GROUND OF TRUTH BIBLE INSTITUTE
G. P. O. BOX 17171 DUGBE IBADAN
EKO IJERE-OKAN
(A) ETE-EKO
YI:
(i)
Lati ran awon Olukopa lowo lati
se awari ebun won tie mi ati bi won yio se le lo daradara.
(ii)
Lati ni iran ti o jag ere fun
ijere okan, ise iranse gbogbo agbaye, ati ojuse akoko fun ijo majemu titun.
(iii)
Lati ko awon adari kristieni
ati awon osise ni orisirisi ona ti ijere okan, ati ona ibanisoro ti kristieni,
gbingin ijo, itopase ati idagbasoke ijo.
(iv)
Lati ko awon adari ati awon
osise, bi won sele rannilowo lati ko awon alagbase ti o ku fun ijere-okan
gbogbo agbaye, Jesu wipe “E ma sise titi
emi yio fi de”
“Laisi awon iranse ti a ran jade ti ana, a
ko le ri awon kristieni ti oni”
(B) ITOKASI
Ise ijere-okan nikan ni ise ti Jesu
Oluwa wa fi le awa onigbagbo lowo nigba ti o ngoke re orun (Maku 16:15) sugbon
loni o seni laanu wipe awon eniyan die pereje ti won ni okan ikanu ni won nse
ise yi. Bi o ti le je wipe lati jade kureo nile eni lo si ile elomiran, kiise ohun
to rorun rara iye awon tin won ba ni okan ikaanu fun awon okan ti o nsegbe lo
le se ise naa. Ikaanu fun okan lo le mu itiju kuro. Mase gbagbe wipe, a kan
Jesu Oluwa wa mo agbelebu laarin awon ole meji, lehin odi ilu, ni ikorita, ti o
mu ki won o ko akole le lori ni ede Heberu, Latini, ati Girikki. Nitorina, iru
ibi bayi ni awon kristieni ti lepin oro ise ti a fi ran wa pelu ife, nitori eyi
gan ni ojulowo ohun ti Kristieni dale. Eje ki a ranti wipe Emi-Mimo ma rin
nipase wa, awa ni tempili mimo re, ti owo wa ba di ti a ko ba jere okan, ko ni
ona miran ti yio gba, o ngbe ninu ago ara wa.
Awon elese ti o wa ni agbegbe wa ko ni ni ibewo Oluwa ti a ko ba lo
bawon soro loruko re (Jesu). Gbogbo awon ti o saisan ati awon ti o wa ninu
tubu; a ko ni be won wo, pelu Emi-Mimo, ti a ko ba lo lati lo ba won ni oruko
re (Jesu). Awon eniyan ko ni ri Olorun – afi ti won ba ri nunu aye wa. Ife
Kristi le farahan nipase wa. Ikaanu re fun awon elese ni a le gbe jade nipase
wa. Jesu Kristi be agbegbe wa wo nigbakugba ti a ba se be, opolopo kristieni
maa nso wipe “awon ni ipongbe okan fu
awon to nsegbe nitori a ma n pe ipade adura fun awon, ore mi, eleyi ko ni
Jesu ni ki a se. Ko so fun wa ki lo si ile-ijosin lati lo lu agogo, tabi ki alo
gbadura fun elese lati wole wa. Sugbon o pa wa lase lati lo si igboro ati
Abuja ona ki a si mu nwon wa, ki ile mi ki o le kun (Luku
14:23).
Nigbati a ba nsoro nipa ijere-okan, o ye ki a ranti otito ti o ye
koro yi wipe “elese kii lo si ile ijosin; a ko le jere okan awon ogoro eniyan
wonyi lati inu ile-ijosin, a gbodo jade lo jere okan won ni. Apeja ko ni pa eja
ninu ile-iwe, tabi ki agbe arokobodunde maa ko ere ninu iyara ijeun re,
nitorina kristieni e jade lo si ibi ti elese wa.
Lati fi kun ipongbe okan wa, titi fi di odun 1972, awon millionu
meedogun awon Ju, 315 millionu Mohammedans, 170 millionu Buddhist, 350 millionu
awon ti o ku, awon ti Kristi ku fun, ti a ko I tii wasu fun pelu ihinrere ti o
ni ibukun. Ni orile-ede Amerika, metadinlogbon millionu awon odo ni ko ti gbo
ihinrere; okandilogorun eniyan lo ma nku ni iseju kookan. Millionu kan ni ose
kookan. Olufe, mo fe ki o mo wipe, ko ni si itujade emi bi ti ojo pentikosti –
laisi ohun ti yoo na ni, o gbodo na o ni nkan ki o to le di ohun ti Olorun fe
ki o da, nini ami ifororo yan, tabi ebun Emi-Mimo nikan ko to. O gbodo se ise
ijere-okan, ki ami-ifororoyan re ba le ma san daradara. (Maku 16:15). Ore mi,
se ise ijere-okan bi eni wipe ko si ojo tabi akoko miran fun o lati se. Bi ko
ba je iwo, tani?, ti ko ba je nisisiyi nigbawo ni? Igbala re je oro ti o kan
eni kookan gbongbon.
ALAYE ITUMO
(a)
Ijere-okan je jijeri ihinrere
pelu okan ti o gbina fun Kristi ati lati ko ni leko, ati wiwasu pelu okan wipe
a o so awon ti o gbo oro naa di omo-ehin. (Ise A. A.7:54).
(b)
Ijere-okan ni biba ni soro ni
asoye ati ni ona ti o muna doko nipa irohin-rere ti Kristi ati igbala re, ki
enikookan le se ipinnu fun tabi lodi sii.
(d) Ijere-okan
ni pipo longo ihinrere pelu ete lati roe lese ti o nsegbe lati fi igbekele won
sinu Olorun.
ORISUN ATI OKUNFA
IJERE-OKAN
Olorun ni o seda eniyan, lehin ti a
ti da eniyan tan, Olorun sure fun, o fi sinu ogba edeni fun iyiriwo (Gen.
2:15-17). Eniyan subu, idajo Olorun wa sori ejo, esu, obinrin na, okunrin na,
gbogbo aiye ati ohun gbogbo tin be ninu won. (Gen. 3:14-19; Rom. 1:18-25). Ese
yi lo fa iyapa laarin eniyan ati Olorun. Laisoro ipokipo ti eniyan le wa,
gbogbo wa die lese niwaju Olorun, (Rom. 3:23; 6:23; 5:12). Eleyi lo fun esu
lanfani lati se ohun to ba wu fun omo eniyan gbogbo aiye lo wa labe ebi, ibinu
ati egun Olorun lati igba naa, ese yi ti wa se akoba fun igbe aye omo ‘niyan
ninu emi, ara, isirasi, opolo, imolara, lati igba na, eniyan wa nilo enikan ti
yoo mu pada sodo Olorun ti o seda re. Ninu Ogba edeni, Olorun ni ajihinrere
akoko. (Gen. 3:9).
AWON OHUN TI O WA NINU
IJERE OKAN
(a)
Irin- Olorun ni ajihinrere
akoko ti o lo si Edeni
(b)
Lo sibi ti awon elese wa
(d) Nina ohun pe
(e) Ikannu – sise itoju nwon.
Nwon gburo Olorun, nwon si fi ara nwon pamo, won ko le ri Olorun mo,
sugbon nwon gburo re. Ibeere ti o too wa bayi ni wipe, Nje o si maa nri Olorun
ninu aiye re, ile-ijosin, ise-iranse, okowo tabi iro re lasan lo ngbo?
ORISI-ONA TI A NGBA JERE-OKAN
Orisirisi ona la ngba jere okan sugbon oro kannaa ni, ete kannaa ni
ilepa kan naa ni. Awon wonyi pelu ona ti a maa ngba:
(a) Ijere-okan ti ilu tabi ti ologooro ero (b) Ijere-okan
ti oju popo
(d) Ijere-okan Abule (e) Ijere-okan
ti iwe kiko
(e) Ijere-okan ti ere ori itage (f) Ijere-okan ti iwe pelepe-ilewo
(g) Ijere-okan ti sinima (gb) Ijere-okan ti ero agbohun sile ati
ero-ibanisoro
(h) Ijere-okan ti ojule de ojule (i) Ijere-okan ile-iwosan ati ogba ewon.
ITAN IJERE-OKAN
Bi a ba fe soro
lori itan ijere-okan, yoo mu wa lo si awon wahala ti o de ba ijere-okan
IKU IJERE-OKAN
Ijere-okan ku ni gbogbo agbaye, ni
irinwo odun lehin iku oluwa wa (Jesu) (by 400 AD). Ni saa ipele ti o tele akoko
majemu tuntun, ijo wonu ariyanjiyan ti imo ijinle ninu Bibeli, eyi ti o gba ipo
ijere-okan ati fifi igbala ati igbagbo eni sile lo sinu ona miran lo wa yori si,
nitorina ni akoko saa ipele kerin (4th century) akoko ti o sokunkun ti bere.
Fun odidi egberun odun, (1000 years) Olorun ko ri olooto ajeri fun un.
TITUN IJERE-OKAN BI
Pelu iranlowo awon alatunse ni (1,
500’s) ni asawari bi Bibeli se seto igbala tabi bi o se fe ki igbala muna doko
to, titun sawari awon ohun kan ti Bibeli so nipa igbala i.e. bi idalare nipa
igbagbo, pelu eyi lase ri eredi ti a fi gbodo se ijere-okan. Lehin iku ati
titunbi ijere-okan ni isoji ijere-okan ti gbogboogbo farahan, iyen nipe lati bi
(1,730 years ago) egberun meji odun o din die seyin, ni a ko ti kan ijere okan
enikan si enikan si, gbogbo eniyan wa doju ko iwasu olopo ero nikan.
IJERE-OKAN ELENIKAN-SENIKAN
Ijere-okan elenikan senikan yi je
akitiyan onigbagbo pato kan lati mu eniyan pato kan was sodo Olugbala pato kan
ni akoko pato kan. (Act. 20:20; Owe 11:30).
(1)
Isodi pupo ti eda, igi
lorisirisi ati eranko (abbl)
(2)
Isodi pupo ti emi, gegebi ohun
gbogbo ti Olorun da ni ti ara se nbisi bakannaa ni o ri nipa tie mi.
AWON APEERE
(a)
Apere ti Jesu: - (Mk. 3:14-15;
16:20; 4:18-22)
(b)
Ase re: - (Johannu 15:16; Matt. 28:19-21)
(d) Ijo-akoko: - (Acts 2:42-44; 11:22-26;
20:20)
(e) Paulu apere ti o dara: - (Acts 14:21-22;
2 Tim. 2:2)
IYAGAN
Ami buburu ni eyi, gege bi awon obi
nipa ti ara se maa nwijo nitori awon omo won ti o ba yagan, won a si ma fie bi
gbogbo sori iyawo, be gege ni inu Olorun ko dun nipa ti awon omo re ti nwon
yagan ninu emi.
DIDAGUN SOJU KAN
Eyi ni adagun odo ti ko san. Omi ti
ko san jade tabi gba wole, iru omi be yio da wahala ti o po sile fun awon
eniyan ti o wa lagbegbe re. awon nkan wonyi la le ri ni adagun odo-omi.
(1)
Efon – (mosquito)
(2)
Awon eweko ti o jabo sinu odo –
idale si (ogunpa)
(3)
Ko ni see mu fun awon eniyan
(ogunpa)
(4)
Ejo le gbe ninu re
(5)
Oorun bi ogunpa tabi geege
(6)
Ewu fun awon omo kekeke ti o
nsere lagbegbe
(7)
Yoo je ibanuje dipo ayo. (abbl)
Idaduro tabi adagun farahan ninu bibeli leemeji, Olorun si koju ija
si, ti o si fin nsan bi o ti ye nigba meji.
(a) IDADUDAPO NI BABELI: Olorun
pase wipe ki awon eniyan o tun kakiri ki won si gbile ka gbogbo aye sugbon awon
eniyan pinnu lati se lodi si ase Olorun, Olorun ni lati lo agbara re mu won tu
ka kiri. (Gen. 11:1-9). Ijo ti o ko lati jade lo waasu, ko lati san ati wipe o
je adagun, iru ijo bee si lewu fun idagbasoke ati ilera ijo.
(b) IJO AKOKO: Ninu Ise A. A. 6:1 bakanna Ise A. A.
8:1-4, akosile adagun miran tun farahan, nigbati awon omo ijo nposi lojoojumo,
ti ko si se eto fun ijere-okan, wahala nla sile, Olorun gba awon (Ju) laye lati
so okuta lu Stefanu ti o fi ku, nigbana inunibini ti o le dide si nitorinaa ijo
ni Jerusalemu. Gbogbo awon ti o tuka si nwasu oro na kakiri ko awon ara ki o si
fun won nise lati se, ran won jade ki won lo waasu.
AWON ILANA PIPOSI NINU EMI
(1)
Lati odo Paulu Aposteli na si
Timoteu
(2)
Lati odo Timoteu si awon olooto
iranse – eniyan.
(3)
Lati odo awon olooto eniyan si
awon miran.
KINNI IHINRERE (GOSPEL)
Oro na, ihinrere je oro Giriki meji
ti a so papo di eyo kan, Rere ati Iroyin – (Gos and pel). Nitorinaa “Gos” lo
tumosi rere – (good) ati “pel” tumo si Iroyin (news).
Nitorinaa, IHINRERE TUMOSI, IROYIN – TABI IHIN-RERE
(Gospel means Good News).
Opolopo orisirisi ihinrere lowa,
bii: Ile sisi, bibimo, igbeyawo, rira oko ayokele, (abbl) sugbon ihinrere ti a
so fun wa lati waasu re ni Jesu Kristi Oluwa wa, lati je ki elese o mo iroyin
rere nipa ti iku ati ajinde ati igoke re orun Oluwa wa Jesu.
KINNI IDI FUN IHINRERE
Idina ti afi gbodo waasu iroyin-rere
ni wipe: Akoko iroyin leyin ajinde Jesu je eyi ti o buru jayi (Matt. 28:11-25)
yatosi eyi ti o wa ninu (Mk. 16:15) o wa pase fun awon omo ehin re lati lo
waasu ihinrere. Ihinrere ni agbara Olorun ti o nsise ninu aye awon elese si
igbala, bikobase ihinrere Kristi, elese ko le ni igbala (Rom. 1: 16).
IGBALA
Igbala ro mo
awon nkan Pataki wonyi:
(1)
Ibi wundia re ati aye re
(2)
Ijiya re ati iku re
(3)
Isinku re
(4)
Ajinde re
(5)
Igoke re orun re.
IGBEKALE IWAASU IHINRERE
Bi a tin jade lo fun ijere-okan, a
nilo lati mo wipe, a o pade iru eniyan meta ti a ti se mo sinu esin orisirisi,
awon bii: -
·
Kristeni lasan- alafenuje
·
Musulumi ati
·
Awon aborisa.
Esu nlo arekereke esin lati di enu-ona okan awon eniyan. Jesu so fun
Peteru pe “Tele mi,” Emi yio so o di
apeja eniyan” ninu ese Bibeli yi, iru ona pipa meji lowa nibe bi ti awon ati ti iwo.
1. AWON: - Awon yoo ko eja ti o po jade lati inu odo, eyi ni a npe ni
ijere-okan ti olopo ero
2. IWO: - Iwo ko ni mu ohunkohun jade lati inu odo
afi eja eyokan soso, eyi la mo si ijere-okan elenikan senikan.
Bi o tile je wipe awon eja je ohun
elemi ti o wa laye, nwon ni oye die, nwon le da ounje, iku, ewu mo. Ko si
ologbon apeja ti yio so iwo ofifo sinu odo be. Pelu iwo yi, a ni ije ati olofofo
lara okun ti yio ma so fun apeja pe eja nbe lenu iwo nisale odo, (Bi o tile je
pe a ko le ri).
Bakannaa, ologbon ajere-okan gbodo
“bo” “cover” bo otito pelu ife olorun
tin se (IJE). Gbungbun igbekele iwaasu ihinrere yi, bi o tile je wipe a
ko le ko sile tan, yio ran o lowo gege bi ajere-okan tabi eniti o soni domo
ehin.
IROYIN-RERE
A ni iroyin-rere lati polongo, iroyin rere nipa ohun ti olorun se
fun omo’niyan ninu Kristi Jesu Lk2: 10-14, IKor. 15:3, Ajere-okan le gbe iwaasu
re kale lona yi.
IGBESE KINNI: Olorun ti o seda gbogbo agbaye ati ohun gbogbo ti o mbe ninu re
dara, o feran re o si fe ki o ni iriri iye lekunrere ati Alafia ninu aiye nihin
ati aiyeraye. Gen. 1:26, 27, Johannu 10:10; 14:27, 16:33, 3:16; Rm. 5:1.
IGBESE KEJI:
Niwon igbati olorun ti seto iye lekunrere
ati Alafia fun omo eniyan, kilo fa ti awon eniyan ko fi ni iriri yi.
IDI: Eniyan je elese ti o ti yapa kuro lodo olorun mimo, olorun dawa ni
aworan re lati ni iye lekunrere. Ko dawa ki a dabi (roboti) ti anti kiri, lat
feran re tabi gboran si lojiji, sugbon o fun wa ni iye-okan ati ominiran yiyan.
Eniyan yan lati saigboran si olorun, a si ninu ki ona ese ti wa. A sit un ma
nyan sibe loni, abayorisi re ni iyapa kuro lodo olorun.
ENIYAN NI AWON IYAPA WONYI
(1) WAHALA KINNI: Gbogbo wa lo ti se, Rm. 3:23; Isa.
53:6; Lk. 19: 10; Rm. 5:10; Efesu 2: 3
(2) WAHALA KEJI: Gbogbo eniyan lo wa labe idalebi
olorun, ti won si dojuko idajo re. Eze. 18:4; Heb. 9:27; Rm. 6:23; John 5:22;
Heb. 10:31; Ifihan 20:10-19; 21:8.
(3) WAHALA KETA: Gbogbo eniyan lo wa labe agbara ati
egun ese, esu ati awon angeli ti o subu pelu re. Isa. 48:22; 57:20; Matt.
15:19-20; Rom. 3:10-18; Gal. 5:19-21.
(4) WAHALA
KERIN: Nitori olorun je mimo,
eniyan je elese o si ti yapa kuro lodo Olorun. Ogbun nla ti o jin wa laarin
awon mejeeji, ni opolopo igba ni enikokan ti ngbiyanju lati di alafo yi sugbon
ko si aseyori, nitorinaa eniyan ko le gba ara re la.
Laalaa omo
eniyan niwonyi sakiyesi ohun ti olorun so nipa won: Owe 14:12; Isa. 59:2
a.
Ododo ara eni tabi ki a ma se
rere. Isa. 64:6; Jer. 17:9
b.
Sise eyi ti mo lese tabi
idalare ara eni, Jer. 17:9; 13:23. Rm. 3:10
d. Gbigbadura fun awon oku.
Lk. 16:26; 2 Kor. 6:2; Isa. 55:6-7
e. Pipa awon ofin mo. John
7:19; Matt. 5:27-28; 22:34-40; Gal. 3: 10-13; Gal. 2: 10
e. Gbigbe awon
eniyan mimo, angeli, tabi sise awon Baba nla loso dipo alagbawi laarin eniyan
ati Olorun bi, Rapheli, Michaeli, Maria mimo, Peteru mimo, Paulu mimo, Ogun-oya
tabi aworan ere. Acts 4:12; I Tim. 2:5.
f. Ifiya jera
eni tie sin tabi ifi’ya jera eni ti esu lori asan: Kol. 2:18-23.
gb. Jije omo
ijo, ounje Oluwa, jije oruko kristieni, gbogbo wonyi dara sugbon fun kristieni
tooto ti o ti ni igbala. Mk. 16:16; I Kor. 1:17; Acts 20:21
i. Ore, “Idamewa” tabi yiyan “Saka”, won dara sugbon won ko le gbani
la. O.D 49:6-8; I Kor. 3:11, 15; 2Kor. 5:10; 14:10-12.
h. Irin-ajo
mimo eyikeyi. Acts 4:12, tabi awon nkan miran ko le gbani la.
Niwon
igbati gbogbo laalaa eniyan lati di alafo yi tabi lati gbe afara sibi alafo na
ti di ofo, ti ko si yori sir ere, ki lo le muwa pada wa sodo, olorun eleda wa?
IGBESE KETA:
ONA ABAYO OLORUN – (KRISTI)
Olorun ti di alafo ti o pin awa
eniyan ati Olorun niya, nipa reran omo bibi re kan soso wa si aye, Jesu Kristi
lati ku lori igi agbelebu dipo wa, ki o si ji dide kuro ninu iboji lati san
gbese iya awon ese wa. Jesu Kristi nikan ni idahun si wahala ti eniyan ni ti o
mu iyapa wa. I Timoteu 2:5; Rm. 5:8; I Pet. 2: 24; Gal. 3:13; Rm. 6:23; Jhn.
14:6.
Nisisiyi ti olorun ti di alafo ti o
mu iyapa wa nipase iku ati ajinde Jesu Kristi, omo Re, bawo ni maa se wa se
ilaja pada si odo Olorun?
IGBESE KERIN: IDAHUN TIWA
Eniyan nilati dahun ipe Olorun fun igbala. Yiyan re je tire, o le
yan igbala na bayi:
(a)
Gba wipe o je elese, ti o nilo
igbala Olorun: Rm. 6:23; 5:12
(b)
Ronupiwada ese re. Mk. 1:15;
Acts 2:37-38; 17:30.
(d) Gbagbo pe Jesu Kristi ku fun o ni ori igi
agbelebu, o si jinde kuro ni iboji. Johanu 3:16.
(e) Nipase
adura, gba Jesu sinu okan re ati sinu aye re nipa pipe wole be enikan. Ifihan
30:20; John 1:12; Rm. 10:9-13
(e) Nigbawo
ni elese gbodo ronupiwada ki o sip e Kristi sinu aye re? Nisisiyi ni. 2Kor.
6:2; Owe 27:1; Isa. 55:6-7.
ADURA WO LO LE
GBA?
O le gbadura bi eyi, Rom. 10: 9-15.
JESU OLUWA MI
OWON;
Momo pee lese ni mi, mo nilo re ninu aye mi, mo nilo
idariji re, mo gbagbo pe o ku fun mi lori agbelebu nitori ese mi, mo si dupe pe
o gba ipo mi, mo si okan mi ati aye mi sile fun o, mo gba o ni oluwa ati
olugbala mi, gba gbogbo akoso aye mi, ki o si somi d’omo ninu idapo tie mi. Mo
dupe fun didariji mi ti o dariji mi ti o si fun mi ni iye ainipekun bi mo ti di
omo re bayi (Amin).
“AKIYESI FUN AJERE-OKAN:”
Leyin igbati a ba ti so oro ihinrere
ni ona ti o jagara, pelu eto fun eniyan ti o si gbagbo, gba adura igbala, ojuse
re ni lati fie se asese gbagbo mule ninu igbagbo. Eyi ni a npe ni itopase tabi
ito-pinpin.
AWON ONA TI A GBA NBANISORO
(i)
IBASORO TAARA: - Lati koju eniyan pelu oro ihinrere laisi iforowero kankan sugbon
ihinrere.
(ii)
IBASORO TI KI ISE TARA TABI IDOJUKO: - Sise adehun papo tabi bibeere pelu oro miran
ki a si pari re si oro ihinrere. Jn. 4:
(iii)
IFOROWANILENU WO: - Eyi ni bibeere ibeere titi e o fib a okan
eni naa pade lati so oro ihinrere fun. A le lo nibikibi tabi nigbakugba isele,
wa anfani ki o si loo.
(iv)
BIBEERE FUN OJU RERE: - O le bere fun agogo (time) tabi ki o ya ohun
kan, lehin ti o ba ti se eyi, bayi o ti pe okan re sodo re, o le pin oro
ihinrere pelu re.
(v)
SISE OJURERE: - Nigbati o ba se ohunkohun fun eniyan kan ti o
ba wa ba o lati dupe, nigbanaa pin ihinrere pelu re.
(vi)
FIFI IWE-ILEWO FUN NI (TRACTS): - Ni opolopo igba ni iwe yi ti mu okan awon
eniyan , lehin ti o ba ti ka, a o si waasu si eni naa lati inu iwe na (Tracts).
(vii)
LEHIN ISE-IRANSE-ORO IHINRERE: - Eyi maa
nsele ninu ijo lehin iwaasu ijosin, pinpin oro ihinrere pelu awon ti o faye won
fun Kristi, tabi awon ti o njosin pelu yin ni igba akoko.
OFIN ITAJA (OWE 11:30)
Nigbati a ti se
ayewo re finifini ni tie mi ati latoke wa nipa igbala, awon kan so wipe a ko le
ta ihinrere tabi awon kan ko si le fifun ni lofe.
EYI MU OTITO MEJI JADE:
1.
Awon nkan kan wa to ju isakoso
ija tita. Eyi ni agbara Emi-mimo.
2.
Nipa imoye eniyan, opolopo
kristiani lo nilo re. E je ki a wo bi Jesu se lo ofin marun ti itaja.
i.
Ifetibale
ii.
Ninifesi
iii.
Pipolongo
iv.
Mimudaniloju
v.
Pipari.
Ko tumo si
nkankan boya o nta nkan bi Aso, Isu, tabi ro awon eniyan lati gba eto tabi
ilana titun, tabi imo ijinle. Ona kanna fun riro ni oun na ni tita otito. Eyi
gan ni Jesu se fun obinrin ti o wa lenu kanga.
1.
IFETIBALE: - Jesu jere okan re kuro ni
ibiti o wa, obinrin na si teti sile fun Jesu. Oro akoko ti Jesu so ni wipe “Fun mi ni omi”. Bawo ni, to fi nbere
omi lowo mi, ko si ohun to pawa po, iwo Ju, emi ara Samaria,” nigbati Jesu ti
pe akiyesi obinrin yi ti o si ti setan lati fetilele, Jesu te siwaju lati ni
ninifesi re.
2.
NINIFESI: - Jesu je ki obinrin yi nifesi oro ti oun nso,
O wipe ti o ba mo eniti o ni ki o fun oun lomi mu, nisisiyi o ti wa setan,
“ninifesi” nitori o fe ni isun omi iye ki o ma baa tun maa wa si ibi kanga mo.
Lati ibe lo, ibanisoro na tesiwaju, lehin ti obinrin yi ti ni ife si oro na, o
fee, ki lo mu fife na wa? Jesu wipe eniti o bam u ninu omi yi, orugbe yoo tun
gbe, sugbon enikeni ti o bam u ninu omi tie mi yoo fi fun, orugbe ki yoo gbe
mo, omi tie mi yoo fi fun mu yi, yoo di kanga omi sinu re ti o nsun si iye
ainipekun.
3.
IPONGBE: - O fe, o si beere lowo Jesu wipe “Fun mi ni omi na” ki orugbe ma ba gbe
mi mo, ki emi ma si wa pon omi ninu kanga yi mo”. “Idaniloju titun”
4.
MIMU DANILOJU: - Omiran ni Idaniloju ese, Jesu wipe “Lo pe oko re wa” Jesu n fe ki o mo wipe elese ponbele ni oun, o so
oju abe niko, nipa ese re, nje Jesu nfe ki oko re o ni igbala bi? Rara, lati
fie se re han ni. Obinrin naa wipe “Emi
ko ni oko”. Iwo wi rere pee mi ko ni oko”., nitoriti iwo ti ni oko marun ri
eniti iwo si wa lodo re nisisiyi kii se oko re, iwo so otito li eyini”, Jesu mu
da loju nipa ese re.
YIYASI-IBOMIRAN:
Obinrin yi gbiyanju lati dari oro won si ibomiran,
o wipe “Awon baba wa josin, ni ori-oke yi, iwo si wipe, ni Jerusalemu ni o ye
ki awon eniyan ti maa josin”. O fe lati dari Jesu si ona miran sugbon Jesu mo
ibi ti oun nlo. Jesu wa lo oro kan ninu or ti o so fun didari re si ibomiran la
ti da pada si oro won, Jesu sib a so ohun ti o je erongba okan re lati mu ki o
se ipinnu ti o ye ki o se;
5.
IPARI: - “Emi eni ti o nba o soro, ni
emi na” Jesu ti mu wa si ibi ipinnu, boya yio gba tabi yoo ko, o ti mo eniti
Jesu nse.
IGBE-AYE—AJERE-OKAN
i.
Ajere-okan ti o segun gbodo ni
iriri isegun lori ese. Psalms 119:11
ii.
O ni lati ni ohun ti yoo pin
pelu awon eniyan. Jer. 20:9; I Pet. 3:15
iii.
O gbodo le soro pelu igboya.
AYE BIBELI NINU JIJERI
a.
Bibeli se Pataki ninu ijeri
b.
Oro na irugbin ni fun
afurugbin, ounje ni fun ojeun. Isa. 55:10
d. Ko si eniti o le ni
igbala laisi gbigbo ati gbigba oro naa. I Pet. 1:23
e. Kritiani ko le dagba laika
tabi laiko oro na. 2 Tim. 2:15.
e. Bibeli nikan lo fi ona
igbala han wa. 2 Tim. 3:15.
SISE AKOJOPO BI A SE WAASU IHINRERE
i.
Se mo soro lati je ki won
fetibale tabi ki won ni inu didun sii
ii.
Ti ko ba je bee, kini mo le se
lati se yi eyi pada?
iii.
Bawo ni mo se da ife Kristi
sinu won to, ati kin won si ni ipa ninu ijoba orun, bawo ni eyi se le po sii?
iv.
Nje emi na ri idaniloju ese re,
o nilo idariji, bi beeko, kilode?
v.
Nje mo mu de ani na loju kedere
wipe o ye ki o pinnu fun Kristi, ki o si fi aye re fun patapata nipa
rironupiwada ati igbagbo? Bi beeko, bawo ni mase bori ija ni igba miran.
IBUKUN-IJERE-OKAN
a.
Nipase ijere-okan ni igbe aye
mi wa yoo maa goke
b.
Nipase ijere-okan ni abela
(candle) olorun ninu wa yoo maa jo. Ifihan 3:15-17
d. Nigbati o ba jade
ijere-okan ni wa to ni iriri ileri olorun ati iwalaye re ninu aye re.
(Matt. 28:19-20)
Mo fe ki o ranti
wipe oro olorun pelu igboran yoo jasi isegun.
e. Nigbati o ba se ijere-okan
ni eni tie mi re yio dagba. Acts 5: 41-42
e. Ijere-okan ma mu o lo si
ipele ikerin idagbasoke ninu emi. Acts 4:8-10, 13
f. Ninu jijere-okan ni awon
ebun olorun yoo ma farahan. Rm. 12:4-7
g. Enikeni ti o ba lo se
ijere-okan aye otosi yi, oluwa yio gba eni naa ni akoko iponju. Ps. 41:1-2
gb. Enikeni ti o ba lo se
ijere-okan ni gbara olorun yio bo bi aso. Isa. 54:15-17; Jer. 1:6-10
h. Ijere-okan
je orisun ayo fun okan ti o yipada, o ko le ni ayo oluwa ti o ba ko lati pin
ihinrere pelu elomiran.
KIKOJU SI ERONGBA ATI IBEERE
i.
Mase jiyan. 2Tim 2:23-24; Owe
15:1
ii.
Mase wo eniti o ba soro, ti o
si bere ibeere bi ope, alaimokan.
AGBARA FUN IJERE-OKAN
Jesu oluwa wa pa awon omo-ehin re lase wipe “E duro ni Jerusalemu
titi e o fi kun fun agbara nigbati Emi-mimo ba ba le yin, eyin yoo si se eleri
mi…” Acts 1:8.
Awon omolehin ni itara, a ti ko won
ni otito, awon naa si ti gba iran ijere-okan gbogbo agbaye mu. Won ti ri oluwa
wa ti o nwaasu ihinrere ti o nse awon ise iyanu, won ri nigbati a nkan mo
agbelebu, o ku ati wipe o jinde, won si gba igoke re orun re gbo. Won gbinaje
pelu otito ati itara; Jesu mo wipe eyi yi ni koto, o mo wipe inunibini,
iselodi, atako ti o koro, ati ofa satani lati odo awon eniyan nduro de won, ati
eyi laisi agbara emi-mimo, ina itara ninu won ko nip e ti yoo fi ku.
Emi-mimo maa nko
ipa ti o se Pataki ninu ijere-okan.
AWON ISE EMI-MIMO NINU IJERE-OKAN
i.
O fi Kristi han bi olurapada
ati awon ipa ise irapada re lori awa eniyan
ii.
O mu ise irapada ti Kristi se
lori okan awa eniyan nipase iku re, isinku re ati ajinde re
iii.
O tun awa onigbagbo yipada.
Jn.3:5; 2Kor. 5:17; Jn. 1:11-13
iv.
O nto onigbagbo lati ni ibasepo
pelu Olorun
v.
O maa nfun onigbagbo ni imo
nipa jije omo Rm. 8:16 ati arole Rm. 8:17
vi.
O maa n to awon onigbagbo sinu
gbogbo otito. Jn. 16:13; IKor. 2:10
vii.
O maa ngbe inu onigbagbo. I
Kor. 3:16 lati nii
viii.
O maa ngbe inu onigbagbo lati
soodi mimo. Rm. 8:5
ix.
O maa ngbe inu onigbagbo lati
bebe fun. Rm. 8:26
x.
O maa ngbe inu onigbagbo fun
ise-isin. Acts 1:8.
No comments:
Post a Comment