Sunday, June 25, 2017

AWON ILANA ATI FIFI ISE OJISE SI ISE

GROUND OF TRUTH BIBLE INSTITUTE
   NO 1, ABODERIN STREET AGBAJE ORITA CHALLENGE IBADAN OYO STATE NIGERIA
Tel: 08056008526

                                           HANDOUT
AWON ILANA ATI FIFI ISE OJISE SI ISE

    

    
   
   ADVANCED CHRISTIAN LEADERSHIP (100 LEVEL)
           
AWON ILANA ATI FIFI ISE OJISE SI ISE

ITOKASI ISE OJISE OLUWA


Ise iranse ni lati jade lo pelu ete kan. Ise iranse si tun je ona kan soso ti Jesu Oluwa seto re lati le mu eto re se. laisi iran ko le si ise iranse, ati wipe laisi ise iranse, ko le si Ojise.

TANI OJISE OLUWA?

1.  Ojise je enikan ti a pe jade pelu ete kan.
1.   Ojise tun je enikan ti a ran.

Oro yi OJISE wa lati inu ede Latini, eyi si ni MITTO ti o tumo si lati ran nise.
Oun na ni a si tun npe ni “APOSTELLO” ni ede Greek ti o tumo si “Lati ran nise”. Aposteli ni iranse pataki fun Jesu Kristi. Enikan ti Jesu fi ase fun lori awon ise kan.

Oro ti a pe ni APOSTELI ni a lo fun awon omo eyin ti Jesu ran jade ni meji-meji ni akoko ise iranse re ni Galili lati mu ki ise iwasu ati imularada re gbooro sii. Ni asiko yi ni a koko pe won ni Aposteli MK.3:14; 6:30.

 Oniruuru Aposteli ni o wa gege bii: Jesu - Olori awon Aposteli eni ti Baba re ti o nbe ni orun ran. Ise iranse re ni lati ra iran eniyan pada. O si se aseyori ninu irin ajo ise iranse re sinu aye yi ati wipe ki ise na ba le tesiwaju leyin re, o yan awon mejila o si so won ni Aposteli fun ise iranse ti gbogbo aye.

Ise ijo ti o tobi ju ni ise iwasu ihinrere si gbogbo aye. Nitori nigba ti Olorun feran, o feran gbogbo aye. Nigba ti yio si tun fi omo re tore, o fi tore fun gbogbo aye, ani omo re, nigba ti Jesu pelu yio ku, o ku fun gbogbo aye. Iran Olorun je iran ti gbogbo aye. Eyi na si ni iran ti O fe ki a ni.



                        IDI TI A FI YAN AWON MEJILA



1.        Ki o ba le ko won
2.        Ki o ba le da won leko.
3.        Lati kun won pelu agbara.
4.        Lati ran won jade lati so orile ede gbogbo di omoleyin (Matt.28:18-20)

Ibasepo ati idi ti o fi yan awon Aposteli ni a so ninu iwe (Jon. 20:21)
Awon Aposteli meta miran nbe ti won ko pelu awon omo eyin mejila, awon bii; PAULU, TIMOTEU ATI BARNABA.
ORISIRISI AWON APOSTELI

1.   Olori Aposteli Jesu Kristi.
2.     Awon Aposteli mejila ti odo Aguntan.
2.        Awon Aposteli leyin igbasoke.
3.        Awon ti won ni iru ise iranse Aposteli.

Bi o tile je wipe awon kan jiyan wipe leyin awon Aposteli Jesu iyen ni awon mejila, ko tun si awon Aposteli mo. Sugbon, gege bi iwe Efesu 4:10-13 ti so. Bibeli fi idi re mule wipe Jesu si ntesiwaju lati maa funni ni ipo yi titi ti ijo yio fi je eyi ti a se pe.
       BAWO NI A SE NYAN WON?

1.             Lati owo Emi Mimo. Ise A.A.13: 4.
2.             Lati owo Ijo Ise A.A.13: 3

Ki enikeni to le jade lo fun ise iranse, o gbodo je eni ti Olorun ti pe, ti ijo si ti da mo, eyi ni pe ti ijo mo nipa ipe ati ise pataki ti o nlo se, ti won si gbadura fun pelu igbowole.

Awon Aposteli ko wa fun lati duro si oju kan, sugbon, won a maa lo kaakiri sibi ti Emi Mimo ba dari won si lati lo. Ise A.A.8:26,29,39 ati 16:6-7. Oro ti a pe ni Ojise ni oseese ki a ma ri ninu Bibeli, sugbon ise Iran jade ni a le ri ninu Lk. 6:13;2Kor.13
 


ORISI AWON OJISE MEJI.

1.             Ojise ni ile wa.
2.             Ojise ni ile okeere.

Bi ojise ile wa ba wa, a je wipe  ise nbe ni ile wa lati se fun won. Bakan na ni, ki a to yan Ojise si ile okeere, oje wipe ise kan wa fun won ni ile okeere lati se ni. Olorun npe awon Ojise nigba kugba ti aini ba wa fun un.

Oye ki igbimo awon Ojise wa ni Ijo agbegbe kan. Awon Igbimo meji ni o se pataki ti o ye ki Ijo ti o nran Ojise jade ni.

1.             Igbimo Ojise agbegbe wa.
2.             Igbimo Ojise ti ile okeere.

Gbogbo awon Igbimo wonyi ni won ni ise won ni Orisirisi ona. Awon Igbimo Ojise agbegbe nsise po pelu awon Ojise ti agbegbe won. Igbimo Ojise ti ile okeere nsise pelu awon Ojise ti won nlo koja asa ati orile ede won lati se ise iranse. Nitori idi eyi, o je ise awon Igbimo wonyi lati seto fun awon ebi won ati ohun gbogbo ti won yio nilo.
IPE ATI ITONI RE (Ise A.A.16:6-10).

1.             Ipe sinu ise ihinrere ati itoni re ni nkan lati se papo pelu ibi ti a o ti se ise na, se nile ni tabi ni oke okun?

2.             Ipe Olorun ma nwa leekan ninu aye eniyan. Nigba ti o ba ti ye ni, ti eniyan si se igboran si, Olorun ko ni tun pe mo. Sugbon ailoye tabi aigboran le fa ki Olorun tun ipe eniyan se, sugbon Olorun a ma pe eniyan leekan.

3.             Itoni nilo titi ojo aye eniyan. Itoni gege bi wipe ‘Ibo ni Olorun ti fe ki o bere ise na, ati wipe bawo ni yio se je eyi ti a se Yanju?’ Nitori idi eyi, eniyan nilo itoni Olorun ki o ba le mo iru ise iranse eyi ti eniyan nlo lati se, boya ni ile ni tabi ni ile okeere.

Lati sise tabi ise iranse kan ti o ti wa, tabi lati da duro, tabi iru asa wo ni. Paulu ni a ran si awon keferi nigbati a ran Peteru si awon Juu. Galatia 2:7-8.
 


            AWON AMUYE OJISE OLUWA



1.             Ogbdo je onigbagbo ti o ti di atunbi.
2.             Ogbodo ni oye kikun ninu oro Olorun, ki o si je eni oro na.
3.             Ogbodo ye nipa ti emi.
4.             Ogbodo je eni ti o ni igboya mimo.
5.             Ogbodo ye nipa ti ara, ki o ma ba mu oro odi ba oruko Kristi.
6.             Ogbodo ye nipa ti eko iwe.
7.             Ogbodo ye nipa ti itara ati ti opolo.
8.             Ogbodo ni ohun (ede) ti o ja gaara.
9.             Ogbodo ni oyaya pelu awon eniyan, nitori awon eniyan ni a ran si.                     
10.         O gbodo le teriba fun awon asaju re, ki o si le fun won ni abo kikun

             IPELE META TI AWON OJISE


1.     OJISE TI ANYIRI WO: Awon wonyi ni aran lati lose ise naa wo lenu eko won, gege bi oluko ti ma nse ikoni ni enu eko won

2.        AWON OJISE OJEWEWE: Awon wonyi sese teri gba ise ojise ni, awon ni won nse labe ojise agba ti ma nse alaye fun won.

3.        AWON OJISE AGBA: Awon wonyi ni awon agba nipa iriri, won ti pe lenu ise na, bi o tile je wipe awon ko ri enikan ni iwaju lati bere oro, sibe won si keko lati inu isubu won, awon ni ojise nipa iriri.


 AWON OJUSE ATI ILEPA OJISE OLUWA

ITOKASI:
 Opolopo ogbon lowa ti a le fi se ise ojise, sugbon ilepa kan soso na ni igbala awon okan.

ISE ATI ILEPA:
Ilepa ni o nmu awon ise sise wa.

1.               Iwasu ihinrere.
2.               Itopase – eyi ni ogbon idanileko.
3.               Isonidi omoeyin – eyi ni ogbon idanileko.
4.               Ijo gbingbin.
5.               Sise eto bi a o se ma se isin (Liturgy)

 IWASU IHINRERE NI ONA META

1.             Iwasu enikan si enikan: Bi eniyan ba mu ijere okan enikan si enikan, isoro re gbodo ba asa won mu, bikose be iwasu ihinrere yio dabi esin ajoji leti won.

2.             Ipade ita gbangba: Ti a ba ni anfani lati fi ara han ni ibi ipada ita gbangba pelu oro ti o dara, gbogbo agbegbe ni o le gba igbarukuti lati teti si o. Tabi ti o ba ni enikan ni agbegbe na ti o le duro bi alarina, won yio wa sodo Jesu Kristi.


3.             Iwasu ti elegbe tabi opo ero: O le se eleyi leyin ti o ba ti se aseyori ninu meji ti oke yi, eketa yi ni a npe ni isoji ita gbangba. Oro ti a npe ni isoji (Crusade) tumo si ogun mimo.





        
        AWON IRINSE IWASU IHINRERE


1.   Igbe aye Ojise Oluwa.
2.   Oro ti a so jade – Eyi ni ona ibanisoro nla fun ise iranse re.
3.   Oro ti a ko sile, bii iwe kiko tabi iwe pelebe ijere okan.
4.   Awon ohun elo ikoni ti a n wo bii: Iwe lile mo ogiri tabi kalenda.
5.   Awon ohun elo ikoni ti onsoro bii: Redio tabi ero igba ohun sile. Etc.
6.   Awon ohun elo ikoni ti ohun ati aworan bii: Ero sinima, amohun maworan, ere ori itage.

AWON ISORO TI OJISE OLUWA NDOJU KO

ITOKASI; Ise iranse ode oni yato si bi o se ri ni nkan bi adota odun seyin. Sibe, awon ti igba na si ni asiwaju ni ori papa nibi ti a ti nilo awon akoni nla, ati ti inunibini si je ipin won. Iyiriwo ko iti di eyi ti a dana sun, ti iponju si tun je ipin awon ti won nteri gba ise na.

McKay ti Uganda wipe “Mo fe ran eyin Igbimo leti wipe larin osu mefa si igba yi, o seese ki e dede gbo lojiji wipe okan ninu wa ku. Ikan ninu wa, paapa ole je emi ni yio subu ki o to to akoko na. Sugbon ohun ti mo fe so niyi: nigba ti iroyin naa ba de, e mase dori kodo, sugbon eran elomiran lesekese lati wo di alafo ti o si sile naa “.

Oro aso siwaju yi si papa se, nitori ni okokan ejeji ni awon omo egbe McKay bere si ku, awon miran ku iku aisan iba, won si pa awon miran lati owo awon omo ilu, nigba ti o ya oseku oun nikan leyin.

Kilofa ti iponju ko fi kuro ninu oro ise iranse?, gbo ohun ti David Brainerd so si oro na, “Emi niyi, Oluwa, ran mi, ranmi lo si opin aye, ran mi lo si ibi ti o buru, ran mi lo si ibi aginju, ran mi lo kuro ninu itunu inu aye, ranmi si iku gangan funrare, bi o ba sa ti je ninu isin re ati lati gbe ijoba re ga” 
Sibe, tun teti si Francis Zavier: “Sibe sii Oluwa mi, igba ti o le sii, irora sii, iponju sii, fun Oluwa.
Eyi ni oro C.T. Studd: “Ti Jesu ba je Oluwa ti o si ku fun mi, a je wipe ko si irubo ti o tobi ju fun mi lati ru fun un.”
David Livingston ni o kede pe, “Iku paapa le yo ayo isegun, nitori iku je isele ti o logo fun eni na ti o nlo sodo Jesu”.
    ALAFO ASA NTESIWAJU LATI EO SI E3

Ajihinrere ati Ojise Oluwa ni ojuse lati so iwasu igbala ti Jesu ti o ba Bibeli mu ni aso yeke- yeke koja ibode asa.

Lati se eyi, won gbodo ni oye ti o jinle nipa asa, ki won si fi idi ilana gbigbo mule. Iru iranse onigbagbo be nilo lati ko bi a ti so asoye nipa Kristi fun awon olugbo ni ona ti ero okan won ati ede ti o ye won.

Gbigbo lati inu ero, ogbon sise ipinnu, ise ati ona idahun si nkan, ati iwoye ti aye.
Ojuse Ajihinrere ati Ojise ni lati ran otito ti o ju asa lo ti Bibeli si eniyan ti o nbe labe ide ti asa.

Bibeli je otito to ju asa lo, ti o koja lati inu asa Eberu ati ti Giriki ti a si tumo fun wa ninu asa awon Geesi  ti awa na si gba lati inu asa tiwa pelu.
             IRUSOKE FUN ISE IRANSE

A nilo lati ru awon eniyan soke fun ise iranse. Bi a ko ba ru won soke, ko ni si ise iranse. Nitori Olorun nyan Oluso Aguntan lati inu awon Aguntan.

  KINI AWON OHUN TO YE KI O RU WA SOKE FUN ISE NA :

1.         Ase  Olorun – Matt. 28:19-20.
2.         Adura          -  Matt. 9:36-38.
3.         Igbaniyanju awon agbaniniyanju ti Olorun. Owe 13:10.
4.         Igbe aye awon ojise ti o je ti Olorun.    Heb.13:7.
5.         Eko Kristi ati igbe aye Paulu.
6.         Ere ti o wa fun igboran.    2Kor.5:10.
7.         Ileri Olorun       Matt.4:19.
8.         Idaniloju wipe Kristi yo ko ijo re, ko si si agbara okunkun ti yo le bori re.  Matt.16:18.
9.         Ileri Olorun wipe oun yo pelu wa, ran wa lowo, to wa, dabobowa ati lati fun wa ni Emi re.   Lk.11:13.
10.     Wipe ija na kii se tiwa, sugbon ti Oluwa ni.   Isaiah 17:47.
11.     Ilakaka sii lati dabi Jesu, gege bi Baba ti ran mi, beni Emi pelu ran yin.  Jn.20:21
                          
          AWON ISORO:



1.       Igbarukuti Rom. 10:14- 16
2.       Ibanisoro Ise A.A. 10; Matt.10:5-6.
IGBARUKUTI

1.        Igbarukuti lati odo Olorun.
2.        Iranlowo ijo.
            [a]  Fun awon ti o njade lo.
[b]  Fun ebi ti won fi sile nile.   Eks.19:17-25.
      Eyi ni ojuse ijo ti o nran ni jade;

     
IBANISORO


 1.   EO-  Oniwasu si awon eniyan ti oni  - i.  Ede kan na
                                                                    ii  Asa kan na
                                                   iii. Igbagbo kan Sugbon ti won ko di atunbi.

2. - E1- Oniwasu si awon eniyan ti oni - i. Ede kan na.    
                                                            ii. Asa kan na . 
                                   iii   Igbagbo ti oyato Sugbon ti won ko di atunbi.

3. - E2  - Oniwasu si awon eniyan ti oni - i. Ede kan na.
                                                                 ii  Asa ti o yato
                                            iii. Igbagbo ti o yato Sugbon ti won ko di atunbi.

4 - E3   - Oniwasu si awon eniyan ti oni - i. Ede ti o yato
                                                  ii  Asa ti o yato
                               iii. Igbagbo ti o yato Sugbon ti won ko di atunbi

Jesu soro ninu iwe Ise A.A.1:18 pe eyin yio se eleri mi ni Jerusalem, Judea ,Samaria ati titi de opin aye.
                                   


No comments: