Friday, August 11, 2017

IJO GBINGBIN


GROUND OF TRUTH BIBLE INSTITUTE
MOBILE; 08056008526 & 07031821386
HANDOUT
IJO  GBINGBIN
                    
      
                 
          

    ADVANCED CHRISTIAN LEADERSHIP (100 LEVEL)

IJO GBINGBIN

ITOKASI:-    Ninu awon ohun ti ose Pataki ti o wa ninu ijo gbingbin, ko si eyi ti o se Pataki bi eniyan ti Olorun lo.  Ijo se Pataki pupo, ati pelu ninu itan ijo, gbogbo igbiyanju iwasu ihinrere ti ko ba yori si gbingbin ijo, je igbiyanju asedenu.

Ere idi pinpin iwasu ihinrere ni lati gbin gbogbo okan sinu ara Kristi. Ko si eleyameya ninu ara Kristi, nitoripe Bibeli wipe okan ni ara, sugbon ti oni eya pupo.

ALAYE ITUMO IJO: - Ijo tumosi ipejopo  awon eni irapada tabi awon onigbagbo, o sit un je awujo ti o wa laaye, tabi ni oro miran, ni ede “Griki” a npe ni “Ekilesia”.
Ijo je ipejopo agbegbe ti awon onigbagbo, bakanna fun awon eni irapada lati ayebaye ti won tele Jesu Kristi gege bi olugbala ati Oluwa won.  Lati inu iwe ihinrere merin ti o wa ninu majemu titun, iwe Mattew nikan ni o fi idi oro yi “Ijo” mule. Matt. 16:18; 18:17.

Ni ojo pentikositi ni a bi ijo leyin igoke re orun Jesu Kristi. Kristi funra re jewo re wipe a ko iti ko, a ko lori iku ati ajinde pelu igoke re orun re – Gal. 3:23 – 25 a ki ba ti le ri ijo, bi o ba se wipe Jesu ko ta eje re sile – Efesu 1:20.
Ijo je “Awujo ti Emi” ti o si ngbe ni ayika ajoji.  Ijo naa si wa ninu aye, sugbon kii ise ti aye.
   IJO GBOGBOGBO

 Ijo Kristi Matt. 16:18 ni gbogbo aye, “EKKILESIA” ni ede Griki tumosi egbe tabi awujo ti a pe jade, eyi ni awon ti won je okan nipa ti Emi ninu Kristi eni ti ise ori fun Ijo.
Egbe tabi awujo ti a fi eje ra, ti o si nrin deede, ati awon eni irapada ninu Kristi Ise. A.A. 9:31, Efesu 1:22; 4:6; Gal.1:18.
Oro ti a npe ni Ijo, ko so nipa apejo onigbagbo nikan, sugbon o nso nipa awon onigbagbo gangan funra won, paapa nigba ti awon onigbagbo akoko tuka kiri, ninu ile won, won si tun je ijo (Ise A.A. 8:1-3) Bi ko tile si aye onijo di'jo, sugbon gbogbo ara, awon onigbagbo apapo, ani awon Kristieni ti o ti di atunbi ni gbogbo aye.
  IJO AGBEGBE


“EKKLESIA NI EDE GREEK” Ijo ti a gbin lotito ni agbegbe je egbe tabi apejopo awon lotito eniyan.  Ti a ya soto kuro lara awon alaigbagbo, ti won npejopo ni oruko Jesu eni ti won gbagbo, ti won nsin ati ti won muran tan lati gboran si lenu.  O je ipejopo agbegbe awon ti o jewo igbagbo ti won si fara mo Jesu. Kiise gbogbo awon ti won ti jewo igbagbo ni won je olotito.
Bibeli se akosile fifi idi ijo agbegbe mule ni ibi pupo – (2 Tess. 1:1; 1 Kor 4:17, 2 Kor 11:8; Gal. 1:2; Ifihan 2:3) Ijo akoko pelu npejopo ni awon ile, Sinagogu, ibi gbongan ati ibi idanileko ti won sin lo fun isin bakanna ti won ngbe awon ara ro.
                                    AWON APEJUWE MIRAN FUN IJO


1.       Agbo kan -  John 10:16                       5.       Ara Kristi – Efesu 1:22 – 23
2.       Ogba Olorun – I Kor 3:9                     6.       Ibugbe Olorun – Efesu 2:22
3.       Ile Olorun – I Kor 3:9                                    7.       Iyawo Kristi – Efesu 5:25 – 27
4.       Tempili Olorun – I Kor 36                             8.       Owon ati ipile Otito – I Tim 3:15
  ISE ONIPELE META TI IJO

Ijo je ohun ini Olorun, ninu eyi ti o ni inu didun.  Ise ijo ni lati fi ogo fun Olorun, ati lati sin ninu Emi ati ni otito – Efesu 1:18, 5:25 – 27; Ise A.A. 13:2; John 4:23 - 24
Ijo ni ise iranse imupeye fun ara re, kiko ati sise awon omo re pe, ati lati fi agbara kun ki o si fi ese mule. Efesu 4:11 – 16; I Kor 12:1 – 19; Rom 12:3 – 16
Ijo ni ise iranse wiwasu iroyin ayo ijoba orun fun awon eniyan ti o ti sonu, ati ki o si mu won pada si odo Olorun nipase iwasu ihinrere, isodomo eyin ati dida ijo agbegbe sile – Ise. A.A. 1:8; Matt.28:18 – 20; Lk 24:47; Mk 16:15.  Kii se eto Olorun ni lati so gbogbo aye di elesin igbagbo I Tim 4:1 sugbon eto ti Olorun ni fun asiko tiwa yi ni lati jeri fun gbogbo aye nipa ihinrere Kristi, ki a sir a awon eniyan pada lati inu aye fun oruko re, eyi ti yio je ohun alagbara ti ijoba Olorun, eyi ti a o fidi re mule nigbe ipadabo Kristi.
AGBIN IJO NAA


Ohun kan ni lati sise fun Olorun, sugbon eyi ti o tobi ju ni lati se ise na bi Olorun ti nfe ki a se. Agbin ijo gbodo ranti wipe alabasisepo ni oun je pelu Olorun ni kiko eniyan jo fun oruko re. Ise A.A. 15:12 – 14.  Ranti wipe ko ko eniyan jo fun ara re lati ba aini ti imotara eni nikan pade. 
Lati sise fun Olorun, o rorun ju ati sise po pelu Olorun, sugbon Olorun pewa lati sise po pelu Re, ki ise lati sise fun lasan.  Agbin ijo le je ojise Oluwa, Ajinhinrere, Olusoaguntan tabi eniyan kan lasan, ninu eyi ti Olorun fun ni anfani lati da ijo agbegbe sile.
AWON AMUYE AGBIN IJO

AWON AMUAYE TI ARA
A.  O gbodo je eni itewogba nipa olaju ati eko iwe papa lodo awon eniyan ti o ti fe sise.
          *   Eniyan ti ipile re je ti ara oko, yio se aseyori pupo ni adugbo abule tabi ni                                   igberiko.
          *   Awon eniyan olaju ni igboro ko ni fetisile fun okunrin ti o ni ipile ati iwa re lati                    oko wa.
          *   Awon alakowe a ma se aseyori pupo bi won ba ri eni ti eko iwe won ba ara mu.
B.   Nitori eda ise gbingbin ijo, onilo ki agbin ijo ma se po pelu awon oju tabi eniyan titun,     
       o gbodo ni irisi ti o wu ni lode. 
          *   O gbodo je eni ti o setan lati ba eniyan titun pade pelu irorun ki o si le ba soro                        nipa awon ohun ti emi pelu iru enikeni ti o ba wu ki oje.
          *   Ko gbodo je eni ti o nda ara re ya soto tabi ti o nfi han wipe oun ko ni igbadun                      tabi itelorun ni oju awon eniyan papa julo awon alejo.
D.   Ifarahan Iranse: Irinisi ni isenilojo, je ki ifarahan re lode fi ogo Olorun han, nipa pe
       “ki o mon, ki o mo niwon, ki o si je ti eni ti o dagba ati iwon tuwonsi ninu iwoso,    
       bata, iru gige etc.

AWON AMUYE TI EMI
A.      O gbodo je eniyan Olorun  Eni ti o ti ba Olorun pade funrare nipa pe o ti yi gbogbo    agbegbe aye re pada.
          *        Eni ti o ni iriri ibi titun, ti o si le fi igboya pin eri igbala okan re.
          *        Eni ti oni igbe aye onigbagbo ti o dagba ninu iwa, pelu isoro ati igbe aye ti o                               je apere fun iwasu ihinrere.
          *        Eni ti o kun fun Emi Mimo.
          *        Eni ti o ni oye kikun ninu oro Olorun.
B.       O gbodo je eni ti o ni inu didun ninu awon eniyan, ti o si ni ibakedun nla fun isoro      awon eniyan.   O si gbodo ni agbara lati lo otito ti Emi fun yiyanju isoro won.
D.      O gbodo je eni ti a ru soke pelu okan ikaanu ti o kinle fun awon okan ti o sonu (Lk      15:3 – 10) Eni ti o farabale nwa awon ti o sonu, ti ki isu titi yio fi ri omo re mu pada     bo wale (Lk 15:11 – 32) Eni ti o setan lati fi akoko ati agbara re ran elomiran lowo.
E.       Eni ti Adura (Kolose 1:9 – 11; 2:1 – 3; Eph 3:14 – 19) Eni ti o ni ifamiororo yan       Pataki yio ri abayori adura wipe a yan awon eniyan titun kun ijo ti a da sile.
C.       Eni ti iran, ati ti o ni igbekele ninu Olorun.
          *        O gbodo maa rip e oseese nibi ti awon ijoku ti nri idiwo.
          *        O gbodo je eni ti yio ni imulokan le nla ti yio si taku nigba ti isele                                         idomi sini lokan ba sele lati mu wa pada seyin.
F.       Eni ti o ni igboya mimo (Heb 10:35)
          *        O gbodo mura tan lati doju ija ko idojuko eyikeyi ti sub a mu wa, papa ni                             papa isoji.
          *        O gbodo mura lati dab obo ihinrere, ki o si fi idi re mule.

IJO GBINGBIN BERE NIBO?

“O” MERIN TI IJO GBINGBIN Ijo gbingbin bere pelu “Eniyan:.  O fere to oro merin ti o bere pelu “O” ti o si ko ipa Pataki ninu ise Olorun.
1.       -         Okunrin       )
2.       -         Oro              )         SIN SINMI LE ARA WON.
3.       -         Ogbon         )
4.       -         Owo            )

Sugbon kokoro si gbogbo re ni eniyan.  Nitori kini?  Ti eniyan ba wa ti yoo waasu oro ti o to, ti o si to ona ti o tona, a je pe, aini owo ko le idena seyori re.  Bi o tile je wi pe opo iranse Olorun ni won ni oro ti o dara lati waasu, sibe won si tun nlakaka fun ogbon ti yoo ran won lowo lati le ni aseyori si.
Sugbon oro ti a o waasu se Pataki ju ogbon ati waasu lo, sugbon sibe laisi eniyan, oro naa ko ni je eyi ti a o le waasu re.
AWON ILANA IJO GBINGBIN

AYIKA: Ijo, gege bi enikookan le se orire nipa re ki a bii daradara.  Sugbon labe ayika buburu, gegebi enikookan, ijo le se orire ki a doju too lati ran idagba re lowo, tabi ki o ku si apa itoju ti o peye ti o si le se akoba fun idagba soke re, paapaa julo ni gba aaro ojo re.

IBUDO RERE: Ayo ni fun ijo ti o ni ibudo rere. Awuju ti o kun fun aini, eyi ti nse anfani fun won. Papa ti ko kun akunfaya fun awon ijo. Ohun ini (ile) ti o fi aye gba gbigboro si
Ile ti o fi aye gba isin ati ise.

BI A SE LE MO AINI FUN IJO:
Gege bi opo ilu okeere, orile ede wa Naijiria naa kun fun oniruuru ijo, awon awujo miran tile ti kun akun faya fun ile ijosin, sibe a tun nri awon ibi ti dida ijo titun sile fi npe nigbagbogbo.  Kini idi? Nibi ti awon ero ba po si, ijo wulo nibe.
Osi tara t’okan ati t’awujo ma nfa ki adugbo kan kun fun ile ijosin.  Opo adugbo lo si kun fun irufe awon osi ati isoro wonyi.
Bi opo awujo titun se nlale hu jake jado orile ede, bee ni anfani ati da ijo sile nsi sii.

BI A SE LE ME AGBEGBE TI O YE LATI DA IJO SILE SI
Agbegbe ti ijo kan wa ni yoo so nipa ojo iwaju re.  Ijo ti o wa ni agbegbe ti o dara ni opo anfani, sugbon ijo ti a ba da si agbegbe ti o lodi wa ninu ahamo nla.

SISETO FUN AGBEGBE:
v Se agbegbe ti ijo naa wa je eyi ti o se de?
v Nje o sunmo opopo ona marose, tabi oju ona nla?
v Nje ibi ti a le de ni gbogbo akoko, igba ati ojo ni
v Se ko jina ju si awon eniyan ti o fe jere?
v Nje agbegbe ti o wu ni ni?
v Nje awon eniyan po  to ni agbegbe naa?
v Nje ile tabi ile naa dara fun ohun ti a fe loo fun?
v Se isin yoo bo lowo idiwo?

OGBON AMULO:
·       Fa ara re sunmo ilu na, boya nipa aworan ilu tabi kin a ‘se jade.
·       Se awari ibi ti o dagba ju ni adugbo na, ki o si se abewo sibe kiakia.
·       Se awari lori aworan ilu, iye ijo ti o wa, ati orisirisi esin ti o wa ni adugbo naa. Ise A.A 17:22 – 23. 
·       Se awari ijo titun ti o wa ni adugbo naa ki o sib ere nipa awon wahala ibere ati aini won.
·       Wa ibi ti o ba isin mu, papa ni agbegbe ti o wa ni okan re.
·       Bere isin adura ati eko Bibeli, boya ni ile Oluso Aguntan bi o ba seese ni ile asese gbagbo kan, tabi gbonga isin.  Sugbon bi o ba je ile asese gbagbo, oni lati ri wipe iru eni be ko ni ninu aye re, ohun ti o le di ihinrere lowo.
·       Bi o ba dara loju re o le se ikede ninu iwe tabi iwe ilewo.
·       Bi o ba si fe o le pe ipade oniroyin
·       O le bere ibewo ojule de ojule, se apejuwe ara re, ijo, ati idi ti o fi wa lati da ijo naa sile, ki o si pe won.
·       Fi idi eto ibewo mule fun awon asese gbagbo ni kiakia.
·       Te iwe ifese-asese gbagbo mule.
·       Bi o ba fe o le se ikede ninu iwe iroyin.

ILEPA OKAN AGBIN JO
      I.          Lati fi Kristi han fun awon eniyan lawujo.
   II.          Lati jere okan awon eniyan ati
III.          Lati fi ese awon asese gbagbo yi mule ninu ijo agbegbe kan.

Opo agbin ijo lo kan bere ijo laini ilepa pato kan ninu okan re.  Abayori iru nkan be ni lilo lati inu eto kan de omiran lai ko ri aseyori kokan ninu re nitori ko si ilepa.
Gege bi iranse ihinrere, agbin ijo, iko Kristi, ani lati gbin ki a si ko ijo fun Kristi, ati nitori eyi a gbodo ni eto fun ise iranse gbingbin ijo wa labe isakoso Emi Mimo.
a.       Iru ijo wo ni o npongbe lati gbin?
b.       Iru eto wo lo se sile fun iru ijo bee?
d.       Kini awon ipinnu ati liana ti o ntele ninu ihinrere ati ise iranse dida ijo sile re?
e.       Kini idi to fi fe da ijo sile ni agbegbe yen gan?
c.       Nje ijo na njihinrere ninu iwa ati isakoso re?
f.        Kini awon ilana fun jije omo ijo re?
g.       Nje o je ijo ti o nkoni ni Bibeli ni?

AWON OJUSE IJO TI O NRANNI JADE
1.       Awon ojuse awon adari ijo
2.       Awon ojuse igbimo ojise Oluwa ti ijo.
Ki ojise to di riran jade, ijo funrare gbodo ni awon amuye kan:
          i.        Fifi ilana kan lele: Won gbodo ni ilepa ati awon eto, eyi ti yio wa lati iya ijo               won.  Eyi yio je ilana eto isin, isuna owo, igbekale, nibo ni a ti nbere                                      idanileko ati iru eniyan ti a fe jere.
          ii.       Fifi apere lele: Eyi je ise olori nipa didari ijo sinu ise.
          iii.      Siseto fun ise iranse: A gbodo so daradara leti won ki a si gba won ni iyanju                   lati fi si ise.
AWON OGBON TI IJO GBINGBIN.

Kiise ogbon kan soso ni o wa fun gbingbin ijo labe itoni ti Emi Mimo.  Ogbon kan le dara, nibi ti awon iyoku ti kuna ni ibomiran.  Nitori idi eyi opo ogbon ni o wa nipase apapo awon ogbon wonyi fun apeere:-
1.       Iwaasu enikan si enikan.
2.       Ijosin ti inu ile.
3.       Iwaasu ihinrere ni ita gbangba.
4.       Iwaasu ihinrere ti ori pepe, tabi ibasoro kikan ilekun.

Ibasoro kikan ilekun, eyi ni ibasoro ti "wa wo", iyen ni pipe eniyan ki o wa wo.

IMURASILE AGBIN IJO

A.      Ajihinrere na ti o nbere ijo titun le bere nipa pe ki o duro sibe gege bi oluso aguntan        won.

B.       Ajihinrere na le mu alaba sisepo kan dani pelu re, ti yio mura lati duro leyin isoji ati          leyin na ki o si di oluso aguntan won.

D.      Ajihinrere tabi ojise Oluwa na, bi ko ba pinnu lati duro ti ko si si alaba sise ti o le     bojuto awon eniyan, le duro pe die lati pese adari agbelero ki o si ko de oju ami ti      yio fi di akose ijo na mu daradara.  Apere iru eyi ni Paulu Aposteli.
PIPOLONGO IHINRERE NAA

Ti ipolongo iwasu ihinrere ba sokunkun, awon liana yi yio je iranlowo nla:

1.       Ajihinrere naa ati awon osise elegbe re gbodo wa si ibi ipade, leyin ti won ti lo opo         asiko ninu adura ati imura sile ti Emi, ki a si maa reti ti Olorun fi ara re han.

2.       Je ki iwasu na rorun, ki o siba Bibeli mu, pelu titenu mo awon otito wipe, Olorun         ngbo o si ndahun adura, je ki o de eti gbogbo awon olutetisile nipa otito iwasu oro       Kristi.

3.       Je ki isin na je eyi ti o wa laaye ati ki o tesiwaju, orin kiko gbodo je eyi ti o ni imisi      pelu opolopo orin egbe lati le je ki awon alejo ni itelorun. 

4.       Eri awon eniyan ti won ti ri itusile kuro ninu ese, tabi iwosan gegebi idahun si adura,     eyi yio mu ki awon olugbo fi eti sile, bakanna yio ru won soke ninu igbagbo.

5.       Aye gbodo wa fun awon eniyan lati fi aye won fun Jesu ninu gbogbo isin.

6.       Awon ti won jewo igbagbo, gbodo je bibewo ni ile won.
IWAASU NAA TI O NGBIN IJO

ITOKASI Iwaasu ihinrere ni ona ibanisoro kan soso ti a fi le fa elese wa si odo Jesu Oluwa.  Iwaasu ihinrere kan ni o nbe, sugbon a le salaye re ni oniruru ona ara.  Ihinrere ko ni yio yi pada, sugbon ona eyi ti a ngbe lati so le je orisirisi lati mu ki o dara leti awon olugbo.  Awon Aposteli salaye ihinrere ni oniruru ona, sugbon iwaasu kan na ni, fun apere:

1.       Odo aguntan ti a fi rubo – Itasile ati ibuwon eje Kristi.
2.       Mesiaya – Imuse naa ti ileri Olorun fun mesiaya ati adari.
3.       A soni di ominira – Eni ti o nbo lati ran awon alailera lowo.
4.       Oluso Aguntan – Eni ti o njade lo lati wa aguntan ti o sonu.
5.       Agbe kan – Eni ti o njade lo lati gbin irugbin.

IWASU NAA TI O NGBIN IJO


Aposteli Paulu mu ni Pataki ani iwasu ti o nwa.  Ninu iwe re si awon ara Efesu, o fi han iru isopo ti o wa larin iwasu ti o wa ati ijo ti o da sile.  “Ninu eni ti eyin pelu gbekele, leyin ti
eyin ti gbo oro otito, ihinrere igbala yin; ninu eni ti o je pe leyin ti e gbagbo, a fi edidi Emi Mimo ileri na se edidi yin” Efesu 1:13.

Bakanna ninu iwe re si awon ara Tesalonika “Nitori eyi ni awa se ndupe lowo Olorun, pelu ninu aisinmi pe nigba ti eyin gba oro ti egbo lodo wa, ani oro Olorun, eyin ko gba bi enipe oro eniyan, sugbon gegebi o ti je nitooto, bi oro Olorun, eyi ti o sise gidigidi ninu eyin ti o gbagbo pelu”. 1 Tes. 2:13.  Ijo agbegbe wa si ifarahan latari iwasu ti a wa.  “Isojulowo iwasu ni yio so nipa isojulowo ijo”  “Bakanna iwasu ti yio ko ijo je iwasu ti o duro lori Bibeli”.  Ninu iwe mimo ni isipaya otitio ti o ngbani la wa.  Je ki agbin ijo je olupolongo irapada otito gegebi a ti se agbekale re ninu Bibeli, ki awon asese gbagbo ba le je eni ti iwe naa. 
Gbogbo iranse ijo onigbagbo ti won njewo iwasu ihinrere, bi o tileje wipe orisirisi alaye ni o wa, die ninu awon oniwasu aye ode oni ti won wipe awon nwasu oro Olorun ni won ni afijo kekere pelu bi awon Aposteli pelu agbara Emi Mimo yio pese iru ijo alagbara ti awon Aposteli pese nigba tiwon.

Iwasu awon Aposteli je eyi ti o fi ori so Kristi patapata.  Eniyan nilo lati ka iwasu awon Aposteli akoko inu iwe Ise Awo Aposteli ki a si ri lilo taara ati lilo jeje.  Ni akoko, iwasu nilo lati jinle die ju pipolongo kikan mo agbelebu ati ajinde Jesu Kristi, Ki a si so fun won nipa idariji ese ati pe iye ainipekun yio wa fun awon ti won gbagbo ninu Kristi.
Awon Olugbo ni a si tun gbodo ru soke lati se iribomi inu odo, ati pe ki a si se ileri pe won a gba ebun ati Emi.  Ise A.A 2:38 – 39.  Bi o tile je wipe oni ilana eko onigbagbo ninu, sibe oni awon iha ti o se Pataki eyi ti o npese ijo onigbagbo, bi o tile jepe awon Aposteli paapa julo Paulu, nipase imisi Emi, nigba ti o ya, won mu eko ijo onigbagbo wa si ise, won si salaye re lekunrere, ani awon eto Olorun, sibe iwasu na si tun duro lori Kristi patapata.
Iwasu ti yio gbin ijo loni gbodo duro bakanna lori Kristi.  Abala ti o tobi ju ninu iwaju ihinrere kun fun alaye nipa iru eni ti Jesu Kristi nse, ohun ti o se ninu aye, ise Pataki iku ati ajinde re, ohun ti o nse lowolowo ati eyi ti o mura lati se fun awon ti o gbagbo ninu re bayi?  Ati isegun re ojo iwaju ni gbogbo agbaye.  Iroyin rere ti irapada eniyan ati ti o nfi idi ijo mule ni a le ri ninu otito ihinrere yi.

Ajihinrere gbodo sora lati ma fun ni ni imoran ti o po tabi tesiwaju ninu oro ti ko kan.  Itokasi oro oselu ninu oro iwasu yio so agbara iwasu di alare.  A ko sope jije onigbagba ko kan gbogbo iha aye eniyan, sugbon ti a nda ijo sile ko si ohun ti o kan wa kan oro ijoba ati aisoto orile-ede.
Ohun  ti o kan wa ju loni ni aini enikokan gegebi elese, olote, omo oninakuna, ti o nilo lati pada si ile baba re, o gbodo sora lati ma fi oro ti ko ye ninu eyi ti o nso ihinrere di alailagbara ninu aye enikokan, dipo be oye ki a je ki won o mo ojuse nla  ti gbogbo agbaye.
Iwasu ti agbin ijo wasu gbodo ba aini awon olugbo oro na mu.   Iwasu ihinrere gbodo je eyi ti a gbe kale ni ona ti aini pato olukuluku yio je biba pade.  Ninu asa ati igbekale awon esin kan, won a ma lo ninu idorikodo fun idalebi ese ti ara, ajihinrere le kede fun iru awon eniyan bayi iwasu idariji ese ti o yato nipase agbelebu Kristi, ninu asa awon miran imolara idalebi ese je eyi ti ko lagbara tabi ti o fere je eyi ti a ko damo.  Ati Jesu ati Awon Aposteli won ko salai ka aini awon eniyan nipa ti ara si nigbati won ban se ise iranse si won, lotito Kristi ma nlo anfani lati salaye aini ti o tobi ju fun okan sugbon sibe o ma nmu won larada nipa ti ara ati nipa ti emi Mk 2:5 – 12.  Nitori idi eyi, eje ki iwasu wa so Kristi tabi duro lori Kristi ki a si salaye awon ohun rere gbogbo ti won le ri gba.  Ati pe ki a doju iwasu wa ko aini awon olugbo ati bakanna a ko gbodo dagunla lori tite ojuse ti a nbere lowo omo ehin mo won leti, ki awon asese gbagbo le je eni ti Olorun ra patapata, ani awon ti yio tele oju ese awon Aposteli ni sise eleyi, a o le fi ipile ti o dara sole fun ijo ati fun gbigboro re ni iha ti wa lori ile aye.

EKUNRERE IWASU IHINRERE NI ONA JEJE
2 Kor. 15:1 – 5, Ekunrere iwasu ihinrere jeje ma ntenumo pe Jesu ku ati pe a sin oku re, lehin eyi o jinde kuro ninu oku.
Agbin ijo gbodo yago fun atenumo pupo lori iwasu odi ninu iwasu re.  Bi o tile jepe, awon odi oro die nilo ni igba miran, nitoripe o ye ki elese gbo sisan ara ododo Olorun ti ofin ti o lodi si ese re ki o ba le tara sasa si aini re nipa olugbala.
Iwa pansaga gbodo je yiyi pada ni oruko Olorun otito, “bawo nipase agbara Emi mimo asiri igbe aye ese gbodo je fifi han, sugbon gbogbo awon woni je ibere pepe ni titokasi olugbala tooto, e je ki a sora gidigidi lati mase te mo won lokan pe jije onigbagbo ni lati mase awon nkan kan.
Otito pe eniyan kan ko mu oti, ko mu siga, ko ta tete, ko jo ijo okunkun, eyi ko so di onigbagbo tabi awon aso, awon ohun elo wura, tabi kikun oju ati kikun ete ti eniyan nse tabi ti ko se.   Igbagbo ninu Kristi nikan lo ngbanila, otito yi gbodo je eyi ti a dabobo titi lae, iwasu ti a wa gbodo wa ni ibamu pelu awon olugbo.
AWON OHUN ELO FUN IJO GBINGBIN

1.       Bibeli gegebi ipile “o dara lati lo bibeli gegebi ipile”.
2.       Emi Mimo ati agbara
3.       Imo.
       AWON ALAYE

Laisi aforiji ni afojuwe bibeli nipe ise iranse bere pelu iroyin ni soki si iwe ihinrere ti Johannu.   Ninu Johannu ni ati ri okan ise iranse bi o ti wa ninu Kristi ojise lati oke wa.  Nigbati oro naa di ara, osise o si gbanila gege bi oluranni leti pe gbogbo aye feran Olorun won si je tire.
Gbogbo onigbagbo ti o mo pe o wa sinu aye yi yio mo gbangba pe majemu titun gba emi re ninu ise iranse, eda ise iranse ati pe o seda ise iranse o si nse ise iranse ni ibi kibi ti o ba lo.

Agbara tumo si ase, nini igbekele ninu ipa, okun irusoke lati dari, ikoranni, abo, lilese, lila aye ati gbigbejo ro, gbogbo nkan wonyi lo nwa lati inu Emi Mimo, bibeli ati Kristi.
Ajinhinrere naa je alailagbara papa julo eni ijakule tabi alailaseyori bi o ba sinmi le agbara re ni sise ise iranse 2 Kor 3:5 – 6.  Ojise Oluwa je eniti aye si sile fun esu lati baja bi ko bani awon ohun ija ti Emi eyi ti Olorun fi funni “nitori ohun ija wa kii se nipa ti ara sugbon o ni agbara ninu Olorun lati wo ibi giga pale” 2 Kor 10:4, Efesu 6:10 – 13 gbigbadura ninu Emi se Pataki pupo.
Imo je agbara, agbara si je imo, ni opo igba ni imo ma nyoni kuro ninu ewu ati orisirisi opo ijamba.

JESU PE WON NI APEJA ENIYAN:  Bi a o ba ko eko nipa amuye apeja, O gbodo ni awon amuye ti o po bii –
     1.  O gbodo le gbo oorun iji
     2.  O gbodo le ri iran iji ati awon isoro
     3.     O gbodo je onisuuru

BIBOJUTO AWON ASESE GBAGBO

Awon omo ti o peye je awon omo ti o peye lati asiko ibi, omo ti akobi pelu ilera ti o pe le ya alaisan titi ojo aye re.  O se dandan pe ki osise onigbagbo se gbogbo ohun ti o ba le se lati ri wipe awon asese gbagbo ninu ijo je eyi ti a bi pelu ilera sinu ijoba Olorun.
     AWON IYARA IKAWE FUN AWON ASESE GBAGBO

Gege bi omo tuntun ti nilo itoju Pataki, beni asese gbagbo nilo iranlowo Pataki ati itosona 1 Pet 2:2, gegebi iyara ikawe Pataki se nilo lati mura asese gbagbo sile fun iribomi ati jije omo ijo.
§  Iyara ikawe fun asese gbagbo ye ki o ma waye ni ekan lose.
§  O le duro gege bi kilasi pataki ni ile eko ojo isinmi tabi ki a ya ale pataki kan lose fun.
§  O dara ki yara ikawe yi ki o bere ki isoji ki o to pari bibeko yio nira lati ri aseyori isoji naa lehin ti ajihinrere ba ti lo.
Idanileko na gbodo je eyi ti o lo tara ti o si rorun, bi o ba sese oluso aguntan ni o ye ki o je oluko ni kilasi asese gbagbo yi, ni iwon bi o ti je pataki lati lowo ninu igbese akoko si Oluwa.

BAMUTISIMU:  Bamutisimu je igbese kan fun awon asese gbagbo, a gbodo sora gidigidi ni mimura re sile ki o bale je eyi ti o ni itumo ti o si kun fun iriri ti Emi fun.  Bamutisimu gbodo waye ni ibere pepe igbe aye onigbagbo bi o ba se le ya si.  O je asise lati je ki osu tabi odun koja laiko mu asese gbagbo wo inu eto Pataki yi –
Awon eko die se Pataki lati mura asese gbagbo sile fun bamutisimu.  O gbodo ni oye ti o kun nipa ohun ti o fe se ati ki o si mo awon ojuse igbe aye onigbagbo.
Opolopo awon Oluso aguntan ni won ki se bamutisimu fun awon asese gbagbo won ayafi ti won ba se tan lati di omo ijo won, looto na, okan bamutisimu ye ko da bi igbese lati di omo ijo lekunrere.  Ko si koko gidi ninu ki a se bamutisimu fun eniyan ti ko setan lati di omo ijo agbegbe kan tabi gba awon ojuse jije omo ijo kan.

Asiko ikeko nse ise Pataki miran.  Opolopo eniyan ni o wa si odo Oluwa nitori isoro ti won ni lori eto igbeyawo won, Bamutisimu ni a se akiyesi re kii se idahun si ijeri okan rere nikan, sugbon ijeri si gbogbo aye nipa igbe aye titun ninu Kristi ohun ti a gbagbo nipa asese gbagbo nilo lati fi idaniloju han nipa iyipada aye re nipa pe ki o gbe awon igbese lati tuna won aye re to. 

A gbodo yago fun ibanisoro ni ona ti ofin ninu iru isele yi niwon bi ese se je isina buburu ti o daju bi o ti wu ki o ri gbogbo ipa ni a gbodo sa lati pa igbe aye ti ko mo run ki a si so eso ti o ye fun ironupiwada. Mt. 3:8.

A gbodo so Pataki bamutisimu, awon ore asese gbagbo ni a gbodo pe ki asese gbagbo si ni anfani lati jewo igbagbo re ninu Kristi ni gbangba.

AWON ISE ASESE GBAGBO
1.       JIJERI – Asese gbagbo ko gbodo joko ki o ma gbo lati enu awon miran nikan,          sugbon won gbodo bere igbe aye onigbagbo re gege bi ajeri ti o munadoko bi ijo ba          je eyi ti o njeri Kristi ni ona ti o munadoko gegebi ojuse aisimi.  Asese gbagbo       gbodo lo pelu won ki a si fun ni anfani lati so ohun ti Kristi se fun.
2.       WIWA SI ILE EKO OJO ISINMI DEDE
3.       JIJERI NIPA IGBE IYE ONIGBAGBO – O gbodo keko pe gbogbo iha igbe aye re   ti ile iwe, tie bi ati ti ohun funrare ni a gbodo muwa si abe idari ti Jesu Kristi.
     IDAGBA TI EMI

A.      A gbodo ko asese gbagbo bi a se nbori ijakule
B.       A gbodo ko bi a se ngbe aye ti o kun fun Emi Mimo 2 Pet. 1:5 – 10
               AWON AGBATERU TI EMI

Agbani niyanju ni Emi kokan fun asese gbagbo ye ki o duro gege bi egbon ki o si ran lowo lakoko die leyin igbagbo re.  Agbateru ti Emi ni a gbodo yan ni asiko ti o sese gbagbo.  O si gbodo je enirere ninu iwa ati igbe aye, ati eni ti ibere aye re fara jo ti asese gbagbo na.

AWON OJUSE AGBATERU GBODO JE
1.       Lati wa aye ibi ibasoro fun asese gbagbo ni kete ti o gbagbo.
2.       Lati lo se ibewo si asese gbagbo na leyin ojo kan tabi meji ti o gbagbo.
3.       Lati ri wipe a jo wa si ipade ti o kan ki a si joko legbe re.
4.       Ki a si gbadura pelu rer leyin isin boya ninu ile adura tabi ni iwaju pepe bi anfani re ba wa.
5.       Lati fi to Oluso aguntan leti asese gbagbo ba ni awon isoro Pataki kan ninu aye ti    Emi re.
6.       Ki o ru asese gbagbo soke lati fi oruko sile ni ibi ikeko fun awon asese gbagbo.
7.       Lati ran asese gbagbo lowo pelu eko agbele ka, ki a si salaye bi o se se Pataki to fun.
AWON IDIWO SI IJO GBINGBIN


Awon idiwo si ijo gbingbin ni wonyi:
1a.     Aiko le gbadura le je idiwo fun ijo gbingbin
 b.      Aiko si iranlowo owo
 d.      Ohun elo rere, eyi ni eniyan ti o peye, ti o si loye ninu Bibeli.
2.       Iwasu buburu:  eyi nip e, bi iwasu ti a wa ba je eyi ti a gbe kale ni ona ti o lodo, o le     di ijo gbingbin lowo, iwe Mimo wipe “Ihinrere Kristi ni agbara Olorun si igbala” o          si le je asigbe kale, bi o tile jepe a ni ihinrere Kristi, sugbon nitori pe igbekale re       lodi, eyi si le yori si titu ijo ka, papa julo awon awujo tile le so oniwasu ni okuta.
3.       Ikuna nipa aiko se imurasile ti o munadoko.
4.       Idojuko awon emi okunkun:  Paulu wipe “Emi fe lati to yin wa ni ojo wonyi, sugbon       iranse satani de mi lona”.
5.       Ikuna nipa mimo ife okan Olorun:  eyi ni pe Oluso aguntan le ma mo ife Olorun fun   ijo re, bakanna ki Oluso aguntan ti o si ma seto fun ijo re.
6.       Ipejopo kan ti o ni itelorun pelu bibojuto iwonba ti won ni, ju pe ki won ma wa omo ijo titun, le di ijo gbingbin lowo.
7.       Eleya meya ma nfa idiwo fun ijo lati de odo awon mira leyin awon eyi ti a ti ni.
8.       Nibi ti oluso aguntan tabi awon alagba nfi gbogbo igba ja lori oro ti ko ni laari, ti         won si dagunla si iwasu oro Olorun.
9.       Bi a ko ba ko awon eniyan nipa ife Olorun si Ijo gbingbin.
10.     Nigba ti awon eniyan ko ni aanu lati de odo awon ti n segbe nipa ise iranse.
11.     Nigba to awon eniyan ba bere si ja pelu ara won ti won si gbagbe oro pe ki a so          gbogbo orile-ede di omo eyin Mt 28:7 – 8.

FIFI OJU WO IRU IJO TI A O GBIN

Ilepa wa gbodo daju na; nitoripe a ko le seto lati da ijo sile fun awon omo owo tabi omo kekere nikan, sugbon bi ilepa wa ba je fun ati je ijo ti enu ona orun apadi ko le bori, ko gbodo je omode nikan ni yo je omo ijo wa, sugbon awon agba.  Bi o tile je pe ko buru lati jeer omode fun Oluwa, sugbon otito ibe ni wipe, bi a ba koko jere awon obi won, yio rorun lati jere awon omo won pelu.  Nitori ijo Kristi gbodo je eyi to lagbara, ki ise alare tabi olokunrun.

Abajade ise iranse ni lati gbin ijo
Iru ijo wo ni o ye ki a gbin?  Nitori a ni ona oniruru lati gbin bayi, e je ki a wo die:
1.       Tiwantiwa
2.       Afunniso
3.       Alailobi
     ALAYE

1.       Tiwantiwa – Eyi ni ijo ti a gbin, ti a si se iranlowo fun lati odo iya ijo, sugbon ti      won yio dawo iranlowo duro leyin osu tabi odun die, gegebi agbara won, ati pe leyin   eyi won yio ma boju to ara won.
2.       Afunniso – Eyi ni ojuse baba ti o wa titi.  Bi ojuse baba ba tesiwaju be titi laiduro,        baba na yio ni isoro bo o ba pe,  nitori idi eyi o dara ki ijo agbegbe kokan le da boju    to ara re leyin gbingbin.
3.       Alailobi – Eyi tumo si jijowo patapata, eyi je iru ijo ti ko ni ibojuto iya, ni oro miran     a le pe ni ijo agbagbe ti ko ni oluranlowo.  Eyi ni da gbe agbelebu re.

Ni ipari:-  A gbagbo wipe eko yi yio je iranlowo si o gegebi iranse Olorun, bi o tile je pe eyi nikan ko ni ogbon re, ki Oluwa bu kun o. Amin.





No comments: