EKO
NIPA ANGELI.
ALAYE ITUMO: Angeli je eda ti orun ti won lagbara ati ogbon ju
eniyan lo.
Angeli je
emi ti Olorun da (Gen.2: 1,Neh.9: 6,Efe.3: 9,Kol.1: 16). A ko mo igba ti ada
won, sugbon won wa ni orun (Matt.22: 30,Efe.3: 10,Joh.1: 51,Lk.2: 13-15).
IGBA
AYE AWON ANGELI.
Oro ti a n
pe ni igba aye wa ninu Bibeli.Ni Majemu titun, igba meje ni a ri, ninu Ojulowo
iwe adako Bibeli o faran ni ona meji.
1.A se
itumo re gege bi igba aye ni igba merin.1Kor.9: 17,Efe.3: 2.Kol.1: 25.
2.A se
itumo re gege bi ise iriju nigba meta.Luk.16: 2-4,1Kor.9: 17,Matt.25: 14-30.
Alaye
Itumo Ise Iriju:
Isakoso ohun ini elomiran bi, eto owo ati ile-gbe.
Ti a ba
nsoro nipa awon Kristeni; Ise Iriju tumo si, Isakoso ise Oluwa nipase ijo ni ona ti a o le se
isiro fun eni ti o ran wa nise na.
Olorun ti
yan awa Kristeni lati je iriju re ni Orile aye.
Igba aye
ninu Bibeli tumo si ISE IRIJU.
Igba aye bi
mesan lo wa.
1.Awon
Angeli - Eyokan
2.Eniyan - Meje
3
Ayeraye – Eyokan. Eyi to
kan meta lokan, Olorun, eniyan, Eyi ni awon ti a ti ra pada ati awon angeli
olooto
Igba
aye ni oju meji:
- Oju ti Emi (Olorun): Olorun ni o wa ni
Isakoso aye pelu awon eniyan ti a da.
- Oju ti Eniyan: Ise Iriju re.
Akiyesi: Eniyan at Angeli ni a danwo ninu ise iriju
won, awon mejeji lo si kuna, fun idi eyi a si dawon lejo.
Alaye Itumo: Igba aye ni osuwon igba kan ti adamo, eyi ti
o ni ohun kan pato se pelu ero ngba Olorun- erongba kan eyi ti o gbodo wa si
imuse ni akoko kan.
Eyi kan ifihan kan pato, idanwo, ijakule ati
idajo.
Igba aye awon Angeli: lusiferi ni ojulowo Gomina aye
ti akoko da lati owo Olorun.
Igba Won: Lati igba ti ati da aye akoko titi di igba
idaru dapo.Gen.1:1,2..
IWALAYE AWON ANGELI.
Oro ti a n pe ni “Angeli” koko
farahan ni Gen.16: 7, Nibi Angeli Olorun ti nse ise iranse fun Hagari lehin ti
Sarah ti hu iwakwa si (1912 B.C).
A da won Angeli lati owo Olorun sugbon a ko mo
igba ti ada won.Kol.1: 16; “Nitori ninu re li ati da ohun gbogbo ohun ti be li
orun tabi ohun ti be ni aye. ”Ninu Matt.4: 11 Awon angeli wa lati se ise iranse
fun Jesu ni igba idanwo la
Ni
Matt.18: 10,Jesu soro nipa awon angeli alayanle “Nitori mo wi fun yin pe
nigbagbogbo li orun li awon angeli won now oju Baba mi ti be li orun” Jesu
gbagbo ninu awon Angeli, bakanna ni Paulu gbagbo.Kol.2: 18, 2Tesa.1: 17.
EDA WON.
Eyi ni eda ti ada won, a pe won jade lati inu
ofo nipa agbara Olorun a ko mo akoko ti
a da won sugbon, a mo wipe ki eniyan to farahan, won ti wa saju, ati wipe
nigbati eyi sele, won wa ni ipa meji-Angeli rere ati Buburu; Nitori pe won je
eda, won ko ki a ma sin won (Ifihan 19:10;22:8-9)Ati eniyan pelu niha tire je
ewo fun lati sin won .Kol.2:18.
AWON
EMI.
Ase apejuwe awon
angeli gegebi emi, nitori won ko dabi eniyan, kosi odiwon nipa ipo to seri ati
eyi ti ko seri, won le farahan won si tu le poora nigba kugba, won si le rin
ninu afefe pelu ipa ti akole salaye, ni ailo ohun elo ti a nri.
Bi otile je wipe won
je emi, won ni agbara lati gbe ago eniyan wo, ki won ba le je ki ifarahan won
di mimo si aye eniyan.
AIKU
Eyi ni pe, won kole
ku. Ni Luk.20: 34-35.Jesu salaye fun awon Sadusi wipe ajinde awon eniyan mimo
yio dabi ti angeli nitori wipe won ko ni leku mo.
OPO YANTURU.
Iwe Mimo ko wa pe won
po gidigdi “Egberun lona egberun mewa, lona egberun mewa.” Danieli 7:10. “Won ju
egbe ogun mejila won angeli.”Matt.26: 53 “Opolopo awon ogun orun” Luk.2: 13.
“Ogoro owo awon angeli” Hebu.12: 22 Eleda ati alakoso won ni a npe ni Oluwa
awon omo ogun”.
WON KO NI EYA AKO TABI ABO.
A maa juwe angeli bi
abo, sugbon ni otito, won ki se ako tabi abo, won ki mu eya ara won jade, eyi
nipe won ki bimo bi eniyan, Luk.20: 34-35,
ONIPO
JIPO WON.
Angeli Oluwa-Bi se sakawe “Awon
angeli Oluwa”. A ya won soto larin won angeli yoku. Agbara idariji tabi dida
aisedede duro ni a fi fun won. Ati pe oruko Olorun wa ninu won. Eksodu
23:20-23. Ni Eksodu 32:34,A ko pe “Angeli mi yio saju re” Ni Eksodu
33:14,Oyato: “Oju mi yio ma ba o lo, Emi yi o si fun o ni isin mi.” Ako mejeji
ni Isa. 63:9 “Ninu gbogbo iponju won oju, a pon o, Angeli iwaju re si gba won.”
Awon ohun meji to se pataki ni, aso nipa Angeli yi: Akoko, wipe oruko Jehofa,
iyen ni ise ti a fi han wa, wa ninu re, ati wipe awon ni oju Jehofa, eyi ni
wipe Oju Jehofa se ri ninu re. Nitori eyi, O ngbala ko si ni dari aisedede jin,
bi otile je wipe, oni agbara lati se be. Se afiwe pelu idamo ti Jakobu fun
angeli pelu Olorun funrare.Gen.32: 30; 48:16.Ako le salai mu wa si opin pe
angeli aramada yi ko yato si omo Olorun, Eni ami ororo, Oludande Israeli ati
Olugbala ti yio gba araye la.
Nitori na, Angeli Oluwa je eda
ti a ko seda re.
Olori angeli – Mikaeli ni a daruko
keke bi olori Angeli, tabi Angeli to jagun.
Jud 9,Ifihan 12:7;Afiwe 1 Tese.4: 16.O farahan gege bi angeli to dabobo
ile Israeli. Danieli 12:1 Eyi fi han pe oni ipo ti oga; onduro ni iwaju Olorun
(Luk.1: 19). Asi fi ise nla to se pataki ni ijoba Olorun le lowo.Dan.8: 16;
9:21.
Awon Angeli ayanfe – Awon
asayan Angeli ni awon ti won duro lotito pelu Olorun, ti won si ri ipo won gba
pada leyin idite Satani. 1Tim.5:21;Matt.25:41.
Angeli Orile Ede – Dan.10:
13,20.Dabi pe o nko wa pe gbogbo iran ni o ni angeli to ndabobo won, eyi to ni
se pato nipa alafia orile-ede bee. Akoko to fun won lati jade ninu igbekun.
(Dan.8: 1-2). Danieli yara re soto lati gbadura ati awe fun ipadapo won. Lehin
ose keta, angeli kan farahan ti o so ohun ti o fa idiwo fun adura re, pe
balogun Persia lo de ipada bo awon Ju lona, boya won o fe padanu ipa won ti won
ni fun ile Persia. Angeli yi so fun pe ninu ijirebe re fun imupada awon Ju, oun
o ni oluranlowo kan kan bikose Mikaeli olori orile-ede Heberu.Dan.10:21.Olori
awon Grikii ko fowosi pe ki Olori Persia ni atilehin pe ki awon Ju jade
lo.Dan.10:20.
Awon Kerubu – Won farahan bi
angeli to ni ipo to ga to so po pelu Olorun ninu ijiya ati irapada to kan enia.
(Eksodu 25:22)
A se apejuwe won pe won ni oju bi ti Kinniun, Eniyan, Malu ati Eye Idi.
Eyi si fi han pe won nsapere pipe Iseda, Kinniun tumo si Ipa, Eniyan- bi
Iiloye, Idi bi Yiyara. Bi won ti sunmo Olorun fun wa ni idanloju pe “a o gba eda papa kuro lowo igbekun idibaje”
Romu.8: 21.
Awon Serafu -Awon Serafu ni a daruko ni Isa.6. A ko mo
ohun topo nipa won, akowe kan ro wipe won je ara awon angeli to lola julo, ati
wipe ami to farahan ninu iwa won ni pe won ni ife to gbona fun Olorun (Itumo
Serafu ni awon to ngbona).
IYE WON.
Iwe Mimo fi ye wa pe won ga “egberun, egberun
ati egberun mewa lona egberun
mewa”Da.7:10. “Won ju egbe ogun mejila awon
angeli”, Matt 26:53 “Opolopo awon ogun orun.” Luk.2: 13 “Ogoro owo awon
angeli.”Heb.12: 22 “Eleda ati alakoso won ni
a pe ni Oluwa awon omo ogun.”
EGBE AWON ANGELI TI A DARUKO.
- Kerubu (Gen.3: 24)
- Serafu (Isa.6: 2,6.)
AWON ANGELI TI AFI ORUKO PE. Mikaeli- Oun ni Olori angeli to ba esu ja nitori oku Mose.
Jud 9.
Gabriel- Oun ni omo alade angeli ti a ran lati orun lati
kede fun Maria ati Josefu nipa omo ti a o bi (Jesu) Lk.2: 9,13) Ohun ni o dari
won lati salo si Egipti. (Matt.2: 13,19).
Lusiferi- (Isa.14: 12, Esikeli 28:11-17)
IWA AWON ANGELI
IGBORAN-Won nmu ase ti a pa fun won se laisi ayewo tabi ise
tiko to, nitorina ni a se ngbadura pe
“Ife tire ni ki a se ni aye, bi won ti nse ni orun”
Matt.6: 5:10.Ps.103: 20, Jud 6, 1Pet.3: 22.
WON NI OWO :ise won tio ga
ju ni sisin Olorun.(1:6,9-6Phil.2:9-11.
WON GBON-“ Bi angeli Olorun…lati
mo rere ati buburu” je owe ni Israeli. 2 Sam.14: 17. Oye angeli ju ti
enia aye yo lo, sugbon dandan ni opin re. Awon angeli ko le dede mo ero okan wa
(1 Awon Oba 8:39) ati oye won nipa ohun ijinle ore ofe ni odiwon.1 pet.1: 12.
Akowe kan salaye “ A gba pe oye angeli nipa ohun ti won ri jina gedegede si ti
enia debi wipe aworan kan soso ni okan won ni alaye ekunrere ju gbogbo eko ti a
fi gbogbo aye wa ko nihin.
WON
LAGBARA: Angeli ni
agbara. (Ps. 103:20). ‘E fi ibukun fun Oluwa, eyin angeli re, ti o po ni ipa’
- Angeli kan soso pa oke mesan le
egbedogbon omo ogun assiria ni oru ojo kan 2Awon Oba 19:35.
- Angeli kan soso pa egbaa
marundinlogoji nigba ti Dafidi dese 2Sam.24:15-16.
d. Angeli kan soso ba agbara
Romu je, o si fo edidi osi yi okuta enu iboji kuro
Mt.28:2&4.
e. Ni ojo kansoso ni angel kan
yio de esu, yio si fi si atimole fun egberun odun.
- Angeli merin tu aadota oke lona
igba elesin Eufrate sile. Ifihan 9:15,16.
Orisirisi ipo ati ona ni a gba to awon angeli
ti won si wa. Mikaeli ni a pe ni olori
angeli, Jud 1:9.Bibeli so nipa Olori angeli, angeli, Ijoye, Olola, Ijoba ati
ite.Kol.1:16,Dan.10:12,21,1tess.4:16,1 Pet.3:22.
Angeli je aiku, Lk.20: 35-36.Laini eya ara,
won kii ku, beni won kii ra,ti Jesu ba di angeli ni ki ba ti ri iku. Angeli ko
ni eya ako tabi abo, a ko si le gbe won ni iyawo.Matt.22:30,Lk.20: 35-36.
WON JE MIMO –Nitori
won je eda ti a ya soto fun Olorun ni won je. “Angeli mimo”.
AWON ISE WON.
- ASOJU OLORUN –A daruko won gegebi awon ti a yan lati
inu idajo Olorun se.Gen.3: 24.Num.22: 22-27,Matt.13: 39,41,49; 16:27;
24:31;Mk.13: 27,Gen.19: 1, 2Sam.24: 14-18.
- OJISE OLORUN-Itumo angeli ni “Iranse”. Nipase angeli, Olorun ran ise.
1. Ikede-Lk.1: 11-20, Mt.1: 20-21.
- Ikilo-
Mt.2:13,Heb2: 2
- Itoni-
Mt.28:2-6,Acts.10:3, Dan.4:13-17.
- Iyanju-Acts.27:
23, Gen.28: 12
- Isipaya-Acts.7;53,Gal.3:19,Heb.2:2,Dan.9:21-27.
- IRANSE OLORUN- “Emi ti njise ki gbogbo won ise, ti a
nran lo lati josin nitori awon ti yo jogun igbala”Heb.1: 14 A nran angeli
lati muni duro (Mt.4: 11) Lk.22: 43, 1Kg.19: 5 ati lati paa mo. Gen.16:
7,Eksodu 23:20,ifihan 7; 1, Lati tusile Num.20:16. Orin Dafidi 34:7;
19:11, Isa.63: 9,Dan.6: 22;Ifihan 8:3,4,A ran won si awon olododo lehin
iku. Luk.16: 22.
IBASEPO WON PELU ENIA.
Nigbati won ba farahan fun enia, angeli
lorekore maa nfi ara han ni awo enia.Gen.18: 2, Dan.10: 18, Sek.2: 1.Nigba
miran ewe, ifarahan won ma mu eru lowo (Onidajo 13:6,Matt
A o ri ninu angeli pe won fi ara han enia
buburu bikose awon ti Bibeli woye pe won dara bi Abrahamu, Mose, Dafidi,
Danieli Jesu, Peteru ati Paulu.A fun won lase lati ma moju to iru awon enia be
ati ki won mase iranse fun won ni akoko aini.(Orin Dafidi 91:11-12,Heb.1:14)Won
ma nse amona ati tito awon enia rere.(Gen.27:40,Esodu 14:19)
Ojuse
yi ni se apejuwe re nipa ipa ti angeli ko nigbati Olorun fun Mose ni Ofin
(Acts.7: 38,53;Heb.2: 2) Nigbamiran itoni won ma nwa nipa ala ti enia nla,
Gen.28: 1; 31:11, Angeli ma dabobo awon enia Olorun (Eksodu 14: 19-20, Dan.3:
28,Matt.26: 53). Won nba aini awon enia pade lorisiri ona ati iranlowo kuro
ninu ebi ati oungbe (Gen.21: 17-19,Mk.1: 13). Ati bibori didagbe ati ifoya (Lk.22: 43).
Nigbamiran won ngba awon enia Olorun sile kuro
ninu ewu.
Lotito, won kii se koko ohun igbala, angeli
nife si igbala enia (lk.15: 10,1Kor.4:9) .Ni pataki julo won kopa ninu isele
toromo ibi ati ijinde Jesu Oluwa
Matt.1:20;2:13,19 ;28:2, Lk1:11-38;2:9-15;22:43;24:23 Joh.20:12. Ikopa won angeli ninu aye enia ti dinku lati
igba Pentikosti.
Jesu soro lokere nipa awon angeli rere ati
buburu. (Matt.13: 41; 26; 53,Mk.8: 38, Lk.12: 8-9). Angeli wa lotito,won ko ipa
pataki ninu eto Olorun fun aye.
No comments:
Post a Comment