Thursday, August 29, 2013

AWON ILANA IBANISORO TI O MUNA DOKO



GROUND OF TRUTH BIBLE INSTITUTE
G.P.O. BOX 17171, IBADAN.

AWON ILANA IBANISORO TI O MUNA DOKO

IBANISORO:        Ibanisoro je ona lati fi ohun, oro, ero tabi iwoye ranse si elomiran ni ona ti oye yoo gba ye eni ti a fi oro naa ranse si. Titi di igba ti oye oro ti o sun mo ero ti o wa lokan oluso yoo fi sele ninu okan olugbo, ibani soro ko ti sele rara. Ibani-soro je lona meji: Ohun ati Ami.

OLUSO:  Oluso je abani soro ti o ni ero, asaro, iwoye tabi imo ninu okan re ti o fe so fun elomiran. Isoro ti o ma ndojuko oluso ni lati mo irufe ede ti o ye olugbo daadaa. Ede, ni gbogbo ona je ipa ti a ngba bani soro. O wa je ojuse oluso lati mo irufe awon eni ti o fe ba soro ki o to bere sib a won soro. O wa je ojuse oluso lati mo irufe awon-eni ti o fe ba soro ki o to bere sib a won soro.

OLUGBO:  Olugbo je eni ti o ngbo or Oluso. Olugbo gbo oro naa nigba ti oye ohun ti oluso nso ba ye e.

O je ohun iwuri lati rii pe ibani-soro nlo ni gbogbo wakati merinle-logun ti nbe ninu ojo kookan. Lai deena p’enu, aye yi duro lori ibani-soro. Oku nikan ni kii banisoro. Ibani-soro nipa ohun wa, ibani-soro nipa Ami naa si wa.

IBANI-SORO NIPA OHUN: Ibani-soro nipa ohun da lori lilo awon akojopo oro enu lati fi so ohun ti nbe lokan eni jade. Nigba miran ewe, a le ko awon oro wonyi sinu takaada (paper). Oluso ma nlo ede ti olugbo gbo lati fi se atagba oro.

Atagba: Atagba maa nsele nigba ti oro ba de eti olugbo. Opolopo oro lati se atagba re lai je oro naa se ise ti a ran an, eyi tin se mimu oye wa. O se Pataki fun wa lati mo pe a fi opo oro sofo seyin nitori awon oro naa ko koja eti awon olugbo. Ibani-soro waye ni igba ti oro ba koja eti olugbo ti o si de inu okan ti o si mu oye jade (orin Dafidi 119:130). “iwole oro re nfun ni ni imole, a si ma fi oye fun awon ope.” Ko le si oye oro naa ti oro naa ko ba wo inu okan olugbo o.

Gbigba oro:         Gbigba oro ma nwaye ni igba ti iyipada ti a fe ba nfarahan, eyi ti a npe ni igboran, ninu aye olugbo. O ye ki ilepa ma wa ninu olubanisoro nigba gbogbo, eyi tin se lati mu oye ti yoo fa iyipada ero tabi iwa jade ninu olugbo.

IBANI-SORO PELU AMI/AROKO:         Ibani-soro pelu ami tabi aroko mu ki a fi ise ran ni tabi bani soro pelu ise tabi ami. Bi okunrin ba fe iyawo nile Yoruba, ti o ba fie kun isana ranse sile iyawo re; aroko yi tumo sip e okunrin naa ba iyawo re ni wundia ni. Bi enikan ban sun labe iwaasu oro olorun, ohun ti olorun naa nso nipe oniwaasu ko ni ibani-soro pelu oun.
ONA IBANI-SORO:  Ona ibani-soro je ipa tabi oju opo eyi ti a ngba fi ise ranni si enikeji. Eleyi le je nipa fifi iwe ranse, nipa wiwo oko lo si ileto miran, nipa ero-ibani-soro (telephone)  tabi Mohunmaworan lati lo se bee.

Ona ibani-soro tun da lori lilo ede. Oluso gbodo mo awon ti o fe ba soro ki o le mo iru ede ti o to lati fib a won soro eyi ni a npe ni ENA.

O san fun oluso lati mo ede awon olugbo re so daadaa, lai je bee ki yoo le si ibani-soro. Lati mo awon ti a fe ba soro ma nran ni lowo lati yan iru ena ti a o lo ninu ibani-soro wa.

ENA:          Ena je irufe ede ti a maa nlo ni awon akoko tabi saa kan, yala eyi ti o jemo oro owo, ise ofin tabi ti eko nipa olorun. Oluso ti a pe lati wa baa won onimo isegun soro, ko ni le ba won soro daadaa ti ko ba lo awon ena ise isegun lati fi ba won soro. Eyi lo faa ti o fi se Pataki fun oluso lati koko mo awon ti o fe ba soro saaju ki o to wa ba won soro. Jesu maa nyi ena re pada lati enikan si enikeji. O lo omi ti o ba aini obirin ara samaria mu lati fi baa soro. O lo eja lati fi se apejuwe ohun ti Peteru, apeja yoo maa se ti o ba tele oun; “Emi o soo di apeja eniyan.”

Oluso ti o muna doko gbodo mo aini awon ti o fe ba soro ti ko ba fe si oro so. Eyi tumo si pe koko oro ti o fe so gbodo ba awon olugbo mu. Aije bee oro naa yoo jasi ariwo lasan.

IMURASILE FUN IBANISORO

1.                 Igbese akoko ninu imurasile fun ibanisoro ni ki oluso fun ara re ni oye oro ti o fe ba awon eniyan so. Ti oro ti oluso fe so ko ba ye oun funrare, a kan s’akiyesi pe oro naa ko ni ni ori beeni ko ni ni idi.
2.                 Oro akoso ninu ibani-soro gbodo je eyi ti o mun yanyan. Iriri akoko ma npe ninu eniyan. Ni igba ti awon oro akoso ba je eyi ti o fa okan olugbo mora, a je wipe oluso ti ri aye ati de inu okan olugbo ni igba naa.
Akoso oro ma nwuni lori ti oro naa ba lo taara si ohun ti yoo fa okan olugbo mora, ti a si so oro naa ti o da sakasaka.
3.                 akoso oro gbodo je eyi ti o da sakasaka, ki o ni akojopo, ki o je soki, ki o si je iwontunwonsi.
4.                 A nilo lati yan ese Bibeli ti o ba oro ti a fe so mun, yala bi emi mimo ti to wa, tabi nitori pee se naa ni o dara julo.
5.                 Ko gbogbo ero ti o ba wa si okan sile bi o ti nwa laibikita boya o wa ni sise-ntele abi bee ko. Eleyi
6.                 Tuna won ero wonyi to ni ona ti won yoo gba ba ogbon mun, ki o si rip e o to won titi yoo fi de aarin gbungbun oro naa.
7.                 Se akojopo oro naa ni ona ti yoo fi mun awon olugbo oro naa se ipinu. Akoso oro ati akojopo oro je awon ibi ti o kere ninu ibani-soro, sugbon won se Pataki pupo fun aseyori ibani-soro.

ARIWO NINU IBANISORO:         Ariwo ni ohunkohun ti o ba ndi ibani-soro ati liloye oro lowo.

Orisi ariwo meji lowa:

1.                 Ariwo Elero (Eyi ti a ro/Mechanical)
2.                 Ariwo ti Itumo Oro (Semantic)

ARIWO TI ELERO:    Ariwo ti elero ni idiwo ti o ma nti ipase awon ohun ti o nrin wa, boya ero ti o sise tabi lati odo awon ti o nsoro nitosi odo wa, o le je ekun lati odo omo kekere, erokero ninu okan, ariwo pipa ninu ibani-soro eyi ti ko wulo ati beebee lo.

ARIWO TI ITUMO ORO:  Ariwo-itumo-oro je eyi ti o ma nwa latari ailoye nipa lilo awon oro ti ko ba ogbon mu tabi lilo awon oro ti itumo re kii tete yeni. Awon elomiran ma nlo awon oro ti itumo re kii tete yeni lati fi gbayi loju awon olugbo, ti o si je pe abajade re je iporuuru okan fun awon olugbo. Fun apeere, eni ti o fe waasu si musulumi kan ti o wa bere ibani-soro re pelu oro yi: Mo fe ba o soro nipa ihinrere omo olorun: laise ani-ani, oro “omo olorun” ti oluso wi yi yoo je ki musulumi yi ti ilekun okan re. apeere miran ni eni ti o fe pe oluso si ori aga iwaasu ti oun naa koko waasu saaju ki awon eniyan le ba mo pe oun naa mo bi a ti waasu daadaa yo ti je ki oro ki o su awon eniyan ki oniwaasu to bere.

Nitorinaa, ariwo le ti inu iwaasu jade, o le wa lati inu ayika, o le wa lati odo oluso, ohun ti a le se nip e ki a ni imurasile fun un ni gbogbo igba ki a si gbidanwo lati ma gba a laaye lati di ibani-soro wa lowo.

ASE ENIYAN:  Ninu gbogbo olugbo ati oluso ni ase wa. Ase yii ni ohun ti a ma nlo lati fi woye gbogbo oro ti o nbo sinu okan olugbo. Ase yii lo ma nso boya ki a gba oro kan tabi ki a ma gba a, o wa se Pataki nibiti a de yi lati se apejuwe bi ase yii ti ma nsise ninu eniyan.Eyi ni bi ase ti ma ngbo oro.

Gbogbo wa pata ni a ni ase nipa eyi ti gbogbo ifitoni-leti ti o nbo ngba wole. Ase omi ma nmu awon idoti ti o ba wa ninu omi kuro ki o le ku ojulowo omi nikan. Nigba ti oro ba to eniyan kan wa, yoo lo taara sinu ase yi eyi ti o ni iriri aye ati beebee ninu. Iriri/iwoye aye je awon iwoye ati igbagbo nipa igbe aye. Gbogbo nkan ni a ma nkoko wo nipa oju iwoye ati igbagbo nipa oju iwoye yii. Ipele ti o tele eyi ni eko ati iriri eni. Eko ati iriri eni yi ni awon ohun ti eniyan gbagbo fun ara re pe otito tabi iro ni; fun apeere: Olorun wa, aye ri roboto ati beebe lo. Ipele ti o kan ni ero/oye eniyan nipa awon igbagbo wonyi. Awon ero yi ni a npe ni iwa/ise-si eda. Eyi ti o keyin ninu ase yi ni ohun ti o mu wa yato si ara wa, eyi ni a npe ni eeyan ey tin se aapo ohun ti a je nipa ti emi, ara ogbon, imo ati ipo wa ni awujo. (Luku 2:52)


ASE ENIYAN


                                                Ibani-soro
                                               
                                     
                                                Iriri/iwoye aye


                                                Eko ati irire eni


                                                Igbagbo ati iwa eni


                                                Iwa/ise eda.







BI ASE TI NSISE: Ti oro kan ba so wipe “Jesu kii se omo Olorun” ti o ba je onigbagbo gidi, ase re ko ni ki oro na ko koja. Isira-si re si iru oro bayi yoo yato si ireti oluso oro naa.  Eyi le mu ki o ti ilekun ase re pa gboingboin tabi ki o ko lati teti sile. Eniyan tile le teti sile lati gbo sugbon ki o mommo si oro naa tumo tabi ki o ko leyin-o-reyin lati te si ohun ti a baa so.

Ni ede miran, bi Kristieni yoo se sira si iru oro ti o wa loke yi, bee ni musulumi naa yoo se sira si oro ti o ba tako igbagbo re.

Nitori naa, lopo igba, iyato ma nwa laarin ohun ti oluso nso ati ohun ti o ye olugbo. Nitori idi eyi, o ye ki oluso gbiyanju lati mo iru ase ti ninu re lati mo iru ase ti o wa ninu olugbo ki o ba le gba ona ti yoo mu esi daradara wa leyin ibani-soro, ati bi a ti ndojuko o, oluso yoo wa joko lati tun ero re to ni ona ti o je pe ero re yo lo ni sise-n-tele, aije bee yoo da oro ru.

IBANISORO WA NIGBATI AWON NKAN WONYI BA SELE:

1.                 Nigbati agbara ati jo so oro bati sonu, ti o se aare tabi ti o baje.
2.                 Nigbati awon eniyan ba n jagbe mo ara won ti won ko lati fi eti bale.
3.                 Nigbati a ba si ero okan tumo.
4.                 Nigbati awon eniyan ba puro fun enikeji won.
5.                 Nigbati ibasoro alapejuwe bad a iporuru okan sile.
6.                 Nigbati iberu bam u idaloro wa ti ife si farasin.

IDIWO SI IBANISORO FARAHAN NIGBATI NKAN WONYI BA SELE

1.                 Nigbati a ba ri aworan enikeji ni ona ti o buru.
2.                 Nigbati asa wa ko ba baramu
3.                 Nigbati ijakadi ba wa lori ife inu ara.
4.                 Nigbati a ba ni ete ti a fi pamo.
5.                 Nigbati a ba njijakadi lori agbara.
6.                 Nigbati a ko ba lo otito Bibeli daradara ninu aye wa.
7.                 Nigbati a ba n bomi rin eta inu.
8.                 Nigbati a ba ni ironu odi.
9.                 Nigbati a ko ba fi aye gba fifesi.
10.            Nigbati a ba n gbe igbe aye fifura.
11.            Nigbati a ba n jijakadi lori awon ojuse.
12.            Nigbati a ba ni iwa aiseeyipada.

OLUFETI SILE

·                   Olugbo ni eni naa ti o nko ipa ninu ibanisoro.
·                   Olugbo kii se eni ti o ko gba oro naa.
·                   O tun oro naa se, o si tun su si ero iwoye aye.

AWON OHUN TI OLUGBO NSE SI ORO NIPA JESU

1.                 A maa tun oro naa gbe:-fun rere tabi buburu
2.                 O ni oye oro naa ni ona kan tabi omiran.
3.                 O n gbegbese lodi tabi fun oro naa lori ipinle ibi ti oye ye mo.

AWON OHUN TI A NILATI YAGO FUN NINU IBANI-SORO

1.       Ariwo ti ko ni itumo: Opo oluso tabi oniwaasu lode oni ni won rope agbara oro siso wa ninu ki a maa pariwo sa. Ariwo ko ni ohunkolohun se pelu ifororoyan. O seese ki ohun oluso goke laarin meji oro, iyen ko tumo sip e o ni ati p’ariwo jakejado ibani-soro re lopo igba lo je pe lati inu itara lasan laisi imisi kan ni ariwo pipa ti ma nwa. Mase bere oro pelu ariwo, nitori pe oo ni le paa jale.

2.       Irinke-rindo ti ko ba ogbon mu: A ko lee sa fun irin sotun tabi si osi ninu ibani-soro patapata. Sugbon ti o ba ti poju yoo tumo si ariwo.

3.       Atunwi awon oro:  Awon oro bii Ke Alleluya” “amin” ni a le lo ni ona ti o ba ogbon mu, won kii se oro ti a ma nlo nigba ti a ko ba ri oro so mo. Ti o ko ba mo ohun ti oo so mo, jowo gbe enu re dake ki o si lo joko. “alleluya” je oro iyin ko si ye ki a loo ni ilokulo.

4        Yiya-kuro loju ona ti ko ba ogbon mu:  Ni igba miran oluso a ma ya kuro loju opo ti o ntoo bo ninu ibani-soro re. sugbon ni igba yiya kuro loju ona yi ma n fa idaru dapo ninu ibani-soro. Eni ti a ni ki o soro lori omi, sugbon nitoripe o feran ina ju omi lo wa soro pupo lori ina ju omi lo; iru eni bee kii se oluso ti o muna doko. Eyi lo fa ti oluso gbodo je eni ti o ni eti lati fi gbo oro daadaa.  Nigba ti  a ba ni ki o so oro lori igbagbo, ma se so oro lori adura, won kii se nkan naa.

5.       Fifi imo ti ko to han: A ti rii fun opo odun seyin pe awon eniyan feran lati ma so nipa aseyori won atijo. Eniyan lee waasu oro kan nibi kan ki oro naa si bukun awon ti o gboo. Ohun ti o ma nsaba sele nipe, nigbati oniwaasu yi ba tun ri anfaani lati waasu, oro re ana ni yoo tun fe lo, bi o tile je ifarahan igberaga ati aibikita fun ohun ti o to. O dara lati toka si oro ti a so lana ti iru itoka bee ba oro t’oni mu, sugbon ri daju pe o tete pada si oju opo re.

6.       Iwa ibaje nipa Akoko Lilo: Lilo akoko wa lara ibani-soro. Ri daju pe oro re mo niwon, nitori pe kii pe ti oro fi ma nsu awon eniyan. Ti oo ba ti e lo koja akoko ti won fun o, koye ki o ju idamewa si ogun lo ninu ogorun. Fun apere, ti o ba je iseju meedogun ni o ye ki o lo, ti o wa lo ogbon iseju, iyen tumo si pe o ni iko-ara-eni-ni-ijanu nipa akoko.

7.       Isoro Ara Eni: Ni igba ti o nba ni soro papa ninu ijo, jowo year fun isoro ara re tabi ija laarin iwo ati enikan ninu oro re. Jowo so oro nipa isoro awon eniyan. Oluso aguntan Paul Jinadu so ninu okan ninu awon iwee re “Eni ti o ba kuna ninu iriri yoo lo lo sori aga iwaasu lati lo soro nipa isoro awon eniyan ti o joko niwaju re.”

8.       Pipari Ija:  Opo awon iranse olorun ni won ti gori aga iwaasu pelu iwaasu akanse lati doju ija ko enikan ti o se won ninu ijo. Eleyi kii se ibani-soro rara. Ti o ba ni wahala pelu enikan ninu ijo, ori aga waasu ko ni ati nna tan bi owo. Iru iwa bayi yo kan o labuku lojo iwaju nitori pe oye yo ye awon omo ijo lojo kan pe iwaasu re kii ti odo olorun wa. Ti enikeni ba se ohun ti ko ti , seto iwadi ti o ye ki a si bi iru eni bee ni ona ti o to. Opo ijo lo ti so idagbasoke ti o dara nu nipa iru iwa ibaje yi. Opo iranse olorun ni o si ti so ola ati iyi won nu nipa ailoye yi.

Ni akotan, “Ni tori gbogbo wa ni a ma nsubu ti a ma nkose ninu ohun pupo. Ti enikan ko ba si kose ninu oro siso-ti kii so ohun ti ko to-oun ni eni ti o dagba ti o si je eni pipe, ti o le ko gbogbo ara ati eda re ni ijanu…bee gege ni ahon je eya kekere ninu ara, o si le foun ohun nla. Wo opolopo igi tabi aginju nla tie se ina kekere le jorun! Ahon si je ina. (ahon je) aye ika ti a fi si eya ara wa ti o nja idibaje ti o sin se idiwo fun ara ti o si nki ina bo ibi eniyan-eda eniyan-eyi ti a ki ina orun apadi bo.” (AMP)

Mo gbadura pe ki OLUWA se o ni Oluso ti o poju owo ni oruko Jesu.

No comments: