Jijeri Ihinrere Jesu
5. Kikiyesi didawa pelu Olorun
Nigbati Oluko ile eko ojo isinmi ba ngbe igbe aye alairiwisi
ninu gbogbo iwonyi, ale fi irorun wipe iru eni na ni eni emi pataki. Ani apeere
iru eyi ninu Bibeli Mimo:
Nigbati
ikunsinu dide nipa ipinfuni onje ojojumo fun awon opo ninu Ise A. A.6:1-3. Awon
Aposteli wipe:
“Nitori naa, ara, e yan okunrin meje
laarin yin, ti won ni oruko rere, ti won kun fun Emi Mimo ati fun ogbon” Ise.
6:1-3.
Lati inu ibi ti a ka
yi, a se akiyesi wipe ohun agbeyewo akoko ni igbe aye eniti yio se ise na, Awon
Aposteli beere fun “awon Okunrin oloruko rere” Eniyan ti ko ba ni oruko rere,
ko le ni ise iranse rere:
a.
Nigbati
arakunrin Poolu nba Timotiu soro ninu 1Tim. 4:16, o wipe “se akiyesi ara re ati eko re daradara” Bi aba wo ese yi
dunju-dunju, a o ri wipe ohun akoko ti Poolu soro nipa re ni igbe aye iranse
siwaju ki o to soro nipa eko, eyi tiise ise ikoni.
Siwaju ki a to se agbeyewo ohun ti a
o ko awon akeko, ohun akoko ti a gbodo yanju ni igbe aye wa, eyi si ri be
nitori pe aye re se pataki ju ise iranse re lo!
b. Ninu isele ti Noah, a se akiyesi wipe
nigbati Bibeli nse afihan Noah, nse ni o bere pelu igbe aye re siwaju ki o to
so nipa ise iranse re.
“Eyi ni iran Noah: Noah se olooto ati eni ti o pe ni ojo aye re, Noah nba
Olorun rin” (Gen. 6:9)
Gbogbo awon koko wonyi fi han wa wipe
igbe aye koro se pataki ju ise iranse re lo.
APEERE AWON TI WON NI IGBE AYE KORO TO
DARA
1.
MOSE: Ale ko opolopo eko lati inu aye
Mose, fun apeere:
a. Aye wa ni agbodo mura re sile ti a o
ba ri Olorun. (Eksodu 19:10-11)
b. Igbe aye koro wa ati ibapade wa ni a
gbodo pamo, bikose be a o fo, eyi ni ki a ba ise Olorun je tabi ki a mu ipalara
ba (Eksodu 24:12-16)
2.
SAMUELI: Eyi ni okunrin miran ti o ni igbe
aye koro ti Olorun le gbo ohun re ni ita gbangba. (1Sam.7:5-15)
3.
DAFIDI: Dafidi tun je okunrin miran ti ko
nilo isodimimo tabi iwenumo pajawiri ki o to le duro niwaju Olorun (1Sam. 16:
4-13)
IGBE AYE ITA GBANGBA TI
OLUKO ILE EKO OJO ISINMI
Igbe aye ita gbangba wa, eyi tiise ohun ti awon eniyan le ri,
ti won si le soro nipa re, eyi na pelu se pataki, fun apeere:
1.
IMURA WA: Imura wa gbodo je eyi ti a le fola
fun, bi o ba se mura ni yioso nipa bi ao se pe o. Nitori na, iwoso wa gbodo je
mimo ati eyi ti o mo niwonba nigba gbogbo.
2.
ISORO WA: A ma ngbe ero okan wa jade nipa oro
siso. Boti wu ki o ri, a gbodo kiyesi wipe iru awon oro kan nbe ti ako gbodo lo
nigba ti a ba nkoni, fun apeere:
(a) Oro itabuku tabi aifola fun oro
elomiran.
(b) Awon ede tabi oro ti iwo gan ko loye
re.
(c) Gbigbe ohun soke to (Eyi ni iwa eni
ti o mo oro’so larin awujo)
3.
IDURO: Oluko ile eko ojo isinmi ti o dara
gbodo le duro daradara nigba ti o ba nkoni, o gbodo ni igboya lati di kilasi mu
lai se basubasu.
4.
IGBOYA LATI WA KONI: Eni ti ko ba ni ese ikoko tabi eniti
o le wa lati doju ti, yio soro ti o ja gaara ni akoko ikoni re. Igboya yato si
igboju.
IKORA ENI NI IJANU OLUKO
ILE EKO OJO ISINMI
Oluko
ile eko ojo isinmi ni won sunmo awon omo ijo ju olusoaguntan gan lo, nitorina
igbe aye Oluko ile eko ojo isinmi ni yio f’arahan ninu aye awon omo ijo ni ona
kan tabi omiran.
Bi
oluko ko ba ni ikora eni ni ijanu, irufe eni na yio pese omo akeko ti ko ni
ikora eni ni ijanu ati wipe bi eyi ba si sele, iwonba ipa ni olusoaguntan le se
lati mu won pada bo lati inu isako lo won, idi niyi ti gbogbo oluko fi gbodo ni
ikora eni ni ijanu.
AWON
IBI TI OLUKO TI GBODO NI IKORA ENI NI IJANU
1.
ESE:
Gbogbo Oluko ile eko ojo isinmi ni o gbodo sa fun ese, eyi si pe fun kiko ara
eni ni ijanu. Ireti Olorun lori wa ni wipe ki a rin ni gbogbo awon ona Re. Bi a
ko ba le ko ara wa ni ijanu, nigba na ni awon adari yio ko wa ni ijanu (Ibawi)
Bi oko ba le ko ara re ni ijanu lati sa fun ese, a je wipe omo ale ni o (Heb.
12:4) Eyin ko iti ba ese ja de inu eje ninu ijakadi yin. Egbodo koju ija si ese
titi de ipele jijiya nitori ododo. O di igba ti o ba so wipe rara fun ese ki
iwo to ni isegun lori ese.
2.
EDE
ENU: Gbogbo Oluko ile eko ojo isinmi ni o gbodo mo bi a ti nni ikora eni ni
ijanu nipa oro siso. O gbodo yago fun awon oro were ati awon asa aye, paapa
julo nigba ti aba fun o ni ojuse ti emi lati se. (1Tim. 1:4; 4:7; 2Tim. 2:23) Igbe
aye Oluko ile eko ojo isinmi je elege; o ko le se isekuse bi awon iyoku.
Omoleyin ko gbodo soro nigbati won ko ba fun lase lati soro, sise lodi je iwa
aini ikora eni ni ijanu.
Oluko ile eko ojo isinmi gbodo mo bi
a ti nba elomiran lo pelu ogbon agba. Enikeni ti o ba kuna lati ko ara re ni
ijanu ni awon agbagba tabi asiwaju yio fun ni ijiya. Mase se aroye nipa awon
aini re niwaju asesegbagbo. Fi ola fun
awon ti o ba ye.
3.
KIKO
OJU WA NI IJANU: Oju wa gbodo je kiko ni ijanu, bi o ba je Oluko ile eko ojo
isinmi ti o ni ikora eni ni ijanu, odi dandan ki o je eni to ni afojusun. Mase
se ojukokoro ohun ti kiise tire. Mase ra nkan lojiji tabi laironu, paapa nigba
ti eto isun re ko lagbara iru re. (2Sam.11:1-end) Aiko ni ikora eni ni ijanu
nipa oju yio yori si ifekufe ninu eyi ti o le sonu ninu re.
4.
KIKO OWO WA NI IJANU: Onigbagbo eyikeyi ti ko ba ko owo re
ni ijanu le gba iyawo tabi oko oloko mu nibi ti ko ye. Arakunrin tabi Arabinrin
ko gbodo tura sile nigba ti o ba fe bowo pelu eya keji, oko gbodo se ni ona ti
yio yori si riro ero ese, bi otile je wipe iru bibowo be ole ma jo ese ni
ibere, sugbon ni ikeyin ole pada yori si ese bi a ko ba tete mojuto, aseju ohun
gbogbo ni ko dara.
Owo mimo: Owo
mimo ni owo ti kiise ibi, o si tun tumo si wipe oko gbodo lowo si sise elomiran
ni ibi. (Orin D. 24:2-4)
5.
IKORA ENI NI IJANU NIPA TI ETO INAWO: Omoleyin gbodo fi ikora eni ni ijanu
han nipa ona ti o gba nna owo, kisepe akole fifunni, sugbon oye ki a gbase lati
odo Olorun, gege bi omoleyin , bi a ba fi owo pamo si o lowo, ti ebi si npao
doju iku, oko gbodo na! Omoleyin ti o nse owo kogbodo lo owo okowo re lati se
inawo, ibaa se isomoloruko tabi igbeyawo tabi oku.
Gege bi omoleyin, ohun ti a nilo
kiise owo, bikose Olorun. Gbigbe Olorun lo si ibikibi ti aba nlo je anfani nla
ti a le je (Mark 14:3-11)
Bi omo eyin ko ba segun owo, owo ni
yio papa segun iru eni na gege bi o se segun Gehasi ati Judasi. Gbogbo omoleyin
ni ogbodo ni ikora eni ni ijanu nipa ti owo. Ise A. 8:18-20. Peter ati Elisa je
apeere omoleyin ti won segun owo, a fun ni owo, sugbon o ko lati gba, nitori ti
Emimimo ko fe ki o gba iru owo be bi o tile je wipe won nilo owo gan.
6.
IKORA ENI NI IJANU NIPA TI AGO ARA:
(1Cor. 9:27) Odidi
eniya ti o peye gbodo ni emi, okan ati ara, o dabi eni pe ara ni o kere julo
ninu awon meteta wonyi, sibe ara kan yi ni o ma nfe lati dari awon ti o ku, ni
opo igba ni idari re ma nlodi si emi ati okan. Lati inu imole eleyi, ife ara ni
agbodo yi danu bi a ko ba fe ni ipalara. Agbodo kiyesi wipe ara yio ma feawon
nkan igbadun, eyi ti yio pada yori si
wahala fun okan ati emi, koda o le mu iku wa ati pipadanu ayeraye.
OGBELE TI EMI
Afihan:
1.
Ogbele
ti emi ni isele ti o mu ki idapo pelu orun ki oja fun igba die (Job 13:23-24)
2.
Ogbele
ti emi pelu le je owon gogo awon isipaya ti emi ati itumo re.
3.
O
si tun je ipo iyerafun ti ko ye si kika oro Olorun ati igbe aye adura adagba.
Bi awon nkan wonyi ba nsele, iwo yio bere si ni se akiyesi
ipada seyin ti emi, awon eniyan ko ni inu didun lati gbo lati odo re mo, nigba
ti awon miran yio ma fi’ga-gbaga pelu re nibi ase.
Bi o ba je oniwasu, iwo yio se akiyesi wipe o ti bere si ni
padanu ifororyan ati iwe ipe lati wa wasu le dinku jojo. Ti ko ba si itete
kiyesara, o le wa be fun opo akoko nipa eyi ti yio fa riru ninu emi ati wipe
nigba miran ole fa ki ipese nipa ti ara gan dinku jojo. Gbogbo awon ese Bibeli
le dake lati mase ba o soro mo tabi jade si o, adura pelu le di wahala nla pelu
aisi aseyori ninu re.
AWON OKUNFA OGBELE TI EMI
1.
Dida dari ara eni: Gen. 12:10-11; 17:1.
Nibi ni a ti se akiyesi wipe iyan kan
mu ni awon ojo Abrahamu, iyan funrare kiise wahala, sugbon wipe Abrahamu dari
ara re lo si Egipiti, nibi ti o ti so ije omoluwabi ru nu. Ni ori ketadinlogun
ni Olorun ti tun sese nse afihan ara re fun Abrahamu.
Iru eyi na losele si Elimeleki ati
Naomi ninu iwe Rutu ori kini ati ikeji (Rut. 1 & 2)
2.
Aigboran: 1Sam. 15:3, 6-11, 19-22; 28:1-24
Nigbati Olorun ran Saulu nise si
Amaleki, lati lo pa won run patapata. Olorun fun ni awopale ise ti o ran,
sugbon sibe o se aigboran. Ogboran si awon ase ti o ba ni ara mu, idi niyi ti
Olorun fi kabamo nipa yian lati joba lori awon eniyan Re. Ki Olorun mase kabamo
wipe o yan o lori awon eniyan re nibi ti o fi o si (Amin).
Olorun ko le ma fi ifororoyan Re sofo
lori omo alaigboran, Soolu siwa nibe sugbon Orun ko ri pe eniyan kan wa nibe.
Nje o si ntele awon itoni isaaju, abi oti ya kuro lati ma lepa owo ati awon
omobirin kekeke inu ijo? Orun yio ti lori gbogbo awon omo alaigboran. Nigba ti
Soolu bo sinu ogbele ti emi, o bere si ni nwa eni ti o ni emi afose kiri,
nitori ti Olorun ko ba soro mo.
3.
Ese: Gen. 12:11-13; Isa. 59:1-2; Awon
Onidajo 14: 15,16
Nihin ni a o tun ti wo igbe aye
Abrahamu wo leekan si, o ni iro pipa yi ninu eje re lati ibere irin ajo re,
koda, nigba ti enikeni ko iti ri tabi ri iyawo re. Nigba ti eri yi wa sinu okan
re, ko tile gbadura rara, beni ko so fun iyawo re, nse ni o bere si ma bee ki o
gba lati pa iro pelu ohun.
Oro Samsoni tun je apeere miran lati
kiyesi. Isoro Samsoni bere nigba ti ifororoyan bere si’wa sori re. Samsoni ko
ri ohunkohun laye re ayafi obinrin nikan. Nigba ti a ma fi de ori kerindinlogun
oti gboye kuro ni riri awon arabinrin, oti bere si ri awon asewo, o yani lenu
wipe ifororoyan si tun nsise.
Boya ifororoyan yi gan ni isoro
omodekunrin yi, boya ti Olorun koba dalohun, boya ib ti ri asise re lakoko,
sugbon ifororoyan re si le gbe ilekun odidi ilu, koda leyi ti o se agbere tan,
o si gbe lo si ori oke, nikeyin osi wonu ogbele ti emi.
4.
Ife aye: Luke 15: 11-16
Ese oro yi bere pelu oro ti o wipe
“Okunrin kan” eyi ti o tumo si pe ole je emi, o si le je iwo, ani enikeni ti o
ba ba ara re ni ipo naa. Nigbati omokunrin na pari gbogbo nkan tan, nigbana ni
iyan de. Ogbele ti emi ma nmu eniyan lo si ile okeere, nibi ti yio ti jina si
Baba.

ABAJADE OGBELE TI EMI
1.
Ajorinpo ti o lodi: 1Sam. 28:1-8; Luku 15:11-16 Nigba ti
eniyan ba wonu ogbele ti emi, yio wa bere si wa iranwo fun ise iranse re, yio
ma lo lati ori oke kan si omiran, yio ma ro wipe esu ni o wa leyin isoro na,
kosi igba ti iru eni na ko ni dara po mo egbe buburu.
2.
Agabagebe: Soolu yi eda re pada lati dara po mo
aje ara Endori. Eniyan ti o ba nwa owo ni ona kona yio yi iwasu re pada!
3.
Iberu: Gen. 12:11-13; 1Sam. 28:5. Abrahamu
pa iro nitoripe o beru awon eniyan ile naa. Soolu pelu beru awon eniyan osi se
ase-mase!
4.
Igbese ti o lodi: 1Sam. 13:9-14
5.
Iponju ti a ko le fenuso: Jonah 1 & 2
6. Itujade ajenirun
7.
Pipada di olusotan: 2Awon Oba 8:4-5
ONA
ABAJADE KURO NINU OGBELE TI EMI
Luku 15. Lati inu Bibeli yi ni a ti sakiyesi bi omo oninakuna
se na ohun gbogbo ti o ni tan ti osi wo inu iyan nla lo. Ogbe awon igbese ti o
le fi jade kuro ninu ogbele ti emi yi:
1.
Sise isiro aye eni lona ti o dara: Bi o ba bere irin ajo pelu ekun rere
epo ninu oko re, sugbon ti opa atoni oko na wa sope epo ti tan de isale, oye ki
o mo funrare wipe wahala ti wa. Oye ki o mo igba ti o ko le ka Bibeli mo tabi
da gbadura mo, nigba ti Bibeli pada di iwe iroyin tabi oogun orun mo e lowo, o
ye ki o mo igba ti o di olusotan lasan lori pepe.
Nigbati omo oninakuna sa jade nile, o
mo ohun ti o ko jade, o si se agbeyewo ara re lona to dara.
2.
O pada sinu oye re: Odomokunrin yi pada sinu oye re, o
si ranti ibasepo re isiwaju pelu baba re; nigba yi ni o pin okan re niya pelu
ile ajeji.
3.
O se ipinu be ni o si muse: Omo oninakuna so wipe ‘emi yio bada
sodo baba mi’ o si se be, bi o ba so fun awon ore re, won iba ti fi enu tembelu
ipinu re. Lati jade kuro ninu awon ohun ko to ko nilo lilo fun imoran.
4.
Irele: Gbogbo igberaga aya ti o dari omo na
jade ti tan bayi. O wipe “mase pe mi ni omo re mo” be na ni o ri pelu Naomi, o
wipe “emase pe mi ni Naomi mo”. O re ara re sile. Otito ti o wa nibe nipe ti
enyan kan ba peyinda, eni na ko si nibe mo, o le je fun osu meji tabi fun odun,
otito ti o koro nipe iru eni be ti sokale. Nitorina, ogbodo ju owo sile fun
awon ti won si wa loju opo, ki oun si lo pada to leyin won.
5.
Pipada sodo Olorun ninu adura: Ohun akoko ti Olorun so nipa
enikeni ti o ba wa ninu ogbele ni pe Wa! (Isa. 55:1). Nigba ti o ba toowa,
onilo lati gbadura, nipa adura yi, iwo yio jewo ese re, oosi tun ibasepo re
pelu Re se.
No comments:
Post a Comment