AGBARA ADURA
NINU IJERE-OKAN
AFIHAN
A ko ni se daradara, ti a ba gboju fo
ipo ti adura wa ninu ise ijere-okan, adura ni igi leyin ogba tabi opa kutele
fun gbogbo ijere-okan ti o ba kese-jari.
Gbogbo ise ijere-okan ti ko ba si adura,
ko lee ti atileyin tabi iranlowo ti orunnnnn; bakan naa ni ko lee mu erongba
tabi ete orun se.
Gbogbo ise ijere-okan ti adura ba je
igi leyin ogba fun, ibaa je ti oniwo tabi ti alawon, yio je eyi ti yio ja si
aseyori, ete tabi erongba Olorun lori re yoo si wa si imuse. Ijere-okan je ise
itusile, ti asi gbodo ri bee (Matt.10:5-8).
Igbelewon aseyori ti ajere okan le ni
duro lori igbe aye re, oro yii Agbara
nso nipa okun, ipa ati lilese.
Okun ti adura nfun ijere-okan ati
ajere-okan je ohun ti a gbodo gbeyewo ti aba fe je eni ikaye ti o munadoko ninu
ise ijere-okan ti Jesus gbe lewa lowo. (Matt. 28:19-20).
Kini adura
Adura je ona ibanisoro tabi biba
Olorun soro (1Sam.1:9-15). Tabi asoye po laarin eniyan atiOlorun.
Bakan naa ni adura je ona lati tu
edun okan jade. (2Kgs.19:14-21, 34-37, 2Kgs20:1-6; Heb.5:7).
Aduraa ni opa Kristiani lati ba
Olorun rin, awon ti won ba Olorun ri lai kaare tabi su won se bee nipa adura
(Is.40:31).
Adura ni on kan gbogi ti o so wa po
mo Olorun.
ONA TI A PIN
ADURA SI
Awon ona meji ni ona ti a pin adura
si, ti a si fi ngbadura, eyi ti a maa gbeyewo ninu eko yii.
i.
Adura gbogboogbo: Eyi je ona siso igbagbo
eni papo mo awon onigbagbo miran loju kan naa lati fimo sokan lori koko oro
kan, ki a sib a Olorun so. Acts.1:14, 4:24-31).
Adura ipejopo: Acts.1:14.
Adura ebi: Adura eleyi je liana ti eniyan fi ngbadura pelu ebi re-
baba, iya ati awon omo.
ii.
Adura enikan pelu Olorun: Eleyi je bibo si egbe kan,
ki eniyan fi gbogbo ibi idiwo seyin, ki o lo sibi ti o dake roro, ti ko si
ariwo, ti o dara tabi ibi iyato lati tu edun okan re jade niwaju Oluwa.
Eks.3:3, 34:1-3, Mk.1:35-36, Eks.24:12, Matt.14:23, 26:36.
IRU AWON
ADURA TI O WA
Orisirisi adura lo wa ti a maa ngba,
sugbon a o maa kiyesi eleyi ti o ni nkan se pelu ijere-okan.
1.
Adura ibebe: Eleyi je ona diduro ni
agbede meji. Erongba Olorun lori gbogbo awon ti oba fe di ajere-okan ni lati
tese bo bata ise iranse Jesu lori ile aye. Esra.9:1-9, Ez.22:30; 1John.2:1-2,
Heb.7:25, 1 Tim.2:1, Dan:9:4-6.
2.
Fifi adura jagun: Eleyi je ona lati gobgun
ti ijoba okunkun lati tu awon onde sile kuro ninu igbkun satani. Isa.61:1
Awon ohun ti
adura nse ninu ijere-okan
Bi oti je wipe ijere-okan kii si ohun
miran bikose ase ti Jesu Oluwa pa fun gbogbo onigbagbo lati dide fun itusile
awon elese kuro ninu agbara okunkunn ti o je gaba lori aye won. O tun je titu
won sile (Elese) kuro ninu ifoju okan won (2Cor.4:4) ki amu won wa sodo Jesu
fun isodotun okan won, (Rom.12:2) mimu won wa sinu ife Olorun.
Jesu to je apeeere wa ninu
ijere-okan, ko ni jade lo fun ise eja pipo lojoojumo bi kose pe o ba gba adura. Mk.1:35-36, Matt.14:2.
i. Adura maa nje ki orun si.
Luke.3:21.
ii.
Adura maa nfa owo Olorun 2Chr.30:27.
iii.
Adura maa nmu itusile wa John.11:38-44, Acts.16:25-26.
iv.
Adura maa nyi igbkun kuro. Awon ti won si wa ninu igbekun esu
sibe le di ominira nipase adura gbigba. Jer.29:12-14, Mk.9:39.
v.
Adura maa ntoni sona. Mk.1:35-39, Dan.6:10, 9:1-4.
vi.
Adura n mu ni dagba: igboya lati rin pelu Olorun je adehun
nipa ise yii ti a lee ri gba nipase adura. Acts.1:4, 8, Acts.2:1
vii.
Adura maa nje ki a de Olorun mo: mk.1:35-39, Acts.1:23-26.
viii.
Adura n woni sa: Mimu alaisan lara da je ona kan pato ninu
ise ijere-okan, eleyi si ndi sise pelu adura. Jak.5:16, Mk.9:39, 2Chr.30:13-20.
AWON IPO GBIGBA ADURA
Awon ipo orisirisi ni
eniyan le wa nigba ti eniyan ba fe gba adura, a o si maa yee awon ipo wonyi wo
ninu imole Bibeli.
i.
diduro: Mk.11:25.
ii.
Kikunle: Dan.6:10, Lk.22:41
iii.
Didojubole: Matt.26:39.
iv.
Kikoju si Ogiri: 2Kgs.20:2
Awon ipo miran wa ti a le
wa nigba ti a ba ngba adura ti o yato si awon ti a gbe yewo monyi:
NIBO ATI NIGBA WO NI ALE GBADURA
Luke.18:1, 1 Sam.1:12, John.2:1, Matt.1:35;
Fil.4:6, 1Tess.3:10, Acts.16:13, 16:25, Acts.3:1, 2:15, Jona.2:1-10.
Gbogbo ibi ti alafo tabi
aye bati wa je ibi ti a tile gba adura, ko si ibi ti a ti gba adura ti Olorun
ko ni dahun.
Awon idena si imunadoko adura
Awon orisirisi nkan ni
olee fa owo Olorun seyin lama le dahun adura, ti o sin mu ki ise ijere-okan ki
o nira, eleyi si fa ibinu Olorun.
i.
Ese tabi ese ti ako jewo: Oro ese yii ti yeye
opolopo akikanju ti iba sun iran won sinu isoji ti a nfe, ki o si mu awon
eniyan kuro ninu ijegaba gbogbo igba satani. Owe.15:8, 29, 2Sm.11:1-21,
Num.32:23.
ii.
Okan aimo: Mk.7:21, Jer,4:4
iii.
Ounje-ajeju: Owe.23:21, 28:7, 23:2.
iv.
Orun-asunju: Owe.10:5, 20:13.
v.
Aini okan ti o gbogbe: Matt.11:30, Gal.6:2.
vi.
Odi-yiyan: 1Pet.3:7.
vii.
Aisotito: Rom.12:2
viii.
Aini igbagbo: Jak5:15
ix.
Ifokanbale to poju:
x.
Omo odo to wulo: 1Sam.9:6-10, 26-27,
10:1-2 (Ero ibanisoro “G.S.M”, Oko ayokele, Oko, Aya, Omo, Orin etc.)
xi.
Ara re: 1Cor.9:27.
xii.
Ibinu: Eks.32:19-22.
xiii.
Nigba ti ibalo to
gunmo/munadoko ko ba si: 1Pet.3:7.
xiv.
Iberu eniyan: Owe.29:25, Dan.6:6-17.
xv.
Ailoye ninu oro Olorun: Fil.4:6, 1Tim.2:8,
Jak.5:13.
xvi.
Ija ti ako pari: Matt.5:23-26.
Awon nkan miran ti otun le
je idiwo fun adura niwonyii: aniyan nipa ojo ola (Matt:6:25-34), itiju
aibaradogba, o je tie de. Jowo gbadura ni ede abini bi re, onimo tara eni nikan
eniyan, ati odaju tun le dini lowo lati ma lee de ibi ite Olorun ninu adura.
AWON OHUN TI
ADURA JE
A.
Adura ni jijirebe fun awon okan ti o wa ninu ahamo
Satani. Luke.22:32-32.
B.
Adura ni titu eniyan sile ninu ide esu, ki a si fie se mule,
ati pe ki a pese re ni yiye fun Oluwa. John.15:7-8, 16.
C.
Adura ni siso okan di Ominira kuro ninu oro esu.
D.
Adura kii se ohun elo ipani, kii se lati pe ina sokale lati
orun sori awon eniyan Ezek.33:11, Ps.116:15, Luke.9:51-56.
JESU, APEERE
WA NINU ADURA.
Labe akori yii a o maa kiyesi apeere
Jesu nipa adura gbigba bi ose ko awon omo leyin gege bi liana ninu iwe.
Matt.6:5-13.
Ese.5-6. Jesu fi ye w ape adura kii
se ohun asehan tabi afe, sugbon ise ti Emi to fara sin ti o si lagbara, adura
kekere ni gbagba je abayori adura pupo ni ikoko.
Ese.7-8. So nipa Pataki ohun ti a
nbeere fun, kii se pe ki a gba adura nikan, sugbon ki a beere fun nkan ayeraya
ti yio wulo ni iran yii ati iran ti onbo.
Ese.9-13. Nso afihan igbekele tabi
liana ti orun la kale lori bi ase gbodo maa gba adura.
i.
Adura Ope (vs.9)
ii.
Adura nipa itesiwaju ise Olorun lori ile aye (vs.10)
iii.
Adura nipa aini wa nipa ti ara (vs.11)
iv.
Adura idariji ese. Eleyi ko faye sile fun dida ese.
(1John.3:8). Nitori pe Olorun ko reti ebo ojoojumo fun ese lati owo wa.
(Heb.10:26). Sugbon ti aba seesi dese (1John.2:1) (vs.12).
v.
Adura igbogun ti satani (vs.13).
EROJA TI O
MU KI ADURA LOKUN
A gbodo di
atunbi (John.3:5)
Olorun ko ni di oju re nigba ti o ba ri ti omo re tooto ba nbeere fun iranlowo
tabi fe mo nipa ohun kan (Heb.1:13, 1John.3:6-10).
No comments:
Post a Comment