Wednesday, June 6, 2012

ESCHATOLOGY YORUBA


ESCHATOLOGY
Oro ti a pe ni Eschatology yi oje oro Griki meji ti a so papo di eyo kan.
Eschatos      -           Tumo si awon nkan igbehin
Logy             -           Eko
Eschatology tumo si eko nipa awon nkan igbehin. Eschatology je ede awon onimo ijinle bibeli ti won fi salaye eko awon ohun ti yio sele ni opin aye. Pataki julo nipa awon isele nipa bibo Jesu lekeji. Ni oro miran ohun ni a mo ni iwe ifihan tabi iwe isipaya or apocalypse.
Iwe Ifihan se pataki ju laarin awon iwe ti o ku, bi o ti se pataki to, awon ti won nka iwe na ti won sin pa oro re mo yi o di eni ibukun Ifihan 1:3.
Ifihan ni iwe ti o kehin ati iwe asotele nla ti o kehin ninu bibeli. Eredi iwe yi ni o salaye re ninu awon oro akoso re “lati fi han fun awon iranse re ohun ti ko le sai se lowolowo”.
Won salaye re pe Ifihan yi wa lati owo Olorun, a si fun Jesu Kristi eni ti o fi ran Angeli re lati lo salaye re fun Johannu mimo olufe ninu orisirise iran.
Iwe na ni ipele meta ti o se pataki:
(1)              Awon ohun ti o koja (awon ohun ti iwo ti ri)
(2)              Awon ohun ti loolo (ohun ti o mbe)
(3)              Awon ohun ojo ola (ohun ti yio he leyin eyi)
Bi o ti se wa ninu oro kinni ese ikokandinlogun (1:19)

ALAYE ITUMO IWE IFIHAN
IFIHAN:- Ifihan je ibasoro Olorun si awon eniyan re ni oun funrara re, gbedeke igbe aye omoluabi ati eto igbala re.
Ifihan tumo si isiso loju tabi isipaya sugbon opolopo ri awon roo inu re gege bi eyi ti iboju bo tabi eyi ti o tii nitori awon apeere ti o tobi ti o wa ninu re.

ENI TI O KO IWE NAA
Orisi onkowe meji ni o ko iwe ifihan e.g.
(1)              Onkowe atoke wa ti n se Olorun fun rara re.
(2)              Onkowe eniyan ti n se Johannu Olufemi eni ti o se akosile re gege bi ese akoko ti so.

“IFIHAN TI JESU KRISTI”
Olorun nse a peko re nipase Jesu Kristi ati lati owo angeli kan si Johannu okunrin na ti o se akosile re ti o si fi ekunrere awon iwe na sowo si awon ijo meje Ifihan 1,4,9 28: Koda awon baba igbaani ninu igbagbo fi idi re mule pe Johannu ni o koo, awon baba igbagbo bi “Irenious”.
            Johannu jiya inunibini labe yoba Binitianim, a wa lo si erekusu patros lati da duro ki o ba ba, sore laarin awujo.
            Isowo kowe ati eto ifihan je ki o di mimo pe enikan ni o se akosile re. Oruko Johanu han ni igba merin ninu iwe Ifihan Rev. 1:1, 4, 9, Chap. 22:8. Nitori awon oro ti o wa ninu re ati nitori ise ti a ran si awon ijo meje, iwe ifihan ni o yara kankan lati tan kan ti o si di ilumoka ti si di atewo gba ninu ijo akoto. Ni gbogbo igba ni a n daruko ti a si dabobo ni akoko awon igba kaloni ni akoko majemu titun.
            Iwe Ifihan ni o soro ju lati tumo laarin awon ori bibeli ti o ku nitori ekunrere ora ti o ngba wo nkan ti awon ami ti o tobi. Bi o ba fe tumo ori kan o ni lati ka gbogbo ori re ati awon iwe woli miran, siwaju ki a to le tumo re, biko se be peu irorun ni iwo o fi subu sinu asise. Nitori idi eyi o ndo lati mo awon liana kokan ninu re.

27-2-08                                  ITUMO MERIN
Itumo merin ti o ye fun akiyesi
1.                  Itumo nipa ona asotele
Awon eniyan kan wa ti a npe ni Preterist, awon preiterist awon ni awon alasotele, awon so wipe Johannu so wipe awon ohun ti o n sele ni awon oju re 96 AD.
2.                  Itumo nipa ona itan
Awon onitan yi so pe Johannu nsalaye awon isele ti yio sele ni akoko ijo.
3.                  Itumo nipa tie mi
Awon kan gbagbo pe gbogbo ohun ti o sele ninu iwe ra ni a gbodo mu gege bi oro owe tabi gege bi oro opolo, o won wipe Johannu nso ni temi, ki n se iriri ti a foju ri.
4.                  Itumo nipa oro ojo iwaju
Awon onitumo ojo iwaju yi ni o dabi pe ona won te ni lorun ti o si tun se itewogba, Ifihan je iwe asotele ti o je pe lati ibe re pepe ni ko nti se, pataki ju lo bere lati ori kerin siwaju. Orisi awon ona merin yi ni awon eniyan gba lati tun.
Iwe Ifihan ni awon nkan wonyi. Awon ohun ti iwo ti ri ninu Chap 1:1-3. A si ri bi oro akoso tabi oro asosiwaju. Awon Ohun ti o wa: Eyi ni ise iran se si ijo meje Chap 2-3.

AWON OHUN TI YIO HU LEHIN NKAN WONYI CHAP 4-22
IWE SI AWON IJO MEJE
Bi a ba soro iwe si awon ijo meje a gbodo se akiyesi awon ilera amulo re ni oniruuru ona.
(1)       Amulo ti agbegbe kan – Eyi ni awon ijo meje ti o wa ni        . opololpe ijo ni o wa ni akoko Johanu sugbon Olorun kan yan ijo meje lati se asoju won ijo to kan ni ojo Johan. Ijo akoko ni:
1.         Efesu
2.         Smyrna
3.         Pergamu
4.         Thytira
5.         Sardi
6.         Filadelfia
7.         Laodiekia
i.          Efesu – Ijo ti o ngbagbe ife isaju.
ii.         Smyrna – Ijo ti o n beru inunibini.
iii.               Pergamu – Won je olooto ti won fe je oluko eko.
iv.               Tiatra – Ijo ti awon Woli eke alagbara kun inu re.
v.                  Sardi – Ijo ti o ti ku nipa tie mi.
vi.               Filadelfia – Eleri olooto.
vii.             Laodikea – Kogbona kotutu ti o se ilo wowo.
(2)       Eyi ni amulo igba aye: Eleyi tumo si ipin meje tabi igba meje ti o wa ninu itan ijo.

            Efesu: O je ijo Aposteli 30-1 a fi we 30-100AD
            Smyirna: A a le pe won ni ijo oninubinu 100-312AD
            Pergamu: A pe ni ijo ijobo 313-590AD
            Tiatira: A pe ni ijo papa 590-1517AD
            Sardi: Ijo ti a tunse 1517-1790AD
            Filadelfia: Ijo onise ihinrere (missionary) 1790-1900
            Laodikea: Ijo eleko eke 1900 – titi di asiko yi

Ona imulo ti asotele-Eyi tumo si ti awon ijo meje eyi ti o wa ni akoko igbe aye ti wa yi.

Amulo enikooko: Eleyi tumo si orisi iwa ti a le ri ninu igbe aye enikookan wa loni.


23-3-08                      AWON ISE TI A RAN SI AWON IJO MEJE
Ohun mefa ni o kiyesi ninu ise ti a ran si awon ijo meje, awon na ni wonyi:

(1)              Ibi ti a ran oro na si
(2)              Apejuwe Jesu si ijo na
(3)              Oriyin fun ijo na
(4)              Idalebi fun ijo na
(5)              Imoran fun ijo na
(6)              Ileri fun ijo na

(1)              IJO TI EFESU (REV 2:1-7)
1.      Ibi ti ran si – Efesu
2.      Apejuwe – Eniti o ni fitila maje ni owo re.
3.      Oriyin – Emi mo sise re, iyen nipe ijo ti n sise won ko ri ra ibi, ifarada ati suru won.
4.      Idalebi – Iwo ti fi ife re saju si le, eyi tumo sipe ife Kristi kokatata mo.
5.      Imoran – Ranti ibi ti iwo ti subu, ki o sise isere isaju
6.      Ileji – Igi iye na.

Ni ipari: Jesu gboriyin fun ijo yi gege bi ijo ti o nsise ti o mo ati ti a yato ti o si korira awon eko awa Nikolia tani. O tun so fun wa bakanna nip e ki awon ti o ni eti ki ogbo, eyi tumo sip e a ni orisi ipele eniyan ninu ijo.
a.      Awon ti ko ni eti
b.      Awon ti won yadi ni gbigbo
c.      Awon onigbagbo ti won bikita nipa ohun temi, won fe gbo won si fe sise fun Olorun.

(2)              IJO TI SMYRNA REV 2;8-11
1.      Ibi ti a ran si – Smyrna
2.      Apejuwe – Emi ni eni isaju ati ikehin, eni ti o ku ti o tun ye.
3.      Oriyin – Ijo ti a se inunibinii si ti o sit un je otusi, won je otusi nipa ti ara sugbon won je eni ibukun nipa tie mi, bakanna ni won nfi oore-ofe nla farada iponju.
4.      Idalebi – Ko si idalebi fun won
5.      Imoran – Maberu, je olooto de oju iku. Jesu wipe esu yi o gbe ninu yin ju sinu tubu bakanna pelu ni e o ni inunibini orisi mewa gege bi a tumo re fun ojo mewa, orisi ijiya mewa ni o nduro de yin.
6.      Ileri – Eyin ki o se alabapin ninu iku keji bakanna pelu ni ade iye.


10/3/08
(3)              SI IJO TI PAGAMU (REV 2:12)
i.                    Ibi ti a ran si – Pergamu
ii.                 Apejuwe – Eni ti o ni ida mimu oloju meji lo.
iii.               Oriyin – Eni ti o ngbe ni ibi ti ite satan wa ati ti o si pa igbagbo Kristi mo ti ko si se
iv.               Idalebi – Fifi aye gba eko Balamu, Nikoli atan; pansaga, iborisa ati eko eke
v.                  Imoran – Ronupiwada
vi.               Ileri – Manna ti o pamo ati okuta kan ati oruko titun kan

EKO BALAMU
Balamu je alafose bi o tile je woli.
AWON EKO EKE NI PERGAMU
1.      Gbigbadura fun oku
2.      Lilo ami agbelebu
3.      Jijosin fun oku, maira mimo ati awon Angeli
4.      Won da awon ase Mose sile
5.      Jijosin fun Maria (Maria mimo)
6.      Eko ni pa Pogatori

(4)              SI IJO TI TIATIRA (Rev. 2:18-29)
1.      Ibi ti a ran si: Tiatira
2.      Apejuwe: Eno to o ni oju bi ina ti o njo lati owo ina, ti ese re si dabi ide daradara.
3.      Oriyin: Mi mo ise re, ife, igbagbo, ipamora ati suru re isinsin yi tobi ju ti isaju lo.
4.      Idalebi: Fife aye iborisa ati ifekufe ati pelu Jesebeli woli obinrin ni.
5.      Imoran: E ma kiyesi ki e si ronupiwada, bakanna ki e fie se ohuntoku mule.
6.      Ileri: A o fi ola fun isolootito, a o si wo won ni aso funfun.

(5)              SI IJO TI SARDI (Rev. 3:1-6)
1.      Ibi ti ran si: Sardi
2.      Apejuwe: Eniti o ni emi meje Olorun ati irawo meje
3.      Oriyin: Emi mo ise re, pe, iwo ni oruko
4.      Idalebi: Oku ijo, ti nse apeere ijo ti o wa ninu okunkun biribiri.
5.      Imoran: E ki ye sara ki e si ronupiwada bakanna ki e si fese ohun toku mule
6.      Ileri: Ijolooto won ni a o fola fun a o si wo won ni aso funfun.

(6)              SI IJO TI FILADELFIA (Rev 3:7-13)
1.      Ibiti a ran si: Filadelfia
2.      Apejuwe: Eni ti o je mimo, otito ati ti o si ni kokoro Dafidi.
3.      Oriyin: Mo ti gbe ilekun sisi si iwaju re ti ko si si enikeni ti o le ti iwo ni agbara die o si ti pa oro mi mo ati pe iwo ko si se oruko mi.
4.      Idalebi: Ko si
5.      Imoran: Di eyi ti o ni mu sinsin ki enikeni ki o ma ba le gba ade re
6.      Ileri: Aye kan ni iwaju Olorun, oruko kan ati Jerusalemu titun.

(7)              SI IJO TI LAODEKIA (Rev 3:14-22)
1.      Ibitia ran si: Laodekia
2.      Apejuwe: Eni ti nje amin, olooto, eleri otito ati ibere gbogbo eda Olorun.
3.      Oriyin: Ko si
4.      Idalebi: Iwo je Ilowowo, oko gbona, o ko tutu, emi yio po o jade ni enu mi.
5.      Imoran; Rev 3:18-19 (Ni itara ki o si ronupiwada)
6.      Ileri: Sise alabapin ite Kristi.

IWE IFIHAN NI ILANA SISENTELE
            Iwe na je iwe isipaya eyi ni Ifihan tabi isisoloju, opo awon eniyan ti npon loju, ni won ti ko bi a ti nsoro ni ena, Johanu lo awon ena, awon amin ati aroko pelu awon oro ti o da bi isokuso ti ko ni itumo sugbon si awon kristieni awon ami ati ena ati iran yi ni itumo pataki ti re. Nitori na oro awon agba Aposteli wonyi raaye koja laru awon alase Romu pelu irorun ti o si de owo awon onigbagbo awon ti o yi o ka ti won yi o si loye ohun ti Johanu nba won so.
            A le fi irorun gba pe awon ami ati awon iran wonyi ko ye wa, nitori idi eyi awon ijakadi ati awon itumo bulabula nipa won. Bi o ti wu ki o ri arin gbungbun otito ti o daju n be nipe okokan awon iran meji ti o daju nibe lati da mo. A ma nwonu isoro ailalopin nigbati a ba ngbinyanju lati mo finifini gbogbo itumo awon aworan, awon erako, awon ipe, awon esin, awon igi, awon okun awon irawo ati awon bee bee lo.
            Iwe isipaya na je iwe ti o ni awon iran ati itumo re ninu, fun apere:
(1)        Iran akoko (Rev 10:3-22) eyi ni isegun na oluwa alaye ti o nrin larin yo re pelu idaniloju pe oun ni eni isaji ati eni ikehin, alaye na eni ti o ni kokoro iku ati ti ipo oku lowo.
(2)        Iran keji (Rev 4:1-8;11): Eyi ni iran odo aguntan na ti a pa ti o sin se akoso isele ati itan.
(3)        Iran keta re 8:2-11: Eyi ni awon angeli meje na pelu ipe meje, awon isoro ati awon iponju niyio se abe wo si odo awon ti ko ronupiwada, sugbon ni ikehin isegun si odo awon eni ti won nsin olorun.
(4)        Iran kerin (Rev 12-14) A ri awon amin orisi meje eyi ti o se ni igbehin pelu isegun fun ododo
(5)        Iran karun (Rev 15-16) A ni aworan awon angeli meje ti o wo lati tun agbana ibinu Olorun da sori aye
(6)        Iran kefa (Rev 17-19) Eyi nso nipa iran idajo pansaga ni ti o joko lori opo omii. Bakanna mo ori ogun ni a ti so nipo mimu ati dide Satani
(7)        Iran Keje (Rev                         ) eyi ni aworan asepe awon itan. Nihin ni a ti ri orun titun ati aye titun ati ti Jerusalemu titun to n so kale bo lati odo Olorun.

ITE NAA NI ORUN
AFIHAN: Iwe Ifihan pin ara re so meta ti o se pataki okookan re ni a salaye ninu ese “ko ohun na ti iwo ti ri” awon na ni wonyi ohun ti o ti kojo lo ati awon ohun ti o wa ti nsi ohun ti lowolowo ati awon ohu ti o hu lehin nkan wonyi. Eyi ni ti o jo iwaju.
            Ori kinni ni eyi ti o kan fun eyi ti o ti koja nipoa ti ori keji ati iketa nso ti lowolowo sugbon lati ori kerin titi de opin iwe na ni ti ojo iwaju.
ITE NAA
Gege bi ese ikesin ori kini ti so, Johannu ni a ti gbe lo si erekusu kan ti an pe ni patimo si nitori igbagbo re nibe ni o ti gba iran pe kokoro ti o si gbogbo iwe na wa ni ori keje ese kinni “kiyesi” o nbowo ni awosan gbogbo oju ni yio si ri ati awon ti won gun loke ati gbogbo eniyan inu aye ni yio ma po ihinrere niwaju re.
            Iwe isipaya yi je osiso loju Jesu Kristi nipa awon ohun ti o nise pelu wiwa re lekeji.
            Johanu ni a fi ite kan han fun ni orun ite Olorun. Awon agba gba merindinlogun si yika gbogbo won ni a si won ni aso funfun pelu ade wura ni ori won, mona mona, ara ati ohun njade lati ibi ite na, opa fitila meje nbe ni iwaju re. Larin re ni awon eda alaye merin wa, eda bibeli kan si pe ni awon eranko niwaju ite yi ni a ti ri okun bi dingi.
            Ni osan ati ni oru ni awon eda alaye wonyi njosin ti won sin yin Olorun ti won nwipe ‘mimo, mimo, mimo’ Olorun  Olodumare re ti o wa ti wa ti o si nbo wa ati bi wpm si ti n yin eni ti o wa laye titi laelae beena ni awon agba merinlelogun na wo lule ti won si josin ti won si fi ae won lele ti won si kigbe pe Oluwa iwo ni o ye lati gba ogo, ola ati agbara nitori iwo ni o da ohun gbogbo ati fun ife inu re ni a si da won.
            Iru iyanu nla wo niyi, koha je ohun iyalenu lati ri pe laarin opo ite ti o wa lori aye a ri ite kan ti a gba kale ti a pe ni ifidumule, ite kan ti ko le kuna. Bawo ni ite ati ijoba yi se ni abo to nitori na ni ite na se wa ni arin gbun gbun eyi ti o tumo si pe ijoba kan lo da duro sinsin.
            Bayi isele na yi pada. Ni orin na ni a si iwa o niwaju ite, sugbon iwe kan farahan angeli kan si kigbe ni ohun re sa fun enikan ti ko si enikan ti o dahun beni Johanu bere si ni sokun. Agbalagba kan si salaye fun pe Jesu Kristi ti bori lati tu edidi naa ti o si bee ki o ma sokun mo. Odo agutan kan farahan, odo agutan to a ti pa. Ohun na ni Jesu Kristi eni ti o gba iwe ne ni owo Olorun.



Ni kete ti awon agbagba bati wo lule niwaju re ti won si ko orin titun na ni ako papo “Iwo ni o ye lati gba iwe na ati lati si awon edidi re nitori iwo ni a ti pa ti o si ti raw a pada nipa eje re lowo gbogbo iran eniyan ati ede ati orile ede ti o si ti so wa di oba niwaju Olorun wa ati alufa re, awa yi o si joba lori ile aye Odoagutan na kin se elomiran bi ko se Kristi fun rarare, nitori oun nikansoso ni olurapada.

AWON EDIDI MEJE NAA
AFIHAN: E ki a ni lokan pe isi edidi merin akooko ni o sele ni kete lehin ipoju gege bi asese akosile re, ati pea won wonyi nitorina ni edidi siwaju iponju. Awon elesin merin ti a fihan wa ni o ha gbangba pe won    aini simi, lala ati darudapo, nitori a ko ti lo esin ninu bibeli lati se alaye alafia ni.

AWON EDIDI MEJE
(1)              Esin akoko je funfungboo nihin ni a ti ri asodi si Kristi tabi Messiah eke, eni ti a jade wa ni ibere odun meje ti o kehin ninu ose aadorin ti Daniel, eyi ti yio mu ki ijoba buburu eyi ti o nti isegun de isegun bere.
O di olori fun Ijoba Romu ti o jinde, o si bori meta ninu awon ohun mewa ti won dide lodi si, o si gbe ara re kale gege ori lori awon meje to ku, o si mu gbogbo aye wa ni iteriba fun.
(2)              Esin pupa na ni ese iketa ati ikerin nse apejuwe ogun eleyi ni o si wa ni pi pe ti o wa ni Matt 24. Ko le si alafin labe ijoba asodi si Kristi rara yato si akoko alaafia nigba ijegaba. Lati igba na lo ijoba re ni yio te le itajesile.
(3)              Esin dudu na ni ese ikarun ati ikefa ni o nse apere eniyan.
(4)              Ni ese 7-8 Esin randanrandan ni ajakule arin ati iku bi o ti je wipe awon nkan wonyi bani leru. Won si buru sugbon sibe won kan je ibere wahala eyi ti a ri ni ibere odun meta abo akoko ni awon ni won silekun fun iponju nla niga ti ajalu ti iponju nla yio bere.
(5)              Labe sisie edidi ikanrun yi eyi ti a leri ni ese ikesan titi de ese ikokanla, iponju nla ti bere eleyi ti o je akoko kan na igbehin pelu ose meje ti o kehin Daniel ati ti o si fi ori so isele ti ti o wo ni Matt 24, opo ni a pa ati gege be a si ti ri ifarahan ninu iwe Psalm, awon eni na nkigbe fun esan, sugbon a so fun won ki won mu suru fun igba die titi ti a o fi pe awon ajeriju miran ti yi o ku iye won nitori opin iponju na ko iti de.
(6)              Edidi yi ni o mu wa lo si ipada bo Kristi mu agbara ati ogo ati lo si akoko ti awon eniyan yi o fi ara won pamo ninu oke ati apata ti won o si ma kigbe pe e wo lu wa ki e si fi wa pamo kuro loju eni na ti o joko lori it ati kuro loju ibinu odo aguntan nitori ti ojo ibinu nla re ti de lati igba na ni won si ti mura fun igba ifarahan ibinu Olorun ati pe isele na si ni se pelu ipada wa elekeji.

AWON IPE MEJE NAA
Ni kikoju lara ori keje eyi ti n se Parentisi (Parenthesis) ti ki nse ara bi a ti n to isele nab o, a o tun tesiwaju ninu alaye naa lekan si ni ori kejo, nibe ni a ti ri didun ohun ipe meje, ninu ese akoko ni a ti si edidi keje ati pe bi o ti ma n ri tele, dipo isele kan soso a ni, labe edidi yi ohun gbogbo awon ipe mejeje.
            Awon ipe wonyi ni a ranti te gege bi ohun ti o mu idajo Olorun wa a si fo won ni akoko ipari iponju nla. Asodi si Kristi na ti joba fun bi odun meje bayi, akoko ipari re si ti wa ni tosi, sugbon ki e to dip e a fi iya je, aye aigbagbo yi ni o ti be wo pelu idajo Olorun Olodumare.
(1)              Ipe akoko ni ese keje:
Ipe akoko ni ese keje ni o pa idakan ninu meta awon igi ati awon ewebe ru.
(2)              Ikeji ni ese ikeje ati ikesan so idamewa omi di eje won si pa idameta eda alaye inu omi run won si baa won oko je.
(3)              Ipe keta ni ese ikewa, so idameta awon omi di kikoro o si fa iku fun awon ti won ba gbiyanju lati mu omi na.
(4)              Ipe kerin ni ese ikejila, ni o so idameta awon orun, osupa ati irawo di dudu eleyi ni o siran wa leti iru ajakale arun ti o sele ni Egypt nipa se Mose. Ni asiko yi idani duro die wa bi won ti n fin ipe na, angeli kan si farahan ti o nfo kiri ni orin ati ti o si kigbe pe egbe, egbe, egbe, fun awon ti o ngbe orile aye nitori ohun ipe awon angeli meta ti o ku eyi ti won ko iti fun, idi fun eyi ko soro lati mo. Awon idajo merin akoko le buru won merin akoko le buru won bani leru gege ni o tiri, sugbon won si mo niwon, ti a ba fi won di won, awon meta ti o nsi nbo. Siwaju si won ni se pelu eda tara nikan (physical nature) nigbati awon meta na awon meta ti o kehin yi buru jojo dip e a n pe won ni awon ipe igbe.
(5)              Nigba ti a fun ipe karun eyi tin se egbe akoko a si ogbun ainisale ni eyi a npe oruko ni iho ogun ninu eyi ti awon emi aimo ti apeni eesu ngbee pelu agbara akeke ni a tun jade. Won wa ni eto eto nitori ti won ni oba lori ara won. A ko gba won laaye pe ki won pa eweko lara lati igi ati ohunkohun ti o to bi ewebe, sugbon pa lase lati doju ija ko eniyan ki won si da won loro ani gbogbo eniyan ti ko ni edidi Olorun ni iwaju ori won sibesibe agbara won mo ni won ba, tori a ko gba won laaye lati pa eniyan sugbon ki won mi idaloro ti a ki le fen u so da fun bi osun marun. Iponju yi yioje eyi ti o ba ni leru nitori ti awon eniyan yi o ma wa iku sugbon ko ni sese fun won lati ku.
(6)              Bayi nigbati ipe kefa dun awon angeli ki a tu sile o dabi pe won ni agbara lati pa awon eniyan ati lati po awon eniyan ru eyi ti o ja si pe idajo won pa idameta awon eniyan aye run, gbogbo irubon awon jagunjagun na je ogorun meji milionu (200,000,000). Iye awon ti o koja iwoye wa. Ise iparun ti o gun esi bikose lati owo awon esin na fun rara won.
A o tun fo ori kewa nitori ti ohun na je perentesisi ati abale akoko ninu ori kokanla a o si tesiwaju lati ma wo egbe keji ni ese ketala, nitosi ipari ipe karun isele nla kan sele omimi kan si mi eyi ti o ba idankin ninu mewa awon ilu je ti o si pa egberun meje awon eniyan o je ohun ti o buru fun igba akoko awon ti o bo ninu wahala yi kun fun eru gidigidi, won si mo pe owo Olorun ni o wa lara nkan.
(7)              Egbe keta ni o sele kankan nig be ti angeli keje fun ipe na ni kankan ni a si mu wa wa si irati ijoba aye ati ijoba aye ti di ti Oluwa wa ati Kristi re. Oun yi o si joba titi aye.
Bayi ni a gbo nipa ikede ibinu Olorun lekan si. Akoko si se ni orun. Awon egbe akoko ni han gbangba pe won wa lati pase iponju, sugbon a ko won yo nipa iselojo Olorun. Sugon awon keji jade lati inu re, “Awon won yi ni won jade wa lati inu iponju nla” ni iwe mimo so. O wi ni w ape a gba awon kan la ni akoko asodi si Kristi.
            Laisi iye meji awon egbe ti a toka si ninu Iwe ifihan ori kerinla Ese karun (Rev 14:5) je awon kan na pelu awon ti ori keje. Isele eleyi sele lorile aye ni Jerusalem lehin igba ti Jesu ti pade de. Yi ka re ni a ri awon oke meje ole egbaji e si je ki a se akiyesi pe edidi baba re wa niwaju ori won. A si so nipa ti won pe won si tele odo aguntan na patapata ti won si ti gbe igbe aye iya soto kuro ninu idibaje. Igbe aye mimo ni o je idiwon won nigbati won wa lori ile aye been ni won ko si dibaje nipase awon ohun aye yi nitori ti won tewo gba odo Olorun ninu Jesu Kristi won je alailabukun won je alailebi patapata. A ran won pada lati inu awon eniyan won je eni irapada lati inu eje Jesu Kristi.
            Iru iran nla wo la fi han wa yi nipa awon egbe keji ti won je keferi sugbon ti won je oke aimoye, a gba won la larin iponju bayi nikehin won si wa ni orun. O ti han gbangban pe Olorun kin se ojusaju eniyan nitori gbogbo orileede ati eya ni o ni asoju. Pelu ayo ni won farahan niwajuu ite olorun ti won si ke pe:- “igbala ni ti Olorun wa ati ti odo aguntan re” ni idahun si re ni awon angeli, awon agbagba ati awon eda alaye merin wo le ti won si sin Olorun ti won si pari wo ni ohun kan pe:- “ibukun ati ogo ati ope ati idupe ati ola ati agbara ati ipa fun Olorun titi lae ati laelae”
            Nibe ni won ti duro, ti won si wo aso funfun. “Tania won wonyi ni okan ninu awon alagba bere, Johanu si fesi iwo ni o mo” pelu ohun isegun ni o fi fesi na, iru isipaya yi ni awon ti won jade lati inu iponju nla ti won si ti fo aso won ti won si ti so won di funfun ninu eje odo aguntan ti won si n sin losan ati loru niwaju tempili re, eni  ti osi joko lori ite naa yio o ma gbe arin won. Ebi ki yio pa won mo beeni oungbe ki yio gbe won mo beeni oorun ki yio pa won mo ni ohunkokan nit un odo aguntan tin be ni ori ite ni yo ma  bo won yi o si deri won lo si ibi orison omi, Olorun yi o si nu omije gbogbo nu kuro ni oju won”
                        Rev14:1
                        Awon Eleri Meji
            Ni titesiwaju ni oju ewe pere ntisisi a o koja si ori ‘ikookanla nibe ni o o ti ri ni ese ikeji  wipe akoko iponju nla yi o wa fun osu mejilelogun (42 months ) ninu eyi ti o je pe odun meta ati abo ni nigba na ni agboro ijoba keferi agbaye yi o gbo gbogbo isakoso lori jerusalemu
            Bayi ni a ri awon eleri meji ti won fi ara han eni ti won je ni a ko mo. Malaki so fun wipe Elijah yi o pade wa ki ojo nla oluwa ki o to de Malk 4:3. Ese ikefa (Rev 11:6) won ni iru agbara kan na ti Mose ati Elijah ni nitori ti won se orun fun ogo, won si so awon omi di eje, won si fi oniruru ajakale arun ko lu aye. Nitorina o sese ki won je mose ati Elijah.
            Olorun ko ti fi ara re sile ri lairi eleri, koda ani akoko iponju nla akoko ti o sokunkun julo ninu itan agbaye, o si tun ni awon eleri re.
            Won yi o si asotele fun ojo ( 1,260), egbefa ojo-o-le-ogota eyi ti o tumo si osu mejilelogun bakan naa odun mefea ati abo eyi ti nse gbogbo akoko iponju. Eri won ni a o se akiyesi pe o parri nigba ti won fun ipe kefa eyi ti nse egbe kerji.
            Won si gba agbara lati pase emi mimo gege bi ese ikerin ti so won yi o ma tan gege bi imole Olorun ni agbegbe meji okunkun aye ni pelu gbogbo idaniloju ni won yi o ma kede fun aye aigbagbo ti a ti tan jee yi nipa otito nipa aisodi si Kristi won yi o si sipaya gbogbo iro ati etan re won o si kilo fun awon eniyan ni pa iparun ti o nbo wa ba
            Awon iranse Olorun ti won duro ni gbungbun ife re ni won je aiku titi ti ise won lori ile aye yi o fi pari. Gege bi ese ikarun ti so awon eleri meji ni a pamo kuro lowo ibinu asodi si Kristi titi ti won o fi pari eri won.
            Nipari ni arin meji nipa pipari ipe kefa ni a pa won lati owo asodi si Kristi fun rara re, ati fun ojo meta ati abo ni oku won fi wa ni igboro Jerusalemu lai gbe won sin, ni igba ti gbogbo aye bere si ni nyo ayo isegun lori won.
            Sugbon wo o, ki o si kiyesi, ni opin ojo meta ati abo na, si iyani lenu gbogbo eniyan, won jinde lojiji. Bawo ni o se je iyani lenu fun gbogbo eniyan to nitori fun odidi ojo meta ati abo ni won ti n fi eebu ranse si ara won.
            Bakanna ni awon onirohin, ni gbogboidaniju ni won, ti ngbe awon akori orisirisi jade ninu irohin ati ti won si ti nko arisirisi oloto nipa isegun alagbara agbaye yii lori awon asoju Olorun ti o keryin ni aye.
            Bawo ni yi o se ri nigba ti awon ago ara mejeji won yi fo dide lori ese won  sugbon [won ki yio raaye wo pepe, nitori ti ohun kan wa lati orun ti o si nsoro ti won si gbo ase na, “E Goke Wa Ihin”. Ni gere lehin na ni ese won kuro ni aye ti won si ngoke lo ninu awosanma, nigba ti awon ota won ti won poo ni egbegberun ni iye bere .si ri won.
            A o ranti ninu awon eko wa nipa egbe keji, a ripe lai to wakati kan lehin ti won goke lo ile mimi buburu kan si ba idamewa Jerusalemu je ti o si gbe emi ti o to egberun meje ati si eyi fun igba akoko, iberu bojo mu okan awon eniyan ti o fi de bi pe ni onakan tabi omiran won mo ri ri Olorun
     
1                    Wura                                2          Fadaka
3          okuta iyebiye                  4         Perili
5         Aso ogbo weewe             6          Elese aluko
7         Seda                                   8          Ododo
9         Igi Olorun didun              10        Eyin erin
11       Igi iyebiye                        12        Ide
13       Irin                                     14        Okuta marble
15       Kinamoni                          16        Ohun olorun didun
17       Ohun ikunra                     18        Turari
19       Oti wainni                         20        Ororo
21       Iyefun daradara               22        Alikama
                 23        Eran nla                            24        Aguntan
                 25        Esin                                   26        keke   
                 27        Eru                                     28        Okan eniyan
                 29        Eso                                     30        Ohun gbogbo ti o dun
Ohun gbogbo ti o wa laye niyi ti aye feran ti won ko se ma dun orun sugbon lojo ti Olorun yio bar o ojo ina le awon nkan wonyi lori, ti o je aye loju.

                        AWON ORUN TITUN ATI AYE TITUN
            Ogo ti o koja fi fi enu so ni a se alaye re ni orikokanlelogun iwe yi lehin gbogbo ibanuje ati iponju ti o ti koja lo. O o bawo ni okan awon woli yi o ti se gbira je nigba ti o nwo awon iran iyanu yi “mo si ri orun titun ati aye titun, nitori ti orun isaju ati aye isaju ti ko ja lo” o pari wo bee.
            Bi johaanu se now aye titun yii, lojiji ni itejumo re yi pada ti o sib ere si ni wo ilu mimo daradara nii, Jerusalemu titun ibugbe olorun fun rara re, ti o titun ibugbe olorun fun rara re, ti o nsokale bo lati orun. HA! Iru ilu daradara wo ni eyi, apejuwe re koja ogbon ati oye eniyan.
            Se ki o so ti awon okuta iyebiye inu re ni, tabi ti enu ona peril tabi igboro re ti oje ti wura gege bi apejuwe ti o ni imisi, “ilu naa ko nilo oorun bakanna ni ko nilo osupa lati ma tan imole fun nitori ogo olorun ni o ntan imole re ati odo aguntan si ni imole ti o wa nibe” Nitori naa “ki yi o si orun nibe”
            Ori ti o gbeyin iwe na fun wa ni awon aworan “odo mimo kan, ti o je omi iye, ti o mo gara bi kristali, ti o si njade lati ibi ite Olorun ati ti odo aguntan” o nso fun wa nipa igi iye kan ati eso re ni orisi mejila a ni igi kan ti o nso eso ni ososu.
            Iwe naa pari pelu ileri ti o logo nipa sisun metile ipada bowa oluwa ese ikeje wi pe “kiyesi emi nbo kankan” ese ikejila kede re pe “si kiyesi emi nbo kankan ere mi sin be pelu mi lati san fun olukuluku gege bi ise owo re o ti ri” ese ogun salaye wi pe “nitoto emi nbo kankan. Lehin na ni Johanu wa fi kan pe “ma bo jesu oluwa”        

No comments: