Friday, July 3, 2015

KRISTI ATI ISE ETUTU



GROUND OF TRUTH BIBLE INSTITUTE
No1, Aboderin Street Agbaje Orita Challenge Ibadan
Website- www.groundoftruthbibleinstitute.blogspot.com
MOBILE: 08056008526 & 07031821386
HANDOUT
KRISTI ATI
ISE ETUTU


 
              BASIC MINISTERIAL TRAINING


KRISTI ATI ISE ETUTU

Eko kkiko: Matiu.1:18-25,Rom.3:23-26, 1 John 1:9
“Yio si bi omokunrin kan, Jesu ni iwo o pe oruko re; nitori on ni yio gba enia re la kuro ninu ese won. Matiu 1:21 (KJV)
IFAARA: Anilo lati ko ki a si loye iru eniti Kristi Jesu nse, ise re lori ile aye ati idi iku re lori agbelebu ni kalfari. Bi ohun nla kan tabi eredi ti o fi ta eje re sile yio ba jamo nkankan ninu aye wa.
Eese ti o fi wa, ti o ku lori igi agbelebu, ti o sita eje re sile, bi ise-etutu, kilode? Nitori wipe “gbogbo enia lo sa ti se, ti won si kuna ogo Olorun” ati pe ko si eniti o le rii tabi mu ogo wa fun Olorun ayafi bi a ba mu ese kuro (1 John.1:8-10) nitorina ni o fi pondandan fun un lati wa ati lati ku iku ti ko buyi kuni lati gba wa la kuro ninu iku ayeraye, nipa mimu ese kuro nipa idariji re, ti o si gba wa sile kuro ninu ide ese patapata, pe ki a ma ba sin ese mo.
“Jesu wipe, looto, looto ni mo wi fun yin, enikeni ti o ndese, oun ni eru ese”. Johannu.8:34 (KJV)
LILOYE ENITI JESU NSE

 Isa.7:14, Jh.1:21, Matt.16:16, Jh.4:25-26.
O se Pataki fun wa lati mo Olugbala okan wa yi, mase je ara Samaria (Jh. 4:22) ko kan gboruko Jesu lori bi eran araara, bikose fun eredi ati gba awon eniyan re la, (Heb.2:14-15, Gal.6:16) kuro lowo agbara ati ijegaba ese.
Ko si iyemeji ninu iru eniti Jesu nse, oun ni KRISTI (Matt.1:16, Jh.4:25-26). Ati rii kedere pe Jesu ni Kristi ti a npe ni Messiah. Olorun tikalarare lo wa ni aworan eniyan lati san gbese iran eniyan tabi gbese ti won je. (Isa.7:14, Rom.6:23).
WAHALA TI ESE DA SILE
Olorun da o lati gbadun ibasepo pelu re, sugbon ese mu iyapa wa. (Gen.3:1-6). Bawo ni ibasepo pelu re sele pada sipo? Ayafi ki a mu oun ti o fa iyapa kuro. Eniyan ko lagbara lati se ohunkohun nipa re (Rom.5:6) ayafi Olorun tikarare nikan soso lo le mu wahala naa kuro, eyi je idi Pataki ti o fi ran omo bibi re nikan soso ti o je aworan Olorun tikarare lati ku lori agbelebu, ati lati ta eje re sile fun irapada wa. (Jh.3:16-21)
ISE ETUTU
Ise etutu je dandan, nitori a gbodo setutu ese gbogbo.
Ise etutu tumo sipe ki a duro ni ona kan lati sipe fun asise tabi aisedede igba kan. (Rom.3:25) Ise etutu ti Jesu ti se nipa eje re mu idande ba gbogbo eniti o ba jewo ese re gbogbo ti o si ko won sile, lojukanna, a we nu ninu eje, o si di mimo, pelupelu o mura tan lati igbe-aye ododo gbogbo (1.Jh.1:9) eyi si seese nipa igbagbo.
IGBAGBO NINU EJE RE
Rom.3:24-25, Rom.5:1-2, Heb.11:5-6
Ise etutu (irubo etutu) di mimuse ati alagbara ninu eniyan kan, niwon igba ti oni igbagbo ninu eje Jesu pe, o we ese oun gbogbo nu ati pe iku Jesu lori agbelebu ti run ese (iseda) oun womu, womu. Gal.6:13-15
OJUTU (ONA ABAYO)
Olorun seto idande eniyan gbogbo kuro lowo agbara ati iseda Ese ti Esu mu wa ti o si gbin sinu eniyan, bere lati inu ogba Edeni. (Rom.5:12, Orin Dafidi.119:9). Idande yi ni o ran nipase omo re, Kristi Jesu, pe enikeni ti o ba gbaa gbo, ki o ma ba segbe, sugbon ki o le ni iye ainipekun.

   BAWO NI OLORUN TI SE?

Agbodo ta eje sile. Eks.12:3-7, Heb.9:12-14, 22; 1Pet.2:2-4.
Nigba ti Olorun seto lati ra Israeli pada kuro ni oko eru, odo aguntan kan ni a gbodo fi rubo ninu ile kookan (Eks.12:3).Eyi ni o ntoka si “Odo Aguntan Olorun” eyi ti yio wa nikeyin (Johannu.1:29) Olorun ko Israeli wipe ko le si idariji laisi itaje sile (Heb.9:23).
Niwon igba ti ofin Olorun ti duro wipe iku ni ere ese (Ezek.18:4, Rom.6:23) Jesu ti o je enikan soso ti ko dese ri ni o gbodo ku ki o ba le gba o la kuro lowo ese re ati nipa eje Jesu ki a ba le we o nu kuro ese re (1Johannu 1:7b; Ifihan 1:5).
         IDELARE NIPA EJE RE.         Rom.5:1-9

Idalare ni ona ti Olorun ngba lati kede eniyan elese gege bi Olododo, ese ikesan (9) so wipe a nda o lare nipa eje re: eyi ni ipe Olorun ninu idalare yi.
Ese akoko so wipe a dawa lare nipa igbagbo, eyi ni ipa tire ninu re ti a si gbodo wa aye fun bi a ti nkeko nipa ise asepo irubo nipa etutu eyi ti o mu itusile wa kuro lowo agbara ese fun enikonkan ti o ba gbogbo. “Nitori okan ni a fi ngbagbo si ododo ati pe enu ni a fi njewo si igbala” Rom.10:9. KJV
ITUSILE PATAPATA NIPASE ISE ETUTU
Rom.5:12, Rom.6:1-14, Gal.6:14-16, Col.1:12-14, Heb.11:5-6, 2Cor.5:17
Ti a ba n so nipa ododo, a je ajigbese patapata (Rom.3:23) sugbon Jesu wa lati tu o sile kuro ninu gbese re lori igi agbelebu. Gbogbo ododo RE ni o san sinu apo ifowopamo re (Filipi.1:9, 2Cor.5:21).
O mu wa kuro ni agbegbe ibi ti ese ti joba ati ibi ti iku si njoba. O siwa nipo pada sinu ijoba ayanfe omo re Jesu Kristi ni ibi ti ore ofe ti njoba si iye ainipekun (Kol.1:13) o mu oro iku kuro (1Cor.15:56) o si fun wa ni iye, gbogbo nkan wonyi ni o se lori agbelebu nipa eje re (Rom.5:9).
O mu itusile patapata wa kuro lowo agbara ati ipa ese nipase iku  re lori agbalebu ni kalfari, o je ise asepe, ki awa ki o ma ba sin ese mo (Jn.8:34, 1Jn.3:6-8).
O ja ijoba ati agbara kuro ni ara re, o si dojuti won  ni gbangba, o fi won sesin, o si yo ayo isegun lori won, o si tuwa sile kuro lowo ese. Nitorina, awon ti won mo. Ti won si ti se alabapade agbelebu Jesu Kristi. Won kii ma dese mo.
Awon ti won si n da ese won ko ti mo Jesu, beeni won ko si ti ri rara. (1Jh.3:6). Bi  enikeni ba si wa ninu ese ti o si wipe oun ni idapo pelu Kristi, Bibeli wipe opuro ni, (1Jh.1:6) iru eni be ti fi abuku kan emi ore-ofe.
“Nitori bi awa ba momo dese lehin igbati awa ba ti gba imo otito ko tun si ebo fun ese mo.
Bikose ireti idajo ti o ba ni leru, ati ti ibinu ti o muna, ti yio pa awon ota run. Enikeni ti o bagan ofin Mose, oku li aisi anu nipa eri eni meji tabi meta.
Melemelo ni e ro pe a o je Oluwa re ni iya kikan, eniti o ti te Omo Olorun mole ti o si ti ka eje majemu ti a fi so di mimo si ohun aimo, ti o si ti kegan Emi ore-ofe” Heb.10:26-29 KJV
“Olododo yio ye Nipa Igbagbo”… Nitori Owa Laaye.

No comments: