AWON WOLI KEKEKE
Ninu iwe mimo
Genesisi si iwe Malaki ni a mo si majemu laelae.
Ninu iwe
Matteu si iwe ifihan ni a mo si majemu titun.
Genesisi – Deuteronomi - Pentatuku\
Joshua – Esther - - Awon iwe itan
Jobu - Orin Solomoni - Awon
iwe Ewi
Isaiah - Daniel - Awon Woli Agba
Ø Hosea
- Malaki - Awon
Woli Kekeke
Mattue - Johannu - Ihinrere
Synoptiki
Ise Awon Aposteli -
Romu - Juda - Episteli ti Paulu
Ifihan - Escatolo
AWON OHUN TI A O GBEYEWO
1.
Afihan
2.
Alaye
itumo
3.
Hosea
- Woli Ife
4.
Joeli
- Woli Pentikositi
5.
Amosi - Woli
Onidajo Ododo
6.
Obadiah - Woli
Olubawi Awon Elegan
7.
Jona - Woli Alaapon
8.
Mika - Woli Awon Talaka
9.
Nahumu - Woli
Elewi
10.
Habakuku - Woli Alarojinle
11.
Sefaniah - Woli
Alasodun
12.
Haggai - Woli
Oluko Tempili
13.
Sekariah - Woli
Ariran
14.
Malaki - Woli
Olukoni
AFIHAN
Laisi ipe ko le si woli ipe ati iran se Pataki ninu ise iranse woli “oro
ti a pe ni Woli o wa lati inu ede Heberu ati ede Giriki, ni ede Heberu Nabhiim
nigba ti Woli ni ede Giriki tumo si ……… ti o tumo si olusi aso loju oro
Olorun. Oro yi tumo si itujade oro tabi
eni ti o fi asotele tu oro Olorun jade.
Awon ojogbon pin awon woli si ona meji.
1.
Escatic
prophets
2.
Classical
prophets
ESCATIC PROPHETS
Escatic prophets ni a amo si awon woli
(7th century) ogorun meje won bere ise iranse won ni 639 – 608BC,
die lara awon woli yi ni Sefaniah Nahumu ati Habakuku.
CLASSICAL PROPHETS
Awon woli classical yi ni a pe ni woli (8th century) ogorun
meje die lara won ni Isaiah, Hosea, Amosi.
Leyin akoko yi ni awon ojogbon tuna won woli pin si ipa meta otooto
(1)
Awon
woli ti won sotele saju akoko igbekun (Pre-exilic prophets)
(2)
Awon
woli ti won sotele ninu igbekun (Exilic prophets)
(3)
Awon
woli ti won sotele leyin igbekun (Post-Exilic prophets).
Lara awon
woli ti o sotele saaju igbekun Hosea, Mika, Sefaniah, Amosi, Isaiah, Jeremiah,
Nahumu ati Habakuku.
Lara awon
woli ti ton sotele ninu igbekun Isaiah, Malaki, Haggai ati Sekariah
Lara awon to
sotele leyin igbekun ni a ti ri Haggai, Sekariah.
ALAYE ITUMO
Oro ti a pe ni woli kekeke ni a fun
awon iwe mejila ti o gbeyin iwe majemu laelae.
Awon wonyi yato si awon woli agba merin ti se Isaiah, Jeremiah, Ezekiel
ati Daniel. Awon idi ti a fi lo gbolohun
oro woli kekeke fun won ni wonyi:
(1)
A
pe won ni woli kekeke nitori akoko ti won lo ati ohun elo ti won lo yato.
(2)
Won
se atunso awon liana ohun ti awon woli agba ti so tele.
(3)
Die
lara awon woli kekeke yi ni won je akegbe taabi ti awon ati woli agba ti jo
sise po, fun apeerre, Hosea, Amosi, Mika, won je akegbe pelu Isaiah gbogbo won
ni won sotele ni akoko isejoba Jotamu, Hezekiah ati Usaiah ti won je oba Juda.
Awon woli kekeke yi won je awon okunrin alagbara takuntakun, won je awon
eniyan ti won le fie mi ji iku ati awon eniyan won se se idamo ibasepo won gege
bi woli pelu Olorun. Ojuse won ni lati
se afihan Olodumare niwaju awon eniyan.
Ojuse won ni lati gbenuso fun Oluwa lori orile-ede, tabi ilu tabi
awujo. Awon woli je eni ti a ko le dun
koko mo tabi ki a pa ohun mo won lenu.
Fun apeere woli Amosi ko ki Amasiah Alufa Beteli ki o dun koko mo ohun
ni akoko ti Jeroboamu keji nsakoso. Woli
Amosi ko gba ki
Amasiah Alufa
o pa ohun lenu mo – Amos 7:10 – 17.
Ni abala miran awon woli mejila yi ti
a npe ni woli kekeke ni opolopo ajalu yi aye won ka, eleyi gbodo ri be nitori
aigboran ati isote awon eniyan won, awon woli yi jiya nitori ifoju temi to de
ba orile ede won, won si yo ninu ojo iwaju ti o dara.
HOSEA – WOLI IFE
Woli Hosea je okan lara awon classical
prophets ti won sise saaju igbeku, Hosea je okan lara awon woli kekeke ti won
sise ni owo kan owo pelu awon woli agba – Hosea 1:1 – 11, Woli yi bere ise
iranse re ni akoko Oba Jeroboamu keji
titi di akoko ti ijoba ariwa fi subu ni odun 721BC.
ORUKO ATI IWA HOSEA
Oro ti a pe ni Hosea wa lati inu ede Heberu kan na gege bi oruko
Joshua ati Jesu.
Joshua - Yeshua won ni itumo kan na ti o tumo si
Jesu - Jesus Oluwa ni igbala wa.
Oruko yi tumo si igbala, iranwo tabi
idande. Hosea je omo bibi apa ariwa
Israeli niti pe o soro lopo igba nipa ijoba apa ariwa, bi Lebanoni, Tabori,
Samaria, Beteli, Jesreeli ati Rama.
Hosea lo oro ti a pe ni Efraimu nigba metadinlogoji (37times) lati fi
soro nipa apa ariwa Israeli. A ma n lo
oro ti a pe ni Efraimu ni opo igba ninu majemu laelae lati fi tokasi ijoba apa
ariwa Israeli. Hosea feran apa ariwa yi
pupo o mo gbogbo awon ojuse won erongba gbogbo ati itan ohun ti won ti la koja,
ikowe Hosea se afihan ati imolara ati ikaanu fun orile ede re ti o je wi pe omo bibi ilu ni o le se
be.
Hosea je oniwa irele eni to ni
arojinle ti o si ni okan ibanuje.
Bakanna o je olotito ni oro siso eni ti o ni ife ni iws, o si ma nsoro nigha gbogbo ni ona
ti awon eniyana yoo fi nife re.
Hosea ni ijoba apa ariwa ni ale fi se
afiwe Jeremiah ni ijoba apa Gusu. Hosea
yi kannaa la inunibini koja, ilakoja re yi si ntoka si irufe iya ti Kristi yoo
je. Awon mejeji yi Hosea ati Jeremiah
won feran ilu won awon mejeji yi si ni emi to le, to ni irrele fun ihuwasi ese. Jeremiah o soro ni gbangba nipa ibanuje toni
lori igba aye ese ilu re be ni Hosea naa fi ibanuje okan re han lati se be
Jeremiah je alarojinle ati onimo ijinle nipa Olorun. Hosea je akewi iwe re je iwaasu ewi. Bakanna ni o so oro ihinrere lekunrere ju opo
awon majemu lailai lo eleyi ki se nitori wi pea won asotele Pataki nipa mesaya
wa ninu re. Sugbon nitori pe ni aimo ye
odun ki Krisiti to de ni Hosea ti waasu nipa ofin tuntun lori oro ife eyi ti awon iwe
ihinrere nkede. Hosea ni woli akoko to
koko ni oye yi wipe Olorun je ife,
ohun ni woli akoko lati waasu re pee se Israeli to tobi ju ni wi pe won ko mo
riri ife
Olorun. Nitori naa a le pe Hosea ni
Johannu Olufe ti majemu lailai.
AKOKO HOSEA
Apele iwe Hosea ohun ni a ri ninu ori
kini ese kini ti o so pe oro Oluwa ti o to Hosea omo Beari wa ni ojo Usaiah,
Jotamu, Ahasi ati lojo Jeroboamu omo Joasi, nitori naa Hosea beresi ni waasu ni
akoko ti ohun gbogbo nlo deedee mo ni ile Israeli titi di igba ti ko fi lo
deedee mo.
IPO OSELU NI ILE ISRAELI NI AKOKO
HOSEA
Hosea bere ise iranse re ni akoko ti
Israeli ni oro pupo, o si pari ise iranse re nigbati orile ede ti so titobi re nu ti won ti kun fun opo
iwa ibaje ati iwa iru ofin. Ni ibere
pepe aye Hosea Jeroboamu keji ni oba nla ni igba na Jeroboamu keji ni oba
alagbara to nsakoso. Ohun ni Olori to je
jagunjagun onigberaga ati apase wa – iran Jehu tooto. Ni akoko re Israeli wa ni ipo to ga ninu
agbara awon omo ologun. Iwe awon obe
keji so fun w ape nighti Jeroboamu ku ijoba na subu si awon akoko buburu. Awon egbegbe ninu ijoba na bere si ni dide
ogun si ara won. Awon Oloselu won ngbe ife inu ara won leke ju ife orile ede lo. Awon ijoye di oniwa aimo won ngbe awon oba
dide ti won ko ni ase aye won si ndopin bi ifofo ni oju omi – Hos 10:7. Agbara gbogbo ti orile ede na ni o bere si ni di alailera.
Jeroboamu yi ni oba to lagbara to
gbeyin ni Israeli. Laarin awon oba mefa
to tele Jeroboamu Menahem nikan ni oku woroweo tabi fi owo rori ku. Orin ote ni orin ti won nko ninu itan akoko naa
– 2 Awon Oba 15.
Sekariah ni oba ti o je fun osu mufa
Shallum je fun osu kan
pere. Laimo ohun ti won fe se oba koko
lgbekele ona kan
leyin naa won tun gbekele ona miran lati wa iranwo ajeji. Won nsan isakole ni akoko fun awon ara Assria
leyin na won tun nsan isakole fun awon ara Egypiti leyin naa ni won 3wa so
ominira nu patapata, ti agbara won fib o lowo won ti oro won naa sib o lowo
won. Lopin gbogbo re, orile ede yi di allllailagbara
eru awon ara Assria.
IPO AWUJO NI ISRAELI NI AKOKO HOSEA
Ni igba ti ominira Israel bo lowo
won, won bere si padanu gbogbo nnkan.
Gege bi eni to ni ife ilu re bi Hosea o je ohun to buru pupo lati fie be
sowo ijoba ajeji fun iranwo – Hos 8:9, Hos 10:6. Iru eleyi ni ko si ona abayo fun iru orile ede tin se aisan tara –
Hosea 5:13. Laifura, Efraimu di ogbo siwaju akoko
re. Eewu ori o ti bo won lori sibe won
ko mo Hosea 7:9. Gbogbo egbe awujo awib
eniyan ni won gba wole. Awon Alufa gan
di igara olosa won tun yo ninu ese awon eniyan, nitori eleyi nje ki owo to
nwole si won lowo npo si. Gbogbo nnkan
bere si baje lowo won ti inu idibaje won aidibaje titi ti woli yi fi wipe “ko
si otito, ko si aanu ko si imo Olorun ni ile na”. sugbon ibura ati eke ipani
ati ole ati ise pansaga won gbija eje si nkan eje. Hosea 4:1- 2, 3 – 6.
IPO TI ESIN NI ILE ISRAELI NI AKOKO
HOSEA
Ipo esin ni
ile Israeli ni akoko yi o buru pupo. Won
yi esin pada si iborisa pansaga igbe aye ebi paapaa julo pada di alaimo ati eyi
ti o kun fun iwa eeri. Nipa ihuwasi yi
ni woli yi se so oro to lagbara jade lati okan re. ati le salaye ipo aini ireti ti Israeli wa ti
woli ri ni o se lo oro “pansaga” ni igba merindinlogun (16 times). Hosea gbe igbe aye re ni akoko ti iji nja
Israeli ati akoko ti ohun gbogbo ko lo deedee ti ile na la koja. Irunu ti o de baa won egbe kookan ni ile na
ni o dabi aaro ti alakara mug bona ti won ko dawo kiko ina re duro Hosea 7:4.
Ni ibi gbogbo
ni awon eniyan didi lodi
si ara won ojo iwaju di eyi ti ko ni ireti orun Israeli beresi wo ni osan
gangan. Ko tile nilo ki eniyan je woli ki o to ri wi pe opin orile ede na ti de. Nitooto kop e leyin ti ko dekun lati wasu ni
won ko orile ede
Israeli ni igbekun lo si ile ilu Assria lati owo oba Sargo ni ni odun 726BB –
Awon Oba keji ori (17).
AWON
OBA APA ARIWA – ISRAELI
1.
Oba
Jeroboamu
2.
Oba
Nadabu
3.
Oba
Baasa
4.
Oba
Ela
5.
Oba
Simri
6.
Oba
Omri
7.
Oba Ahabu
8.
Oba Ahasiah
9.
Oba Joramu
10.
Oba Jehu
11.
Oba Jehoahasi
12.
Oba Jehoasi
13.
Oba Jeroboamu II
14.
Oba Sekariah
15.
Oba
Sallumu
16.
Oba
Menahemu
17.
Oba
Pekaniah
18.
Oba
Peka
19.
Oba
Hosea
AWON OBA APA GUSU – JUDA
1.
Oba
Rehoboamu
2.
Oba
Abijah
3.
Oba
Asa
4.
Oba Jehosafati
5.
Oba Jehoramu
6.
Oba Ahasiah
7.
Oba
Ataliah
8.
Oba
Joasi
9.
Oba Amasiah
10.
Oba Asariah (Usaiah)
11.
Oba Jotamu
12.
Oba Ahasi
13.
Oba Hezekiah
14.
Oba
Manase
15.
Oba
Amoni
16.
Oba Josiah
17.
Oba Joahasi
18.
Oba Jehoiakimu
19.
Oba Jehoiakini
20.
Oba Sedekiah
APE HOSEA LATI JE WOLI
Opo awon
akeko iwe Hosea gba pe ise iranse Hosea waye laarin odun mewa amosa o sese ki
akoko yi o po ju be lo. Oba kan nbe ti a
nipe ni Hoshea, Hoshea ni oba ti o keyin ni apa ariwa ni ile Israeli ati wi pea
won ojuse awon ara Egpiti lodi si awon ara Assria eyi ti iwe Hosea 7:11, 9:3 –
6, 11:5, Hosea 12:1 soro nipa re ni you mu wa sokole lo si akokop oba
Hoshea. Amosa ori kewa ese (14) ni woli
ti ntokasi shalmanaser eni to ko Beth-arbel ni gbekun ni odun 725BC wi pe ako
ilu yi ni igbekun lati owo awon ara Assria.
Igba akoko ti won ko ilu yi ni gbekun ni igba ti won ko Beth-arbel ti
won si fi ipa mu Israeli lati san isakole fun.
Igba keji ni igba ti won fi iya je oba Hoshea nitori pe o ba adehun to
nbe laarin awon mejeji je. Gbogbo isele
yi ni o se nigba ti woli Hosea nsise iranse re. Ise iranse Hosea bere ni odun 750BC osi pari
ni odun 725BC. Odun meta siwaju ijoba
apa ariwa di eyi ti a ko ni igbekun lo si ilu Assria lati owo oba Shagoni
ITAN IGBE AYE HOSEA
Itan
igbe aye Hosea ni a le pe ni kokoro ti o si itumo ikoni re. Idi nip e o now itan igbe aye re gege bi
aworan ibasepo Olorun pelu Israeli. Pelu
pele ati ikiyesara ati laini imolara itiju ni Hosea fi so itan igbe aye ebi re
ti o bani lokan je.
Eko meji la o ri ko
IJO lotito ife Olorun si Israeli ati aini okan aimoore
Israeli
Aijo looto Israeli si Olorun eni ti
ti dara si Israeli.
Olorun pe
Hosea lati lo fe obinrin pansaga kan ki o le ni omo lati ipase pansage nitori
pe ile na ti se pansaga pupo nipa gbigbagbe Olorun obinrin ti Hosea yan ni a
npe oruko re ni Gomeri omobinrin Diblaimu, obinrin yi ni o loyun ti o si bi
omokunrin meji ati imobinrin kan. Oruko
omo akoko ni Jesreeli – Itumo Jesreeli ni emi o be ese Jesreeli wo ni ara ile
Jehu a le pe oruko yi ni esan. Oruko omo
keji ti se obinrin ni Loruhama ti o tumo si emi ki o sanu fun ile Israeli mo
nitori emi yoo mu won kuro, oruko omo keta ni Loami ti o tumo si eyin ki si se
eniyan mi, emi ki yoo se Olorun yi. Awon
oruko yi ntoka si idajo ti yoo wa si ile Jeho gbogbo akosile itan Hosea ati
Gomeri yi je ohun ti o sele gan, o je ohun ti o sele bi Hosea ti salaye
re. Isele yi je eko apeere laarin Olorun
ati awon omo Israeli.
IWAASU HOSEA
O
fere je ohun lati to iwe Hosea ni bi won se to tele ara won sugbon gbogbo
iwaasu Hosea ni aleri ninu iwe Hosea ori kerin titi de ikerinla (ori keji si
iketa ni o nso nipa igbe aye Hosea.
Amosa ale pin iwe yi si ipa meji nla.
Eleyi ni ori kini si iketa ti o n so nipa woli funra re ati oro idile re
nigba ti ori kerin si ikerinla sin so npa iwaasu ti woli yi wa ori meta akoko
yi ni o nso nipa itan igbe aye temi fun Hosea, o je abala kan asotele.
Awon akosile awon ori wonyi o wa lati inu arojinle okan Hosea okan to ti
gbo gbe pupopupo. Nipa ife ti oni si Gomeri eyi ti arabinrin yi ko
sile, nipa re ni Hosea se awari ife
Olorun fun eniyan.
Abala
keji ti se ori kerin si ori kejila ni o kun fun orisirisi awon iwaasu kukuru
won je awon iwaasu kukuru to kun fun awon ikilo ati awon ileri. Biotileje wipe iwe Hosea koni akosile bi
isele se to tele ara won to dan moran sipe a le ri ninu iwe re orisi awon
igbese ti o ti orile ede Israeli si iparun die lara won ni wonyi:
1.
Aini imo:- Hos 4:6 – Awon eniyan mi segbe nitori won ko ni imo, ohun ti Hosea
nso nibi yi ni wi pe aini imo Olorun ni o npa Israeli ku lo.
2.
Igberaga:- Hosea 5:5 – Igberaga Israeli ti jeri gbe a re ogo Israeli loju ara
re. Israeli ni okan ti n saisan awon
eniyan Israeli ki se wi pe won feran ilu won sugbon won fe je alagbara agbaye
ti o ju ti keferi lo, oro ti Israeli ni pada di panpe fun won ola gbogb gbo
pada yi si itiju gbogbo gbo fun won.
3.
Aile duro sinsin:- Hosea 6:4 – Ife Israeli si Olorun dabi ikuuku owuro o si dabi iri owuro
ti o nkoja lo ijosin won to ye, ko kun fun emi o ti wa di tara
lasan ti o kun fun agabagebe. Isoore ko
pada je isoore tooto mo nitori na ni Oluwa se soro ni ori kefa ese kefa.
4.
Ife aye: Hosea 7:8 – Efraimu ti dara re po mo aye Efraimu ni akara ti a ko yi
papda, eleyi nso wi pe iselu orile ede yi ti buru pupo, Israseli gbona ninu oselu
sugbon won tutu ninu esin, won dabi akara ti apa kan re njona ti egbe keji ko
ti wo inu epo.
5.
Iwa ibaje:- Hosea 9:9 – Won ti ba ara won je pupo pupo bi ti ojo Gibea eleyi tumo si
wipe eto esin Israeli ti jera. Iwa ibaje
ninu oselu buru pupo sugbon bi iwa ibaje ba wonu esin o buru jai.
6.
Ipehinda/Ifaseyin: Hosea 11:7 – Awon eniyan ni tit e si ifaseyin kuro lodo mi, eleyi
tumo sip e ipehinda tabi ifaseyin yiyipada kuro loro Olorun ti di iwa baraku
fun awon omo Israeli o je ohun to ma nsele ni gbogbo igba, awon eniyan nsegbe
nitori imoran buburu won, ibi ti o si nlepa won je ohun ti won ko le bo ninu re
Hosea 11:8.
7.
Iborisa:- Hosea 13 : 2– Nisisinyi, won si da ese kun ese, won si ti fi fadaka won se
ere dida fun ara won ati orisa imo won se ere dida fun ara won, ati orisa imo
won ise onisona ni gbogbo rre, eleyi tumo si wi pe Israeli ti jowo ara re
patapata lati ma se ibi. Ko si woli to
kegbe orisa ti a fi owo ko to to ti Hosea.
AKOJOPO:- Awon
ese wonyi ni ese meje gbogi ti o ti Israeli lo si oko iparun patapata won ko ni
oye to tona nipa Olorun; Israeli gberaga; Israeli ko ni iduro sinsin ninu
ijosin tooto; Ninu oselu sise Israeli ti
da ara re po mo aye; Israeli di oniwa ibaje ninu esin; Israeli ti yipada kuro
leyin Olorun re: Israel ti bere si ni sin awon orisa.
EKO TA RI KO
1.
Iwa
ibaje ni orile ede
olewu ju ota ode lo.
2.
Iwa
were lo je ki eniyan jowo alaafia ilu re sile nitori ere adani ti eniyan fe ni.
3.
Iya
yoo wa fun eni ti o ba fi aye gba iwa ibi laise idajo re.
4.
Aisan
to ndagba kiakia ni orile ede
ohun ni ni gba ti awon adari elesin ba di oniwa ibaje.
5.
Ijiya
yoo wa fun eni ti o ba ko ofin Olorun sile.
JOELI – WOLI PENTIKOSITI
ITAN IGBE AYE RE
A
o mo ohun ti o po nipa ibi ti a ti bi ati nipa itan igbe aye re. Ise oojo re ati ihuwasi re farasin fun wa,
die ni ikowe re toka si a ma nri iru idakeje bayi lori awon iranse Olorun temi
ninu majemu laelae. Ere idi re ni wi pe
ki Olorun nikan soso le gbe ogo ki o ma je eniyan. Amosa a mo wi pe woli Joeli omo bibi Petuali
ni se eyi ti o tumo si “Riro Olorun”.
Oruko
joeli lati inu ede
Heberu “yo-el’ ti o tumo si Jehofa ni Olorun, oruko re yi wa lati inu oruko
Olorun meji Jo/el.
El -
Jehofa ni Olorun / Jehovah is
God
Gege bi oruko Mika oruko yi je ijewo
igbagbo to se afihan re wipe awon obi re je eni Olorun. Oruko Joel farahan lopolopo ninu majemu laelae. Die lara awon eniyan to nje Joeli ninu bibeli
ni wonyi.
1.
Joeli
ti o je akobi woli Samueli – 1 Sam 8:2
2.
Iran Simoni kan 1 Kro 4:35
3.
Iran Reubeni kan – 1 Kro 5:4, 8
4.
Olori
ebi ni iran
Gadi – I Kro 5:12
5.
Omo
Lefi kan to
wa lati in ebi Kohati – 1 Kro 6:36
6.
Iran Issakari kan – I Kro 7:3
7.
Okan
lara awon okunrin alagbara Dafdi I Kro 11:38 a pe ni egali ninu II Sam 23:36.
8.
Ijoye
kan lati inu
ebi Gersomu – I Kro 15:7,11
9.
Okan
lara awon oluso ile isura ile oluwa – I Kro 23:8, I Kro 26:22
10.
Ijoye
kan ni
Manase - I Kro 27:20
11.
Iran
Kohati kan ni
akoko Hezekiah – II Kro 29:12
12.
Omo
Juu kan to fe
iyawo ajeji – Ezra 10:43
13.
Olori
ninu eya Benjamin ti o gbe ni Jerusalemu – Neh 11:9
14.
Joeli
okan lara awon woli kekeke omo Petueli ti o gbe ni Juda ni akoko isejoba Usaiah
– Joeli 1:1.
O sese ki
Joeli je omo bibi ile Juda paapaa julo Joeli sese ki o je omo Jerusalemu nitori
pe o soro pupo nipa sioni ati awon omo sioni Joeli 1:23, bakana ni o
soro nipa Juda ati Jerusalemu bakanna ni o soro nipa awon omo Juda ati Jerusalemu
Joel 3:1, 6. Nitori ife ti oni si tempili ni a se ro wi pe o sese
ki Joseli je alufa Joseli 1:13-
17 boya eleyi je otito abi be ko o han gbangba lati inu awon asotele re pe
Joeli ki se akewi nikan sugbon o je eni ti o ngbadura ati wi pe o tun je ariran
ati woli.
AWON OHUN TI A O GBEYEWO TABI AWON
OHUN TI O WA NINU IWE NA
Ipin meji ni a pin iwe Joeli si awon na ni wonyi.
1.
Ori kinni ese kini de ori keji ketadinlogun (1: 1- 2: 17 )ni abala yi ni woli yi soro. O bere oro re nipa sisalaye pelu gbolohun oro
to ja gaara nipa ajakala arun esu eyi ti o gbele yoo tele, o si pari oro re
pelu isipe si awon eniyan lati ronupiwada.
2.
Ori keji 2:18 – 3:21 ni abala yi luwa ni o soro Oluwa
kede ni ohun jeje o si soro ni pa iparun ti o nbo wa sori awon ota Israeli o
pari oro re pelu si sakawe isegun ologo ti nbo wa fun awon eniyan Olorun.
Idaji iwe yi
nitori na o bere ninu okunkun o si pari sinu im9ole. Apa keji iwe na o bere pelu idajo o si parti
pelu isegun.
Awon
asotele ti o wa ninu abala akoko ninu eyi ti Joeli ti soro lo pese ona sile de
asotele nipa opin aye ti o wa ninu abala ekeji eyi ti Olorun ti so. Arojinle wa ninu gbogbo iwaasu woli na. A le pe iwe Joeli ni owe nipa eesu ati ohun
to fe ka ko nipa re. Nitori na a ko iwe
Joeli ni ona ti o yato ninu gbogbo awon iwe miran ti o wa ninu majemu laelae.
ISELE TO FA ASOTELE NA
Iwe
Joeli yi je asotele ti o waye nitori ajakale arun eesu ti Olorun fib a awon omo
Israeli ja, eesu yi je wahala ti Olorun fi pon Israeli loju nitori aigboran won
– Joeli 1:4 O dabi eni pe isele yi ni Olorun fi senu woli yi lati fi kilo fun
awon omo Israeli wi pe ohun yoo ran awon omo ogun ti pale won mo si won bi a ba
se afiwe iwe yi pelu iwe Deuteronomi chapt 28 – 38, eesu yi je apeere wahala,
idaamu ti Olorun si oko awon omo Israeli lati jerun.
Awon
ojogbon kan so wi pe isele yi se ni December 1951 gege bi arakunrin Johun D
Whitting ti eesu je gbogbo irugbin won isele naa lagbara ti won ko le gbagbe
re.
KINI ITUMO EESU YI
A
le bere ibere yi wi pe se looto ni
ajakale arun eesu sele ni a bi Olorun kan fi se alaye owe ti o nbo lojo iwaaju
se awon kokoro orisi merin ntoka si awon ijoba merin. Itumo to dara ti a le fun Joseli ni wi pe
isele naa sele ni ki se owe, isele naa sele ni akoko Joeli gbogbo eniyan ni o
si mo.
IWAASU IWE NAA/JOELI
Iwaasu
Joeli ni a le pin si ona meta lehin ti Joeli si ti wasu re yi ta ni awon woli
miran bi Nahumu, Sefaniah, Amosi, ati Isaiah ya oro re lo.
Awon ohun ti iwe na da le lori
1.
Ojo
Oluwa
2.
Ero
titun ti Olorun fi si okan Joeli nipa oke Sioni
3.
Itujade
emi mimo.
Bi a ba wo
iwe Joeli iwaasu re akoko ti akori re je ojo Oluwa je iwaasu to lagbara. Ona meji otooto ni won ma ngba lo ojo Oluwa
ninu bibeli, Johannu olufe lo oro yi ninu iwe ifihan nipa ojo Oluwa o nso nipa
ojo kinni ose (ojo Sunday) – Ifi 1:10
sugbon Joeli nso nipa ojo idajo nigha ti o nkede Oluwa ojo ti awon aligbagbo
yoo so ekun kikoro – Mt 24:21, Joeli 3:14.
Bibeli
fun wa ni awon oruko mefa miran ti a fun ojo Oluwa eyi ti Joeli nso nipa re.
Ojo Oluwa Sefaniah 2
Ojo Na tabi ojo ikeyin Joeli 1:15,
Joeli 3:14
Akoko iponju Jakobu – Jer 31:7
Ojo nla ojo ibinu – Ifi 6:17
Ojo Esan – 1 Thes 1:8, Isa 16:4
Ojo Ibanuje ojo wahala – Ezk 7: , Isa 24:1 – 23, Dan 9:20 – 27.
ERO TITUN TI OLORUN FI SI OKAN JOELI
NIPA OKE SIONI
Apeere meji ni o se afihan re idi ti iwaasu Joeli fi dagba ju
ti awon woli yoku ti won ya oro re lo lo.
Ninu Joeli 3:16 – Joeli wipe Oluwa
yoo bu ramuramu lati sioni wa yoo si fohun re jade lati Jerusalemu wa, awon
orun ati aye yoo si mi sugbon Oluwa yoo se aabo ati agbara awon omo Israel
“Ninu iwe Amosi 1:2 a ka wi pe Oluwa yoo bu jade lati Sioni wa yoo si fohun re
lati Jerusalemu wa, ibugbe awon oluso aguntan yoo sofo, oke karmeli yoo si
ro”. Abala akoko oro Joeli ati ti Amosi
yi won jora won se Joseli lo ya oro Amosi lo ni abi Amosi ni o ya oro Joeli
lo? O han gbangba pe Joeli ni eni to
koko ko oro yi
Ninu Joeli 3:10 – Olorun baa won
orile ede soro ti o si wipe “E fi irin oko itule yin ro ida, ati doje yin ro
oko: je ki alailera wi pe, ara mi le koko” Ninu Isaiah 2:4, Mika 4:3 awon woli
yi ti won ti wa siwaju Joeli won so asotele nipa akoko ti awon eniyan yoo fi
ida won ro oko itule, won o si fi oko won ro doje. Tani ninu won to koko soro yi siwaju Joeli ni
tabi Isaiah tabi Mika? Ninu iwe Joeli
ohun elo alaafia ni oko ati doje ni a palase fun won lati fir o ohun elo ogun
ti se ida ati oko. Ninu Isaiah ati Mika
ohun elo ogun ni a ni ki won yipada di ohun elo alafia
Doje ida
Doje
Joeli nso nipa ohun ti awon eniyan gbodo se ni akoko na sugbon Isaiah ati
Mika nse o nipa ohun ti o nbo wa sele ni ojo iwaju.
ITUJADE
EMI MIMO
Joeli soro daradara ju awon woli miran
lo nipa itujade emi mimo si ara awon eniyan gbogbo. Joeli 2:28 -29 asotele yi ni o fun Joeli ni
eto ti a fi npe ni woli pentikositi, bio tileje wi pe Joeli ko ni oye to kun to
nipa ohun ti oro na tumo si ninu eto nla ti Olorun ni – Ise Awon Aposteli 2:15
– 21.
AMOSI – WOLI ONIDAJO ODODO
Opo awon akeko majemu laelae ni won
gba pe Amosi je okan lara awon woli akoko ti o ko iwe. Bi eleyi ba ri be aje wi pe iwe re ni ekun
rere iwaasu to koko farahan. Amosi je
okan lara awon woli ti ki beru ti o si kun fun agbara Olorun. O je oniwaasu to ma nwasu nipa ironupiwada
ati idajo. Onkowe kan wi pe Amosi je okan lara ifarahan iyanu
ninu itan iran
eniyan. Oruko re tumo si eru wuwo tabi
oluru eru to wuwo woli yi dagba ninu aginju kan ti a npe ni Tekoa o ngbe laarin awon
olusoaguntan ni tenkowa.
Gege bi Elijah ati Matin Luda ati awon
adari esin miran Amosi je woli ti a se aye re pe lati ipase akoko ti o dagba
si. O je asoju akoko re. Amosi je okunrin takuntakun eni ti ki beru ti
o le bi ako okuta ti o si ni ihuwasi ominira oni okan to le ati iwoye to ja
gaara. Amosi je okan lara ifarahan ti a gbodo
kiyesi ninu itan Heberu. O je okan lara
awon woli ti won se akosile re ti o si bere akoko tuntun miran ninu itan
Israeli.
ILU RE ATI ISE OOJO RE
Amosi dagba ni eti bebe aginju ti o to
mile mejila si apa Gusu Jerusalemu ni ibe lo ti ngbe ni arin awon darandaran ni
Tekowa Amosi 1:1. Amosi ngbe ni ilu yi
bi omo oko gege bi Mika a o da oruko Baba re ni bi kankan.
Nitori idi eyi o se se ko wa lati idile talaka ati ebi ti ko se Pataki
lawujo. Ise re ni lati je darandaran
olusoaguntan, eleyi si ran lowo lati je olusoaguntan kan dagba lona to yato, awon aguntan to ni irun to rewa. Iru awon aguntan ti Amosi nsin yi won kere
irisi won ko si re wa sugbon won ni irun lara.
Won ma nronu pupo lori awon aguntan yi, Amosi nitori owu ti won yoo ri
lara won ni. Amosi se akawe ara re gege
bi olutoju igi Sikamore.
O han gbagba nitori na pe Amosi je eni
to gbe ni ona to sunmo iseda o ngbe ni agbegbe ekun Juda ti o je oju ona
geregere si ila okun oku. Awon eranko
ehanna ni won ma nri ni awon agbegbe yi laisiyemeji nibiyi ni Amosi ti ko nipa
irawo ni asale to si nkiyesi bi ooru ti nyipada ati iyanu ti o ri bi oorun ti
ndi alaranmoju ni ila oorun. Amosi ni
anfani si awon afefe itura ni aginju o si le gun oke Juda ti o ga julo. Ise Amosi lo pa ni dandan fun lati lo si oja
owu (wool market) ni awon ilu apa ariwa.
Nibe lo ti ko lati mo nipa igbe aye awon eniyan ati esin awon
eniyan. Amosi ko kawe nitori pe ninu
aginju Tewoka lo dagba si. Sugbon o je
eni to lola ni iwa o je eni ti o le ti o si ni alaafia to pe ninu ago ara re
leyin akoko pipe Johannu baptisi o lo opolopo ajodun ninu aginju yi kanna ninu
eyi ti Amosi ti dagba. Ninu ipo yi ni
Amosi ti mu ara re dagba gege bi alatunto esin.
Ohun to kan
Amosi julo ni lati soro nipa eto to to si Olorun ati idajo ododo laarin awon
eniyan re.
IPE AMOSI
Amosi ko ni imurasile Pataki lati je
oniwasu. Ko lo si ile iwe kanakan ri
idanileko re je akiyesi igbe aye to nbe ni ayika re Amosi ki se woli lati idile
wa ko jogun beni ki se omo woli, Amosi ko si lara awon eniyan ti won lo si ile
eko woli. Amosi wipe oluwa kan mu mi lati inu dida
eran ti o si so fun mi wi 0pe lo ki o si so tele si Israeli eniyan mi Amosi 7:14 – 15 nibe ninu aginju yi,
aginju ti o kun fun iji ati afefe lile ni o ti ronu nipa Olorun. Ojiji kan
sinmi le okan re ti o je ko ni oye idajo Olorun sori awon eniyan. Bi idajo yi si ti ola loju ti o si han
gbangba si ni o se kigbe jade nitori ibanuje okan re sori awon eniyan.
Nigbati Olorun ba pe iru awon eniyan
yi lati abule wa ti o sip e won si igbe aye igbooro iru won a ma mu ki oselu
ati esin o wa ni alaafia. Iwaasu. Amosi
o je iwaasu Pataki si awon apa ariwa Israeli.
Nitori na Amosi lo si Beteli irin ajo to to mile mejila si apa ariwa
Jerusalemu. Nibe ni abe ojiji afin oba
ni o ti gbe ohun re soke ninu ekun to le to si jinle to si npe fun idajo ododo.
AKOKO AMOSI
Amosi so asotele ni aye Usaiah Oba
Juda ati ni ojo Jeroboamu omo Joasi Oba Israeli, odun meji ki akoko ile riri to
waye Amosi 1:1. A fi idi gbolohun oro
wonyi mule lati inu oro asotele Amosi 6:13, 7:11 akoko ile riri yi, amosa ni o dabi eni pe ko da
ju. Sugbon ile riri na je eyi ti oni
agbara pupo nitori pe Sekariah eni ti o wasu leyin ogorun meji (200yrs) leyin
akoko na o soro nipa isele na Sek 14:5.
Apapo ija oorun ati osupa (Eclipse of the sun) ni o dabi pe o tele isele
ile riri na o dabi enipa Amosi 8:9 toka si.
Awon amoye irawo se iwadi re pe isele ki oorun wo ni osan gangan yi o
waye ni June 15, 763BC. Eleyi mu ki
akoko woli je odun 760BC. Eleyi ni akoko
ti ogo Israeli ntan nigbati won ni oro gbogbo gbo.
Ni akoko yi Jeroboamu II ni o wa lori
ite, o je oba to le. O nsakoso lori awon
agbegbe to po gege bi Jona ti so asotele si pe yoo se II Awon Oba 14:25. Sugbon pelu ailayo, bi o tile je pe oro to po
wa ni ilu na sibe ogbon kukuru ni won ni ase ati ayeye ni o gba aaye esin lowo
won. Gbogbo awon eniyan lapapo won di on
wobia. Iwa ibaje ati aisi idajo ododo
die se ojoojumo. Ipa pada die to awon
olowo ngba ile lowo awon talaka. Awon Larinlord won nsakoso/dari ijoba ki
won le fiya je awon agbe ti won ya ile lo lowo won. Abayori si eleyi nip e awon olowo nlowo si
awon talaka ndi talaka si. Awon eniyan
kegan eto ara si bere sir o won ni Sioni Amosi 6:1 ni ibi gbogbo ni ife oro wa, awon eniyan
si nfe ohun mere mere gege bi o ti wa saaju isubu Romu. Esin so okun enu awon eniyan si ko igbe aye
rere sile aijoloto, ajolododo, iwa ibaje ati iwa buburu nina owo ni ina apa ati
ailakasi lodi
iwa to gbe awon olowo wo to be ti won fi di aborisa ninu ohun gbogbo ayafi
oruko lasan to ku fun won. Alabajo ti
woli ti o wa lati inu aginju yi fi kigbe ti o ni ipalara ju bi o ti ye lo. Abajo ti o fi wasu to le ati iwasu iparun
sori orile ede
elese na. Amosa o yaw a lenu wi pe woli
yi ko bu enu ate nu awon maalu ti a gbe male ni Beteli ati Dani ati pe ko kede
oruko awon ota ti o pa Israeli run. O se
ajeji si wa wi pe Amosi ko daruko Assria!.
OKAN IWAASU AMOSI
Okan iwaasu Amosi ni wi pe “a o pa samaria run” orile ede Israeli ti won ti pon
fun idajo. Amosi ni woli akoko ti o koko
kede re pe A o pa Israeli run. Ni ojo
ase nla ni Beteli o gbe ohun ekun re soke ti o si wi pe wundia Israeli ti subu
ki yoo si le dide mo lai (Amosi 5:2) eleyi ni orin isinku ti a ko si orile ede na. Ipo ti won wa ni igba na o buru pupo ojo
iparun Israeli nbo wa ojo Oluwa, nibi ti Joeli ti dawo duro nibe Amosi ti berre
ise re o kigbe wi pe Oluwa bu ramuramu lati Sioni wa o si fohn re lati
Jerusalemu wa Amosi 1:2 pelu igboya nla ni Amosi fib a awon eniyan soro awon ti
won ngbe igbe aye won lati di oloro o so nipa idajo to gbodo tele nigbati esin
ati igbe aye buburu ba nrin papo.
Awon ohun ti o se okunfa idajo yi o han gbangba. Awon na ni iloro ati ohun oso, ailakasi ati
iwa ibaje, oro ti iwa ipa tele aafin igba ojo ati aafin igba erun, awon ibusun
olowo iyebiye, waini mimu ati awon orin buburu.
Awon nnkan wonyi ni awon iwa buburu ti o npe fun idajo. Woli aginju yi ri kedere pe ohun kan nbe ti Olorun
olododo le se. Siwaju si awon iwa ipa kan pato wa ti won ti
won tile buru ju awon iwa ese ti a ti daruko loko yi lo. A n ja awon talaka lole, a ngba aso lorun
awon talaka lati fi di gbese, a nfi esin bo iwa pansaga ati imuti para mole,
won ko san idamewa lati inu okan, pipa ojo isinmi mo di popo fo ati aisotito,
irin ajo si ile mimo niwon nse lati year fun awon ojubo orisa ti kobu ola fun
Olorun Israeli – gbogbo awon nnkan wonyi ati awon nnkan miran ni o fa ti o kan Amosi fi gbogbe ti o si la enu
re lati so asotele. O se awari re pe ni
ibi gbogbo ni okan awon eniyan ko ti wa ni alaafia. Amosi ni idaniloju pe Olorun ti yan ohun gege
bi Alatunto igbe aye awon omo Israeli.
Nitorina iwaasu re je iwaasu idajo ki se ti aanu, iwaasu re je ti ofin
ki se ti oore ofe.
AWON OHUN TO WA NINU IWE RE
Awon
asotele Amosi ni a pin si abala meta awon ipa na ni wonyi.
A.
Ori kini ati ikeji
Awon
ori yi kun fun orisi idajo mejo ti akedo lori Israeli ati awon alamulegbe won. Igba
mejo ni akiyesi aworan Olorun gege biu eni to wi pe nitori irekoja meta tabi
merin emi ko ni yi ijiya”.
1. Damasku:
- Nitori
ti won fi ohun elo irin ipaka pa Gileadi – Chapt
1:3– 5
2. Gasa: - Nitori ti won ko gbogbo igbekun ni igbekun lo lati fi won
le
Edomu lowo – Chap 1:6 – 8
3. Tire: - Nitori
won fi gbogbo igbekun le Edomu lowo, won ko si
ranti
majemu arakunrin 1: 9 – 10.
4. Edomu: - Nitori
o fi ida lepa arakunrin re, o si gbe gbogbo aanu
sonu,
ibinu re si nfaniya tit o si pa ibinu
rre mo titi lae 1:11 – 12.
5. Ammoni: - Nitori
won ti la inu awon aboyun Gileadi, ki won le baa
mu
agbegbe won tobi – 1:13 – 15
6. Moabu: - Nitori
o ti sun egungun oba Edomu di eeru 2:1 – 3.
7. Juda: - Nitori
won ti gan ofin Oluwa, won ko si pa ase re mo, eke
won si ti mu won sina, eyi ti awon baba won ti tele – 2:4 – 5.
8. Israeli: - Nitori
won ta olododo fun fadaka, ati talaka fun bata ese
mejeeji
– 2:6 – 16.
Gbogbo
idajo mejejo yi ni o nko wa ni ipile ofin bibeli fun awujo rere.
1.
Olorun
ni Olorun gbogbo eniyan ati Olorun gbogbo orile-ede.
2.
O
je ese fun eniyan lati pa eniyan akegbe re lara.
3.
Gbogbo
iran
eniyan ni won gbodo jiyin ise won gbogbo fun Olorun.
Amosi ni woli akoko ni Israeli ti o koni wi pe ofin nbe fun
orile ede ati
wi pe Olorun ni o se ofin naa.
B. Ori keta si
ikefa ( 3- 6)
Abala yi kun fun orisi iwaasu meta ti o nso nipa idajo
to le. Okookan won bere pelu ipe “e gbo
oro yi ti Oluwa so si yin”. 3:1, 4:1,
5:1. Gbogbo iwaasu meteta yi ni o nkilo
fun Israeli gidigidi a le se akawe awon iwaasu na bayi:
1.
Ori
keta – Oluwa yan Israeli niwon igba ti Israeli ba si nje Olotito, ori ti o tobi
ju ni ori keta yi.
2.
Ori
kerin – Ikilo si awon omo obinrin samaria
“”Eyin maalu Basani” ti won je alainironu oni wa imotaraeni nikan ati iwa ipa
Isa 3:16. Biotileje pe Olorun ti fi oniruru ajakale
arun kilo fun won ni opolopo igba Oluwa ti kilo fun won nipa iyan, nipa ogbele
– Amosi 4:7 – 8 o ti fi iparun ba won wi ati ida 4:9 – 10 ileri ri vs 11 sibe
Israeli ko yipada si odo Olorun.
Nitorinaa ni woli na se kigbe wi
pe eyi pada e mura lati pade Olorun yin iwo Israeli.
3.
Ori
karun ati Ikefa – Iwaasu yi je ewi ati ipohuntrtr rkun niyoti Israeli ko le bo
lowo aisan temi to nse won.
Awon ohun ti o fa aisan ti a ti
Israeli sinu iku ni yi.
a.
Israeli
ti kegan ododo won so idajo di iwa 5:7
b.
Israeli
korira ibawi 5:10.
d. Pelu egan ni Israeli fi n so wi pe ki ojo
Oluwa ode – 5:18
e. Ase esin ati awon ipade
ajo owo ni won ko fi tinutinu se nitori na ni Olorun
se korira won – 5:21
e.
Israeli
ko teti si ipe Olorun wi pe e wa Oluwa ki esi ye – 5:4, 6, 14
Nitori na woli yi kede ijiya oni pele meji sori Israeli ati gbogbo awon
ijoye re wi pe won o lo si igbekun a o si pa ilu won run 6:7, 8, 11.
D. Ori keje
si ikesan (7 – 9 ) – Abala yi kun fun orisirisi awon iran marun ti o je opin ireti ati
itunu. Leyin opin iran eleketa ni
Amasiah Alufa Beteli dasi oro na lati gbena woju woli na 7:10 – 17.
Bi awon iran
iran
marun na se lo niyi
1.
Iran nipa awon eesu – 7:4 – 6
2.
Iran nipa ina ajonirun – 7:4 – 6
3.
Iran nipa iwon ododo – 7:7 – 9
4.
Iran nipa agbon eso eerun – 8:1 – 14 opin
ti de ba Israeli.
5.
Iran nipa tempili ta pa run – 9:1 – 6
Iwe yi parti pelu ileri imubosipo 9:7 – 15.
AWON EKO TA RI KO
1.
Amosi
fihan pe Olorun Israeli je Olorun to ni imolara
2.
Amosi
ko w ape ijosin ta fe loju ti ko ba ti inu okan ododo wa abuku ni si Olorun
5:21
3.
Amosi
ko w ape idajo ododo gbodo wa laarin eniyan si eniyan.
4.
Amosi
ko w ape bi a ba gba ibukun lowo Olorun a gbodo fi sise ki a si lo ni ona toto
5.
Amosi
ko w ape gbogbo ajalu lo je ipe titun si ironupiwada
6.
Amosi
fi ye wa pe ikilo ti Israeli nilo lati teti si awa na nilo re pelu.
7.
Amosi
ko wa pe bi woli ba je woli tooto o gbodo ni idaniloju pe Olorun pe ohun lati
waasu.
OBADIAH – OLUBAWI AWON ELEGAN
IWE NAA
Obadiah ni iwe to kere ju ninu majemu
laelae. Ese mokanlelogun (21) ni iwe na
ni a ko ya oro lo ninu re be ni a ko toka si lati inu majemu titun. Laarin iwe woli mejila iwe yi ni o tele iwe
woli Amosi. Awon akeko majemu laelae ro
pe iwe na tele iwe Amosi nitori pe o tesiwaju lati salaye asotele kukuru to wa
ninu Amosi 9:12 ti a so lodi si Edomu wi pe won yoo jogun eyi to seku ni Edomu. Iwe yi je iran ti a so tara
lo di si Edomu. Iwe na kuru sugbon o le,
bi o se kuru si ni o se le si.
ENI TI O KOWE NA
Obadiah ko ni itan aladani oruko re
tumo si olusin Oluwa. Opolopo awon
eniyan ni won nje Obadiah ninu majemu laelae die lara won ni wonyi.
1. Olori ebi eni ti o wa lati iran Dafidi – 1
Kro 3:21
2. Iran Tola kan ti se omo Issakari – I Kro 7:3
3. Omo Aseli eya Benjamini kan – I Kro 9:44, I Kro
4. Lefi kana ti se omo semaya – I Kro 9:16
5. Ara Gadi kan eni ti o dara po mo Dafidi ni siklag – I
Kro 12:9
6. Baale kan ni ile Ahabu Oba Israeli ohun ni o fi
awon woli Oluwa pamo ti o si
nbo
won ni akoko inunibini Jesebeli – I
Awon Oba 18:3 -16.
7. Ikan
lara awon ijoye Juda ti o ko awon eniyan ni ofin ni akoko Jehosafati – 2 Kro 17:7
8. Baba
Isimaya – I Kro 27:19
9. Omo Lefi
kan ti o je
alabojuto sise atunse ile Oluwa ni ojo Josiah – 2 Kro 34:12
10. Omo Jahieli kan – Ezra 8:9
11. Alufa kan to fi edidi majemu
ti Nehemiah se – Neh 10:5
12. Oluso ibi
mimo kan –
Neh 12:25.
13. Obadiah
eni kerin laarin awon woli kekeke eni ti o gbe leyin iwopale Jerusalemu - 588BC. Sugbon a ko mo nnkan miran leyin re
mo – Obad 1:1.
IWAASU RE
Gbogbo iwaasu re ni ale se akojopo re si
gbolohun oro meji:
1.
Iwopale
Edomu 1:16
2.
Imupaddabosipo
Israeli 1:17 – 21
Ilepa okan woli yi amosa ni wi pe yoo ki fun Edomu ki
a tu Israeli ninu, Awon nnkan yi ni o je koko iwaasu yi, awon ohun elo inu iwe
yi ni a pin si ipa meta.
1.
Ese
kinni si ikesan – eleyi nso nipa iparun Edomu bi o tile je pe o fi ara re pamo
sinu apata
2.
Ese
ikewa si ikerinla (10 – 14) – Eleyi ni so nipa idi fun iparun yi, nitori iwa
ipa re si Israeli ati nitori pe o yo nitori isele ibi to se si Israeli.
3.
Ese
ikedogun si mokanlelogun – o so nipa imubosipo Israeli.
AKOKO
Opolopo awon ojogbon majemu laelae ni
won gbagbo pe iwe yi ti wa tip e. Won ko
gba pe Obadiah nikan ni o ko sugbon won gba pea won onkowe meta miran lowo si
iwe na. Gbogbo awon mererin ni won jinna
si ara won nipa akoko okookan won lo ko ohun to yato ti won si ko papapo sinu
iwe na.
Ninu ero awon ojo gbon yi won gba wi
pe Obadiah gbe ni odun 46o. O bere
asotele re lo di si Edomu o si so ni pa bi won yoo se bori won 1:1 – 4, Obadiah
se afikun si ikilo re ni 1:5 – 14, 15b.
Woli kan to gbe leyin ogorun odun leyin Obadiah
ni o so asotele nipa imubosipo Israeli
Israeli si ipo agbara re igani ati ogo 15a, 16 -18. Nnkan wonyi ni o se afikun re si nnkan ti
woli ese kokandinlogun si 19 – 21 ninu awon ese yi o fid a awon Ju loju wi pe a
o fi idi ijoba mule ati wi pe Olorun yoo nikan joba lae. Ako akosile ni akoko isote awon ara Makabisi
ni 168BC.
Iwe yi ko so akoko ti a ko a gbodo fi
idi akoko ti a ko ni 850BC. Ni odun yi
awon ara Filistini ati ara Arabia gbogun ti Jerusalemu won si ko oro tin be ni
aafin Oba lo – II Kro 21:16 – 17. Akoko
miran ti awon miran so pe ako iwe yi ni odun 312BC ni akoko ti awon ara Edomu
di eyi ti awon ara Nabateans koni igbekun.
EDOMU
Gege bi a ti ri Obadiah so asotele
nipa Edomu paapaa julo nipa awon olugbe Edomu.
Awon ara Edomu ngbe ninu ilu olokuta ti a fi okuta se ibi isadi won ti
won si nro ni okan won pe ako si eni ti a le bori won. Nitorina ni Obadiah se kowe “Igberage aya yin
ti tan yin je eyin ti ngbe laarin palapala okuta, ibugbe eni ti o ga ti o nwi
ni okan re pe tani yoo mu ni sokale?”.
Apata ti a n toka si inhin yi ni a npe
ni ilu “Petra”. Ilu yi lati igba atijo wa ni o je ilu olodi
ati ilu aabo fun orile ede. Awon Arabu odo oni npe ni “wadymusa”. Ara Siria igbani kan ti oruko rre nje Josefus so fun wa wi pe
a npe ilu apata yi ni rekemu gege bi oruko omo Oba Midiani kan eni ti o subu loju ija pelu Israeli ni
ilu Moabu ni ojo Finiasi Num 31:8.
Petra
o da duro laarin awon ilu igbani ni gbogbo orile ede agbaye fun ewa re to yato ati ibi to fidi
sole si. O fere soro lati salaye ilu
apata yi lekun rere. Ilu yi wa nig gere
gere oke seiri. Ni gbogbo ayika ilu yi
apata to rewa pelu awo to dara lo yika irufe awon ewa ati oso daradara eyi ti a
ko ri ni ibomiran. Ilu Petra yi ni a npe
ni iyanu aginju.
Ilu to rewa yi to si se ajeji ni
eniyan yoo be ona tooro inu apata wo inu re lo ti o sir in to mile kan ninu apata naa ko to
bo sinu ilu naa. A n pe ni sik or cleft
ibi isadi o je agbegbe awo dami enu.
Isan omi kekerre kan
n san labe ati
ni gbogbo oju ona to wo ilu na. Oju ona
to wo ilu yi o tooro o si jin to be ti o fi ma nsokunkun ni osan gangan. Awon apata yi ti won ga soke ni gbogbo egbe
kinni ati keji ni won rewa peupo ti a si kun ni oda amutorunwa gege bi ti
esumare.
Awon awo apata yi se afikun ewa si ilu
yi. Won ni awon awo bi awo ododo elese
aluko, olomi osan, alawo ofefe, awo funfun, awo alari, ati awon awo orisirisi
miran ni iseda seto ni ona iyanu ni oniruru ona. Awo kan yi wonu omiran ti won si lo wonu ara
won lati mu ewa to dara jade ti yoo je oju ni gbese fun awon to be se abewo si
ilu na. Gbogbo ilu yi ati ayika agbegbe
re ni o ni awo to rewa pupo ti o je ori oke, palapala ati awon ibi ikerusi ti
okuta se loso funra re pelu awon ogbon ati afonifoji ati awon agbegbe ati okuta
se iboji si ati awon agbegbe oorun. O je
agbegbe to rewa to si ni aabo, ibi isadi fun okowo ati oro aje ti yoo te gbogbo
awon onisowo lorun.
Sugbon si iyalenu nla gbogbo ewa to
dara yi lo yi ilu to ti di oku yi ka. Petra ti di ahoro ati
korofo awon eniyan ti ko sile ni gbogbo ayika re ni jinni jinni ati iparoro iku
wa. Awon eranko buburu ni won ngbe ninu
ilu yi biotileje pe ilu yi je aarin gbungbun asa ati okowo tele, sugbon o ti di
ibi iparun ti akosile. Gbogbo ikilo
Obadiah ati asotele re lo pada se.
AWON EKO TI A RI KO
1.
Ikilo
woli yi nipa awon elegan – vs 12 Edomu.
Edomu yo lori isubu Juda won kegan won bu enu ate lu Israeli nitori
isubu won. Edomu yo nitori iparun to de
ba Juda, nitori eyi ni woli Obadiah se be awon ara Edomu wi, Egan ati ibuenu
atelu ni ma nwa lati inu okan igberage nigba ti a ba kegan awon elomiran a nfi
iru emi to nbe ninu wa han, ikegan ma nse afihan asi ife ara. Nigba miran o ma nje arimu ikorira. Edomu ati Israeli ni wo ti korira ara won ni
opolopo odun ninu akosile itan won fun amoye ogorun odun ni won ti je ota ti
won kosi ba ara won laja leralera ni won ti be ogun esan ti ara won, imotara
eni nikan ti gbogbo ati eleyameya o ti so won d iota ti ko dariji ara won. Leyin o reyin awon ara Babaloni bori awon omo
Juda, eleyi losi mu awon Edomu beresi kegan awon Juda. A fi iya je Edomu nitori iwa ota to fi han
Juda. Sibe olukuluku won jiya ese re,
igberaga ni ma nsiwaju iparun.
2.
Ese
10 – 15 eko nipa ijiya to le –
Obadiah tenu mo pe idajo Olorun ayeraye ni enikeni ko leparun. Ojo Oluwa nbo wa lori Edomu ati lori awon
orile ede miran
ni woli na ki gbe. Igberage ogbon Edomu
yoo jakule. Awon ologun re yoo di afoju,
won ki yoo ri iparun ti o nbo wa ba won.
Olorun yoo mu gbogbo ogbon kuro ni Edomu ki won ma ba bo fun iparun ti o
nduro de won.
3.
Ireti
to daju nipa ogo Israeli to nbo wa vs. 17 ile Jakobu yoo ni ini re/tabi ini
gbogbo orile ede,
eleyi ni asotele ti Obadiah so fun awon orile ede re.
Ni ipari a o se ikawo Edomu yoo pada di ara ijoba Israeli olugbala yoo
goke lo si oke si oni lati joba oke Esau ijoba na yoo si je ti Oluwa vs 21.
JONA – WOLI ALAPON
Iwe Jona je iwe ti o tobi ti o si kun
fun itan Jona fun ara re. Yato si adura re ni ori keji gbologun oro kan soso ni a le pe ni
asotele ninu gbogbo iwe re. Eleyi ni o
wa ni ori keta ese ikerin. Amosa irufe
nnkan yi ko wop o laarin awon woli. Nigba
miran, a ma nse akosile iriri awon woli sinu iwe won fun apeere Hosea 1:1 – 3,
Amosi 7:10 – 15, Jer 1:25 – 29, 36 – 38.
ITAN IGBE AYE JONA
Jona je eni ti a mo ti o sise bi woli
ni Israeli. O fere je pe gbogbo awon
ojogbon ni won da Jona mo gege Jona omo Amittai, eni ti o so asotele si
Jeroboamu nipa imubosipo Israeli si awon gbegbe re atijo 2 Awon Oba 14:25.
Jona
je omo bibi ilu Gath-hepher ni Galili.
Ilu yi o wa ni agbegbe ti o to mile merin si apa ariwa nasareti, ati wi
pe a mo ilu yi si ilu Arabu ti a mo si El –meshed 2 Awon. Oba 14:25.
Nigbati Olorun pe Jona lati lo si Ninefe lati waasu o takao ise na
patapata. O sa niwaju Oluwa (Joh 1:3,10)
o si salo si ilu Tarsisi, ilu ti o wa ni apa Gusu iwo orun spain. Nitorina Jona ko ise iranse woli re sile. Omo odun melo ni Jona ni akoko yi a ko mo,
sugbon o sese ki o ti ma duro niwaju Oluwa fun opolopo odun seyin. A ka ni pa Kaini bakanna eni ti o sa kuro
niwaju Oluwa Gen 4:16. Nitori na a le pe
Jona ni iran
Kaini tooto.
Kini didi ti jona fi mori le apa iwo oorun ni gbati ti o
ye ko lo si apa ila oorun kini idi ti Jona fi fie mi ara re wa ewu omi okun ti
awon Ju ma nyera? O fun wa ni idi to fa ti o fi wu iru iwa be, o wi pe “Nitori
emi mo pe Olorun oloore, ofe ni iwo
ati alaanu, eni ti o lora lati binu, ti o sin se ohun pupo, eni ti o kun fun ife alailegbe ti o si
nronu piwada ibi naa”. Jon 4:2 Bi Jona
ba ni idaniloju wi pe Olorun yoo pa ilu na run, laisiyemeji ni yoo fi lo si ilu
Ninefe. Sugbon Jona fe je omo Israeli toto
ju ko je onigbagbo to ngboran lo, o je eni to njowu to si nfe idalare. Kori idi ti Olorun fi so wi pe ki o lo waasu
fun awon eniyan ti won ti mura tan lati pa Israeli run. Jona jinna si iru eniyan ti Jesu soro re eni
ti o nwa alaafia awon ota re Lk 6:27
– 28.
Jona lo si Joppa olu ilu ibudoko oju
omi fun ile mimo. Nibe ni o ti rioko ti
o nlo si apa iwo
oorun. O wo inu oko oju omi yi o san owo
oko o si sokale lo sibi agbara ninu oko naa, gege bi sisera ti se farahan ninu
ago Jaeli eni buburu ni ud 4:21)
beeni Jona sun lo fonfon. O dabi eni pe eri okan Jonan a paapaa sun lo
fonfon. Jona tan ara re lati to wipe
ohun nip e jinna rere si Oluwa. Iji nla kan dide sugbon sibe
Jona sit un nsun. Jesu naa ti fi igba kan sun be ni akoko iji
sugbon ohun le se be nitori pe aye re fara pamo si owo Olorun ki se wi pe o sa
kuro lowo Olorun. Nigbati eniyan kan ba fe gbiyanju ati
bori Olorun iji kan
ma dide si.
![]() |
DRAWING II
Iji yi lagbara pupo to be ti gbogbo awon atuko fi gbadura si Olorun ti
won sugbon iji naa ko dawo duro. Awon
atuko yi ro pe orisa kan
ni o nbinu si awon. Won ji jona loju
oorun wi pe ko gbadura si Olorun tire sugbon si iyalenu Jona ko ma lolorun ti
yoo gbadura si won dibo, ibo si mu Jona pe ohun ni eni ti nyo won lenu. Won bi Jona lere nipa ilu ti o ti wa ati ise
oojo ti o n se Jona pada jewo fun won pe ohun se niwaju Oluwa ni, sugbon Jona
je enikan to ni igboya pupo o fa ara re fun awon awako ni ki won ju ohun sinu
okun ki ohun le die tutu fun Olorun ti ohun ti se. Awon awako na ju Jona sun okun loju ese ni iji
dawo duro (Jona 1:6).
Ese bibeli meji ni o so bi a se gba
Jona kuro ninu okun Jona 1:17, 2:10. Oluwa pese eja nla to gbe Jona mi, Jona si wa
ninu eja na ni osan meta, ati oni meta.
Jona leyin ti o ti ko eko ninu eja
Oluwa fun ni anfani elekeji lati lo waasu ni Ninefe ni akoko yi o gboran o si
pada di eni ti a le pe ni (missionary akoko) si awon keferi.
Bi Jona ti wo ilu Ninefe o bere si
kigbe ni ede
ilu re ni o fin so wi pe Niwoyi ogoji ojo a bi Ninefe wo 3:4. Lede Heberu oro marun pepe ni a fi nso ohun
ti Jona so yi eleyi fihan wa iru okan igbesan ti woli yi fi nkede ikilo.
Iwaasu Jona yi lagbara to be ti gbogbo
ilu Ninefe fi ronupiwada. Olorun naa
paapaa ronupiwada ibi ti o ti pinnu ti ohun o se fun won 3:5 – 10. Nigba ti Olorun pe lati mu idajo wa sori ilu
na Jona bere si binu. Nje Jona binu
nitori pea won eniyan yoo kegan re nitori asotele re ko wa si imuse? Tabi o binu nitori awon eniyan ko ni gba ni
woli tooto mo? Beeko ki se eleyi ni awon
idi ti Jona fi nbinu. Jona nbinu nitori
Oluwa ti se aanu fun Ninefe, Oluwa ti moomo da ilu na si, ilu ti o tesiwaju
lati ma gbogun ja Israeli , ti yoo si ma mu Israeli ssan isakole ti o
tobi. Jona binu nitori o je omo Israeli
oni mo tara eni nikan (selfish Israelite) ju
ati je omo Olorun tooto lo. O gbe ife Israeli leke ju ife Olorun lo, Jona gba
pe Olorun padanu anfani nla lat fi iya je Ninefe. O gba pe lai pe awon eniyan oun yoo padda di
piparun lati owo Ninefe. O san fun mi
lati ku ni ero ti Jona nroju ati gbe ninu aye ti iru Olorun yi nsakoso re. Ninu ipo aini ireti yi ni Jona jo Elija (I
Awon Oba 19:1 – 18). Sugbon iyato wa
laarin awon mejeji awon mejeji ni won ni idi ti o fi ye ki won sa, sugbon Jona
ko ni idi irufe eyi ti Elija fi sa.
Elija ja fun Ola ti o to fun Olorun sugbon eyiti o kan Jona ani Olorun ti yoo bu si ilu re.
Jona nfe ri ki a pa ilu Ninefe
run. O joke labe oorun o fe mo ohun ti yoo sele si ilu na
Olorun ba Jona wi nitori ibinu re, sugbon eleyi ko yi iwa Jona pada. Lati dabobo Jona kuro lowo ooru oorun to
gbona Olorun mu ki igi kana ohun jade pelu iyara lona aiyanu lati gba Jona lowo
oorun. Inu Jona dun pelu ohun ti Oluwa
se yi, sugbon bi Oluwa ti mu igi nah un lo mu yara mu kuro Oluwa ran kokoro kan
lati mu igi na kuro, igi na si ku, igi yi lale hun ni asale, o si parun ni
asale Jona 4:10. Nitori pe Jona padanu
igi ti o siji bo ori re Jona beresi ni binu okan re si baje gidi gidi, o si nfe
ku. Lakoko o nbinu nitori Ninefe ti
Oluwa dasi sugbon nisinsinyi o nbinu nitori igi ti Olorun ko da si. Leyin na ni Oluwa fesi Oluwa si se afiwe ilu
na pelu igi lasan be ni Oluwa ola ti Jonan fun igi lasan ati iha ti o ko si
odidi ilu Jon 4:9 – 11.
Jona je eni kan ti ife
ti o ni si Olorun ati ife
ti oni si orile ede
jo njijakadi bibu ola fun Olorun ati sise ojuse omo ilu o nta kora ninu aye
Jona. Jona beru Olorun sugbon o sa fun
ise ti a ran. Jije Olooto si ilu re ni o
fe se iku pa ife
ti o ni si awon elomiran ni ilu miran.
Jona je eni ti o ni ife
esin ti o si ni imolara fun esin sugbon ko lagbara ati se. Jna sunkun nitori Oluwa ko pa Ninefe run
nigbati won ronupiwada. E ma gbagbe pe
Jesu sokun lori Jerusalemu nitori won ko lati ronupiwada eleyi ni iyato nla ti
o wa laarin Jona ati Jesu.
AKOKO WOLI NA
Jona gbe ni akoko isejoba Jeroboamu
keji oba apa ariwa Israeli eleyi je bi odun 790 titi di 750 BC. Nigbati Jeroboamu gbaijoba agbara ijoba nab
ere si rewesi. Nitori pe lati igba aye
Jehu ni a ti fi ipa mu awon omo Israeli lati ma san isakole fun awon ara Siria. Amosa labe
isejoba Jeroboamu agbara ijoba na atijo beresi pada wa. O ko ilu Hamati ati Damasku ni igbekun o si
da gbogbo agbegbe Israeli fun won lati Hamati titi ti o fi de okun oku 2 Awon
Oba 14:25 nitooto Jeroboamu ni oba ti o lagbara ju laarin awon oba ti o joko
lori ite samaria ojo iwaju ijoba na si ni ireti pupo.
Ni ilu Assria ni oro miran ipo ti ilu
na wa lapapo je odi keji ohun gbogbo lomu irewesi baa won eniyan. Assria n reyin si lojoojumo Israeli ndi
alagbara si Assria ndi alailera. Akoko
to da ti Oba Adadnarri kerin IV to fi sakoso ni odun 873 – 810 o sese wa si
ipari ni. Ni akoko ijoba yi o se ayewo
alaini lo si ilu Palesitini ati awon ile miran ni apa iwo oorun.
O ti gba isakole lowo awon ara Hitti, Tire, Sidoni ti se ilu Omri apa
ariwa Israeli, Edomu ati Filistia.
Nipase awon isegun re ni oba yi so ara re di okan lara awon oba Assria
ti o lagbara julo. Ko si Oba Assria kankan ti o je siwaju Oba
ayi ti o se akoso lori agbegbe ti o to eleyi.
Ko si awon to ni awon ilu to nsan isakole to oba yi. Adadnariri yi ni igbagbo ninu esin sinsin
Olorun kan
soso. Ninu akosile kan ti o fi sile ni a ti ka pe “Fi igbekele
re sinu Nebo ma fi sinu orisa miran.
Adadnariri yi je Oba Ninefe ti o ki Jona kaabo nigba ti o wa waasu. Amosa o sese ki Oba Adadnariri yi ti ku ni
akoko ti Jona wa si Ninefe ti ipeyinda ilu Assria si ti bere. Leyin isakoso Oba yi ina Assria bere si jo
ajoreyin ifaseyin ba won titi ti won fi rewesi koja ohun ti won lero lo. Irewesi yi omu ki Jona fe, ki ilu Assria o di
alailera si.
Amosa isoro kan dide nihinyi ni akoko yi gan titi di
odun 507 BC ilu calah
ni o je olu ilu Assria. O sese ki a le
salaye isoro ti o fi ara han yi nigba ti a bar anti wi pe Calah ati Ninefe je
ilu ti won fi ogun mile jinna si ara won.
Ninefe je ilu atijo ti a ti owo Nimrodu da sile Gen:11.
Akiyesi: Jona yi ni omo opo sarefati ti Elija
so di alaaye. Jona yi ni Elija ran lati
yan Jehu loba.
MIKA – WOLI AWON TALAKA
ORUKO RE
Mika je eni kefa laarin awon woli kekeke oruko
mika je ijewo igbagbo. Oruko Mka wa lati
inu ede Heberu
ti a npe ni “Mikayahu”a ti o tumo sit a lo dabi Olorun Mika 1:1, 7, 8 Jere
26:18, Oruko Mika dabi oruko Michael ti o tumo sit a lo dabi Olorun. Oruko yi farahan pupo ninu iwe mimo. Die lara awon to nje Mika ninu iwe mimo ni
wonyi.
1.
Ara Efraimu kan
eni to subu sinu pansaga ti o si gba omo lefi kan lati je Alufa ohun ti awon ara Dani si
ji orisa re lo onidaj. 17, 18.
2.
Mika eni ti se ara eya Reubeni – I Kro 5:5
3.
Omo Meriba – I Kro 8:34 – 35
4.
Lefi kan
lati inu Ebi Asafu – I Kro 9:15
5.
Lefi kan
lati inu ebi Kohati – I Kro 23:20
6.
Baba Abidoni 2 Kro 34:20
7.
Mika eni kefa laarin awon woli kekeke ara ilu
Moresetigati apa iwo
oorun Jerusalemu.
ILU RE
A pe
Mika ni ara morasti nitori pe abi ni ilu moresetigati (ese 14) lati ilu Gati ni
a ti nsakoso ilu yi ilu na wa ni bi ogun mile apa Gusu iwo oorun
Jerusalemu. Gege bi Amosi Mika yin a je
omo oko. Ijosin tooto ati esin tooto ma
nwa ni oko ju igbooro lo nitori na ni Mika ko se ni fe Pataki si igboro.
![]() |
Mika so asotele ni ojo Jotamu, Ahasi ati
Hezekiah awon Oba Juda. A ri arigbamu
akoko yi ninu iwe yi ati wi pe a fie se re mule ninu Jeremiah 26:18 eyi ti o ya
iwe Mika 3:12 lo. Mika nitorina je akegbe kekere si Isaiah o ti
waasu siwaju ati leyin isubu Samaria (722BC) o sese ki
akoko to waasu yi je bi odun 735 – 715.
Awon ojogbon kan so wi pe o waasu ju
ogoji odun lo.
Labe
oba Jotamu orile ede
na ngbe labe
oro to po. O ko ilu ibi aabo ati awon
aafin ni Jerusalemu opolopo awon talaka ni emi won sofo ninu ise ile kiko ti
Jotamu gbe kale yi. Labe Ahasi Juda nsan
isakole fun awon ara Assria. Ohun ti
ogun jija laarin siria ati Efraimu nna won ni odun 734 oga pupo. Gbogbo nnkan yi ni o sele si talaka ati olowo
bakanna.
Awon oni wobia arije ni modaru
larinlodu won lo agbara won lati pon talaka loju won gba ohun won lo won si le
awon opo kuro ninu awon ile won. Gbogbo
irufe awon aisododo wonyi ni o wa ni ile na ti awon olowo si nje talaka
run. Hezekiah oba gbiyanju lati se
atunse si ipo buburu yi, sugbon ni akoko isejoba tire nnkan bubu jai. Awib eniyan dekun ati ni igbekele ninu ara
won. Jerusalemu pada di ilu oloselu to
buru. Awon onimoran ni okan won o so kan ninu igbimo
won. Awon kan gba oba ni moran lati
towo to iwe adehun pelu Egipiti ki won jo le gbogun ti Assria, awon miran si
gba oba ni imoran ki won jowo ara won fun awon ara Assria lero. Awon ti won nbojuto ofin won si gbara lo,
Awon olola nre awon ti ko rowo hori je, awon adajo ngba riba; awon woli nso
tele lati tea won olowo lorun; awon alufa nkoni fun owo oya (Mika 2). Ni ibi gbogbo ni ese ipongbe fun iloro
wa. Awon olowo ti won je oga ni ilu won
a ma fi idajo se eleya. Eto ati esin ni
won gbe ju si egbe kan
ki awon okowo ati ona ti a ngba rowo ma se ni idiwo kankan.
IWAASU
MIKA
Iwaasu Mika fi okunkun eyi ti Isaiah tele, awon mejeji gbe ni akoko kan na, Isaiah je woli
awon to wa ni ipo to ga, Mika je eniyan pele to wa lati abule. Isaiah je alagba to lenu ni ilu, Mika je
Ajinhinrere ati akeko igbe aye awon eniyan.
Ohun to kan Isaiah ni igba tire ni wahala oselu ni akoko na sugbon Mika
ni tire o ti o kan ni oro esin olukuluku eniyan ohun to to ati eyi ti ko to
lawuju. Mika je eni to wopo ju Isaiah
lo, Mika ko so ara re po mo awon eniyan lasan.
Isaiah koni wi pe a ko ni bori Sioni, Mika ko ni wi pe a o pa Sioni run
Mika 3:12. Awon ti o wa ni ipo giga ni won ni erongba to
yato nipa Olorun won nro pe nitori won je eni aponle lawujo ko si idajo kan to
le wa sori awon Mika 3:11. Nitori idi
eyi ni Mika se ro wipe esin tooto ati igbe aye omoluabi ni o gbodo ri ibi ti o
dara duro si ninu aye gbogbo awon iwaasu re ni awon oro wonyi awon ti won ngbe
igbe aye iloro ati imotara eni nikan ni won je amu je eje talaka ni iwaju
Oluwa. Oluwa ki yoo tewo gba ebo iyebiye
won.
ALAYE
LORI IWE MIKA
Awon ohun elo ti a lo ninu Mika
ni a pin si awon ona wonyi.
a.
Ori
kinni si ori keta – idajo
b.
Ori
kerin ati ikarun – itunu
d. Ori kefa ati ikeje – Ona
igbala
Pelu awon ipin meta yi eniyan lo wa iwaasu to danmoran
lode oni.
(1) Ori kinni si ori keta -
Awon ese yi nsoro nipa ibaniwi to le ati iparun to lagbara
lori Juda. Won kun fun ibaniwi ati ipeni
si akiyesi fun awon oloye ninu ijo ati orile ede. A
to idajo jo bi okiti ogan ati opo iderubani titi ti awon eniyan ko fi fe gbo
oro na mo ti won si kigbe wi pe ki woli na dake Mika 2:6. Mika ni eni akoko laarin awon woli ti o koko
deruba Jerusalemu pelu iparun. Mika
3:12. Mika ma nse iyato amosa laarin
orile-ede Juda ati ilu Jerusalemu. A o
pa ilu yi run sugbon ase ileri ibupada bo sip o fun orile ede na.
2. Ori kerin ati ori karun -
Ni abala yi ni Mika ti se afihan ofefe/itansan ogo ti
nbo wa. Oluwa se ileri igbala fun won
ninu ileri igbala yi ni ireti fun messiah wa ati ireti ogo ni opin aye. Mika woe yin wo ati bakanna o tun wo
iwaju. Iran re fun ojo iwaju lo ni se pelu
awon isele to nse ni ayika re. Irufe
awon isele yi ti sele ni awon akoko kan
seyin ninu itan. Ninu idande Juda to nbo
wa Mika ri isegun ojo iwaaju nipase ododo.
Bi o se nronu nipa ojo iwaju ti o nduro de Israeli aworan orisi ogo meji
ni o wa sokan re. Aworan na ni igbega ti
o de ba Sioni ati ibi messiah ni Betlehemu.
a.
Ori
kerin ese kinni si ikarun se afihan Sioni fun wa ti o pada ri aarin gbungbun
ilu temi tun gbogbo aye. Isa 2:2 –
4. Mika ri awon arinrin ajo ti won nwa
lati gbogbo orile ede
agbaye lati fi di ijosin agbaye mule lati owo isejoba Olorun Israeli. Ninu ijosin yi won yoo tewo gba ofin Oluwa
gege bi ilana fun ijoba alaafia gbogbo gbo.
Israeli yoo je eni ti o ga julo nipa esin ati wi pe akoko ogo nla ti won
ti nduro de yoo pad ate won lowo.
b.
Ori
karun ese keji siwaju – eleyi kun fun asotele ni pa Messiah ti o wi pe a o bi
Messiah ni Bethlehem
gege bi ti Dafidi. Isaiah ti so asotele
nipa ibi wundia ti Messiah yi Isa 7:14. Mika sotele nipa ilu ti a o ti bi leyin (700
yrs) ni akoko isejoba Herodu nla ni awon amoye lati ila orun wa ti won wa
Kristi omo na eyi ti irawo re ti won ri si to won debe. Pelu iranwo awon olukoni Ju ti won npa ni
Rabi won tesiwaju lati gba ohun gbogbo ti won nilo fun irinajo won – Mt 2:1 –
6.
3.
Ori kefa ati ori kejie
Abala yi ni a le pe ni ariyanjiyan ti Olorun. O je iforo wero, ajosopo laarin Olorun ati
awon eniyan re. Ninu iforowero yi Olorun
da ara re lare nipa awon ona ti o ti dari Juda.
Awon eniyan ro pe Olorun je eni to le, oga ti ma nlo ni lowo gba, gege
bi awon Larilord ti won ti mo tele. Won
fe mo nitori na ohun ti Olorun nfe lowo won.
Nipase ona ika ati ilana ti ko to ni won gba lati te Olorun lorun tele
ki won si mu ibinu Olorun kuro lodo won.
Won ti fi eso ago ara won ru ebo
fun ese okan won – Mika 6:7.
Olorun fesi si won ti o si
se agbeyewo awon oro nla nla ti a ti so ninu majemu laelae – 6:8, 10, 15 – 16,
7:4, 8 – 9.
KOSEMANI
META TI MIKA GBE KALE LATI LE JE OMO OLORUN
(1) Lati se
ododo - Ododo ninu bibeli ohun ni agba
si ohun Pataki ti eniyan ti le se ife
Olorun. O je ipile ihuwasi rere o je
okan eniyan rere o si je ihuwasi ti Olorun ni fe si – Mt 7:12.
(2) Lati fe
isoore (okan ikanu ati anu) – ede Heberu ti Mika lo fun isoore yi ni a pe ni
“hesed” e o ranti wipe isoore ni oro ti Hosea feran ju, isoore je ohun ti o ga
ti o si lola ju idajo ododo lo. Opolopo
eniyan lo je olododo sugbon ti won ki fi be soore nigba gbogbo. Isoore lo fi idi re mule wi pe idajo ododo
yoo waye tabi a o fi idajo mule.
(3) Lati rin
ni rele – Amuye eleketa ni yoo je ki o se se fun eniyan lati se meji ti akoko,
eniyan ko le je olododo ki o si feran isoore ti ko ba je oni rele okan.
Lati rin ni irele okan o tumo si jijowo ara wa fun Oluwa, o
tumo si titeri ara wa be gege niwaju Olorun gege bi omode. Iwa irele ni oso ti o tobi ju fun esin.
NAHUMU
– WOLI ELEWI
ORUKO
RE
A o mo ohun to po nipa Nahumu ayafi oruko
re. Oruko re yi ko farahan nib o miran
ninu bibeli gege bi awon woli miran gbogbo Nahumu fere kere ju ohun lo. Amosa oruko ni itumo nitori o tumo si
olutunu.
ILU NAHUMU
Ase afihan woli yi Nahumu ara Elkosi.
Eleyi nso nipa ilu ti a ti bi woli yi.
Bakanna ni a ka nipa Elija ara Tisbi.
Awon Septuagint so wi pe Nahumu yi ara Elkosi ni orisi iwoye merin ni o
wa nipa ilu ti a ti bi Nahumu yi.
1. Al-kush,
ilu yi je abule toto 24
miles si apa ariwa mosul
ti o sunmo ilu Ninefe. Won so wi pe
iboji Nahumu wa ni ilu yi ti awon Musulumi ati onigbagbo ma ntoka si paapaa
awon Ju agbegbe na.
2. Ain-Japhata
– ilu yi je ilu kekere ni apa Gusu Babiloni ni Odun 1165AD ni won so wi pe won
tun kefin iboji ni ilu yi.
3. El-kauze
– ilu yi je ilu kekere ni apa ariwa Galili amosa awon miran kapenamu ni Galili
ni ilu woli yi. Won ro wi pe oro ti a pe
ni kapernaumu o wa lati inu oro ti a pe ni Kefr-Nahumu o tumo si ilu Nahumu ni ede Arabic – Jh 7:52.
4. El-ikese
– Ilu yi ni o to ogun mile si apa Gusu iwo
oorun Jerusalemu a npe ilu yi niisinsinyi ni Beit – Jibrin ilu yi wa ni
agbegbe eya Simoni opo awon onigbagbo ati awon Septuagint ni won gbagbo pe ilu
yi ni ilu Nahumu.
AKOKO
NAHUMU
A mo lekun rere akoko ti Nahumu gbe ati igba ti o so asotele. Nah 3:8 – 10 soro nipa isubu Thebes ni apa oke Egipiti. Ati ko ilu yi ni igbekun tele, isubu Ninefe
si ku si deedee. Oba Assurbanipal ni o
ko ilu Thebes ni igbekun 663BC ati wi pe Nabokolasari ni o ko ilu Ninefe ni
gbekun ni odun 612BC o sese ki Nahumu so asotele rre ni arin akoko mejeji yi.
Assurbanipal je oba to buru. Ninu
akosile ti a sawari a ma sogo ninu awon iwa ipa re ati awon iwa itiju ti o
nhu. Oba yi a ma jai san eyin ese awon
oba a si ma ge ete won. Ni igba kan o fi tipatipa mu
awon ijoye Elamu ti o ti ko ni igbekun lati ma ti keke ogun re la ilu ja, o si
fi agbara mu awon ijoye ilu na o si fi agbara mu won wo akoto o ri oba si ori
won. Ni igba kan Assurbanipal oba yi nje ase pelu awon
iyawo rre ni agbala nibi ti o ti so ori oba Kaldea ro si eni ti o fi tipatipa
mu wi pe ki won o pokun so. Ko si Oba
igbani kan ti
o sogo lori iwa buburu ati iwa eranko bi ti oba yi. Bi o ti gbe igbese si one Egipiti ninu
irinajo sise amin re oba mejilelogun (22) ni o wa pade re ti won si nteriba
fun. Ni kete ti o gunle si ilu Egipit ilu
menfis ti o je olu ilu isale Egipit ati ilu Thebes ti o je olu-ilu oke Egipiti ni won ko
ni igbekun kuro lowo oba Tirkahah ti won sip on won loju gidigidi.
Awon eniyan Juda ati Jerusalemu, ti won ngbe laarin Assria ati Egipit ni
won fi oju ri ti eti won si gbo iwa buburu ti oba yi hun nitooto fun opolopo
iran ni awon ara Assria wa nwa nko Palestine ni igbekun leralera. Shalmanezer II ko won ni gbekun ni odun
842BC. Tiglathpilesar III ko won ni igbekun ni odun 734BC.
Shalmanezer IV ati Sargon II won ko won ni gbekun ni odun 724 – 722BC
ati Sennacherib won ko won ni gbekun ni odun 701BC. Esarhaddoni ko won ni gbekun ni odun 672BC,
ati nisinsinyi oba Assurbanipal. Ninu
oba Assurbanipal ni ohun ti o buruju ti sele.
Juda dabi alailera lowo agbara ota won to buru, abala to gbehin ni ori
kinni ese kedogun ati ese meji to si ori keji ntoka si bi ilu na ti se jiya
pupopupo to lowo awon ara Siria. Ninefe
ti o je olu ilu fun awon ara Assiria ni won si wa ni ipele ogo won to ga ni
akoko na Chap 3:16 – 17 Woli yi ri wi pe isubu awon ara Assria oni pe de
biotilejepe awon eniyan miran ko ri.
Nitori isele ayika yi ise
iranse Nahumu nsense ko wa ye ni odun 650BC.
NINEFE
Ilu Ninefe ni o wa ni apa ila orun Tigris ni odikeji ilu igbalode ni ti a
npe ni mosun. Nimrodu ti ilu Babiloni ni
o da ilu na sile Gen 10:11
ati wi pe sinsin orisa obinrin ti won npe ni Histani o wopo ni ilu na. Ilu Ninefe je olu ilu awon Oba Assria lati
odun 1100 titi di 880 BC ati bakanna leyin ti Senakerubu di oba ni odun 705BC. Nitooto ilu Ninfe je olu ilu fun ijoba na, o
je ilu Pataki ilu ti o lagbara t a si fi odi yika asi gbe ogbun yika ki o to kan odi awon ibi isadi
ati ile iso ni won nbe lori odi ila na.
Awon odi ilu yi won gun to mile 7 ½ feet yi ilu na ka won si fe pupopupo
ti keke elesin meta le sare ni egbe ko egbe lori odi naa. Bi ilu Ninefe se ri niyi ti se olu ilu fun
ilu ti o kun fun ese ati iwa ipa ati orile ede to lagbara ju ti o ti farahan lori ile
aye. Awon omo ogun won, won je akose
mose lodi
diduro ti ilu, to won si fi igba gbo gbogbo kigbe idoti ! idoti !! idoti
!!!. Sugbon Nahumu wi pe gbogbo oludoti
ni ni agbaye ni a pada doti – Nah 3:1 – 6
Awon asotele Nahumu yi ni o wa si imuse ni awon ona ti a o le
gbagbe. Esahaddoni ni Oba Ninefe ti o je
gbeyin awon ara Medes ati ara Babiloni ni won koko ba gbogbo awon ibi isadi ti
o yi ilu na ka je. Leyin na wo dojuko
ilu yi won si doti won si ko gbogbo orisa won danu – Joba 3:15, sugbon gbogbo re bo si asan ilu Ninefe
subu.
Awon alase igbani kan
salaye bi idoti na ti se waye ni asale ojo ti isubu won sele ati bi won ti se
lo ale ti o seku ninu ita gbongbon imuti para – Nah 1:10, 2:5.
Ni akoko yi ni oba alilera yi fi apeere lele. Ni asale na odo tigris kun koja eti bebe re o
si ya awon odi ilu naa lule. Lati ipase
awon ona ti o si sile yi ni awon ota gba wole si ilu na lara. Ni gba ti oba yi rip e ohun ti padan ohun
gbogbo o ti ina bo ara re ninu afin rer o si jo ara re mole (Chap 3:3 –
19). Gbogbo oro ilu yi ni awon to segun
ilu yi ko lo (Chap 2:10 –
12) ilu yi subu ni odun 611BC iparun Ninefe pari.
AWON
OHUN TI O WA NINU IWE NA
Awon asotele
ti o wa aninu iwe Nahumu fun ara re pin si ipin nla meta.
1.
Ori
kini – Orin isegun lori isubu Ninefe ti
o nbo wa
2.
Ori
Keji – Idajo to nbo sori ilu na aiwulo aabo re
3.
Ori
keta – Ebi ilu naa: Iwai pa re, Iwa
wobia re, Iwa eke ati ayineke re, iwa pansage ati iwa ika re.
Nahumu wi pe Ninefe yoo subu patapata isubu re yoo je ekun rere awon
orile ede
gbogbo yo yo lori isubu re. Ko ni si eni
ti yoo seku lati tu ninu.
IWAASU
NAHUMU
Nahumu salye gbogbo iwaasu re ni ori
kinni ese keje si ikesan 1:7 – 9, Nahumu je eni ti o ni iwa kan, iwa ti o ni yi ti o nfarahan ni iparun
ti yoo wa sori Ninefe. Nahumu ni
idaniloju pe bi Olorun tile lora lati binu lai pe yoo pada gbesan lara awon ota
re, Nahumu teju idajo Olorun mo Ninefe, o si nkorin isinku si awon aninilara to
ga ju lagbaye. Idajo Ninefe je eyi ti
won tai nduro de tip e sugbon o je idajo to daju yoo je ekunrere yoo si je
opin.
AWON
EKO TA RI KO NINU IWE NAHAMU
1.
Idajo
Olorun ti gbogbo gbo lori eniyan ati orile ede
2.
Idajo
ododo nbe ninu ijoba ti Olorun
3.
Idajo
Olorun je amugbalegbe pelu ife
Olorun
4.
Idajo
Olorun je eyi ti eniyan ko le sala labe
re
5.
Ofin
atoke wa wa fun idajo ododo
6.
Bi
ese ba ti loyin yoo bi iku
7.
Idajo
Olorun le fani le sugbon o daju.
8.
Oluwa
ki yoo da eniyan buburu sile ki o lo lofe.
9.
Olorun
yoo gbesan lara gbogbo awon ota re
10.
Olorun
je alagbara rere ni Oluwa sugbon Olorun njowu.
HABAKkUKU – WOLI ALAROJINLE
ORUKO ATI IGBE AYE RE
A o mo ohun to po nipa Habakuku yato
si iwe re ti o n je oruko re. Oruko
Habakuku yi wa lati inu oro ti a pe ni “Habhak” eyi ti o tumo si lati ko ni
mora tabi ikoni mora. Eleyi ntoka si
ijijakadi pelu Olorun tabi eni ti Olorun feran tabi ki o je wi pe Habakuku je
Olutunu fun awon eniyan re. Martin
Luther so wi pe Habakuku ni eto ati oruko ti o to fun ipo woli re nitori oruko
re turmo si eni ti o nruni soke tabi eni ti nfi ni si okan, eni to nsoro jeje
si omo to nsokun to si mu eru okan omo na lo.
Nitori awon idi wonyi ao tile mo boya oruko Hababuku ni oruko ti woli yi
nje gan tabi a kan fun ni oruko yi nitori asotele ti o so fun Israeli.
Gege bi Haggai ati Sekariah a pe ohun
na ni woli na Hab 1:1 eleyi toka sipe Habakuku je eni ti o wa lati Juda ti
gbogbo oju si mo ni Jerusalemu, nitori na ni o se faramo agbegbe ati ipo ti
oselu won wa Hab 1:3 -4 ni gbogbo ona a ni idi rere ti a fi gbodo gba pe
Habakuku je okan lara awon Okunrin alagbara ni akoko re. Osese ko je okan lara omo leyin Isaiah woli
– Isa 8:16. Habakuku je alarojinle to ni ominira o ma
nmu awon eniyan bere ibere esin nitori idi eyi opo ni won ti ni iyemeji lori
oro esin. Amosa Habakuku je eni ti o
le ni igbagbo o je iru okunrin ti Olorun lo lati bere akoko iwulo titun fun ijo
re. Awon kan gba pe Habakuku ni oluso ti a soro re
ninu Isa 21:6 eni ti a ran lati wa bere fun ami isubu Babiloni. Awon miran gba pe ohun ni omo obinrin Sunemu
ti eni ti Elisa ji dide 2 Awon Oba 4:36
– 37. Ko si ohun ti a le se ju ki a kan mo daba eni ti
Habakuku nse lo. Sugbon a mo pe
alarojinle eniyan ni eni idurosinsin ti ki gbojege. A le pe ni eni to ni ilana igba aye to ni ona
to ngba ronu to sin se agbekale ironu re ni ona ti lagbara. O ni emi irele o mo bi a ti gbadura gidigidi
ti a si fie be wa ranse si Olorun, o si gbagbo gidigidi ninu ilana isakoso ti
eko ti Olorun.
ERONGBA WOLI YI
Erongba kan soso ti woli yi ni ni lati sotele nipa
isubu awon ara Kaldea to nbo wa (Babiloni) ati nipa sise eyi ki o le ru okan
awon ara Juda soke ni akoko aini won.
Asi iwe yi pelu apele to se akawe ihuwasi iwe na. A pe iwe rre ni oro Olorun tabi oro imo ti
yoo se afihan awon nnkan to farasin lati ipase woli na.
AKOKO WOLI YI
Akoko asotele woli Habakuku da lori
akoko ti awon ara Kaldea bere si segun aye to yi won ka. Ni gba wo ni won bere si jade fun isegun yi?
Ori kini ese kefa so wi pe mo nru awon ara Kaldea soke” eleyi ni o ntoka si
ibere isegun awon ara Kaldea ko si itokasi kankan ninu iwe yip e awon ota ti bere si
dasi igba aye awon Juda. Opo awon alase
n won gba pe ako iwe Habakuku ni odun 604 tabi 603BC. E ma gbagbe pe Ninefe ti subu ni odun
612BC. Nebukadnessari sese bere ipolongo
isegun re lo si apa iwo
orun Asia.
Ni ilu Carchemish
o segun farao-necho ti egipiti ni odun 605BC isegun yi tumo si iyipada nla ninu
itan akoko na. Laarin odun 608 ati 605BC
Egipit ti yo Juda lenu pupopupo.
Nisinsinyi awon ara Kaldea ti mu Egipiti teriba won ti segun won won ko
ni le dide si ipo giga mo.
ALAYE ATI OHUN TI O WA NINU IWE NA
A si iwe yi pelu ajoso oro pelu Olorun
ati woli na. Leyin na won tesiwaju lati
kede awon egbe lodi
si awon ara Kaldea. Iwe na pari pelu ewi
to rewa nipa igboya pe Olorun yo gba awon eniyan re la. A le pin gbogbo iwe yi si abala mefa otooto
1. Awawo woli na – Hab 1:2 – 4
Habakuku bere asotele re pelu igbe fun ipo ruru okan “Oluwa yo tip e to
ti iwo yoo fi
ma kigbe ti iwo
ki yoo gbo?” Woli yi ko ni oye idi ti
Olorun fi fi aye gba ibi ki o sele
2. Idahun Olorun Hab1:5 -11
Olorun so fun Habakuku pee mi nse ise kan ni ojo yin” vs 5
ise ti Oluwa ni oun se yi je ise ti o le fun Israeli: Oluwa ngbe awon ara Kaldea
dide lati fi iya je awon eniyan re vs 5 – 11 ni o salaye iwa ati isegun awon
ara Kaldea a pe won ni orile ede to koro ti o si yara ti won si nyan la ti bu
toro aye ja. Won buru won si kun fun eru
won a ma ko ikogun jo bi igba ko iyanrin jo.
3. Isoro Woli yi Hab 1:12 – 2:1
Idahun Olorun o mu igbagbo woli yi le si sugbon o tun dakun
isoro okan re, eto Olorun da lokan ru.
Kini idi ti Olorun yoo lo awon ota to je elese lati fiya je Juda Israeli
ko wa se olododo ju awon ara Kaldea lo bi?
Bawo ni Olorun eni ti o ni oju ti o mole gara ju ati wo iwa ibi yoo ti
se fi aye gba awon alaini gbagbo ara Kaldea lati gbe awon eniyan yi mi? Bawo ni Olorun to mo yo se lo eni ika ara
Kaldea? Se ijoba atoke wa nbe sa? Awon nnkan wonyi ni isoro Habakuku. Bawo ni eniyan buburu yoo se ma lagbara si ti
awon Olododo yo di eni itemole? Habakuku
ri idahun si isoro re yi nigba ti o di eni igbagba. Biotileje wipe ori aye ninu iparun ni ayika
re sibe o ni itunu ninu igbekele ninu agbara Olorun Hab 2:1.
4. Idahun Olorun To Kehin
Ori oke ile iso eyi ti Habakuku gbe ara re ka je ile iso
igbagbo. Ninu ile iso yi ni o ti nduro
de idahun Olorun. Ko nilo ko duro pe
titi ti idahun yo fi de. Olorun ba soro
nipase iran. O gbodo ko iran na sori waala ki o han ni ona
ti o danmoran ki eni ti o nka o le ma sare lati so idahun. Olorun so fun Habakuku pe bi iran na tile
pe, ki o duro de, ni dide yoo de ki yio sip e mo.
Leyin o reyin o ri idahun si isoro re ti o
tobi. O han pe onigberaga ati eni ti
nfiya jeni ko le pe titi. Olododo yoo
segun ti o ba tesiwaju lati gbekele Olorun.
5. Orisi awon Egbe marun Chap 2:6 - 20
Ninu awon ese wonyi a ri wi pe opolopo awon orile ede ni awon ara Kaldea ti
segun won gbohun won soke lati bu enu ate awon to ni won lara. Ni hin yi ni Habakuku ti soro ni ipo awon
orile-ede ti won ti segun won. O soro
gege bi Nahaumu ti soro lodi
si Ninefe, o gba pe eni ti o ba fi ida pani ohun na yoo ti ipa ida segbe. O gba pe ifiyajeni ni o ma ndarisi ipokunso,
pea won ara Kaldea won je odaran ati wi pe aisi idajo ododo won o mu aye won
jera. Awon egbe ti Habakuku kede le won
lori ni wonyi.
1.
Egbe ni fun eni ti o mu ohun ti ki se tire po si,
yoo tip e to? Ati fun eni ti ndi eru ilori lowo gba ru ara rre vs 6 – 8.
2.
Egbe ni fun eni ti nje ere ijekuje si ile re, ki o
le bag be ite re ka ibi giga, ki a le ba gba sile lowo ibi e:9 – 11
3.
Egbe ni fun eni ti o nfi eje bo ilu ti o si nfi
aisedede te ilu nla do 2;12 – 14.
4.
Egbe ni fun eni ti nfi ohun mimu fun aladugbo re ti
o si nfi oti lile re fun ki o ba le mu amupara pelu ki iwo bale wo ihoho won –
2:15 – 17.
5.
Egbe ni fun eni ti o wi fun igi pe, ji, fun okuta ti
o yadi pe, dide, oun o ko ni! Kiyesi wura ati fadaka ni a o fib o yika ki yoo
si yoo si eemi kan
ninu re.
AWON EKO TI A RI KO
1.
Otito ijiya atoke wa
2.
Otito nipe eniyan buburu yoo pa ara rre
3.
Otito nipe nipa igbagbo nikan ni ale ye.
Ni ipari eko Pataki ti Habakuku ko wa ti a
gbodo daruko nip e, a ni lo imulokanle ni akoko idarudapo 3:17 – 19.
Eni ti o ba ka Habakuku
daradara yoo ni imolara pea won olukawe re ni imulokanle ki won si ni ayo ninu
ipo kipo. Habakuku nfe ki eniyan gbe
okan re soke si Olorun nitori ni be ni won yoo ni alaafia. Nigba ti eniyan bay a ara re kuro ninu ohun
ini ti o wa lode o gbodo gbekele Olorun nikan ki o si ni igboya ninu
Olorun. Iru ayo igboya ni Habakuku fun
ara ni nitori naa ni o sele fi ko elomiran.
SEFANIAH – WOLI ALASODUN
ITAN IGBE AYE RE
Yato si woli yi ti ankeko
nipa re awon Sefaniah meji tun wa ti a tun daruko re ninu majemu laelae. Okan lara won je eya Kohati lati inu eya
Lefi; o je baba nla fun Hemani akorin – I Kro 6:36, Sefaniah keji je alufa eni
ti o gbe ni akoko Jeremiah ti osi nfe ki Israeli ndore pelu Egpiti – 2 Awon Oba
25:18 Jer 21:1, Jer 37:3. Ni ede Heberu oruko Sefaniah
turmo si eni ti Olorun ndabobo Ps 27:5.
Itumo yi ni o ye fun iwaasu woli yi.
Gege bi o ti sele ninu iwe
Isaiah, Jeremiah, Joeli ati Sekariah a ri itan iran Sefaniah ni ibeere iwe
re. Ninu iwe Sefaniah atenumo itan iran re ju bi a
ti so nipa awon woli yoku lo. Idi nipe o
sese ki Sefaniah yi je omo omo omo Hezekiah oba.
Sefaniah yi dabi eni ti o
gbe ni Jerusalemu eleyi dabi eni ti o ntoka si ona ti yoo gba soro nipa enu ona
eja (Bode eja) ati hihu lati iha keji wa, ati iron la lati oke kekeke won-on-ni
wa. Sef 1:10 – 11, ti o se
afihan pe Sefaniah je, eni ti o sunmo ilu Juda.
AKOKO SEFANIAH
Ese ti o si iwe Sefaniah
ni o kede re pe Sefaniah so asotele ni ojo Josiah, eleyi ntoka sip e Sefaniah
ko iwe ni arin odun 639 – 608BC, gbogbo ohun ti o wa ninu iwe yi ni o faramo
akoko yi.
Ninu iwe yi woli yi benu
atelu awon eniyan Israeli fun igbe aye iborisa won, iwa ibaje, fun iwa ipa ati
asi idajo ododo eyi ti won jebi re. Sibe
o dabi eni pe Sefaniah ko soro lodi
si iwa buburu kan
pato. O nfe ki iwe re o je iwe ti o ba
gbogbo eniyan soro ni akoko gbogbo ati nibi gbogbo. Nitorina ko baa won eniyan akoko kankan tabi awon eniyan
ibi kan
soro. Awon isele ti o nkoja lo dabi eni
wi pe ko kan
woli yi. Sefaniah je woli fun gbogbo
awujo.
AWON OHUN TI O WA NINU IWE NAA
Akori nla fun awon asotele
Sefaniah ni “Ojo Oluwa” ti o nbo wa. Ase
agbeyewo koko eko yi ni ipele meta.
1.
Ideruba ati idajo Sef 1 abala yi ni o kede pelu
idalebi ati ideruba ojo ibinu Oluwa ti o nbo wa. Ibinu yi yoo wa si ori gbogbo aye, sugbon yoo
wa taara lodi
si awon aborisa ati awon to subu kuro lodo Olorun ni Jerusalemu ati ni Juda.
2.
Ikilo ati igbaniyanju Sef 2, a fi ise yi ranse si awon
orile-ede to yi Israeli ka: Filistia, Moabu, Amoni, Ethopia, Assria.
Leyin eleyin ni woli yi rawo
ebe si Jerusalemu ki won o ronupiwada ki won le bo lowo iparun to nbo wa Sef
3:1 – 7.
3.
Igbani niyanju ati ileri Sef 3:8 – 20 a se ileri igbala fun awon
ti o ronupiwada paapaa julo fun “awon ti o seku ni Israeli”. Awon wonyi ni yoo di eni ti gbogbo aye yoo mo
gege bi eni irapada Oluwa ti yoo ma gbe niwaju Oluwa titi lai.
AKORI IWE SEFANIAH
Akori
nla ati akori kan
soso ti iwe Sefaniah ni ni ojo Oluwa ti nbo wa, ni Ojo na Oluwa yoo se afihan
ara rre ni ekunrere si gbogbo agbaye.
Yoo se idajo awon a sebi yoo si pari ise irapada re laarin awon eniyan.
ISOWO KOWO SEFANIAH
Isowo
kowo Sefaniah ni lati kowe re ni ede
to lagbara. Iwa pele ati iwa rere ni ko
tayo ninu ikowe re sugbon ipa ati okun ti o fi soro lofi idi iwa rere mule ni
ko tayo ninu ikowe re sugbon ipa ati okun ti o fi soro lofi idi iwa rere mule
ko si woli kan ti o soro daradara nipa ojo Oluwa bi Sefaniah. Ara ojo ibinu Oluwa ti o nbo wa ni o yi jade
pelu agbara Oluwa nipase iwe yi to be ti awon atumo ko le tu lekunrere si ede miran.
Ni
ipari Sefaniah se afihan ero tuntun ti o kere die ju ti awon woli yoku lo. Isowokowe re dabi ti Isaiah. O mo bi a ti n so atunso oro ati ifaara pelu
opolo pipe lati fi okun kun oro ti o nso.
Lara awon oro re ti o la ipa ni wonyi.
“Emi yoo fi fitila wa Jerusalemu kakiri” Sef 1:12 won o ma rin bi afoju” 1:17 “Ho orile ede ti ko ni itiju” 2:1. Awon kan
wi pe bi eniyan ba fe ri oro woli ni erefe je ki o ka iwe Sefaniah.
HAGGAI – WOLI OLUKO TEMPILI
ITAN IGBE AYE RE
Die
lamo nipa itan igbe aye Haggai yato sip e ohun ni woli akoko laarin awon igbeku
ju ti won pada bo lati Babiloni si Jerusalemu 536BC. Ninu iwe re ati ninu Ezra 5:1 ase afihan rre
gege bi Haggai woli na. O sese ki Hag
2:3 toka sip e Haggai je agbalagba nigba ti o so asotele re. Biotiwu ki o ri o dabi pe Haggai dagba ju Sekariah
lo, nitori pe nigba ti oruko won ba farahan papo oruko Haggai ni won ma nkoko
da. (Ezra 5:1, 6:14). Itan igbaani kan so wi pe a bi Haggai ni
Jerusalemu asi ko ni igbekun lo lati owo Nebukadnessari ni odun 586BC, ati wi
pe Kirusi Oba ni o pada fun wo ni ase lati pada si ile mimo ni odun 536BC. Eleyi ni o mu je agbalagba nitooto.
Ni
ona miran, onkowe igbaani kan
ti a n pe ni Epiphanius so wi pe o jade kuro ni Babiloni nigba ti o si je odo.
Awon
eda igbaani meta ti won je majemu laelae ni won gbe oruko Haggai ati Sekariah
si ori awon psalmu kan. Awon eda meta na ni won yi eda Giriki ti won
npe ni Igbimo aladorin (Septuagint) ati eda Latin to won npe ni (vulgate) ati
eda Syria
ti won npe ni (peshitta).
Awon
ojogbon kan
gba pe Haggai ati Sekariah sese ki won je eni ti o ko awon psalmu wonyi 111,
125, 126, 137, 145, 146 – 148.
Oruko
Haggai lati inu ede
Heberu ni o wa lati inu oro ti o ntoka si iyara tabi igbese bi ti inu ijo. Ede
yi ntokasi pea bi ni akoko ase. Oruko ti
a pe ni Festus (ase) o je apeere awon oruko ninu itan awon Romu. Nigba miran awon Heberu ma nmu oruko won ni
awon ona wonyi fun apeere Barzillia ti o tumo si okunrin irin ti o wa lati inu
oro ti a pe ni Barzel ti o tumo si irin.
Ni oro miran o sese ki oruko Haggai wa lati inu Haggaih ti o tumo si
(Festival of the lord) Ajodun Olorun I Kro 6:30, o sese ki oruko yi wa lati inu
oruko ti a npe ni Haggariah ti o tumo si igbamu Olorun.
ISE RE
Titun
tempili ko ni aarin gbungbun iwaasu Haggai.
Gbogbo iwaasu re ni o yi akori yi ka.
O je erongba to ga ju lokan re lati ru awon Ju ti o wa ni Jerusalemu
soke ki won o dide lati tun tempili Solomoni ko eyi ti Nebukadnessari wo pale
ni odun 586BC. Ko si woli to soro taara
ni ona ti o lagbara si awon eniyan ilu re tabi woli ti o ni aseyori bi ti Haggai
Oluwa pe Sekariah eni ti se akegbe re kekere lati ran lowo ninu ise nla
kanna. Haggai waasu laarin akoko kukuru
sugbon ni igba ti o le ni. Sekariah ko iran nipa koko
tempili o si se afikun re pelu awon asotele temi to ni ye lori fun gbogbo
akoko.
AKOKO TI HAGGAI SO ASOTELE
Gbogbo asotele Haggai ni o
waye ni odun keji isejoba Dairusi Hag 1:1, 15, 2:10 eleyi je odun 520 BC.
Opolopo awon asotele Ezekieli ni o waye ni akoto yi kanna. Bi a ba fe lo ye igba ti Haggai so asotele
ati igbe aye re a gbodo se abewo si iwe Ezra.
Ninu iwe Ezra yi opo ekunrere
alaye ni pa Haggai ni a so fun wa ati awon akoko re ti a ko ri ninu iwe Haggai
funrara. E kiyesi Ezra 1:1, 4:24- 6:15. Ninu awon ese
bibeli yi a gbo wi pe idapada kan
sele si ile mimo ni odun 536BC. Idapada
yi ti a le pe ni ijadelo elekeji kuro ni oko igbekun, ni Oba Kirusi mu ko sese
ti se Oba Persia. Oba yi ni o fun awon
Ju ni ase lati pada si Jerusalamu Ezra 1:1 -4.
Awon ti won je adari won ni Zerubabeli eni ti oni ase isejoba ati Joshua
eni ti o je olori elesin. Labe
idari awon eniyan mejeji yi awon eniyan ti won to 42,360 ti won je Ju ni won
pada si ile Palestine. Won fidi kale si Jerusalemu ati ilu
alamulegbe bi Bethlehemu, Beteli, Anatioti, Gideoni ati awon ibi miran gbogbo
Ezra 2.
Iwe Ezra ntesiwaju lati so
fun w ape a se ti Kirusi pa lati tun tempili ko ni won ko gbe jade fun opolopo
odun Ezra 4:1 – Awon igbekun Ju ti won ti pada de lati Babiloni npongbe lati se
afilole ijosin inu tempili lekansi. Won
ti gbe pepe ore ebo sisun ro si ipo re atijo Ezra 3:8 – 10. Sugbon a mo pe won o ti pari kiko tempili ti
won ti bere awon ara samaria ni o di won lowo awon wonyin je apakan keferi ti
won si je iran awon igbekun lati orile-ede miran ti won fi tipatipa mu lati
joko ni samaria lati owo Sagoni Oba Assria I odun 722BC A Oba keji 17:24 – 41
nigbati awon Ju ko ti won o tewo gba iranwo awon ara Samaria lati ba won ko
tempili, awon ara samaria pada d iota won.
Nitori isoro ti won ni pelu awon ti o tele won ise kiko tempili yi pada
duro patapata Ezra 4:1 – 5, 24, 5:16.
Fun odun merindilogun (16)
ni ise kiko tempili fi dawo duro.
Ipongbe won akoko pada di ailakasi.
Ona ati lowo pada di ohun ti won nife si. O dabi eni pea won Ju tewo gba inunibini si
kiko ile Oluwa nitori pe o fun won ni anfani lati lo akoko won ati owo won lati
ko ile ara won Hag 1:1 – 3 pelu ihuwasi inu Olorun ko dun si won odun osi si
tele fun awon Ju.
Amosa, nigbati Dairusi di
Oba, akoko tuntun bere fun awon Ju ni Jerusalemu, Dairusi di Oba ni Odun
51BC. Ijoba awon Persia ko
lagbara ni igba naa. Dairusi bere ise imosokan.
Awon oba nla ti won ti sakoso siwaju re, Kirusi ati Kambyses awon je oba
jagunjagun nikan. Won ti segun awon
orile ede ti
won si ti mu ijoba won gbooro si. Sugbon
opo awon orile ede
ti won ti segun re tele ngbiyanju ati gba ominira lekansi. Nigbati Dairusi di oba iwa ote be sile
jakejado gbogbo ijoba na. Awon ekun
metalelogun (23 provice) ni won sote lara won ni Susaina, Assria, Arnenia,
Perthia. Lati le kappa awon ote wonyi
Dairusi ja ogun mokandinlogun (19 battles).
Isele yi ni ijoba Persia de
ipinle won paapaa julo ni odun 520BC ninu eyi ti Haggai waasu. Eleyi lo ntokasi oro ti woli yi so pe Oluwa
yo mi awon orile ede
Hag 2:6, 7, 21 – 22. Haggai ntokasi mimi
awon orile ede gege bi isele to gbodo siwaju mesaya, o si nwoye kiko tempili
gege bi imurasile to se Pataki fun Israeli lati tewo gba oba won atoke wa.
EKO TI A TI KO NINU IWE HAGGAI
1.
Gbogbo iwaasu ni orison re ninu Olorun.
2.
Ese ki eniyan pe la ti se ife Olorun je ajakale arun.
3.
Ijo je aarin gbungbun esin ni gbogbo agbaye.
SEKARIAH – WOLI ARIRAN
ITAN IRAN RE/ ITAN IGBEAYE RE
E se akoko iwe yi ni a o fi bere
soro:
Ese akoko soro nipa Sekariah gege bi omo Berekiah ti n se omo IDDO ori
kini ese ikeji 1:7.
Ninu iwe Esra asoro nipa woli yi gege bi omo Iddo. Laisiyemeji woli yi
kanna ni an soro nipa re ninu awon iwe mejeji. Ninu iwe Esra a soro nipa woli
yi gege bi eniti o gbe nigba kanna pelu
akoko ti a fun wa nipa asotele awon mejeji. Haggai 1:1 – 10 , Sek. 1 & 2.
Awon mejeji ni irufe ise kanna lati se. ise won ni lati dari ati lati ru
awon eniyan Isreali soke lati tun
Tempili ko. Sekariah okere die ni ojo
ori si Haggai Sek. 2 :4 , Hag.
2 :3. Sekariah je eni ti okun fun ogbon Olorun ti o si kun fun oye oni
anfani lati wo ojo iwaju gege bi awon ti o siwaju re na ti se. niwon igbati o
je alufa ti o sit un je woli bakanna (Neh.12:16).
Bakanna lo tun je olori ebi, ipa akoran ti o ni ni Isreali opo pupo. Oruko re
ntoka si eni ti ati fun ni ebun pataki ati agbara pataki lati se ise Pataki
nitori oruko re ntumo si “Eni Olorun
Ranti”.
AKOKO SEKARIAH ARIRAN
Akoko iwe Sekariah yi je odun keji isejoba
Dairusi. Amope eleyi waye ni odun 520BC. Akoko miran ti won tun da ba re fun woli yi pe o se ise iranse re ni odun
kerin isejoba oba Dairusi Sek. 1:1&7; 7 : 1. Osese ki o je pe woli yi tesiwaju iwaasu re titi di
odun 516 Bc nigbati won pari kiko tempili Esra 6:15. Nitorina akoko ti Sekariah
gbe igbeaye re je akoko pelu ti Haggai. Nitori pe Haggai bere ise iranse woli
re ni osu meji ki Sekariah ti o bere titi re Hag. 1 : 1
Ni akoko yi awon isele kan se ti o mu irukerudo wage ti awon
iyipada si ti farahan ninu gbogbo ijoba na. nigba ti a ka ninu iwe Seka. 1:11 nitorina pe gbogbo aye wa ni
isinmi o si duro je, eleyi tumosi pe inunibini ati atako si
awon Ju ni o dawo duro ki ise ati
tesiwaju kiko tempili le tesiwaju.
Nigbati awon JU pada si Jerusalemu lati
Babiloni asotele Jeremiah nipa aadorin odun ti won si imuse Jer.25:11 Jer.
29:10. Ise ( ti bere) lori titun tempili ko labe idari Joshua ati Zerubabeli. Awon atako nipa awon alamulegbe awon omo Ju lo mu
ki won sun ise na siwaju ti won ko fi teteepari kiko ile Oluwa.
Ni akoko isun siwaju yi awon omo Ju ti rewesi
nitori won ko ni anfani lati mu Sioni pada wa si ipo re. Won ti fi ipile
Tempili na le le ti pe sibe ko si ile kankan
ti won ko sori ipile na. Pepe ore ebo sisun ni won ti gbe duro si ipe re atijo
sugbon ko si alufa eye ti o eyi ti o ye lati sise isin lori pepe na Esra 3:2-3,
Sek. 3:3.
O se Pataki ki won ka si awon eniyan lati pada tun tempili na ko. Haggai fon ipe y sita
ti o mu ki awon eniyan bere kiko tempili na. Zekariah na so asotele awon eniyan
na si gba irunisoke ti o mu ki ise
tempili na wa si opin tabi pari. Gbogbo eleyi waye ni ojo keta osu adari ni
odun kefa isejoba Dairusi oba Esra 6:15.
ALAYE ATI AWON OHUN TI O WA NINU IWE
NAA
Awon asotele sekariah pin ara re si
ipa meji. Ipa akoko ni ori kini si ori koje , nigbati ipa keji je ori kesan si
ikerinla.
Awon mejeji yi bere pelu igba ti
Zekariah gbe igbeaye re won si n wo ojo iwaju ti ti di igba ti
akoko opin aye yoo de.
1). Ori kini si
ori kejo: Eleyi ni awon iwaasu meta ti won so ni bi
isele meta ototo.
a). Ori kini 1:1-6: Eleyi je oro akoso si gbogbo iwe naa. Iwasu na
waye ni osu kejo odun keji Dairusi (519 BC).
O se agbekale Ihuwasi si gbogbo
iwe naa. Iwasu yi je okan lara ipe temi si ironupiwada ti o lagbara ju ti o si jinle ju
ninu gbogbo majemu laelae.
b). Ori 1:7 – ti ti de Chap.
6 : 15 :- Ni abala yiyi ani ati ri orisi iran mejo ti Sekariah ti Sekariah
ri ni oru.
Awon Iran
yi ni won je apeere tabi aworan ona ti Olorun yo gba ba isreali lo. Lehin na ni
ase ti Oluwa pa fun Sekariah tele pe ki
o de Joshua olori alufa lade.
Gbogbo awon iran oru yi ni o waye ni ojo kerin-le-logun (24) osu kookanla odun keji isejoba oba Dairusi. Eleyi je osu
meji kerege lehin ti won ti fi okuta ninu
tempili na le lele Hag. 2:18 ,
Zek. 1 : 7. Awon iran yi wa fun
lati ru awon JU soke awon ti won ti igbekun
de si Jerusalemu lati tesiwaju ki won si pari kiko Tempili ile Oluwa. Won ko wa ni awon ekko wonyii.
1). Awon iranse lati Orun wa
Sek. 1:1-17
Iran
yi ko wa nipa iboju Pataki ti Olorun ni fun awon omo Isreali. O so gbangba pe
“A o ko ile mi.”
2). Iwo
merin ati Gbenagbena Merin Sek. 1:18-21
Iran
yi n ko wa pe awon ota Isreali ti pa ra won
run nipaogun ti won gbe dide ko si alatako si kiko ile Oluwa mo.
3). Okunrin Ti o ni Okun iwon ni owo re . Sek. 2:1-end.
Iran
yi n ko wa wipe, Olorun yoo so Jerusalemu di ilu nla lekan si.
Olorun fun ra re yo gbe ninu Jerusalemu yo
dabobo ilu na yo si dagba titi ti fi di Olu ilu nla. Ilu Jerusalemu ki yo ni
odi, nitori Oluwa ni yo je odi ina yi ka ati wipe Oluwa ni yo je ogo laarin re.
4). Joshua Olori Alufa ti o wo aso
eeri, ti o rue e ara re ati awon eniyan:-
Sek 3 : 1-end
Iran yi ko wa pe a o we oye
alufa mo ati wipe yo tesiwaju. Yo pada di aworan eka messiah eni ti o n bo wa.
Ni ojo re wa o mu ese ile na kuro patapata.
5). Opa Fitila Wura Ati igi
Olifi Meji Sek. 4.
Iran yi ko wa wipe ohun temi yo lagbara ju ohun
ti a le fi oju ri loki nse nipa “Emi mi ni Oluwa awon omoogun wi” Nipa se awon
eni ami ororo meji Zerubabeli ti n se olori agbegbe ati Joshua ti n se olori
awon JU Fitila tempili Olorun yoo jo pelu itansan to da ni ona yi a o le ko ile
Oluwa.
6). Iwo kika ti o nfo Sek. 5 : 1-4
Iran yi ni ko wa pe Olorun ti
kede egun lori iwa ika o si ti pinnu lati ke gbogbo awon elese kuro.
7). Osuwon Efah Sek. 5 :5-11
Iran yi n se akawe iwa ika
gege bi
obinrin buruburu. Obinrin yi wa ninu osuwon Efah eyi ti a gbe lo jinarere si ile Simari. Sekariah fe so ni ihin yip e
nigba ti a bat un tempili ko a o mu ese kuro ni ile naa.
8). Keke ogun Merin Sek. 6 :
1-8
Iran yi n ko ni wipe keke merin yio ti iwaju Oluwa ti onigbagbo ile aye jade wa.
Won wa fun aabo awon eniyan Olorun ati
ile mimo. Nehemiah le ko awon odi ile na, sugbon aabo Jerusalemu to daju iso
Olorun lori Jerusalemu ni.
Awon iran yi pari pelu bi a se de Josua
olori alufa lade. Josua ni aworan mesaya
eka na, alufa nla ti o nbo wa ati oba nla ti o nbo wa. Eleyi ni ekunrere ati aworan to pe nipa eni
to nbo wa ninu majemu laelae.
D. Chap 7 – 8: Awon ori meji yi je idahun Sekariah si awon eniyan
to to wa lati Beteli lati wa beere nipa aawe.
Oro yi waye ni ojo kerin osu kesan odun kerin Dairusi eleyi ni odun 518BC.
Lati igba isubu Jerusalemu ni odun
586BC ni awon Ju ti ma ngbawe lori awon ajodun ayeye nla merin lori awon itan
won ti akoko yi, awon ayeye merin yi ati awon akoko ninu odun ti won manse won
ni yi.
1. Kiko Jerusalemu ni igbekun
lati owo Nebukadnessari; osu kerin (4th month)
2. Didana sun tempili lati owo
Nebukadnessari osu karun (5th month)
3. Sise iku pa “Gedeliah” ti se gomina tabi
Baale. Osu keje (7th month).
4. Ibeere idoti Jerusalemu; osu kewa (10th
month) .
Ninu idahun re si awon okunrin Beteli, Sekariah tenumo pe
aawe Israeli yoo dekun ati je aawe ibanuje yoo pada di odun ayo. Opolopo awon orile-ede yoo darapo mo awon
Israeli lati wa Oluwa Olorun awon omo ogun ni Jerusalemu Sek 8:18 – 23.
A. ASOTELE NIPA IJOBA OLORUN TITUN – SEK 9 – 11
Abala yi ni se pelu awon ileri ile na
ti Israeli yoo gbe ati awon isegun lori ijoba awon ota. Bakanna ni asotele yi nsoro lori awon ibukun
ti a fi fun won loko ati ninu ile ati agbara gbogbo gbo.
Abala yi o pari pelu owe idajo eyi to
sele nipa bi Israeli se ko Olorun sile ati awon Olusoaguntan ti Oluwa ti
ran. Ni ori kesan Sekariah so asotele pe
a o mu Juda ati Efraimu pada bo sip o a o si mu wa sokan won yoo si je asegun
lori gbogbo ota won. Bakanna ni a tun
seleri ile fun won ati Oba.
Ni ori kewa a o gba Israeli la a o si
fi okun kan;
ati wi pe ni ori kokanla Israeli yoo jiya fun kiko ibojuto Olusoaguntan ti
Olorun ti ni fun.
B. ASOTELE TI O NSE AKAWE ISEGUN IJOBA
OLORUN TITUN ATI OJO OLUWA TI O NBO WA – Sek 12 - 14
Abala yi ni se pato pelu opin aye. O se afihan aworan meta okookan won yato o si
dan moran nipa awon isele to tele opin aye.
Be ninu ori kejila a o do ti Jerusalemu lati owo awon ota re sugbon a o
gbala nipa agbara Olorun: Ni ori ketala
awon to seku ni Israeli ti a ti fi iponju so di mimo ni aa o pa aye won
mo. Ni ori kerinla awon orile ede ti o do ti Jerusalemu
ti won si ko, won ko ara won papo si ilu na, won o si se ajoyo ase ago ajao
pelu awon Juu. Ni na ohun gbogbo yoo di
mimo ati pelu awon ikoko to nbe ni Jerusalemu ati awon saworo tin be lorun awon
esin. Ohun gbogbo ati kekere ati nila ni
a o fi jin fun Oluwa. Gbogbo abala yi je
iran
nipa idajo ati irapada nipa opin aye.
MALAKI – WOLI OLUKONI
ORUKO ENI TO KO
A ko mo ohunkohun nipa woli Malaki
yato si iwe ti o nje oruko re. Niwon
igba ti o je pe ohun ni woli ti o keyin ninu majemu laelae a ni ireti wi pe o
ye ki o je eni ti a damo daradara sugbon oro yi kori be. Niwon igba ti oruko Malaki ko farahan ni
bomiran ninu majemu laelae, awon miran ti ro pe o se se ki oruko yi ma je oruko
eni to ko iwe yi. Ni awon akoko kan, amosa, awon kan gba pe oruko eniyan
ni Malaki je biotileje pe, ko si woli majemu laelae ti o kowe labe oruko ti ki se tire.
Oro ti a pe ni Malaki yi tumo si
“iranse mi”. Oro yi ni a lo ninu malaki
3:1, 2:7. Oro Heberu “Malakhi” o je
isoro di kekere lati inu “Malakhiyah” ti o tumo si “iranse Olorun”. Woli Haggai naa bakanna je eni ti a ma npe ni
iranse Olorun. Nitori na o sese ki oruko
Malaki ma je oruko eni to kowe yi sugbon ti o gba oruko yi nigba ti o di woli.
Bi o ti wu kori, iranse Olorun yi
gbodo je akikanju eniyan kan
ki o to le doju ko ipo awon alufa be.
Nitorina itumo oruko re se Pataki.
Awon oro to si iwe re ye
fun agbeyewo. Oro asotele (imo) ti Oluwa
ti o ran si Israeli lati owo Malaki Mal 1:1.
Gbolohun yi oro “imo Oluwa” ni a ri bakanna ninu Sek 9:1, Sek 12:1. Awon onkowe igbani so pe Ezra ni eni ti o ko
iwe Malaki. Awon miran so wi pe
Zerubabeli tabi Nehemiah ni eni to kowe na.
Sibe awon miran gba pe Malaki yi gan je omo Lefi, Malaki tumo si eni ti
a fi si ojuse mimu oro Olorun wa, a le pe Malaki ni (Missionary) awon ti a fun
ni ise iranse ijadelo.
AKOKO WOLI NA
Iwe yi ko toka si akoko gan ti a
ko. Amosa, won gbagbo pe eni ti o ko iwe
yi o lgbe ni igbakan na gege bi Ezra ati Nehemiah. Nitorina
o kowe yi ni aarin odun 460 – 430BC.
O je akoko ti awon ara Persia
nsejoba. Won ti tun tempili ko ti won si
ti fi jin fun Olorun ni odun 516B ijosin ati irubo ojoojumo ni o ti nwaye
nisinsinyi fun bi odun (65yrs) marundinladorin.
Igbe aye temi ni ko lo soke rara ni Israeli. Awon alufa ni won ti rewesi ti won ti di eni
ti ko si ninu emi mo. Awon eran ti ko ye
fun irubo ni won nfi nrubo lori pepe.
Awon eniyan ko san idamewa won mo ati wi pe iwa ikora eni sile o wopo
laarin won. Won gbagbe majemu Olorun
awon eniyan si nbeere boya Olorun si je olododo sibe. Won nbeere nitooto boya awon gan ni awon
eniyan ti Olorun yan. Awon nnkan wonyi
ni awon ohun to nsele ati ipo ti awon eniyan wa ni akoko Nehemiah Neh 3:5, 5:1
– 13.
Awon iwa buburu ti woli yi gbogun ti
dabi irufe eyi ti Nehemiah na gbiyanju ati se atunse re nigba to se abewo si
Jerusalemu ni igba keji ni odun 432BC. Neh 13:7 – 9.
AWON
ESUN MEFA TI A FI KAN
ISRAEL
NINU IWE MALAKI
I
III I I
V
VI
IV
Iwe yi bere
pelu oro to ja gaara to si le nipa koko oro eyi ti woli yi nfe koni. Eko na nipe Oluwa si feran Israeli 1:2 –
5. O pari pelu ipe nla si Israeli lati
ranti ofin Mose 4:4 – 6.
Leyin oro afihan ti o wa ni ori kinni
ese kinni, iwe na pin ara re si ona meje.
Awon na ni
wonyi.
1. Ori 1:2
– 5 –Ni abala yi woli yi fihan pe Olorun si feran Israeli. Lati se afihan eleyi o so iyato laarin Israeli
ati Edomu Israeli wa ninu igbekun sugbon a ti mu pada bo lati inu igbekun. Ijiya ti Israel gba je fun igba die. Edomu, ni abala miran, ni a ati le kuro ni
ori oke re ti o je ibi isadi fun won ki yoo si pada bo lai. Ijiya Edomu ki se fun igba die sugbon titi
lae ni.
2. Ori 1:6
-9 – Abala yi baa won Alufa ati awon Lefi wi.
Won ti ko yara ise iranse won
mimo sile, won ti di alailakasi si ofin ati majemu pelu Olorun. Woli yi kigbe wi pe o san ju ki a tilekun
tempili ju ka ru ebo si Oluwa ni awon ona ese.
Ni ona yi o pea won alufa si ironupiwada pelu okan ti o dan moran.
3. Ori 2:10 – 16 – Abala yi je ibawi si
awon eniyan nitori iborisa ati kisile won.
Itokasi ikosile ni yin je kiko awon aya won sile ti awon Ju gun le ki
won le fe awon obinrin ajeji. Iru
igbeyawo be je ona iborisa ni igbe ti woli na nke, o si lodi si ipinnu Olorun lati pa iru omo Olorun
mo.
4. Ori 2:17 -3:6 – Abala yi je ikede idajo to nbo
wa. Awon eniyan ti beresi se iyemeji
gidigidi boya Olorun onidajo ododo tile wa chap 2:17b. Malaki dahun si iyemeji yi ni ede to soro jinle nipa
mesaya to nbo wa. Olorun ti awon eniyan
nwa yoo de ni ojiji fun idajo ni woli na wi.
Ki o we awon omo Lefi mo ki o si we ile elese na mo. Amosas, nitoripe Olorun je eni ti ki yipada a
ki yoo pa awon omo Jakobu run chap 3:6.
5. Ori 3 – 12 – Nihin yi ni
woli yi fun wa ni apeere miran nipa ese ti awon eniyan da. Won ti kuna a ti san idamewa won ati awon
ojuse miran. Nitori na akoko oda eesu,
ati iyan yoo fi de. Sugbon bi won o ba
san awon gbese won lekunrere ile na yoo tun pada di ile ti Olorun feran.
6. Ori 3:13
-4:3 – Eleyi ni abala keji ti a ko si awon eniyan to nsiyemeji Olorun. Ninu Mal 2:7 won ti so wi pe nibo ni Olorun
onidajo ododo wa? Nisinsinyi won wi pe o
je ohun osan lati sin Olorun? Ki ni rere
ti o wa ninu pipa ilana re mo? Awon
eniyan buburu nse rere, beni ni awon eniyan rere nse rere 3:14 -15.
Sugbon woli naa dahun pe Olorun mo awon ti se tire. O ni iwe akole fun awon to beru Oluwa ati
awon to nru enikeji soke ninu igbagbo 3:16.
Iru igbaniyanju yi le je ibere synagogue leyin o reyin.
7. Ori 4:4 – 6: - Abala yi je
abala ipe si opin Mose, ileri ni yoo tele pe Woli Elija yoo wa ni akoko lati
dabobo idajo to nbo wa. Yoo se eleyi
nipa mimu ota kuro lara awon eniyan ati mimu okan won sokan mora. Nipa eleyi malaki nfe so pe iran ti o ti
koja ati iran
tit un la o mu papo lati loye ati lati tewo gba ara won 4:6.
INIYE LORI IWAASU MALAKI
Malaki
je omo Israel
to feran Israeli to si ni ipongbe lati mu ki Israeli je orile ede alagbara lekansi. Erongba re akoko nipa ikowe re ohun ni lati
ru awon eniyan re soke. Awon asotele ati
Sekariah ni ko hi ti wa si imuse tan biotiye.
Eleyi ba won eniyan lokan je pupo won nfe ri bi ijoba mesaya yoo se fi
idi mule.
Isiyemeji
nipa ipese Olorun ati idajo ododo loni gbongbo re lori ijakule won yi. Akoko atunse titun fun awon eniyan se Pataki
ni akoko yi. Lati le se eleyi woli yi
tenu mo awon koko oro wonyi.
1.
Iniye
lori tooto fun ijosin temi 1:6 –
2.
Iwa
ipa to wa ninu ikosile – 2:1 –
3.
Wiwa
mesaya ati ijoba – 3:1 –
4.
Ikora
eni nijanu ayeraye to wa ninu ofin 4:4 -6, 2:7 – 8, 2:17 -:12.
Ni ipari o
han gbangba lati inu iwe malaki pea won eniyana ti ni akoran nipa oye to sun mo
won nipase awon orile-ede to yi won ka.
Siwaju si ati siwaju si ni won nfi awon ayeye igbaani seyin ati awon
igbagbo igbaani ti baba won ni won ngbagbe re.
Malaki
ba emi titun yi ni Israeli nipa gbigbe ofin Mose laruge. Pipa ofin yi mo ni o je orison okun ni awon
orile-ede yi ti o ti koja. Malaki mo bi
a ti paamo ati bi a ti lo awon ohun rere ateyinwa. Gege bi o ti wa pelu Kristi be ni malaki ri,
ko si kekere ninu ofin oluwa ti yoo koja lo tabi ti yoo di alaiwulo. Pelu Oluwa ohun gbogbo ni sise tesiwaju lati
pa ofin Oluwa mo yoo si dara fun o (Amin).
```


No comments:
Post a Comment