IBANISORO
TI O MUNAD’OKO
NINU
EKO ILE OKO OJO ISINMI
AFIHAN:
Ibanisoro
ti o munad’oko ninu ikonu ni ile eko ojo isinmi, se pataki nitori ojusse patako
ti ile-eko ojo isinmi nko ninu isin. O kan
lara awon ona ti Olorun ngba nfi awon eko Bibeli sowo si okan awon
eniyan Re. Titi di igba ti iwaasu tabi eko yio fi di eyi ti a so daradara si
okan awon olugbo, erongba tabi ipinnu ti o wa ninu okan Olorun, ti o fi nfi
iwaasu tabi eko s’owo yio fi ori s’opon.
Olukoni ti
o dara, ti o ni oye eko re dajudaju, ti o si nmura sile gidigidi lati fi ekko
ranse si awon akeko, irufe olukoni bee yio pada di ariwo lasan, nibi ti won ti
nreti iwaasu tabi ikoni ti o dara lati
owo re. (2Sam.18;19-32)

IBANISORO
TI O MUNAD’OKO
KINNI A NPE NI IBANISORO TI O
MUNADOKO?
Ibanisoro
ti o munadoko je ise ti angba fi irayin s’owo si awon elomiran ni onati o
munadoko tabi ni ona ti o danmoran, ti ero okan dieyi ti a s’alaye re lati
ipase oro Olubanisoro. (Ise Aposteli.6:9-10).
Ibanisoro
ti o munadoko je ona ti ngba fi iwaasu, irayin, erongba, tabi imolara s’owo si
elomiran ni ona ti oye ti o gun rege ngba nfidi mule ninu okan awon olugbo.
Amosa, titi di igbati oye ti o dara, ti o sunmo erongba, tabi ero ti o wa ninu
okan Oluso yio di eyi ti a rusoke ninu olugbo, ibanisoro ko i tii waye.

ORISI
ONA IBANISORO
Orisi awon ona ibanisoro meji ni o wa:
a. Ibanisoro nipa or Enu
b. Ibanisoro ti kii se nipa oro Enu.
A.
IBANISORO NIPA ORO ENU
Ibanisoro nipa oro enu ni i se pelu lilo oro enu lati fi
iwaasu tabi ikoni tabi iroyin sowo si elomiran ni ona ti o munadoko.
B.
IBANISORO TI KII SE NIPA ORO ENU
Ibanisoro ti kii se nipa oro enu nii se
pelu fifi iwaasu s`owo tabi fifi iroyin s`owo nipa awon amin, tabi awon ise.
Fun apeere, nigba ti oko ba tan ina lati ya si ibikan, amin ajuwe ninu patako
ajuwe, aso ara ogiri, iwe ale mo ogiri, iwe ilewo, patako ajuwe nla tabi
nigbati eniyan kan ba sun labe iwaasu, irufe eniyan yi nso wipe, oniwaasu naa
ko bani soro rara.
ARIWO NINU IBANISORO
Kinni a npe ni ariwo?
Ariwo je ohunkohun ti o ba ntako ibanisoro tabi se idiwo si liloye awon olugbo.
Orisi awon ariwo meji ni o wa ninu ibanisoro:
(a)
Ariwo elero
(Mechanical noise)
(b)
Ariwo asilo oro (Semantic noise)
(A)
ARIWO ELERO:
Ariwo elero nii se pelu ohunkohun ti o ba wa, boya lati ipase ohun elo ti o ba
nrin, tabi ero ti o nsise, tabi oko ti o nkoja, tabi awon eniyan ti o nsoro
legbe re, ekun omode, awon ero ti o nmu okan yapa, ikigbe ti ko ye ni akoko
iwaasu ati bee bee lo.
(B)
ARIWO
ASILO ORO: Ariwo asilo oro nii se pelu ailoye nipa awon oro ti ko tona tabi
oro ti ko ye eniyan ti a lo ninu ikoni tabi ninu iwaasu. Awon eniyan maa nlo
awon oro ti kii tete ye eniyan lati awon oro ti ko ba ohun ti a nso mu lati fi
mu inu awon olugbo dun, sugbon otito ni wipe, won le pada da oro naa ru mo awon
olugbo won loju.

AWON ENIYAN MEJI TI WON SE PATAKI NINU
IBANISORO
Orisi awon eniyan meji ni
won se pataki julo ninu ibanisoro. Awon naa ni wonyi:
(1) ENI TI O NSORO (SPEAKER)
(2) ENI TI O NGBORO (RECEIVER)
ENI TI O NSORO 
Oluso ni oniwaasu tabi
olukoni tabi soro-soro ti o ni erongba, ero okan, imolara, iwaasu tabi ikoni ti
o fi ns`owo si elomiran. Olusoro maa ndojuko awon isoro mimo ede ti olugbo loye
re. Ede ni o je awon ona gbogboogbo ti a fi nbanisoro. Nitori naa, o je ojuse
olusoro lati mo awon olugbo re, ki o to bere ilana ibanisoro.
AWON OLUGBO 
Olugbo ni awon eniyan tabi
awon akeko ti won ngbo iwaasu tabi eko olusoro. Olugbo ni o gba oro tabi eko
naa nigbati o ba ti loye koko iwaasu tabi ikoni naa.
O je ohun ti o dun mo wa
lati mo pe, ibanisoro nlo nigbagbogbo laarin wakati merin-le l`ogun ti o wa
ninu ojo kan. Nitooto, a gbe aye yi kale lori ibanisoro (Gen. 1:3-5) oku nikan
ni kii ni ibanisoro, ibanisoro maa nlo ni ibi gbogbo.

JIJA OKUN IBANISORO
Iye ti o wa ninu oro
Olorun yio di alailera ati alainiye ninu, nigbati agbara lati ba ni soro
isipaya Olorun sinu okan awon eniyan ba sonu tabi ti o ja. YEWO: (LK.24:1-11).
Ibanisoro ti o munadoko ni okun iye
laarin oro Olorun ati awon olugbo. Eredi ikoni yio di alaiwulo ti oore-ofe
paapa yio s`ofo nigba ti a ko ba so oro naa ni ona ti o munadoko sinu okan awon
olugbo.
Nitorinaa, okun ibanisoro
maa nja:
(1). Nigbati ipa lati ni ibanisoro ti o ni itumo
ba sonu, tabi alailera tabi ti o baje.
(2). Nigbati awon eniyan ba pariwo le ara won, ti
won si ko lati gbo ara won ye.
(Jak.
1:9-21)
(3). Nigbati erongba iwaasu tabi ikoni ba di eyi
ti won ti tumo re si ohun miran.
(4). Nigbati
awon eniyan ba puro mo ara won, ti won si nso ohun buburu nipa ara won. (Jak.
4:11-12)
(5). Nigbati o ba soro ni ona ti o koja oye awon
eniyan. (1Kor. 3:1-2)
(6). Nigbati owo ba ropo otito laarin awon
eniyan. (Matt. 28:11-15)

AWON IGBESE SI
IBANISORO TI O MUNADOKO
Ibanisoro
ti o munadoko se pataki ninu fifi iwaasu tabi ikoni ile Eko Bibeli ojo Isinmi
s`owo si awon olugbo. Bi o ti wu ki ojo ori re ri, tabi ipile re, tabi iriri
re, ibanisoro ti o munadoko je imo ti o gbodo ni, ki o le ni ipa akoran rere
lori awon eniyan Olorun. Abajade esi die ni a nri nigbati a ko ba so oro Olorun
ni ona ti o munadoko.
AWON
IGBESE SI IBANISORO TI O MUNADOKO
1)
Seto agbegbe ti o dara fun ibanisoro: akoko ti o dara ati ibi ti o dara wa fun ohun gbogbo.
Siseto agbegbe ti o rewa ni akoko ti o tona yio nran o lowo lati le ba awon ti
o ngbo e soro ni ona ti o munadoko.
Bi o ba nilo lati fi ohun kan ti o se
pataki to eniyan kan leti, ti e si nfe ki o gba daradara, lowo mase baa so ni
ita gbangba.
2)
Mu gbogbo idiwo kuro: O se pataki lati mu ohun kohun ti o le fa ki okan
awon eniyan si kuro ninu eko lodo awon olugbo re. Pa gbogbo awon ero ti o le
pariwo ni akoko ibanisoro. Mase gba . aaye fun gbogbo ohun idiwo lati ode laaye
lati je igi woroko ti yio yi ibanisoro re danu. Won yio je idiwo fun o ati awon
olugbo oro re, ti won yio si farabale pa inu ibanisoro naa. (Acts.21:37-40;
22:1-2).
3)
Je ki ibanisoro re wa leeto
a)
Wa leeto ki o si mu ki awon erongba okan re dan moran: O gbodo ti se eleyi, ki o to gbiyanju lati so erongba
okan re. Bi akori kan ba mu o lomi, o le pada di eniti yio maa sa kiri, ti o ko
ba ti pese awon koko oro ti waa tenu mo nigba ti o ba nsoro.
b)
Je ki oro re dan moran: So ohun ti o nfe fi s’owo si awon eniyan di mimo
lati ibere. Je ki awon eniyan ni oye ohun ti o nfe ki won ni, ki o le dari won
laisi idiwo kankan.
c)
Duro lori akori: Ni kete ti o ba ti bere si soro lori koko akori, ri daju pe gbogbo
ohun ti o nso ni o nse afikun awon oro re. Mase beru lati lo awon gbolohun oro
ti o ba wa si okan re, lati fi gbe oro re leyin.
d)
Dupe lowo awon
olugbo re: Leyin gbogbo ikoni, dipe lowo awon eniyan fun akoko ti won fi sile
lati gbo ati isirasi won.
4)
Banisoro Pelu Awon Oro Oore-Ofe
a)
Fi Okan Awon Olugbo Re Bale: Je ki awon olugbo re ri awon oro oore-ofe ti o njade
lati enu re. Eleyi yio fi han won pe, Oluwa ti sise lori aye re gidigidi ati
pe, oro re yio je ibukun fun won (Kol.4:6).
b)
O se pataki
fun o lati soroja gaara, ki iwaasu tabi ikoni res le wa ni oma ti awon olugbo
re yio gba loye. Won a maa rantsi oro
re nitori pe awon eniyan yio ranti ohun ti o nso loju ese. O tumosi pe siso oro
re ni ona ti o ja gaara, paapa lilo awon oro ti o rorun yio ran awon olugbo re
lowo lati di eko naa mu. (Acts.26:-1-32).
c)
Yera Fun........:
Lo ibojuto pataki lati se alaye awon koko oro ti o ye ki o so, lati le yera fun
aigbara-eni-ye.
d)
Farabale daradara nigbati o ba nfeti sile, ki o si ri
daju pe, awo oju re se afihan ife re si oro naa: Farabale te’ti sile pelu ise. Ibanisoro je oju opo
ona meji. Ranti wipe, nigbati o n soro, iwo gaan ko keko. Sugbon ninu tite eti
sile, o le se odinwon bi oro iwaasu tabi eko re se raaye ninu awon olugbo re,
boya won tewo gba eko naa tabi bee ko.
e)
Fi Ife Han Ni Oro Re: Mase so agbara iye ti o wa ninu isipaya oro Olorun ti
o npin pelu awon eniyan nu, sugbon sisoro fitinfitin ko le din leti. Gbe ohun
re soke pelu oro irele nigbati o ba ntenumo awon oro pataki tabi nigbati o ba
nse akojopo eko re.
IBANISORO NIPA EDE-ARA (BODY LANGUAGE) 

1.
DA AWON ENIYAN MO: O daju wipe, o le ma mo awon eniyan ti o wa ninu iyara ikeko re tabi eni titun ti o wa
labe eko re, sugbon won nfi ori dahun si oro re, ti won si nwo e bi eni ti won
mo bakanna. Eleyi tumosi pe, won ti so po mo e. Nitorinaa, fi didawon mo san ere
pada fun won.
2.
FIFIDI ITUMO ORO RE MULE LE WAYE NIPA LILO EDE-ARA RE
BAKANNA: Moo mo lo awo oju re lati se
alaye oro re. Pinnu lati se afihan ikaanu, ki o si mu iye to awon olugbo re lo,
nipa lilo jeje, oro pele pelu oro oore-ofe lati fi mu oro Olorun de inu okan
won. Yera fun awo oju ti ko dara, bi fifa-oju-ro tabi kika oju soke.
Mirasile de awon ihuwasi ti o ke reti, sugbon ti yio
fi han o, pe o ti nfi ori gba’ri pelu rire asa koja. Bi o ko ba mo asa awon
olugbo re, beere ibeere lori awon ipenijaa ibanisoro, ki o to bere sii ba awon
eniyan soro lati inu ohun ti o wa ninu asa won (Acts.21:15-40; 22:1-3).
3.
BANISORO PELU OJO-SI-OJU: Ki oju pade oju maa nfidi ibasepo mule, o maa
nranilowo lati fi da awon eniyan loju wipe, eniti o see gbeke le ni o, ti o si
fii si ise. Ranti lati ko gbegbo awon olugbo re mora. Bi o ba nko iyara ikeko
kan, wo gbogbo omo kilasi re ni oju. Mase yo enikeni sile ninu won, nitori
eleyi le pada di ami esse, ti o si le mu o padanu iwaasu re. Bi o ba nkoni duro
die, ki o si wo enikookan won laarin iseju aaya meji ki o to tun tesiwaju.
Eleyi yio mu ki enikookan won ni imolara iniye lori. (Acts.14:8-12).
4.
LO MIMI KANLE ATI IDANU-DURO DIE FUN ANFANI ARA RE: Agbara wa ninu didake die. Didake die ninu ikoni maa
nmu awon olugbo lati gbe eko mi, ki won si fi eti sile. Yio ran o lowo lati
teni mo koko oro re ati lati fi aaye sile fin awon olugbo lati je ohun ti won
gbo kunna.
5.
SE IKAPA AWON ITONI EDE-ARA MIRAN: Sora fun oju ti o nrin kiri ninu eko, tabi owo ti o
nfa owu lara aso re ati wiwo yan-yan-yan nigbagbogbo. Awon is kekere wonyi maa
nto ara won jo, won si le pagi-dina imunadokko iwaasu re.

AWON OHUN TI A
GBODO YERA FUN NINU IBANISORO
Opolopo
awon nkan ni a gbodo fi ogbon Olorun yera fun ninu ibanisoro, ti won le di
agbara oro lowo lati le wole si okan awon olugbo ni ona ti o munadoko. Awon nka
naa ni wonyi:
1.
ARIWO TI KO WULO: Opolopo awon olukoni tabi awon oniwaasu lode oni, ni won roope,
agbara iwaasu tabi ikoni wa ninu ariwe
pipa. Ariwo pipa kii mu ifami ororo-yanwa, bee ni kii fi agbara tabi ipa kun
iwaasu. Kaka bee, yio ba ipa rere oro naa je.
2.
RINRIN KIRI TI KO WULO: A ko le dekun lati ma rin rara nigbati a ba nisoro.
Sugbon, ti irinkiri ba ti poju, yio pada di ariwo.
3.
PIPARI AAWO/IJA: Mase wa siwaju pepe pelu ikoni tabi iwaasu ti a moo mo pese lona
pataki lati fi kolu enikeni ninu ijo tabi ninu iyara ile eko ojo isinmi. Eleyi
kii se ibanisoro ti o dara. Bi o ba ni wahala pelu enikeni, ori pepe tabi iyara
ikeko kii ise ibi ti o ti yanju re.
4.
SISE ATUNSO ORO: Olubanisoro rere gbodo yera fun sise atunse oro, eleyi maa niyorisi
idarudapo ati gbigbe ni okan. Awon oro bi “E yin Oluwa”, “Halelluyah” tabi
“Amin”, ni a le fi ogbon lo, sogbon kii se bi ohun ti a fi alafo nitori airi
oro so.
5.
YIYA KURO NI OJU OPO TI KO WULO TABI TI KO WA NI
IBAMU: Nigba miran, oluko oro Olorun
le ni idi ti o fi ye ki o ya kuro loju opo die ninu ikoni, sugbon nigba miran,
bi a kko ba sora, yiya yi le mu idiwo wa. (Eni ti o ye ki o soro lori “IFE”
sugbon nitoripe “IGBAGBO” je eyi ti o faran ju ife lo, wa pada bere si so nipa
igbagbo. Iru eni bee kii se oluko oro Olorun ti o dara).
6.
SISE AFIHAN OYE TI KO WULO: A ti sse awari re ni opo odun seyin pe, awon feran
lati maa so nipa awon aseyori ana. Won a maa toka si awon iwaasu tabi ikoni ni
wonana, ti won ti ko nibikan tabi ni igba kan ti ko si ni ibamu pelu eyi ti o
nko lowo. Eleyi ko dara rara!
7.
AINI-IKORA-ENI-NI-IJANU
NIPA LILO AKOKO: Akoko je ara ibanisoro. Ri daju wipe o se ni iwontun-wonsi,
nitori pe o seese ki eniyan padanu ife ti oni si eko naa, bi eniyan ko ba pa
akoko mo.
8.
WAHALA ALADANI:
Bi o ba nso oro Olorun (paapa julo, ile eko ojo isinmi) jowo, yera fun siso
nipa awon wahala ti ara re tabi awon nrunu ti o ni si enikeni ninu ijo. Jowo,
te oju mo akori ti won fun e, soro nipa isoro awon eniyan.

NIGBATI ORO BA PADA DI ISIPAYA
Ko
si ohun ti oluko ile-eko ojo isinmi ti o dara, tabi iransse oro naa le so ni
ona ti munadoko ti o si le mu iyipada nla ba aye awon-eniyan, yato si oro
Olorun. Oro Olorun ni onigbowo iyipada. Bi oro Olorun ko ba tona, aye awon
eniyan naa ko ni tona. Oro Olorun kii wa lati se ojurere si enikeni, ati awon
oba paapa. Yewo: 2Kings.3:6-19, 1Kings.22:6-28
Nigbati
omi oro Olorun ba gba atunse, nigbanaa ni ko ni si iyagan mo. Awon iyangan ti
emi po nisisinyin ninu ijo, nitori pe omi oro Olorun ti o wa nibe buru. Opolopo
awon akosile nipa awon aisan ni o wa ninu ijo ti ko si si imularada nitoripe
omi oro ti ko dara. Ni kete ti omi oro yi ba ti gba atunse, awon aisan ti emi
yio poora. (2Kings.2:19:22).
Nipase
oro Olorun nikan ni eniyan le gba di atunbi (Didi omo ijoba orun). Elese ti o
ba se alabapade omi oro Olorun yio di wiwe mo. Oro Olorun ni o maa ngba eniyan
lowo dida ese, ohun ni oludaabo bo lowo ese. (Psm.119:11; John.15:7; 1Pet.1:23;
2Tim.3:1-17, 2Tim.4:1-5)
NIBO
NI ORO OLORUN WA?


Oro
Olorun je ohun ti o wa labe atimole.
Yewo:
Owe.25:2
Oro
Olorun je ohun ti a pa mo lati ohun ti o farasin. A nilo lati se awari re jade.
A gbodo gbiyanju lati si aso loju re, kuro labe ahamo. A ko le koni ni oro
Olorun ni ona ti o munadoko, nigbati oro naa ko ba tii di isipaya ni okan wa.
Yewo:
Luke.11:5-13
A
gbodo se agbekale ayika ti o dara fun ibasepo pelu Oluwa.
A=
Ore ni oganjo oru
B=
Ore kekere
D=
Ore agba
Ore
ni oganjo oru wa si odo ore re ni oru. Ore ti o to wayi ko ni ohunkohun ti o le
gbe kale fun. Ore kekere yi lo si odo ore re, eyi tii se ore agba.
AWON AWAWI ORE
AGBA
·
ma yomi lenu.
·
A ti se ilekun
·
Awon omo mi wa
pelu mi lori ibusun
·
Mi o le dide.
Ipo
ti oro Olorun naa wa niyi. Ko si oro Olorun ti o maa nwa laisi kikan ilelun
lera-lera, ki ilekun le si. Nigbati o ba ntesiwaju lati kan ilekun, Jesu tii se
ore agba yio fun o ni isu akara. Matt.7:8; Jer.29:13, Ps.40:1; Eksd.24:12-18.
ORISI AKARA MEJI

Orisi
akara meji ni o wa, awon akara ti o wopo wa ati akara mimo. Yewo: 1Sam.21:1-6.
Akara
ti o wopo wa nibi gbogbo, sugbon o ko le ri akara mimo laisi okan mimo. Oro
Olorun ti o je ifihan ko lee farahan fun eniyan ti ko le ya ara re si mimo.
O
gbodo le fi ohun ti o se iyebiye san idiyele lati le ri oro Olorun. (Lk.22:36,
LK.24:45; 1Sam.9:25-27).
AWON IGBESE SI
SISO ORO OLORUN DI IFIHAN/ SIPAYA
1.
IMURASILE TI AYA: (Owe.16:1-2; Jer.4:3-5)
Ko le si gbigbin irugbin lai tu ile. Gbogbo eniyan ni
won je Olorun ni gbese ojuse lati mu okan wa dara. Ojuse Olorun ni lati gbin
irugbin si okan irufe eniyan ti o ti mura re sile. Okan ni iranse re ti o ngbe
kaakiri, imirasile okan je ojuse eniyan.
Yewo: Jer.17:9, Gen.6:5
2.
MIMU ORISA TI A GBE KALE SINU OKAN KURO: Ezk.14:3-4
Oro Olorun ko lee di isipaya, nigbati awon orisa wa
ninu okan wa. Awon orisa ti o gbe kale ninu okan ndi Olorun lowo lati fun wa ni
ifihan titun. Ko si iwe mimo ti o le si fun wa l’otun, nigbati a ba fi aaye gba
orisa lati joko ninu okan wa.
3.
FA OKAN RE YA:
(Jak.1:21, Jer.29:13) A gbodo we okan wa mo kuro ninu awon nkan wonyi ki Oluwa
to le gbin oro re sinu okan wa:
·
Mu awon egbin
kuro
·
Mu iwa eeri kuro
·
Mu iwa/ise aito
kuro
·
Mu iwa ika kuro
·
Mu iwa buburu
kuro
Yewo: Jeol.2:12-13
4.
SE OKAN RE NI ILE
RERE: Matt.13:3-9; 16-23
Ko si ile rere ti o le farahan fanra-ara-re, ilana
gbodo wa. Gbogbo awon ipejopo nibi ti won ti n pin oro Olorun maa npin si ipele
merin:
|
A
|
B
|
D
|
E
|
|
OJU ONA
25%
|
OKUTA/APATA
25%
|
EGUN
25%
|
ILE RERE
25%
|
Lati orisun kan naa ni awon irugbin yi ti wa.
Iniyelori irogbin naa je bakanna, sugbon ile ni isoro.
5.
O GBODO JE IWE-KIKA: Ezk.2:6-10; 3:1-15
O gbodo ri iwe-kika yi daradara, ki o si je. Jije
iwe-kika ni o gbodo siwaju siso oro Olorun. Okan re gbodo si paya lati je
iwe-kika, ki o le ni opolopo oro ti o fi ko elomiran. Ti o ko ba je, ko ni si
ohunkohun ti oo so jade. Emi oro Olorun (ifihan) ko ni wa, titi di igba ti
eniyan yio je iwe-kika. (Ifih.10:9-10)
Yewo: Isa.6:1-8; Ezra.7:10.
6.
IDAGBA ATI OKUN TI INU: (Onidajo:8:18-21)
O nilo idagba ti emi ati okun ti inu lati le gbe oolu
oro Olorun ni ona ti o munadoko.
“Eni ti o to okunrin ni o le se ise okurun” ni
gbolohun oro ti Zeba ati Zalmuna so fun Gideoni, nigbati Jether ko le fi ida pa
awon oba yi. Ko ni iye ti inu, gboya, ogbon ati iriri ti yio parapo di okun ni
oju ogun.
No comments:
Post a Comment