Wednesday, June 6, 2012

EKO IRIBOMI


GROUND OF TRUTH BIBLE INSTITUTE
             G.P.O. BOX 17171 DUGBE IBADAN
 E-mail groundoftruth@yahoo.co.uk g.s.m 08056008526
EKO IRIBOMI
                  ITOKASI

 Baptisimu je Igbese kan ti o le mu eniyan ye fun orun, gege bi iwe MK. 16:16 eyi ti o wipe, “Enikeni ti o ba gbagbo ti a ba si baptisi re yo la, sugbon eniti ko ba gbagbo yo jebi”. Acts. 8:13. Ninu oro ti a so loke yi a kiyesi wipe gbigbagbo je Igbese akoko ati sise iribomi je Igbese keji, sugbon opo eniyan ti se asito ase nla yi. Nitorina, ti o ba ti si to ni onakona, o je ohun ti o han gbangba pe o ko iti ye fun orun, ayafi ti o ba tele eto ti orun se yi.
                                          GBAGBO KI O SI LA. 

Ti a ba wo awon oro meji yi, o dabi enipe o dojuru, nitori ti a ba wo niti ara, won ko le wonu ara won, sugbon ti a ba wo niti Emi, o je oro ti o wo inu ara won, “gbagbo ki o si la” nitori idi eyi a o farabale wo ikokan won ki a ba le mo itumo awon oro pataki wonyi.

GBALA


Oro yi ni orisun re lati inu oro ti a pe ni igbala, nitori idi eyi, fun wa lati ni ekunrere itumo re, a nilo lati wo oro igbala.

Kini igbala nipa ti ara? Igbala ni gbigbani kuro ni ipo ewu bo sinu ipo ailewu”. Fun wa lati ni oye ti o jinle lori oro yi, a nilo lati tan imole nla sori ohun ti a npe ni ewu. KINI EWU? Ewu je isele ti o sele si eniyan ti o si le mu iku dani. e.g.
1.    Nigbati ijanba moto ba sele.
2.   Nigbati eniyan ba sesi ja sinu kanga.
3.   Nigbati ile ba njona ti awon eniyan ba si wa ninu re ti won sun.
4.   Nigbati awon adigunjale ba ya bo ile kan.
Enikeni ti o ba bo sinu okan lara awon isele wonyi ti wa ninu ewu, O si nilo enikan ti yo gbala kuro nibe lo si ibi ti ko si ewu. Nitori idi eyi, eyi ni a npe ni igbala nipa ti ara. “Lati gba enikan kuro ninu ewu bo sinu ipo ti ko lewu.
       
                                     IGBALA NIPA TI EMI


Niwon igba ti a ti mo alaye nipa ti ara ati itumo nipa ti Emi pelu, eyi si ni o tobi julo. Igbala je yiyo enikan kuro ninu ewu ese, ati ki a si yo iru eni be wa si odo Oluwa Jesu Kristi eniti ise Olugbala araye.
                            ORISUN IGBALA NAA.

Nitori idi eyi, niwon bi ese ti tipase enikan wo inu aye ati iku nipase ese beni iku si rekoja sori gbogbo enia nipase eniti enia ti dese (Rom. 5:12 NIV) “Nitori iku ni ere ese, sugbon ebun ofe Olorun ni iye ti ko nipekun ninu Kristi Jesu Oluwa wa”(Rom. 6:23 NIV).

       Lati inu awon ese Bibeli oke yi o ye wa yekeyeke pe ese o mu idajo ati idalebi wa si iran enia, a le wa ibi ti ese yi ti se wa, a le wa pada wa si odo Adamu. Nigbati Adamu dese, ese ti ipase won wo inu iran enia.
Rom 5:12(LB)
       Ese Adamu lo fun esu laaye lati le gba Isakoso aye, nitori Olorun ko da aye fun esu ati ese.
                  OJULOWO ETO OLORUN FUN EDA

     Nigbati Lusiferi padanu ipo re ni orun lo so di Satani, Olorun pa ogo ti o wa lari re run, o si di okunkun lojiji. Nigbati Olorun koko be aye wo leyin rudurudu ti esu fa, O ri bi okunkun se wa lori ile aye ati pe ohun akoko ti Olorun se ni pe O mu imole wa. Gen.1: 2-3,Imole ti a ri nibiyi ko ri bakan naa pelu Gen.1: 14-19 ati pe okunkun ti Olorun pin si meji ko ri bakannaa.
 Ti a ba ka Johanu 1:1-5 a o ri pe imole nso nipa Jesu Kristi ati pe okunkun ni esu.

Ninu Efesu 5:8-11, Ites. 5:5-8 Imole ti Olorun palase da yato ti ise eda kan, eni yi ni iye ninu, iye re ni imole na, iru imole yi je eyi ti okunkun ko le bori.



                                                                                
                                                                                       Imole

                                                                                       Iye
   
                                                                                       Ara


Awon nkan wonyi ni Olorun gbin sinu Adamu, ki o le je pipe, nibikibi ti Adamu wa, okunkun ko le duro nibe. 
                               Emi

   Ogbeni eran ara   Johannu 1:9 so wipe “gbogbo okunrin ti a bi sinu aye tipase okunkun wa sinu aye. Ohun ti Olorun so nibi kii se pe eniyan ko ni rin mo nigbati ko ba si ina elektriki, sugbon o tumo si pe, okunrin tabi obinrin bee ko ni tele Ogbeni okunkun mo, iye okunrin tabi obinrin bee ti so Ogbeni okunkun di alailagbara.





Fun Olorun lati se Isakoso Ogbeni ti a n pe ni okunkun yi patapata, a ri pe ese 26 nibi ti Olorun ti wipe “Je ki a da eniyan ni aworan ara wa, nigbati a ba n so wipe Olorun da eniyan, a n so wipe Olorun da ikoko ti o le gbe imole si eyi ti ise inu aye re.
 




Nitorina nigbati a da Adamu, ere idi Olorun ni pe nigbati won ba bere si ni bii si, Ogbeni okunkun ko ni le ni anfani lati duro nitoripe ni gbogbo ayika ni enikookan yo wa ti yo ma gbe imole kaakiri eyi to wa ninu aye iye. O o le pade Oluwa tii se imole, ki o si je okunkun ni apakan aye re, o o ti pade Jesu, elomiran lo ba pade. IICor.4:6.
                              ISUBU ENIA

        Nigbati Olorun da Adamu, O fi imole sinu iye ati pe O fun ni ofin kan pe ko gbodo je ninu eso imo rere ati buburu pe ni ojo ti o ba je, kiku ni yo ku. Ni ojo ti Adamu je eso yi, o ku, sugbon kii se pe o subu lule, sugbon iye ti o ni imole ku, agbara ti esu beru ti kuro ninu enia, iye miran ti gbasakoso ikoko yi. Bi Adamu se je eso igi yi, o so imole iye di oku, eda ara si gba Isakoso.
ABAYORI ARA TABI IYE T’ARA
 


    
Lesekese ti Adamu dese, iye miran wo inu aye re, eyi ti a npe ni ara tabi iye t’ara tabi Ogbeni okunkun.
 

                                                                                Ara
                                                        Iye Okunkun
                                                        Ogbeni Okunkun                   


Ohun akoko ti a kiyesi ni fifi ara pamo. Gen. 3:10,
Ekeji ni pe ko gba ebi re. Gen. 3:11-12

Eketa ni pe won ko ri Olorun mo, ohun ti won ngbo ni iro ese Olorun ati ohun ti o nse ninu aye awon elomiran. Gen.3:8

Ekerin nipe won bere si iberu itiju. Won le gbe igbe aye buburu nitori ki oju ma ba ti won. Gen.3:10.

Ekarun ni iwa imotara eni nikan, oro ti ow si enu Adamu ni kete ti won subu ni oro; emi, emi, emi. Gen.3:10.

 Ti o ba bere si ise ayewo Bibeli re lati igba ti Adamu ti subu, a o se akiyesi pe orisirisi ese lo wa laye, fun apeere, Kaini pa aburo re, aini telorun, kiko obinrin ati okunrin jo, oti mimu iro pipa ati bebe lo.

 Eda ara ko le te Olorun lorun, ko le fowo sowo po lati sise Olorun, ati pe eda ara ko le wo ijoba orun.


GBAGBO


          Nigbati a ti mo abayori isubu eniyan, a nilo lati wo ona ti Olorun gba wa idahun si, eyi ni ona abajade ti Olorun. “Bi enikan ko ba gbagbo, ko le di eni igbala”. Kristi Jesu ni odo aguntan Olorun ti a fi rubo fun imukuro ese eyi ti Adamu da. Gal.3:13. Igbala duro lori ohun marun eyi ti bi enikeni ko ba gbagbo, igbala iru eni bee ko pe.

(1)       Ibi wundia ati aye re.
(2)       Ijiya ati iku ori igi abgbelebu.
(3)       Isinku re.
(4)       Ajinde re.
(5)          Igoke re orun re.

           Ninu Peteru 1:9, Bibeli so fun wa wipe, “A o gba abayori, ilepa, ati   
     asepe igbagbo wa ani igbala okan wa.


        
              IJINLE OGUN IYE AYERAYE


Marku 10:17, Matt:19:29, Lk 18:18

Ese Bibeli ti o wa loke yi fihan pe Olorun ti seto iye Ayeraye fun gbogbo eniyan to ba gba Kristi Jesu, Sugbon ibeere nla nipe bawo ni eniyan se le jogun Olorun ti ko le ku? Idi niyi to fi ye ki a mo ohun ijinle Olorun nipa sise ohun ti kosese yi lese-lese. Heb. 9:15-19 so pe ”iwe ogun kii ni ipa ayafi bi eni to se ba ku.

BABA- Lo se iwe ipin ogun yii.
OMO-  Ku fun iwe ogun yii.
EMI MIMO-  So fun elese pe oruko re wa ninu iwe iye

                   ABAYORI IGBAGBO

Nigbati eniyan ba gba Jesu Oluwa wa gbo pelu gbogbo okan re ti o si pee wa sinu okan re, ohun ti yo sele ni yiyi eda re pada. Bi ko ti seese fun aja lati je ewa ti a ko se, be si ni ewure ko le je eran tutu, nitori eda won yato si ara won. Be na lo se ri fun eni to fi aye re fun Jesu, eda re a yipada. E ma se gbagbe Oba Nebukadnesari ti eda re yipada, o se bi eranko.
Wonyi ni abajade eda titun.
(1)      Ese ati Ogbeni okunkun pare      I Jn 3:5-6, I Jn 1:5-7
(2)      Eso ti emi     (Gal. 5:22-26)
(3)         Ife si Olorun  (I Jn. 2:3-6, 15-17)

 IRIBO

Oro yi, ‘iribo’ je oro giriki ti a n pe ni Baptiso, eyi to tumo si lati sin ohun kan sinu ohun miran ki a si ma ri mo rara. apere, omi, iwe, ile ati bebee lo.


        APEERE IRIBO

(1)    Kikan mo abgbelebu  (Rom.6:6, Gal. 2:20)
(2)   Iku        (Romu 6:3)
(3)   Isinku    (Romu 6:4)
(4)   Ajinde   Romu 6:5)
(5)   Rinrin ninu iye titun   (Romu 6:9-10, Efesu 4.17-24)

                       IDI IRIBO?

(1)    Ohun ni asepari igbala wa.  (Marku 16:16)
(2)   Ase Jesu Kristi ni     (Matt. 28:19)
(3)   Oun ni eri okan rere si Olorun.   (I Pet. 3:21)

               APEERE IRIBO TI KO DARA

(1)    Ami agbelebu ni iwaju ori.
(2)   Wiwon Omi si eniyan lara.
(3)   Sisare labe aso funfun tabi aso pupa.
(4)   Sisare koja labe mariwo.

                                             
                                       IRIBO TO DARA

(1)        Iribo to to ni iribo eyi ti a ri ti o si ni ifidimule ninu Bibeli, eyi ni iribo ninu odo to n san
(a)       Johannu n ri awon enia bo odo   (Jn. 3:22-24, Mk 1:4-5)
(b)      Jesu wa ki a le se iribo fun ni odo Jordani (Mk. 1:9-10)
(d)      Iwefa ara Etiopia se iribo ninu odo ti o nsan (Ise Aposteli 8:35-39)



                        AWON ISORI TI A PIN IRIBO
           TO BA BIBELI MU SI



Bi a se mo pe iribo wa lati inu ede Griki to tumo si lati si ohun kan sinu omiran. Opo ohun to sele ninu Bibeli ti a pe ni iribo, botile je pe ko soro nipa omi sugbon sibe iribo ni nitori ohun ti iribo je. Sibe a nilo iribo yi ninu aye wa ti a ba fe dabi Jesu, bii;

(1)     Iribo Israeli si Mose ni okun pupa    (I Cor 12:13)
(2)    Iribo si ara Kristi  (I cor.12:13)
(3)    Iribo sinu iku Kristi   (Rom. 6:3)
(4)    Iribo sinu Emi mimo. (Matt.3:11)
(5)    Iribo sinu ina.  (Matt.3:11)
   

No comments: