EMI – MIMO NINU IJERE OKAN
ITOKASI
TANI EMI MIMO? O dara lati mo iru eni ti Emi mimo je, ki o to dip e a lo sinu ekunrere ojuse re ninu ijere-okan. Bibeli je ki o ye w ape, emi mimo ni eni keta ni orun “1 John 5:7……so pe” Awon meta ni njeri ni orun, Baba Omo ati Emi-mimo”…………Awon meteta yi je okan……..
1 John 5:7
Baba naa, omo ati Emi mimo je okan ti ko se pin niya, iyen nipe ibi ti Baba ba wa, omo wa nibe Emi-mimo papa wa nibe.
AWON OJUSE EMI MIMO FUN RA RE
1. Emi-mimo ma nja Gen. 6:3 nigba ti o ba fed a ese lebi ninu aye awon Eniyan re.
2. Emi-mimo maa nkoni Jh 14:26 Emi mimo ni oluko ti o dara ju, o ma nkoni. O si ma nran ni leti awon ohun ti a ti ko.
3. Emi-mimo maa njeri si Jh 15:26
4. Emi-mimo maa ntoni Jh 16:14 Rom 8:14
5. Emi-mimo maa nfi oye yeni Jh 16:8
6. Emi-mimo nran ni lowo Rm 8:26a
7. Emi-mimo maa ntuni ninu Jh 16:7
8. Emi-mimo maa nbebe fun wa Rm 8:26b
9. Emi-mimo maa nwa inu okan 1 Kor 2:10
10. Emi-mimo maa nsoni di mimo Rm 15:16
11. Emi-mimo maa npase Act 16:6 – 7
12. Emi-mimo maa njeri Rm 8:16
AWON ORUKO EMI – MIMO
1. Emi – Olorun 1 Kor 2:10 – 14
2. Emi – Kristi Jh 15:26
3. Emi – Mimo naa
4. Emi – Olutunu naa Jh 14:15 – 20; 26
5. Emi – Ileri naa Lk 24:49, Jh 14:17, Joel 2:28, Gal 3:14
6. Emi – Otito naa 1 Jh 5:6, 1 Jh 4:6, Jh 14:17, 14:6
7. Emi – Iye naa Rom 8:2, Rev. 11:11
8. Emi – Ore Ofe naa Heb 10:29, Zekah 12:10
9. Emi – Isodomo naa Rom 8:15
AWON OHUN TI O NSAPERE EMI – MIMO
1. INA – Heb 12:24 , Jer 20:9, Isa 4:4, Matt 3:11 , Lk 3:16
2. AFEFE – Jh 3:8, Ezek 39:7 – 10, Act 2:2
3. OMI – Jh 7:37, A nlo apere Omo, Ojo ati iri lati fi se apere iwa laye Olorun.
4. EDIDI – Efe 1:13, II Timo 2:19 A nlo edidi lati fi se ami (a) Oni nkan (b)
ojulowo ati ase (d) Aabo
5. ORORO – 1 Sam 10:1, Ex 40:9, 15, Lef 8:12, Ps 92:10
6. ADABA – Adaba nfihan (i) iwa pele (ii) Iwa – tutu (iii) funfun (iv) Alaafia (v) Ni ni
AWON OJUSE EMI – MIMO NINU IJERE OKAN
Emi mimo ma nko ipa Pataki nini ise iwaasu ihin rere laisi Emi – mimo, a ko le jere okan fun Krisit, laisi Emi-mimo gbogbo laala Ajere okan ni yoo jasi asan.
Apeja Eniyan ti o lo pelu iwo , okun opa, ati pelu ije sugbon ti o gbagbe Olofofo si’le gbogbo akitiyan re lati mu eja yio jasi asan. Be gege ni Ajere okan ti o mura iwasu to dara pelu Bibeli to dara, ti o si jade lo lati fi Kristi ninu Olorun han fun awon Eniyan, laisi Emi-mimo, gbogbo laala re asan ni.
AWON OJUSE EMI – MIMO NINU IWASU IHINRERE NI WONYI
1. Emi – mimo ni agbara ajere okan
2. Emi – mimo maa nran ajere okan lowo
3. Emi – mimo nfun ni ni oye oro Olorun
4. Emi – mimo yio ran asese gbagbo lowo lati gbe igbe aye mimo
5. Emi – mimo nran asese gbagbo lowo lati gba ife Olorun
6. Emi – mimo nran asese gbagbo lowo lati ni imo ti o kun ninu Olorun
7. Emi – mimo nso asese gbagbo di mimo, ninu emi, okan ati ara 1 Thess 5:23
8. Emi – mimo yio ma jeri si ohun ti Ajere okan nso ninu aye asese gbagbo
9. Emi – mimo yio ran asese gbagbo ati Ajere okan lowo lati dagbe ninu igbagbo
10. Emi – mimo yio to Ajere okan ni igbese ti o kan
11. Emi – mimo yio ma ma ran asese gbagbo ati Ajere okan lowo lati la iponju ati ijiya koja Heb 12:6 – 7
12. Emi – mimo yio ran ajere okan lowo lati gbo ohun Oluwa nigba ati o ba npe
13. Emi – mimo ki yio gba asese gbagbo ati ajere okan laaye lati ni ife aye (nitori pe a ma fun won ni ami ni gbogbo igba) 1 Jh 2:14 – 17
14. Emi – mimo yio ma ko yio sit un to ajere okan eyi ti asese gbagbo bi eniyan se le dagba nipa tara ati temi
15. Emi – mimo yio ran asese gbagbo ati ajere okan lowo lati ya ara won soto fun Olorun.
16. Emi – mimo yio ran won lowo lati gboju won si ohun ti orun.
EMI MIMO NINU ISEDA
Emi – mimo ni eni iketa ninu metalokan, nipase agbara re ni a fid a aye, Emi Olorun si nrababa loju omi ti o si gba ogo iseda Gen. 1:2, Jobu 26:13, Ps 33:6, 104:30
Emi mimo gege bi Enikan fi iwa laye re han ninu gbogbo Eda, nipaa ohun ti a npe ni ofin eda.
Oun (Emi mimo) ni liana ti a ntele ati igbe aye Agbara ti o nseto iseda gbogbo ipa ti o wa ninu iseda je Eri iwalaye Eniyan Gen. 2:7, Job:33:4 gbogbo eniyan boya o sin Olorun tabi ko sin ni o wa laaye nipa agbara ti iseda ti Emi Olorun Dan 5:23, Act 17:28
Ninu igbe aye majemu laelae Emi mimo ru awon eniyan kan soke lati sakoso ati lati dari awon omo ijoba na ati lati bojuto itesiwaju igbe aye ifara eni ji won.
Ise agbara Emi – mimo pese orisi iranse meji
(1) Awon Osise fun Olorun (2) Awon Agbenuso fun Olorun
AWON OSISE FUN OLORUN:- Awon eniyan Pataki a ni iru awon apeere awon osise fun Olorun ti Emi – mimo ti kun inu won, awon bii (1) Josefu Gen 34:40 – 43 (2) Bezalee; Eks 35:30 – 31 (3) Mose Num 11:16 – 17 (4) Josua Num 27:18 – 21 (5) Othniel Judg 3 – 10 (6) Gideon Judg 6:34 (7) Jefta Judg 11:29 (8) Samsoni Judg 13:24 – 25 (9) Saulu 1 Sam 10:6.
AWON AGBENUSO FUN OLORUN:- Awon agbenuso fun Olorun je awon eniyan ti o le, ti won duro sinsin ati awon eniyan ti ko dap o mo aisoto. Awon wonyi ni awon eniyan ti Emi mimo mi si lati je ohun Oluwa….. Won je awon eniyan ti Olorun pe ti o si ran nise. Bibeli wipe “Eniti Oluwa pe, ti o si ran, a ma soro Olorun oun ni a si fun ni Emi laini Osuwon…….” Opo awon oluko ti won ngba oro lati odo Olorun ti won sin so fun awon eniyan, Esek 8:1 – 3 Awon woli gege bi Esekiel, Jeremiah, Isaiah, Daniel, ati awon woli kekere.
DAFIDI ATI EMI – MIMO: Dafidi je oba ni ile Israeli o si da ojuse Emi Mimo mo ninu aye eniyan kan . Olorun pe Dafidi ni Eni bi okan oun nitori pe o ma nda emi mimo ati ise re mo ninu gbogbo isele.
Dafidi mo wipe Emi – mimo wa ni ibi gbogbo, o si nsise awari awon ona eniyan, o sin tan imole Olorun sinu okunkun aye Eniyan. Lehin ti o da ese nla o gbadura pe ki Emi Olorun, iwaleye Olorun, Emi ti o ntun iwa se ki o ma se fi oun sile Ps. 51:11.
EMI – MIMO NINU IJERE OKAN: Emi – mimo ti wa ni enu ise lati igba aye awon Aposteli. Isokale Emi mimo yi je imuse ileri Jesu Kristi fun awon omo ehin re pe “Emi yio si gbadura si Baba, yi o si fun yin ni Olutunu mirran, ti yio le ma ba yin gbe titi, A ni Emi otito ni, Eni ti Aye ko le gba nitori ti won kori beni won ko si mo, sugbon eyin mo, nitori ti o ba yin gbe, ati pe yio si wa pelu yin”. Jh 14:16 – 17
Imuse ileri yi farahan ni ojo penticosti nigbati awon omo ehin pejo ni iyara oke gege bi igboran si ase Jesu Kristi Oluwa.
“Nigba ti ojo penticosti si de gbogbo won si fi okan kan wa ni ibi kan …. Lojiji iro si dun lati orun gege bi iro efufu lile o si un gbogbo ile ni ibi ti won gbe joko si…….Ela ahon bi ti ina sib a le eni kookan won”…….Act 2:1 – 4.
Nibi ni awon Aposteli ni iriri baptisimu meji ni ekan soso, be ni Emi – mimo si bere ise re ni aye won.
1. Baptisimu ti Emi – mimo – igbe aye ti o kun fun Emi – mimo
2. Baptisimu ti ina – igbe aye ti a sun.
PETERU ATI EMI MIMO NINU IJERE OKAN:- Ni bii ogoorun mejo odun seyin siwaju ibi Kristi ni wole joel ti soro nipa wiwa Emi – mimo pelu awon ede wonyii “yi o si se ni ojo ikehin, Emi yoo tu emi mi jade sara eniyan gbogbo ati awon omo yin okunrin ati awon omo yin obinrin yio ma so tele, awon arugbo yin yio ma la ala, awon odo’mokunrin yio ma ri ran ati pelu si ara awon omo odo okunrin ati si ara awon omo odo obinrin ni emi o tun Emi mi jade ni ojo wonni” Joel 2:28 – 29 Ni ojo penticost ni Peteru salaye oro yi ti a ti enu woli Joeli so. Peteru wa soro pelu igboya bayi, nitoripe Emi mimo ti yi aye re pada sir ere o si ti gba Agbara oro naa nipase Agbara Emi mimo. Peteru eni ti o je ojo nigbati won nse idajo Jesu Kristi, Eni ti o se Olugbala nitori ti Emi-mimo ko ti bere ise. O so pe “Bi o tile je ati’ku Emi yi o ba ku” nigba ti awon eniyan si nwa Jesu Oluwa lati mu, “Peteru eni ti o ni ida si fa yo o si be omo Odo Olori Alufa ni Eti Otun re so nu. Oruko iranse na a si ma je Makusi……..Ni gba naa ni Jesu wi fun Peteru pe, te ida re bo inu ako re, ago ti Baba fi fun mi Emi o se Alaimu bi? Jh 18:10 – 11.
Nigba naa Peteru ko le se ohun kohun nitori o gbekele Agbara ida re. Lehin naa Peteru se Oluwa nigba meta ki akuko ki o to ko, lehin naa o wa sun ekun kikoro (ironupiwada pelu okan ibanuje Lk 22:54 -62, Jh 18:19 – 27
Lehin Ajinde, Jesu Krisiti Olutunu ileri Emi-mimo se “kiyesi Emi nran ileri Baba si yin sugbon e duro ni Jerusalem titi ti a fi fi agbara wo yin lati oke……………A o si fi Emi mimo baptisi yin, ki ise ojo pupo lati oni lo”……Eyin yio gba Agbara nigba ti Emi-mimo ba ba lee yin…..ileri na si wa si imuse ni ojo ti penticost de. “Gbogbo won si fi okan kan wa ni ibi kan (Iyara oke) Lojiji iro si ti orun wa bi ti efufu lile o si kun gbogbo ile nibi ti won gbe joko, ela ahon bii ti ina si yo si won…….. gbogbo won si kun fun Emi-mimo won si bere si fie de miran soro gege bi Emi-mimo ti fun won ni ohun” Act 2:1 – 4.
Peteru eni ti o ti pada si ise re atijo wa di eni ti o nfi igboya soro bayi nitori pe Agbara Emi-mimo ti yi aye re pada. O bere iwasu re akoko, eyi ti o gba opolopo okan la fun Jesu pelu Agbara Emi-mimo, O si ilekun ise iyanu pelu Agbara Emi-mimo ni enu-ona tempili daradara. Emi-mimo ni agbara ti a nilo pupo ninu ijere okan.
NI IPARI
Emi-mimo ni asoju ti o dara julo ninu ise ijere okan Awon ajihinrere akoko se aseyori ninu ise ijere okan won pelu Agbara Emi-mimo. Nitori idi eyi, o dara fun o lati je Ajere okan ti o dara, o gbodo kun fun, ki o si gba idari ki a si baptisi re ati ki o si maa gbe ninu Emi-mimo ni gbogbo igba.
No comments:
Post a Comment