Friday, June 26, 2015

PULINE EPISTLES Yoruba


AWON EPISTELI POOLU


ORO AKOSO/AFIHAN
Awon Episteli Paulu je eyi ti iniyelori re ko se siro rara, nitoripe Paulu, labe imisi Emi mimo, ni anfaani lati yanju awon wahala kan pato ati awon isele akoko re pelu awon iwoye ti o je ti gbogbogbo ati eyi ti akoko re ko lopin.

Ninu awon Episteli metala yii, papa awon isele inu aye ni o funni ni ironu ti o ga pelu okana ti o dara lati fi ogbon Olorun yanju awon oro naa.

Lilo awon Episteli gege bi ona ibanisoro isipaya orun ni a ko gbo nipa re rara titi di akoko Paulu ati awon ak’egbe re.  Awon Episteli Paulu ati awon miran ni won ni ibasepo pelu awon aini ati awon isele ti ko daju nipa igbe aye tooto, awon wonyi si je jade lati inu iponju, ayo, ibanuje ati ikaanu awon onkowe ti won je eniyan Olorun yi.

Episteli wonyi kun fun opolopo eko, sugbon a seto re fun igbe aye ifisise ki si se fun imo ori lasan.  Nitori bi awon iwe yi se ri ati awon ihuwasi re, a npe awon iwe Paulu ni leta.  Won n’to pase ilana awon ibukun si eniyan, koko oro inu iwe naa, oro idagbere pelu ikinni ni opin oro naa ati bibu’woluwe.

Majemu titun ni awon Episteli mesan (9) ti a ko si awon ijo ati Merin (4) si awon eniyan kan.  O daniloju, a mo sa, wipe Paulu ko awon iwe kan ti o sonu (1 Korinti 5: 9; 2 Korinti 10: 10; Kol. 4:16; 2 Tess. 3:17).
Awon Episteli Paulu metala ti a tewogba ni a to ni sise ntele, ki awon mesan (9) akoko (si awon ijo) ati merin (4) ti o gbeyin si awon eniyan kan) le wa ni iwontunwonsi.
ENITI O KO IWE NAA


A bi Saulu gege bi omo bibi ilu Romu ninu ilu Tarsu ti kilikia, ti o je aarin gbungbun ikeko.  O se e se ki o ti gba eko griki (Ise Aposteli 17:28; Titu 1:2) ki awon obi re to lo si Jerusalemu.  O ko nipa ise ati-baba (Ise 18:3) sugbon gegebi omo bibi ile Juu lati inu eya Benjamini o gba anfaani kikeko labe Rabbi Gamalieli (Ise 22:3).

Okan akin ati itara esin re ni o mu u de inu esin awon Juu ti o si tayo awon ak’egbe re lo (Gal. 1:14), gegebi odomode Farisi, Saulu wa ni ibi ti a ti so Stefanu l’okuta (Ise 7:58, 81).  O nfi agbara se inunibi si awon Kristiani ti o wa ni Judea, o si pinu lati gbe ipolongo re losi apa Ariwa ila-oorun si Ilu Damasku nigbati ibapade re pelu Krisiti ti o jinde yi aye re papa patapata.  O lo odun meta ni Arabia ati Damasku (Gal. 1:7 – 18) ki Barnabas to fihan awon Aposteli ni ilu Jerusalemu.  Leyin ojo meedogun, idite ti won se si ni o ti jade (Ise 9:26 – 30, Gal. 1:18 – 21), o si lo odun mewa ni Kilikia ati Syria.  (Ti a npe ni Tarsu ati Anatioku tele ri).

Barnabas ati Paulu ni won mu edawo wa lati Antioku si Jerusalemu lati ran awon ara ti iyan nba ja ni Judea lowo (Ise. 11:25-30).
Lehin ti won pada si Antioku, Barnabas, Poolu ati Marku ni won bere irin ajo ise iranse iranjade akoko (Ise. 13-14).
Marku tete pada lehin won, sugbon Paulu ati Barnabas se ise iranse ni Kipru; Pamfilia ati Galatia.  Lehin irin ajo naa, won pada lo si Jerusalemu lati yanju awon isele ti o wa laarin awon keferi ati ofin Mose (Ise 15) lehin naa ni won pada lo si Antioku.

Paulu mu Sila lowo ninu irin ajo iranse iranjade re eleekeji (Ise 15:36, 18:22) eyi ti tejumo agbegbe Makedonia ati Giriki.
Irin ajo ise iranse iranjade eleeketa, bere lati Antioku bakanna, won te’jumo agbegbe Asia pelu Efesu gegebi Olu ilu re (Acts 18:23, 21:16).  Paulu lo si Jerusalemu fun igba ikeyin pelu edawo awon talaka, sugbon won tete fi esun kan wipe, o re ofin Tempili koja ti irukerudo si bere.
Awon ara Romu si mu u wa si Kesarea, ti gomina Felisi si fii pamo sinu tubu fun odun meji (Ise 24:27).  Paulu wi awijare niwaju Felisi, ati adele re Festusi ati Agrippa oba ki o to rin irin ajo ti o l’agbara lo si ilu Romu (Ise. 24:28, 16).  Ni be ni o wa ninu tubu fun odun meji, bi o tile je wipe iwe ise awon Aposteli danu duro nibiyi, o daju wipe, lati inu iwe Paulu si Timoteu ati Titu ati lati enu awon alaigbagbo fi han wipe, a tuu sile kuru ninu tubu.

Paulu ni anfani miran lati se abewo si ilu Spain, Krete, Asia, Makedoni, ati Giriki ki o to lo sinu ahamo awon Romu lekeeji, ti a si pa ni odun A.D. 67 – 68 lati owo Nero.
Igbe aye Kristeni Paulu je eyi ti a se apejuwe re nipa ifarenijin ti o tayo fun Kristi ni oju ijiya.  O ni oye ti o dara nipa ipe orun, ife ti o lagbara fun awon ti o jere fun Kristi, idaniloju ti ko le ye, ati ase ati emi igbekele ninu Kristi ninu ohun gbogbo ti o ba se.
EPISTELI SI AWON ARA ROMU

Episteli si awon ara Romu, Ise Paulu ti o tobi julo, ni a gbe siwaju laarin awon Episteli re metala ninu majemu titun.  NIgbati awo iwe ihinrere merin nso nipa awon oro Kristi, ati ise Kristi, Episteli si awon Ara Romu nso nipa Pataki iku ifaara eni rubo Kristi.  Nipa lilo ona ibeere ati Idahun, Paulu se akosile eko sisen’tele ninu Bibeli.  Iwe Romu ju iwe eko ni pa Olorun lo (theology); O je iwe fifi igbaniniyanju si ise ihinrere nipa Jesu Kristi ju awon otito ti eniyan lee gbagbo lo; o je igbe-aye ti o ye ki eniyan gbe, - igbe aye ododo ti o ye eniyan  “Idalare l’ofe nipa ore-ofe Re (Olorun) nipase irapada ninu Kristi Jesu (omu 3:24)
AKOKO TI A KO IWE NAA

Paulu ko Episteli si awon ara Romu ni A.D. 57, ni opin irin ajo ise iranse iranjade re eleketa (Ise. 18:23-21,14, Romu 15:19). O daju wipe a ko iwe yi ni akoko osu meta ti o lo ni ilu Giriki, (Ise. 20:3-6) ni pato, ni ilu Korinti.  Paulu ngbe pelu alagba Gau ti Korinti (Rom 16: 3; I Korinti 1:14, bakanna ni o daruko “Erastu” eni tii se akapo ilu (Rom 16:23)

Edawo ti Paulu gba lati owo awon ijo Mekedonia ati Akaia fun awon Kristeni alaini ni ilu Jerusalemu ti pe, (Rom. 15:26), o si ti se tan lati mu owo naa lo (Rom. 15:25)

Eyi ti Paulu iba fi wo oko lo si Jerusalemu taara, Paulu yera fun ote awon Juu nipa kikoko lo si apa Ariwa si ilu Fillipi.  O fi iwe yi fun Febe lati inu ijo ti o wa ni Kenkrea nitosi korinti, obinrin yi si mu iwe yi wa si Romu. (Ise 16:1-2).



IDI TI A FI KO EPISTELI YI
           

Paulu ko ko iwe Romu lati yanju awon isoro kan pato ninu ijo, sugbon lati pese okan awon ara sile de ibewo re ti won ti nduro de tipe si ijo yi (Rom. 15:22-24).  Paulu ti gbiyanju lati be ilu Romu wo ni opo igba, sugbon gbogbo akoko ti o ba ti mura tan ni o ma nni idiwo. (Rom. 1:13, 15:22).
Nipa kikowe yii, Paulu ni ireti lati gbe awon onigbagbo ilu Romu ro ninu imo ati igbagbo, lati gba ijo ni iyanju, ti won kun fun adalu ijo awon Juu ati awon keferi, lati sise papo gege bi ara kan.

Paulu tun beere fun atileyin adura won nitori inunibini ti o lewu ti o nduro dee ni Jerusalemu.  Siwaju si, iwe Romu kiise iwe Paulu akoko, sugbon, a moo mo gbe siwaju awon Episteli Paulu, kii se nitori wipe o je ise Paulu ti o gaju, sugbon nitori ti o pese awon ipile eko lori ti awon Episteli miran sinmi le.  O je iwe ti a to leseese julo ati eyi ti o siso loju awon eko ijinle nipa otito ninu Bibeli.  Iwe Romu yi tejumo eko nipa ese ati igbala.  Gegebi gbogbo eniyan (awon Juu ati awon keferi) ti je elese, Olorun fi ore-ofe Re mu igbala wa fun awon  ti won ba fi igbagbo won sinu Kristi Jesu.

PINPIN IWE ROMU


IPIN KINNI:-  IFIHAN NIPA ODODO OLORUN (1:1 – 8:39)
I           ORO AKOSO……………………………………………… ……………………....1:1 – 17
II         IDALEBI: IDI TI A FI NILO ODODO OLORUN…………………………………1:18 – 3:20

A         IDALEBI FUN AWON KEFERI…………………………………………………...1:18 – 32
1.         IDI TI AWON KEFERI FI JEBI……………………………………………………1:18 – 23
2.         ABAJADE IDALEBI AWON KEFERI…………………………………………….1:24 – 32

B         IDALEBI AWON JUU……………………………………………………………...2:1 – 3:8
1.         A SE IDAJO AWON JUU NIPA OTITO…………………………………………..2:1 – 5
2.         A SE IDAJO AWON JUU NIPA ISE WON…………………….............................2:6 – 10
3.         A SE IDAJO AWON JUU LAISI OJUSAJU………………………………………2:11 – 16
4.         AWON JUU KO GBORAN SI OFIN………………………………………………2:17 – 27
5.         AWON JUU KO GBAGBO NINU EMI……………………………………………3:1 – 8

C         IPARI:- GBOGBO ENIYAN JEBI NIWAJU OLUWA……………………………3:9 – 20

III        IDALARE:-    FIFI ODODO OLORUN SINU ENIYAN………………………….3:9 – 20
A.        ALAYE NIPA ODODO…………………………………………………………....3:21 - 31
B.        APEERE NIPA ODODO…………………………………………………………..4:1 – 25
1.         ODODO ABRAHAMU LAISI ISE………………………………………………..4:1 – 8
2.         ODODO ABRAHAMU LAISI IKOLA…………………………...........................4:9 – 12
3.         ODODO ABRAHAMU LAISI OFIN……………………………………………..4:13 – 15
4.         ODODO ABRAHAMU NIPA IGBAGBO NI…………………………………….4:16 – 25

C         ANFAANI ODODO………………………………………………………………5:1 – 11
1.         ALAFIA PELU OLORUN………………………………………..........................5:1 – 2
2.         AYO NINU IPONJU……………………………………………………………..5:3 – 8
3.         IGBALA KURO NINU IBINU OLORUN………………………………………5:9 -11
D         IYATO LAARIN ODODO ATI IDALEBI………………………………………5:12 – 21

IV        ISODIMIMO:- FIFI ODODO OLORUN SI ISE………………………………...6:1 – 8:39
A         ISODIMIMO ATI ESE…………………………………………………………..6:1 – 23
1.         IKU ONIGBAGBO SI ESE NINU ILANA……………………………………..6:1 – 14
2.         IKU ONIGBAGBO SI ESE NI IFISISE………………………………………...6:15 – 23

B         ISODIMIMO ATI OFIN………………………………………………………..7:1 – 25
1.         DIDOKU SI OFIN ATI ALAAYE SI OLORUN……………………………....7:1 – 6
2.         OFIN KO LEE GBANI LOWO ESE…………………………………………...7:7 – 25

C         ISODIMIMO ATI EMI…………………………………………………………8:1 – 39
1.         EMI NI O’GBANI LOWO AGBARA ERAN ARA…………………………...8:1 – 11
2.         EMI NI O NFUN NI NI AGBARA LATI DI OMO…………………………..8:12 – 17
3.         EMI NFUN NI IDANILOJU OGO OJO IWAJU……………………………...8:18 – 30
4.         EMI NFUN NI IDANILOJU ISEGUN IKEHIN……………………………..8:31 – 39

IPIN KEJI: IDAJO NIPA ODODO OLORUN………………………………………9:1 – 11 – 36
1.         ISRAEL L’ATIJO: AYANFE OLORUN………………………...………….9:1 - 29
A.        IBANUJE PAULU…………………………………………………………...9:1 – 5
B.        AGBARA ISEJOBA TI OLORUN………………………………………….9:6 – 29

II         ISRAEL NISISINYI: IKOSILE OLORUN…………………………………9:30 – 10:21
A.        ISRAELI NWA ODODO NIPA ISE………………………………………..9:30 - 33
B.        ISRAELI KO KRISTI SILE……………………………………...................10:1 – 15
C.        ISRAELI KO AWON WOOLI SILE……………………………………….10:16 – 21

III        OJO IWAJU ISRAELI: IMUPADA BO SIPO LATI OWO OLORUN…....11:1-36
A.        KIKO ISRAELI SILE KII SE PATAPATA………………………………...11: 10
B.        KIKO SILE KII SE OPIN…………………………………………………....11:11 – 32
1.         IDI TI A FI KO ISRAELI SILE………………………………......................11:11 – 24
2.         ILERI IMUPADABOSIPO ISRAELI………………………………………..11:25 – 32

C.        IMUPADABOSIPO ISRAELI: ONA LATI FI OGO FUN OLUWA……....11:33-36

IPIN KETA: FIFI ODODO OLORUN SI ISE……………………………………....12:1 – 16:27
1.         ODODO OLORUN NI FI SI ISE NIPA OJUSE AWON KRISTIENI… …..12:1 – 13:14
A.        AWON OJUSE WA SI OLORUN………………………………………….12:1 – 2
B.        AWON OJUSE WA SI AWUJO……………………………………………12:3 – 21
C.        AWON OJUSE SI AWON ALASE NI IPO GIGA…………………………13:1 – 7
D.        AWON OJUSE SI AWON ALABAGBE PO……………………………….13:8 – 14

II         ODODO OLORUN TI A FI SI ISE NIPA OMINIRA KRISTIENI………...14:1 – 5:13
A.        AWON ILANA OMINIRA KRISTIENI……………………………………14: 1 - 13
B.        FIFI AWON OMINIRA KRISTIENI SI ISE………………………………..15: 1 – 13

III        IPARI………………………………………………………………………...15:14 – 16:27
A.        IDI TI PAULU FI KOWE YI………………………………………………..15:14 – 21
B.        IDI TI PAULU SE FE RIN IRIN AJO………………………………………15:22 – 23
C.        IYIN PAULU ATI IKINI……………………………………………………16:1 – 27

     EPISTELI AKOKO SI AWON ARA KORINTI

Ni ogorun odun akoko, ilu Korinti ni o gbegba oroke ninu oro aje ni apa guusu ilu Griki.  Ilu yi ko gbajugbaja nitori iwa eri re ati nitori iwa iborisa.  Sugbon pelu gbogbo awon idiwo yi, Paulu ni anfaani lati gbin ijo Kristieni nibe ninu irin ajo ise iranse re eleekeji (Ise 18: 1 – 7).  Bi o tile je wipe won ni ebun Emi, ti won si ndagba, sibe, ijo yi kun fun awon wahala:  Nipa ti ara, nipa eya, nipa eko, ati ifisise, wahala gbogbogbo ati ti eyo enikan.
Paulu kowe episteli kinni si awon ara Korinti yi lati le yanju awon wahala yi, ati lati dahun awon ibeere ti awon kristieni ilu Korinti ti beere lori awon isele ti o takoko.
AKOKO TI A KO IWE NAA

Korinti je ilu kan Pataki ninu ilu Griki atijo titi di akoko  ti a paarun lati owo awon ara Romu ni odun 146B.C.
Julius Kaesari ni o se atunko re gegebi ilu Romu ti a tun ‘tedo ni odun 46B.C, o si dagba, o se rere, osi pada di Oluilu agbegbe Akaia.

Ede Pataki ti won nso ni Latin, sugbon Griki ni ede gbogbo eniyan.  Ni akoko Paulu, Korinti je Olu-ilu peloponnesu, niwon igba ti o je wipe ilu yi wa laarin okun meji, laarin okun Aegeani ati okun Adriatiki, eyi ni so peloponnesu pelu ariwa Griki.  Nitori ibudoko oju omi meji ti won ni, ilu yi di ibi taja, ti awon oko oju omi kekeeke si ngule si ebute Korinti lati le yera fun irinajo ogorun meji ibuso ti o lewu ni tosi guusu ile Griki.

Awon inunibini ti owa ni Makedonia ni o dari Paulu lo si iha guusu si Atheni, lehin naa ni o rekoja lo si Korinti.  Paulu ko iwe ekini ati ikeji si awon ara Tessalonika, o si gbe ise iranse re kuro in sinagogu lo si ile Titu Justu nitori inunibini, o si yi Kripu lokan pada, eni tii se olori sinagogu.  Paulu ko awon eniyan ni eko oro Olorun ni Korinti fun osu mejidinlogun (18 months) ni odun AD 51 – 52.

Lehin ti Paulu lo, Apollo wa lati Efesu lati se ise iranse ninu ijo Korinti (3:6, Ise 18:24 – 28).  Nigbati Paulu nkoni ti o si nwaasu ni Efesu ni akoko irin ajo ise iranse re eleeketa, o gbo iro ibinuse lati odo awon ara ile Kloe nipa awon wahala ti o wa ninu ijo Korinti (1 Korin 1:11).  Ijo naa si ran awon asoju okunrin meta (1 Korinti 16:7) awon ti won mu leta wa, ti won si nbeere fun idajo Paulu lori awon isele kan (I Kor. 7:1).  Paulu ko episteli yi lati fesi si awon wahala ati awon ibeere awon ara korinti (o ti ko iwe kan si won tele (I Kor. 5:9).  Paulu npete lati kuro ni Efesu (I Kor. 16:5-8); ntokasi wipe a ko episteli akoko si awon ara korinti ni odun A.D. 56.

IDI TI A FI KO IWE NAA

Idi ti a fi ko Episteli yi ni lati fi ilana igbe aye Kristieni si ise ninu aye olukuluku ati laarin awujo.  Agbelebu Kristi ni iwaasu ti a ya soto lati yi aye awon onigbagbo pada, ki o si so won di eni oto; gegebi eniyan ati gegebi ara apapo laarin aye ti o yi wa ka.

Sugbon awon ara Korinti nba eri won je nitori iwa eeri ati aisokan.  Paulu ko Episteli gegebi iwe ibaniwi si awon irohin nipa awon wahala ati awon iwa aito ti o wa laarin awon ara Korinti (I Kor. 1:10 -17).
A seto Episteli lati se atunse awon iwa ati isesi ti ko dara ati lati gbe emi isokan laruge laarin awon ara ninu ibasepo ati ijosin won.  Paulu ko fe be won wo pelu ogo  nitori okan ife baba ti o ni si won (I Kor. 4:14 – 15;  4:21) (Ise. 18:24 – 19:1).

Nipase ilakaka ise iranse iranjade Paulu ati awon miran ni a gbin ijo si ilu Korinti sugbon, o nira fun Paulu lati yo Korinti kuro ninu ijo.  Igbe aye keferi awon ara Korinti ni agbara akoran lori awon Kristieni ti o wa ninu ilu  ti o di baje yi – wahala oniruuru ni o yi won ka.

Ninu iwe ikora-eni-ni-ijanu yi, a fi ipa mu Paulu lati lo ase Apostoli re bi o se nyanju awon wahala ipinya, iwa agbere, aibowofun ofin, imotara-eni-nikan, biba ounje ale Oluwa je, Biba awon ebun Emi je, ati sise ajinde Jesu.  Paulu so awon iwoye ti o po lori awon ibeere ati awon isele ti awon ara Korinti so nipa re ninu iwe won.

PINPIN EPISTELI KINNI SI KORINTI


IPIN KINNI:- IDAHUN SI IROHIN NIPA IPINYA………………...........…………1:1 – 4:21)
I           ORO AKOSO…………………………………………………………………1:1 – 9
A.        IKINNI PELU ORE OFE……………………………………………………..1:1 – 3
B.        ADURA IDUPE………………………………………………………………1:4 – 9

II         IROYIN NIPA IPINYA………………………………………………………1:10 – 17
III        AWON IDI IPINYA………………………………………………………….1:18 – 4:21
A.        NINI OYE TI O LODI NIPA IWAASU IHINRERE………………………...1:18 – 3:4
1.         IHINRERE KII SE OGBON TI AYE YI……………………………………..1:18 – 2:5
2.         IHINRERE JE OGBON TI ATOKEWA……………………………………..2:6 – 3:4

B         NINI OYE TI O LODI NIPA AWON IRANSE IHINRERE………………...3:5 – 4:5
1.         AWON IRANSE JE ALABASISE PAPO PELU OLORUN………………...3:5 – 17
2.         AWON IRANSE JE ENI TI YIO SIRO ISE WON FUN OLUWA………….3:18 – 4:5
C         NINI OYE TI O LODI NIPA ISE IRANSE PAULU………………………...4:6 – 21

IPIN KEJI: IDAHUN SI IROYIN NIPA AGBERE………………………………….5:1 – 6:20
1.         NIPA IBALOPO LAARIN IBATAN……………………………… ………..5:1 - 13
A.        FI AWON ALAGBERE NAA FUN IFIYAJE………………………………..5:1 – 8
B.        YERA FUN AWON ONIGBAGBO ALAIMO……………………………….5:9 -13
II         NIPA FIFI EJO SUN NI ILE EJO LAARIN AWON ONIGBAGBO…………6:1 – 11
III        IKILO LODI SI IWA AGBERE……………………………………………….6:12 – 20

IPIN KETA: IDAHUN SI IWE AWON IBEERE……………………………………..7:1 -16:24
I           IMORAN NIPA IGBEYAWO…………………………………………………7:1 – 40
A.        AWON ILANA FUN IGBE-AYE IGBEYAWO…………………………….7:1 – 9
B.        AWON ILANA FUN AWON ONIGBAGBO T’O GBEYAWO……………7:10 – 16
D.        AWON ILANA NIPA DIDURO NINU IPE OLORUN……………………..7:17 – 24
E          AWON ILANA FUN AWON TI KO TII GBEYAWO……………………...7:25 – 38
E          AWON ILANA FUN TITUN-IGBEYAWO  SE……………………………7:39 – 40

II         IMORAN NIPA AWON OHUN TI A FI RUBO SI ORISA…………………8:1 – 11:1
A         AWON ILANA OMINIRA ATI AWON ARAKUNRIN ALAILERA………8:1 – 13
B         APEJUWE PAULU ATI OMINIRA TIRE…………………………………...9:1 – 27
D         PAULU SO NIPA ETO RE GEGEBI IRANSE OLORUN…………………..9:15 – 27
E          IKILO NIPA BIBA OMINIRA JE……………………………………………..10:1 – 13
E          IRUNISOKE LATI LO OMINIRA LATI FI SE OLUWA LOGO…………...10:14 – 11:1

III        IMORAN NIPA IJOSIN ITAGBANGBA…………………………………….11:2 – 14:40
A.        AWON ILANA NIPA ADURA ITA-GBANGBA……………………………11:2 - 16
B.        IBANIWI LORI SISE LODI SI ILANA OUNJE ALE OLUWA……………..11:17 – 34
D         ILANA NIPA LILO AWON EBUN EMI……………………………………..12:1 – 14
1.         IYIRIWO NIPA BI A SE KO EMI NI IJANU………………………………...12:1 – 3
2.         ONIRUURU AWON EBUN…………………………………………………...12:4 – 11
3.         PATAKI AWON EBUN………………………………………………………..12:12 – 31
4.         LILO AWON EBUN PELU IFE………………………………………………..13:1 – 13
5.         TITAYO EBUN ASOTELE…………………………………………………….14:1 – 6
6.         EBUN ONIRUURU EDE……………………………………………………….14:7 – 25
7.         LILO AWON EBUN NINU IJOSIN ITAGBANGBA………………………….14:26 – 40

IV        IMORAN NIPA AJINDE………………………………………………………..15:1 – 58
A.        OTITO NIPA AJINDE KRISTI………………………………15:12 – 19
D.        ILANA/ETO NIPA AJINDE…………………………………………………….15:20 – 28
E.         ITUMO TI ARA NIPA AJINDE KRISTI……………………………………….15:29 – 34
E.         AWON ARA OKU T’O JINDE…………………………………………………15:35 – 50
F.         AWON ARA ALAAYE TI A SI NIPA PADA………………………………….15:51 – 58

V         IMORAN NIPA EDAWO FUN JERUSALEM…………………………………16:1 – 4
VII      IPARI…………………………………………………………………………….16:5 – 24

          EPISTELI KEJI SI AWON ARA KORINTI

Lati igba Episteli Paulu akoko, ijo Korinti ti gbile pelu awon oluko eke ti won nru awon eniyan soke lodi si Paulu.  Won wipe paulu maa ntete yi pada, eni ti o gberaga, eni ti irisi re ko wuni, eniti oro enu re ko dara, alaisooto ati eniti ko ye lati je Aposteli Kristi.
Paulu ran Titu lo si Korinti lati lo yanju awon oran isoro yi, nigbati o pada de, inu re dun lati gbo iroyin nipa iyipada okan awon ara Korinti.   Paulu kowe yi lati fi okan idupe han fun awon ogooro eniyan ti o ronupiwada ati lati sipe fun awon olote die ti o ku lati gba ase re.
Ninu gbogbo iwe yi, Paulu daabo bo ihuwasi re, isesi re ati ipe re, gegebi Aposteli Oluwa Jesu Kristi.
AKOKO TI A KO IWE NAA

Paaulu wa ni ilu Efesu nigbati o ko iwe Korinti kinni, ti o si nreti wipe ki Timoteu se agbeyewo si ilu Korinti ki o si pada wa sodo re (I Korinti 16:10 – 11). Timoteu mu irohin to Paulu wa nipa inunibini ti o ti dide lodi si ninu iwe ise awon Aposteli, sugbon itokasi re wa ninu 2 Korin. 2:1. 12:14. 13:1 – 2)
Nigbati Paulu pada si ilu Efesu, Paulu fi ibanuje kowe si ijo Korinti ti o si nro won lati fi iyaje awon adari alatako naa (2:1 – 11, 7:8).

Titu ni o mu leta (iwe) yi lo si Korinti.  Paulu npongbe lati gbo esi oro naa, o koja lo si ilu Troasi, o si tun re koja si ilu Makedonia lati pade Titu ninu irin ajo re (2 Kor. 2:12 – 13, 7:5 – 16).  Inu Paulu dun gidigidi nipa iroyin ti Titu mu pada wa, wipe opolopo awon ara Korinti ti ronupiwada kuro ninu iwa ote won, ti won se lodi si ase Aposteli Paulu.

Amo sa, inunibini ranpe si wa sibe, eyiti awon egbe elesin Juu ndari re. (10 – 13) Nibe ni ile Makedonia ni Paulu ti kowe Episteli keji si awon ara Korinti ti o si fi ran Titu ati arakunrin miran (8:16 – 24).  Eleyi sele ni opin odun A.D 56, ati wipe ilu Makedonia ti a ti ko iwe yi ni a npe ni Fillipi.  Paulu rin irin ajo re eleeketa lo si ilu Korinti lehin nkan wonyi (12:14; 13:1 – 2, Acts 20:1 – 3) nibe ni o ti ko iwe si awon ara Romu.

IDI TI A FI KO IWE NAA


Idi ti a fi ko Episteli keji si awon ara Korinti da lori awon Aposteli eke ti won bere ipolongo ti o munadoko lodi si Paulu ninu ijo ti o wa ni Korinti, Paulu si gbe awon igbese ti o po lati bori inunibini naa.  Episteli yi fi ayo Aposteli yi han lori isegun ti ihinrere otito ni ni ilu Korinti (1 – 7); o si gbe iwuri fun “Ikedun  ti Olorun” ati ironupiwada opo awon onigbagbo ti o wa nibe.  Bakanna ni o ro awon ara Korinti lati mu ileri won se nipa ore atinuwa fun awon alaini ti o wa laarin awon Kristieni ti o wa ni Judea. (8 – 9).  Edawo yi ki yio je iranlowo fun awon alaini nikan, sugbon yio fi okan ikaanu awon kristieni keferi ti o wa ni Makedonia ati Akaia han fun awon kristieni Juu ti o wa ni Judea, eleyi yio si fi isokan laarin awon keferi ati awon Juu han ninu ara Kristi.  Inunibini ti a soro re ni ori 10 – 13 je eyi ti o kun fun awon omo Juu (Ara palestini tabi awon Helleni; 11:22) ti won so wipe Aposteli ni awon ise (11:5, 18; 12:11) sugbon ti won nwaasu bi onde ninu sise olori won (11:20).  Ori 10 – 13 ni a ko lati tu asiri “awon osise eletan” ati lati da abo bo ase ti Olorun fun Paulu ati ise iranse re gegebi Aposteli Jesu Kristi.

PINPIN EPISTELI KEJI SI AWON ARA KORINTI


IPA KINNI:-  ALAYE PAULU LORI SE IRANSE RE…………………………………1:1 – 7:16
I           ORO AKOSO/AFIHAN…………………………………………………………..1:1 – 11
A         IDUPE PAULU SI OLORUN…………………………………………………….1:1 – 7
B         WAHALA PAULU NI ASIA……………………………………………………..1:8 – 11
II         ALAYE PAULU LORI IYIPADA IPINU RE……………………………………1:12 – 2:13
A         OJULOWO ETO/IPINU PAULU………………………………………………...1:12 – 22
B         IYIPADA IPINU PAULU………………………………………………………...1:23 – 2:4
D         ISIPE PAULU LATI DARIJI……………………………………………………..1:5 – 13

III        IMO IJINLE PAULU NIPA ISE IRANSE………………………………………..2:14 – 6:10
A         KRISTI NI O NMUWA YO AYO ISEGUN……………………………………...2:14 – 17
B         IYIPADA AYE – ERI ISE IRANSE………………………………………………3:1 – 5
D         MAJEMU TITUN NI IPILE ISE IRANSE………………………………………..4:1 – 7
E          KRISTI NI AKORI NLA FUN ISE IRANSE……………………………………..4:8 – 15
E          IDANWO MBE NINU ISE IRANSE……………………………………………...4:16 – 18
F          IRUSOKE NINU ISE IRANSE……………………………………………………4:16 – 5:2
            1.         IRUSOKE NIPA AWON IWOYE TI ODE………………………………..4:16 – 18
            2.         IRUSOKE NIPA IFARAHAN KRISTI NI OJO IWAJU…………………5:1 – 8
            3.         IRUSOKE NIPA ERE OJO IWAJU………………………………………5:9 – 10
            4.         IRUSOKE NIPA IFE KRISTI…………………………………………….5:11 – 16
            5.         IRUSOKE NIPA ISE IRANSE ILAJA…………………………………...5:17 – 21
            6.         MASE OHUN IKOSE NINU ISE IRANSE……………………………...6:1 – 10

IV        IWAASU IMORAN PAULU SI AWON ARA KORINTI………………………6:11 -7:16
A         PAULU BEBE FUN ILAJA……………………………………………………...6:11 - 13
B         PAULU BEBE FUN YIYA KURO LODO AWON ALAIGBAGBO…………...6:14 – 7:1
D         IPADE PAULU PELU TITU……………………………………………………..7:2 – 7
E          IDAHUN AWON KORINTI SI IWE PAULU……………………………………7:8 – 16

IPA KEJI: EDAWO TI PAULU GBE FUN AWON AYANFE…………………………..8:1 – 9:15
I           APEERE AWON ARA MAKEDONIA…………………………………………...8:1 – 6
II         IWAASU IRUSOKE SI AWON ARA KORINTI…………………………………8:7 – 9:15
A         APEERE KRISTI…………………………………………………………………..8:7 – 9
B         EREDI IFIFUNNI…………………………………………………………………..8:10 – 15
D         ALAYE LORI AWON ASOJU…………………………………………………….8:16 – 9:5

1.                  AWON IPINU NINU IFIFUNNI…………………………………………..8:16 – 24
2.                  IMURASILE NINU IFIFUNNI……………………………………………9:1 – 5
E          IRUSOKE SI IFIFUNNI…………………………………………………………..9:6 – 15
            1.         AWON ILANA NIPA IFIFUNNI…………………………………………9:6 – 7
            2.         AWON ILERI NINU IFIFUNNI………………………………………….9:8 – 15

IPIN KETA:   IDAJO OTITO PAULU NIPA JIJE APOSTELI RE……………………...10:1 – 13:!4
I           PAULU DA AWON OLUFISUN RE LOHUN…………………………………...10:1 – 8
A         ESUN NIPA AWON OJO GBE IDAHUN………………………………………..10:1 – 2
B         IDAHUN SI ESUN NIPA RIRIN NIPA TI ARA…………………………………10:3 – 9
D         IDAHUN SI ESUN NIPA AILERA ENIKAN……………………………………10:10 – 18

II         PAULU DA ABOBO JIJE APOSTELI RE……………………………………….11:1 -12:13
A         IKEDE PAULU LORI JIJE APOSTELI RE………………………………………11:1 – 15
B         IJIYA PAULU JE ATILEHIN FUN JIJE APOSTELI RE………………………...11:16 – 33
D         AWON ISIPAYA PAULU JE ATILEYIN FUN JIJE APOSTELI RE……………12:1 – 10
            1.         IRAN NIPA PARADISE…………………………………………………..12:1 – 6
            2.         EGUN NINU ERAN ARA RE…………………………………………….12:7 – 10
E          AWON AMI PAULU JE ATILEHIN FUN JIJE APOSTELI  RE………………...12:11 – 13

III        PAULU KEDE IBEWO RE TI O NBO……………………………………………12:14 – 13:10
A         PAULU KO FE JE ERU IYONU NIPA ETO ISUNA OWO……………………...12:14 – 18
B         PAULU KO FE BA WON NINU IGBE AYE ERAN ARA……………………….12:19 – 21
D         IKILO PAULU LATI YE ARA WON WO………………………………………..13:11 – 14
IV        IPARI……………………………………………………………………………….13:11 – 14

EPISTELI SI AWON ARA GALATIA

Episteli si awon ara Galatia ni a pe ni “ASE OMINIRA KRISTIENI” o je iwe ti Paulu ti fi idalare nipa igbagbo han ati ominira ti o njade lati iru re.  Paulu fi iwe ase ominira kristieni s’owo si awon eniyan ti won ti se tan lati fi ominira won ti ko se diyele sile eyi ti won gbe ninu Kristi.  Awon amofin Juu kan ni won ngbiyanju lati se akoran fun awon onigbagbo ti o wa ni Galatia lati fi ominira won ti won gba ninu Kristi d’okowo fun igbekun si ofin.
Paulu kowe yi lati tako ihinrere eke won nipa awon ise, ati lati fi ajulo idalare nipa igbagbo han.  (kii se nipa ise ni a fi ngbanila, bikose nipa idalare nipa igbagbo).
AKOKO TI A KO IWE NAA

Paulu se abewo si ilu Galatia fun igba akoko ninu irin ajo ise iranse re eleekeji, boya nigba ti o wa ni oju ona si ilu Troasi, (Ise 16:6).
Ninu irin ajo ise iranse Paulu eleeketa, Paulu tun se abewo miran si awon ijo ti o wa ni Galatia eyi ti o ti da sile (Ise 18:23).  O si ko episteli yi boya ni Efesu (A.D. 53 – 56) tabi Makedonnia (A.D. 56) tabi ni ilu Rome.  Paulu kowe yi lati f’esi si awon iroyin wipe awon ijo Galatia ti yara fi aye gba awon eko eke lati bori won.  Eko eke yi ni awon elesin Juu kan nko ti won fi enu lasan njewo Jesu, sibe ti won nwa ona lati fi awon keferi ti won sese gbagbo si abe awon ohun ti ofin Mose nbeere. (Gal. 1:7, 4:17, 21, 5:2 – 12, 6:12 – 13).


IDI TI A FI KO EPISTELI NAA


Iwe Galatia je iwe pajawiri ati iwe itoni sona ti o se afihan awon ipele meta ti o je idi ti a fi ko episteli si awon ara Galatia.
ORI KINNI – IKEJI ni a ko lati fi daabo bo ase Paulu gegebi Aposteli, nitori eleyi fi ese iwaasu ihinrere re mule.
ORI KETA – IKERIN ni a ko lati fun wa ni idabo bo nipa eko imo ijinle nipa ilana idalare nipa igbagbo lati fi tako eko eke ti idalare nipa ofin.  Paulu lo ofin papa lati fi gbe oro re lehin.
ORI KARUN –IKEFA ni a ko lati fi han wipe ominira kuro ninu ofin ko tumo si aiteriba fun ofin (ko tumosi aibowo fun ofin) gege bi awon alatako Paulu ti so tele.
Episteli yi fi han wi pe awon onigbagbo ko si labe ofin, sugbon a gba wa la nipa igbagbo nikan.  Olorun gbe Paulu didi gegebi Mose fun awon Ijo Kristieni lati gba won ninu igbekun esin awon Juu.  (ofin ati awon irubo).  Agbara emi mimo ni o nran awon kristeni lowo lati gbadun ominira larin ofin ife.

PINPIN EPISTELI SI AWON ARA GALATIA


I           A DAABOBO IHINRERE ORE OFE……………………………………………………1:1 -2:21
A         ORO AKOSO/AFIHAN…………………………………………………………………..1:1 – 9\
            1.         IGBALA: IPILE ORE OFE……………………………………………………….1:1 – 5
            2.         ISELE AYIKA – YIYA KURO NINU ORE OFE………………………………..1:6 – 9
B         ISIPAYA ATOKEWA NI O NFUN NI NI IHINRERE ORE OFE………………………1:10 – 24
D         AWON ADARI JERUSALEM NI O NBUWOLU IHINRERE ORE OFE………………2:1 – 10
E          ASE IDAJO OTITO SI IHINRERE ORE OFE NIPA BIBA PETERU WI………………2:11 – 21
II         ASE ALAYE NIPA IHINRERE ORE OFE……………………………………………….3:1 – 4:31
A         A NFI EMI MIMO FUN NIPA IGBAGBO, KII SE NIPA ISE…………………………..3:1 – 5
B         A DA ABRAHAMU LARE NIPA IGBAGBO, KII SE NIPA ISE……………………….3: 6 – 9
D         IDALARE JE NIPA IGBAGBO, KII SE NIPA OFIN…………………………………….3:10 – 4:11
            1.         KRISTI TI RA WA PADA KURO NINU EGUN OFIN…………………………3:10 – 14
            2.         MAJEMU ABRAHAMU KO S’OFO NIPA OFIN………………………………..3:15 – 18
            3.         A FUN WA LOFIN LATI TI WA SINU IGBAGBO……………………………...3:19 – 22
            4.         AWON ONIGBAGBO TI DI OMINIRA KURO NINU OFIN…………………  3:23 – 4:11
E          AWON ARA GALATIA GBA IBUKUN NIPA IGBAGBO, KII SE NIPA ISE………….4:12 – 20
E          OFIN ATI ORE OFE KO LE E GBE PAPA……………………………………………….4:21 – 31
III        A FI IHINRERE ORE OFE SI ISE…………………………………………………………5:1 – 6:18
A         IPO OMINIRA: DIDURO SINSIN…………………………………………………………5:1 – 12
B         FIFI OMINIRA SI ISE: FE OMONIKEJI RE………………………………………………5:13 – 15
D         AGBAA FUN OMINIRA: RINRIN NINU EMI……………………………………………5:16 – 26
            1.         IJAGUDU LAARIN EMI ATI ARA………………………………………………..5:16 – 18
            2.         AWON ISE TI ARA…………………………………………………………………5:19 – 21
            3.         AWON ESO TI EMI………………………………………………………………   5:22 – 26
E          AWON OHUN TI A GBODO SE NINU OMINIRA: SE RERE FUN GBOGBO ENIYAN.6:1 – 10
E          NI IPARI……………………………………………………………………………………..6:11 – 18
            1.         ERONGBA AWON TI O K’OLA…………………………………………………   6:11 – 13
            2.         ERONGBA PAULU APOSTELI………………………………………………...….6:11 – 18

EPISTELI SI AWON ARA EFESU

A ko Episteli yi si egbe awon onigbagbo kan, ti won je oloro pupo ninu Jesu Kristi, sugbon ti won ngbe aye atoroje nitori wipe won je ope si awon ohun oro won, ati wipe won ko lo oro won bi o ti ye.  Won si nrin gegebi otosi ninu emi.
Paulu bere pelu sise alaye ni ori kinni – keta pelu awon oro nipa awon “iwe ifowopamo ti kristieni ti o wa li orun: isodomo, itewogba, irapada, idariji, ogbon, ogun edidi emi mimo, iye ore ofe, jije omo ilu orun aikukuru, gbogbo awon ibukun ti emi.
Lati inu awon opolopo isura ti emi yi, awon kristieni ni gbogbo isura ati ohun alumoni ti won nilo lati gbe igbe aye won”Si iyinlogo ati orre-ofe re” (1:6).
Ori kerin – ikefa fi ara jo ile iwosan nibi ti a ti nto egungun, nibi ti awon onigbagbo ti nko bi a ti nrin ninu emi lati fi ese mule ninu isura tabi oro ti emi ti o je tiwon.
AKOKO TI A KO IWE NAA

Ni opin irin ajo ise iranse re elekeeji Paulu se abewo si ilu efesu nibi ti o fi Priskilla ati Akuila si (Ise 18:18 – 21).  Paulu duro ni ilu Efesu to bi odun meta ni akoko irin ajo ise iranse re eleeketa (Ise. 19:2 – 30), oro Olorun tan kale ni gbogbo agbegbe Asia.  Ise iranse Paulu ti o munadoko bere si kolu gbogbo awon alalupayida ati awon agbegilere ni ilu naa, eleyi ni o si mu irukerudo sele ninu gbogan isere awon ara Efesu.  Paulu si fi ilu naa sile lo si ilu Makedonia lehin naa, sugbon Paulu se ipade pelu awon alagba Efesu nigbati o nrin irin ajo re lo si Jerusalem (Ise 20:17 – 38).

Paulu ko “Awon Episteli ogba ewon” (Iwe Efesu, iwe Filippi, iwe Kolosse ati iwe Filemoni) ni akoko ti o wa ni ogba ewon awon ara Romu ni odun AD 60 – 62.  Efesu 3:1, 4:1, 6:20 Filippi 1:7, 13 – 14, Kolose ati iwe Filemoni ni o daju wipe a ko won ni akoko kan naa (Efesu 6:21 – 22, Kol. 4:7 – 9) ni odun 60 – 61 A.D.  Ako iwe Filippi ni odun A.D 62, ni kope re ni a tu Paulu sile.

A ko kowe yi lati fi yanju awon asise kankan ninu ijo agbegbe naa, sugbon a ko lati se idaabo bo kuro lowo awon wahala ninu gbogbo ijo l’apapo, nipa gbigba ara Kristi ni iyanju lati dagba ninu Kristi.  Ako iwe yi bakanna, lati je ki awon onigbagbo mo nipa ipo won ninu Kristi, nitori eyi ni ipile awon ohun ti won nfi si ise ni gbogbo igbe aye won.  Ida akoko ninu iwe Efesu so nipa awon ohun ini ti orun ti o je ti onigbagbo, bi, Isodomo, irapada, ogun agbara, iye, oore ofe, jije omo orun ati ife Kristi.  Ko si awon ohun pajawiri ni ori kinni – iketa, eyi ti o tejumo awon ebun atoke wa.  Sugbon ori kerin – ikefa ni awon ohun marundinlogoji ti o je itoni ti o so nipa olukuluku.  Nitorinaa, iwe Efesu bere ni orun osi pari si inu ile ati ninu gbogbo awon ibasepo igbe aye ojoojumo.
PINPIN IWE EFESU

IPA KINNI:- IPO KRISTIENI…………………………………………………………………....1:1 – 3: 21
I           IYIN FUN IRAPADA…………………………………………………………………….1:1 -14
A         IKINI LATI OWO PAULU……………………………………………………………….1:1 – 2
B         AWON TI BABA YAN…………………………………………………………………...1:3 – 6
D         OMO SE IRAPADA……………………………………………………………………....1:7 – 12
E          EMI MIMO FI EDIDI DI………………………………………………………………….1:13 – 14
II         ADURA FUN ISIPAYA…………………………………………………………………..1:13 – 14
III        IPO AWON KRISTIENI…………………………………………………………………..2:1 – 3:13
A         IPO AWON KRISTIENI GEGE BI ENIKOOKAN………………………………………2:1 – 10
            1.         IPO ATIJO: OKU SI OLORUN…………………………………………………...2:1 – 3
            2.         IPO TITUN: ALAYE SI OLORUN……………………………………………….2:4 – 10
B         IPO AWON KRISTIENI LAPAPO……………………………………………………….2:11 – 3:13
            1.         ILAJA LAARIN AWON JUU ATI AWON KEFERI…………………………….2:11 – 22
            2.         ISIPAYA NIPA ADIITU NIPA IJO………………………………………………3:1 – 23
IV        ADURA FUN ISINIYE…………………………………………………………………...3:14 – 21
IPA KEJI:  AWON OHUN IFISISE ISE KRISTIENI……………………………………………4:1 – 6:24
I           ISOKAN NINU IJO……………………………………………………………………….4:1 -6
A         IWAASU IYANJU SI ISOKAN…………………………………………………………..4:1 – 3
B         ALAYE KIKUN NIPA ISOKAN………………………………………………………….4:4 – 6
D         AWON ONA SI ISOKAN AWON EBUN………………………………………………...4:7 – 11
E          AWON IDI FUN AWON EBUN…………………………………………………………..4:12 – 16
II         IGBE AYE MIMO………………………………………………………………………...4:17 – 5:21
A         BO OGBOLOGBO OKUNRIN ATIJO SILE……………………………………………...4:17 – 22
B         GBE OKUNRIN TITUN WO………………………………………………………………4:23 – 29
D         MA SE MU EMI MIMO BINU…………………………………………………………….4:30 – 5:2
E          RIN GEGEBI OMO IMOLE……………………………………………………………….5:13 – 17
E          E KUN FUN EMI MIMO…………………………………………………………………..5:18 – 21
III        AWON OJUSE NINU ILE ATI NIBI ISE…………………………………………………5:22 – 6:9
A         AWON AYA: TERIBA FUN OKO TIRE…………………………………………………5:22 – 24
B         EYIN OKO: FERAN AWON AYA YIN…………………………………………………..5:25 – 33
D         EYIN OMO: E GBORAN SI AWON OBI YIN…………………………………………...6:1 – 4
E          ISE ISIN NINU ISE OOJO………………………………………………………………...6:5 – 9
IV        IHUWASI NI AKOKO IJAGUDU………………………………………………………...6:10 – 24
A         GBE IHAMORA OLORUN WO…………………………………………………………..6:10 – 17
B         GBADURA FUN IGBOYA………………………………………………………………..6:18 – 20
D         NI IPARI……………………………………………………………………………………6:21 – 24

EPISTELI SI AWON ARA FILIPPI

Episteli si awon ara Filippi je Episteli ayo ati imulokanle laarin awon isele ayika ati ko ba ara mua.  Ninu Episteli yi, Paulu se alaye daradara nipa ife ailegbe ti oun ni si awon ara Filippi, papa julo nitori awon eri won ti ko ye ati atileyin won.  Paulu fi tifetife ro won lati gbe awon ise won, ero won le agbara Jesu Kristi.  Paulu, bakanna, nwa ona lati se atunse wahala aisokan ati ifagagbaga, ti o si nro awon oluka ise yi pe ki won se afarawe Kristi ninu iwa irele ati ihuwasi iranse re.

Ni ona yi ni ise iranse ihinrere yio ti tesiwaju, gegebi awon onigbagbo se nlepa lati duro sinsin, ti won si ni okan kanna, ti won si nyo nigbagbogbo, ti won si ngbadura nipa ohun gbogbo.
Paulu k’owe idupe si awon onigbagbo ti o wa ni ilu Filippi fun iranlowo won ni akoko aini re, bakanna ni o lo iwe yi lati fi awon itoni nipa isokan onigbagbo s’owo si won.  Ninu Kristi nikan ni isokan tooto ati ayo se e se.
AKOKO TI A KO EPISTELI NAA


Ni odun 356 B.C, Oba Filippi ti ilu Makedonia (Baba Alexanderu nla) ni o gba ilu yi ti o si mu ilu yi gboro si, ti o si tun pa oruko ilu yi ni FILIPI.  Awon ara Romu ko ilu yi ni igbekun ni odun 168 B.C; ati ni odun 42 B.C. Ipe Paulu si Makedonia nigbati o wa ni Troasi ni akoko irin ajo ise iranse re eleekeji ni o mu ki Paulu bere ise iranse ni ilu Filippi pelu iyipada okan Lydia ati awon miran.  Paulu ati Sila ni a fiyaje ti a si ti won mo inu tubu, sugbon eleyi yori si ijere-okan oni tubu ni ilu Filippi.  Paulu tun se abewo miran si awon ara Filippi ninu irin ajo ise iranse re eleeketa (Ise 29:1, 6).  Nigbati won gbo nipa ahamo awon ara Romu ti Paulu wa, ijo Filippi ran Epafroditu pelu iranlowo owo (4:18), won ti ran Paulu lowo lemeji ninu awon isele bayi miran( 4: 16).

Epafroditu fere de oju iku ninu aisan ti o se sibe o wa pelu paulu fun ojo pipe tobe ti awon ara filippi
ti gbo nipa aisan re. Lehin ti ara re da tan, Paulu fi iwe yi ran an pada si awon ijo filippi(2: 25-30).
Sila, Timoteu Luku Paulu ni won koko wa si ilu filippi ni A.D. 51, odun mokanla ki Paulu to ko
Episteli yi. Awon itokasi wonyi (1:13, 4:22) fi han wipe a ko ni ilu Romu, bi o tileje wipe awon oluwadi
Kan wipe ilu kaeserea ni tabi ilu efesu. A ko iwe filippi ni odun A.D. 62, ki a to tu Paulu sile ninu ogba
ewon.

                                                            IDI TI A FI KO EPISTELI NAA


A ko iwe yi lati fi ife ati imoore Paulu han si awon onigbagbo ti o wa ni ilu Filippi ati lati gba won ni imoran si igbe aye isokan, iwa mimo, ati ayo.
Paulu papa gbadun ibasepo ti o dara pelu awon ijo Filippi, ijo ti o dabi eni pe o feran julo.  Won ni isiniye pupo si awon aini eto isuna owo fun Paulu, won si n ba aini re yi pade pupo ju awon ijo miran lo. (4:15 – 18, 2 Kor. 8:11), o si dabi eni pe won ko ni isoro laarin ara won.
A ko iwe Filippi lati yanju irukerudo kankan, sugbon lati fi ife Paulu han si won, ati imoore re fun awon ebun won, o si gba won niyanju nipa idagba kristieni won, o gba won niyanju ki won ma fi eti si awon eko eke, ati awon ero ti o ni nipa ikola re.

Paulu fi iroyin nipa ewon ti o wa to awon ara Filippi leti ati ise iranse ti o ndagba nipa ipolongo iwaasu ihinrere (1:12 – 20); o si mura won sile de wiwa Timoteu ati oun papa bi o ba se e se (2:19 – 24).  O kilo fun won ni awon ewu meji nipa awon olofin ati awon alatako ayanfe, sugbon o so eleyi lati da abo bo won, ju ibawi lo.
Ni ona miran, Paulu se idamo wahala aisokan ti o ndagba si laarin ijo Filippi ati wipe o nwa ona lati se atunse re ki o to po si.

PINPIN EPISTELI SI AWON ARA FILIPPI


I           ALAYE PAULU LEKUNRERE NIPA IPO TI O WA LOWOLOWO………………....1:1 – 30
A         ADURA IDUPE PAULU………………………………………………………………...1:1 – 11
B         IPONJU PAULU GBE IHINRERE GA………………………………………………….1:12 – 18
D         IPONJU PAULU GBE OLORUN GA…………………………………………………...1:27 – 30
II         ISIPE PAULU LATI NI OKAN KRISTI………………………………………………...2:1 – 30
A         IWAASU IYANJU PAULU LATI NI IWA IRELE……………………………………..2:1 – 4
B         APEERE IWA IRELE KRISTI…………………………………………………………..2:5 – 16
D         APEERE IWA IRELE PAULU………………………………………………………….2:17 – 18
E          APEERE IWA IRELE TIMOTEU………………………………………………………2:19 – 24
E          APEERE IWA IRELE EPAFRODITU………………………………………………….2:25 – 30
III        ISIPE PAULU LATI NI OYE NIPA KRISTI…………………………………………...3:1 – 2
A         IKILO LODI SI NINI IGBEKELE NINU ARA………………………………………...3:1 – 9
B         ORO IYANJU LATI MO KRISTI………………………………………………………3:10 – 16
D         IKILO LATI MASE GBE IGBE AYE WA FUN ERAN ARA…………………………3:17 – 21
IV        ISIPE PAULU LATI NI ALAFIA KRISTI……………………………………………...4:1 – 23
A         ALAAFIA PELU AWON ARA GBOGBO……………………………………………..4:1 – 3
B         ALAAFIA PELU OLUWA……………………………………………………………...4:4 – 9
D         ALAAFIA NINU IPOKIPO……………………………………………………………..4:10 – 19
E          NI IPARI…………………………………………………………………………………4:20 – 23

EPISTELI SI AWON ARA KOLOSSE

Iwe Kolosse ni iwe ti Kristi je itejumo julo ninu gbogbo awon iwe Bibeli.  Ninu re, Paulu tenumo ajulo Kristi ati igbala pipe ti o pese lati le doju ija ko awon eko eke ati awon ayederu eko ti ko ba bibeli mu ti to o ngbile si ninu ijo Kolosse.
Kristi, Oluwa lori gbogbo iseda ati ori Ara, tii se ijo Re, je eni ti o to fun gbogbo aini ti emi ati ti ara tabi aini miran ti o nba onigbagbo finra.  Isokan awon onigbagbo pelu Kristi ninu iku Re, Ajinde Re ati igbega Re ni ipile eyi ti a gbodo ko igbe aye re ni aye yi le lori.
Awon ibasepo ninu ati l’ode ile wa le se afihan awon iyipada ojojumo eyi ti igbagbo ninu Jesu Kristi nse ninu irin awon onigbagbo.
AKOKO TI A KO EPISTELI NAA

Kolosse je ilu kekere ti o to ogorun maili ila oorun Efesu ni ekun ijo meje ti Asia ninu iwe Ifihan ori kinni si iketa.  Kolosse je ilu ti o gbajugbaja teleri ti o si je orisun olokowo, o l’okiki nitori owu didan ti o je dudu ti won ni.  Ni akoko Paulu, awon ara ilu ti won wa nitosi won ti ko won ni igbekun, awon ara Laodikea ati Hierapoli (4:13) ilu yi si ti rehin.  O daju wipe Paulu ko tii se abewo si ijo Kolosse eyi ti a da sile lati owo Epafrasi (1:4 – 8, 2:1).

Ninu irin ajo re eleeketa, Paulu fi bi odun meta jin fun ise iranse agbegbe Asia ti o wa ni Efesu (Ise 19:10, 20:31) ati wipe boya akoko yi gan ni Epafrasi fi aye re fun Jesu Kristi.  O gbe ihinrere lo si awon ilu ti o wa ni afonifoji Likusi (Lycus).
Iwe Kolosse, iwe Filemoni, ati iwe Efesu ni a ko ni akoko kan naa, labe iru isele ayika kan naa.  Paulu ko awon Episteli yi  ni akoko ti o wa ni ahamo awon ara Romo l’akoko.  Ti o ba je be, Paulu ko iwe kolosse ni Odun A.D 60 tabi 61, o si fi ran Tikiku ati eru ti o ti yipada ti a npe ni onesimu si awon ara Kolosse. (4:7 – 9), Efe 6:221, Filem 10:12).

IDI TI A FI KO EPISTELI NAA


Paulu ko Episteli yi lati gba awon ara Kolosse niyanju lati tesiwaju ninu igbagbo, ki won fi ese mule, ki won si duro sinsin (1:23), ki won lee dagba, ki won si so eso ninu ogbon Kristi (1:10) Sise alatileyin gidi fun ihinrere tooto yio fun won ni ifesemule ati agbara lati da gbogbo ofa akoran pada.  Idi miran ti o wa ni okan Aposteli yi ni o farahan ni ori keta (3:1 – 4:6).  Paulu nfe ki awon ara Kolosse ni oye to ‘dara nipa ajulo Kristi, wipe kii se nipa eko nikan,  sugbon ninu ise pelu agbara ajulo Kristi je abalakan, jijowo ara eni fun Kristi ni abala keji.  Ipo onigbagbo ninu Re (3:1 – 4) ni o nmu ipile ati agbara fun igbe aye t’o yi pada ni gbogbo ona wa.  Kristi ni ori gbogbo awon ijoye ati awon agbara (2:10).  Kristi ni Oluwa gbogbo iseda – 1:16 – 17.  Kristi ni olupilese ilaja – 1:20 – 22, 2:13 – 15.  Kristi ni ipile ati eredi onigbagbo – 1:5,23, 27.  Kristi ni orisun agbara igbe aye otun fun onigbagbo – 1:11, 29.

Kristi ni olurapada ati olulaja awon onigbagbo (1:14, 20 – 22, 2:11 – 15).  Kristi ni aworan ekunrere Olorun ti a ko ri – 1:15, 19, 2:9.  Kristi ni eleda ati eni ti o mu ohungbogbo wa laaye.   1:16 – 17.  Kristi ni ori gbogbo ijo – 1:18; Kristi ni Olorun ninu eniyan ti o jinde, Oun si ni Olugbala ti o ni anito ati aniseku.

PINPIN EPISTELI SI AWON ARA KOLOSSE


IPA KINNI:- AGBARA AJULO KRISTI NINU IJO……………………………………………1:1 – 2:23
I           ORO AKOSO…………………………………………………………………………….1:1 – 14
A         IKINI PAULU SI AWON ARA KOLOSSE……………………………………………..1:1 – 2
B         IDUPE PAULU SI AWON ARA KOLOSSE……………………………………………1:3 – 8
D         ADURA PAULU SI AWON ARA KOLOSSE…………………………………………..1:9 – 14
II         KRISTI JU OHUN GBOGBO LO………………………………………………………..1:15 – 2:3
A         KRISTI TAYO NINU ISEDA……………………………………………………………1:15 – 18
B         KRISTI TAYO NINU IRAPADA………………………………………………………..1:19 – 23
D         KRISTI TAYO NINU IJO/AJULO KRISTI NINU IJO………………………………….1:24 – 2:3

III        OMINIRA NINU KRISTI………………………………………………………………..2:4 – 23
A         OMINRA KURO NINU AWON ORO ETAN…………………………………………..2:4 – 7
B         OMINIRA KURO NINU IMO ASAN…………………………………………………...2:8 – 10
D         OMINIRA KURO NINU IDAJO AWON ENIYAN…………………………………….2:11 – 17
E          OMINIRA KURO NINU SISIN AWON OHUN TI KO TO……………………………2: 18 – 19
E          OMINIRA KURO LOWO EKO AWON ENIYAN……………………………………..2:20 – 23

IPA KEJI:- IJOWO ARA  ENI FUN KRISTI NINU IJO……………………………………...3:1 – 4:18
I           IPO ONIGBAGBO………………………………………………………………………3:1 – 4
A         BO OGBOLOGBO OKUNRIN NI SILE………………………………………………..3:5 – 4:6
B         E GBE OKUNRIN TITUN WO…………………………………………………………3:5 – 11
D         ASE IGBE AYE MIMO FUN WA……………………………………………………...3:18 – 4:6
            1.         IGBE AYE MIMO NINU EBI………………………………………………......3:18 – 21
            2.         IGBE AYE MIMO NINU ISE…………………………………………………..3:22 – 4:1
            3.         IGBE AYE MIMO NI AARIN AWUJO………………………………………..4:2 – 6

III        IPARI……………………………………………………………………………………4:7 – 18
A         ORO IWURI FUN TIKIKU…………………………………………………………….4:7 – 9
B         IKINI LATI OWO AWON ORE PAULU……………………………………………...4:10 – 14
D         AFIHAN NIPA IWE YI………………………………………………………………...4:15 – 18



EPISTELI PAULU AKOKO SI AWON ARA TESSALONIKA


Fun oye ti o dara nipa awon ori marun Episteli akoko si awon ara Tessalonika, je ki a lo ka iwe Ise Awon Aposteli 17:1 – 10, 20:1 – 16.
Ninu ibi ti akoko daruko ninu iwe ise awon Aposteli, nibe ni a ti ri akosile ibewo Paulu akoko si ilu Tessalonika.  Ilu yi je ibudoko oju omi ni apa Ariwa ile Hellene ati okan lara awon ileto Makedonia.  Lati inu ise awon Aposteli 20:1 – 6, O dabi eni wipe Paulu tun abewo se si ilu yi ni igba meji ni akoko irin ajo ise iranse re eleeketa.

Lehin ise iranse ibadore  ranpe ti o se ni ilu Tessalonika, Paulu rekoja lo si ilu Berea nitori inunibini lati owo awon Juu, lehin naa ni o tesiwaju lo si ilu Ateni, lehin naa si ilu Korinti.
Paulu si duro ni ilu yi fun bi osu mejindinlogun (Ise. 18:11) o si lero wipe o ko awon Episteli mejeeji si awon ara Tessalonika ni akoko ti o duro ni ilu yi.

AKOKO TI A KO EPISTELI NAA.

Episteli akoko si awon ara Tessalonika ni Episteli akoko ninu gbogbo iwe ti Paulu ko eyi ti a si fi pamo sinu majemu titun.  Pelu idaniloju, ako episteli yi ni odun A.D. 52.

IDI TI A FI KO EPISTELI NAA


Lehin ti a ti le Paulu jade kuro ni ilu Tessalonika ti oun papa ti rin irin ajo lo si apa guusu Hellene, o ni ipongbe lati mo ipo ti awon Kristieni kekere yi wa ninu ilu Tessalonika ti o kun fun inunibini.
Paulu papa iba ti pada wa, sugbon o fi to wa leti wipe satani de oun lona (2:18).  Eleyi fihan wipe Paulu mo daju pe lehin isota awon ara Juu, agbara satani nwa ona lati di ise Olorun lowo.  Paulu ni anfani lati ran Timoteu lati Atheni (3:1, 2). Lehin naa, Timoteu pada wa si ilu Korinti, ti o si mu oro iyanju wa nipa bi awon ara Tessalonika ti duro giri ninu igbagbo laarin inunibini ati awon iponju miran.  O ko iwe igbaniyanju yi, ti o si da lori ipada bo Oluwa leekeji.  Ni akoko inunibibi, ko si otito ti o nmu itunu wa si okan awon onigbagbo ju ti ipadabo Jesu Kristi Oluwa.

Ni afikun mimu itunu wa sinu ijo Tessalonika nipase eko ipadabo Oluwa leekeji; Paulu se awon atunse nipa erongba ti o lodi.  Fun apeere, awon kan wa ti won banuje gidigidi, ti won lero wipe awon onigbagbo ti won ti ku ki yio ni ‘ipin ninu ifarahan ologo ti Oluwa.  Paulu se atunse eleyi ninu 1 Tess 4:13 – 18.  Awon miran tun wa, ti won nronu wipe Oluwa yio de nigbati enikeni ko l’ero won si si eleyi tumo wipe enikeni ko nilo lati se ise oojo kokan Paulu se atunse eleyi bakanna 1 Tess. 4:11, 12.
    KIYESI ELEYI


ORI KINNI –             Mu imisi wa fun Kristieni kekeeke
ORI KEJI –    Mu imulokanle wa fun awon iranse Kristi Olooto
ORI KETA – Je ireti iwenumo ati ipe si igbe aye mimo fun awon onigbagbo (3:1 – 4:12)
ORI KERIN – Mu itunu wa fun awon ti won padanu awon eniyan won (4:13 – 18)
ORI KARUN – Je ipe si ikiyesara ati isora gidigidi si awon ti won nrewesi ninu igbe aye kristieni won.
PINPIN IWE KINNI SI AWON ARA TESSALONIKA


I           AWON OHUN TI PAULU SO NIPA AWON ARA TESSALONIKA………………1:1 – 3:13
A         PAULU GBE IWURI FUN WON NIPA IDAGBA WON…………………………....1:1 – 10
B         BI PAULU SE DA IJO NAA SILE……………………………………………………2:1 – 16
D         BI TIMOTEU SE MU IJO NAA LOKUN…………………………………………….2:17 – 3:13
            1.         SATANI DI PAULU LOWO………………………………………………….2:17 – 20
            2.         PAULU RAN TIMOTEU……………………………………………………...3:1 – 5
            3.         AWON IROYIN IYANJU TIMOTEU………………………………………...3:6 – 10
            4.         IPONGBE PAULU LATI BE WON WO……………………………………...3:11 – 13
II         AWON ITONI PAULU SI AWON ARA TESSALONIKA…………………………..4:1 – 5:28
A         AWON ILANA LATI DAGBASOKE………………………………………………...4:1 – 12
B         ISIPAYA NIPA AWON OKU NINU KRISTI………………………………………...4:13 – 18
D         APEJUWE OJO OLUWA……………………………………………………………...5:1 – 11
E          AWON ITONI FUN IGBEAYE MIMO……………………………………………….5:12 – 22
E          IPARI…………………………………………………………………………………...5:23 – 28


      EPISTELI KEJI SI AWON ARA TESSALONIKA


Episteli keji si awon ara Tessalonika ni iwe Paulu ti o kerejulo ninu awon iwe ti o ko si awon ijo – iwe Paulu si Filemoni nikan ni o kere ju Episteli yi lo.
Ko ye ki o le pupo fun wa lati awon ori meta iwe yi ni opo igba, yio si je ohun iranlowo lati ka Episteli yi ni awon eda Bibeli miran ti o wa bi: (N.C.V, G.N.B., A.M.P.,N.I.V., K.J.V., R.S.V., N.L.T., L.B., C.E.V. etc).  A ko Episteli yi si awon onigbagbo ni ilu Tessalonika, a se itokasi eleyi ninu awon ori miran tabi ninu Episteli akoko si awon ara Tessalonika.
Ibewo Paulu akoko ni o yorisi dida ijo sile ni ilu Tessalonika, ohun ni o si faa ti o fi ko Episteli akoko si won.
AKOKO TI O KO IWE NAA


Episteli keji yi ni a ko ni nkan bi osu die lehin ti ako iwe akoko, boya ni odun A.D. 53.  Lehin ti Timoteu ti mu iwe akoko lo fun awon ara Tessalonika, o pada si odo Aposteli.  Laisi iye meji, Paulu si wa ni ilu Korinti, nigbati Timoteu mu iroyin nipa itesiwaju won wa, bi o tile je wipe awon inunibini si ntesiwaju, bakanna ni o royin re pe awon miran wa ti won ti gba eko eke laaye, ti won si wipe awon ti ni isipaya nipa ipadabo Kristi leekeji tabi iwe miran lati owo Paulu (2:2).
Eko eke yi ni o fihan wipe ipadabo Kristi yio waye laipe (igbakugba).  Eleyi ni o si fa ti awon miran fi ko ise oojo won sile ati awon ojuse miran, to be ti awon miran fi gbe atije ati atimu won lori awon itore anu ti awon miran nse fun won, ti won si ko lati se ise. (3:9 – 13)

IDI TI A FI KO EPISTELI KEJI NAA


Paulu Aposteli Kristi ni o fi Episteli keji s’owo si awon ara Tessalonika lati fun won ni awon itoni si nipa ipadabo Kristi leekeji, nitori eleyi ni o fa akori Episteli yi.  Bakanna ni Paulu baa won ti won ko lati se ise oojo won ati awon ojuse miran wa ninu Episteli yi.  Ni afikun si awon imoran dara dara yi, o kilo fun awo ijo nipa ihuwasi won si awon ti won ko fe gba tabi gboran si imoran yi (3:14, 15).  1 Tess 5:13 – 18 at Tess 2:1 - 12 ti a ba fi won we ara won, awon mejeeji tenumo ipadabo Kristi leekeji.

Ninu didojuko tabi sise atunse ati nitori awon ihuwasi eke ti awon miran gba, Paulu Aposteli so wipe awon ise kan yi koko waye ki ojo idajo to de, eyi nipe, ki ojo Oluwa wa to de.
Ninu Episteli yi, o so di mimo wipe, nigbati bibo Kristi ba sun mo etile, awon miran yio subu kuro ninu igbagbo (2:3) ati wipe Kristi yio wa fun awon tire nikan (1:10); lehin naa ni a o se afihan eni ika ni (2:8) lehin naa ni Oluwa wa yio farahan ni idajo 2:8).

PINPIN EPISTELI KEJI SI AWON ARA TESSALONIKA


I           ORO IYANJU/IRUSOKE PAULU NINU INUNIBINI………………………………….1:1 – 12
A         IDUPE FUN IDAGBASOKE WON……………………………………………………...1:1 – 4
B         ORO IRUNISOKE/IYANJU NINU INUNIBINI WON………………………………….1:5 – 10
D         ADURA FUN IBUKUN OLORUN………………………………………………………1:11 – 12
II         ALAYE PAULU LORI OJO OLUWA…………………………………………………...2:1 – 17
A         AWON ISE TI YO SAAJU OJO OLUWA……………………………………………….2:1 – 12
            1.         LAKOKO SISUBU KURO NINU IGBAGBO/IYAPA…………………………..2:1 – 3
            2.         FIFI ENI ESE NI HAN……………………………………………………………2:4 – 5
            3.         MIMU OLUDENA KURO NI OJU ONA……………………………………….2:6 – 7
            4.         IPADABO KRISTI LEEKEJI……………………………………………………2:8 – 12
B         ITUNU GBOGBO ONIGBAGBO NI OJO OLUWA…………………………………...2:13 – 17
III        ORO IRUSOKE PAULU SI IJO…………………………………………………………3:1 – 18
A         FI SUURU DURO DE BIBO KRISTI…………………………………………………...3:1 – 5
B         YERA KURO LODO AWON ONISEGESEGE………………………………………....3:1 – 15
D         IPARI……………………………………………………………………………………..3:16 – 18

EPISTELI AKOKO SI TIMOTEU


Awon iwe meta yi, Iwe kinni ati ekeji si Timoteu ati iwe Titu, ni a ko papo ti a si npe ni AWON EPISTELI OLUSO AGUNTAN”.  Eyi ri bee nitoripe a ko won si awon eniyan kan, kii se si awon ijo.  Won s’oju awon iwe Paulu meta ti o ko gbeyin ti a fi pamo fun wa ninu majemu titun.  A ko won nigbati Paulu ti di arugbo, o si ko won jade lati inu ekunrere iriri re gegebi missionary, ajinhinrere, olusoaguntan ati olukoni.
Awon Episteli meta wonyi ni ako si iranse Olorun ti o je odo, ti o si kilo fun Timoteu ati Titu lori awon anfaani aati awon ojuse osise kristieni.
Iwe yi soro nipa awon wahala tabi isoro ti awon oluso aguntan tabi iranse Olorun le dojuko ninu ipe won.  Nitori naa, a le pe akori awon Episteli yii ni “AWON ANFAANI, AWON OJUSE ATI AWON ISORO OLUSO-AGUNTAN ATI/OSISE KRISTIENI”.
AKOKO TI A KO EPISTELI NAA


Ninu ori ti o kehin iwe ise awon Aposteli, a ka nipa Paulu, onde ni ilu Romu.  Ni akoko yi gan ni o ko “AWON EPISTELI OGBA EWON”.  Paulu, amosa, se abewo miran si ilu Efesu, sugbon ko ni anfaani lati duro pe ni ilu yi, o fi Timoteu sile nibe lati dari awon onigbagbo nibe.  Lehin naa ni won tun mu Paulu, ti won si fii sinu tubu ni igbakeji ni ilu Romu, o si dabi enipe ni odun A.D. 68 ni o ku iku ajeri fun Kristi.  Filip. 2:24, Filemoni 22, 1 Tim 1:3; Titu 3:12, 2 Tim 4:13, 20.
            Paulu si beere wipe ki Timoteu yara kankan lati to oun wa (2 Tim 4:9, 11, 12).  A ko Episteli akoko si Timoteu ni akoko ti o wa laarin igba ti Paulu fin se ewon akoko ati eleekeji ni ilu Romu.

Gegebi a ti ko iwe naa si Timoteu, eni ti Paulu se apejuwe re ninu 1:2 gegebi “Omo mi tooto ninu igbagbo” ati bakanna ninu 2 Tim. 1:2 gegebi “Omo mi Olufe owon”, o dabi eni pe Paulu ni o mu Timoteu wo inu Oluwa.  O daju wipe ibasepo ti o dara kan bere laarin awon mejeeji.  Paulu ni baba ninu igbagbo fun Timoteu ati wipe Timoteu ni omo ninu igbagbo fun Paulu.  Baba Timoteu nipa ti ara je Hellene, iya re si je omo bibi ile Juu, o si dabi eni pe Timoteu tete fi aye re fun Oluwa lati igba ewe re.  O ngbe ni ilu Lystra (Ise 14:6 – 21, 16:1 – 3) Paulu se ibewo si ilu Lystra yi, o si pada lo lati ko awon onigbagbo ti o wa nibe. (vs 21). Ni igba akoko ti Paulu wa si ilu yi ni won so ni okuta ti won si gbe si eyin odi ilu ni oku (Ise 14:19).  Nje Timoteu yi pada bi ni akoko yi?  Nje nse ni Oluwa ba Timoteu soro bi o se ri ti won nso Paulu l’okuta bi?  Tabi akoko yi gan ni odomokunrin Timoteu yi, eni ti o je omo kekere ti ojo ori re kere, gbo ipe Olorun lati je iranse fun Olorun bi?

Ko seese lati fi idahun to gun rege fun awon ibeere wonyi.  Ninu iwe ise awon aposteli 16:1 – 5, a ka wipe Paulu tun se abewo miran si ilu Lystra ni akoko irin ajo ise iranse re eleekeji, ati wipe lati akoko yi ni Timoteu ti darapo mo Paulu, bi o ti le je wipe a ko lee so boya Timoteu ti pe omo ogun odun (20 yrs) ni akoko yi.  Bayi ni ibasepo ti o so Paulu ati Timoteu po se bere ti o si ran awon mejeeji lowo gidigidi.
Ninu Timoteu, Paulu ri odomokunrin eyi ti o se e gbekele, eni ti o si fi awon ise Pataki le lowo ati awon ojuse ti o le (1 Tess. 3:1, 2, 1 Korin. 4:17, 1 Korin. 16:10, 11, 1 Tim 4:12 – 16, 2 Tim 2:1 – 7, 2 Tim 4:1 – 2.
Ninu korinti keji 1:1, Filippi 1:1 ati 1 & 11 Tess 1:1 oruko Timoteu so po mo ti Paulu ninu fifi awon iwe naa ranse.  Akoko ti o dabi eni pe Paulu kowe si Timoteu ni A.D 66, sugbon ibi ti Paulu ti ko iwe naa ko daju.  Sugbon awon oluwadi miran so wipe a ko iwe naa ni odun A.D. 62 – 63.

IDI TI A FI KO EPISTELI KINNI SI TIMOTEU


Idi Pataki ti a fi ko iwe yi ni pajawiri ni lati gba Timoteu ni iyanju, ati lati kilo fun ni awon ikoni eke ti o nrapala wo inu awon ijo ati lati kilo fun bakanna, ati papa, gbogbo kristieni ti o je osise ati awon iranse Olorun, wi pe kii won gbe igbe aye mimo ati wi pe ki won duro sinsin ninu igbagbo ati ki won si waasu eko ti o ye kooro.
Okan lara awon eko eke ti Paulu gbiyanju lati dojuko ni eko eke nipa angeli gegebi o ti dojuko won ninu episteli si awon ara Kolosse.  Awon eleko eke yi (Anostics) gbagbo ninu ki angeli se Olubebe laarin Olorun mimo ati awon eniyan elese.  Won nko won wipe oni-ruru ipo awon angeli ni o wa, ti won si din Jesu ku si ipo okan lara awon angeli nla.  Paulu tako eleyi ninu iwe 1 Tim 2:5 “Alarina kan ni mbe laarin eniyan ati Olorun, oun papa eniyan, ani Kristi Jesu”.

PINPIN EPISTELI KINNI SI TIMOTEU


I           ORO ASE PAULU NIPA AWON EKO………………………………………………1:1 – 20
A         AWON ORO ASE TI PAULU FUN TIMOTEU TELE……………………………....1:1 – 11
B         AWON ORO ASE KRISTI FUN PAULU TELE……………………………………..1:12 – 17
D         ASE AKOKO: “JA IJA RERE”………………………………………………………..1:18 – 20

II         ORO ASE PAULU NIPA ISIN ITAGBANGBA……………………………………...2:1 – 3:18
A         ADURA NINU ISIN ITAGBANGBA………………………………………………...2:1 – 8
B         AWON OBIRIN NINU ISIN ITAGBANGBA………………………………………..2:9 – 15
D         AWON AMUYE FUN AWON BISOPU……………………………………………...3:1 – 7
E          AWON AMUYE FUN AWON DIAKONI……………………………………………3:8 – 13
E          ASE KEJI: “MO BI O TI YE LATI MA HUWA NINU ILE OLORUN”…………….3:14 – 16

III        ORO ASE PAULU NIPA AWON OLUKO EKE……………………………………..4:1 – 16
A         APEJUWE AWON OLUKO EKE…………………………………………………….4:1 – 5
B         AWON ITONI FUN AWON OLUKO OTITO………………………………………..4:6 – 10
D         ASE KETA:    MASE ALAINANI EBUN…………………………………………….4:11 – 16

IV        ORO ASE PAULU NIPA IBANIWI NINU IJO………………………………………5:1 – 25
A         BI O SE YE KI A SE SI GBOGBO ENIYAN………………………………………...5:1 – 2
B         BI O SE YE KI A SE SI AWON OPO………………………………………………...5:3 – 16
D         BI O SE YE KI A SE SI AWON ALAGBA…………………………………………..5:17 – 20
E          ASE KERIN: MA SE AKIYESI NKAN WONYI LAISE OJUSAJU………………...5:21 – 25

V         ASE PAULU NIPA OKAN SISE OLUSO AGUNTAN……………………………...6:1 – 21
A         ORO IRUSOKE/IYANJU SI AWON IRANSE………………………………………6:1 – 2
B         ORO IYANJU SI IWA BI OLORUN PELU ITELORUN……………………………6:3 – 16
D         ORO IYANJU SI AWON OLORO……………………………………………………6:17 – 19
E          ASE KARUN: SE ITOJU OHUN TI A FI SI IKAWO RE……………………………6:20 – 21









EPISTELI KEJI SI TIMOTEU


“………Nitori a nfi mi rubo nisisiyi, ati lo mi si sunmo etile.  Emi ti ja ija rere, emi ti pari ire ije mi, emi ti pa igbagbo mo……..” (2 Tim 4:6, 7).
Episteli keji si Timoteu ni iwe ikehin ti Paulu ko, bi e ti nka iwe ti o ni ori merin, e o  ri edun okan Aposteli agba yi, bi o ti mo wipe oun yio fi emi oun lele laipe.
Episteli naa nmi ile gidigidi pelu ipongbe ti Paulu ni lati so oro iyanju ikehin, lati kilo ati lati gba Timoteu niyanju, bakanna ni o nro Timoteu lati yara  to oun wa.

AKOKO TI A KO IWE NAA

O dabi eni pe, lehin ti Paulu ko iwe akoko si Timoteu, eniti o wa ni ilu Efesu, Paulu kuro ni ile Hellene, o si tele Titu lo si ilu Krete nibi ti o fi Titu sile si, ti o si pada lo si ilu Hellene.    Pelu idaniloju, o wa ni irin ajo re lo si ilu Nikapoli, ti o si lero wipe oun o lo akoko otutu nibe (Titu 3:12).  O dabi enipe Paulu tesiwaju lo si ilu Miletu nibi ti o fi Trofimu, eni ti o se aisan sile si (2 Tim 4:20) ati wipe awon itokasi nso wipe Paulu fi Erastu sile ni ilu Korinti, o si tun tesiwaju lo si ilu Troasi nibi ti o ti duro pelu onigbagbo kan ti anpe ni Karpu (2 Tim 4:13).  Nibe ni a ti mu Paulu lojiji, ti ko si ni anfaani lati ko gbogbo eru re.  A mu Paulu gegebi elewon lo si ilu Romu, gbogbo eniyan si gba wipe a se iku pa Paulu ni ibere odun A.D. 68.  Eleyi tumosi wipe Episteli keji si Timoteu ni a ti ko nigbati akoko otutu odun A.D. 67 nkase nile.

Lati inu akosile iwe yii, o dabi eni wipe, a mu Paulu wa sodo Nero ti a si gbo ejo re, lehin naa ni a sun igbejo re siwaju (2 Tim 4:17), sugbon o daju wipe o nreti ki won pe si igbejo eleekeji ati wipe o mo daju pe akoko ati lo re ti sunmo etile. (2 Tim 4:6).

IDI TI A FI KO IWE KEJI SI TIMOTEU


Paulu arugbo mo wipe laipe, ao pe oun lati fi aye yi sile, ki oun si duro niwaju Olorun ti oun ti sin pelu gbogbo otito inu.  Paulu nfe ki Timoteu pelu wa ni olotito ati olododo.  Ninu eredi ti Olorun ti o lagbara ju, nitorinaa, ikowe yi nkilo nipa idide awon asise, aiwabi-Olorun ati iyapa kuro ninu otito, sugbon bakanna, o ngba awon omolehin Oluwa niyanju lati duro sinsin ninu igbagbo, ki won di awon eko ti o ye kooro mu, eyi nipe, awon otito nipa Olorun ki won si je olooto nigbagbogbo ninu kikede tabi pipolongo ihinrere Jesu Kristi.  Ni oro miran; lati se ise iranse ti a fi le gbogbo iranse Olorun tooto lowo.
Eleyi ni oro iwaasu lati odo Olorun si olukuluku wa, sgbon o wa lati ipase gege bi imisi Paulu Aposteli bi Emi Mimo ti dari re ati Olorun Baba si fi aye gba a.  Ko si ohun elo eniyan eleran ara ti a leyan lati se akoso awon oro wonyi, nitori Paulu ti dojuko ohun gbogbo ti onigbagbo tabi iranse Olorun le fe dojuko ninu ise iranse.
Paulu mo ohun ti o tumosi ki eniyan ni iriri ijakule, o mo ohun ti o tumosi lati dojuko ewu tabi inunibibi, o mo ohun ti o tumosi lati dojuko awon ti won nyi otito ti o nwaasu re pada; O mo ohun ti o tumosi ki awon ti o f’ehin  ti ja’akule, o mo ohun ti o tumosi ki o dojuko iko oro (iku ajeri Kristi) ti ko le ye nigbakugba; sibe Paulu tun kigbe wipe “Awon nkan wonyi ko mi mi rara, sugbon emi ko ka emi mi si nkan rara bi ohun ti o sowon fun mi, ki emi ki o ba le fi ayo pari ire-ije mi ati ise iranse ti mo ti gba lodo Jesu Oluwa, lati ma rohin ihinrere ore ofe Olorun” (Ise. 2024).
Paulu tokasi orisi awon eniyan meedogbon (25) ninu episteli yi, awon miran nipa fifi iwuri fun won, ati awon miran ni o daruko pelu ibanuje okan, fun apeere, Dema ninu 2 Tim. 4:10.

Itokasi iya Timoteu ati iya iya re (1:5) ati bi won se mu Timoteu dagba ninu ife Olorun je ohun ti a ko gbodo gbe oju fo rara (3:14, 15).  Ninu 3:8, a daruko Janesi ati Jamberi gegebi alatako fun Mose.


PINPIN EPISTELI KEJI SI TIMOTEU


I           IFAYARAN NI AKOKO IDANWO………………………………………………….1:1 – 2:20
A         IDUPE FUN IGBAGBO TIMOTEU………………………………………………….1:1 – 5
B         RIRAN TIMOTEU LETI AWON OJUSE RE………………………………………...1:6 – 18
D         AWON IHUWASI IRANSE OLORUN OLOOTO…………………………………...2:1 – 26
            1.         SISO AWON OLUKO MIRAN DI OMOLEHIN…………………………….2:1 -2
            2.         OMO OGUN RERE TI O NI OKAN KAN…………………………………...2:3 – 5
            3.         AGBE TI O F’AYARAN……………………………………………………...2:6 – 13
            4.         ASISE TI O NI AAPON………………………………………………………2:14 – 19
            5.         OHUN ELO MIMO…………………………………………………………...2:20 – 23
            6.         IRANSE OLORUN GBODO JE ENI PELE………………………………….2:24 – 26

II         NI IFARADA NINU IDANWO OJO IWAJU………………………………………..3:1 – 4:23
A         EWU IGBE IKEHIN NSUNMO TOSI……………………………………………….3:1 – 17
            1.         IGBA EWU TI O’NBO……………………………………………………….3:1 – 9
            2.         DIDOJUKO IGBA EWU……………………………………………………..3:10 – 17
B         ASE LATI WAASU ORO NA………………………………………………………..4:1 – 5
D         IKU PAULU NSUNMO TOSI………………………………………………………..4:5 – 22
            1.         IRETI PAULU NINU IKU……………………………………………………4:6 – 8
            2.         IPO TI PAULU WA NI OGBA EWON………………………………………4:9 – 18
            3.         AWON IKINNI NI IPARI ORO PAULU…………………………………….4:19 – 22

EPISTELI SI TITU


Episteli si Titu yi ni ori meta, nitorinaa yio je ise ti o rorun lati joko ki a si ka iwe naa tan laisi ohun idiwo kankan.  Nigbati a tokasi ibere Episteli si Timoteu ninu eyi ti a ti tokasi irin ajo Paulu eyi ti o tele sise ewon re akoko ni ilu Romu.  O dabi eni pe Paulu tun se abewo miran si ilu Hellene ati agbegbe Asia, ti o si fi Timoteu sile nibe lati se itoni ati alabojuto ijo ti o wa ni Efesu.

Lehin naa ni Paulu lo si Krete pelu Titu eni ti o fi sile bakanna lati se itoni ati alabojuto ijo ti o wa nibe ati lati dojuko awon isele ti o ye fun ibawi nibe.  Laisi iyemeji Paulu pada lo si ile Hellene tabi Makedonia ati lati ihin ni o ti k’owe si Titu. (1:5).  Paulu ni l’okan lati ran Artenia tabi Tikiku lati wa gba ipo Titu, ki Titu le ni anfaani lati darapo mo Paulu ni ilu Nikapoli (3:12).  O dabi eni pe Paulu ni o dari Titu sinu ife Oluwa (1:4) boya o gbagbo ni ibere ise iranse Paulu, nitori a ri itokasi wipe o ba Paulu ati Barnabas wa si Jerusalemu fun ipade pelu awon Aposteli ni opin irin ajo ise iranse akoko (Gal. 2:1 – 3).  Titu pelu Paulu bakanna ninu irin ajo ise iranse eleeketa, ti Paulu siran lati ilu Efesu si ilu Korinti lati mu iroyin ipo ti ijo naa wa ati lati je ki Paulu mo bi won se t’ewogba iwe re akoko si awon ara Korinti (2 Korinti 2:12, 13;
8: 1 – 9;  9:1 – 5).

Titu se alabapade Aposteli Paulu laarin akoko ti a daruko ninu Ise 20:1 – 2 (2 Korinti 7:5 – 8).  Paulu ni idaniloju ni ipa ti Titu ni lati fi ogbon yanju awon oro, pelu okan ikaanu sibe, pelu awon ibeere nipa iyapa ti o wa laarin awon Kristieni.
Pelu idaniloju, Paulu fi si orun Titu lati fi ogbon see pelu suuru laarin awon isele ti o le.  Titu je keferi.

AKOKO TI AKO EPISTELI NAA SI TITU


A ko mo bi ijo ti se fidi mule nibe, sugbon awon idaniloju wa wipe, awon kristieni kan wa ti won tuka kaakiri ka gbogbo erekusu naa.  O dabi eni pe lara awon eniyan yi wa ni iyara oke ni ojo Pentekosti, awon ni won gbo iwaasu Peteru akoko nipa ihinrere ti won si mu iroyin rere naa pada to awon eniyan won lo (ise 2:11).  Pelu idaniloju, Paulu se abewo si ilu Krete lehin ihamo re akoko ni Ilu Romu (1:5) ati lehin eyi ni o k’owe si Titu.  A ko episteli yi ni kete ti a ko episteli akoko si Timoteu ni odun A.D. 66 Nitorinaa odun A.D 67 ni a ko Episteli yi si Titu.

IDI TI A FI KO EPISTELI SI TITU


Paulu lo lara oro okan lara won wooli tabi akewi ilu Krete lati se apejuwe ihuwasi won. (1:12) ati wipe apejuwe awon ara Krete yi je otito si awon akosile miran.  Titu ni opolopo wahala lati se idari awon ara Krete, oni wahala wipe ki won gboran si ase ati lati gbadura fun awon ti won sese yan si ipo le won lori ninu awon oran Pataki (3:1).
Paulu tenumo idi ti a fi nilo ise rere (1:16; 2:7 – 14, 3:1, 8, 14).  Laisiyemeji, ohun ti o fa eleyi ni nitori awon ohun ti awon ara Krete se alaini re ninu ihuwasi won.  A ko le so ni pato wipe, Paulu nsoro nipa igbala nipa awon ise, nitori o so gbangba wipe igbala maa nwa nipa oore-ofe Olorun ati nipase ise Emi mimo (3:5).

PINPIN EPISTELI SI TITU


I           YAN AWON ALAGBA……………………………………………………………….1:1 – 16
A         ORO AKOSO/AFIHAN………………………………………………………………..1:1 – 4
B         YAN AWON ALAGBA TI WON PE OJU OSUNWON……………………………..1:5 – 9
D         BA AWON OLUKO EKE WI…………………………………………………………1:10 – 16
II         MU OHUN GBOGBO BO SIPO………………………………………………………2:1 – 3:15
A         SO OHUN TI O YE SI EKO TI O YE KOORO……………………………………….2:1 – 15
B         MAA TOJU AWON ISE RERE……………………………………………………......3:1 – 11
D         IPARI…………………………………………………………………………………...3:12 – 15
EPISTELI SI FILEMONI


Ka iwe Efesu 2:1 – 6, 10
Episteli Paulu si Filemoni ni iwe Paulu ti o kereju lo ninu awon iwe re ti o wa ninu majemu titun.  Nitorinaa, ko je ohun wahala lati ka gbogbo iwe naa laisi idiwo rara.  Iwe je iwe kansoso ti o je iwe asiri to Paulu ko si enikan ti a fi pamo fun wa ninu majemu titun.  Iwe naa ni ese marundinlogbon, sugbon iniyelori iwe yi ni a ko le diwon re nipa bi o se gun to.  Eleyi je asiri ijinle ti emi.

AKOKO TI A KO EPISTELI NAA


A ko Episteli yi lati ilu Romu, o si pelu awon Episteli ti a pe ni awon Episteli ogba ewon, ti a tokasi ninu ifaara akoko ninu iwe si awon ara Efesu.  Ako iwe yi ni akoko kanna pelu iwe Kolosse, ati wipe Onesimu ba Tikiku pada wa nigbati o pada si ilu Kolosse.
A ko iwe yi si Filemoni eniti Paulu tokasi gegebi “Olufe owon” ati “Alabasisepo” sugbon o daruko awon miran bi: Affia ati Arkippu “Omo ogun egbe wa” o fi ikini ranse si “ijo ti o wa ninu ile re”.  Nitorinaa Episteli si Filemoni ni a ko ni Odun A.D. 60 tabi 61 Paulu si fi iwe naa ran Tikiku ati Onesimu eru ti o salo.

IDI TI A FI KO EPISTELI NAA


Onesimu, eniti o je koko eko Pataki ninu episteli yi, oje eru ti o salo.  O fi Filemoni oga re sile ti o si salo si ilu Romu.  Nibe ni o ti se alabapade pelu Paulu ti o si yi pada.  O dabi eni pe Onesimu ti gbo nipa oruko Paulu daradara nigbati awon onigbagbo ba npejo ninu ile Filemoni.  Eleyi le di ohun ti o faa ti o fi gbiyanju lati wa Paulu ri nigbati oun wa ni ilu Romu.

Bi Paulu se mo iniyelori ise Onesimu (vs 11,13) sibe, Paulu ko gbaa sodo laigba ase lati odo Filemoni.  Ni itesiwaju, o mo wipe labe ofin ile Romu, eru ti o ba sale le bo sinu iya nla ti won ko ba pa papa.  Lati inu eyi, bi eniyan, Paulu ni itara lati gba okunrin yi la, nitorinaa ni o se ran Onesimu pada pelu Tikiku eni ti yio se olulaja laarin Onesimu ati Filemoni.  Bakanna o fi iwe yi ran Onesimu, ninu eyi ti o so ohun ti o dara nipa eru ti o salo naa fun oga re, o si se eyi pelu ogbon Olorun.  Paulu kowe nipa idaniloju ti o ni wipe lati isinsiyi lo, pe Onesimu yio je eniti o se e gbekele ati eniti o lere pupo.

Ninu ebe Paulu, a kiyesi bi Paulu se tokasi si otito naa pe oun je “Paulu onde” (vs 1, 9, 10).  O tokasi otito miran wipe oun ni “Paulu Arugbo”.  Pelu idaniloju, Paulu ti to omo ogota odun  (60 yrs) ni akoko yi (vs 9).
Ni itesiwaju, kiyesi bi ni ese 19, Paulu ko se ileri lati se oniduro fun Onesimu nikan, sugbon o ran Filemoni leti wipe o je oun (Paulu) ni igbese igbala re.  O ro Filemoni lati mase gba Onesimu bi eru mo, sugbon bi arakunrin olufe.  Ninu iwe Kolosse 4:9 a fa Onesimu le ijo ti o wa ni Kolosse lowo lati so ohun gbogbo di mimo fun won, a sipe Onesimu ni “okan ninu yin” ati “Oloto ati arakunrin olufe” eleyi fihan wipe o ti di kristieni tooto.
            A mo sa, o tun wa fun iranti pe awon iwe aladani bi eleyi ko wa fun tito leseese.  Iwe yi fi ipo nla ti ihuwasi Paulu wa han, nitori ninu iwe kekere yi, o fi ara re han bi eniti ko ni imotara eni nikan, eniti o kun fun ife ati iwa pele.  O kowe si Filemoni ni ilu ti o jina rere ni Kolosse, ti o si nbebe gidigidi fun Onesimu, eru ti o salo, eniti Paulu gba gegebi omo re (vs 10) ati gegebi arakunrin olufe (vs 16).  Iru iwapele ati kikun fun oore ofe wo ni o fihan ni ese 17 nibiti, o ye ki o lo ipo ati ase re bi Aposteli, Paulu ba Filemoni da’moran pe bi Filemoni ba gba oun bi alabasise po ninu Oluwa, ki o gba Onesimu pada.  Itumo Onesimu ni ede Griki ni “Eni ti o wulo” tabi “Eni ti o lere” Paulu si farabale lo itumo oruko re yi.  Eru ti o salo je alaiwulo, sugbon eru ti ayipada le pada di eniti o wulo, ti Filemoni ba gba pada ninu okan ti o dara.  Gba pada ni ebe ti Paulu nbe Filemoni, “Ki I se bi eru mo, sugbon…….gegebi arakunrin Olufe” (vs 16).

PINPIN EPISTELI SI FILEMONI


I           ADURA IDUPE PAULU SI FILEMONI………………………………………………….1 – 7
II         ISIPE PAULU FUN ONESIMU…………………………………………………………...8 – 16
III        ILERI PAULU SI FILEMONI……………………………………………………………..17 – 25






ONK’OWE AWON IWE MAJEMU TITUN

ORUKO
ORILE EDE
ILU IBILE
ISE OWO
   IBASEPO
AWON ORI
AWON ESE
AWON IWE TI WON KO
MATTEU
OMO ILE JUU
KARPANAMU
AGBOWO ODE
APOSTELI JESU
      28
    1,071
IHINRERE TI MATTEU
MARKU
OMO BIBIILE JUU/ROMU
JERUSALEM
MISSIONARI
OMOLEHIN PETERU
    16
      678
IHINRERE TI MARKU
LUKU
HELLENE
ANTIOKU
ONISEGUN OYINBO
OMOLEHIN PAULU
    52
   2,158
IHINRERE TI LUKU, ISE AWON APOSTELI
JOHANNU
OMO BIBIILE JUU
BETHSAIDA TABI KAPARNAUMU

APEJA
APOSTELI JESU KRISTI
    50
   1,414
IHINRERE TI JOHANNU, EPISTELI KINNI, KEJI ATI EKETA TI JOHANNU ATI IWE IFIHAN
PAULU
OMO BIBIILE JUU
TARSU
SISE

ATI- BABA
APOSTELI JESU KRISTI
    87         (100)
   2,033       (2,336)
IWE ROMU,                TESSALONIKA
KORINTI KINNI         KINNI, IKEJI,
KORINTI KEJI,           IWE KINNI SI
GALATIA, IWE          TIMOTEU, IWE
EFESU, IWE                KEJI SI
FILIPPI, IWE               TIMOTEU, IWE
KOLOSSE, IWE           TITU (IWE
SI FILEMONI.              HEBERU).
JAKOBU/
JEMISI
OMO BIBIILE JUU
NAZARETI
GBENAGBENA
ARAKUNRIN JESU KRISTI
    5
     108
IWE JAKOBU/JEMISI
PETERU
OMO BIBIILE JUU
BETHSAIDA
APEJA
APOSTELI JESU KRISTI
    8
     166
EPISTELI KINNI ATI EKEJI PETERU
JUDA
OMO BIBIILE JUU
NAZARETI
GBENAGBENA
ARAKUNRIN JESU KRISTI
    1
      25
IWE JUDA









           
























AKOJOPO AWON EPISTELI EYITI PAULU KOO

IWE NAA
AWON ORI TI O NI
ENITI
O KO
KOKO ORO NINU IWE NAA
IBI TI A TI K’OWE
AKOKO TI
A KO IWE
AWON TI A KO IWE NAA SI
IWE ROMU
   16
PAULU
SISAN LEKUNRERE
KORINTI
A.D. 57
AWON OLUFE OLORUN NI ILU ROMU
IWE KORINTI KINNI
  16
PAULU
NINA AWON AYANFE
EFESU
A.D. 56
IJO OLORUN TI O WA NI KORINTI, A SO DI MIMO NINU KRISTI JESU.
IWE KORINTI KEJI
  13
PAULU
ALAYE NIPA APOSTELI
MAKEDONIA
A.D. 56
IJO OLORUN TI O WA NI KORINTI, GBOGBO AWON AYANFE JAKEJADO AKAIA.
IWE GALATIA
   6
PAULU
AINI IJANU
ANTIOKU
A.D. 53 - 56
IJO TI O WA NI GALATIA
IWE EFESU
   6
PAULU
KIKO AGO-ARA
ROMU
A.D. 60 – 61
AWON AYANFE NI ILU EFESU
IWE FILIPPI
   4
PAULU
BI A SE LE NI AYO NIPA IRELE
ROMU
A.D. 52
AWON AYANFE NINU KRISTI TI O WA NI FILLIPI
IWE KOLOSSE
   4
PAULU
OLORI OGUN
ROMU
A.D. 60 – 61
AWON AYANFE ATI AWON ARAKUNRIN OLOOTO NINU KRISTI TI O WA NI KOLOSSE
IWE KINNI SI TESSALONIKA
   5
PAULU
DIDURO LORI ILEPA
KORINTI
A.D. 51 – 52
IJO TI O WA NI TESSALONIKA
IWE KEJI SI TESSALONIKA
   3
PAULU
AWON OSISE TI WON NDURO
KORINTI
A.D. 52 – 53
IJO TI O WA NI TESSALONIKA
IWE KINNI SI TIMOTEU
   6
PAULU
IWE BI A TI SE OLORI
MAKEDONIA
A.D. 56
TIMOTEU, OMO MI TOOTO NINU IGBAGBO
IWE KEJI SI TIMOTEU
   4
PAULU
IWE IDOJUKO
ROMU
A.D. 67
TIMOTEU, OMO MI OLUFE
IWE SI TITU
   3
PAULU
IWE IHUWASI/ETO
KORINTI
A.D. 66 – 67
TITU OMO MI TOOTO NINU IGBAGBO KANNAA
IWE SI FILEMONI
   1
PAULU
IGBEKUN SI AWON ARAKUNRIN
ROMU
A.D. 60 - 61
FILEMONI ARAKUNRIN WA OLUFE


ONK’OWE AWON IWE MAJEMU TITUN


ORUKO
ORILE EDE
ILU IBILE
ISE OWO
   IBASEPO
AWON ORI
AWON ESE
AWON IWE TI WON KO
MATTEU
OMO ILE JUU
KARPANAMU
AGBOWO ODE
APOSTELI JESU
      28
    1,071
IHINRERE TI MATTEU
MARKU
OMO BIBI ILE JUU/ROMU
JERUSALEM
MISSIONARI
OMOLEHIN PETERU
    16
      678
IHINRERE TI MARKU
LUKU
HELLENE
ANTIOKU
ONISEGUN OYINBO
OMOLEHIN PAULU
    52
   2,158
IHINRERE TI LUKU, ISE AWON APOSTELI
JOHANNU
OMO BIBIILE JUU
BETHSAIDA TABI KAPARNAUMU

APEJA
APOSTELI JESU KRISTI
    50
   1,414
IHINRERE TI JOHANNU, EPISTELI KINNI, KEJI ATI EKETA TI JOHANNU ATI IWE IFIHAN
PAULU
OMO BIBIILE JUU
TARSU
SISE

ATI- BABA
APOSTELI JESU KRISTI
    87         (100)
   2,033       (2,336)
IWE ROMU,        
KORINTI  KINNI &  KEJI       
IWE GALATIA,
IWE  EFESU,
IWE FILIPPI,
IWE KOLOSSE
TESSALONIKA KINNI &  KEJI
TIMOTEU, KINNI &  KEJI, IWE TITU,
IWE SI FILEMONI.              (HEBERU).
JAKOBU/
JEMISI
OMO BIBI ILE JUU
NAZARETI
GBENAGBENA
ARAKUNRIN JESU KRISTI
    5
     108
IWE JAKOBU/JEMISI
PETERU
OMO BIBI ILE JUU
BETHSAIDA
APEJA
APOSTELI JESU KRISTI
    8
     166
EPISTELI KINNI ATI EKEJI PETERU
JUDA
OMO BIBI ILE JUU
NAZARETI
GBENAGBENA
ARAKUNRIN JESU KRISTI
    1
      25
IWE JUDA
AKOJOPO AWON EPISTELI EYITI PAULU KO


IWE NAA
AWON ORI TI O NI
ENITI
O KO
KOKO ORO NINU IWE NAA
IBI TI A TI K’OWE
AKOKO TI
A KO IWE
AWON TI A KO IWE NAA SI
IWE ROMU
   16
PAULU
SISAN LEKUNRERE
KORINTI
A.D. 57
AWON OLUFE OLORUN NI ILU ROMU
IWE KORINTI KINNI
  16
PAULU
NINA AWON AYANFE
EFESU
A.D. 56
IJO OLORUN TI O WA NI KORINTI, A SO DI MIMO NINU KRISTI JESU.
IWE KORINTI KEJI
  13
PAULU
ALAYE  NIPA ASE APOSTELI
MAKEDONIA
A.D. 56
IJO OLORUN TI O WA NI KORINTI, GBOGBO AWON AYANFE JAKEJADO AKAIA.
IWE GALATIA
   6
PAULU
AINI IKORA NI IJANU
ANTIOKU
A.D. 53 - 56
IJO TI O WA NI GALATIA
IWE EFESU
   6
PAULU
KIKO AGO-ARA
ROMU
A.D. 60 – 61
AWON AYANFE NI ILU EFESU
IWE FILIPPI
   4
PAULU
BI A SE LE NI AYO NIPA IRELE
ROMU
A.D. 52
AWON AYANFE NINU KRISTI TI O WA NI FILLIPI
IWE KOLOSSE
   4
PAULU
OLORI OGUN
ROMU
A.D. 60 – 61
AWON AYANFE ATI AWON ARAKUNRIN OLOOTO NINU KRISTI TI O WA NI KOLOSSE
TESSALONIKA KINI
   5
PAULU
DIDURO LORI ILEPA
KORINTI
A.D. 51 – 52
IJO TI O WA NI TESSALONIKA
IWE KEJI SI TESSALONIKA
   3
PAULU
AWON OSISE TI WON NDURO
KORINTI
A.D. 52 – 53
IJO TI O WA NI TESSALONIKA
IWE KINNI SI TIMOTEU
   6
PAULU
IWE BI A TI SE OLORI
MAKEDONIA
A.D. 56
TIMOTEU, OMO MI TOOTO NINU IGBAGBO
IWE KEJI SI TIMOTEU
   4
PAULU
IWE IDOJUKO
ROMU
A.D. 67
TIMOTEU, OMO MI OLUFE
IWE SI TITU
   3
PAULU
IWE IHUWASI/ETO
KORINTI
A.D. 66 – 67
TITU OMO MI TOOTO NINU IGBAGBO KANNAA
IWE SI FILEMONI
1
PAULU
IGBEKUN SI AWON ARAKUNRIN
ROMU
A.D. 60 - 61
FILEMONI ARAKUNRIN WA OLUFE




No comments: