Monday, May 5, 2014

ISAKOSO AKOKO



   GROUND OF TRUTH BIBLE INSTITUTE

                     No1, Aboderin Street Agbaje Orita Challenge Ibadan

                                                                 MOBILE; 08056008526

HANDOUT
            

    TIME
   MANAGEMMENT

              

    ADVANCED CHRISTIAN LEADERSHIP
(100 LEVEL)
                                      `
                                                                        
           ISAKOSO AKOKO
Akoko ni orisisrisi itumo ati orisirisi alaye itumo. Iwe atumo oro oxford so alaye itumo bi mejidinlogun (18). Akoko ma ntumo si akoko isele kan tabi “asiko ti o ba erongba kan mu”. Fun awa, eko yi yio da lori ibi ti a fa ila si yi. Eyi ri bee nitori pe eko wa ki se nipa gbogbo akoko, bi kose, bi akoko se ni ajosepo pelu asiko ti o ba erongba kan mu, ti o je eto tabi erongba Olorun, lori aye wa gege bi Kristeni ati pataki julo gege bi adari lala ise ihinrere ni oniruru ona. Erongba ni bibeli se apejuwe re gege bi igbimo tabi ife inu. Bibeli naa wipe:
“ete pupo ni o wa ninu aya eniyan; Bi oti wu ki o
ri, igbimo Oluwa nikan ni yio duro”.(KJV)

“Opolopo eto nibe ni aya eniyan, sugbon erongba
ti Olorun nika Ni yio bori” (NIV)

“Awa eniyan a ma da opolo wa
Lamu nipa eto ati ohun ti ayan,    
Sugbon erongba Olorun ni o ma bori”
(THE MESSAGE) Owe.19:21
Ohunkohun ti o je eto eniyan, erongba Olorun nikan fun ni yio wa si imuse. Olorun nikan ni o ma nfi owo ti erongba re leyin ninu aye eniyan kan.
Nitori idi eyi yio je asedanu ati ifi akoko sofo ati fifi awon oun ini miran sofo fun enikeni ti o ba nlakala lati mu ipinu kan se, ninu eyi ti ko ba ilana ati erongba Olorun mu fun un.
Isakoso tumosi lati se ikawo, lati seto, lati satunto tabi ti wiwa ni abojuto ohun kan.
Isakoso ni oro kan, tumosi “sise abojuto”.
Nitori idi eyi, isakoso akoko, tumosi sise abojuto akoko ti a ya soto fun imuse erongba Olorun ninu aye kan pato, O tun je mimo bi ati nseto, bi a ti satunto ati bibojuto akoko tabi asiko kan ti Olorun fi fun ni fun erongba re si wa nihin lori ile aye.
Bi o ti wu ki o ri eko  wa yi ni o fa wa sile si nini isakoso akoko ti o munodoko. Eyi ribe nitori pe gbogbo awawi awon eniyan ni wipe, “ko si akoko”.
     IDI KIKO ISAKOSO AKOKO

Oniwasu 3:1-11. Awon eniyan ro wipe akoko wa fun ohun gbogbo. Rara ohun ti bibeli so ni wipe:
“akoko kan wa fun ohun gbogbo, ati igba kan fun gbogbo ise labe orun”. (NIV)
“Si ohun gbogbo ni igba wa fun, ati akoko kan fun ohun gbogbo labe orun” (KJV)
“Awon akoko kan ma nje anfani lati se nkan, akoko kan to to fun ohun gbogbo labe orun” (The message). Eccl.3:1
Ese yi fihan wipe kii se  ki enia se nkan ni isoro, sugbon ki enia se nigba ti akoko fi anfani ati gbe igbese sile lati se e, ni oro miran, kii se ki enia furugbin ni ohun to soro, sugbon ti enia ba furugbin ni asiko ikore, nse ni iru eso be yo sofo danu.
Akoko le wa fun ohun gbogbo labe orun sugbon kii se gbogbo akoko lo dara fun gbogbo nkan. Idi niyi to ye ki enia ko lati seto akoko re ki enia ba lese ohun to to ni asiko to to.    
              OYE JESU NIPA ISAKOSO AKOKO 
“emi ko le ses alaise ise eniti o ran mi, nigbati enikan ki o le se ise” (KJV).
“gbogbo wa ni a gbodo yara lati gbe ise ti a ya soto fun wa jade lati owo eniti o ran mi, nitoripe akoko kukuru lo seku ki ale tole ati ti gbogbo ise yo wa si opin” (LB)
“a gbodo fi gbogbo ipa ati okun wa ni enu ise eniti o ran wi wa sibi, ki a si sise nigbati orun si ntan. Nitori nigbati ile basu ojo ise yo dopin” (THE MESSAGE) Jn.9:4

Ohun pataki meta kan wa ti oye re ye Jesu
I.            Ise na ti a ya soto, to gbodo di sise.
II.            Eni to ni ise na – eni na t o ran ni.
III.            Ajosepo akoko na si ijafafa Jesu

I.         ISE NA TI A YA SOTO TO GBODO DI SISE:
Jesu mo wipe wiwa si aye oun kii se wipe o sesi gege bi awon enia miran ti nro si. Jesu mo eyi , o wa lori ile aye nihin fun ise pataki kan. Jesu ko wa si aye nibi gege bi enia to se asise.

Enikeni ti yo ba je eni imuse gbodo tete loye wipe ohun wa sinu aye yi fun ise pataki kan. Fun Jesu ise ti a ran kii se onipo keji bikose ise akoko.
ise na ti a fun kii se ohun ti a o se lehin o reyin, sugbon ohun ti a gbodo se, dandan ni si Jesu, ko siona abuja miran fun eyi, idi niyi to fi gbodo runpa- runse sii. Osi gbodo jowo ohun gbogbo sinu re.

Ko si eni ti yio ni ipa ti o ni itumo ninu aye, ayafi bi o ba koko moo ise ti Olorun yaa soto fun ki o si ju gbogbo aye re sinu ona imuse re.

II.      ENI TI O NI ISE NA- ENI TI O RAN NI:
Olorun ni eni akoko ti o ni ise naa. Eyi ni Olorun ti o ran Jesu, ko da wa sinu aye yi ni agbara ara re, Olorun ni ma nran enikan wa saye lati lose ohun pato kan.

Oye ti Jesu ni nipa ibi ti o ti jade wa, ati ibi ti yio pada si ni o ran lowo lati da ohun gbogbo oun ti o ni sinu ise ti aya soto fun. Bibeli wipe:

“Nigbati Jesu mo wipe Baba ti fi ohun gbogb si ikawo re, ati wipe o wa lati owo Olorun ati wipe oun tun npada lo sodo Olorun” (KJV)

“Jesu mo wipe oun  walti odo Olorun ati wipe oun yio tun pada sodo Olorun” (LB)

“Jesu mo wipe Baba ti fi isakoso Ohun gbogbo sowo oun, pe o wa lati odo Olorun ati wipe o ti wa nmi oju ona re lati pada sodo Olorun” (The Message) John13:3

Bi enikookan ba mo ohun ti Jesu mo nigba aye re lori ile aye, nipa ibi ti a ti jade wa ati ibi ti a o pada si, ao  hu iwa ti o dara si ojuse ti a ya soto fun wa. Bi onigbagbo kookan tabi adari ba mo wipe oun wa lati odo Olorun, nigba na ni ko ni si eni ti yio fi ojuse Olorun sile lati ma lepa ojuse adase fun ara re.

III.   AJOSEPO AKOKO NA SI IJAFAFA JESU:
Jesu mo wipe oun le fi ipa kun ise na, nigba ti orun si nran lowo. Pe bi o tile ye Jesu, sibe akoko  kan wa ti orun aye re yio tan da ati wipe iru akoko be nikan ni o le fi agbara se ise fun eni ti oran nise. Igbati Olourn ran ati igbati aye nilo re.

Jesu loye wipe ko kan ni je “maa tan, maa tan” nigba gbogbo. O mo wipe akoko miran nbo ti ko ni si okun lati se ise mo. Akoko kan ti wakati. Ise yio pari. Akoko ti gbogbo ise yio dopin.

Nitori idi eyi, o sise nigba ti orun re nran, ti o si je osan re, ki orun to de. Ko si enikan bi o ti wu ki o ri ti ole fowo si ijafafa nigba ti oru re bati de.
Jesu tun salaye siwaju sii.

“Jesu si dahun wipe, wakati mejila ko ha nbe ninu imole ojojoo, ati wipe ni akoko wakati re, eniyan le sise laisewu ti ko si ni kose. Ni asale nikan ni ewu sisi ese gbe wa, nitori ti ale le” (LB) John.11:9-10
SEse ti aka yi fidi re mule wipe, igba aye olukuluku wa ni ona meji ti o ba ra mu.
A.   Imole ojo
B.   Oru
Ohunkohun ti eniyan kan ba fe se ni o lese ninu imole ojo re, nitori ko le kose, sugbon ni oru ni ewu sisi ese gbe wa.
ISAKOSO AKOKO ALAYE
LATI INU AYE JEHU

1 Awon oba.19:15-17, 19-21; 2Awon Oba.9:1-10, 11-13.
Nigba ti Elija fi ise si le fun Olorun, ni Olorun wa pase fun wipe ki o fi ororo yan awon eniyan meta ki o to kaja lo tan. Olorun so pe ki o yan Hazeali ni Oba lori Siria, Jehu gege bi oba lori Israeli ati Elisha gege bi Woli ni ipo ti ara re. Enikankan ti a fe yan yi ni o ni ojuse pataki lati se ni kankan.
Elisha ni Elija koko ri ni 2Awon Oba.2: 9-15 ti o si fi ororo yan gege bi woli ti yio gba ise lowo Elijah. Sugbon Jehu, titi di igba na ni ko ri ipo tabi aye kankan lati wa.
Bi o tile je wipe Elijah ko le fi ororo yan Hazaeli gege bi oba lori Siria, sugbon Elisha pada wa fi roro yan (2Awon Oba.8:7-13) Oseni lanu wipe a ko iti ri Jehu rara.
Elisha, eni ti o ye ki o je akegbe Jehu ti bere ise re nigba ti Jehu si sakolo. Jehu si je omo ogun Israeli nigba ti o ye ki o je oba lori Israeli.
Ogunlogo awon eniyan ni won dabi Jehu loni. Odabi eni pe won nse ohun ti o dara lowo, sugbon otito ni wipe won nse asise ohun ti o ye ki won se.
                                SISE AWARI JEHU    
2Awon Oba.9:1-2  Nigba ti a fi ma se awari Jehu fun ise ti a fi ko soke fun, Elisha ti o ye ki o je akegbe re ti ni awon woli ti o le ma ran nise kiri. Elisha ran ikan ninu awon ti o pese  lati wa Jehu kiri. Eyi wa so Elisha di “Baba agba” fun Jehu, nigba ti o je omo Elisha ni yio bi Jehu sinu eto Olorun gege bi a ti le so fun Jehu.
Jehu ti sonu si arin awon arakunrin, a gbodo mu ki o dide larin won, opo awon ti Olorun ibati ran lowo lo dabi enipe nse ni won dagun, nitori ti won ko ri koja ohun ti awon ara yoku nri. Elisha pase fun omo woli na lati ya Jehu soto larin awon arakunrin, ko si okunrin kan ti  yio ni iduro ti o dara nipa ojuse ti Olorun, pelu iwonba akoko perete ti o wa, ti yio ri aye ma figa gbaga pelu awon arakunrin ti won nse ohun to gbaju gbaja.
Ni otito, nigbati odomokunrin woli na de Ramoti-gilade, Jehu joko repete larin awon olori ogun (2Awon Oba.9:4-5) Jehu je alaifura ati alaini iran, debi pe nigbati omo woli yi kede ise ti a fi ran, Jehu ko ri ara re gege bi eni ti Olorun le ran iru ise be si. O ro pe ise ti omo woli yi mu wa le wa fun enikeni ninu won.
AALA ISE TI A RAN JEHU
(1Awon Oba.19:16-17; 2Awon Oba.9:3,6-10) o fi oju han wipe aala ise ti aran Jehu gege bi ati fun Elijah ko iti yi pada, bi o tile je wipe Jehu ti fi asiko pupo sofo. Nigbati odomokunrin woli yi de leyin oreyin lati fi ororo yan Jehu gege bi oba lori Israeli, a se akiyesi wipe Olorun ko din ise ti o ran ku.
Eyi fi han wipe Olorun ko ni eto fun iye odun ti o ba fi sofo, ki o to bere si da eto Olorun mo fun aye re. Bi o  ti wu ki akoko ti ofi sofo na po to, aala ise nako ni yi pada.
 
FIFI ISE NA DIWON AKOKO TI O WA NILE
2Awon Oba. 9:11. Nigbati Jehu jade lati inu gbongan, nibi ti won ti fi ororo yan fun ise na, o han gbangba pe eru nla kan ti bo si lori. O wa soro fun lati pada lo joko sipo re atijo laarin awon olori ogun.
Ohan gbangba pe awon akegbe re sakiyesi pe oju re ti yipada. Won si fi ohun kan bere wipe “se alafia ni” nigbeyin Jehu ti wa ri ise ti o wa niwaju oun ati bi o se je yajo yajo to.
  IWAKO TI JEHU NA

2Awon Oba.9: 12, 13: 16-20. Okunrin kan ti o ti fi asiko sofo ko ni ma wa ajoyo, ifijoye ati idelade kaakiri, ite alagbeka ti to fun. Lilo opo osu ni ori awon oke, lati gbadura fun ero-isoro, ile ijosin ti o dara, abbl. Je itansan fun okan ti ko iti ni ifuraa ikanju ati yajo yajo ise na. Jehu ko duro de ade, opa oye ati iwe eri idelade ki o to bere ise ti a ran.
Awon elesin ti won wa lati pade re, niko fun laye ejo riro nitori Jehu ko ni asiko fun ohun alaiwulo (2Awon Oba.9:17-19)
Alore na sapejuwe iwako jehu fun Oba:
“Oluso na si so wipe, on tile de Odo won,
ko si tun pada wa mo: wiwa keke na si dabi wiwa
Keke Jehu omo Nimsi; nitori o nwa bo bi asiwere
(digbolugi)” (NIV) 2Awon Oba.9:20.

Nje ona miran ha tun wa fun eni ti o ti fi idaji ojo imole re sofo lati tun wako? Nigba ti awon eniyan na owo, okun ati akoko pupo lori ajodun ati be be lo, enu ma nya wa wipe nje awon wonyi tile loye pataki akoko.
  TITA OFA LORI ERE
2Awon Oba.9:21-24 Joramu sese jajabo bo lowo ida Haseli ni (2Awon Oba.9:15) ati wipe Olorun ti ba Elijah soro nipa eni ti o ba sa lowo ida Hasaeli, ni Jehu yio pa. Bayi ojuse jehu ni lati ri wipe Joramu ko sa asala.
Sugbon nigba ti Joramu ri wipe Jehu ko ba oro ore wa, o yi keke ogun re pada o si na papa bora. Jehu ko sese ma wa ogbon ayinike kankan. Bibeli wipe:
“Jehu si fa orun kan yo pelu gbogbo agbara re,
osi ta Joramu larin apa re mejeji, ofa na si gba okan re jade,
o si daju bole ninu keke re”.
Jehu ti mura tan lati lo gbogbo anfani ti o ba si sile fun, ko si fun ohunkohun ni anfani keji. Gbogbo anfani ni o gbodo di yiyipada. Jehu ko fi iwa ole ta ofa, beni ko si ta nigba meji, o ta ofa na pelu gbogbo agbara re.
Eni ti o ba ni oye isakoso akoko ko ni fi anfani sofo, iru eni be yio se amulo gbogbo anfani ti Olorun ba mu wa soju ona re.
SISE AMULO AWON ONA MIRAN

2Awon Oba 9:27 Bi o tile je wipe Jehu pa Joramu fura re, sugbon ni ti Ahasiah, bi o tile je wipe o lepa re, sibe o  pase fun awon omo ogun miran lati pa.
Nigba ti Jehu de Jesreeli ni Jesebeli  jade lati wa tan je, sugbon o lo awon iwefa lati tari re sile (2Awon Oba.9:30-37) gbogbo nkan wonyi ni Jehu se ni ojo kan soso! Igba ti Jesebeli ku tan ni Jehu to sinmi die lati sare jehun. Eyi sele ni ojo kan yi ti a fi ororo yan ni Oba lori Israeli, onje ti o je kan wa fun ati lokun si ni, kise nitori ati je igbadun.
Nigba ti o tun di ojo Keji Jehu tun tesiwaju pelu okun titun, ni iru asiko eyi, o lo ona iwe kiko lati fi gbe ise re jade (2Awon Oba.10:1-11) nipa iwe kiko o rorun fun lati pa awon omo Ahabu bii Adorin.
Nigba ti o fi ma di ojo keta, o ti pa gbogbo awon alagbara ninu awon eniyan Ahabu ati gbogbo awon ibatan re ati awon alufa re, titi ti ko fi seku enikan fun  Ahabu gege bi oro Olorun (2Awon Oba.9:12-28) larin awon ojo die, Jehu ti pari gbogbo ise ti Olorun pase sile fun.
Ni sise akoso akoko, a gbodo beere fun ogbon pato lowo Olorun, lati ri awon agbegbe ti a o se amulo re, ki oba le ran wa lowo lati leba ati lati se ikawo awon ile ti o ti sonu mo wa lowo. Irufe awon nkan be le je, awon eniyan ti o wa ni ayika wa tabi kiko awon iwe kan ati, be be lo.

IDAJO OLORUN LORI AKOKO
TI A LO DARA DARA
(2Awon Oba.10:30)
“Oluwa si wi fun Jehu pe, nitori ti iwo ti se rere ni sise eyi ti o to li oju mi, ti o  si se si ile Ahabu gege bi gbogbo eyi ti o wa li okan mi, awon omo re iran kerin yio joko lori ite Israeli” (KJV).

No comments: