Wednesday, June 6, 2012

ITOKASI GBOGBOGBO SI BIBELI APA KEJI


ITOKASI   GBOGBOGBO   SI BIBELI  APA KEJI


AWON OJULOWO OHUN ELO TI A FI KO BIBEL

                ITOKASI TABI AFIHAN


 Opolopo ohun elo ni awon onkowe lo lati fi ko oro Olorun sile, bi o ti le je wipe Bibeli ko daruko awon ohun elo wonyi, ayafi ni ibi kansoso ti a ti ko pe “Olorun si ko oro naa sori okuta” Ex 31:18; eje ki a tokasi awon ohun elo naa.

1)    OKUTA TABI APATA: Ni ile Egipti ati Philistine, awon eniyan atijo ama lo okuta ati apata  lati fi oro pamo lori won, eleyi si rorun nitori pe nigba laelae, ede awon Hebrew ko ni oro ti afi nso oro po (pre-position) nitori naa won a maa lo aake ige nkan tabi ohun igerin (chisel) lati fi gbe oro naa sori apata.

2)   AMO: amo je ohun elo kan ti awa lati inu ile ni aye atijo, ni bi 500BC si 35BC ohun elo amo yii ni Jeremiah papa lo,Jer17:13, Ek.4 :1 ni odun 1877  Obinirin onimoijinle kan wa ni ilu Egpiti; eniti o se awari iwe kiko ninu eyi tio tako iwadi onimoijnle Sayensi, nitori awon gba pe eniyan kankan ko ti mo iwe ka ni gba naa, sugbon si iyolenu, bi obinrin yii ti nwa ile lo se awari awon biriki kan, osi ko won jade, osi to won lese-lese tabi lokookan, eyi si ni awon ti ako sori awon biriki naa ‘THE HITTITES HABIRI’, eyi ti otumo si ile ikowe awon Heberu, SUPER HEATED NEBILA, awon eniyan wonyi gbagbo pe ni ibeere ko si ohun to nje eniyan tabi igbeyawo, won so pe aye kan wa gegebi ikoko ti ale gbe ka ina, pe lati inu re ni aye yi si ti jabo, sugbon isele ti a ko soke yii ja iro awon onimo ijinle  sayensi  yii tabi tako wo.

     Larin Genesisi si iwe malaki, Oluwa wipe tabi Olorun si wipe farahan ni igbe 2,600, Majemu laelae ati titunni ofi idi ne mule pe Bibeli je iwe mimo to kun fun inisi, jesu papa daruko re be osi gbe iru igbe aye be awon Apostteli pelu tokasii, won si gbe igbe aye won pelu, Lk 3;2, Rom 3;2,Act 1;l6-20 II Tim 3;16 Act3;18.
3)  PAPYRUS; papyrus yii je ise to dara to si ndgbe lati adagun odo tabi ni egbe odo, asi maa ga to ese mejila pelu awon ewe to rewa lori re.
      Okowo ise papyrus yii je ise to dara to si gbajugbaja ni ile egpiti ni ibiti tiwon ti nlo     
      tabi tihun bati ati oko ojuomi oko ti agbe mose sim inu re pelu je ise papyrum Ex 2; 3.
      Opolopo ohun ti a nlo papyrus fun nigba naa ni iwe Opolopo kiko debi pe, nigbe to ya  

     papyrus wa pada di ibi ti a ti mu oruko pepa jada wa, awon eniyannlo papyrus lati   
      500BC – 400AD, nigbati awo wa gba ipo re, nitori idi eyi Opolopo iwe mejmu titun ni  
      ako si inu papyrus.

4)  Awo; awo yi je eleyi ti a nri lati ara awo eranko, awon erako bi ewure, aguntan, malu,   ati Etu , awo ni alo ni ibeere adako iwe mejemui titun,Iitim 4;13, awon nkan wonyi ko farahan ayati    
     igbati Diodetian nlo won wonyi ni won si di ohun elo ikowe ni igba naa.

5) ASUNKI TABI AFUNPO(KODESI) Majemu titun ni ako titi ibeere si ori papyrus ki o      
     to dipe  awa dako si ori papyrus asunki tabi atunpo, ti ayipada kuro ninu iwe gboro si     
     iwe atunpo ti se oju ewe pepa ti ani loni ni o waye ni odun 800AD, awon onigbagbo nilo      
     ati wa oju ewe ni kiakia bakannaa ni alu iwo si awon iwe ti asi se doju re ko ara won ki       
     ole rorun lati ma si lati ibikan si ekeji
                                          
      AWQN OHUN TI A FI KQ IWE BIBELI

1.       STYLUS: Eleyi tumo si, peni lasan ti a fi nko iwe sori pepa
2.      CHISEL: Eleyi ni a nlo ti a fi ngbe apata ki a to fi ko nkan.
3.      PEN: Eleyi ni a nlo lati fi ko oro si ori amo.
4.      PEN KNIFE: [Obe igbe gege]A nlo eleyi lati fi pon chisel.
5.      INK IRON: [Iwo aro ikowe] Eleyi ni ife ti a nlo lati fi se aro lojo pamo.
6.      THE INK [ARO IKOWE NAA] Eyi ni aro ti a fi nko iwe.


 
             AKOSILE BI ASE DA BIBELI KO  


1.           AUTOGRAPHS  [IWE IGBA IWASE ] :- Akosile bi a se da Bibeli ko, oro                                                                            tumosi Ojulowo iwe ti eni to gba oro naa lati odo Oluwa ko sile. Iwe igba iwase yi ko si nibikibi mo toripe won ti segbe tan , gbogbo ohun ti a ni loni, adako lati inu Ojulowo ni, eyi gan-an papa ni e le ri ni ile itoju nkan ise nbaye [Museum]






             
AWON IDI TI KO FI SI AWON IWE IGBA IWASE.



1.     Nitori awon ohun elo elege ti a fi ko awon iwe naa si, Opolopo awon iwe wonyi la ko si ori papyrus.

2.    Nitori irinkiri awon Ju: Ni opopolopo odun seyin , a fi tipatipa le awon Juu kuro ni ile ini won. Pataki julo ilu Jerusalem ti a segun re ni igba adota-dinmeta (47) larin 1800BC si 1948AD.
     Igbe aye aiduro lojukan yi se akoba nla fun titoju awon iwe Oluwa won tabi iwe    
     mimo won, Opolopo iwe Majemu lailai ni awon ota moomo parun danu.

3.    Opolopo alase ile Romu leyin iku Kristi ni won korira esin Kristeni, won si sa gbogbo ipa won pe won parun, nipase be opo iwe awon onigbagbo ni won parun.

4.    Ni igba laelae, won ni asa kan larin awon onkowe ati Olukoni eyi ti oje sin-sin iwe mimo sinu ile, eleyi je iwa to gbajugbaja laarin awon juu, laisi ani-ani opo awon iwe igba iwase yi ni o parun. 

5.    Ohun miran ti o fa ti iwe igba iwase fi sowon ni pe, ofin kan wa larin awon onkowe eyi ti opalase fun won lati maa sin iwe to ba ni asise ninu ati lati ma sin iwe ti o ba di ogbo sinu ile nipa asa TALMUDIC, eyi ti o so pe gbogbo iwe mimo to ba ni asise ati awon to ba ti gbo koja lilo ni won si sin ti won si toju eyi to ba dara nipa be opo iwe igba iwase yi ni oparun.

6.    Nitori iborisa Bibeli, iborisa Bibeli tumo si jijosin fun Bibeli, ibasepe afi iwe ti awon woli ati awon Aposteli ko pamo, Opolopo awon asiwere eniyan ko ba ti so di ohun elo irubo gegebi ati ri ni ojo Esikaya Oba Judah, ti awon eniyan nsun turari fun Ejo ide ti Mose se, Awon Oba keji 18;1-4 ninu eyi ti Oba Esikaya parun nitori won rubo sii.

                                                                                                   
2     IWE ADAKO MANUSCRIPT: Eleyi ni won tun maa npe ni scripto ninu ede Grikii ni eyi ti o tumo si adako lati inu iwe Ojulowo.

ISE OWO AWON ALADAKO.                                                         
Awon ti o tun awon iwe Bibeli ko ni a npe ni awon aladako
Oro yii ni itumo kan naa pelu sise eda eyi ti a le pe ni sise afarawe ojulowo awon meji ni won se ise yii;

1   BARUKU
2   EZRA.
      Awon ni olubojuto akosile isele ni ilu, won maa nse abojuto akosile gbogbo isele to ba sele ni awujo, awon meji wonyi ni atileyin ofin Oba, awon ni amo gege bi oniroyin igba naa.   
      Ise ti aya won soto fun ni ise ilu ati ise awon Ologun, sugbon won yi ise won pada fun ara won si ti Olorun.

 ISE WON PIN SI IPA MEJI.
1   Lati se adako ofin.
2.  Lati se awon ohun ti ako lojo pamo.
Idagba soke nla ni o sele ni asiko awon wonyi, ati fun ogorun odun leyin aye won

 MASSORET; Awon wonyi ni alabojuto eda iwe mimo, awon ni won se akojopo iwe awon  Heberu, niti Majemu titun, ako nilo awon Massoret nitori ohun elo ti alo je ti awo ati awon iwe kekeeke ati pe Opolopo re ni awon Aposteli wa fun ara won tabi ti won pese re, sugbon eleyi ko ri be ni ti iwe Majemu laelae.

     Gege bi ati so ni oke, awon juu ni asa kan ti anpe ni asa TALUMUDIC eyi ti o wipe bi Ojulowo iwe ba ti di arugbo to, a ko gbodo sonu, dipo be, agbodo fi pamo sinu apoti irin ki a si sin sinu ile teye-teye tola-tola ati tesin-tesin, leyin ti a ba ti se adako re.

      Eda Bibeli Majemu laelae to dagbaju ni ari ni LEHUNGARD ni ilu RUSIA, odun ti a si ko ni 916 AD, osi ni awon iwe wonyi ninu Isaiah, Jeremiah Ezekiel ati awon woli mejila ninu.
      Iwe miran si wa ti a n pe ni Pentateuch ti a ko ni odun 58AD, eyi to je pe ni ile iko nkan isenbaye si, ni ilu LONDON nikan ni ati le ri, bakannaa ni iwe miran wa ni ile-  ise-nbaye miran.

                            AKOKO MASSORETI- 500AD.


Ekun rere ilana ati igbekale ni o wa fun kiko iwe mimo ni asiko yi ati ilana ati igbekale ti a fi sawari awon kanoni ti won ko awon iwe Bibeli jo.

         SISE AWON IWE MAJEMU LAELAE LOJO PAMO.

Labe re ni atiko oro lori TALAMUDIC [1st period] 300BC-500AD, ni asiko yi Opolopo iwe ni o wa ni sinagogu lati ka, oro ti a pe ni sinagogu yi bere lehin igba ti oba kan dide to sun Tempili,eleyi ni o wa mu ki awon ju fon kaakiri, nibikibi ti won ba ngbe, won a da sinagogu sibe. Sinagogu je ibi ti a npe ni kekeke, ti ijo aye yi je sinagogu , ti ijo si nbe ni orun.

 


AWON MAKABIOSI [MACCABEES]



Oro ti a pe ni makabiosi, waye ni odun 168BC nigbati ANTIOCHUSI kerin ti o gba oye Epiphanes ti o tumosi olorun farahan ti o si di oba Siria ni odun 175BC. O gbiyanju lati pa esin ju run.
                   
AWON ORO MIRAN TI WON FI TAKO ESIN JUU.
1.Ko gbodo si irubo ni Tempili mo.
2.Won ko gbodo pa ojo isinmi mo.
3.Won ko gbodo koni ni iwe mimo mo.
4.Won ko gbodo ko omo ni ila mo .
5.O so Tempili di alaimo nipa pe o fi elede se irubo ZEUS ti ise olori awon Griki.

Eleyi ni o fa darudapo larin awon ju labe Isakoso Mattathius eni ti o je Alufa ati awon Omokunrin re marun ni eyi ti gbajumo arin won je Judas ti a npe apeje re ni MAKABIOSI oro ti o tumosi OOLU. Awon Makabiosi yi ni a npe ni omo ogun ti won si segun awon ara Siria ni December164BC , won si fo Tempili mo, isele yi ni awon Ju nse ajoyo re gegebi ase imole, eleyi je ajodun olojo mejo to ma nwaye ni asiko keresimesi. Nitori idi eyi Opolopo iwe majemu laelae ni o parun ni asiko rogbodiyan yi.

                                         IWE AWO OKUN DUDU

Iwe awo okun dudu ni won ri lati owo awon Olofintoto tabi onimo ijinle ti won ma nwa nkan ise nbaye kiri.
Bakanna ni odun 1946 February, won tun ri omiran ni apa gusu Jeriko, okunrin ti o si sawari re yii je oluso-aguntan eni ti o ju okuta si aguntan kan ti o si gbo iro kan ti o sajoji, o wa pinnu lati awari re, nigbati o si ri, o ri wipe iwe mimo ni o wa nibe, bakannaa ni won se awari pe ibe je ibi iko iwe pamo si ni atijo ti a npe ni ESSENES.
                   
                                             IBI TI A TI KO BIBELI

Apakan re ni a ko ni aginju Sinai bakanna ni Jerusalemu ati nigbati awon Ju wa si ile igbekun ni Babiloni, bakanna ni a ko awon jo ni ogba ewon, atun ko awon kan ni erekusu Patimo ti o je erekusu larin agbami Meditarenia





                                           AWON TI O KO BIBELI.

A ni Opolopo awon ijiyan nipa awon ti o ko Bibeli sile, sugbon awon ojogbon Bibeli so pe 36 ninu awon onkowe wonyi je oba, awon Ijoye, awon egbe Dokita,Darandaran, Agbowode, Jagunjagun, Woli, Apeja, Agbejoro, ati awon akowe.  Asiko ti won je 1600[year] iyen odun; ko to dipe o le pe odidi gegebi won iwe miran .NI aye atijo, a ko Bibeli ni oloro nla ti a npe ni [capital letter]. Ni bi ogorun mesan odun seyin, Bibeli ko ni ori , be si ni ko ni ese titi di igba ti STEPHEN LANGTON ti o je olori awon Bisobu ni CANTERBURY fi pin si ori ni odun 1226AD, bakannaa ni ROBERT ESTIENOK ti o je atewe omo ile Franse[France] ti o gbe ni ilu GENEFA [GENEVA] wa pin awon ori wonyi si esese ni odun 1551AD.Bibeli Genefa ti won te ni ilu Genefa ni odun 1560AD ni Bibeli akoko ti o ni awon ori ati awon ese.

                     ORUKO AWON TI O KO BIBELI SILE

Mose, Dafidi, Joshua, Samueli, Amosi, Oba Solomoni, Jeremiah, Danieli, Matteu, Johannu, Marku, Dokita Luku, Peteru, Johanu Olufe, Jakobu, Juda, Paaulu Aposteli eni ti o ni iwe eri diploma ninu iwe imo ofin,

                               AWON EDE TI A FI KO BIBELI

Ojulowo awon ede ti a fi ko Bibeli ni; Heberu, Arameki, ati griki. Bibeli majemu laelae ni a ko ni ede Heberu ayafi awon wonyi; Danieli 2:4-7:28, Ezra 5:4-6;8 & 7:12-26, ti a ko ni ede Arameki tia tun da pe ni kaldea, ese kan ti se Jer.10:11 ni a ko ni ede Arameki, sugbon gbogbo Majemu titun ni a ko ni ede griki.

                                   AWON EDA BIBELI

Ni bii 400 AD eniyan  pupo lowa nipa bibeli ni gba naa, awon oludari ijoba Romu ko lati fi eto ati anfani to ye fun awon Kristeni, won si gbojun ti awon kristieni pelu inunibi, beni won pa won. Jeromu ni eni akoko to koko ti Bibeli si ede latine a sinju Bibeli re ni LATINE VULGATE. Awon ore meta kan wa ti won se ise karakara lori yiyi Bibeli pada si awon ede miran;
Awon ni;
1. WYCLIFFE   -  JOHN     [1320-1384] AD
2.  WILLIAM    -   TYNDALE    [1491 – 1526] AD
3.  MILES  -   COVERDALE [1488 – 1569] AD


                                                JOHN   WYCLIFFE

A bi ni odun 230 ni ilu oba England [oba oyinbo] .ni asiko Wycliffe yi, ekunrere Bibeli ni ede oyinbo wa di dandan fun awon eniyan nitori idi meji pataki wonyi:
  1. Nitori ede Anglosaxon atijo ti ndi ogbo lo.
  2. Bibeli Latine Vulgate ko te awon oyinbo lorun mo, o wa se eda Bibeli re lati inu Bibeli Vulgate, a te Bibeli re ni odun 1340 nigbati apapo bibeli jade ni 1342. Atejade Bibeli Wycliffe yi mu ki hilahilo ati darudapo wa, o to akoko kan ti awon Bisobu mejo ati awon  eniyan pataki ninu ijo joko lati se idajo ti won si da Wycliffe lebi, lehin eyi ni mimi nla ati irokeke sele ni ilu London lehin idajo yi ni awon igbimo ri eyi gegebi owo Olorun ti o lodi si ipade won, nitoripe won ni eko eke ni lati soro iwe mimo ni ilu England.


WILLIAM  TYNDALE

William Tyndale ni a bi ni odun 1491, A mo gegebi agbedegbeyo, O si gbo bi orisi ede mejo daradara; awon ede bi;Heberu, Griki, Latine, Itali, Dutch, Spain, French, ati English. Leke gbogbo re Tyndale funrare fi ara re jin fun iwe mimo.Tyndaleko ipa nla ni titu Bibeli si ede   geesi  tabi  ede oyinbo .Ninu ilakaka re lati tu Bibeli o gbiyanju lati wa iranlowo awon bisobu ilu London sugbon won ko je ko se aseyori ,ni eyin ore yin okunrin onitaja aso kan ninu  ilu London si wa lati ranlowo ,sugbon okunrin  yii ni won gba mu ni igbehin ti   won, ko je ,si fi  si   ogba ewon nitori pe oran  tyndale  lowo  Tyndale  fi tipatipa  salo  si HAMBURH ni Germani ni odun 1576.

Bo ti wu ki ori  Tyndale sa gbogbo ipa  lati pari ede Bibeli oyinbo ti majemu titun o si te jade ni ipari osu keji 1526, nkan bi egberun mejidinlogun 1,800 ni ose fayawo re wo ile England nipa pe ofi won bonu bali aso (bound) ati awon opo iyefun (flower).

           Inu Opolopo dun pe won ni Bibeli majemu titun ni ede won, sugbon alase igba naa gbe ofin titun kan dide lati fi pa Bibeli run, won si dana sun gbogbo awon Bibeli wonyi, iwe iyebiye yii ni won dana sun gbogbo Bibeli wonyi, ni ibi meta ni England, ibi ikinni London, ekeji ni Oxford ti eketa re ti n se Antwerp, Tyndale tesiwaju ninu ise ologo yii ni Antwerp ni agbegbe ti o ti lero pe o pamo, sugbon okunrin ketoliki (catholic). Kan ti oruko re nje Herry piti pe nigbati odipon ti ose pe rare ni ore Tyndale, osi un iwa apanpa ni pape odale Tyndale ni osu karun, (May) 1535 ni abe osi se EMPEROR CHARLES, V, be ni a ji  Tyndale gbe lo si ogba ewon, ti o si tun tesiwaju lati ma tu majemu laelae lo,ki won to bere ati ki won to pari ejo re, o ti pari titu iwe owe ati gbogbo awon iwe woli, won se ejo re won si dalebi fun eko eke ni osu kejo odun 1536 [odun kan ati osu meta ] won ro loye gegebi alufa won si fa le awon ijoba aye lowo pe ki won lo paa, eleyi ti won si se ni ojo kefa osu kewa ni odun 1526,             nigbati o wa ni papa nibiti won o ti pa ,Tyndale gbadura bayi pe ’Oluwa la oju awon oba ile England O” lehin eyi ni won yi orun re si odi won si tun da ina sun ni ilu Belgium. Agbejade Bibeli Oba Jakobu ni o dabi idahun adura eniyan Olorun yii, nitoto awon omowe tabi awon ojogbon so pe Bibeli oba Jakobu je ida 90% ninu ise William Tyndale [ iyen adorun ].

MILES COVERDALE

Okunrin Coverdale yi ni eni akoko to koko te odidi Bibeli ni ede [Griki] geesi eyi ti o te ni ilu England, bi o tile je wipe William Tyndale ku nitori igbagbo re, sugbon o bori re, eda Bibeli re se iranlowo nla nini Bibeli ni ede oyinbo, Olorun si oju awon oba England lati ri ogbon ati pataki Bibeli ni ede oyinbo . Fun gbogbo eniyan Miles Coverdale mo riri pe oun lo ise orisi eniyan marun ninu titu Bibeli eyiti ise Tyndale poju ninu re.




                AWON OTA ATI ALATAKO BIBELI


Gegebi ati so ni isaju wipe okunrin kan TRANPENI ANTIOKOSI 4, eni ti o gba oye Epiphanes eyi ti o tumo si olorun farahan eni ti o ba Tempili je nipa fifi elede rubo ninu eyi ti MATTATHAIS to je alufa ko awon oro re jo nibi ti a ri oruko MACCABIS yo jade,wahala yi ni o koko bere igbogun ti Bibeli, ni asiko yi bosi asiko arin majemu iyen 1668BC, awon eniyan yi ni won duro ti Olorun ti won gbija Bibeli nitori Opolopo awon oba ni won dide lodi si Bibeli fun apere:
  1. Diocletine eniti o pase ki a ma danasun Bibeli .
  2. Constantine eniti o koko gbogun ti awon Kristieni ko to di wipe o wa gbagbo.
  3. Claudius eniti o le awon Juu Kristieni kuro ni ile Romu gege bi iwe Act.18:2 ti wi.
  4. Nero eniti o se okunfa pipa Paulu ati Peteru.
  5. Vespasion eniti o teri awon Ju ba ni odun 66-70.
  6. Titus eniti o je omo Vespasion eniti Oba Jerusalemu je ni opin awon Ju.
  7.  Domition eniti Opolopo awon onimo ijinle gba pe oun ni Emperor to wa lehin iwe   
      ifihan 4 titide ori 22.
  1.  Pope eniti o je olori elesin ti oun pelu si se lodi si Bibeli nitori ti o gba pe Bibeli otito yo je ideruba fun ijo Aguda. 
  2. Trajan Emperor akoko ti ki ise omo italy.
  3. Oba Jakobu eniti o je oba akoko fun ile England lehin ti won yapa kuro ni Romu ni 1603-1625AD eniti o ko agbajopo ojogbon Bibeli jo ati awon agbagba lati ko Bibeli eda oba Jakobu.

Enikeni ti won ba ti ri Bibeli lowo re nigbana yo ku pelu re ni, iwonba eniyan die ni o ni anfani lati ko Bibeli nigbana.
Bi awon eniyan ti nba Bibeli sote bee ni Bibeli npo sii, ogo ni fun Olorun pe ki se gbogbo Bibeli igbana ni won danasun, Olorun si se 170 pamo fun ara re,.Pope to je olori elesin ati olori ijoba ni ile Romu se ikeede nigba tire wipe ko si enikan ko si enikan gbodo ka Bibeli nitori naa won si fi ofin nla kan ti lehin, bakannaa ni ijiya nla wa fun eniti won ba ba ni owo re.


                  IGBOGUNTI BIBELI NI ILE ADULAWO



Onile-ede akoko ni ile adulawo ni ilu mali ti Bibeli koko wo, awon ojise Oluwa alawo funfun ni won mu Bibeli ti akoko wo ile [alawo dudu] adulawo gegebi itan ti so, fun odun 25[years] ati nse inunibini si won, ati ni awon odun wonyi, Opolopo won ni won pa, nitori pe oba o obinrin kan je ni ile England eniti o pase pe ki won ma pa awon ojise Olorun yii. Kakiri ile adunlowo, sugbon odun pe lowo Olorun pe Opolopo won loni aseyori ninu ise iranse won ni ile adulowo. Ina isoji ti awon eniyan yi dasile bere sini ran ni ile adulowo awon eniyan si bere sini  pongbe fun oro Olorun.

OPIN BIBA BIBELI SOTA [JAKOBU DI OBA NI ENGLAND].

Ni odun 1611 AD oba Jakobu to je okan lara awon ota Bibeli ni oni igbala ti o si pase pe ki won ma te Bibeli ati ki eda kookan ki omaa wa ni synagogu ati Tempili, ni gba naa ni awon  eniyan ni ominira ti won ka Bibeli ni itagbangba, Bibeli ti a si te nigba naa ni a n pe ni Bibeli oba Jakobu.

 ITAN BIBELI TI AKO NI PUPA LATI OWO [LOUSI KIOSEL 1899]


                 

Gegebi o on kowe se n ko iwe lori akole kan si ite ise iranse iroyin kristieni kan oju ese Bibeli kan ninu iwe Luku 18:20, ofin si fi kalamu pupa fa ila si abe ase oro yii, nitori idi eleyi ni oro ninu ara re wipe ose se lati fi ila si gbogbo oro Jesu ki o le rorun fun eniyan lati tele damo nitori idi eyi, o to awon agba agba inu ijo lo lati bere fun anfani lati te irin iwe be lehin alaye lori to fi fe gba ase fun tite iru iwe bee an fun ni anfani lati se be.

             Nitori idi eyi ite iwe akoko jade 1899 pelu 600,000 Bibeli gbodo ye wa wipe iwe ti ako ni Kalama pupa yi to ti gbe ra afikan fun Bibeli, bakannaa lo n se pelu awon Bibeli miran, nitorina iwe akoko to koko te ede lo te ko to di pe ako ti ede oyinbo.



IMISI   BIBELI



                                                

Itumo lati owo Webster

Imisi ti Olorun ohun ni agbara tabi ipa ti Olorun to n ru awon woli ati Aposteli soke lati le ko Iwe mimo, eyi to mu won ye lati le so otito lai se asise, Agbara ipa Olorun yi ohun lo mu    awon to ye soke lati le gba ati lati so otito ti Olorun.



Itumo lati owo Dokita L. GAN SSEN

     Imisi ohun ni agbara ti ko sese alaye ti Emi ijinle Olorun ma n fi fun awon eni igba ni ti o ma n ko iwe mimo lati le ko ninu oro ti won ye ki won ko ati lati le da bobo won kuro ninu asise ati lati le ma so gbogbo oro pataki nu.

 Itumo lati owo WILLIAM EVANS.             
    Imisi ohun ni emi to lagbara ti eniyan maa n mo ti Olorun orun fun awon to kun oju osuwon lati le so otito oro Olorun, ohun nipe ki Olorun sunmo nipase eniyan.

Itumo lati owo ROBERT LEE. 
    Imisi tumo si agbara ti ko se fojuri ti Olorun n dari lori kiko Majemu laiai ati titun.

Itumo ti BIBELI
      Imisi ohun ni abayori tabi ifarahan agbara Olorun to n sise loni, ninu ati nipase awon woli ati awon Aposteli ati nipase awon to ko Bibeli eyi to fun won ni anfani lati le ko sile ati mimu jade ni ona tio se gbekele awon otito eyi ti won gba ni ifihan.

ITUMO TI   BIBELI   IKEJI.
     Iwe mimo gba imisi o si fi idi mule, sugbon Bibeli ko se alaye bi ase mi si awon eniyan ati bi awon eniyan se n gba imisi. II Tim 3:15, II Pet 12:19-21.

     Nitorina, Olorun lo eko eniyan nipa kiko iwe sile bo ti le je wipe won gba imisi sise                                                                                               won nlo ogbon eyi ti a ko lati owo eniyan lati le so erongba okan won si ita, imisi ki se oro  
Bibeli, sugbon o wa lati inu ede latine eyi lo nse alaye agbara afikun eyi to rumi soke,
         
John 32:8, abayori awon otito ti ako lati fi ko Bibeli kun fun otito eyi to fe ki awon eniyan re ko mo ati so fun araye awon ohun meji ohun ni alo ninu alaye imisi ninu Bibeli.
         
ORO TI AKO ISILE ATI EYI TI AFI ENU SO
      
Oro ti a ko sile -  Eyi tumo si ekun tabi ope itumo eyi ti ori okonkon ati ese ti Bibeli a ri Bakaana lati odo Olorun.

Oro ti a fi enu so-: Imisi awon oro ti a fi enu so nfi mule wipe awon oro iwe yi ati awon oye eyi ti o fi han oje eyi ti ko se fi oju ri, ti imisi Olorun nipase Emi Mimo.

Bibeli ki kan se awon iwe ti a fi ogbon eniyan ko, sugbon oje eyi to salaye Olorun yekeyeke,                                                                                                                                                                                                botile je pe Bibeli ko salaye bi Olorun se misi awon iranse re, sugbon odaniloju pe ki n se eyi ti a ko nipase ona ero Olorun, Olorun Emi mimo, eniketa ninu metalokan oun lo sise ninu eniyan.
                                                                                                                                                                                                                                                                                                            
   Bakaana, bawo ni eni kan se le ni ipa lori elomiran, ki ni idi ti oro awon elomiran se ni ipa lori awon eniyan kan ju elomiran lo?


 orisi nkan lo nfa ti ipa lori awon elomiran fi ma nlagbara ju ara won lo, awa mo wipe Olorun ni orisun Bibeli ati pe awon to ko, awon ni adari tabi ti ato nipa Emi mimo. Emi Mimo ti o sise ninu aye Maria wundia eyi si je apeere rere bi Olorun se n sise ninu awon oluko Bibeli.    
                                          TITO BIBELI

  Awon ibeere kan je jade ninu boya Bibeli to, Awon wonyi ni-: Nje Bibeli to? 
                                                                  Nje Bibeli se simi le?
                                                                  Nje eniyan le ni igboya si?
                                                                 Nje ose fo kan te?

 Idahun-: 
[1] Eri awon eniyan mimo fihan pe Bibeli to fun igbala okan awon eniyan. 

[2] Nipase igba niyanju ti Emi mimo, ni ojojumo ni angba igba niyanju, ati pe awon ohun ti a       
      ngba yi lati owo Emi mimo fi han pe, pelu Olorun isegun daju.

[3] Imole okan ijakadi ninu okunkun ati imole si onigbagbo, fun awon alaigbagbo eniyan, awon eniti a ko iti gbala, egbe lo je [iparun loje].



                               
                       AWON OHUN TO KUN FUN



Okun fun awon ohun ifihan Olorun to yani lenu eyiti aye komo.



                                  AWON IPA RE


Oti mu imole to ngba orile ede la ati enikookan lagbara lati le yi gbe aye won pada
.

                  AWON ORUKO BIBELI ATI ODUN WON.

(1)  Original   Manucript                                        1,500 Bc-100AD.
(2)  Second    Manucript                                           500 AD-950AD.
(3) Masoretic Jewish scholera                                  500 AD-950AD.
(4) Why clife              Version                                   1525/26 AD.
(5) Tyndale                 Version                                   1525/26 AD.
(6) Coverdale              Version                                   1535 AD.
(7) Matthews               Version                                  1537 AD.
(8) Great      Bible        Version                                  1539 AD.
(9) Geneva   Bible        Version                                   1560/67 AD.                                                          (10) Bishops Bible        Version                                   1568 AD.
(11) Tony     Bible        Version                                    1610 AD.
(12) King     James        Version                                  1611 AD.
(13) Reversed standard Version                                 1881 AD.
(14) America standard Version                                  1901 AD.
(15) M. English Translation Version                          
(16) Isorkely                                                             1952
(17) Living Bible                                                        1971
(18) Simplified Living Bible                                       1990
(19) New America standard                                      1971
(20) Amplified                Version                              1965
(21) Jerusalem    Bible                                             1966
(22) NIV                                                                  1978/79
(23) New King James     Version                               1982                                                                (24) Good News              [T. E. V]                             1987
(25) New Century          Version                               1987
(26) The Answer            Version                              1993
(27) New Revised Standard Version                        1989
(28) New Jerusalem Bible.
(29) Arabic                   Version                                 930
(30) Ethiopia                 Version                                
(31) Bohairic                 Version                                 {Ede awon gusu ile Egypt}
(32) Saidic                     Version                                 {Ede awon ara Thebes}
(33) Gothic                    Version                                350
(34) Armenian               Version                                439
(35) Slavonic                 Version         
(36) The Message                                                             
(37) Donay         Bible                                               1582-1609 AD.
(38) Latine    Vulgate    Version                               1380 
(39) Philip Modern English Version





                                 AWON EDA TI YORUBA


            Ni odun 1884 Olorun lo Bishop Ajayi Crowder lati tumo Bibeli si ede yoruba ni igba akoko ati lehin eyi Opolopo Bibeli yoruba lo ti wa,

fun apeere-:
(1) Bibeli mimo ede yoruba                                                              1909
(2) Majemu lailai ti ase atunte re                                                    1909
(3) Majemu titun ti ase agbeyewo re                                               1930
(4) Bibeli yoruba eda ti atunse [lati owo United Bible societies]      1969
(5) Bibeli yoruba mimo ti atunte lati owo Nig. Bible society             1900
(6) Bibeli yoruba Armour Bible House
(7) Kaybal yoruba Edition -:Atoka                                                    1980
(8) Awero yoruba Bible
(9) Bibeli mimo Alakori [lati owo “His Mercy Bible League”] -:ATBB




                                    AWON ASE RE



        Oba aini ile ejo kotemi lorun ti esin pade, papa julo awon ile ejo eke ri pe ose pataki fun awon lati yo lo lati fi ba awon eniyan soro.

                                   PIPEYE RE

      Iyato wa larin Bibeli ati iwe miran ti ko si eda kan to le salaye re, Bibeli je iwe [66] merin dinlaadorin ti ako lati owo orisirisi eniyan ti oto bi ogoji ti o si gba akoko bi 1,600 year otale legberun, ti o si ni orisirisi awon akori ati erongba ti o dogba ti o jepe eniti Otobi julo lo le salaye re.

                                   ATAKO


     Itan ati iwadi awon onimo ijinle ti fi idi Bibeli mule, bakanna osi tun tako awon on kowe kan, awon kan ti so awon iseye biye won nu,  sugbon eyi ko ribe nipa Emi mimo, Bibeli ni iwe to dagba ju ni gbogbo agbaye, sibe imiye lori re ko dinku.
     Melo ninu awon iwe ti oku ni ole duro sinsin, tabi to le de awon ibi ti Bibeli de? Sugbon ale ke Bibeli igba ogorun sibe ko ni sa loju wa, bakaana ni ko ni su awon to nka.


                                  ABAJADE IMISI

Bi o tile je pe awon kan so wipe, Bibeli ti a ngbe kiri ko pe, sugbon awon otito kan wa ti a n ri ninu Bibeli wa, to wa fihan pe odidi to peye ni.

(1) Isokan Bibeli mimo naa.
(2) Itesiwaju irapada aye.

     Lati Genesis de iwe Ifihan, Olorun ko iti ko iran eniyan sile, ati pe, lehin igba soke, Olorun yoo si tun gba awon kan la “awon ayanfe igba iponju”. Anilo lati bi ara wa la won ibeere kan;
(1)  Nje Bibeli to fun igbala wa?
(2) Nje ale sin mi le?
Idahun re nipe, bee ni.
(3) Isokan nbe laarin awon to ko Bibeli sile ati wipe lehin ohun  gbogbo, ijoba kan wa fun wa.
                 ISIPAYA BIBELI


Oje akosile isipaya Olorun si eniyan, Olorun ba awon eniyan re soro nipa Olorun funra re,  
igbekele Re ati eto Re fun igbala.

       Olorun ti so ara re di mimo fun eniyan ni ibi gbogbo ni ona iyanu nipa ti eda ati ti eri okan, eyi ti oni agbara lati fi imo han, bi o se nse akoso gbogbo aye ni o pe sinu re.

       Olorun ti fi ogo re han lori ohun gbogbo. Ps 19:1-6 nigbati a ba n so nipa isipaya, a n so nipa bi Olorun se fi ara re han nipase Bibeli.

       Olorun fi ara re han ki eniyan kan le mo, ko si josin fun, nipase iwe naa [Bibeli] ki se ki o ma sin ara re, sugbon ofi han wa iru igba ti oye ka ma sin Olorun.

        Bibeli ki kan se iwe ifihan Olorun si eniyan Job 5:39-49, sugbon Bibeli je akosile bi Olorun se fi ara re han fun eniyan ati imole fun eniyan lati gba iye ti afi fun nipase re.



        BAWO LA SE LE MO OLORUN NIPA EDA TABI ELEDA


 Isipaya Olorun kakiri gbogbo agbaye so di mimo pe Olorun nbe tabi pe, Olorun wa ati                                                                                                                                                                                                                                     
 pe Olorun to da awon oke, awon omi, awon okun, awon ewebe, awon eranko ati eniyan o si je ologbon ati alagbara julo Roman 1:20, psalm 104:24, 29:1-9.

 Bibeli mimo je iwe esin ki se iwe imo ijinle sayensi osi ni se pelu awon ohun temi, tabi ki                                                                            
 aso pe pataki ise ohun ni ise laarin Olorun ati eniyan ati bi ase ra eniyan pada sodo Olorun nipase Jesu Kristi.



AWON ALAYE ITUMO ISIPAYA

(1)      Oro ti ape ni Isipaya wa lati inu eda Latine eyi lo tumosi ka so ohun kan di mimo tabi ka se awari tabi ohun kan to sapamo to di mimo fun wa.
(2)      Isipaya je ise to koja ogbon eniyan tabi ilana ti Emi ninu eyi ti Olorun fi anfani fun awon iranse re to je eniyan lati yoju wo Oun funrare [Olorun] ; ona re ati otito Re.



       Olorun soro ara re fun eniyan ninu otito fun idi pataki kan, bi a ti nsoro nipa isipaya ni a nso ni a nso ni ibamu pelu Bibeli, ose pataki ki a mo daju nipa oun ti a nso nipa re. 

Ninu isipaya ni gbogbo ohun ti Olorun je patapata ni Olorun fihan, ni akoko oje ti itan,                                         iyen nipe o koko bere ni ona oye eniyan bi awon isele to ma n sele gegebi ati nso lori ile aye.

                                  OGBON FUN ISIPAYA

 Eyi ni mimo akosile Bibeli, sugbon Olorun ko fi wa sile sinu okunkun nipa agbara re, nipa Isipaya, ohan gbangba pe eniyan kise orisun Isipaya, beni ko le fowo soya pe oun loun ni Isipaya.

 
                 Orisun ati iranwo fun Isipaya


A       Nje Olorun le fi ara re han?
B       Nje eniyan le gba Isipaya?

 Idahun gbogbo re ni beni, nitori pe oun ni Olorun, nitorina,Oni agbara lati fi ara re han    
 fun eniyan bi Olorun, eniyan naa ni agbara nitori, eniyan je aworan Olorun.

  Nitori idi eyi eniyan ni agbara lati odo Olorun.

Olorun je Emi bakana eniyan je emi, eniyan ni ara ogbon ati ise iranse biti Olorun, Olorun je alagbara julo to wa laaye.

          Olorun nse ijoba ni orun ati pe eniyan si ndari lori ile aye, bi o ti le je wipe eniyan subu, sibe Olorun ko fi eniyan sile.

          Oda awon nkan, sugbon ko fi won sile, nse ni O dari won to si se alabojuto lori won,  nitori Olorun da awon orun, osupa, irawo ati beelo. Won ko si ise se lati igba ti a ti da won.




                       OHUN TI ARI NINU ISIPAYA



      Ohun ti o wa ninu Isipaya ni Olorun funra re, ki se eda, be ni ki se eniyan tabi ohun kohun miran ti Olorun da, eniyan papa ko le mo Olorun ni ona ti Oluwa gba fi ara re han.
Ko sese fun eniyan lati mo Olorun lekun rere ayafi igba ti aba de orun gan-an.

Jesu nikan ni ale ri nisinsin yi, sugbon awon mejeji [Jesu ati Olorun] ni a o ri papo ni orun. Olorun ni aseda ohun gbogbo ninu ola-nla Re.




                   AWON OHUN META PATAKI TO YE KA MO NIPA OLORUN


(1) Olorun je eni ti ako da.
(2) Olorun je alagbara julo.
(3) Olorun je Olugbala gbogbo aye [araye].
                                      IBI ISIPAYA

     Bi aba fe bere pe ibo ni ibi Isipaya, idahun ye ki oje pe nibi kibi ti eniyan ba wa ni                                                                                 
Olorun le fe ba soro, tabi lo le fi ara re han fun [eniyan] boya ninu soosi, ni                        odo tabi ni ibi ise.

       Nibi kibi ti eniyan ba wa ni Olorun ti le ba a soro, nigba kigba, nitori aipeye eniyan, nibi ki bi ti Olorun ba ti ba eniyan pade, nibe ni Olorun yio ti so nipa ara re fun iran eniyan.

      Akosile Isipaya Olorun, ninu oro Olorun nikan (Bibeli) ni o wa, kosi si ninu iwe miran, bikose ninu Bibeli mimo nikan, Bibeli naa  ti a mo ni iwe kan soso ti o so fo nipe Olorun ati Kristi, nitori pe Bibeli je oro  Olorun, asiko sile nipa imisi Olorun fun ki a maa tumo re.

BI A SE FI BIBELI FUN WA

 Eyi tumo si bi ati se fi Bibeli fun ni ati bi ati se se lojo pamo ni opolopo odun sehin.
 Eleyi si ni awon kan wonyi ninu;
(1) Ki kowe.
(2) Adako
(3) Titu Bibeli
(4) Sise Bibeli lojo pamo.

Nigbati ofin kan bere pe ki won ma pa gbogbo Bibeli run, nigba na ni awon eniyan fi oju lowo eda kan pamo, eyi lo fa ti afi ni eda tiwa loni.

                                     EDE  BIBELI  NAA 

      Olorun ni Opolopo ona to n gba so ono re, sugbon ti o ba so bawo ni oye yio se yeni, tio si se akosile ohun ti Olorun fe fi ranse si.

      Olorun soro nipase eniyan, nitori idi eyi, Olorun wa wo ona ti yo ma gba se eleyi, o si se eyi nipase awon ona wonyi:

(1)             Olorun ba awon Woli ati Aposteli ati awon onkowe soro Heb 1:1
(2)            Nipa awon Angeli Gen 18:3
(3)            Nipase awon Woli loju ala
(4)            Lati inu iran tabi Isipaya Isaiah 1:1, Ezekiel 1:1
(5)            Nipase ise iyanu Exodus 3:2
(6)            Nipa iriri, bi ti Jona
(7)            Nipa eda tabi abuda Psalm 8:3
(8)         Ohun ti inu, nipase eri okan olukuluku Psalm 19:1, Rom 2:15                      
(9)       Nipa ibo didi tabi keke sise
(10)  Kika awon iwe woli
(11)       Urimu ati Tumimu. Ti o ma nwa ni aya olori Alufa.
Nipase eleyi, Olorun yio soro sinu okan Alufa naa. Ama ju sile lati wipe ki o soro wipe beni tabi beko si isele to ba sele lai je pe oba salaye, owe 16:33, Ex 28:10-30.



Gbogbo awon nkan wonyi ni odara ni aye ti won, sugbon won ki se ona to peye lati                       
             bojuto oro Olorun.

 Bi Olorun ba soro ti ako si se akosile oro re o daju wipe iru oro be ole di gbigbagbe,
 Olorun n fe ki gbogbo oro ti o ba fi ranse si eniyan ki o wa ni akosile dara dara, idi                                                  
 fun eleyi nipe, eniyan ni opolo tio kuru.

                                              
                                        AKOJO PO


Orisi idi merin lowa ti Olorun fi lo ona akosile lati fi dabobo Bibeli.
(1)      Nitori Opolo eniyan ti ko to nkan
(2)     Imisi ko le duro pepepe
(3)     Otito le pada di adalu.
(4)    Oda bobo sise atunwi nkan wonyi fun awon elomiran eyi ni ogbon agbekari Ifihan 1:1

Gege bi ohun ti a ka ninu ese yi, iwe eyi keyi ti ako ba gba lati owo awon kannoni ni ako laaye lati di pinpin larin awon onigbagbo. Ki iwe eyikeyi to jade lo si arin awon ero iru iwe be ni agbodo koko ka si eti awon baba igbagbo, ki oto di pe afi aye gba larin awon kristieni.

Ati tu Bibeli si orisi ede bi ogorun, ohun si ni a ka ju ni orile-ede agbaye.
                                                                                   
                                       
               
                                      OGBON TI AFI YOLO


 Awon Aposteli yo akosile ara won lo, eyi nipe eniti o yo oro lo naa ti koko ka      
  iwe, eni ti o yo oro re lo.

         
                                     A I KO SI AKOKO

Ohun ni iwe to dagba ju ninu awon iwe igba iwase, ohun si ni iwe ti o dara ju ni igba iwase ati ti okan eniyan ko le dagba ju koja kika re.




          IFIDIMULE AWON IWE WONYI NI ONA IFISISE

Ninu ile ijosin eyikeyi tabi ninu ipejo po eyikeyi enikeni yoo dide duro laarin awon to ku yo si ka iwe naa si eti awon Baba igbagbo ki o to di pe won tewo gba gegebi iwe mimo ti Oluwa,,awon olutewo gba awon iwe wonyi gbodo wa lati arin awon baba igba gbo awon wonyi si ni awon olutewo   gba awon iwe wonyi.

                  AWON EGBE OLUTEWO GBA MEJI


(1)          Poly cap;
Egbe kan la pe ni poly cap awon orisi awon eniyan ti o wa ninu egbe naa ni a pe ni Just-ting tabi Marters irenous.

(2)    Clement ara ALEXANDRA.
Awon egbe keji ni awon igbimo, kannoni ati awon olutumo Bibeli.




             

           

                      AWON OLUTUMO META TO SE PATAKI.


(1)       OLD SYRIAIC: Eleyi ti o wa ni 400AD ti osi ni iwe Majemu titun metadinlogun                                                                                                                (2)      OLD LATINE CANON: Ti o wa 200AD ninu eyi ti iwe Heberu, iwe Jakobu,    
    Peteru kinni ati ekeji ti di awa ti.

(4) MAURITANS CANNON: Ni  odun 170AD ni a tumo re, Bibeli si fa gagbaga pelu latine ohun pelu ko ni awon iwe wonyi ninu, awon iwe bii: Heberu, iwe Jakobu, Peteru kinni ati ekeji.

                                   AWON IBIJOKO AWON KANNONI


           Ile igbimo ti HYPPO 393 AD.
           Ile igbimo ti CATTAGE 397 AD.
           Ile igbimo ti NICEA.
           Ile igbimo ti COSTANTINOBLE.
           Ile igbimo ti ECUMERICAL.


                                       OGBON KIKA


          Gegebi iwe 1Tes 5:28, Ifihan 1:3, ti so, iwe Satani ni ako gbodo gba laaye ki a ka si eti awon eniyan mimo sugbon, awon ese Bibeli ti a daruko loke yi wipe agbodo ka iwe mimo laarin awon eniyan mimo.

                                          ASEPARI BIBELI NAA


          Laktan, Bibeli gegebi iwe mimo, ohun ni iwe kan soso ti o fi ona otito han wa, eleyi ni imole ti a ntan lati orun fun awon to fe wa ni oun, Bibeli mimo yi ti to fun gbogbo eniyan to n be lori ile aye.











          
                                                                           
   

                                                                                                











                         
                          






   

No comments: