GROUND OF TRUTH BIBLE INSTITUTE
G.P.O. BOX. 17171 DUGBE IBADAN PHONE 08056008526

ORO IFISIPO ATI EJE FUN
IRANSE OLORUN
ORO ASOSIWAJU
OLUKO AGBA: Arakunrin
wa olufe ninu Olorun, awa nihin loni niwaju Olorun oga ogo, Olorun baba wa ti Jesu Kristi ati niwaju awon
eniyan mimo re lati ya Arakunrin/Arabinrin wa_____________
__________________________________________soto
fun ise iranse pelu igbowole awon alagba.
Jesu Kristi Oluwa wa ti fi apeere lele
ati ise pataki iru ise yi nipa pe o fi gbogbo oru gbadura lati wa oju Olorun
oga ogo ki o ba le mo larin awon omo eyin re eniti o ye ki a ya soto fun ise
iranse.
Eyin
ayanfe Olorun. Mo ni ore ofe ati anfani
ninu Jesu Kristi lati pee jade niwaju ipejopo mimo yii eniti Olorun ti ya soto
fun ise iranse eni na ni Arakunrin/Arabinrin
wa__________________________________________________lati wa siwaju Olorun ati
ipejopo mimo Re
[Eni ti afe fi
sipo bo siwaju o si duro niwaju iranse
Olorun]
OLUKO AGBA: Arakunrin to duro nihin yii ti gbiyanju
lopolopo igba, lati fi eri igbala re, han pelu eso ifara eni-jin. Asi ti bojuto
niinu oro Olorun eyi ti o le ranlowo lati dagba kio si je eniti amurasile fun
ise rere gbogbo. Ifara enijin re ati ijoloto ni ati danwo ni poplopo igba
nipase orisi-risi awon ise ati awon ojuse ti a ti fi le lowo siwaju ojo oni ati gege bi eni ti oye lati fi si
ipo____________________________
Awon Aposteli
igbani, ni ifisipo akoko, leyin ifarahan Emi Mimo wipe : Nitorina, ara, e wo okunrin meje
ninu yin, oloruko rere, eniti o kun fun Emi Mimo ati fun ogbon, eniti awa iba
yan si ise yi [Ise A.A 6:3]
Arakunrin
Poolu wipe “O si ye ki o ni eri rere lodo awon ti mbe lode. Ki o ma ba bo sinu
egan ati idekun Esu. Ki a si ko wadi awon wonyi daju pelu, nigbana ni ki aje ki
won oje oye” [I Tim 3: 7 &10]
Lati mu imole iwe mimo meji oke yii.
Mo bere wipe ki Arakunrin/Arabinrin
____________________________________________________ko jusi ijo eniyan mimo yi
fun ijeri gbe tabi ijeri lodi si iwa re.
[Eni ti a fe yan
yio yiju pada, yio si koju si ijo eniyan]
OLUKO AGBA: Mo
fe bere lowo ipejopo mimo yi paapajulo lati owo awon omo
ijo____________________________________________ti a ba ri enikeni ti o ri idi
pataki ti ko fi ye ki a ya eni yi soto gege bi
______________________________________je ki iru eni be ki o wa siwaju ki o si
wa so niwaju ijo eniyan mimo yii
[Iranse
Olorun yio si duro fun esi lati mo boya a o ri alatako]
OLUKO AGBA: Mo
pe Arakunrin kan ati Arabinrin kan lati inu ijo
_____________________________________________lati soju gbogbo awon ara ti o ku
fun ifowosowopo pelu ifororo yan.
[Iranse Olorun yio duro de awon Arakunrin ati awon Arabinrin wonyi ki
won o kede ifowosowopo won]
OLUKO AGBA: Mo pe
enikan ti o wa lati inu ijo miran tabi lati inu ebi eni yii ki o jade wa siwaju
lati wa kede ifowosi re loruko awon ara ti o ku.
[Iranse Olorun yio duro de eni naa
lati wa kede ifowosi re]
OLUKO AGBA: Niwon igba ti gbogbo ipejopo awon omo
Olorun yii wipe kii _______________________________________gba ifororo yan lori
si ipo_____________________________________mo wa pe adari ile iwe Ground
of truth Bible Institute lati bere awon ibeere ti o ye lowo
Arakunrin/Arabinrin wa bi o ti fe se ibura si ipo yii niwaju ipejopo mimo yii.
Siwaju ki ato fi ororo yan.
[Alakoso bo siwaju lati ba eniti a fe
yan si ipo soro, o si pe iyawo/oko eni ti a fe yan si ipo si egbe re
ORO IPENIJA
ALAKOSO ILE IWE: Mo fe ran o leti loni niwaju Olorun
ati ipejopo mimo yii gege bi o ti mo wipe iwo yio duro niwaju ite idajo Kristi
lati fesi si gbogbo idahun eyi ti iwo yio dahun
eyi ti iwo yio dahun ni oni yii. Nitori idi eyi, mo pe o nija lati je
olotito ati olododo ninu awon idahun re
gegebi ati gbagbo pe Olorun yio ran okan re lowo
Bibeli
wipe “Bi
enikeni ba fe oye Bisobu ti amo gege bi alabojuto tabi oluso aguntan o nfe ise
rere. Oluso agutan tabi Ajinhinrere gbodo je alailegan, oko aya kan, ti o ni
omo ti o gbagbo, ti a ko fi sun fun
wobia, ti won ko si je alagidi, ki o maje ase tinu-eni, oninu-fufu, omuti, aluni,
olojukokoro, bi ko se olufe alejo sise, olufe awon eniyan rere, alairekoja,
olooto, eni mimo, eni iwontunwonsi, ki o ma je onija tabi olufe owo eniti o kawo ile ara re girigiri ti o mu awon
omo re teriba pelu iwa agba gbogbo. Nitori bi eniiyan ko ba mo bi a ti nse
ikawo ile ara re oun yio hati se le toju ijo Olorun, ki o ma je eni titun ki o
ma ba gberaga, ki o si subu sinu ebi esu. O ye ki o ni eri rere pelu lodo awon
ti o mbe lode. Ki o ma ba bo sinu egan ati sinu idekun esu.
Nitori
idi eyi, mo bi o lere niwaju awon eniyan yii pe se iwo yio je oko aya kan /aya
oko kan laiba ara re je pelu awon Obinrin/awon Okunrin, gegebi o ti wopo larin
awon eniyan laye ode oni.
ESI: Beeni,
emi yio se nipa ore ofe ati iranlowo Olorun
ALAKOSO ILE IWE: Nje o mura tan lati gbe igbe aye alailabuku bi o
tile je wipe a nsoro awon iranse Olorun kan ni buburu, eri tire gangan larin
awon eniyan yio je pe iwo yato larin won?
ESI: Beeni,
emi yio see, ki Olorun ki o ran mi lowo
ALAKOSO ILE-IWE: Nje iwo yio mu awon omo re teriba?
Nje iwo yio sa ipa ti o wa ni ikawo re lati ri pe awon omo re gbe igbe aye iwa
bi Olorun ki ise iranse ma ba di isoro odi si
ESI: Beeni,
emi yio se nipa ore-ofe Olorun
ALKOSO ILE IWE: Nje o ti ko siga mimu sile, Ogun olooro ati oti mimu nitori
ihinrere?
ESI: Beeni, mo
ti ko sile
ALAKOSO ILE IWE: Nje o ti mura re pe iwo ki yio so
ise iranse di okowo; wipe iwo ki yio so awon aguntan Oluwa di ounje ni ona ti
ko ba iwe mimo mu gege bi o ti wopo larin awon iranse Olorun ode oni. Nje iwo
yio se laala laisi imotara eni nikan ati wipe iwo yio gbekele Oluwa lati pese fun awon aini re gege bi o ti ba iwe
mimo mu tabi ni ona ti o ba iwe mimo mu.
ESI: Beeni,
emi yio se be ki Olorun ki o ran mi lowo
ALAKOSO ILE IWE: Nje iwo yio ko lati ja awon eniyan
mimo lole owo won ati awon ohun ini won nipa lilo ogbon ewe ififuni? Nje iwo
yio ko won ni ona Oluwa lai beere wipe ki won san owo fun won. Boya nipa owo ti
a foju ri tabi ise rere kan?
ESI: Emi
yio se be nipa ore ofe Olorun
ALAKOSO ILE IWE: Nje iwo yio fi tokantokan re bojuto agbo Kristi ninu eyi ti o fe fi o
se alabojuto re? nje iwo yio ko lati so ara re di Oluwa lori won. Nje iwo yio
lo irele ati ipamora lati fi ona ododo
han won.
ESI: Beeni,
emi yio see, ki Olorun ran mi lowo.
ALAKOSO ILE IWE: Nje iwo yio ko oniruru igberaga ati
asehan eran ara sile ki o ba le se ojuse re pelu okan tutu ati irele gege bi
oro Olorun
ESI: Beeni,
emi yio se ki Oluwa ki o ran mi lowo
ALAKOSO ILE IWE: Nje iwo yio gbe igbe aye iwa bi
Olorun ti o mo gaara larin awon ara, ti o je wipe aye re yio mu imisi wa fun won ninu iwa mimo ati igbe aye iwa bi
Olorun
ESI: Beeni,
emi yio se be ki Oluwa ki o ran mi lowo
ALAKOSO ILE IWE: Nje iwo gba iwe mimo gege bi oro
Olorun ti oni imisi. Ti o dara fun eko, igbani ni iyanju, ibawi ati itoni?
ESI: Beeni
ALAKOSO ILE IWE: Nje
o mura tan lati ko gbogbo otito ti o nbe ninu Bibeli oro imisi Olorun
ESI: Beeni,
mo ti mura tan ki Olorun ki o ran mi lowo
ALAKOSO ILE IWE: Nje o mura tan lati gbani niyanju
lati baniwi, lati toni, laisi ikunsinu gege bi oro Olorun
ESI: Emi
yio se ki Olorun ran mi lowo
ALAKOSO ILE IWE: Nje o mura tan lati bo agbo
Kristi ati laifi won se ije gege bi awon
iranse Olorun alaiwa bi Olorun
ESI: Beeni, mo ti
mura tan
ALAKOSO ILE IWE: Nje o mo pe Jesu ni Oluso agutan agbo re ati wipe
iwo kan je alagbatoju? Nje o mura lati pese agbo fun oninkan ki o ma si so di
ti ara re?
ESI: Beeni
mo ti mura tan ki Olorun ran mi lowo
ALAKOSO ILE IWE: Nje
o mura tan lati gba ibawi gege bi iranse Olorun. Nigba kigba ti o ba se
asise tabi ti o re oro Olorun koja.
ESI: Beeni,
mo setan lati gba ibawi, ki Olorun ran mi lowo.
ALAKOSO ILE IWE: Nje o mura tan lati sise ni abala
eyikeyi ti Olorun tabi ise iranse yi ba fi o si tabi gba lati lo se ise iranse
Jesu Kristi ni ibomiran kakiri agbaye?.
ESI: Beeni,
mo mura tan, ki Olorun ran mi lowo
[Eni ti a fe fi ororo yan yio kunle pelu aya tabi oko re fun igbowo le
nigbati gbogbo ijo yio dide duro.].
ALAKOSO ILE IWE: Olorun
Baba, Olorun Omo ti nse Oro Olorun, Emi Mimo, mo mu aye ti o se iyebiye yi wa
siwaju re ki o ba le ya soto fun ise ti
o ti pe fun gege bi a o ti gbe owo le. Je ki ifororo yan lati ori ite re
wa wo inu aye eni yii, si je ki o di
Okunrin/Obinrin miran, lati oni lo, jeki ore ofe ati agbara ipo yii o sokale sinu aye re, ni oruko Jesu
Oluwa wa lati isinsinyi lo ati titi lai
lai.
[A o si gbe owo le eniti afi ororo yan a o si
gbadura fun]
IBURA/IJEJE
Mo jeje
pe___________________________________________________________ni ati fi ororo yan
bayi gege bi _____________________________________________________lati oni
yi______________________________________titi lai ni oruko Jesu Kristi Oluwa wa.
Mo kede
re wipe o koju osunwon lati sise ninu gbogbo ipade kristieni ni ibikibi kakiri
agbaye: Lati wasu , lati koni ni oro Olorun, ni koro ati ni gbangba, lati
runisoke ati lati gba awon eniyan ni iyanju. Lati so okunrin ati
obinrin po ni igbeyawo mimo ati igbeyawwo ti o ba Bibeli mu. Lati seto ounje
ale Oluwa , lati seto iribomi fun awon asese gbagbo. Lati dari eto isinku ati
awon isin miran ti o ye ni igbakugba ti a ba bere lowo re.
Mo fi o
le eni naa ti o le pa o mo lowo isubu ti o si le fi o sinu ogo laini abawon
pelu ayo nla, Olorun ogbon ati Olugbala eniti ogo ati ola je tire yio se o pe
ninu gbogbo ise rere, yio di o mu, yio si fi ese re mule lati isinsin yi lo ati
titi lailai. Amin
[Alakoso
ile iwe ati awon iranse Olorun yio bowo pelu eniti asese fi ororo yan nigba ti
alakoso ile iwe yio toka si aye ti o ye ki o joko si]
……………………………….. ……………………………
Oruko
ati ifowo si eniti a yan ALUFA
TI O DARI ISIN
……………………………………
MOSES
ADELEKE ADENEYE
Rector
No comments:
Post a Comment