MAJEMU

ITUMO
Majemu ni adehun ti o so egbe meji po
lori ajoso tabi asoro won, beni awon egbe meji yi ni a mo si eni nla ati eni
kekere. Ni iru ipo bayi, eni nla gbodo setan lati se iranlowo fun eni kekere ni
igbakugba to ba nilo iranwo re. Ni ede Heberu, ,majemu ni a npe ni BERITH.
BERITH yii tumosi Majemu ti Oluwa, sugbon ni ede Giriki a npe ni DIATEKE ti o
tumosi majemu.
AWON ONIRURU MAJEMU
1.
HEZED-
Eyini majemu ife
2.
TUBAH-
Eyini majemu wiwa ni irepo
3.
SALAM-
Majemu alafia tabi majemu ibukun
4.
YADAH-
Sise oloto gege bi majemu na ti ri
5.
KARAT-
BERITH- Dida majemu, nihin a ki se majemu, sugbon a ma nda majemu ni. Wiwo nu
majemu. (1Sam. 20:8) Eyi ni majemu to gaju nile Israeli. John 9:1-17; 18:19;
Joshua 10:1-8.
MAJEMU NINU BIBELI


Ninu majemu lailai, ipele orisi majemu
meji ni o wa:
1.
Majemu
larin eniyan ati eniyan, eya ati eya tabi larin orilede ati orilede.
2.
Majemu
larin Olorun ati okunrin tabi olorun ati awon eniyan.
Orisun nini oye dida majemu ti odo
olorun wa. Ero tabi aba yi yio si je tire lailai. Lockyer so eyi ni ona miran.
Ni asotan oro majemu se wa lati odo olorun fun ire eniyan lati gbe igbeaye to
dara ninu aye. Lati odo Re, Olorun kole daa majemu re kole kuna. “majemu mi li
emi ki yio da, beli emi ki yio yii ohun ti o ti ete mi jade pada (Ps. 89:34).
AWON OHUN META GBOGI TO NFARAHAN NINU MAJEMU
1. Awon egbe to pahun po tabi to fimo sokan.
2. Ileri to wa nibe
3. Awon ilana ti won fi lele.
O tun fihan pe o seese lati da majemu
laarin awon mejeji tabi eyi ti a gbekale lati owo alase agba. O je ohun to
daniloju wipe majemu to nbe laarin Olorun ati eniyan ko le je ogbogba sugbon o
je eyi ti a gbe kale lati orun wa. Gbogbo eredi majemu ti o wa ninu iwe majemu
lailai ni lati fi ododo mule ni irepo. Majemu lailai kun fun opolopo apeere,
majemu larin eniyan si eniyan, oba si oba, tabi orilede si orilede ninu
Genesisi. 21:21-32, o je iyalenu fun Abimeleki lati ripe ohun gbogbo ti
Abrahamu dawo le, ni o nse aseyori ninu re. O si woye wipe emi ohun kode ki
agbara Abrahamu ma baa je eru ati ipaya fun alaafia igbeaye re. O si pinnu lati
wonu majemu pelu Abrahamu osi sofun Abrahamu:
Nje nisisiyi fi olorun bura fun mi nihinyi pe iwo ki
yio se etan si mi, tabi si omo mi, tabi si omo-omo mi: sugbon gege bi iseun ti
mo se si o, beni iwo o si se si mi ati si ile ti iwo ti se atipo ninu re (vs
23).
Ki won to bura, bi otileje wipe Abrahamu
so fun Abimeleki nipa kanga omi kan, ti awon omo odo Abimeleki fi agbara gba.
Abimeleki wipe ohun ko gbo nigba eyi beni ohun ko mo eniti o se nkan yi beni
enikeni ko so fun mi, bikose loni yi. Abrahamu si mu aguntan ati ako-malu fun
abimeleki, awon mejeji si da majemu. Iwoye to jagara lati fi ebun da majemu nihin-yi
je ohun ti o ye fun akiyesi.
Abrahamu si ya abo odo-aguntan meje ninu
agbo si oto fun ara won. Abimeleki si bi Abrahamu pe, “Kili a le mo abo
odo-aguntan meje ti iwo ya si oto fun ara won yi si? O si wipe, nitori abo
odo-aguntan meje yi ni iwo o gba lowo mi, ki nwon ki o le se eri mi pe emi li o
wa kanga yi. Nitorina li o se pe ibe ma ni BEER-SEBA. (Gen. 21:28-31).
Agbara re lati wa ni alaafia, ni o jeyo
lara okan ninu awon oriki re. JEHOFA-SALOMU, isopo re pe pelu Salomu je ohun ti
o jagara. Sugbon ko gbodo ni ipa to le se idiwo to jinle fun ilana ti a fi
lele. Awon woli nse aroye lemolemo wipe awon omo oba lokunrin nte idajo loju
nipa gbigba riba tabi owo eyin. (Fun Apeere Isaiah. 1:23, Mika. 3:11) Ohun ti aunba
wa wi fun ni bi atise ma nfi oju yepere gba awon ebun lowo eniti o fi won fun
ni: a ma fi ebun fun ni lati wa oju rere eniti a fun lopolopo igba, ti o baje
wipe o gba ebun na. Jijoju ebun se pataki ninu majemu ti a nda ninu iwe majemu
lailai, bi o ti le je wipe ki se dandan. O le je ohun-ini bi aso tabi eniyan
sugbon Emi ti o so eyi se pataki. Ebun na le bere lati ori eyi ti o tobi julo
titi debi eyi to kere julo lati fi bu ola fun ni. Saulu, fun apere, fi Mikali
omobinrin re fun Dafidi gege bi aya lati fi imore re han, nitori isegun nla ti
Dafidi mu ba awon omo-ogun Isreali. 1Sam. 18:20-21.
MAJEMU OGBOGBA 

Iru majemu yii ni aripe ni majemu ti
odogba. Nitori o wa larin eniyan meji tabi egbe meji ti ohun kohun ko si le
yawon. Yala, iku ko le ya tabi baaje. Isele ti o sele laarin Dafidi ati
Jonatani fidire mule nigbati Jonatani ku, Dafidi ko gbagbe majemu ti o wa larin
won, bakanna majemu ti o wa larin Jakobu ati Labani je majemu oloogbogba. Bi o
tile je wipe Jakobu je omo aburo Labani ati oko omo re, bi o tile je wipe o ti
di okunrin, ti o si ti ni oro pupo.
O fi Labani sile lai duro gba ayeye
nitoti owo lile ati ailanu ti Labani fi mu, nigbati Labani ro pe Jakobu le yo
oun lenu ni ojo iwaju ati wipe o le lo awon omobinrin re mejeeji to di aya re
ni ilokulo, laifi owo to dara mu won tabi lai toju won bi o tiye. Nipa ogbon
ayinike, Labani yara lepa Jakobu nigbati o gbo wipe o ti fi ohun sile lo ni ona
ero. Nigbati Labani baa o soro, o si mu ki o ba ohun da majemu o wipe:
Nje nisisiyi, wa, je ki a ba ara wa da majemu, temi
tire, ki o si se eri larin temi tire, Jakobu si mu okuta kan, o si gbe ro se
owon, Jakobu si wi fun awon arakunrin re pe. E ma ko okuta jo, nwon si se
okiti, nwo si jeun nibe lori okiti naa. Labani si so oruko re ni Jegari
Sahaduta, sugbon Jakobu soo ni Galeedi. Labani si wipe, okiti yi li eri laarin
temi tire lonii. Nitorina li a se so oruko re ni Geleedi ati Mispa,
nitori ti o wipe ki Oluwa ki o ma so temi tire nigbati a o ya kuro lodo ara wa.
Bi iwo ba pon awon omobinrin mi li oju, tabi bi iwo ba fe aya miran pelu awon
omobinrin mi, ko si enikan pelu wa, wo o Olorun ni eleri temi tire. Labani si
wi fun Jakobu pe, wo okiti yi, si wo owon yi ti mo gbe ro larin temi tire (Gen.
31:44-52).
Jakobu je eje, o si rubo lori oke gbogbo
won si jo jeun lori oke naa won si sun. O si je ohun ti o rorun fun Labani lati
lo ni alafia ni owuro ojo keji.
MAJEMU
IGBEYAWO 

Igbeyawo ri bi majemu ninu iwe majemu
lailai. Ti o wa larin eniyan meji ti kii se ebi kanna. Niwon igba ti obinrin ba
ti se gbeyawo pelu okunrin kan o ti di ara kan pelu re. A si ma gbe po pelu re
lati jo ma gbe eru kanna. Obinrin ko binrin tabi okunrin ko kunrin ti o ba da
majemu igbeyawo ti o wa larin Dina omobinrin re, omo oba ati omo oba Shekemu,
niwon igba ti won bere fun ikonila gbogbo okunrin ilu Shekemu ti won si se bee
(Gen 34).
Malaki wipe Israeli mu wahala wa sori
ara won nipa dida majemu igbeyawo. “Eyi li eyin si tunse eyin fi omije, ati
ekun ati igbe bo pepe Oluwa mole, to be ti on ko fi ka ore yin si mo, tabi ki o
fi inu-didun gba nkan lowo yin. Sugbon eyin wipe nitori kini? Nitori oluwa ti
se eleri larin iwo ati larin aya ewe re, eniti iwo ti nhuwa etan si beli egbe
re li on sa ise ati aya majemu re (Malaki. 2:14-15). Bi o tile je wipe a fi aye
gba ikosile lori alebu ti o ba wa lara iyawo ni eyi ti otumo si, aisoto tabi
aisododo re. (Deut. 24:1-4).
MAJEMU
LAARIN TOKO-TAYA 

Iru majemu miran ni eyi ti o wa larin
toko-taya ti won ti gbera won ni iyawo ti won si feran ara won dokan. Won a maa
se iru majemu yii ni ikoko. Nipa yiya arawon pelu abe, ole je apa won mejeeji,
won a si fi obi yii eje ti o ba jade ni oju ogbe yii, won a si je. Iru majemu
yi won ko gbodo da ara won ninu ohun gbogbo ti won ba fi enu ko sii. Ti won si
fi enu ko si wipe awon mejeeji yio jo kuu ni ojo kanna yio ri be. Ore igba kan
ti wa ti iwo naa ti daa iru majemu yii.
IBURA
Bibura li ona miran tun je dida majemu
ninu majemu laialai. Ki o to ran iranse re Eleseri si Mirani lati lo fe iyawo
fun omo re Isaki, Abrahamu ni ki iranse wonu majemu nipa bibura pelu re.
Abrahamu so fun pe ki o fi owo si abe itan on ki o fi Oluwa bura, Olorun orun
ati aye wipe on ki yio fe iyawo fun Isaki lati nu awon obinrin Kenani larin
awon ti on ngbe.
Onkowe ntumo Bibeli ti a npe ni Wycliffe
salaye pe “Fifi si abe itan elomiran je ona ero sisalaye ti ibura na, bi ibura
na ba ye awon omo ati omodomo yio jiya aisoto na nipa ibura iranse na yio wa
ninu ide ti imunadoko lati ri fun be on pese iyawo ti o se itewogba fun Isaki. Nigbati
Jakobu ri wipe igbe aiye on summo opin, o so fun Josefu pe ki o se ibura fun on
nipa fifi owo si abe itan on, ki o si se ileri tabi (ibura) pe on yio fi anu
ati otito ba on lo, pe a ki yio sin on si ile Egypti, sugbon ki o sin on pelu
awon baba won ni ile palestine (Gen. 47:29-30).
O je ohun ti o lewu ti o ma buru pupo ki
a se ibura tabi ki a wonu majemu lo pelu enia tabi Olorun ki a da ileri tabi
majemu na. Yato si dida majemu tabi yato si biba majemu je (ti o je ese si
Olorun ki a da ileri tabi ohun irira si Olorun) awon eru ti a tun mu je eni ti
o di eniyan yepere ninu eyi ti o ti la isin isodiminira ni ona jeje koja,
nigbati a jeje koja, nigbati a ge eran ti a fi serubo si ona meji.
Ti eniti won jo se majemu si gba arin re
koja. (Gen.15:7-10; 11:18). Oro nipa agbara re nipa lati fi iyato si majemu ati
mulerupada awon ti Heberu pon loju. Eleyi mu Jeremiah binu, o si wipe Yahew yio
fun awon adari Juu ni idande kuro ninu
ise won ati idande lati kuu nipa ogun, ebi ati arun.
Ninu iwe Ezekieli 17:11-21, oro ti a npe
ni IBURA ati MAJEMU maa sise po wo nu ara won. Oba Babiloni ti apeere nje
(Nebukadinesari) wa si Jerusalemu, o si mu oba won ati omo oba okunrin lo si
Babiloni.
MAJEMU IYO
Iyo je ohun ti a nlo lati fi da majemu
ninu majemu lailai lati le mu ki o se eyi ti o se farada ati eyi ti o npe titi.
Iyo je ohun ti a nlo ni gbogbo igba lati fi dabobo onje wa, lati fi adun si
ounje wa, ati lati dabobo eran ki o ma ba dibaje. Lati je iyo (Ezra 1:4) je
ohun kanna lati je ounje eniyan ati nigbati alejo ba to onje wo ati iyo, o wa
ni abe abo eya. Iyo je gege bi ohun ti a nri lo lati fi se akosile ifowosopo
larin ilu meji o le je ami mimo toni toni, ti o dapo mo ibare ti o se pinya ti
a dasile nipa jije iyo oludari tabi adari. Ninu iwe numeri 18:19, Olorun se
majemu ayeraye pelu Aaroni ati awon iru omo re nipa fifun won ni ore Israeli
fun ise alufa wo. Eyi tumo si majemu iyo ko gbodo baje (Lev. 2:13, Num. 18:13,
11Kro. 13:15) kini ohun ti o je iyo ti a si fi pamo lai di baje, tabi lai da;
ohun ni a o si kasi ohun irubo mimo lati yasoto si Olorun nihin ni alaye na
dale lori nipa lilo iyo ninu aka ati ninu irubo, nigbati a ba fi aka naa si ori
agbegbe tabi ori pepele. Ni eyi ti a gbin pelu iyo o fi han wipe ile naa ni ti
ibere ati ya soto fun ohun ti orun. Osije, ohun ti o lewu lati gba ile naa ohun
ti a fi fun olorun (1king. 16:34, Josh. 6:26). Niti ise iyo a ma di wiwon sori
eran, lati je ko je si irubo si Yahweh (Ezek. 43:24; Mk. 9:40).
Nigbati ogun be sile larin Abijah ati
Jeroboamu, Abijah ran awon omo Israeli ati Jeroboamu lati wipe Olorun ti fi
isakoso ijoba na le Dafidi lowo gegebi majemu iyo. O so wipe Abijah si duro
lori oke Semariamu, ti o wa ni oke Efrimu, o si wipe, e gbo temi, Jeroboamu ati
gbogbo Israeli! Ko ha to ki eyin mo pe Oluwa Olorun Israeli ti fi joba lori
Israeli fun Dafidi laelae, ani fun un ati awon omo re nipa majemu iyo (11Kro.
13:4-5).
MAJEMU NI ILE YORUBA
ITOKASI: Dida majemu je
ipa pataki ninu igbe aye ikoko ati gbangba ni arin awon omo Yoruba. O si je ohun ti o jinle larin
ilana esin ati igbe aye won. Awon oro Yoruba ti o tumo si majemu ni wonyi,
Ileri, Imule, Adehun, ileri je oro ti a so ti a si pamo.
IBURA: Eniyan le bura nitori idi meji,
idi ti o dara tabi idi bubuu. Sugbon ti eyi bati waye, eni na ti fi ara re sinu
ojuse kan ti o si nilo lati pamo lai ro abajade re. Ibura ma nwa larin oko ati
iyawo ninu ile, larin awujo awon ole, ni arin awon elegbe ibile, larin awon
eniyan ti won taja tabi sise kanna ati larin Oba ati awon alaba sise po e. awon
to sunmo oba a ma bura ni odoodun nitori ki idaniloju le wa wipe won ki yio fun
oba ni majele je tabi gbagbode fun oba eyi ni akotun tabi atunda majemu won
pelu re. (N.A. Fadipe, 1970:205-207).
MAJEMU (Fifaramo Majemu): Eyi ni
fifaramo tabi majemu ninu imule majemu si ona isakoso. Majemu le sakoso ni
oniruru ona, bi lilo obi ati ataare, mimu eje ara won ni won igbati imule je
gege bi pipo ile-mu gegebi eleri si majemu.
Ni ilu Ibadan, iru majemu kan ma nwaye
nipa ilo igba meta, ikan ni iyepe ati omi ninu, omiran a si ma kun fun eja
gbigbe ti ati run si wewe beni eku gbigbe ti won ti run si wewe a ma wa ninu
omiran. Awon egbe to duro fun majemu na, asi koko mi eja gbigbe ni sise ntele,
won a si tun mu eku gbigbe bakanna. Ni ekeji won a si koko mi omi eyi ti o wa
ninu igba akoko (ti nse igba erupe ati omi), eni kokan a fa mu le meta, leyin
na won asi korin yii:
O
gb’orile o j’eku o,
O
gb’orile o je ja
O
gb’orile o da mi
Ase
d’owo ile t’ajo mu.
Orin yi pari pelu majemu obi ati atare
lama nda pomo awon eroja to nbe ninu igba akoko ti okun fun omi ati aye nipase
eyi, okokan ninu awon egbe to nbe ninu majemu yio mu die ninu eso (Alawe meta)
atare ati die ninu awe obi ti won pin.
Awon oloye meta yio pin obi naa
funrawon: won o tun pin ona otun ati okan eniyan naa fun arawon eyi ni titun
majemu won se pelu enikan kan. Ti enikeni ninu won ba gbo awon oro ti ko dara
ti a so si enikeni ninu won, won gbodo je ki eniti oro naa kan mo eyi. Awon
eran eniyan ti won ti fi se irubo ti o se ku ni won ma nsaba fun awon odo
kunrin lati je. Awon okunrin wonyi ko gbodo mu lara eran yii lo si ile debi ti
iwo osesi fifun iyawo won lati je. Ewu ti o wa ninu obinrin ti o ba je iru eran
ti a fi rubo fun orisa, iru obinrin bee ti o je iru eran bayi yio ma se nkan
osu re ni gbogbo igba (Eleyi ti mo mo pe o je okan lara awon ohun elo ati eroja
ti a fi nse eran fun iru eniyan be).
Eyi ni igbagbo awon eniyan ati obinrin
naa ko ni fe lati yee otito iru oro be wo. Awon Yoruba ma nmu esin won
lokunkundun, ati pe won ko feran ki eniyan dale ohunkan. Nitori ENITI O BA SE OHUN
TI ENIKAN KO SE RI, OJU RE YIO RI OHUN TI ENIKAN KO RI RI. Enikeni ninu awon
oloye meta ti o ba da majemu o di dandan ki o ku fun iwa eri okan.
Oloye olonade ohun lo gbodo salaye
siwaju si wipe awon aborisa ti fi si idi orisa bibo won ki fi gbogbo igba gba
idariji papa nigba ti aba fi idariji fun won. Won gbagbo daju pe enikeni ti o
ba da majemu di dandan ki oku . awon alaisododo eniyan won ki ri idariji gba
won a si ku sinu ese won: bo tile je pe elese a ma ri idariji gba ninu esin
Kristeni, eleyi ko da ibawi Olorun duro lori ese won.
MAJEMU LARIN ORE MEJI
Fifara mo oro siso larin ore ama duro
gegebi majemu, okunrin kan mu iyepe die fun ore re o si so fun pe nigba ti o ba
ku, omo re ko ni bikita lati ni ipin ninu sinsisn oku re, ti okunrin na ko ba
jiyan, ti o si gba ki omokunrin na ki o ni ipin ninu ayeye isinku re iru enibi
ti da majemu idajo re si ni iku. Ohun ti o sele ni Ijebu-Ode in odun 1976 eyi
ti a so nipase Oloye Thompson Olusada, okunrin kan fi pele kutu be aburo re ati
omo re wpe nigbati on ba ku a ko gbodo gbe oku on lo si ile igboku si, nigbati
o ku, aburo re ati awon omo re si gbe oku re lo si ile igboku pamo si. Nigbati
won padabo lati ile igboko pamosi won ku ninu ijamba oko.
ILE TITA
Ile tita tabi oko fifi renti tabi gbe
fun ni a maa fi aye sile fun majemu dida tabi majemu sise. Ti o ba je wipe afe
taa ile tabi oko ni aye atijo olutale ati eni ti o fe raa awon memeji ni yio jo
lo si ILEDI OSUGBO (igbimo awon agbagba ni ilu naa).
Oluwa yio gbe gege lori
re, obi ati ataare ninu ikoko kekere , awon egbe mejeeji ti oran naa se mo lori
yio gbe ikoko na lo, won a si boo mole si ibikan ninu oko naa, won won a si
gbin peregun ati igi ti alawo eweko daradara yi ibi ibi oju aala na ti won ri
ikoko na mo ka.
Ekan ti eleyi ba ti
sele, olutale yi ko ni ile yi mo ayafi ti o ba tun ra pada, bi ko ba sebe, ti o
ba tun yo lo sinu oko na ni bonkele, egun yio wa sori re, yio si foju wina
ifiyaje ti o wa labe oran naa. Bi oba si
fi ile na se ayalo, ti a si pe eleri lati jeri si oran naa, oko na ko ni di
gbigba pada leyin odun meta.
Bi enikeni ninu egbe na
ba da mejemu yi, iru eni na yio ku, bi ko ba si ku, yio wa labe egun ti yio so
are re sinu aisan titi di opin aye re. Majemu a maa wa laarin Onifa ati awon
isomogbe re, ohun ti Onifa ba ti so fun awon isomogbe re ni won gbodo se,
ibaaje okunrin tabi obinrin, lai se be, iru enibe ti ifa ba pase fun ti ko ba
se, o ti da majemu ti o wa larin oun ati ifa.
Oloye Olusada so nipa
obinrin kan ti ko ri omo bi ti o si lo si odo awon amoye lati ba ifa ni
gbolohun.
MAJEMU NIPA OUNJE KANNA TABI
ONJE TI O WOPO



Oloye Olusade so
wipe,awon idile kan tabi awujo kan le wo majemu nipase ounje. Irufe ounje bee
saba ma n je anomo ati eran. Won si maa n po eje mo iru ounje bee. Ati wipe won
o te eni sile fun gbogbo awon to fe wo majemu basepo lati joko le lori.
Ona ti won saba maa n
lo lati gba enikeni to ba fe wo majemu ibasepo nipe: ENI TI O BA TO AKO EFON
K’O WA IWO WARIWA (whosoever is as strong as a male buffalo, let him stretch
his horns).
Iru majemu bayi wa fun
awon okunrin nikan, enikeni to ba si joko sori eni yi, to si tun jeun nibe ko
gbodo dale. Enikeni to kopa ninu majemu bee ko gbodo dale, ti o ba si dale, bi
won ba gegun iru eni be yo se mo lara.
MAJEMU LARIN AWON AGBA


Awon agba saba maa ndi
ara won sinu majemu nipa pinpin awe obi tabi odidi obi je. Nile yoruba obi je
ohun mimo. A ma n lo obi lati wadi awon isele nipa ojo ola. Obi duro fun ohun
to le tete adura gba. Idi niyi ti yoruba fi wipe: ORISA KI I KO EBE FUN OBI.
Bi awon agba ba pin awe
obi laarin ara won, irufe igbese be ti di majemu, bi won ba si fe ko tubo fese
mule sii, eni kookan won le fi eyo ata re meta kun. Eyi lo fa, ti nkan o ba lo dede ti won fi
nwipe: GBOGBO AGBA TI E JO JE AWEBI, E PE ARA YIN JO.
Atare ma nje ki majemu
waa sori aromodomo tori pe atare duro fun isodipupo ninu asa yoruba , lati le
fi majemu naa mule sii. Be si ni orogbo duro fun ‘ikoro’. Igbagbo won si nipe
eni to ba dale majemu yii, yio pari aye re ninu ikoro. Orogbo ni won saba maa n
lo gbeyin.
MAJEMU NIPA IRIN ISE OJO O

Ohun elo ise pelu wa
ninu awon nnkan ti a fi nda majemu
laarin awon olokowo tabi onise owo iru kanna. Won ko gbodo dale ara won. Awon
agbe maa nlo ada; awon ode maa nlo ibon; awon ahunso ma nlo ohun elo ihunso ati
awon poa ihunso. Won le gbadura si irinse won pelu obi, won yio si pin obi naa je.
Bi agbe ba dale agba, ole se ara re lese. Bi olode ba dale ibura re, ole si
ibon ta. ,bi ahunso ba dale ahunso miran, okowo re yio run
MAJEMU LAARIN AWON OBA ATI AWON IJOYE 

Ohun ti o sele laarin
oba ati ijoye ni okitipupa fihan iru majemu ti o wa laarin oba ati ijoye. Awon
Ijamu ni gbogbo ilu Ikale pelu oba ati awon oloye agba, ni ase afiwe re pelu
oba ati iwarefa, (ni eyi ti o tumosi Oba ati awon ijoye mefa). Ni awon ilu
pataki ni ile yoruba. Mo ni ore ofe lati ri oba ilu okiti pupa ati awon ijoye
merin ni ilu okiti pupa ti won a so fun mi nipa awon Ara Ijamu. Ada egbe Ijamu
sile nipase okunrin kan ti a npe oruko re ni Gbeji ti Ajueli ti o je adari agba
ni agbegbe ibe. Awom eniyan re feran re nitori igbeaye ife ati ikonimora ti
ongbe ni aarin won. A si maa ba awon ijoye soro wipe ki won ma feran ara won.
Eka egbe yii gbile lopolopo ni ilu okiti pupa. Ti okan lara awon omo egbe yii
ba si kuro ni ileto kan ni okiti pupa losi ibomiran laarin ilu naa jeje ni yoo
darapo mo awon egbe miran ti o le wa ni ileto ibi ti o sese ko de lai si wahala
kan tabi isoro kan ti o le di lowo.
Ona ti eniyan ngba joye
ni ilu Ikale pin si ipele meta. Ipele akoko ni a npe ni Ipeere (Youth). Awon odomodekunrin ni o ma je oye ni
ipele yi ti apele re nje, Arogun Olowodasa,a ti Lomofe, Ipele keji, ni an npe
ni Remo, apele oye ti won je ni atunpe ni sugbon, eleyi je ti awon odomokunrin
ti o wa larin meji ti won si ti ni iriri nipa oye jije. Ipele keta, ipele iketa
ni a npe ni Ijamu. Ni eyi ti o je igbimo awon agbagba.
Awon
oye ti wo maa je ninu Ijamu yii ni OBA, LISA, PETU, ODOWU, SASERE, LEMODORO
ATIKOGUN Ijamu yii ni awon alase ati adari ni ilu Ikale kookan ojo ori nilo ki
o to di wipe a gbe enikeni sinu oye yii tabi fi eniyan woo inu egbe naa. Omo
gbe gbodo je eni ti o ti koja adota odun ko to di wipe agba sinu egbe naa.
Nitori
wipe awon oloye Ijamu je awon aboba jiroro tabi agboba ni imoran.
Gbogbo
ohun aigbodo mase ni won gbudo se ni ojubo ti won ti ya soto fun Ajuelu ti nse
oludasile egbe naa, ni odun meta mata won a ma gba omo egbe tuntun. Ni ojo
igbani wole yii won a ma pese obe eja ti o yato ti o sini ata, iyo ati olorin
sugbon ki yio si epo tabi ororo ninnu re. Iyan a wa ni igba kan loto beni obe
naa yoi wa inu isasun.
Ni
ojo igbaniwo yii, omi ti won ma nmu ni won ma nlo bu ninu odod meje ti nbe ni
agbegbe naa. Won ki so oro igbani wole fun awon ti won ko gba wole, sugbon
lehin ti won ba tibura funawon omo egbe tuntun, enkoo-kan yio bu akasu iyan won
a si fi ruu obe ti o wa ni isasun. Won ki gbe ohunkohun to ba seku ninu obe ati
iyan yii fun enikeni, won a si danu, lehin naa won a si pin awon ounje miran ti
won se funara won.
Won
a si fi ounje to baku fun awon omode to tele baba won wa. Gbogbo awon omo egbe
ni won yio mu omi inu ife kannaa botile je wipe onikaluku ni o nle ife tire
lode oni. Awon omo egbe a ma joko gege bi ipo won, beni won a si je beni mu
gege bi ipo won. Nigbati oba ba wole gbogbo omo egbe ni lati dide lati fi ije
oto ati owo fun ati igboran won han si oga nigbati omo egbe miran ba wole awon
to kere si ni ipo nilati dide duro fun beni won asi joko bi o bati njoko.
Nigbati omo egbe kan ba fe wole sinu ile ipade, ko gbodo sare wole tabi se
waduwadu ti o ba fe wole. Ogbodo koko wuko lehin lekun.
Bi
awon ino egbe to wa ninu ile ba fe gba wole, won ma wipe “Kade”. Awon omo egbe
ti nbe ni agbegbe kookan ma npade ni ojo mesan-mesan fun ayewo ara won. Won maa
n fe ki gbogbo omo egbe jewo ohun ti won ba se laarin awon ojo die lehin ipade
fun ara won.
Omo egbe lati je oloto ati olododo ati eni to se
fokantan si are wo, ti omo egbe kan ba wa omo egbe re, lo sile ti o je wipe
akoko naa ni omo egbe yii ba iyawo re sepo, o di dandan fun lati fi iyawo re
sile lati loda omo egbe re lohun. Ifenukowon ni wipe EDI MEJI KII DI ARA WON,
omo egbe meji ko gbodo dara won.
MAJEMU
DIDA NINU EGBE OGBONI 







Oloye
Jonathan Olonode Lasore, Baba ijo eleto (Methodist church), ni itesi, abeokuta
ni Oloru agbode-gbe mi. Abi si idile Kristeni nipase eyi ko ri aye lati dara po
mo awon eniyan ti ki nse Kristieni. Baba re agba ni o je Oluwa Itesi eyli ti se
egbe Ogboni tile Itesi nitori eyi gbogbo awonomo re nilati wo inu egbe Ogboni,
beni a si mu Oloye Jonothan Olonode Lasore wonu egbe ogboni.
Bi
o tile je wipe opolopo ona ni won ma ngba wonu
majemu ile-Yoruba ninu egbe okunkun, ninu oro tire, ide ni opolopo won
ja si o je omo egbe opolopo egbe okunkun, sugbon egbe United Brothers of
Friendship, eyi to je okan ninu awon oludasile re ni ilu Abeokuta, dabi enipe
ohun ti o dara ju ninu gbogbo egbe okunkun to wa nitoripe nibe ni ife ti o
gboro julo fi farahan. Beni kosi le tu asiri egbe yi fun enikeni ti ki ise omo
egbe na. Ninu gbogbo majemu dida tinbe ni agbaye, majemu eje ni o je eyi to
lagbara julo, nitoripe emi je yo ninu re, beni eje siini emi (Leviticus 17:11).
Opolopo
eniyan ni o ti wo nu majemu funrara won tabi lai mo ni igba kan rii. Opolopo
wonu majemu nipa afera tabi akofera won asi wo inu majemu yii nipa dida eje won
po. Won a si jo mu won a ma se eleyi nipa fifi abere tabi fi abe mimu ge ara
won lati mu eje jade. Opolopo a po eje yii mo oti tabi ohun miran won a si pin
tabi ki won se ni ona mira.
Nigbati
Jesu farahan niwaju Pilatu, Pilatu ko lati kan mo agbelebu, bio tile je wipe ko
ri ese kan kan lowo re sugbon awon eniyan ni “Kan mo o agblebu” ki eje re ki o si
wa sori awon ati awon omo won be lo ri fun awon ara Juu titi di oni oloni.
Omobinrin kan wa ti o lo fun itusile (deliverance) ni odun 1993. O ti se idanwo
oniwe mewa (W.A.E.C) lemeta yi iwe re ko de odo awon alamojuto igbomo WAEC. Ni
igba meteta. A ma poora laimo. Odobinrin yi je omo Olorun, o ti di atunbi, okun
fun Emi Mimo sugbon oluso aguntan re kole so ohun kohun nipa re tabi ohun ti on
sele. Awon olubewo fi iwe re jise si ile igbimo WAEC sugbon won ko rii iwe
tire.
Ati
pelu, lara igbogun ti ti o dide si ni baba re ti odede yipada sii nitoripe ko
balo si odo babalawo tabi yemiwo, ki won lo wo ohun ti o sele si. Iranse Olorun
onitusile gbadura fun ohun kankan ko sele beni iyapada kan ko si fun. Nigba ti
o ya, emi iku bere si palara nigba miran a gbe bo si enu oko.
Awon emi esu yi fe lati pa aye re run patapata
ni. Nigbati o ya won Juu sinu awe olojometa pelu adura sugbon pabo ni gbogbo re
jasi. Ni ojo kan odomobirin yi jewo wipe ohun ti da majemu eje pelu ore kunrin
re ni igba ti ko ti gbagbo ati wipe nigba ti ohun ti gbagbo ti ohun si ti di
atunbi gbogbo re ti pari sibe niye ati
wipe o ti di a fi seyin ti egungun nfi aso. Sugbon ni ojo ti o ba ore kunrin re
yi pade o so fun pe se lo kan fi akoko re sofo.
Ti
ko ba pada wa sodo oun ohun gbogbo ti awon ti jo so ki o to di pe awon mu eje
yi ni yio ma wa sori re. Awon oro ti o so yi ni o fun iranse Olorun ni oye lori
ohun ti o fa isoro re. Ni gbayi iranse Olorun gbadura o si ba gbogbo majemu ti
o ti sopo pelu eje yi je oruko Jesu. Iransebirin naa si gba itusile kuro ninu
majemu eje.
No comments:
Post a Comment