Wednesday, October 8, 2014

EKO IPILE IGBAGBO KRISTIENI




EKO IPILE IGBAGBO KRISTIENI
ORO AKOSO
Gege bi oro ipile se ri si ile beeni oro idanilekoo yii si kristieni to sese gbagbo, to mnmura won sile fun igbe aye to danganjiya to si ni ilera ninu Oluwa. A kiyesi wipe opolopo awon ti ko I ti ni irapada lo wa lori pepe wa bayii ti won si mu awon onigbagbo ti ko jinna denu tabi ti kooooo jinna rere jade. O rorun lati foju tenbelu oro  ipile yii ninu irin ajo wa, tabi ki a foju wiiiipe a ko nilo re woo, ti a ba se eyi, a o kan je kiki olujosin, to kun fun awon ede esin, tabi iwoso elesin laisi iwa rere kristieni. Eyi si je okan lara idi ti awon ti a npe lomiran nipat t’emi fi n subu.
ITUMO AWON ORO
Eko ipile tumo si awon nkan pepepe ati ile liana werewere ninu ise to si ase Pataki, tabai ki a so pea won nko ti a ko    kiyesii sugbon to se koko ninu ise lori eyi ti a o ko ohun nla, ti tobi, ti o se ri gedegbe ti o si hann gbangba le lori. Fun apeere ipile ile to n so bi ile yoo ti ga to, bi yoo ti fidimule si, bi yoo ti duro nile, bi yoo ti yo jade to, bi yoo ti pe to, bee gege ni eko ipile nmura eniyan sile fun irin ajo to ni itumo to si lo geere.
EKO IPILE IGBAGBO KRISTIENI
Nitori naa eko ipile igbagbo kristieni tumo si awon igbese ibere kekeke tabi ipile ninu irin ajo igbagbo kristieni to n silekun fun itesiwaju miiran nipa ti emi. Awon igbese wonyi tele ara wo lowoowo ni, ti a ba fo okan da, yoo baa won nkan miiran je lojo iwaju fun wa ninu irn ajo igbagbo. Heb.6:1-9,5:11-14.
Eko ipile yii ni awon osise kristieni miiran ti sonu ati awon oniwaasu wa, idi niyi ti awon asise wonni to n ti ori pepe de odo awon omo ijo fi po loni.
AWON EKO IPILE IGBAGBO KRISTIENI TI AO GBE YEWO
1.     IRONUPIWADA TOOTO: Eyi nii se pelu “ibanuje eni iwa biOlorun” to n sise ironupiwada, atunse ona wa – mimu gbogbo aito wa si tito. Mimu eda Adamu kuro. Gbogbo awon nkan wonyi lo nse ise igba ti Bibeli lowo si pelu idaniloju to peye. 2Cor.7:9-12, 5:17, 18 Pro.28:13, Ise.23:1-5.
2.     AWON ILANA (IGBEKALE) BIBELI: Awon ni Ibaptisi ninu omi (iribomi) gege bi ijewo igbagbo eni nita gbangba, si ipa mimu gbogbo ododo se ati ounje Ale Oluwa. Ise.28:19, 3:13-17, Rom.
3.     IGBOWO LENI LORI: Fun awon idi Bibeli lowo si pelu lilo ororo itasori lona to ba Bibeli mu.
4.     ISIN: Looto itumo eyi gbooro sugbon a o menuba kiki akoko alada nikan-wa pelu Oluwa ti a npe “Wakati idakeje” ati akoko ijosin ebi ti a npe ni “pepe ebi”. Mak.1:35, Mk.6:31.
5.     OKAN ENIYAN: Bibeli fidi re mule wipe okan eniyan ni aaye ti oniruuruu iwa buburu ede ese ngbe.
6.     JIJE OMO IJO: Oun la o ma so  kadii eko yii. Ojuse Pataki ati ipo olukuluku ara Kristi la o tenu mo nihin gege bi akosile Bibeli. Gege bi ara pipe t Kristi je ori. Heb.10:25, 2:41:-47.
IRONUPIWADA NI TOOTO
Ironupiwada nitooto ni yiyi pada kuro ninu ese patapata ati gbo gbo etan ati igbadun igba die re (Heb.11:25) eyi la si n bere  lowo gbogbo eleseko to dip e yoo le gba Jesu gbo tokan tokan ati ni yiye kooro pelu igbagbo ti o gba ni. (Owe.28:13 Isa.55:7, Ezk.18:21-23, Mk.1:15, Luku.24:46, 47). Idaniloju to n wa lati inu ifihan otito oro Olorun ati ife Re ti o sin se ise iyipada lati mu ona buburu  pada si otitoo. Ki se igbala fun ra re sugbon igbese Pataki si igbala. (Ise.2:38,3:19)
A.    IRONUPIWADA TO BA JE TOOTO GBODO:
a.     Bere lati inu idaniloju ifihan Oro Olorun. Ise.20:20, 21
b.     Toka si Olorun ati jije Oluwa Jesu. 2Cor.7:7, 11
c.      Toka si mimo otito. Tim.2:25,26
B.     APEERE IRONUPIWADA ADAMODI
a.     Farao (eni fun opo igba to nfe ki awon omo Israeli maa lo nigba ti o ba da loro sugbon ti yio takun ti ara ba ti tu u)
b.     Simony oso. Ise.8:9-24
c.      Agiripa (to ni idaniloju sugbon ti ko ni iyipada). Ise.26:26
C.     APEERE IRONUPIWADA TOOTO
a.     Egberun meta eniyan. Ise.2:37-42
b.     Onitubu ara Filipi. Ise.16:29-33
c.      Iwefa ara Etopia. Ise.8:35-38.
D.    EESO IRONUPIWADA TOOTO. Isess.26:16-18.
a.     Idariji ese/iyipada.ise.13:38, Romu.3:25.
b.     Ogun laarin awonn ti a so di mimo. Ise.20:32, Efesu.1:11, 14. Eyi ni yoo mu iyato nla wa laarin igbe aye atijo ati ti isinyi.
ATUNSE
Atunse je ipa Pataki ninu ironupiwada nitooto. Oun ni dida ohun ti a jeje, jigbe tabi ti a fi ona aito gba pada fun eni to ni won nitooto. Oun ni sisan gbese. Ohun ti aya sugbon ti a ko da pada, ohun ti a jigbe tabi ti a si mu (darapo mo ti wa). Jijewo iwa odaran ti a se ni koko ati jijewo iro ti a ti pa. o je ifi di mule pe a ti di ti Kristi, o si n mu idalebi kuro lokan wa. (1Jn.3:19-22, Matt.5:23,24, Eksodu.22:1-70).
ORISUN ATI SISE ATUNSE
Si awon elomiran atunse je aserege, si opo atunse ko ba igba mu mo. Opo wipe jijewo ese tito Numeri.5:71, sugbon atunse je ohun tii.
1.     O je ase Oluwa. Gen.20:1-8
2.     Awon woli koni. 2Sam.12:1-6, Owe.6:31, Ezek.33:14,18.
3.     Jesu naa koni. Luku.18:8, 9, Jn.4:15-19, Lk.3:13
4.     Awon Aposteli naa ko o. Ise.23:1-5, Filemoni.1:21, Filipi.1:27
5.     Awon oba gbaa gbo won si se e. 2Sam.19:5-8 pelu 19:16-23, 1Oba.20:34, 2Oba.8:1-6, Neh.5:6-13.
AWON ANFAANI ATI ERE ATUNSE
O ye ki a tenumo nihin wipe
1.     Elese ko le e se atunse
2.     Ti a ba se lai gba itoni lowo ojise Olorun to kun Emi mimo ti ouw naa ma nse atunse o le di asise.
a.     O n mu idalebi kuro. Rom.8:1-2
b.     O n mu eri okan ti ko ni ikose. Ise.24:16.
c.      O n fun ni ni igboya si Olorun ati esi si adura. 1Jn.3:19-22.
d.     Idariji ese. Lefitiku.6:5, 7.
e.     O n mu egun kuro. Neh.5:13, Ise.25:5, Ekso.23:28.
IJIYA FUN ATUNSE TI A GBOJUFO
Ijiya n be fun enikeni to se ainani eyikeyi ninu oro Olorun. Jakobu.2:10-12.
AWON ILANA BIBELI
            Awon meji ni liana yii ti SBibeli pa lase fun gbogbo kristieni lati ma a se gege bi Jesu ti se won
a.     Ibaptisi ninu omi. Matt.28:19
b.     Ounje Ale Oluwa. Lk.22:19
a.     IBAPTISI NINU OMI (IRIBOMI)
O je ijewo iyipada wa ni gbangba. Ibaptisi omi je leekan soso (kii se lee meta) “ni oruko Baba, ti Omo ati ti Emi Mimo gege bi Jesu ti pa lase. Matt.28:19, 3:13, Mk.16:15, Ise.2:38, 39, 19:1-6, Rom.6:4,5. On se apeere isokan Kristieni ati Kristi Gal.3:26, 27 ati fifi ara han pelu Kristi Rom.6:4-13 eni ti yoo se iribomi gbodo le fi eri idaniloju igba re han (kii se bi simony- oso) Ise.20:21. Oro ti a n pe ni ibaptisi wa lati inu ede Giriki ti a npe ni “BAPTIZO” Itumo re ni “iribo” tabi “kiki bo inu” (kii se dida le lori tabi wiwon le lori) kiyesi awon ede wonyi:
a.     Ninu odo Jordani. Matt.3:16, Mk.1;5-19
b.     Won si jumo sokale sinu odo, goke kuro ninu odo. Ise.8:38, 39 Jn.3:32
EREDI IBAPTISI
a.     O je igbonran si ase Kristi. Mk.16:16.
b.     O je titele ase Jesu. Peteru.2:21, Matt.3:15-17
c.      O je lati mu gbogbo ododo se. Matt.3:15.

APEERE AWON ONIGBAGBO TO TO SE IBAPTISI NINU IJO AKOKO
a.     Onigbagbo akoko Pentikosti. Ise.2:41.
b.     Onigbagbo Samaria. Ise.8:12
c.      Iwefa Etopia. Ise.8:38
d.     Soolu ti Tasu. Ise.9:18
e.     Lidia ara Tiatira. Ise.16:15
f.       Onitubu ara Filipi. Ise.16:38
g.     Onigbagbo ni Korinti. Ise.18:8
h.     Awon omo eyin ni Efesu. Ise.19:5
Eni ti o ba gbagbo ti a si baptisi re yoo la. Maku.16:16
OUNJE ALE OLUWA
Jesu lo fi lole ni ale to saaju Gestimani (Matt.26:26-36, Mk.14:22-24). A se apeere re lasiko ajo irekoja laarin awon omo Ju ninu majemu laelae. Ekso.12:1-28.
ORISIRISI ORUKO RE
a.     IDAPO Mimo. 1Kor.10:16
b.     Eje ati Ara Jesu. Matt.26:26,28
c.      Tabili Oluwa. 1Kor.10:21.
d.     Ounje Ale Oluwa. 1Kor.11:20
e.     Bibu Akara. Ise.2:42, 20:7
AWON OHUN ELO IDAPO MIMO
Akara aiwu (akara ti ko ni iwukara). Iwakara je apere ese, ibi, igberaga, agabagebe ati etan. Eyi ni Jesu pe ni Ara oun (Matt.26:26). Bibu akara je bibu iye Jesu ninu etutu fun irapada. Eso ajara n se apeere eje Jesu 1Kor.11:24, Matt.26:27-29.
EREDI OUNJE ALE OLUWA.
a.     O je ase lati odo Oluwa. Lk.22:19, 20, 1Kor.11:24-34.
b.     O n fi iku irapada Oluwa han. 1Kan.11:26.
c.      O n ru ireti pipade wa Oluwa soke ninu wa. 1Kor.11:28, Ise.7:55,56.
d.     “wiwo Eyin” si Kalfari nibiti Jesu ti ku ni ipo wa. 1Kor.11:26.
e.     “wiwo iwaju” fun ipada tie mi leekeji.
f.       “Wiwo inu” lati ye ara re wo. 1Kor.11:28-32.
Kikopa laiye ma n fa aisan ati iku aitojo. 1Kor.11:27-29.
IGBOWO LE NI LORI A TI ILO ORORO ITASORI TO TONA
Oye kikun nipa iwulo oro itasori, itumo ati bi a tin se yoo je anfani nla tun wa ifororoyan funra re je itujade oore ofe fun ise akanse tie mi kan. Eyi ko pon dandan lati lo ororo-1Johanu.2:20-27 (Amp, KJV, NIV, Goodnews) Ni igba miran a le pe ni.
a.     Ipa
b.     Oore ofe ti Emi. Kor.1:4,5.
c.      Ifikunni. Rom.1:11, 1Tesalonika.2:8
d.     Igbe agbara woni.lk.24:49, Ise.1:8.
e.     Ohun. Efesu.6:19, Col.4:3.
OHUN TI A FI SE ORORO ITASORI- EKSODU.30:22-23
Awon ohun daradara, mimo gaara ati ohun didun Olorun didun la fi se ororo itasori. A se bi ororo ikunra oloru didun. Ohun ti a o lo o funn lo mu ki a fi asayan eroja ti ko ni idoti ati ninu poo.
AWON AKIYESI FUN ILO RE
1.     A ko gbodo da a sara eran ara (eni ara) Eks.30:32
2.     A ko gbodo se eda re. (Eks.30:32).
3.     A ko gbodo da sara alejo (alaigbagbo) Eks.30:33
ILO ORORO ITASORI TO TONA
Iwa mimo ni iwe to se akojopo asa ati akoso iwa huhu fun awon arinrin ajo ni oju ona si ijoba orun. Nitori naa o se akosile ilo ororo itasori
1.     Lati yan Oba/Wooli
a.     Soolu. 1Sam.10:1
b.     Dafidi. 1Sam.16:13
c.      Elisha. 1Oba.19:16
d.     Jehu. 2Oba.9:6
e.     Joasi. 2Oba.11:12
2.     Lati yan Alufaa/iranse Olorun
a.     Aroni ati awon omo re. Lefi.8:2, 10-12, 10:7.
3.     Fun imularada alaisan. Lk.10:33, 6:13, Jakobu.5:13-16.
4.     Kiyesi eyi. Matt.26:6, Mk.14:3, Jn.12:3

ORISUN IFOROROYAN TO TONA
1.     Taara lati odo Olorun
-         Lati ipase akoko ara- eni pelu oro Olorun Jobu.29:6
-         Nipa diduro de Oluwa. Isa.40:31
2.     Nipa igbowo leni lori eni to tayo eni nipa ti Emi.
-         Deut.34:9, 2Tim.1:6
3.     Nipa yiyande ara eni fun ise Oluwa.
EREDI IGBOWO LENI LORI
Igbowo-leni-lori je okan Pataki laara eko ipile igbagbo ti a se itenumo re ni Heb.6:1-2, o nilo ki a salaye, ki iwulo ati eredi ryeni daradara.
1.     Fun ifikun ni oore ofe “Emi. 1Tim.4:14j ati fun iyan ni si ipo Ise.13:3
-         Poolu gbowo le Timoti. 2Tim.1:6
-         Awon Aposteli mejila gbadura fun awon Diakoni meje. Ise.6:6
-         Mose gbowo le Joshua. Deut.34:9, Num.27:18-23
2.     Fun iwosan aisan. Mk.16:17, 18,Ise.9:17.
3.     Nigba miran fun lati gba Emi Mimo
-         Peteru se be fun awon onigbagbo Samaria. Ise.8:17
-         Anania gbadura be fun Poolu. Ise.9:17, 18
-         Poolu ati Kristieni Efesu. Ise.19:6,7

IRARAENI JIN
Ifara enijin fe pupo pupo, sugbon a o kiyesi waketi idakeje ati pepe ebi tabi adura owuro/ ale gbogbo ebi.
WAKATI IDAKEJE. GEN.19:27, MK.1:35
Wakati idakeje la le pe ni ofa atamatase onigbagbo lati je ogun ojumo kan. Oun ni agboorun to n dabobo onigbagbo kuro lowo in oorun lojojumo. Oun ni bata onirin to se rin aginju aye. Oun ni kokoro ati aje to n tuko igbe aye Kristieni lojoojumo.
·        Aises wakati idakeje daradara tabi aise rara dabi oko fifun lai lepo.
·        Sise pelu ilora yoo mu ki onigbagbo so adun, oore ofe ati ogo Olorun pelu igbni nipa t’emi nu. O je akoko ti a ya soto laaro kutukutu tabi lale patapata lati ni idapo pelu Olorun.
·        Isegun yoo ma fo onigbagbo to ba dagunla si wakati idakeje da.
·        Ti kpo ba si ajumosepo to dan moran pelu Olorun ko le si  irufe idapo ti o wuyi
EREDI WAKATI IDAKEJE
1.     Fun okun ojoojumo Kristieni fun iri ajo iwaju won. 1Obaa.19, Jn.15:5
2.     O n tun idagbsoke ati iduro sinisin wa se. 1Peteru.2:2.
3.     O n ra ni lowo lati ko iha to dara si idanwo ati iyiri wo to wa soju ona wa. Heb. 12:10:11, Jn.1:2-4, 1Peteru.4:1, 2, 2Pet.1:3-7
4.      O n ran igbekale ati igbagbo wa lowo ninu Olorun.
5.     O n fun onigbagbo ni oore-ofe ojoojumo fun idojuko ojoojumo
OHUN ELO FUN WAKATI IDAKEJE TO GBAMUSE
1.     Titeteji lati dena idiwo
2.     Fifo oju re tabi ki o yara we
3.     Mu bibeli, iwe ajako.
4.     Wa ina si tosi ki okunkun ma ba ran oogbe lowo.
5.     Fin sotun, sosi lati dena oorun.
OHUN TO YE LATI SE
1.     Orin iyin to moriya, didupe laarin re ti a fi orin adako/orin inu iwe la larin. Filipi.4:8
2.     Idapo pelu Olorun nipa adura ati Bibeli kiika (Adura naa gbodo je soki, gbigbona ati pelu okan kan) ki o si fi adura ibebe, adura isipe, adura edun okan ati ife okan re sii. (1Tim.2:1).
3.     Se ayewo Bibeli finni finni, tinu tinu, pelu otito inu ati ni isasaro o ko ni sainilo ipinnu okan ati ikora eni ni ijanu lati ja fafa wakati idakeje re. O.O63:1, Gen.28:18, Joshua.3:1, 6:12, 7:16, 8:10.
PEPE EBI
Pepe ebi fere je ohun kanna pelu wakati idakeje, iyato kekere to wa ninu re nipa, eyi ma n waye laarin ebi onigbagbo (lati odo baba titi de omo to kereju ninu ebi) nigbati wakati idakeje je laarin onigbagbo kana tin Olorun re. sugbon pepe ebi je ikorajopo ebi kan (lati ori eni meji de gbogbo ile) fun idapo ajumose ni waju Olorun. Deut.6:6-9, 4:9-10, 11:19-21. Ohun gbogbo ti a nse lasiko wakati idakeje la gbodo se lasiko pepe ebi/tabi ijosin ajumose. Sugbon ko ye ki o pe ju bi o ti ye lo. Ranti wipe “ebi to ngbadura po yoo gbe po”
OKAN ENIYAN
Okan eniyan ni “Inu” eniyan kookan. Oun ni ipa to n mu eniyan sise. Ohun kohun ti eniyan ba ri tabi gbo ma nlo sinu okan oun ni yara ikerusi gbogbo eniyan. Okan eniiyan tabi ero inu oko. Enikeni to ni okan lo ni eniyan naa. (Rom.6:16. Matt.12:34, 35, 15:18 Lk.6:45. Mk.7:21-23).
APEJUWE OKAN ENIYAN
Bibeli salaye ipo idibaje ti okan eniyan wa leyin igba ti a subu kuro ninu oore ofe sinu ese. Okan eniyan buru jai. O kunnn fun etan ju ohun gbogbo lo tani o le mo o? Jer.17:9.
Eyi ni ibi ninu ohun gbogbo ti a n se labe oorun, pe isele kanna lo nsele si gbogbo won, pelupelu okan omo eniyan kun fun ibi, isinwin si n be li aya won nigba ti won ngbe leyin eyi won o si dapo mo awon oku. Eccl.9:3.
Sugbon awon nkan wonni to tie nu jade ti inu okan  ni ero buburu. Ipaniyan pansaga, Agbeer, Ole, Eri Eke, Oro Buburu. Matt.15:18, 19 ese Bibeli ti a ko si oke yi n salaye ati sepajuwe bi idibaje okan eniyan se ri. Irufe ese ti eniyan bad a n se afihan ipo ti okan re wa, nitori pe bi okan se ri ni o n so ihunwasi eniyan. Ihuwasi afihan ipo ti okan re wa, nitori pe bi okan se ri ni o n so ihunwasi eniyan. Ihuwasi awon eranko kan yoo ran wa lowo lati salaye idibaje to wa ninu okan eniyan.
1.     Agbe/Okin: Eye yii rewa  o si kun fun orisirisiii awo. O duro fun igberaga. 1Pet.5:5, Owe.8:13, 16:18
2.     Obuko: Eranko yi loori\un pupo o si kun fun ifekufe eyi to n sapeere ifekufe, ailamaduro, agbere ati pansaga. 1Kor.6:18-19, 3:17.
3.     Elede: Eranko yi doti o si je onijekuje. O man je ohun to ba ri yalal mimo tabi aimo. O je japeere to n ronu ibi eeri ati ibaje ni gbogbo ojo. Ijekuje, siga mimu, taba finfin. 1Kor:16, SDeut.21:18-21, Owe.23:21, 28:7, Isaiah.5:22, Hab.2:15, Isaiah.5:12, 1Kor.6:9, Efesu.5:18, Jn.7:37.
4.     Ijapa: Eranko yii yole, o si n sapeere imele, iwa ole oso sise aigbogbo. Owe.21:25, Lef.19:31, Deut.18:10-12.
5.     Amotekun: O je eranko ti o buru jai, ti o si duro fun ikorira, ija ati ibinu ti o so ospo di apaniyan. Psm.37:8, Owe.27:4, Oniwasu.7:9, 11:10, Kol.3:8
6.     Ejo: O duro fun owu jije ati etan. Orin Solomoni.8:6
7.     Opolo:Iyepe ni ounje eranko yi a ma gbe ninu amo, eyi mun ki o duro fun ojukokoro, ijekuje, ife owo eyi ti se gbongbo oun buburu gbogbo. 1Tim.6:10, Matt.6:19, 22, Joshua.7:19-26, Lk.12:15, 12:22-34.

                             IPO TI OKAN ENIYAN WA NIGBA TI A GBALA
A gbodo fiyesi pe awon ara eniyan, iran, itedo ati giga, irisi ati ipo ti oju eniyan wa ki yipada. Oun ti o man un sele ni pato ni “Itungbin okan, tabi pasiparo okan – I Sam. 10:9, siwaju iyipada, eniyan OKAN OKUTA Esekieli 11:19, Nigbati a wasuu Ihinrere fun O GBAGBO PELU OKAN Rom.10:10, ni akoko iyipada, afi okan tuntun ropo okan apata ti o ni tele ri Esekiel 18:31, 36:26, nigbati ti eni ti o gbagbo naa ngbe ninu Kristi,O UNGBE INU RE ( Efe 3:17)

                                 AWON OUN TI ALE SE PELU OKAN WA
1.     Nigba ti a tan eniyan je okan re ni atan je Jer. 17:9
2.     Okan ni o ma un yigbi – Mk. 8:17, 10:5, 16:14
3.     Idariji irekoja enikeji eniyan ma unwa lati inu okan Matt. 18:35
4.     Inu okan pelu ni ama  unpa oro Olorun mo si – Psm. 119:11
5.     Ama mo Olorun ninu okan wa – Jer 24:7
6.     Lati inu okan ni ati unfe Olorun – Lk 10:27
7.     Ipa lati se ife Olorun ma unsele tabi waye ninu okan ara – Efe 6:6
8.     Diduro sinsin ninu Olorun ma un waye lati inu okan – Heb 13:9

                              JIJE OMO IJO/ DIDI OMO IJO  
Ohun pataki meta kan wa ti a gbodo ba pade ninu okan wa ati pelu ti a gbodo se yanju nipa ti ara, ki a to le gba eniyan kan wole bi omo ijo Olorun.
1.       IYIPADA: Eyi nise pelu ironupiwada si Olorun, igbagbo ninu Jesu Kristi ati didi atunbi. Hn 3:3, 5, 16, 18, 36 Ise Aposteli 3:19, 20, 21
2.     IRIBOMI/ITEBOMI: Eyi je ami ti ode ara pe eniyan je omo eyin Jesu ni Oluwa Mk 16:15, Ise Aposteli 2:41, 8:21, Rom 6:1-14.
3.     IJEWO ITA GBANGBAN: Lati jewo pelu enu w ape agba Jesuni Oluwa ati Olugbala wa.
Didi ara ebi Olorun nise pelu nini ibasepo pelu Olorun (1 Jn 1:3) ati pelu sise ipade po pelu awon ara ninu Olorun (Ise apos. 2:37-47) Bibeli kilo pupo lori kikuna lati ma darapo mo awon eniyan Olorun. Heb. 10:25.

                                  ISE PATAKI JIJE OMO IJO   
Ikorasi ati itoju gbodo wa fun omo-eka ijo kookan omo eka ijo kookan nilo ara won (1 Kor. 12: 14-26) won gbodo ma nise pelu igbe aye eni kookan, ati pelu ki won ma gbadura fun ara won (Efe 6:18) won gbodo ma ruu eru ara won. (Gal. 6:2) ki won ma se rere fun ara won (Gel 6:10, Jhn 13:35) ati peluki won ma ba aini ara won pade. Rom 12:13. Bakanna pelu ni isokan idapo ijo pelu Olorun.
1.     Oun fi ese asese gbagbo munle lati di Kristeni ti o dagba doju iwon.
2.     O ma un pese ogun fun imubosipo awon apada seyin.
3.     O ma un fi anfani sile fun irusoke isokan.
4.     O ma unfi ese onigbagbo munle lori otito.
5.     O ma un munra onigbagbo sile fun orun.    


No comments: