Wednesday, June 6, 2012

ORO IFISIPO AWON DIAKONI


GROUND OF TRUTH BIBLE INSTITUTE
G.P.O. BOX. 17171 DUGBE IBADAN PHONE 08056008526

ORO IFISIPO ATI EJE


ORO ASOSIWAJU

ALUFA:                 Arakunrin wa olufe ninu Olorun, awa nihin loni niwaju Olorun oga ogo,  Olorun baba wa ti Jesu Kristi ati niwaju awon eniyan mimo re lati ya Arakunrin/Arabinrin wa_____________
                            __________________________________________soto fun   ise iranse pelu igbowole awon  alagba.

Jesu Kristi Oluwa wa ti fi apeere lele ati ise pataki iru ise yi nipa pe o fi gbogbo oru gbadura lati wa oju Olorun oga ogo ki o ba le mo larin awon omo eyin re eniti o ye ki a ya soto fun ise iranse.

Eyin ayanfe Olorun. Mo  ni ore ofe ati anfani ninu Jesu Kristi lati pee jade niwaju ipejopo mimo yii eniti Olorun ti ya soto fun ise iranse eni na ni Arakunrin/Arabinrin wa__________________________________________________lati wa siwaju Olorun ati ipejopo mimo Re

[Eni ti afe fi sipo  bo siwaju o si duro niwaju iranse Olorun]



ALUFA:                 Awon Aposteli igbani, ni ifisipo akoko, lehin ifarahan Emi Mimo wipe: “Nitorina, ara, e wo okunrin meje ninu nyin oloruko rere, eniti o kun fun Emi-Mimo ati fun ogbon, eniti awa iba yan si ise yi.  [Ise A.A 6:33]

[Eniti a  fe yan yio yiju pada si ijo eniyan]

ALUFA:                 Mo fe bere lowo ipejopo mimo yi paapa julo lati owo awon omo ijo______________________________________________________ti a ba ri enikeni ti o ri idi pataki ti ko fi ye ki a ya eniyi soto gege bi _________________________________________je ki iru eni be ki o wa siwaju ki o si wa so niwaju ijo eniyan mimo yii

[Iranse Olorun yi o si duro fun esi lati odo ijo boya A o ri  alatako]

ALUFA:             Bakanna elomiran lati inu ile tabi ijo miran….

[Iranse Olorun yio si tun duro fun esi lati odo ijo miran boya A o ri  alatako]

Bi ko ba si ALUFA YIO WIPE;


ALUFA:                 Ni won igba ti gbogbo ipejopo awon omo Olorun yii,  wipe ki ………………………………………..gba ifororo yan lori si ipo………………..………mo fe  kati beere awon awon ibeere ti o ye lowo Arakunrin /Arabinrin wa. Bi o ti fe se ibura si ipo yii niwaju ipejopo mimo yii. Siwaju ki a to fi ororo yan.

[Iyawo/ Oko eni ti a fe yan si ipo yio bo si egbe re]

ORO IPENIJA


ALUFA:     Mo fe ran o leti loni niwaju Olorun ati ipejopo mimo yii wipe iwo yio duro niwaju ite idajo Kristi lati fesi si gbogbo idahun eyi ti iwo yio dahun  ni oni yii. Nitori idi eyi, mo pe o nija lati je olotito ati olododo ninu awon  idahun re gegebi ati gbagbo pe Olorun yio ran okan re lowo

Nitori idi eyi, mo bi o lere niwaju awon eniyan yii pe se iwo yio je oko aya kan /aya oko kan laiba ara re je pelu awon Obinrin/awon Okunrin gege bi o ti wopo larin awon eniyan laye ode oni?.

ESI:               Beeni,  emi yio se nipa ore ofe ati iranlowo Olorun

ALUFA:     Ni asiko yi mo bere lowo yin pe; nje eyin ti ye ara yin wo bi e ba ye lara, lokan ati lemi fun  ipo ti a nyan yin si?

ESI:              Beeni, mo ti ye ara mi wo, mo gba pe emi ye fun ipo na

ALUFA:     Nje eyin mura lati maa lo kiki agbara Olorun ati ti Emi-mimo re nikan lenu ise nigba gbogbo laiko fi ohun miran kun?

ESI:               Beeni nipa ore ofe Olorun ati iranlowo re

ALUFA:     Iwo ha mura tan tokantokan lati pa isokan  Emi mo pelu awon asiwaju re: ninu eko ti o ye koro gege bi ati fi ko o pelu eto ati ilana eyiti ijo pa lase fun eko, itoni ati  ibaniwi ijo, laiko to ipa, idamoran ati ife inu re lati se aigboran, aiteriba ati iyapa?.

ESI:               Beeni, nipa ore ofe Olorun ati iranlowo Re, emi ki yio se tabi fa iyapa

ALUFA:     Iwo ha mura tan tokan-tokan lati je olugboran si awon olori ati oludari ijo ninu eto rere ti a ba dari won lati se fun o niti ibawi ati ikilo won, lehin ti a gba o laaye lati so ti enu re?

ESI:              Beeni, nipa iranlowo Olorun ati ore ofe Re

ALUFA:     Iwo ha mura tan lati fi ara re fun Bibeli kika,  kiko si ori ati kiko awon eko ijinle ti o le fi ese oro Olorun mule ninu re fun eko  ti o ye koro, ti o si le mu ni dagba ninu agbara, ife  ati inu ti o ye koro bi a ti so ninu 2Tim. 1:7, pelu igbekale oro na lati se awon eniyan Olorun ni asepe?

ESI:               Beeni, nipa ore ofe Olorun ati iranlowo Re

ALUFA:     Iwo ha setan lati fi ara re fun adura ati awe, lati di ara re ni amure lati ja  ogun ati lati sare ije ti o wa niwaju re pelu agbara Emi mimo laisimi ati laise aare?

ESI:               Beeni nipa ore ofe Olorun ati iranlowo Re

ALUFA:     Iwo ha gba pe ise ti Oluwa ba ti owo re se ninu ijo yi ti Oluwa ni, ati pe kise dukia ti enikeni le pe ni nkan tire, ki o si koo lo bi iwo ba tesiwaju  kuro ninu ijo yi?

ESI:               Beeni nipa ore ofe Olorun ati iranlowo Re

ALUFA:     Iwo yo ha yago fun iwa oju kokoro ti nmu ojise ihinrere miran fi agutan Olorun se oja tita, ni jije ere ijekuje lara won ati ni gbigba owo ore tabi nkan miran lona, ti o lodi si oro Olorun ti o si le mu egan ba ise iranse yi?

ESI:               Beeni, nipa ore ofe Olorun ati iranlowo Re

ALUFA:     Gege bi eko ti a ko yin, nje iwo gba pe Oluwa lo fi o je oye sinu ijo yi ati pe o gbodo gba ase ijo yi ki o to te siwaju kuro ninu ijo yi ki o ba yori si iyapa?

ESI:               Beeni, emi  ki o yapa, ki Olorun ki o ran mi lowo

ALUFA:     Nje iwo gba pe bi o tile tesiwaju kuro ninu ijo yi iwo ki yio fa enikeni ninu ijo yi lati tele o lo?.

ESI:               Beeni, emi mo be nipa iranlowo Olorun emi ki yo se iru ese buburu yi

ALUFA:      Nje o mura tan lati gbe igbe aye alailabuku bi otile je wipe A nsoro awon iranse Olorun kan ni buburu, eri tire gangan larin awon eniyan yio je  pe iwo yato  larin won?.

ESI:               Beeni, emi yio see, ki Olorun ki o ran mi lowo

ALUFA:     Nje iwo yio mu awon omo re teriba, nje iwo yio sa ipa ti o wa ni ikawo re lati ri pe awon omo re gbe igbe aye iwa bi Olorun, ki se iranse ma ba di isoro odi si?

ESI:               Beeni, emi yio see, nipa ore ofe Olorun

ALUFA:     Nje o mura tan lati bo agbo Kristi ati laifi won se ije gege bi awon iranse Olorun alaiwa bi Olorun?

ESI:               Beeni mo ti mura tan

ALUFA:     Nje o gba pe ijo yi ni agbara lati da o duro kuro ni ipo yi bi aye re ko ba ti ba oro Olorun mu mo?

ESI:            Beeni, sugbon emi ki yio se ohun buburu be ki Oluwa ki o ran mi lowo

ALUFA:     [Gegebi eto ifinijoye, o gbodo je eje niwaju Olorun ati gbogbo ijo loni yi]





KINNI AWON EJE RE ?


OLOYE:  Mo je eje niwaju ogun orun ati awon omo igbala loni yi pe:-

1.     Emi yio fi ara mi fun ise Oluwa ninu ijo yi ni ona gbogbo, Pataki ninu adura, awe, Ijakadi igbagbo, ati ise itankale ihinrere na. Ki Oluwa ran mi lowo

2.     Emi yio so iwa mi lati so eso Emi bi Oluwa ti bere lowo mi, papa ni ife, Ayo, Alafia, Ipamora, Iwa pele, Isore, Igbagbo, Igbona-okan. Ki Oluwa ran mi lowo


3.     Emi yio wa ni isokan pelu gbogbo eniyan ijo yi. Emi ki yio fi inu ba enikeni ja bikose bi ohun ibinu kan ba de ki a se eyiti Kristi pa lase pe oorun ko gbodo wo ba ibinu kan ninu mi. ki Oluwa ran mi lowo.

4.     Yato si awon alagbara okunkun bi Oso, Aje, Emere, ati be bee lo, emi ki yio ro ibi tabi se ibi  tabi gbogun ti omo ijo yi. Ki Oluwa ran mi lowo


5.     Emi yio teriba fun gbogbo awon oloye ti o ga ju mi lo ninu ijo yi emi yio si fi owo so owo po pelu won ati awon elegbe mi ninu ise Oluwa ninu ijo yi. Ki Oluwa ran mi lowo.

6.     Emi yio ma fi itara gbogbo se ise ti a yan fun mi ninu ijo yi tayo tayo fun ogo Olorun wa, emi ki yo ro ti ara mi nikan. Ki Oluwa ran mi lowo.


7.     Emi yio ma fi akoko mi sile, fun ipade gbogbo ti a ba yan mi si. Emi yo si gbiyan ju lati de ile isin siwaju asiko ti isin yo bere lati le gba eyiti ise ise iriju mi fun isin na. ki Oluwa ki o ran mi lowo.

8.     Emi yo kapa ile mi, emi yo si ri wipe gbogbo ara ile mi ni won fi ara won fun Olorun. Ki Oluwa ran mi lowo


9.     Emi yio gbiyanju lati pese fun awon ara ile mi bi Oluwa ti palase ninu [ITim.5:8] ni iwon bi agbara mi ti mo. Ki Oluwa ran mi lowo.

10.                        Emi yio fi gbogbo aya mi, gbogbo okan mi , gbogbo iye mi ati gbogbo agbara mi fe ati beru Oluwa Olorun mi ati ijo yi. Emi ki yio yapa, tabi sote  tabi fi imele sin Olorun nihin. Emi ki yio woju enikeni lati sin Olorun mi. ki Oluwa ran mi lowo.


11.                        Emi yio si tun ko Agbere, Ole, Iro pipa, Ogo-asan ati kiarimi  sile. Oro Oluwa ni yo ma se amona mi. ni iwon bi o ti se pe awa ko le se ohunkohun bikose pelu iranlowo Olorun. Ki Oluwa ran mi lowo.

12.                        Ni jijise Olorun fun awon eniyan, emi ki yio so ohun ti Olorun ko so, tabi ohun ti Olorun ko wi tabi tan enikeni je nitori idajo Olorun. Ki Oluwa ran mi lowo lati mu  awon eje yi se[Amin]

[Eni ti  a fe fi ororo yan yio kunle pelu aya tabi oko re fun igbowo le nigbati  gbogbo ijo yio dide duro]

[Alakoso ile iwe ati awon iranse Olorun yio bowo pelu eniti asese fi ororo yan nigba ti alakoso ile iwe yio toka si aye ti o ye ki o joko si]


………………………………..                                           ……………………………
Oruko ati ifowo si eniti a yan                            ALUFA TI O DARI ISIN
                                                                                                    

                                    ……………………………………
                                    MOSES ADELEKE ADENEYE
                 Rector

No comments: