Tuesday, August 25, 2015

LILOYE ISE IRANSE IJADELO KRISTIENI



LILOYE ISE IRANSE IJADELO KRISTIENI

LILOYE ISE IRANSE IJADELO KRISTIENI
Liloye: Liloye  tumo si nini imo ti o ja gaara tabi iwoye nipa ero okan.
ISE IRANSE IJADELO: Gege bi iwe atumo ede se soo:
a.       Ise ranse tumo si ise pataki kan ti o wa fun eniyan kan tabi awujo, ti won silo se nibikan pato.
b.       Wiwasu nipa esin enikan.       
   ITUMO LATI INU BIBELI

ISE IRANSE IJADELO:  Tumo si jijade pelu ete kan pato.
IRANSE:  Eyi ni enikan ti o jade pelu ete kan, se iranse ijadelo maa nbere pelu IRAN.
Nigba ti  eniyan ba ri iran, ti o si jade lati mu iran re se; iru eni bee ni o yi iran re si ire iranse
Eni ti  o ri iran ti ko si jade lo fun iran re ni Oluriran lasan won ko si I di iranse lailai.
Eniyan ti a pe jade pelu ete ni iranse nitori o ni ise kan lati se tabi muse.

ISE IRANSE IJADELO KRISTIENI:  Lati jade pelu ete kikede iyinrerre  irapada Kristi fun Awon eniyan ti won je ope sii, lati fi idi ise iranse igbagbo Kristieni mule nipa kikede Kristi lo si asa rniran lati ba aini awon eniyan ti won ko i ti gbo nipa Kristi ati ise igbala re pade. Lati fi awon eniyan, ara ati asa sile, ki a si mu imole ihinrere to orile ede ati asa miran lo.

SE IRANSE LJADELO ATI  IJERE OKAN:  Gegebi a ti salaye siwaju, ise iranse ni jijade pelu ete kan pato. Ijere okan ni ona lati mu ise iranse Kristieni se. Nipa bayi, iranse ni a tun le pe ni Ajihinrere. Alaye  yi je ko di mimo fun wa wipe ise iranse ati ijere okan so mora won.  Iyato ti a wa ni awon ona ti a ngba lati se won, a maa nse ise iranse laarin awan eniyan ti asa ati ede won yato, nigba ti a nse ijere okan laarin asa wa.

IRANSE KRISTIENI :  Je enikan ti o jade lo lati mu ise iranse se, tabi ki a so wipe eniti a orile ede miran lati lo  waasu esin re. Oro ti  a npe ni iranse jeyo lati inu ede LATIN ti a npe ni “MITTO” ti o tumo si “IRAN JADE”, a si tun wa ni ibamu pelu ede GRIKI, kan, eyi APOSTELLO ti oun naa tumo si IRAN JADE”

Jesu Kristi ni olori ati iranse majemu titun tabi Aposteli akoko. Olorun ni Omo kan soso, o si se Omo naa ni iranse (John 3:16) Omo Olorun be aye yi wo lati nkan bii egberun odun
meji seyin fun ise iranse irapada. O wa lati wa kiri, lati gbala ati lati fi Emi Re lele fun iran
eniyan. Ni pipari  ise yi, jesu koju si awon Aposteli wipe:

“Bi baba mi ti ran mi beeni mo ran yin (lJn. 20:21). Olorun je iranse, Omo Olorun je iranse, ijo Kristi paapa si je ile-eko ise iranse, Gbogbo onigbagbo tabi Kristieni ni eleri, sugbon gbogbo Kristieni ko ni iranse gege bi ipe Olorun.

TANI IRANSE AKOKO: Lati inu iwoye Majernu laelae, Olorun ni iranse akoko. Ni ipilese ni o ti kan Olorun gbongbon nipa eto alaafia, ohun elo ati ohun ti Emi ti aye nilo. Olorun da aye fun idi kan pato. Sugbon nigba ti eniyan yi eto O!orun pada, Olorun si tun iran eto irapada miran ti o si muse nipase omo Re Jesu Kristi.

AWON  IRANSE DIE  NINU MAJEMU LAELAE: Opolopo awon iranse lo wa ninu majemu laelae
Awon wonyi ni Olorun pe ti o si ran jade pelu iran ati ilepa. Die ni  aseyori ninu ilepa won. Nigba ti awon miran kuna. i U Co PY
I
APEERE AWON TI O  SE ASEYOR!: Noah, Abrahamu, Esteri, Nehemay,  A.b.b.i.
APEERE AWON TI O  KUNA: Saulu, Mose, ati opolopo awon miran.

AWON IRANSE MAJEMU TUNTUN: Lati inu iwoye Majernu Tuntun, a le ri Oluwa wa Jesu Kristi gege bi iranse akoko; Sugbon bakanna ni a tun le ri Johannu Onitebomi gege bi iranse ti oun pelu pari ohun ti Olorun pe e fun, eyi ni lati mura tabi tun ona se fun Olugbala. O si se aseyori ninu re. Ni ona miran, a tun le so wipe Johannu Onitebomi ni iranse akoko ninu majemu tuntun.

IRUSOKE FUN ILOWO SI ISE IRANSE: Bi aye ti ndagba fihan bi ise iranse wa ti ngbooro si. Ise iranse ninu aye ti gbooro si paapa ni odun die seyin. Ni akoko ti wa yi, ti ko si ri bee tele, gbogbo aye ati ipejopo eniyan ni oju won ti la si ihinrere. Opolopo Kristieni ti lo si oniruru ilu, ti won si nko ede si, ti won si ntumo Iwe Mimo si awon ede miran; ti won si ngbin ijo si ninu eyi ti iru akosile bee ko si. Ni opolopo ilu ti ko si musulumi, tabi igbagbo ninu ijoba ni Kristieni ndarapo mo ijade lo yi, won ni oye pe ise iranse je ohun ti o se pataki ninu ijo Kristi.

ODIWON ILOWO SI ISE IRANSE IJADELO: Ise iranse ko pin si akitiyan ti awon ara oke okun tabi oludasile nse nikan, sugbon oje ilana ninu eyi ti gbogbo onigbagbo gbodo lowo si. Ise iranse Maa nni ifesemule ibasepo pelu awon asako ki a ba le raaye kede ihinrene ni ona ti won yoo fi loye kikun tabi gbooro ninu re. Awon ti won gba iroyin ayo naa gbo ni a kojopo gege bi awujo onigbagbo. Ara Kristieni a.b.b.i..



IRANSE TI O  GBONA: 1972. Lati di kun erun wuwo aye yin ati t’emi pelu, gbo eyi; Millionu meedogun awon ju; Millionu meedogun le ni Oodunrun awon omo ehin Muhammodu, Aadorin millionu elesin Budda, aadota le loodunrun millionu konfukainisti ati Tanisiti, Otalenigba odin marun millionu Hindu, Aadorun millionu shritoists ati aimoye oke millionu eniyan ni Kristi ku fun ti won ko si gbo nipa ihinrere onibukun. Paapa awon olujosin lasan ninu ijo ni Ameria to nkan bii millionu metadinlogbon, odo ti won ko ju omo odun mokanlelogun tabi ogun odun lo ti won ko si gba eko Kristieni ati egberun mewa ileto tabi igberiko ni won ko ni ile ijosin. Aimoye millionu eniyan ni won nku ninu aye yi losoose laini Kristi, Se eyi ko je nkan si o bi?

Bi a ti nkeyesi pataki ijere okan awon eniyan ni orile ede wa, ni eko yoo je ki a ma ipile biba awon eniyan soro nipa ihinrere koja asa ki a si ba awon eniyan bi millionu meta ti  won ko ri enikeni so nipa Jesu Kristi fun won. Eyi beere fun idanileko ti ifara eni ji patapatan Kristi. Iranse ni eni ti agbodo yan ki a si ran nipase Oluwa ikore. fowosowopo, adura ati imulokanle gbodo ti odo ijo Kristi wa nigbogbo igba nitori ipe imulokale ijo lo le fi agbara tabi ipa kun iranse lati te siwaju ninu ise iranse! Irewesi maa nwa nigba ti ko ba si ifowosowopo.

IDI  TI A NI LATI FI LOWO SI ISE IRANSE.
Kini idi fun ise iranse? Sise awari inilo igbala eniyan. lkaanu omo eniyan ati ife lati yi aye pada farahan daada. Nigba ti eyi je idahun ti o ya ni lenu, won gbagbe ipile idi ise iranse. Iwe Mimo fi han wa wipe ipile ise manse nbe ninu iwa Olorun, ase Kristi ati ipo ti asako ti won ko tile gbo nipa Knisti wa.

A.      WA OLORUN: Awon iwa Olorun ni Mimo, idajo, ododo ati ife. Olorun je Mimo o  si korira ese. O da iya ayeraye fun esu ati awon angeli ti a dite pelu re, sughon ko fe ki eniyan kan segbe pelu won 2 Pet. 3:9 Olorun ki isi se eniyan ti yoo fi seke Hos. 11:9
B.      ASE KRISTI: Pelu ase ati idaniloju ti a ye kooro, Jesu mu ki awon atunbi Kristieni owo ninu se iranse. Eyi ko tumo Si pe O pase pe gbogbo onigbagbo ni o gbodo je iranse ti a ran jade, sugbon O pase fun awon mejila ati pelu awon apejopo eniyan ti a wa ni yara oke lati Iowo ninu siso ni di omo leyin nigbogbo orile ede (MK. 16:15-20,  Ise AA 1:8,)
D.      IPO ASAKO:  Ninu iwe Luku 16:23-38, ni oloro ninu ise oro ti bebe fun aanu  ti o si beebe  pe ki a ran Lasaru alagbe lati fi ika re kan omi si ahon fun itura. Nigba ti a si so fun un pe o tip e ju, o si bebe ki a ran enikan lati lo kilo fun awon arakunnin oun marun ti o wa ninu aye. Ninu okan ikaanu fun awon asako fi han pe e nlowo ninu ise iranse iranjade.


ABAJADE 1LOWOSI ISE IRANSE IJADELO: Jijowo are eni fun ise iranse ijadlo ni o nfi  bi ijo se dagha ninu Emi si han. Ijo ti o kopa ninu ise iranse ijadelo daada yato gedegede si eni ti o kan fi ife die han si awon ti won ko tii gbo nipa Kristi. Paapa ninu majemu titun a ma nri iyato laarin awon ti won ni okan ise iranse ati awon ti ko ni. Awon onigbagho ni Korinti, fun apeere, fi iwa anikan-jopon won han nipa didawa ni awon nikan ati aini okan kaanu fun awon asako. Awon ijo Antioku ni ona miran kiyesi oro naa, won si ran awon arakunrin ati arabinrin ni Jerusalemu lowo kuro ninu iyan, won si ran Barnaha ati Paulu jade lo fun ise iranse koja asa.

1.       FIFI IGBAGBO IJO SI ISE: Eto se iranse ijadelo to nipon maa npese eri to daju ki ipejopo, le mu igbekale eko ni baada ki won si wa ona lati fi won si ise ni gbati won ba nse agbeyewo.

2.       PIPESE AWON OHUN ELO FUN IJERE OKAN AGBAYE:  Ijo ti o  ba seto ti o si se irubo lati na ohun gbogbo lori ise iranse ijädelo maa nni ipa lori gbigbooro ihinrere.

3.       SISO IWULO AWON ONIGBAGBO DI MIMO: Ijo to ba lowo si ise iranse ijadelo maa nru awon omo ijo won soke lati mu ki awon ebi, awon ohun ini ati awon akoko won wa ni arowoto fun Olorun Ise. A.A. 5

4.       MIMU IJERE OKAN AGBEGBE GBOORO SII: Iru okan yi ma nfi kun anfaani pipese ninu ikoni awon Ajihinrere ijo, olugbin ijo ati awon oluko Bibeli fun ise iranse asa milan.

AWON ONA LATI LOWO Sl 1SE IRANSE IJADELO: Gbogbo Kristieni ni o le lowo si ise iranse ijadelo kii se nigba ti a be jade lo si ede tabi asa miran nikan, sugbon nigba ti a wa nile pelu. lye onka ti a ngbo ti aye ti npo si loorekoore nipa awon ti won ko gbo ihinrere maa nmu awon ti won nife si ise naa rewesi. B i a ko tile de odo gbogbo won, sibe a le kan die lara ninu won. Kristieni ti o kan gbongbon le beere. “Bawo ni mo sele je  iranwo? Kini mo le se lati fi yato han”? Nigba ti a bajowo ara wa fun Olorun. Oun ni oniruru ona lati lo wa fun ise ijere okan agbaye. Awon ona ti a Ie fi lowo ninu ise iranse niyi.
A,      KIKO ILE AGBARA ADURA: Laisiyemeji, adura ni orisun ise iranse ti o ga ju. Jesu so wipe “E gbadura si Oluwa ikore, ki o ran alagbase sinu likore Re” Matt, 9:3 Onigbagbo kookan le kopa ninu adura ti o muna doko.

B.      KIKO IJO ATI EBI NIPA ISE IRANSE IJADELO: Niwon igba ti awon onigbagho ba nmo si nipa ise ijere okan agbaye loni, beeni won o ma tiraka ati lowo ninure. Eko ni  o ma nsi oye ati oju eniyan paapaa fun eniyan ni iran ise ti o wa ati se.


D.      ISE AFIKUN ETO ISUNA: Olorun ti fun awori iko eniyan Re ni sure ti a se iyebiye.ninu oro Paulu si awon ara Korinti ninu iwe Korinti Keji 9:6 si nsise si awa naa pelu. Eni ti o funrugbin kiun, yoo kore kiun, eni ti o si funrungbin lopolopo yoo kore pupo” ififunni ti ifaraenijin, itoni ti a gbogbon je ona lati so eso koseemani ilowo si ise iranse ijadelo, nipa fifi ohun ini wa fun ise na. Acts 20:35.

 E.      SISETO AKOJO AWON IRANSE TITUN: Opolopo ojuse lo wa Iori ijo agbegbe lati seto akojo awon osise titun fun ise iranse ijadelo. Olorun le lo Olusoaguntan, Obi, Oluko ojo isinmi ati awon miran fun ipenija, ikoni ati riru awon ado so ipe Olorun si se loll  paapa.   

ILOWOSI PAJAWIRI ISE IRANSE IJADELO: Ni wakati kookan  ni a nbi egbeegberun omo sinu aye ti egbeegberun eniyan si nku. Egberu lona egberun ni ko tile se awari ijinle ati pataki aye won ki won to koja lo si ayeraye okunkun ati inira.

IWOYE BIBELI LORI ISE IRANSE LJADELO: Awon eniyan kan gbagbo wipe ise iranse jadelo je itankale ijo Gusu Amerika ati pelu ijagaba asa nwon lori wa. Awon miran tile wo ise iranse  ijadelo bi itankale ipa oselu ati abojuto eto Iori awon orile ede ti ko dagba. Sibe awon kan tile gba pe ise iranse ijadelo je itesiwaju olaju awon akonileru. Iru ero bayi lori ise iranse ijadelo ko b’ogbon mu ko si ba Bibeli mu pelu. Lati inu iwoye Bibeli, ise iranse ijadelo ko bere wa lati odo eniyan. Aba ise iranse ijadelo wa lati ado Olorun. Olorun feran eniyan ti o da to bee ge, ti o je wipe ninu isote won, O wa ona lati ra won pada ki O si mu won pada bo sipo.  Kii se pe Olorun nwa awon alaigbagbo nikan sugbon o mu ki okunrin ati obinrin lowo ninu kikede ihinrere.

MAJEMU LAELAE: Majemu Iaelae lo se afihan eto Olorun nipa ise irapada Ninu ilepa Re ti o ga ju lati pese igbala fun gbogbo eniyan ati lati so nipa iroyin aya ti ipese yi, Olorun fi ara Re han ni yiyan awon eniyan ti o si ya orile ede kan soto. Bakanna ni O si tun to orile ede miran lo ni onuruuru ona. A ran Jonah lo si ilu awon keferi lati waasu fun awon eniyan Ninefe.

IDI IGBALA: Iran eniyan ti kuro ninu ife Olarun ni kete ti Adamu ti se aigboran si Olorun. Itan so nipa bi aye ti njinle ninu iborisa. Gen 3:1-8, Iwe Genesisi fihan orisun ese ati wipe Olorun ni lati se idajo.





PESE FUN GBALA: GEN. 3:15, Ninu gbogbo majemu Iaelae, Olorun  npese eniyan ti yoo o ti jeri fun awon orile ede nipa ipese Re ati ohun ti oun Olorun je. Isreali ni ona ti Olorun fe lo lati soro sugbon kii se si gbogbo eniyan ti yoo gbala. Ni kete ti gbogbo eniyan ti dese ninu Adamu , ni Olorun ti seleri Olugbala ti yoo pese imupadabosipo ati ibasepo pelu Re. Niun ipe Re si Abrahamu, Olorun se opolopo ileri “ Ati ( nipase) ninu re ni gbogbo aye yoo ti di eni iibukun Gen 12:1-3

MAJEMU TUNTUN: Alaye Jesu niinu iwe Johanu 30:21 “Gege bi Baba ti se ran mi bee ni mo ran yin pelu” Se alaye ni kukuru nipa ohun ti ise iranse ijadelo tumo si ninu majemu tuntun. Iwe ihinrere se akosile ijowo ara eni ti Jesu se ni mimu ise iranse ijadelo ninu eyi  ti Baba Re ran. Bakanna ni iwe Ise Awon Aposteli ati Episteli ni akosile bi ijo se gboran si ase nla ti Kristi pa fun won, bi a ti se farahan ninu ise iranse ati aye Paulu Aposteli.

ETO FUN 1SE IRANSE LJADELO: Fun nkan bi odun die sehin ni Ijo ti ndagba ni oniruru ona. lati se ise iranse ijadelo. O  je ohun ti o se pataki pe a ni oye nipa eto O!orun fun ise iranse ijadelo gege bi a ti gbe kale ninu Bibeli ati ipa ti o ni fun wa ninu ise ti o ti pari loni.

ILEPA ISE IRANSE IJADELO: Ise ranse ijadelo ju akojopo ohun rere ti awon eniyan se lati fun awon alaini ati fi ran alainiranwo lowo lo. Ise iranse ijadelo pelu ibamu Bibeli tejumo biba aini awon eniyan pade nipa temi, ati lati dari iru eni bee lo si ibi ti Olorun ti le lo lati ba aini awon elomiran pade.

A.                                                               B
IJERE - OKAN                                      SISO N DI OMO LEYIN


         (MISSION GOAL)
   ILEPA ISE IRANSE IJADE


      GBIGBIN IJO
 
 
\

A. IJERE OKAN:        Ijere okan ni a Ie se ni ona meta:
i.        Nipa igbe aye wa
ii.       Nipa kikede (ibanisoro) ihinrere ati
iii.      Nipa riro eniyan tabi fifoju sano fun idahun ti a tona.
Eni ti  o nse ijere okan gbodo maa kiyesi itesiwaju ninu eni ti oun nwaasu fun. Igbese lati se ipinnu fun Knisti nbere lath kikobiara si ono ihinrene ti o n gbo ati ona ti asese qhaqho nfese awon miran mule.
B.      SONIDOMOLEYIN: Leyin ti iwaasu ti pari, ti eni naa ti pinnu ati fi aye re fun Kristi, ohun ti o kan ni lati maa ko ni awon eko ti o file di omo eyin Kristi nitooto Matt. 28:19-20. Ohun kan ni fun wa lati jere okan, ohun kan ni ki a gbin ijo, ki a ko ile, ki a fun awon onigbagbo ni itoni, ki a baptisi won sibe ki a kuna ati so won di ommo leyin.

D.      IJO GBINGBIN:  Gege bi iranse ti o jere okan ti o si ti so won di omoleyin, O gbodo tun gbiyanju lati dari won sinu ipejopo awon onigbagbo ti won npin ibasepo kannaa pelu Kristi, Ni tori o ti di ebi ijo ati paapa ijo ti a wa ni agbegbe , asa ati ede kanna.

ENIYAN T A 0 BA PADE N SE RANSE IJADELO ACTS 1:8
1.       E0:    Eniyan ti ede kanna
Eniyan ti ede asa kanna)
Eniyan ti ede igbagbo kanna)
Sugbon ti won ko di atunbi ) JERUSALEMU

2.       E1:    Eniyan ti ede kanna )    
Eniyan ti asa kanna)
Eniyan ti igbagbo atoto) ‘
Sugbon ti won ko di atunbi)    JUDEA

3.       E2:    Eniyan ti ede kanna )
Eniyan ti asa yato)
Eniyan ti igbagbo wo yato)
Sugbon ti won ko di atunbi) SAMARIA

4.       E3:    Eniyan ti ede to yato)
Eniyan ti asa to yato ) OPIN  ILE AYE
Eniyan ti igbagbo to yato)
Sugbon ti won ko di atunbi)

IRANSE TI IJO RAN JADE: Ni nkan bi ogorun odun akoko, awon onigbagbo ti mu ihinrere de Antioku; ti ijo pelu si ran Paulu ati Barnaba si ile alawo funfun. Ni ogorun odun lona ogun, iru igbese bayi si nte siwaju. Awon ijo agbaye keta nipase awon iranse ti a ran jade bere si ran awon eniyan koja si asa miran nipa awo iranlowo ti won fun won lath de opo ilu ati eya. Sibe nigba ti won kiyesi eko Kristi ninu iwe Luku 12:48 “Lowo eni ti a fun ni pupo Ia o ti bere pupo” bee sini di ojuse wuwo ninu ijo.

idi niyi ti jo ni lati lowo ninu ise iranse ijadelo lati mu ipinnu tabi eto Olorun re se.Ilowo ninu dagba ise iranse iranjade gbodo ni pa ati igbe aye ti a jina ninu ijo.

OJUSE ADARI: Adari ni awon ojuse kan ti o se pataki ni eyi ti o gbodo maa fi si ise ni gbogbo igba fun imunakodo ise iranse ijadelo, bi beeko ijo ko ni mo ohun ti o ye lati se.

FIFI ILANA LELE: Bi awon jo kan ba tile gbagbo pe ilana akosile ise iranse ijadelo ko se pataki at ti awon miran ko tile ronu lori re, sibe Emi Mimo nse itoni ti o ja gaara ti o si dan moran. Ti a ba nsoro lori fifi ilana. lele, o nso  fun wa bi ijo ti ni ifara-eni-jin fun imuse ojuse tire ninu iwaasu ijere okan agbaye.

FIFI APEERE LELE: Botile je wipe Olusoagutan lo gbodo je ohun fun ise iranse ijadelo ninu ijo. Ohun ti o kan gbongbon gbodo je ifisise ni ona ti oni ipa ti o dara. O  si gbodo je eni ti yoo maa fi apeere han fun awon ijo re ninu ohun gbogbo.

ETO:  Awon jo miran maa nwo Diakoni tabi alagba gege bi Olusoaguntanninu ise iranse ijadelo.
Opolopo ijo ni won mo anfaani ti o wa ninu igbekale igbimo fun ise iranse ijadelo lati fun ni aye ti o ga julo.  Ete igbeke!e igbimo kii se lati ran Oluso-aguntan tabi awon igbimo alabe sekele lowo tabi ijo ninu ojuse ise iranse ijadelo bikose 1atiseto bi ijo yoo se lowo ati lati kobi ara ti o ye si onuruuru ona ise iranse ijadelo ni ona ti yoo fi muna doko. Oludari agbo ni o si gbodo se eleyi.

AWON OJUSE IJO: Opolopo Kristieni ni oye ilepa ise iranse ijadelo ko ye. Won ni oye ti o kuru nipa lilowo si ikede ihinrere ati gbingbin ijo si ilu ati asa miran. Ijo agbegbe ni ojuse ni siso fun awon omo ijo won nipa ise iranse ijadelo ati bi a tile ran ife awon iranse ti a ran jade lowo.

1.       EKO ISE IRANSE IJADELO: Bi apejopo yoo ba dagba ninu lilowo Si ise iranse ijadelo, a nilo lati ko won daada lori ise iranse ijadelo. Eyi si je otto ni akoko ti a wa yi bi aye ati ogbon ise iranse ijadelo ti nyipada lojoojumo. Bi awon eniyan ba ti nmo si nipa aini ati ohun ti won yoo se ati bi won yoo ti se, bee ni won ti gbiyanju ara won ni sise si.

2. IDAMO ATI PIPESE AWON IRANSE TUNTUN: Fun swan ipeere ni anfaani ati iroyin ise iranse ijadelo ati bi ilowo si won se le je iranwo. Pe awon ti idaniloju wa pe won ni Ebun Emi, awon ti a dagba ti won si ni iriri ti o munadoko ninu ise iranse, niwon igba to je wipe ete Oborun ni fun won lati sise fun oun gegebi Kristieni. Math 28:26.
3.       SISONIDOMOLEYIN: Niwori bi o ti je ase Kristi “So gbogbo orile ede di ornoleyin”, awon ti won tele ase na gbodo so ara won di ornoleyin. Awon omo eyin Re gbodo je eni ti yoo so eniyan pupo di omo leyin si. Matt. 28:19.

4.       ADURA: Lati igba ti ijo akoko ti bere ni Antioku ni adura ti je agbara is iranse ijadelo. Ni idahun si adura awon onigbagbo Olorun ti ba satani ja ki ise iranse ijadelo ba le ni agbara ifowokan. Nipa bee onigbagbo ni lati maa gbadura fun gbogbo ipele ise 1ranse ijadelo. 1 Tess. 5:17-1 9.

5.       IDAHUN SI ETO ISUNA: Bi ijo ba nmu ojuse ise iranse ijadela se, a je wipe eto isuna kii se eru wiwo fun won. Ninu Matt. 6:20-21 Jesu salaye pataki fifi owo wa pamo sinu ohun ti ayeraye nigba ti o so pe ki e to isura yin jo fun ara yin ni orun. . .Awon eniyan ti o ni okan fun ise iranse ijadelo yoo fi ayo kore 1. Pet. 1:4.

6.       ITOJU AWON IRANSE LAKOKO ISIMI:  Isinmi kii se ifehinti fun awon iranse, bi a tile je wipe o je akoko ti a wa fun isinmi, a je akoko ati tun ebi se, lati tun ijo to, ati ibasepo to moyanlori, pinpin ohun ti Olorun ti se lori papa, anfaani ati ire ti eniyan ti ri gba ati lati so murasule fun ise ojo iwaju.  Awon ifisise itoju ati iranwo ti ijo ba pese yi le je irusoke fun iranse ninu Emi ni eyi ti yoo le mu ki o pada sori papa fun ise. Awon ona wonyi ni ijo fi le je iranlowo.

a. To iranse ati ebi re lati te si atunse awon ajeji isele ti a suyo nigba ti ko si nile.
b. Seto ile gbigbe ati isuna oko wiwo gege bi ibeere
d. Pese itoju Olusoaguntan nipase igbaniyanju, ni ibasepo ati imulokanle pelu iranse ati gbogbo ebi re
e. Gba lati se iranlowo fun iyawo Olusoaguntan gege bi ore ati bi iyawo iranse ti a ran jade.
e. Mu won lokun, seto ki a si tun se irawon nipa eto eko.
f. Mura sile fun pipade iranse si ori papa nipa pipese fun gbogbo eto isuna ati awon ohun miran ti a ye. -

AWON AMUYE IRANSE TI A RAN JADE: Nitori oniruru ojuse se iranse ijadelo, iranse ti a ran gbodo ni eri ti o daju pe ni gbogbo aye re, iwa Kristieni njeyo ninu re lai tun se iwadi Ati daju saka wipe a gbodo je atunbi ki a to le pe bi iranse.
1.       IDAGBA NIPA TEMI: Niwon igba ti iranse ti a ran ko ti je onigbagbo afenuje, a gbodo je eni ti o ni eri pe o dagba nipa temi Iai beere. O gbodo mo Olorun ati bi a ti oro Olorun lati ba aini tire gan pade.

2.       IDAGBA NIPA IBASEPO PELU ENIYAN: Iwa tito ati ibasepo rere pelu eniyan se pataki fun iranse ti a ran jade. O ni iati se itewogba pelu ife Olorun ti yoo fun ni igboya lati so mo eniyan, awon alase ti o ga ju lo, awon eniyan ti o nsise iranse pebu, ko si aye fun “Emi” ibaje, iwa buburu, awawi ati emi ni mo wa nbe.

3.       IDAGBA NIPA ETO EKO: Eko ise owo ati eko iwe ati awon iranwo ise iranse miran je pataki bakanna bi a ti nbere. Ni a fikun, opo igbimo ki nbeere fun odun kan, o kere ju ninu imo eko Bibeli lowo awon ti won ko lo si ile eko Bibeil tabi serminari.

4.       IDAGBA NIPA TARA ATI EKO EDA ENIYAN: Oniruuru anfaani ibagbepo eda ni orile ede miran bere fun okun ti o to nipa tara. Bakanna ni o se pataki fun awon ojulowo kosemani eniyan fun ayika ti a nilo isegun.

IBASEPO: Ibasepo iranse ti a ran peiu ijo, si awon iranse miran ati laarin ebi re se pataki fun idagba oun funrere ati si imunadoko ise iranse yi.

1.       SI IJO: Ise iranse ijadebo tejumo idagba ijo ni gbogbo agbaye. Ni ibasepo ojoojumo, bi a tileje pe, ohun ti o kan iranse yi gbongbonje ijo meji: akoko, ijo ti o ran an jade ati ekeji nibi ti o ti nsise iranse.

2.       SI AWON IRANSE MIRAN: Ni lie, a rorun iati yara yan ore ati awon alabasisepo Kristieni tabi ki eniyan yan awon aniruuru Kristieni ti yoo le ba ni sise papo ni tori asa kan naa ati ede kan naa. Nigba ti iranse maa nni odiwon asa ati ede ni orile ede tabi asa miran ti kii se tire. Ise re ati ibagbepo pelu eda yoo din ku paapa julo ni awon odun ti ko i ti ko ede won ti ko si ti darapo mo awon eniyan agbegbe na.

3.       LAARIN EBI: Ninu iriri ati otito ti o wa ninu ibagbepo ni asa miren, ibasepo ebi kii maa nsaba ri era re bi alejo. Bi obi, paapa juio Baba, se maa nni igbagbo ati igbekeie ninu Oluwa maa nfl iyato han. Igbe aye re ninu Emi ati ilepe re yoo tubo ran ibasepo laarin ebi lowo ati ebi si awujo. Bi o tile je wipe kii se gbogbo ebi ni o ma nkopa ninu eto kanna, o se pataki ki enikookan ni oye ise naa ati pe gegebi ebi, ki a sa ipa tire ni papa ise iranse. Ilowosi ati aseyori maa nmu ki a bori gbogbo isoro.



AWON AYIPADA ATl IPENIJA TI O  WA NINU ISE IRANSE
Gege bi iranse ti a ran ti maa ndojuko iji ati isoro, bakanna ni a o si wa, sugbon o beere fun akoko ti o yi pada Emi Mimo ti o je awako ninu jo akoko ti o si mu won laaja nipa itoni, si ndari awon Adari oni sinu awon orisun tuntun ati awon ona ibanisoro ti a muna doko.

a.       ORISUN EDA TUNTUN: Aye ti a wa yi nsare lo ti oun ti  ifekufe inu re. Bakannaa ni anfaani ati awon ona ti a nilo fun iwaasu ijere okan aye npo sii.

b.      ISE ‘IRANSE IJADELO AGBAYE KETA: Agbaye keta tumo si awan orile ede ti won gbagbo ninu ijoba sugbon ti kii se ninu Olorun ti Russia ati U.S. nse adari won ni akoko ogun agbaye keji. Opolopo ijo ti a gbin ni lie Alawo dudu nipase awon iranse iwo orun wa di ti ijoba ara eni ti o si dagba. Fun opolopo, ominira ti dagba de bi pe won di iranse ti ijo ran.

Opobopo awon iranse agbaye keta wa lati mu igbimo ijo ati ise iranse India, Fillipi, Brazil ati Naijiria. Nigba ti eto isiro nyipada kankan ti won si ni ipenija laarin odun 1 982 lati ni Egberun meedogun awon iranse ti won ran jade pelu iranlowo ijo agbaye keta idamesan nimu mewa ni won kun fun iwaasu ijere okan tabi ijo gbingbin, papa ju  ti awon ti won wa lati iwo oorun lo.

d.     AKOKO KUKURU FUN ISE: Iwulo fun akoko kukuru ise ko ni odiwon. Ife  ndagba si. Ni odun 1965, awon osise akoko kukuru bii 580 sise pelu awon ise iranse ijere okan. Ni odun 1980 onka won ti to 17, 608. Ni sinsiyi, ida mejilebogbon ninu ogorun ninu awon iranse Iwo Oorun ru won nlo akoko kukuru pelu ete pe ohka naa yo po si. Eyi ni iroyin ti a nreti titi di isinsiyi.

e.       ETO IBANISORO NI ASA MIRAN: Bi awon orile ede tuntun ti ndara po ni nkan bi odun meedogbon seyin, (titi di ogun 1979 ni awon ti won kii se ara iwo Oorun ti nji girl pelu igberaga ati ori pipe ti a ga fun idanimo). Ni ile Eesia ati Alawo dudu, esin adayeba kan bi Shitism ati animism gbiyanju lati gbajoba lowa awon orile ede tuntun.
Opoopo ohun ni o npe Bibeli ni iwe awon alawo funfun ati pe Kristieni je esini Iwo Oorun. Won ko iwaasu won gege bi asa ati eniyan won ti lodi si.

e.       OYE ALAYE OTITO BIBELI: Alaye otito Bibeli farahan ninu ise iranse ijadelo lati soro yekeyeke ki won ba le so gbogbo orile ede di omoleyin gege bi ase inu iwe
Mat. 28:20. Ede Griki fun awon orile ede ni asa yi ni “Ajeji” tabi ni ede tode oni “Apejopo enlyan oto”
Alaye otito Bibeli tumosi liloye, alaye ati ifisise otito Bibeli gege bi asa. O  wa ona lati salaye otito ni ede ati ona ti olugbo ni asa miran file dupe.

f.       AKOJOPO ONIRUURU IGBAGBO: Kristieni kookan npo si. Qpo nwoye pe Kristieni je esin kan ti a fi ogbon on eniyan gbe kale lati fagagbaga pelu esin nia kan ni aye. Bi gbogbo esin ba ni ohun rere ninu won, bi awon kan ti so wipe kini idi ti Knistieni fi dara ju awon esin yoku lo? Kini idi ti a fi nyi esin eniyan pada paapa julo eyi ti o ni gbongbo? Akojopo afiwe oniruru igbagbo yi ni a npe ni SYNCRETISM” Oniruru ona ni o wa ti awon eniyan fi ngbojege lati fi Olorun we esin miran. Olorun si kilo gidigidi fun awon eniyan Re lati ma se darapo ma awon ara Kenani ati esin won.

“SYNCRETISM duro lori ileri pe Otorun ati oro Re dara pupo sugbon ko si Kristieni ti o dara pelu otito kan gbogi ti esin eniyan leduro le lori.



No comments: