IDAGBASOKE IJO
ITOKASI: Akeko idagba soke ijo gbodo sakiyesi oludasile, olumo ijo ati ipinle ninu eyi ti ako ijo lD"MsoNormal" style="margin: 0in -9pt 0pt 0in;">
IJO AGBEGBE
.
IJO GBOGBOGBO.
Ijo gbogbogboo ti Kristi ni gbogbo okan ti ati rapada, okan kan ti a ti fi eje Jesu rapada, ti EMI-MIMO si ti yi pada. Awon ti oruko won wa ninu iwe iye, die ninu won wa lori ile aye, awon die si ti lo sodo Oluwa.
ALAYE ITUMO IDAGBASOKE IJO
1. IDAGBASOKE IJO:- O tumo si awon ilana ninu eyi ti Olorun nmu ijo
Kristi gbooro sii kakiri agbaye.
2. IDAGBASOKE IJO JE:- Pipo sii ti o dogba.
a. Ni pipo yanturu.
b. Ni pipeye
c. Ni wiwa leto leto ijo agbegbe.
GBOGBO IDAGBASOKE IJO
Ti opo yanturu
GBOGBO IDAGBASOKE IJO
Ti wiwa ni eto Ti pipeye
1. Idagba ni pipo yanturu
2. Idagba ni pipeye
3. Idagba ni wiwa leto leto.
SISE AYEWO OHUN TO NBE NINU IDAGBASOKE IJO
1. IDAGASOKE NITI PIPO YANTURU:- Eyi ma nsele nigbati onigbagbo kookan tabi apapo awon onigbagbo ma ngbe iwasu ihinrere kale fun gbogbo araye, ti opolopo eniyan si dara po mo ijo. Idagbasoke ti pipo yanturu yi ba Bible mu, sugbon ogbon ti a fi nse ninu ijo kookan yato si ara won.
2. IDAGBASOKE NIPA IPEYE:- Eleyi tumo si idagbasoke to ntesiwaju ninu ara lati le di aworan Kristi eniti nse ori. Idagbasoke ninu iri Kristi ati ninu gbogbo ihuwasi ati ise re, isokan ti o peye ninu ijo.
Iru idagba soke yi maa nfarahan nigbati awon onigbagbo ba fi aaye gba eko iyebiye ti won si ni anfani lati fi awon ilana ti Emi si ise ninu ebi, ijo ati ninu aye.
3. IDAGBASOKE TI WIWA LETOLETO:- Eyi maa nfarahan ninu ilana ati
igbekale eto ijo. Gegebi ijo ti ngba awon omo titun wole sinu re, ti iye won
si npo sii, beeni won gbodo wa ni eto eto. Awon osise gbodo po si beeni
awon ohun elo ti afojuri, bii;- owo, awon osise, ati ki won si tun gbooro si ninu siseto ijoba ijo.
Opolopo eko ni a le ko ninu idagbasoke ijo, nipa sise akiyesi awon akosile ninu Majemu titun. Botilejepe ijo bere larin meji inu-ni-bini, sibe won dagba lona to lagbara.
Paulu salaye idagba soke ijo nipa fifiwe ise agbe. “Emi ngbin, Apollo mbomirin sugbon Olorun ni nmu ibisi wa” (IDAGBASOKE) 1Kor.3: 6. Gegebi Ojulowo agbe gbingbin ati bibomirin se pataki fun idagbasoke eso, siso eso ati ikore, bakannaa iwasu ihinrere, isonidi omolehin ati pipese adari se pataki fun idagbasoke ijo. Eniyan ni ojuse tire ninu eyiti Emi Mimo ati Olorun yio fi ipa kun lati mu idagba. Nitori idi eyi idagba soke ijo ma nwa lati odo eniyan. Ifowosowopo Olorun ninu Kristi lo nko ijo re.
BI A SE LE MO IDAGBASOKE IJO AGBEGBE
1. Ijo agbegbe tabi awujo kan ti o je kiki Ojulowo onigbagbo ni omo ijo re. Ti o si fi iyato nla han larin awon omo ijo ati eni ti okan ya lati wa josin (Ise.A.A. 16:4-5; -47).
2. Awujo kan ti o ma npade ni ona ti o yato ni ojo akoko ninu ose (1Kor.16: 2; Ise.A.A. 20:7).
3. Ijo ti o ni okan ti o gbina nipa awon okan ti o nsegbe ti o si mu idagba ijo ni pataki (Ise.A.A. ).
4. Ijo ti o ni afojusun idagbasoke ti Emi fun awon asese-gbagbo re ati awon omo ijo lapapo (1Kor.6:19-20; 1Pet.2:2).
5. Ijo kan ti o nlo Bibeli gegebi Ase ati Opa iwon igbagbo ati fifi igbe aye onigbagbo si ise.
7. Ijo ti o ntenumo aini iribo ti Emi-Mimo fun ise isin ati kikun fun iwa Mimo.
8. Ijo ti o seto ara re ni isokan ati bakannaa won a maa fi eto yanju ebun Emi ninu ife , isokan ati idagba ijo laise. Efesu.4:16; 1Kor. 12:1-31.
9. Ijo ti nse sakaramenti mejeji ti ounje ale Oluwa ati Iribomi.
10. Ijo ti o ngbadura.
11. Ijo tabi ipejopo ti o le salaye ipe sinu ise iranse fun awon ojise Oluwa ati
osise ninu ijo. O gbodo je ijo ti o npese eko ti o peye ninu iha kookan ninu
ise iranse won.
12. Awujo ti o ni awon olori ti o ko ara won ni ijanu ti won si gbe awon ojuse
ijo agbegbe le ejika won. Ati nibiti awon Diakoni Okunrin ati Diakoni
Obinrin ti won mu iduro won ni agbegbe ijo nipa ti Emi ati nipa ti ara.
13. Ijo ti o ntele igbekale Bibeli gegebi, amuye fun awon iranse Olorun, awon
Alagba ati awon Diakoni ati osise (1 Tim ;Titus. 1:5-9).
14. Ijo ti o fi owo to gbona mu ikora eni-niijanu, ijo to se ikawo gbogbo
agbegbe re (1Kor. 5:1-5.)
IDAGBASOKE IJO NINU MAJEMU TITUN.
Olorun koni inu didun ninu ijo dida sile kakiri lasan, sugbon ireti Olorun ni pe ki o dagba soke. Omo ti o ndagba soke ni inu didun obi re.
Jesu da ijo sile fun itesiwaju ise irapada re. Nitori eyi o fi ase nla sile nipa iwasu agbaye fun ijo.
Niwon igba ti a bi ijo ti o si nrin pelu aye Jesu Kristi, a nreti ki ijo o maa dagbasoke nipa ti ara ati leralera, bi ko ba si wa dagba, a je wipe ijo ti gba aisan laaye, bi a ko ba si bojuto yio ku laipe.
Ojuse tiwa nigba naa ni lati bojuto ilera ijo, nigba na ni yio dagba gege bi o ti ye.
IWA IDAGBASOKE IJO.
INU OLORUN KO DUN SI:-
1. Dide odo lai mu eja (LK 5:4-11)
2. Tabili apeje ti o sofo (LK. -23)
3. Fifurugbin lai kore (Matt. 13:3-9)
4. Igi opoto ti ko so eso (LK. 13:6-9)
5. Aguntan ti o sonu ti a ko si mu pada wa sinu agbo (Matt ).
6. Owo ide ti o sonu ti a wa sugbon ti a ko ri (LK. 15:8-10)
7. Ikore ti o pon ti a ko si kore (Matt -38).
IDI TI AWON IJO KO FI DAGBA
ITOKASI:- A nilo lati koju si otito ki a si mo wipe awon ijo kan wa ti won ko dagba tabi ti idagba won mo ni iwonba. Ki a ba le seto fun idagba ijo, ose pataki lati mo awon ohun ti o ndi idagba lowo. Bi a se nwo odikeji idagbasoke ijo, a se akiyesi pe awon idiwo ti a to si isale yi ko gbeyin ninu re, bakan na ni orisi risi idi wa ti ijo ko fi dagba. Ijo nilo lati se akiyesi awon wonyi:
1. Opo ijo ni o nfon ipe aidaju, ise iranse won ko da won loju.
2. Oniwa kan , opo ijo lo je wipe won ko fi aye fun Emi-Mimo sugbon ninu iwa kan ni won duro si.
3. Asa, diduro le awon ohun kan ti a ti so di asa ko le fi aye gba ohun titun ti Olorun ni lokan fun ijo re.
4. Ai ko ba aye ode oni mu: paapa bi olaju se ba ise iranse lati mu idagba wa
kiakia.
5. Awujo ti o nyi pada: nitori aini ero ninu, sibe awon ti a ko iti wasu fun wa
nibe, nitori awon eniyan titun nde adugbo nigba gbogbo.
6. Ai ko si adari rere: ko lori Jesu, kii ise ninu agbara anikanjopon re, ko bi a se nwa ati bi ase npese awon olori.
7. Ijo le ti so ife re akoko nu, Ijo le so iran ati idi ti a fi da sile nu. Awon omo ijo le teju mo ile kiko ki won si gbagbe awon eto miran, tabi ki won to gbagbe itara won isaju fun ise iwasu ihinrere, ki won si wa pada di ko gbona ko tutu ijo.
8. Boya isoro nipa ti Emi tabi ti ara: O seese ki iyapa wa ninu ile isin, bi iyapa ko ba si je eyi ti a tete bojuto, tabi ti Oluso Aguntan tabi omo ijo ti o je gbajugbaja kan ba duro sinu ese lai si Igbese ijiya kan kan, iru ijo be yio so agbara re nu, masi se gbagbe pe Olorun ni o nmu ibisi wa, sugbon iranse ese yio di ise Olorun lowo.
9. Ijo ti ko le sakiyesi idagba: Ijo ti ko farabale se akojopo itesiwaju ati ti ko si mo idi ti o fi nilo ati dagba, nipa bee ti ko si seto fun idagba. Iru aikoni idari yi ni ale fi se apejuwe odomokunrin ti a ko ran lo si ile iwe ti o si gba bee, ti ko tile ronu nipa re.
10. Nigbati awon omo ijo ba tako iyipada: Awon omo ijo to je abaya-gbangba le tako ayipada ninu eto won. Ki won ki o si so wipe,” Kini ohun ti o buru pelu ohun a se ninu ijo wa?. A feran re bi o ti wa yi, Iru iwa yi kii fun ijo ni anfani ati se ohun ti o dara ati ise ijoba orun.
11 Nigbati owo oluso Aguntan ba di ju: Ni Opolopo ijo Oluso-Aguntan ki lo omo ijo dardara, sugbon won a ma da ise na se fun ara won, eyi ki si je ki won le fi titun miran kun, nitori ti owo won di ju.
Ni awon ijo miran awon omo ijo a maa yo ise sile ninu eyi ti o ye ki won fi ran ijo lowo. Paapa ninu awon eto to mu ki ijo dagba ni won nfo nitori ti own wipe, e je ki Oluso- aguntan se gbogbo re” Eyi si je eko eke ti o tobi ju o si fa ajakale-arun wo inu ijo.
12. Nigbati awon omo ijo ko ba ni inu didun si awon ara ita: Nigbati omo ijo ba nse isin won pelu aiko inu didun si awon ara ita, awon alejo ni won ko ni ki pelu idunnu tabi ki a pe won fun ojo miran, papa julo ti won ko baje eya wa. Awon omo ijo ko sakiyesi ojuse won lori awon ti o nu ati okan alaini ti o wa ni awujo.
13. Nigbati awon omo ijo ko fowo sowopo mo olori ti oni eko: Nigbati awon omo ijo ko mo riri olori ti oni eko debipe won lese atilehin fun Oluso-aguntan ti o ni eko idagbasoke ijo.
14. Nigbati aba ndari ijo lati owo enikan tabi enikan: Ijo le je ijo ti enikan tabi ebi kan ndari. Sugbon ki ijo o to le je ti Majemu titun, awon omo ijo gbodo je agbarijopo onigbagbo ti won ni ominira ti won si dogba, sugbon ti a fi ife Kristi so po.
Kristi ti ise ORI NI O GBODO JE ORI IJO, KISE OMO RE KOOKAN
15. Ijo le ma lo ogbon to lodi : Opo ijo nlo ogbon ti aye lati se ise Olorun, Olorun ko si ni bukun fun aigboran.
Nigba miran, awon ijo ma nlo awon ogbon ti yio sise dara dara legbe kan tabi pelu awon eniyan kan sugbon ti ki isise fun gbogbogbo.
Fun apeere ogbon ti a nilo pe Orisirisi laarin awon ti o ngbe ni igboro pelu awon ara oko, awon to kawe ati awon ti ko kawe.
Bi ijo ko ba le yi ogbon re pada si eyikeyi to ba ba pade, ati dagba yio ni idiwo.
16. Wiwa ni ibudo ti o lodi .
17. Iwasu ti o lodi nse idiwo fun idagba soke ijo.
NI IPARI;- Awon kan nwipe aikosi idagba soke je aisan ti o seewosan ninu ijo. Lotito awon idiwo ti a to si oke wonyi ni oseese ki o kuro, bi o tile je pe awon ijo miran ko ni le gbaa, nipa bee won ko ni le dagba laelae.
Oluso-Aguntan gbodo sakiyesi awon idiwo si idagba ki o si tete bojuto lati kekere, o gbodo mo daju pe idagba le ya kankan , o si le fale, osi le ni idaduro fun igba die. Awon adari ijo gbodo kiyesi otito pe idagba soke ijo ki isele lojiji, sugbon awon isele abenu gegebi agbegbe ati awon ipo ti Emi ni o ma nse iranwo fun. Nigbati ijo ba loye idi ti on ko fi dagba, eyi ni Igbese akoko lati gba iwosan tabi imularada.
AWON ILANA IDAGBA SOKE IJO:
1. GBADURA FUN IDAGBASOKE: Niwon igbati ako le mu ijo dagbasoke fun ara wa, ati nitori pe Olorun ni o nmu idagba wa, nitorina a gbodo simi le Olorun fun idagba, a ma nfi isimi le Olorun wa han nigbati a ba ngbadura.
a. Emi-Mimo ni o fi idi ijo kale Jon. 16:8-11, .
b. Emi-Mimo nfi agbara kun ijo Efesu. ; 2Tim. 3:16-17.
Ti a ba fe ki igbekale wa ninu Olorun wa han, a gbodo gbadura dara dara. Adura gbodo je eyi ti agba pelu igbagbo ninu Olorun, nitori Olorun ni o mu ki awon isele ki o sele, ko si si ohun ti yio sele bi a ko ba gbadura.
2. OKUNFA FUN IDAGBASOKE: Idagba soke ijo simile ilana ijo. Ohun gbogbo to nsele si eda alaye ni o nmu dagba ayafi ti aisan ba se idiwo fun idagba soke. Nitori idi eyi, ilera ijo gbodo je eyi ti abojuto, lati mojuto ilera ijo, a si nilo ki a mo okunfa.
OKUNFA:- Tumo si sise akojopo alaye awon ami ati awon ise ti o nlo ninu ara ki a si ti pa bee mo ipo ilera ijo.
ORISI MEJI: Okunfa ti idabobo wa, eyi ni ayewo olododun ti a nyewo nigbati wahala ko ti de ti ohunkohun ko iti lodi .
Okunfa ti didahunsi awon isoro, eyi ni anse nigbati a ba ti kefin awon isoro. A nse awon wonyi lati fi mo aisan nigbati awon nkan wonyi bati nfarahan.
Opo ijo lowa ni ipo alaisan loni nitori ko si enikan ti o wa okunfa arun ijo na.
AWON AISAN NINU IJO.
1. Fifi aye gba ese ti a mo. Eyi ma nfarahan nigbati ko si idagba, iwa ti o lodi tabi aisi isokan.
2. Aiko ni ipongbe atidagba ni pipo yanturu, ni eto eto ati ni pipeye.
3. Aiko fara eniji fun adura.
4. Aiko ni idagba soke olori.
5. Awujo ti o nlo igbekale ijoba, ti won si yan awon alaipeye si ipo nitori ibo Opolopo eniyan. Awon alaipeye a si taku si ipo titi di asiko ibo miran.
Idagba ijo ma nwaye nipa ifisise Emi Mimo, nitori Emi Mimo ni ndari ni jijere awon okan to sonu, kiko ijo ati riran jade ati fifi agbara kun eri jije. Awon onigbagbo ti won ba se dede ni Bibeli kika ati adura gbigba ni a nsilekun idari Emi Mimo fun.
Ijo ti o ba tenu mo gbigba adura fun enikookan ati gbogbo eniyan yio wa ni ipo lati dahun si awon anfani ti Emi Mimo yio mu wa. Ijo ti o mu adura ni dandan yio je ijo ti o ndagba.
IFOJUWONLE IDAGBA IJO.
Ose iyebiye lati ri ona ikowe afinimona fun ijo fun awon odun die seyin. Bi o tile je wipe, iru ero bee ko fi han boya ijo dagba tabi o lo sile. Sibe oye ki a ni akojopo ti a to sile fun awon odun die ki o ba le rorun lati fi oju wo ijo fun iye asiko kan . Iru ifojuwo bee lo nso bi agbara ijo ti po to lapapo tabi ni awujo kookan.
O rorun lati se alaye bi a ba lo aworan afinimona fun nkan bi odun mewa, bi o ba see se. Idi niyi ti o fi se pataki fun ijo lati se akojo iroyin olododun re ki o si se lojo pamo. Iroyin ko wulo bi a ko ba lo, sugbon pataki iwulo re ni lati ru wa soke lati boju to apakan ninu ise iranse wa.
O ye ki oluso-aguntan le da gba ojuse kiko iroyin olododun jo fun ijo re. Bi akowe ba tile ko won jo, sibe o tun se pataki fun Oluso-Aguntan lati ye wo finni-finni, ki o si wa lo lati fi pe awon omo ijo nija fun itesiwaju, bakan na ni o ye ki a yin awon ti won nse dara-dara.
Iwe aworan yi je apeere ifojuwonle idagba ijo fun bi odun mewa. Bi iwe iroyin fun odun mewa ko ba si ni arowoto tabi awon akosile opo odun. Bi iroyin olododun ko ba je eyi ti afi pamo, o ye ki ale ri orisirisi akosile eyikeyi ti ijo ni ti o ba wa ni arowoto. Nigba ti akosile fun opo odun ba je tito sile ni okan kan fun akojopo, yio wa rorun lati le so wipe a ntesiwaju tabi a duro pa, tabi a ti so iduro wa nu.
Anfani nla ni o wa ninu ifojuwonle yi ti o le mu wa mo ipo ilera ijo. Akosile wiwa si ipada ni afinimona ti o fi oju han ti idagba. Iye awon ti o se iribomi je osuwon ti o dara ti a fi nmo ijafafa iwasu ihinrere ti ijo. Bi a ba se iribomi lera-lera ni ododun, sugbon ti iye wa duro pa soju kan , o ye ki a bere lowo ara wa wipe ki lo de? Se adugbo yi le ju ni tabi awa ni a ko so awon asese gbagbo wa di omo eyin.
A si tun le ri awon ti o se iribomi miran ti ko iti gbagbo bi o ti ye. Fun ayewo ifinimona ti yio sise fun eto wa, a ni lati sun Igbese na siwaju nipa lilo ona ti isiro lati siro awon ifinimona gege bii osuwon iribomi, ije omo ijo tabi owo ti o wole fun awon omo ijo nipa idamewa ati be-be lo. Iru ifojuwonle yi le tun wulo lati se akojopo egbe ninu ijo.
IFIMONA AWON ODUN 1980 1981 1982 1983 1984 1985 1986 1987 1988 1989
WIWA SI ISIN OWURO 42 72 85 128 138 144 171 209 222 244
ILE EKO OJO ISINMI 41 69 83 96 102 115 158 192 208 209
WIWA SI IDANILEKO 23 33 41 59 70 78 79 93 86 87
WIWA SI IPADE ADURA 25 28 32 38 41 53 54 58 68 62
AWON TI O SI IRIBOMI 14 16 21 08 27 05 03 28 15 04
AWON OMO IJO TITUN 12 10 10 04 15 0 0 16 05 0
APAPO IDAMEWA/ ORE 1,800 750 484 2,000 4,000 595 3050 884 3,500 2,400
GBOGBO OORE 32 84 126 167 204 258 293 312 323 343
ILE EKO OJO ISINMI OKO FUN IDAGBASOKE IJO.
ITOKASI:- Ile eko ojo isinmi a maa pese aaye fun idagbasoke ijo ati lati maa fi oro Olorun bo awon ti o ti sonu tabi sako lo, lati le se awari okan ati aye won.
Bakannaa, eko ojo isinmi a maa ran awon onigbagbo lowo lati le dagba ati ni oye kikun ninu ise isin won.
Ni abala ibi yi, a fi enu ba ona marun otooto ti ile eko ojo isinmi ngba ran ile ijosin lowo lati dagba:
1. A ma se awari awon asesewa.
2. A maa mu awon asesewa wole wa si ile ijosin.
3. A maa wasu si enikookan.
4. A maa koni ni oro Olorun.
5. A maa mu ete Bibeli je ete wa.
1. A MAA SE AWARI ASESEWA:-
JESU SO PE: “Nitori omo eniyan de lati wa awon ti o nu kiri, ati lati gba won la”. (Lk. 19:10). Ise akoko se ti ijo ni lati se awari awon ti o ti sonu, ki a baa le mu won to Jesu wa fun igbala okan won. Jesu ko so pe ki awon ti o ti sonu wa si ile ijosin, sugbon o so fun ile-ijosin lati se awari won.
TANI ASESEWA? Igbese akoko ni lati lo ile eko ojo isinmi fun ise ihinrere ati idagbasoke ijo, ati lati se iwadi tani awon asesewa ile eko ojo isinmi. Orisi ona meta gboogi ni o wa fun asesewa:
a. Awon ti ko ko oruko won sile ni ile ijosin
b. Awon ebi ati awon ore omo ijo
c. Awon ti kii lo ile ijosin lokurin, lobinrin, ni odo okunrin ati odo-obinrin.
A le maa beere idi ti fifi oruko sile ni eko ojo isinmi se le ran ijo lowo lati dagba soke. Ose gboogi, ni fifi oruko eniyan tabi kiko oruko eniyan sile lati tun je okan ninu won.
Yato si eyi, kiko awon omo ijo ni oro Olorun a tun maa ran ijo lowo lati dagba dara dara. Lona keji ti a ba ko oruko omo ijo sile, o see-see ki a ri lara awon idile re tabi lara awon ore re pelu. Lona keta nipa jije omo ile eko ojo isinmi ati omo egbe ajumo ko Bibeli ale je ki o je ogbontagi osise ile Olorun ti a ti le yan adari.
Gbogbo awon ijo gbodo je akeko ojo isinimi, ogbudo maa lakaka lati mu gbogbo ebi re gbogbo awon ore re ti ki lo ile ijosin ati awon alabagbe tabi aladugbo re wa si egbe ajumo ka Bibeli ni ile ijosin.
Nitooto o le maa ronu nipa eleyi, ayafi ti a ba so fun-un, ti a ran leti, ti a si ro lati se eyi. Ihinrere Jesu da bi igba ti a ba nti oko oju omi soke. Lai je pe o ndagba, o kan maa jo ajo reyin ni. Nitori idi eyi awon adari ile eko ojo isinmi ni ise pataki tabi ojuse lati se nipa fi-fi si okan awon omo ijo.
A ko ti se ojuse wa to nipa sise awari awon ti o ti ‘nu tabi sonu, ayafi ti a ba se iwadi agbegbe tabi ikaniyan ti esin wa. A le ro pe gbogbo awon ti o wa lagbegbe wa ni a ti mo, sugbon iwadi a se afihan awon ti ko ti lo ile ijosin, ati papa awon okan ti a ko ti gbala, sugbon ti Jesu ku fun.
Oluwa wa so wipe, “Mo ni awon Aguntan miran ti ki se ti gbo yi: Maa mu won wa pelu”.
2. O MU AWON ASESEWA WA:-
Ka tile so pe ile ijosin se iwadi, ki o wa ri pe igba ati eedegbewa asesewa ni a ri. Nje Oluso-Aguntan a le waasu si enikookan ki o to ku tabi kuro nibe?
3. O NSE IWASU SI ONIKALUKU:-
A gbodo maa lo awon omo egbe ile eko ojo isinmi lati maa se abewo si ara won. A gbodo yan ise tabi ojuse fun gbogbo awon omo egbe ile eko ojo isinmi lati maa wa ara won, papa awon ti won ba ri pe ko wa si ile ijosin lojo isinmi, lati le emi irewesi lo, ki a se aajo won nigba ailera ki a si waasu si won nigba aini.
4. O NKO ORO OLORUN:-
Eda Bibeli ti Oba Jakobu, ninu iwe Romu 10:10:17 so wipe “Nje nipa gbigbo ni igbagbo ti wa, ati gbigbo nipa oro Olorun, o tun so ninu iwe Heberu 4:12 “Nitori oro Olorun ye, o si lagbara, o si mu ju idakida oloju-meji lo, o si ngun ni ani titi de pinpin okan ati Emi niya, orike ati ora inu egun-gun, oun si-ni olumo ero ati ete okan”. A le ni igboya pe ti a ba ri asesewa ninu egbe ajumo ka Bibeli pelu okan ise-dee-dee, ati pelu ti a baa wo Olorun lati lo okan wa lati ko wa loro Olorun, ki awon ase-sewa le ni idaloju Olorun fun-rare.
5. ETE BIBELI NI ETE WA:-
Ete Bibeli ni ifihan ati irapada Olorun. Nitosi ipari ihinrere, Aposteli Johanu se alaye idi ti o fi ko iwe re, o si le salaye kan naa fun awon iwe lati Genesis de Ifihan. O wipe, “sugbon wonyi ni a ko, ki eyin le gba gbo pe, Jesu ni se Kristi naa, omo Olorun, ati pe ni gbigba-gbo, ki eyin le ni iye ni oruko re” Jn.20:31.
Ni ipari ko si eni ti o le keko tan kuro ninu ile iwe Bibeli, Imoran Mose si awa eniyan nipa iwe ofin nipe “Yio wa lodo re, oun osi maa to o lojo aye re gbogbo Deut .
Ni otito, Bibeli maa ndun sii, bi eniyan ba ti nka si. Nitori idi eyi ile eko ojo isinmi nran idagba ijo lowo nipa gbin-gbin otito oro Olorun ati riran ni lowo lati fi si ise ninu aye awon okunrin, obinrin, odo-mo-okunrin ati odo- mo-obinrin. Ki Oluwa bukun o.
No comments:
Post a Comment