Email:- groundoftruth2@yahoo.comWebsite:- www.groundoftruthbibleinstitute.blogspot.com
MOBILE 08056008526. A.C.L. 125 & B.M.T. 021
HANDOUT
IPE SINU
ISE IRANSE IHINRERE
ADVANCED
CHRISTIAN LEADERSHIP (100 LEVEL)
ITUMO
ISE IRANSE
Nigbati awon omo eyin nse ariyanjiyan lori oro yi pe
tani o tobi ju. Jesu bi won lere pe “Tani o tobi ju, eni ti o joko lati jeun
tabi eni tio nse iranse fun un”? Si opo eniyan eni ti o joko ni, sugbon Jesu
wipe “Emi nbe larin yin bi onise
{Lk.22: 24-27}. Awon omo eyin re mo pe oga awon ni Jesu nse, ati wipe awon ni
omo eyin re, sugbon sibe o tun nse ise iranse fun won. Oro Giriki ti a lo
nibiyi je oro (Diakoni), ti o tumo si “Lati se ise iranse”. (DIAKONES)
Eyi ni iranse ti o si je oro ti awon oluko Majemu titun fun ise iranse.
AWON OLORI ONIGBAGBO JE “Iranse”
tabi OJISE: Esin onigbagbo nikan ni esin kan soso ni gbogbo aye ti a npe
awon olori won ni iranse tabi ojise. Idi ni pe, Jesu ti oje olori won ti se ara
Re ni iranse tabi ojise. O fi eyi han ni gba ti o we ese fun awon omo eyin
Re,{Jn.13: 13-16}O mu awo iranse wo, o si so fun awon omo eyin re lati se bee
gege.
Gbogbo onigbagbo ni a npe sinu ise iranse, nitori ase
ti o wipe ki a se bee gege ko wa fun awon olori nikan bikose gbogbo onigbagbo.
Eyi ni Aposteli Paulu salaye fun ijo Korinti ninu .1 1Kor.3:5; 4:1,2 Kor.4:5.
Aje iranse ni orisi ona meta:
1. A
je iranse fun Olorun.
2. A
je iranse fun Onigbagbo elegbe wa.
3. A
je iranse fun awon eniyan agbaye.
Ni gbogbo ona ni a gbodo tele apeere Jesu Oluwa, Eni
ti oni iwa Olorun, ti osi fi gbogbo re sile ti O si mu awo iranse. Ore ara re
sile O si gbe igbe aye igboran de oju iku. (Filipi 2:6-8) “Gbogbo awon eniyan
Olorun ni o ye ki won mura sile fun ise isin onigbagbo lati ko ara Kristi.
(Efesu 4:12) sugbon larin ara Kristi ti ise ijo, Orisirisi eniyan ni a fun ni
Orisirisi ise tabi ise iranse lati se, ki eniyan Olorun ba lee mura sile fun
ise iranse.
ITOKA
SI IPE: Ipe tabi ipe Olorun ni gbongbo re ninu Olorun ati gbogbo
iwe Bibeli. Ti a ba woo daadaa, ipe tabi ipe Olorun pin si ipa meji gbooro:
1.IPE GBOGBOGBOO
2. IPE PATAKI
2. IPE PATAKI
IPE
GBOGBOGBOO
Eyi ni akoko ati ipinle ti o wa fun gbogbo eniyan inu
aye loni. Leyin dida eniyan, esu wa lati dan eniyan wo, eniyan si subu si owo
esu. Lati igba isubu yi ni eniyan ti ntele itanje esu ti eniyan si ta eto
Olorun fun aye re. Eyi ni o si le eniyan kuro niwaju ati ninu eto Olorun.
Eyi lowa mu Jesu wa sinu aye yi lati wa ku fun iran
eniyan lori abgbelebu. Olorun je mimo, eniyan si je elese julo. Ipo ese buburu
yi ni o da ogbun nla saarin eniyan ati Olorun, ti eniyan elese ko lee de odo
Olorun mimo.
Sugbon Jesu ni ori igi abgbelebu duro si aarin ogbun
na osi na owo Re kan si eniyan ati okan to ku si odo Olorun ti osi wipe “Emi
ni ona ati otito ati iye: Ko si eni ti o le lo si odo Baba bi kose nipase mi” (Jn.14:6)
Nitori idi eyi, ipe gbogbogboo:Eyi
je ipe sinu ijoba Olorun ,ani ipe si ironupiwada kuro ninu ese. (Ise A.A.3: 19,
IIKor.5: 19).
PATAKI IPE GBOGBOGBOO:
Gege bi o ti se pataki fun awon omo wa lati ni eko alakobere ki won to le
tesiwaju de ibi giga, bee na ni ipe gbogbogboo. Eyi je. ipinle lori eyi ti ise
Oluwa duro le lori Bi a ba wo aye awon Leefi fun apeere, ao ri ohun kan ti a
npe ni akosile-ibi (GENEAOLOGY), Ki enikeni ninu
won to le ye lati sise ninu Tempili, oruko re ni a
o farabale wo ninu akosile, sugbon awon
ti a ko ba ri oruko re ni a pe ni awon Odibaje. (Ezra
7:1-6;2;58-63,Mat.1:1-17).Nitori idi eyi, enikeni ti Olorun yio ba pe fun ise
pataki yio koko dahun ipe ti o logo yi, ki a
si ti ko oruko won sinu iwe iye.
|
IPE SINU OJUSE
GBOGBOGBOO
|
O je otito pe gbogbo wa ko le je Oluso-Aguntan tabi
Ajihinrere ati bee-beelo, sugbon o je ohun ti o lodi lati ro wipe bi eniyan o ba
je Oluso-Aguntan tabi Oniwasu a je wipe Olorun ko pe iru eni bee.
Bi a ba gbe igbe aye wa de oju osuwon Olorun, a o ri
wipe gbogbo onigbagbo ni won ni ojuse ototo ti a pe wa fun lati se fun Olorun
ki a ba le mu ojuse gbogbogboo se. Eyi je ohun ti a le se, lati se awari otito
yi ninu aye wa ni lati joko, ki a si ye aye wa wo, ki a si gbadura si Olorun
pelu ibeere pe agbegbe wo ni O ti fe ki a ti sise ninu ogba ajara Re?.
|
|
Ipe Pataki je pipeni si ojuse pataki kan ti elomiran
ko le se. Eyi kii se ohun miran bikose ireti orun nipa onigbagbo kan. Akosile
orun fun enikan yi ni a npe ni IPE PATAKI.
Maaku 3:13-15 awon ti a npe nibi yi kii se pe a pe won
kuro ninu aye nikan, sugbon a pe won larin awujo. Jesu lo sori oke, O si pe
awon ti O pe ni Aposteli ki won le maa ba gbe ki o si le ma ko won, ki o si le
maa ran won lo lati le emi esu jade ati lati mu alaisan larada.
Awon wonyi ni won sun mo ju awon ogooro lo. Nitori idi
eyi, Ipe pataki ni pipeni jade kuro ninu Ipe gbogbogboo lati mu ise pato kan se
ninu ara Kristi, eyi si ma nwa pelu itoni.
1. Olorun eto (Efesu 3:1-11). Ipe Pataki wa lati
mu eto Olorun kan pato se. Olorun kii se bo ba ti wu ki ori, sugbon o je
2. Lati
gba ise lowo enikan to ti f’eyinti tabi ti o fe f’eyinti.
3. Lati
di awon alafo ati lati yo awon eniyan kan ninu ewu.
4. Lati
da ohun titun kan sile pelu akanse ona (Ikor.2:9)
5. Fun
ise iranse, fun apeere awon eniyan mimo ati imudagba ara Kristi.
(Efesu 4:11-12).
ALAYE
ITUMO IPE
Alagba “Webster” salaye Ipe gege bii pipeni
sinu ojuse, tabi si ibi ise, tabi igba-ni s’ise kan pato. Nitori idi eyi a le
tumo Ipe gegebi idaniloju atinuwa nipa ise pato kan ti orun ti pese sile fun
okunrin tabi obinrin pato kan.(Gal.1:15-16)
|
AWON
TI OLORUN KO PE
|
Awon ti Olorun ko pe ni a nda mo nipase awon nkan wonyi:
1. Aiko
le fi ara da iponju gege bi ogun rere ti ti Kristeni.
2. Ifarahan
ifagagbaga tabi idije.
3. Bibere
ise iranse gegebi abajade iyolenu awon obi..
4. Sise
ise iranse gegebi ise ti o ku leyin ifeyinti.
5. Nitori
ife tabi ipongbe fun owo.
6. Sise
ise iranse gegebi ise ti a ko fun ise asela.
7. Bibere
ise iranse fun Olorun lati itara tabi ewu (wi wu)
Igbese akoko si sise aseyori ninu ise iranse fun aye
wa ni liloye ipe naa. Opo iranse ati ise iranse ni won kuna nibi yi.
Kikuna nibi yi tumo si kikuna laelae. Ipe Olorun yio
bere si munadoko ni kete ti a ba ti loye ohun ti orun nreti lori aye wa..
Gbogbo aye ti Jesu gbe ni o je lati mu ohun ti a ti kowe nipa Re se.
(Matt.26:22-24).
BAWO
NI ENIYAN SELE MO WIPE OLORUN NPE OUN SINU ISIN ONIGBAGBO
1. Ipe
sinu ise isin Oluwa je idaniloju ti Emi, nitori idi eyi, kiki awon eni
irapada ni o le gbo ohun Oluwa yekeyeke. (II Kor.2:14,I Oba.19:12)
2. Olorun
funra re ni o maa lo npe eniyan sinu ise isin. (Johan.15:16, Esk.34:23-25)
3. Ona
ati ogbon ti Oluwa fi npe sinu ise isin le yato si ara won:
a.
|
AWON
IGBESE LATI
MO IPE SINU
ISE IRANSE
|
b. A
fi ororo yan Dafidi lati owo Samueli. (II
Oba.16:11-13)
c. Amosi
gbo ohun iranni-nise Olorun. (Amosi
7:14-15)
d. Paulu
gba ipe re nipase iran orun. (Ise A.A.
26:15-19)
e. Timotiu
ati Titu ni a pe nipase ohun elo Paulu.
(Ise
A.A.16:1-3,Itim.1:3, II Kor.8;16-17,Titu 1:5).
Oluwa npe olukuluku gegebi o ti ye. A ko gbodo ma wo
apeere ti elomiran lati fi idi ipe tiwa mule, tabi ka seto ise iranse wa gegebi
ilana kan ti eni kan ti o lo tele. Olukuluku eniyan ni o se pataki. Olorun si
lee fun enikookan ni ilana pataki ninu ipe re.
1. Nipase
itenumo Emi Mimo, eniyan yio bere si ni fura pe oun naa ni inu didun si ise
isin fun Olorun.
2. Ipongbe
yi, ni oro aikopeye lati inu wa yio bo mole.(Fili.4:13)
3. Bi
o ti wu kori, ebun isise wa yio wa di eru wuwo fun wa de bii pe yio maa rowa
pe; “aye ati ise iranse ni se pataki julo ti eniyan lee ni.”
4. Awon
Ebun Emi Mimo ti won yio waaye idagba fun ara won laipe yio wa bere si fi ara
han (II Tim.4:14, II Tim.1:6, Ise A.A. 13:1-37)
5. Oluwa
yio fi idi ipe wa mule ni oniruuru ona, bakan naa ni atileyin gbogbo yio wa fun
bi a se nlo sinu ise Oluwa.
Ifororoyan ijo nipase adari ti a yan yio fi idi
ifororoyan ti Oluwa funra Re ti fi yan wa mule. (Ise A.A. 9:15;13:2)
Akoko wa fun ifororoyan, bee si ni akoko wa fun
idelade. Leyin ti o ba ti ri idaniloju Ipe Olorun ninu aye re, o ye fun o lati
mu suuru de asiko iran-jade ti Olorun ati ti ijo. Ranti DAFIDFI, JOSEFU ati
ABRAHAMU.
Mase gbagbe pe aigboran si ipe Olorun je ese, masi se
tun gbagbe pe nipa iru aigboran bee iwo yio doju ti Olorun bee si ni iwo yio ja
iran ti o wa yi kule.
DIE
NINU AWON TI OLOYE IPE WON.
1. Jesu
Oluwa wa (Maaku 8:31033, Luku 23:12-18)
2. Samsoni
(Onidajo 13:1-5)
3. Paulu
(Ise A.A. 9:3-16, Gal.1:15-16)
Bi o ko ba farabale wadi ohun ti eleda re ati pese
sile fun o lati se, ko nipe ti o fi di irinse ayalo lowo Oga ti kii se oga rere
(esu). Ogbeni Judasi ko mo pataki ipe re, o gbagbe oye Bishobu ati Aposteli re
ati ifororoyan re, osi gba ogbon owo fadaka, owo ti ko ni na ninu re, o si ta
Jesu Oluwa, bakannaa ni o si ta ipe re atorunwa pelu re. Neh.7:62-65.
IPESE OLORUN FUN
IPE RE
|
Si gbogbo iran nla ni iranlowo nbe fun. Bi ipe re ba
je Ojulowo, Olorun ko ni fi iya iranlowo je o, nitori ti ko si omo ogun ti nlo
si ogun ni inawo ara re.
|
|
OJULOWO IPE
Ojulowo ipe ko nilo lati maa toro baara fun owo tabi
ohun elo ti a nilo. Opo iranse Oluwa ni won ti di onibaara, bi o tile je pe nse
ni o ye ki won duro de Oluwa ti o pe won, sugbon dipo be nse ni won ngbe apo
onibaara kiri. Eyi ni isoro opo iranse Oluwa ti o so won di onibaara.
1.Ohun ti won npe ni ise iranse ki se ise iranse rara
bikose itara lasan, bee ni Olorun ko ni pese fun itara.
2.Opo eniyan, ko
fe lati gba Ojuse: Ti o si je pe leyin ipe, Ojuse nbe. Nigba ti Olorun pe Abrahamu, O
fun un ni
ileri ati ojuse (Gen.17:1-13;18:16-19). Olorun ko setan lati gbaruku ti o,
ayafi ti o ba setan
lati gba
Ojuse.
3.Omiran ni imurasile tabi eto. Olorun ko ni fi awon
ohun ini re sile bi ko ba si eto ti o dara.
Ki ijoba to le gbe ise, fun agbasese kan, ohun akoko
ti agbasese naa ni lati se ni pe, yio koko siro ohun elo ti o nilo ati bi yio
se se ise naa, yio so asiko ti yio pari ise naa. Iru eyi na ni o sele ninu iwe
Nehemiah 2:1-8 nibi ti Oba ti beere ibeere meji ninu eyi ti iwo pelu nilo lati
dahun re bi o ba je wipe Ojulowo ipe ni o ni, ati pelu bi Olorun yio ba gbaruku
ti o ninu ise naa. Awon ibeere naa wonyi:
a. Ninu ese 4 Oba bere
wipe “ Kini ebe tabi ibeere re?
b. Ninu ese 6 Oba bere
wipe “Ajo re yio ti peto?
Ipe Olorun ko le je gbigba lo patapata lai boju wo
eyin, o gbodo so eto re fun un yekeyeke ki o to le pese fun ise iranse re. Mase
ku gburu lo sinu ise iranse lai gba igbarukuti Olorun. Eyi lofaa ti opo iranse
fi di onibaara ki won to le gbe aye won. Bakan naa ni ise iranse pelu ko ni lee
te siwaju. Ohun kan ni pe ki Olorun pe eniyan, omiran ni pe ki Olorun ran
eniyan. Bi o ba lo lai je pe a ran o, laipe ni iwo yio pada de. Yanju eyi ki o
to lo.
Leyin ti Esra Wolii ati Olukoni ni ofin Olorun ti gba
gbogbo awon amuye wonyi, ko tile beere fun owo ki a to fun un lopoloplo (Esra
7:10-27). A o se akiyesi- ohun ti o po ninu ese Bibeli yi:
1. Esra
ko gba ominira ayafi igba ti o gba lati se ise Oluwa.
2. Ni
gba ti Esra mura tan, Oba kowe lati fi owo ran ise na lowo.
3. Oba
yonda fun gbogbo awon ti won fe lati baa lo si Jerusalemu.
4. Oba
fi owo ati gbogbo ohun elo sile lati gbaruku ti Esra.
5. Oba
pase fun gbogbo akapo lati fun Esra lowo ni gba kugba ti o ba nilo re.
Bi ipe re ba je Ojulowo, iranlowo fun ise Olorun yio
wa nipa ase, kii se nipa bibebe, kii se nipa imoran, kii se nipa jije
eje, sugbon nipa ase. Ninu 1 Awon Oba 17:2-4,8-9, Olorun ba Elijah soro
lati lo si apa ila oorun “ni tori ti mo ti pase fun eye iwo lati ma bo
o” leyin eyi O tun wipe “Lo si sarefati Nitori ti mo ti pase fun Obinrin
opo kan nibe lati ma bo o”.
Ni ipari, duro
de Olorun ki o ran o ki o to lo, ati pelu, mase gbagbe lati dahun awon ibeere
wonyi: Olorun ko ni gbaruku ti o, ayafi ti o ba ri idahun fun awon ibeere
wonyi. Oluwa yio bukun fun o bi o se nlo ba Olorun ninu adura..
OSUWON
ASEYORI
|
OSUWON
ASEYORI
|
ITOKASI: Bi a o ba soro nipa sise
aseyori ninu ise iranse, opo le maa wo awon ohun ti owo won ti te gegebi
aseyori. Sugbon otito ti o wa nibe nipe ohun ti owo ti te kii se aseyori, ko
tile le duro gegebi aseyori. Sugbon iwo yio je alaseyori ni gba ti o ba pari
ipe re. Eyi nipe, ni gba ti o ba se ohun ti Orun ko sile nipa re pari, ti o si
dun mo Olorun eni ti o pe o ninu, nigba naa ni o se aseyori. (1 Awon Oba
10:30).
MIMO AMI
Mimo ami tumo si mimo ibi ibere ati ibi ipari, bakan
naa ni mimo asiko ibere ati ipari. Fun agbasese tooto, o se pataki fun un lati
mo ohun ti yio se. Fun apeere, bi ijoba ba fe lati da oda si oju ona kan,
agbasese tooto yio beere iye ibuso ti oun yio da oda si, ibi ibere ida oda naa
ati ibi ti o ni lati pari si.
Gbogbo ipe ti Olorun gbe le eniyan lori ni o ni ibu,
oro, fife, jinjin ati giga. O ni ona pato kan, bakan naa o ni
aala ti emi, eyi ni ibi ti Eleda fe ki ise naa ko de.
Ni tori idi eyi, o je Ojuse gbogbo iranse lati beere
lowo Eni ti o ni ise Re. Iwo yio je olori awon ope ti o ko ba mo eyi.
1 SATANI
2. AWON AINI AYIKA
3. AWON ARA NINU OLUWA.
AWON APEERE NINU
BIBELI
1. PAULU
JESU
2. SAMSONI
3. JOSHUA
Ni ipari, o nilo lati duro de ilowosi Olorun ki o to
bere ise naa. Jesu ati Johanu Onitebomi duro dee fun bi ogbon odun ki won to
bere ise naa.
Ki Oluwa bukun fun o bi o se nto Olorun lo ninu adura.
No comments:
Post a Comment