GROUND OF TRUTH BIBLE INSTITUTE
IJO ATI ISE IRANSE AWON OMODE 
Lakoko, a ni lati mo itumo
ijo ati kini ise iranse awon omode.
IJO: Ijo je awon eniyan
kan ti a fi eje iyebiye ti nse ti Jesu Kristi ra pada, awon ti a ti ra ni iye
kan ti won si tun ti di atunbi.

ISE IRANSE AWON
OMODE
1. Ise iranse
awon omode je akojopo awon ona ti a le gba ko awon omode ni eko nipa ibagbepo
eda, ti emi, ti oro Olorun, nipa ti ara ati nipa imudagba onigbagbo.
2. O je kiko
omode ni gbogbo awon ona ti Olorun, lati le wa ni abe aabo, itoju ati ibukun
Olorun, lati le di awon ileri Olorun si awon onigbagbo mu lati gba iye ninu
Jesu Kristi.
Niwon igba ti a ti mo awon
eyi, ibeere mi ni wipe; nibo ni awon omode duro ninu ijo wa? Se aarin gbungbun
ni won wa tabi egbe kan? Nje eto awon omode yii wa ni ibamu pelu Olorun?

IDI TABI PATAKI ISE IRANSE AWON OMODE
Igbekale eko yi ni lati
ran awon Oluso-aguntan ati awon Oluko ewe ijo lowo nipa awon ilana yi:
a. Nini iran je pataki ninu ise wa
b. Ko bi a ti nba awon ewe soro ni ona ti o muna doko.
Fun idi eyi gbogbo ijo ti
o ba ni omode ninu okan won ni a ro lati bere eto ise iranse awon omode lati le
mu won dagba soke fun ojo iwaju.

AWON IDI
1. Ase Oluwa ni Dent 11:18-31
2. Jesu fi si ise Mk 10:14, Lk 18:15-17
AWON IBI AKIYESI NINU
ISE IRANSE OMODE
Awon ibi kan se pataki ti
a ni lati yewo ninu eyi ti a o ti mo ise iranse (Ministry) ewe:
a. Awon ibi ti
o ye ki a tejumo Owe 29:17 Ni igbesi
aye ewe, akiyesi se pataki. Ninu eyi pelu ni a ti gbodo wo:
(1)
ibawi tabi atunse (ii) idanileko Owe 4:3-4
b. Awon ibi ti
a ko ti nani omode: ohun ti o buru ju
ni pe omo ti a ko nani yoo padanu ohun pupo Owe 29:15, 13:24. (i) ikosile (ii)
akoso ise ati bi ti o ti jina si (iii) a iri awon ohun igbalode fun won (iv)
Aiko si abo ti o peye: lilaju si isekuse, Jagidijagan abbl.

ILANA BIBELI FUN ISE IRANSE AWON OMODE
Ise iranse omode je ohun
ojo pipe. O ti wa lati igba dida aye.
KI A WO NI ONA ERO
Adamu ati efa ko awon omo
won (kaini ati Abeli) won ko won ni ona Oluwa, tabi ki a kuku wipe; Olorun
funrara Re lo ti ko won, bi be ko Oluwa ko ba ti ko ore Kaini Gen .4:9. Oro yi
fiye wa wipe Kaini mo ohun ti o dara.

KI A WO NI ONA TAARA
Ona taara je ona ti o po
sugbon a o te pele mo ona ti Abrahamu ati Mose.
1. Abrahamu ni a doju ko taara pelu ojuse lati moju to
agbo ile re Gen 18:17-19.
2. A pase fun Mose
lati ko awon omo Israeli ki won le ko awon omo won.
Nipa bayi, o je ojuse ebi
ati ijo lapapo.
1. OJUSE EBI
Mose palase pe ki ebi
kookan won ko awon omo won Deut 1:7, 11: 19. Ninu Deut 6:7 a ro awon obi lati
ko awon omo won lai saare nipa wipe nigbati won ba joko, dide, tabi rin, eyi
tumosi wipe won ni lati ma ko won ni igba gbogbo. Kise kiko nikan, won gbodo
pase fun won lati ma tele ilana Olorun. Deut 32:46.
2. OJUSE IJO (DEUT 31:11-13)
Kiko omode ko duro ninu
ebi nikan, ijo na gbodo ko ipa pataki. A gbodo tele ilana ati igbekele eko,
awon omode ni lati gbo, ko, beru, ati lati se ife Olorun. Rom. 10:9; matt
11:29, Owe 1:7, 9:10 Eyin a ma waye nigba ti gbogbo awon omode wonyi ba korajo lati orisirisi ebi lati
keko oro Olorun.
3. OJUSE TITI LAILAI
Okan Olorun dara si Israeli
gege bi ti ijo loni lati tesiwaju ninu ise iranse omode ninu ebi ati ninu ijo
agbegbe eleyi gbodo je asa titi lai Deut 4:9. Olorun fe ki o ma tesiwaju ki
ibukun re ki o le ma san lati iran de iran Deut 7:8,9,12&15
4. JESU ATI AWON APOSTELI
(a)
Jesu feran awon
omode o si n gbadura fun won, o fi won se apeere
ijoba
Olorun Mk 10:13-16
(b)
A ko gbodo se
awon omode Matt 18:5-6, Col 3:21.
(d) Awon obi ati awon adari ijo agbegbe
gbodo je alapere rere ti
awon omode
wonyi gbodo tele fun igbe aye won. 1 Tim 3:1-9, Titus 1:1-6

IDI TI EMI
Olorun ko le pa awon
eniyan re lase lati se nkan lai ni idi. Awon ete Olorun ninu eko ise iranse
awon omode ni a to leselese sile ninu Orin Dafidi 78
Ki won ki o le “Mo” ese 6a
Ki won ki o le “ranti”
Ki won ki o le “Fi ireti
won sinu Olorun” ese 7, 1 Sam 17:32
Ki won ki o ma le “rin ni
ona ese ti awon baba won ti nrin” ese 8

AWON ONA TI A LE GBA SE AWON
OMODE
Oniruru ona ni a le gba se
awon omode ti awon obi won ati awon adari ijo won ko ba se akiyesi:
1. Nipa pipa iro mo won
2. Nipa ariwo pipa
mo won
3. Nipa ailepese fun won
4. Nipa aifi aye
gba won lati ri eyi-keyi awon obi won.
5. Nipa tito sona tabi nina won nigba ti won ko mo ohun
ti won se.

AWON ERO BUBURU NIPA ISE IRANSE
AWON OMODE
Opolopo ero ni o wa leyin
idasile Ise iranse awon omode ti o le ran idile lowo ati ijo. Sugbo o seni
laanu wipe gbogbo awon erongba yi ni a ko se amulo bi o ti to. Ju gbogbo re lo,
eyi je ki won o bo sinu erongba buburu. Awon erongba buburu naa ni wonyi:
A. Ki a kan mu owo won di ni ibikan ni tosi ile ijosin ki
won ma ba di isin awon agba lowo.
B. Ki won ko eko oro Olorun fun isin ajodun lasan ki won
si se afihan imo won laisi ifi oro Olorun si ise.
D. Sise awokose
awon ijo miran nipa ise iranse awon omode laini igbaradi to koju osunwon lati
ba aini ati ipenija ise naa.
E. Ise Iranse
ikowojo lasan. Won a ma lo lati gba owo ti ko leto lowo awon omo ijo.

PINPIN AWON OMODE SI IYARA IKEKO
Gegebi iwe atumo, oro ti a
npe ni omo tumo si omodekunrin ati omodebinrin. Ni ona miran ewe, atun le pe
awon , omode ni awon ti ko i tii tojuubo, ti ojo ori won bere lati omo oojo si
Odun Merinla ni ojo ori.
Bayi, bi a ti se mo awon nkan
ti omode je, pipin si iyara ikeko yoo yato nitori ojo ori ati oye won ati
agbara oluko kookan.
i.
Lati omo oojo
titi de omo odun kan ni a le fi sile pelu awon obi won, awon wonyi ni omo omu.
ii.
Odun meji si odun meta aabo, awon ewe weere
(ounje ati itoju)
iii.
Odun merin si
odun mejo, awon omo ile iwe alakobere (orin kiko).
iv.
Odun mesan si
odun merinla. Kiko eko oro Olorun titi de fifi si ise ninu igbe aye won.
Nipase gbogbo pinpin awon
ori wonyi, nitori ogbon tabi ihuwasi won, won ko gbodo ju mewa lo ninu yara
ikeko. Iye omo ti o kere ju ti oluko kan le lagbara lati ko, ko gbodo ju marun
(5) si mefa (6) lo ni yara ikeko.
Bi o ba seese a le ni
oluko meji ni yara ikeko kan, bi ko ba ri be, yoo re eyo oluko kan.
AWON EKO NINU ISE IRANSE AWON OMODE
Gege bi a se pin ojo ori
won, gege be ni eko won se gbodo ri. Awon kan wa ti won ko nilo ju orin Olorun
lo, awon miran itan inu bibeli, awon miran ese akosori lati inu oro Olorun.
AKIYESI
FUN AWON OLUKO OMODE
Gbogbo oluko ewe ni yoo bi
ara re ni awon ibeere nipa ohun ti won o ko ni yara ikeko won.
Awon
ibeere naa le lo bayi:
(1) Ta ni mi? :- Labe ibeere yi, awon nkan bayi ni a gbeyewo
(a) Nje mo je Onigbagbo ti o ni idaniloju eko ti
o fe fi ko awon omode?
(b). Nje oro wonyi ko ipa
kan fun mi?
(d) Nje won ba aye ode oni mu?
(2) Tani
Olugbo/Olutetisi oro mi? ;
(a) Nje mo nsoro pelu awon ti won dogba ni ojo ori?
(b) Nje awon ojo ori kan wa ti o ye ki ngbe yewo?
(d) Ede wo ni o le ye won? Ede ti o lagbara tabi ede ti o rorun?
(e) Bawo ni o se rorun si lati de odo won?
(e) Kini ohun ti won nilo ju?
(3) Kini
ilepa mi?: Nje o rorun lati se itoju
won ki a si boju to won pelu ayo ati idakeje?

AWON OHUN ELO TI A NILO NINU
ISE IRANSE AWON OMODE
Opolopo awon ohun elo ni o
nbe ti a nilo ninu ise iranse awon omode eyi ti yoo ran ni lowo gidigidi lati
mu ki eto Olorun wa si imuse ninu aye won. Apeere ni wonyi:
(i) Bibeli
(ii) Awon iwe (iii)
Iranlowo : eyi ti yoo wulo fun afihan awon eko gegebi aworan, ohun ti
aya abbl. (iv) Awon ami: eyi ni awon ohun elo ti a lee ri ti
awon omo si le muu dani.
ALAIGBORAN
OMO ATI IJIYA
Ti a ba ri awon omo ti o
ya alaigboran dajudaju o ye ki ijiya o wa fun iru omo be. Ti ko ba si ijiya
tabi ibaniwi, iru aigboran bee yoo wopo larin awon omode, eyi si le dari won
kuro ninu ife Olorun.
Lakoko na, a gbodo mo
kinni itumo Alaigboran omo? Owe 23:12-14. Oro yi fi han wa wipe Aya Omode ni aigboran
disi........nitorina, alaigboran omo tumo si elese omo.
Ijiya:- Oro yi ijiya
tabi ni ona miran ikora ni ijanu. Eyi tumosi pe ki a so awon omo wa di omoleyin
ni ona Olorun Efesu 6:4 A si gbodo ko awon omode ni ibawi ni ona wonyi:
(a). ITONI: Eyi ye ki a se amulo re si
gbogbo eka aye won, nitori pe awon omode yoo fe mo ohun ti o ye ki won se, yala
ni aarin awujo tabi ile ijosin.
(b) IGBORAN: Ohun ti
ibawi tooto nmu wa ni igboran. Omode ti o gba itoni fun igbe aye gidi ni o le
fi owo fun ase tabi ilana ti a la sile fun-un. O n ko eyi, ti won ko ba bowo
fun ase yii, ayorisi re ko ni dara.
(d) ATUNSE: Heb. 12:6,
Owe 23:13-14, Owe 20:11. Ti a ko ba ba awon omode wi, won yoo ma ru awon ofin
ati ilana ti won ba la sile fun won, ti iwa aigboran yoo si gbile ninu aye won.
(e) IKORA
ENI NI IJANU: Ikora eni ni ijanu gbodo je ilepa wa ti aba nko awon omo wa.
Eyi ni ki eniyan ni oore ofe lati le ba ara re wi, eyi ni ipa lati so pe beko
ni akoko ti o ye abbl.

SISE AKOSO ISE IRANSE
AWON OMODE
Eto isakoso ise iranse
awon omode gbodo ri gege bi ti isakoso
ise iranse ti awon agbalagba. Sugbon, a ni lo awon adari lati wa ni awon aye
kan fun ija gaara ise iranse, ara won ni:
a.
Akowe (b) Akapo (d) Akowe eto owo (e) Akowe eto ayeye.
Eyi ni awon oloye/adari ti
o le ma se ise ni ile ise iranse awon omode. Nigbati awon oluko yoo je igbimo
fun ile ise iranse awon omode.
Ni ile ise iranse awon
omode ti o tobi/gboro, gbogbo awon oloye ati awon oluko ni yoo je omo igbimo.

OJUSE AWON IGBIMO
1. Lati seto idanileko odoodun fun awon oluko.
2. Lati ri pe eto fun awon omode nlo deede.
3. Lati jiroro lori bi won o se ni eto idanileko to jinle
fun olokan ojokan awon oluko titun ni odoodun.
4. Awon igbimo ti gbodo seto saaju akoko ti awon nkan
wonyi yo waye lodoodun.
5. Awon igbimo gbodo se igbelewon gbogbo awon eto won
odoodun ki won si wona fun idagba soke sii. Awon eto bii:
i.
Akoso ise iranse
awon omode
ii.
ojuse awon igbimo
iii.
Awon oluko ile
eko ojo isinmi
iv.
Idije Bibeli si
awon omode.
v.
Eto akoko isinmi
fun awon omode,
vi.
Eko bibeli.

IPENIJA FUN ISE IRANSE AWON
OMODE NI AKOKO TIWA
Gbogbo awon ipenija ti
awon omode nkoju ni aye ode oni npe fun akiyesi oju ese ninu awon ile ijosin wa
loni, ki a ba le mu awon omo wa, wa sinu ife Olorun.
Ki Olorun ma je ki a jebi lori
omo ti a fi fun wa tabi ti a ko le wa lowo. (Amin)
GROUND OF TRUTH BIBLE
INSTITUTE
No1, Aboderin Street Agbaje
Orita Challenge Ibadan
Website- www.groundoftruth.net.ms
MOBILE: 08056008526 &
07031821386
HANDOUT
CHURCH
AND CHILDREN MINISTRY
![]() |
![]() |

ADVANCED
CHRISTIAN LEADERSHIP
100 LEVEL


No comments:
Post a Comment