Wednesday, June 6, 2012

IFOJUWONLE BIBELI APA KINI


Ifojuwonle bibeli apa kinni
Ifojuwonle Bibeli: Yoo fun wa ni anfanni lati ri Majemu laelae lerefe.
A o tejumo awon koko ati awon isele ti o ni ohun se pelu eko wa. Eko yi ko le fun wa ni iroyin lekunrere lori gbogbo koko tabi otito inu Bibeli, sugbon yoo je eko ti o da lori awon iwe ti o wa ninu majemu laelae. Eko yi yoo te oju wa mo eto Olorun lori opolopo asiko ninu itan iran eniyan.

Eto olorun fun iseda
Olorun kii se Olorun bo-ba-ti-wu-kori, o je Olorun ete ati eto. Ki se Olorun eesi, o je olorun ti ma yan ti o si ma nni ere idi fun ohun ti o ba yan. Omowe kan beere lowo akeko re ibeere ti o se koko yi: “Taa ni o da aye yii?” ki awon akeko yi to fesi si ibeere omowe yi, ara san gbogbo yara ikeko si mi tipile tipile. Gbogbo won pa kese. Omowe naa wipe “ohunkohun ti mo ba wi nisisiyi ko le ni itumo ti o to ti ara ti o san yi. Onikaluku e maa lo ile yin” Gbogbo awon akeko rerin, ara gbogbo won si bale pese.
Leyin ti gbogbo awon akeko yoku ti jade, okan ninu awon akeko naa tese duro o si nba omowe yi nforo jomi tooro oro po. Akeko na wipe “Ara yen ran mi leti ese Bibeli kan, ninu Orin Dafidi 29:3 ti o wipe Olorun ogo nsan ara……” Omowe naa fesi pelu ese Bibeli miran: “Awon orun nroyin ogo Olorun, ofurufu nfi se re han.”

OLORUN NI ETO: O han gbangba lati inu iroyin Bibeli ati ninu ara ti nsan loke pe Olorun ni o da aye yi. Ko le si aworan kan laisi oluyaa re. Leyin aye ti a ya daradara ti o si lewa yi, Oluyaworan Nla kan ni lati wa nbe.
Bibeeli so wipe “…..Olorun da orun oun aye,” Gen. 1:1. Olorun ko kan taji lojo kan ko sib ere si ni da aye, o ni eto tabi ipinnu Re ni Bibeeli pe ni “Ipinnu Ayebaye” tabi “Eto Ikoko”. Efesu. 3:11.
Saaju ki a to da awon orun ati aye; ari Olorun: Baba, Omo ati Emi Mimo seto won si ya batani fun aye yi.
ISEDA Heb. 1:1-2; 11:3; Gen. 1:2 Agbara iseda Olorun wa ninu ORO RE. Ni gba ti akoko to lati mu awon eto tabi ipinnu Re wa si ise, o soro, gbogbo awon eto Re si farahan lojukoju. O da imole ni ojo ekinni, o ya omi lara omi, osi mu ofufuru wa ni ojo keji. Ni ojo keta o fe ki omi ti isale korajopo si apakan o si pee ni Okun. O mu ki iyangbe ile jade wa, o soro si iyangbe ile ati ewebe, igi ati oniruuru ohun ogbin jade wa. Ni ojo kerin Olorun pase ki oorun, Osupa ati awon irawo ki won wa, o si mu ki won maa gbe ni awosanma nibiti won yio ti ma nsakoso osan ati oru. O pase ki won wa fun igba ati akoko. Ni ojo karun Olorun ba oni soro pe ki o mu awon eda kan jade. Ni ojo kefa o da awon eranko, o tun tesiwaju lati fi erupe ile mo eniyan, eyi ti nse ade ori gbogbo iseda Re, ni aworan ara Re gegebi iri Re ni o daa. O mi eemi iye si iho imu eniyan, eniyan si di alaaye okan, eyi ti o yato gedegede si awon ohun ti o ku ti o da. Olorun fe eniyan. O si moomo fi joba lori gbogbo ise owo Re. Gen 1:1-31; 2:1-4.
BI OHUN GBOGBO TI JE AIRI: Awon akosile ibi ti a ka ninu Bibeli ti o wa loke yi fihan wape Olorun ni o da aye ati ekun re. Bibeli fi idi re mule pe Olorun lo ORO RE lati da ohun gbogbo ti a le ri loni. Johannu. 11-3; heb. 11:3. Awon onimo ijinle sese se awari otito ti o ti o wa lati ojo pipe ninu Bibrli ni. Won sese ri daju pe ohun gbogbo ti o wa ninu aye lafi awon ohun ti a npe ni atoomu, elekitronu, protonu ati ninu neutronu, gbogbo eyi ti ko see foju ri da.
AWON DAINOSOOSI: Dainosoosi je eranko nla eya eda afayafa to ko si mo. Awari Dainosoosi (ibeere ati iparun won) ti mu wahala nla baa won eniyan ni gba ti won ba nronu nipa iseda. Nibo ni awon eda wonyi ti wa? Eese ti Bibeli ko menuba won rara? A mo wipe ko seese ki Bibeli menu ba ohun gbogbo. Fun apeere, Bibeli ko menu ba oro ologbo, sibe a gbagbo pe Olorun lo da ologbo. Nitoripe Bibeli. Nitori pe Bibeli ko menu ba oro Dainosoosi, ko ni nkankan se pelu pipeye Bibeli. Bi o tile je pe Bibeli ni o je ki a ri awo ojiji won ninu itan iseda inu Bibeli. Ti awon Dainsoosi ba je eda, a je wipe won wa lara orun ati aye ti Olorun da ni Gen. 1:1. Olorun pa aye akoko run eyi ti Dainosoosi naa wa ninu won, aye si wa wa ninu okunkun laisi eda abemi kankan nibe. Olorun si wa tun aye da bi a se rii loni.
Awon otito iwakusa kan wa ti o fi idi re mule pe iparun ojiji kan sele ti o seese ki o mu Dainossosi na dani ni aye atijo. Ale fi iparun yi si akoko saaju atunda aye ti a ti moo loni yi.
ALAFO EKO NAA
GENESISI WIPE:
ALAYE WIPE:
Ni atetekose Olorun da orun oun aye Gen. 1:1
Ni akoko yi ni Olorun da Dainosoosi.
Aye si wa ni juju o si sofo (odi ofo ko si see gbe) okunkun si wa loju ibu… (1:2)
Nigba yi ni gbogbo Dainosoosi ku (Jer, 4:23-27)
Olorun si wipe je ki imole ki o wa……….. (1:3)
Ni gba yi ni asiko ti Olorun bere si ni tun aye da fun awon olugbe inu re lojo oni. (Isa. 45:18; O.D 104:30).

Aworan oke yi salaye ohun ti a npe ni Alafia Eko naa nitori ifura pe alafo kan wa laarin iseda akoko ati iseda eekeji.
Iseda Akoko
Akoko Alafo
Iseda Tuutu
Akoko Dainosoosi
A pa awon eda akoko run
Olorun da awon eda bi a ti ri won loni.

A ko le fi idi aheso oro yi mule, nitori naa a ko le pee ni otito ponbele. Sugbon sa, otito naa duro laelae pe Olorun se eto aye yi, oun ni o daa ti o si see lati gbe fun eweko, eranko ati eniyan.

ETO OLORUN FUN OKUNRIN ATI OBINRIN AKOKO
Opolopo awon aheso oro ti o ni imisi esu ninu ni o wa lode lati tako otito oro Olorun ti ko lee mi laelae. Awon eyiti o gbajugbaja ninu awon aheso naa ni Aheso Ilalehun. Aheso yi gbagbo pe aye yi kan hu yo nipa “awon isele kan”, sugbon Bibeli duro lae! O fihan wa gbangba pe Olorun kii se bi o ba ti ri. A maa seto nkan Re. Eniyan ko lale hu. Olorun fi eto Re han gbangba. E WA E JE KI A DA ENIYAN NI AWORAN WA ”Gen. 1:26, 27-31; 2:7-25.
Olorun seto ki okunrin akoko dabi oun. O seto lati se okunrin akoko ni aworan ara Re. gege bi eto Re, o se eniyan dabi Re. Olorun je metalokan, Oda eniyan lati ni emi, okan ati ara. Olorun ni imolara, o si fun eniyan ni imolara. Olorun le ronu, bakan na ni Oda eniyan ni agba ironu. Olorun le soro a da eniyan pelu lati lo oro enu lati salaye ara re. Olorun je alakoso, o se eniyan naa lati sakoso lori ohun gbogbo ti o da. Olorun nfun ni ni iye, o si da eniyan lati mu iye wa sinu aye nipa ibimo.
IDANWO NAA: Olorun tun ni eto lati dan okunrin ati obirin akoko wo. Satani ti pe Olorun nija ni gba kan ri. O saaju idakan ninu meta awon Angeli lati sote si JEHOFA sugbon o kuna. Lati igba naa ni ipo re lorun ti sonu. Olorun si pinnu lati lo eda ti ko lagbara to satani lati ni ohun ti satani nlepa, eleyi si waye lati kan satani labuku sii ki idajo ikeyin to waye.
Olorun seto lati gbaaye fun esu lati dan Adamu ati Eefa wo. Olorun mo pe won yo kuna idanwo naa. O ti seto eleyi sile paapaa ninu iru ohun elo ti Olorun lo lati seda eniyan.
1.                 Ko da eniyan ni eda ti nwa laaye lae.
2.                 O se eniyan ni amo ti a ko fi ina sun ki o le rorun fun lati yoro ninu omi (baptisimu), ki atunmo o le seese.
Olorun mo pe eniyan yoo subu, isubu naa yoo si fa owo aago seyin fun igba die ninu aye okunrin ati obirin akoko. Sugbon o tun seto pe lojo kan Oun yoo ran Omokunrin Oun wa sinu aye lati ra eniyan pada Gen. 3:1-15.

ETO OLORUN TI A BAJE TI A SI TUN TUNSE.
AMOKOKO: A so fun Jeremiah lati lo si ile amokoko ki o le ri bi amokoko ti n mo ikoko re, lojiji ikoko naa baje lowo amokoko. Jeremiah kiyesi pe amokoko naa gbe ipinni re akoko lori ikoko naa ti segbe kan. Amokoko naa ro ra gbe ikoko ti o baje yi lo sori okuta ilo amo, o si lo amo naa (iriri ti o nbo wa lojo iwaju ninu iribomi), titi ibi ti o baje naa fi kuro. O tun gbe amo naa pada sori keke ti o nfi-mokoko, o si fi mo ikoko isaaju. Amokoko naa wa sun un ninu ina (iriri ojo iwaju npa iribo ina Emi Mimo), lati le je ko wa bee. Ni gba ti o si tutu tan, o gbe kuro ninu ina, si kiyesi, ikoko ti o baje naa ti di awati!
          OLORUN : Olorun dabi amokoko. Olorun ko ko eniyan sile ninu ipa ibaje re ni gba ti esu mu eniyan dese si Olorun. Olorun mo pe isubu naa lee fowo aago eniyan seyin fun igba die. Bee ni Olorun yoo ran Omo Re sinu aye lati ku fun ese eniyan ki o le se atunda aworan ti o sonu, ti o si le fi ina sun un nipase Emi Mimo.
OHUN TI O SONU: Adamu ati Eefa so opo ohun iyebiye nu ni abayori ese won ninu ogba Edeni. Won so igboya lati ba Olorun rin nu. Won so idapo Mimo pelu Olorun nu. Won so aye won nu pelu, nitori won bere si ku, ara won bere si gbo aisan de, eru joba lokan won. Eefa so ayo re nu o si jogun ipinju. Ounje daradara sonu, o wa ku egun ati esusu. Won ni lati laagun ki won to jeun. Olorun le won jade kuro ninu ogba lo sinu aginju. Gbogbo nkan wonyi ati awon miran ni won padanu.
Amo sa, Olorun seto pe ki awon adanu wonyi ma je laelae. O seto lati da eniyan sinu ogo re isaaju ki o si tun le nii sii.
ONA ABAYO: Ona abayo meta ni Olorun la sile lati mu eniyan pada si odo ara Re:
1.                 O seleri awon omo fun won ati iru omobirin. Lojokan yoo ran omo Olorun wa sinu aye lati wa salabapin eda eniyan. Ki o si fo agbara esu ati ese lori aye won ni pa iku ati ajinde Re.
2.                 Olorun mu itiju Adamu ati Eefa kuro nipa bibo ihoho won pelu awo eran. Eleyi tumo si pe Olorun pa eranko kan lati ri awo re lo. Aso yi fun Adamu ati Eefa ni anfaani lati wa ba Olorun sugbon lati okeere. Iku eranko yi nfihan gbangba iru iku aropo ti Jesu Oluwa yoo ku.
3.                 Olorun seto pe lojo kan Oun yoo mu eniyan pada bo sipo patapata leyin iku won ati iku omo Re lojo iwaju – Iru Naa. Nigba naa ni a o fun won ni ara tuntun,  a o si mu won pada si odo Re patapata.

ETO OLORUN TI A GBA TI A SI TUN KO.
YIYAN NLA: Olorun se eniyan pelu agbara ati yan, ibasepo laarin Olorun ati eniyan lati igba isubu Adamu ati Eefa da lori yiyan. Eniyan, ni opolopo igba lo ni lati so pe beeni abi beeko si eto Olorun fun igbala. Yiyan yi lo si ma ntoka si iru ibi ti eni bee ti o ti gbe laye yoo ti lo ayeraye re.
Awon omo akoko ti Adamu ati Eefa bi ni lati yan ti won naa bi iwo ati emi, Kaini, akobi, ko ona Olorun sile o si mu ona tire pon. Olorun pelu si koo sile. Sugbon Abeli yan ona Olorun, Olorun pelu si tewogba oun ati oore re.                 Gen. 4:1-6. Olorun ko Kaini nitori  pe o sa igboran si ife Olorun ti a fihan, ni gba ti Abeli aburo re gbaa. “Nipa igbagbo Abeli ru ebo ti o dara ………..”  Heb. 11:4. O daju pe orisun igbagbo Abeli gbodo je nipa gbigbo lati odo awon obi re. Rom 10:17.
ONA KAINI: Nitori pe Olorun gba ebo Abeli o si ko ti Kaini, Kaini bere si ni se ilara arakunrin re eyi ti o sun lati paa, ti o si di apaniyan akoko laye. Iwa odaran yi je ki o gbe igbe aye adanu laye. O si di isansa.
Opo lo dabi Kaini loni ti won ko ni tele ona Olorun bikose ona ara won. Nigba ti Olorun ba si ko won sile, won a bere si ni se ilara awon eni diduro sinsin, won a si maa lepa won. Elomiran yoo tile maa ba oruko arakunrin re je kiri ki oun baa le wa laaye.
Aye ti nburu sii.   Leyin oro kaini ati abeli, ogooro awon eniyan ni o tele ona ti won. Awon kan gba eto Olorun,awon iyoku si koo. lwa obaje wa npo sii bi awon eniyan ti nko ona Olorun ti won si ngba ona ti ara won, eyi ti esu mu wa. Abajade ipo yi ni ese ti o npo si, iwa ipa si gbale kan. Olorun si wo kaakiri aye naa o si ri noa nikan ti o nrin niwaju oun. Olorun si wa pinnu lati pa aye naa re pelu ikun omi Noa nikan ati ebi re ni o ri ojurere lodo Olorun, eniyan mejo pere ninu gbogbo aye.Gen.6;5-7.
Ikun omi; Iwa ibi awon eniyan ninu aye dun Olorun de okan. Olorun pinnu lati pa iran eniyan re ki o si da awon si. Olorun fi asiri yi han Noa, o si pase fun un lati kan oko, Eyi ti gbogbo awon ti yoo ri igbala yoo wo. Noa gboran o si kan an. Ikun omi de bi Olorun ti seleri, ibi abo kan ti o wa laye ni inu oko naa. Leyin ikun omi Noa ru ebo Olorun didun si Olorun, inu Olorun si dun lorun ni gba ti o gborun okan imore Noa, ti a si mu un ranti irubo nla eyi ti omo re yoo se ni ojo kan. Olorun woye bi yoo ti dara to ti gbogbo eniyan ba le gbagbo bi Noa ki won si ri aabo ninu eto igbala re. Gen.7;10,12,,13,15,23; 8;1,2,19,20-22 Titi doni ni Olorun si nfi ife re han fun awon eniyan Re. O se ni laanu pe ko si okan ninu awon ti Noa gba bi osise lati ba kan oko naa lori igbala. Opo awon Onihinrere lo wa loni ti o je wipe oko lasan ni won nkan. Nitori owo nikan ni won se nse ise kii se Nitori igbala okan won. Bi o tile je pe Olorun gba wa bi osise, sibe o ye fun wa lati woo inu oko naa.

ETO OLORUN TI A TUN SO FUN AWON EBI OLOOTO.
Ile ise nla:  Leyin opo odun ti Noa olotito ti ku, awon eniyan inu aye tun so iwa omoniyan won ni won si tun lo sinu iwa ese si Olorun. Won gba Ara won jo lodi si ife Olorun ti a fihan. Won pinnu lati ko ilu kan, de iso kan ,ki won si Fun ni oruko kan.
Won pinnu lati ko ile kan ki won ba le maa gbe aye ominira kuro lowo Olorun. Ki a ma sakoso won ti sun won, won fe ominira. Won tun pinnu lati ko ile iso ti yoo ga de orun, ti o ba seese lati ma so Olorun. Ki ma ba da si oro won, tabi boya ki ile iso naa o je ibi aabo fun won. Paripari re nipe, awon naa fe da oruko ni fun ara won. E ha ti se ti won yoo maa je oruko mo Olorun ni gba ti awon naa le da oruko je fun ara won?
Olorun ko yi okan re pada lori oro re. o ti soro leekan pe ki won fon kaakiri, ni gba ti gbogbo won si pinnu lati ma fon kaakiri, a o ba ro pe olorun ko yi okan re pada lori oro re, o wa si da won ni ede ru, won si fi  ohun ti won nko sile. Lati igba naa ni aye to kun fun orisirisi eya ati orile tie de ya si otooto.
Olorun yan Abrahamu: Olorun mu Abrahamu re pelu eniyan duro lori eyo eni kan ati ebi re, awon eni ti o tun eto re si fun. Olorun si yan abramu tabi Abrahamu. Olorun pee jade nu Uri o si so fun lati lo si ile kan ti oun yoo fi han an. Olorun fi awon oleri nla kin ipe yi leyin. Olorun seleri lati soo di orile ede nla, ati pe oruko re yo din la, oun yoo bukun fun un, oun yoo soo di orison ibukun ati pe a o bukun fun gbogbo idile aye lati ipase re.Gen.12;1-4.
Abrahamu gba Olorun gbo, o si tele awon itoni ti a fun un. O fi ilu re sile, o si lo Olorun si ile ti  Olorun seleri fun u. Abrahamu ko iti bimo ni asiko yi, sugbon sibe o gba Olorun gbo,  eni ti o seleri pe oun yo fi ile ti naa fun iru omo re ni ini  Abrahamu ko opolopo pepe ni  kenaani lati fi igbagbo  re ninu Olorun han.o ba iyan pade, o ja ogun o si dojuko idanuto nla meji. Gen.12;25.
Idanwo kinni. Idanwo kinni gba abrahamu ni odun meedogbon. Fun awon odun yi ni abrahamu nreti imuse ileri Olorun nipa omo. Olorun fun un ni omo yi gbati o fee to omo ogorun odun. A pe oruko omo yi ni Isaaki. O wa di baba nla Jesu Kristi. Gen.21;1-5.
 Idanwo keji. Idawo keji ti Olorun fun Abrahamu dabi eyi ti o le ju ti akoko lo. Olorun ti fun un ni omo, o si ti fi idi re mule ni opo igba pe Oun yoo fi idi ete Oun mule nipase Isaaki. Nisisiyi, Olorun so fun abrahamu lati lo fi omo naa rubo si Oun. Bawo ni Olorun yo se le mu ileri lati bukun gbogbo idile aye se nipase Isaaki ti o ba ku? Sugbon Abrahamu gbagbo pe ti oun ba ti e fi Isaaki rubo sisun si OLUWA,OLUWA ni agbara lati jii dide kuro ninu oku. Odaju pe ko si ohun ti Olorun fe fi iku Isaaki se, o kan fe dan otito Abrahamu wo ni. Gen.22;1,2,10,12; Rom.8;31,32; Heb.11:17-19.
Itan josefu. Olorun tesiwaju lati maa fi e to Re han leyin iku Abrahamu pelu Isaaki. O tun eto re ti o so fun Isaaki, o tun soo fun Jakobu pelu. Olorun si yan okan ninu awon omo Jakobu ni gba ti o ya lati sapejuwe eto re. Opolopo afijo lo wa laarin Jesu ati Josefu. Awon arakunrin Josefu korira re, beeni awon arakunrin Jesu naa korira Re.
Awon arakunrin Josefu taa, a ta Jesu naa lati owo Judasi, arakunrin ti o sun mo. Awon arakunrin Josefu koo gegebi olori won bee naa ni awon Ju ko Jesu. Josefu Jiya ese ti ko da: Jesu pelu jiya ese ti ko da.
Leyin o rehin, won gba Josefu bi olori won bee gege ni Israeli yoo gba Jesu bi Oba won. Gen. 37:50.
Latari iyan ti o mu hanhan ni kenani, gbogbo awon arakunrin Josefu ati baba won sokale wa si egipiti lati wa se atipo nibe. Aadorin le marun eniyan ni o sokale wa si egipiti bi ebi kan. Nibe ni Olorun ti so won di pupo. O si sele pe nitori eru aibamo, a so won di eru ti won si. Ti won si nfi iya je won. A pa awon omodekunrin won, a so ninu won sinu odo Naile nitoripe won je Heberu. Nitori iponju won, won kigbe soke si Olorun, Eni ti o gbe enikan dide fun won lati gba won kuro ninu igbekun. Lati ibe ni Olorun ti bere si ni fi eto Re han, ki ise fun ebi kan mo bi ko se fun orile ede kan. Ekd. 1: 1 – 7, 13, 14.

ETO OLORUN FUN ORILE EDE KAN – IDASILE RE.
ORILE EDE AWON ERU. Awon omo Jakobu dagba lati Aadorin ole marun okan si bi egberun lona egberun kan. Lakoko, a toju won daadaa nitori pe Josefu di ipo ti o powole Farao mu.  Nigbati baba won ku, ti won si gbe oku baba won kuro ni Egipiti lo si kenani fun isinkun re, won ko ri ohun abuku kankan ninu gbigbe Egipiti won, gbogbo won tun pada si Egipiti leyin. Isinku baba won. Nigba ti Josefu arakunrin won ku won ko ri owe ile too lo, nse ni won fi lofinda oloorun didun sara oku Josefu won si duro ni Egipiti. Lehin o rehin, Farao ti nse ore Josefu naa ku, sibe won tun duro ni Egipiti. Won ro pe yoo maa rosomu fun won lo titi, ayafi igba ti Farao miran ti ko mo ohunkohun nipa Josefu fi gori aleefa ti o si bere si ni fiya je won. Nitori naa, won gbin, won ke, won kerora. Ekd. 2:23 –25.
AWON AJAKALE ARUN. Olorun gbo igbe awon eniyan wonyi o si ranti majemu Re pelu Abrahumu pe awon omo re yoo je eru fun orile ede ajeji fun irinwo odun, lehin naa oun yoo si tu won sile. Gen. 15: 13 –14. Olorun ninu otito Re yan okunrin kan ti a npe ni Mose lati da Israeli sile kuro ninu igbekun. Imurasile Mose je eyi ti o fanimora. O keko ninu aafin Farao, a si koo lati gba ipo Farao lehin ola ni Egipiti. O jade lati be awon Heberu wo lojokan, ko si le gba ohun ti o ri mora rara. O lu ara Egipiti ti o jebi pa, o si sin in. Isele yi de etigbo Farao, Mose si ni lati sa lo si Midiani fun aabo. Omo ogoji odun nigba ti o sa lo si Midiani. O  gbe ni aginju yi pelu Jetro gegebi olusoguntan, o si lo ogoji odun nibe ki  Olorun to pee lati se ise eyi ti  a  tori re bii.

Olorun mu Mose pada wa si Egipiti gegebi agbanuso Re, o si so oro Olorun fun Farao. Je ki awon eniyan mi ki o lo lati sin mi. Farao ko jale lati je ki Israeli lo, nitori naa Olorun bere si ni fi agbara re han lori  Farao ati lori awon ara Egipiti. Olorun mu ajakale arun bi eje, idin, esinsin, opolo, ina, yinyin, eesu, okunkun ati iku akobi ba won. Ninu gbogbo isele yi, ko si okankan ti o de ile Gosheni nibi ti awon Israeli gbe tedo si.

Lori  isele  ti o   kehin, ti  nse iku akobi, Olorun pase fun Isreali lati mu odo aguntan kan olodun kan, ki won o paa ni ebi jebi, ki won si  fi  eje re ami si opo enu ona ati aterigba ile won, nitori nibiti eje ba wa nikan ni Angeli apanirun yoo  daabobo. Olorun si se olooto si ileri re, gbogbo akobi awon omo Egipiti titi o fi dori ti  Farao ni o ku; latari isele yi ni a tu Isreali sile loko eru. O fe to egberun lona egberun lona meta awon eniyan ni won to lowoowo jade kuro ni Egipiti won koju si ona ile Kenani. Eks. 2:12.
EKSODU. Bi Isreali ti to lowoowo jade pelu oro ile Igipiti, iye Farao soji, o ro pe se oun yoo gba Isreali lati lo pelu iru oro bee ati iru ise ti won nba ounse? O wa pinnu lati lepa won. Olorun ajulo han Farao. Olorun pin okun niya niwaju Isreali, o si mu won koja ni iyangbe ile, Igipiti pelllu lepa won bo sinu okun, ni gba ti o ya olorun pase fun Mose lati na owo re sori okun lati da omi naa pada si aaye re, beeni ogun Farao  ri sinu okun.  Eks. 14:5-131.

A FI OFIN FUN NI: Israeli ti o ti di ominira wayi gbodo  ni agbekale, ni tori naa Olorun mu won wa si ori oke Sinai nibi ti  a ti fun  won ni agbekale gege bi orile ede to dangajiya. EKS 20:23. ofin yi wa fun ati dari won lori iwa hitiu ati ise si won. Lori oke yi kanna ni Olorun ti so fun Mose ki o pago ki olorun ba le gbe laarin won bi oba won. Ninu Ago yi ni a o ti ma ru oniruru ebo awon eniyan yoo sii le ni idapo pelu Olorun. Lef.4:27-31.

A BA OFIN JE. Mose eni ti o lo sori oke lati lo gba ofin pe niwaju Olorun, o wa nibe fun ogoji ojo. Oro naa su awon eniyan won si so fun Aaroni lati ya orisa fun won, eleyi ti o ba ofin meji  akoko je eyi ti Mose lo gba. Aaroni se egboro malu fun  won o si pee ni olorun won eyi ti o mu won goke lati Egipiti wa. Awon eniyan si bere si ni sin in, ni gba ti Mose ri ohun itiju ti Isreali se bi o ti nsokale lati ori oke, o le okuta ti a ko ofin naa si mole, o si foo ninu ibinu. O fi ina sun egboro malu yi, o si da eeru re sori omi ti awon eniyan naa nmu o si kan an nipa fun won lati mu omi naa. Ogunlogo awon eniyan lo ku latari ese yi. Mose ni lati sipe fun awon enia na ki Olorun to dariji won. Mose pe lu ni lati tun  pada sori oke fun ofin tuntun miran, lero yi, oun ni o fowo ara re han an sara okuta ni tori ti o fo ti isaju pelu ibinu. EKS.34:1-4

Ofin ti a fun Isreali so won di orile ede oto ti o nlo eya ijoba ti Olorun. Olorun pinnu lati fi won se awokose, orile ede  ti yoo ni itan agbayanu.

ETO OLORUN FUN ORILE EDE KAN NI IRIN AJO SI KENANI

IJIYA FUN AIGBAGBO: Leyin ti Israeli ti ni agbekale bi orile ede, Mose ran awon amin mejila lati lo se amin ile kenani, ki won si mu lroyin wa. Awon eniyan naa lo gegebi a ti ran won, awon meji ninu awon mejila ni won mu iroyin rere padawa, awon mewa ti o ku mu iroyin buburu wa. Iroyin awon mewa yi fa eru si ibudo Israeli, O si je ki won bere si ni kun si Olorun ati Mose. Won si  pinnu lati pada si Egipiti. Won fi oju wo arawon bi  elenga (Tata) legbe awon olugbe Kenani. Josua ati Kalebu nikan ni won gbagbo pe  Olorun ti fun won ni ile naa. Nitori isele yi Olorun je ki won maa rin kiri ninu aginju fun ogoji odun titi igba ti gbogbo awon ti ojo ori won to ogun odun ni gba ti won kun si Olorun fi ku tan ni aginju.
ADARI TUNTUN:  Mose ati Aaroni naa ku ni aginju, ni gba ti o ku die ki Israeli wo ile ileri, Olorun gbe okunrin  miran dide gegebi adari won, oruko eni naa ni Joshua. Mose ran Josua ati gbogbo Israeli leti ofin ati awon ileri Olorun. O ko awon ofin naa sinu iwe kan o si fi le Joshua lowo. Deut. 31: 1-13.
AWON OGUN BERE: Leyin iku Mose, Josua gori aleefa. O je jagunjagun. O ni oko ni owo re. Ko se ojukokoro opa Mose. Mose ti ku pelu opa re ni owo re. Josua ran awon Amin meji si Jeriko lati se amin ile naa. Iroyin ti awon amin wonyi mu wa fihan pe Olorun ti fun won ni ile naa. Olorun pase fun won lati yipo odi ilu naa  fun ojo meje. Ni ojo keje, Olorun wo odi ile naa. Won gbiyanju lati kolu ilu Ai kekere pelu iwonba awon ologun, sugbon kayefi ni pe Israeli sa niwaju ota won. Inu Josua baje gidigidi o si gbadura, Olorun si so fun pe, ese  wa ni ibudo. Akani ti mu ohun iyasoto ni Jeriko. Gbogbo ikogun ni Jeriko ni a gbodo ya soto fun Olorun. A yo Akani jade, Olorun si fi isegun fun Israeli.
A GBA ILE NAA: Opolopo isegun miran lo wa ti Olorun fun Israeli. Oba mokanlelogbon ni asegun, a si gba lara ile ileri. Josua pin ile naa laarin awon eya Israeli.  Awon omo Lefi nikan ni ko ni ile ini  bi awon iyoku, a kan fun won ni ilu laarin awon eniyan, ki  won ba le fa awon eniyan ti won ngbe laarin won sunmo Olorun. Josua. 24 : 1- 13. O se ni laanu pe Josua ko mura eni kankan sile ti yoo gba ipo leyin re, nitori naa, ni gba ti o ku, ko fi eyin sile fun enikankan pato.

ETO OLORUN FUN ORILE EDE KAN – LATI AWON ONIDAJO SI AWON OBA.
ESE SI OLORUN: Ni gba ti Josua  wa laaye,Israeli sin Olorun, sugbon ni kete ti Josua ku, awon eniyan naa bere si  se eyi ti o buru ni oju Olorun. Won bere  si ni sin awon orisa awon orile ede ti o yi won ka, nipa eyi ni won ri ibinu  Olorun. Nitori naa ni iye ti o yi odun ti won ba fi wa ninu ipehinda, nigbati ijiya won ba de oju e, Israeli a ronupiwada, won a si ke si olorun. Won, Olorun yoo wa gbe oludande kan dide fun won eni ti yoo da won nide kuro lowo awon ota won. Leyin itusile yi, oludande naa yoo sakoso tabi se idajo won fun iyoku aye re. Ni iru akoko bee, Israeli yoo sin Olorun sugbon leyin iku onidajo naa, won yoo tun pada sinu ipeyinda won. Onidajo. 2: 7 –19.
AWON ONIDAJO:  Opolopo onidajo ni o se akoso ni Israeli ni akoko laasigbo yi. Ninu ki awon onidajo yi je alufaa, jagunjagun tabi woli. Ninu won ni Ofinieli, Ehudu, Shamgari, Deborah, Baraki, Gideoni, Tola, Jairu, Jefta, Ibsani, Eloni, Abeloni, Samsoni, Eli ati Samueli.
Awon eniyan naa beere fun oba ni igba aye Samueli: Samueli banuje lori oro naa ni tori pe o ti sin pelu otito inu. Olorun si so fun un pe ki se Samueli ni won ko gegebi adari won sugbon Olorun ni won ko bi oba won. Olorun so fun Samueli lati fi ororo yan oba fun won. A si yan Saulu loba lori Israeli.
OBA SAULU: Saulu bere daradara, sugbon leyinoreyin o peyinda. Ni tori naa Olorun koo loba lori Israeli, Samueli si so fun un pe a ati gba ijoba lowo re a si ti fii fun aladugbo re. A ran Sumueli lati lo fi ororo yan Dafidi dipo Saulu. Akoko yi ni Israeli nba filistini jagun, Olorun si lo Dafidi lati pa olori ogun Filistini. Isele yi lo so Dafidi di aayo ni Israeli. Saulu gbe Dafidi ga o si soo di olori ogun Isele yi lo so Dafidi di aayo ni Israeli. Saulu gbe Dafidi ga o si soo di olori ogun Israeli. Ni gba ti o ya, iwa Saulu si Dafidi yipada. Lakoko, awon obinrin ile naa gbe oriyin nla fun Dafidi, won si fun Saulu ni kekere. Eyi si faa ki Saulu maa jowu Dafidi, ti o si bere si ni lepa emi re. Dafidi, eni ti o ngbe laafin Saulu ni gba naa saa niwaju Saulu. Leemeji ni Dafidi ri anfaani lati pa Saulu, sugbon o ko lati na owo si eni ami ororo Olorun. Ni gba ti o se, Saulu lo soju ogun, on si ku nibe.
DAFIDI OBA: A fi ororo yan Dafidi ni eemeta:    
1.     Laarin awon arakunrin re
2.     Lori Juda. O joba lori Juda fun odun meje aabo.
3.     Lori gbogbo ile Israeli.
Dafidi se opolopo ohun ti o mogbon wa ni Israeli. O gba gbogbo ile ti a fun won pelu Jerusalemu. O so Jerusalemu di olu ilu Israeli.
O gbe apoti eri wa si Jerusalemu. O tun eto isin se ninu Ago, o si fi lilo ohun elo orin kun isin Jehofa. O ko pupo ninu psalmu. O pinnu lati ko tempili fun Olorun, sugbon Olorun ko fun un, Olorun si so fun un pe omo re ni yoo ko tempili naa. Olorun se ileri fun Dafidi pe idile re ni yoo ma joba laelae. Bio tile je pe Dafidi je oba nla, sibe o ni awon ikuna tire. O dese pansaga pelu Batseba o si pa uraya oko re. O jewo ese re niwaju Olorun, Olorun si dariji i. IOba. 10:1-9. Bayi ni orile ede Israeli dagba lati eya mejila ti a nsakoso lotooto di orile ede ti o sokan.

ETO OLORUN FUN ORILE EDE KAN –IPADASEHIN ATI ISUBU.
IJO BA TI O YAPA: Ni  gba ti o ku feefe ki aye Solomoni wa si opin, awon iyawo re yi lokan pada lati maa sin awon orisa, Olorun si wa se ipinnu lati fa ijoba re ya si meji. Ipinnu Olorun yi se ni akoko omo re ti nje Rehoboamu.
I Oba. 11: 4- 13. Leyin iku Solomoni: Jeroboamu eni ti o ti je okan lara awon oloye Solomoni dari isote si Rehobamu, a si pin ijoba naa si meji. Eya mewa tele Jeroboamu ni gba ti meji faramo ile Dafidi – Juda ati Lefi. Awon eya mewa  ti o wa ni apa ariwa orile naa ni a  npe ni Israeli ni gba ti awon eya meji ti o wa ni apa guusu ile na ni a npa e ni Juda, ti a wa npe won ni Juu nigba ti o ya.
I Oba. 12: 1 – 5, 12:12-14, 19- 20.
ISUBU IJOBA NAA. Awon ijoba meji ti o pinya yi farajora ni awon ona kan, a sakoso won lati owo opo oba ni gba ti o si ya awon ota won segun won, a si ko won lo si igbekun. Israeli ti iha ariwa dese pupo ju awon Juda lo. Israeli wa fun bi otalerugba odin mewa odun 250 years, a si ti owo oba Asiria ko won si igbekun won si di eya mewa Israeli ti o sonu. Juda wa fun orin leloodunrun o le marun odun (385 years). Awon ara Babiloni lo wa ko won leru a si da won si le ni igba ijoba awon ara Pasia. Serubabeli, Esra, ati Nehemiah ni awon ti Olorun lo lati dari awon omo Israeli pada sori ile won.
AWON WOLI: Akoko lati igba ijoba titi di igba ti a segun Israeli ati Juda lati owo awon ara Asiria ati Babiloni ni a npe ni akoko Isaju igbekun. Awon woli ti o sotele ni ijoba ariwa ni Ahijah, Elijah, Mikaya, Elisha, Jona, Hosea, Amosi, ati obedi: Awon ti won sotele ni guusu ni: Shemiah, Ido, Asariah, Hamani, Jebu, Elieseri, Habakuku, Sefaniah, ati Obadiah. Meji lara awon woli ti o sotele ni igbekun – Awon woli igbekun, awon ni Esekieli ati Danieli, Jeremiah duro ni tie ni Juda, nibe ni o si sotele.
Awon woli miran tun wa ti won tun sotele leyin ti won ti pada si ile won, woli leyin igbekun. Awon naa ni Hagai, Sakariah ati Malaki. Awon woli yi ni won da awon eniyan pada sodo Olorun. Sakariah 9: 14    
   


  

No comments: