ISAKOSO
IJO
ORO AKOSO;
Isakoso ijo je ise kan ti a gbodo farabale dojuko pelu ikiyesara lati le yago
fun arifin tabi sise lodi
si eni ti o ko ijo. Jesu funrare kede re
pe ohun yoo ko ijo ohun (Matt16: 18) Oro yi fi yewa pe Jesu ni olusakoso agba fun ijo.
Ijo gege bi o ti je , o je awujo awon eniyan ti a “pe
jade” O je apejopo awon onigbagbo ti
a ti fi eje we ninu Jesu Kristi Oluwa wa .Ti awon eniyan ti a ti fi eje we ko
ba pejo papo lati josin fun Olorun ,boya iba ma ti si iwulo sise adari, ipejopo awon onigbagbo ti a npe ni kritieni fi aye gba Isakoso. Ifihan
isakoso yi ni o bi ise adari eyi to se bojuto ni ona to munadoko.
Niigba ti a ti fi idi re mule pe Jesu ni o ko Ijo Re,
nitorina, Isakoso iru Ijo bee gbodo wa ni ilana ati irufe eyi ti o maa nlo, bi
a ti ko loju oju iwe majemu titun, pataki julo ninu awon iwe ihinrere. 1kor.
12: 4 – 6 gbe awon ipa kan
kale ninu ijo eyi ti Baba, Omo ati Emi Mimo maa n mojuto.
Awon ebun wa ni ikawo emi mimo, baba ni alakoso tabi
alabojuto awon ise, Jesu Kristi Oluwa ni alabojuto awon ojuse ti Isakoso. Ohun ti King James pe ni “Isakoso”
ohun kan naa
ni a pe ni “ise” ati ise iranse ninu Bibeli (Amp). Awon ise iranse ni Bibeli New American
Standard pe, nigbati Bibeli New Century Version pe ni ona lati sin.
Ti a ba se agbeyewo oro yi daradara, a o se akiyesi pe
Isakoso, eyi to tunmo si pe bi a se le mojuto igbe aye ni igba gbogbo, ko ri
bakannaa gegebi ti ijo. Isakoso tunmo
si isin, ise iranse ati ona lati sin.
“Sugbon Jesu pe won si odo ara Re o si so fun won pe,
Eyin mo wipe awon eni ti a damo ti won nse isakoso ti won ye ki won dari awon keferi (awon orile
ede) ma njoba lori won – ti won ma njegaba pelu gbogbo agbara won si nmu won
teriba- awon eniyan nla won si ma nlo ase ati ijoba won le won lori. Sugbon eyi ko ye ki o ri be laarin yin
Dipo be enikeni ti o npongbe lati je eni nla larin yin gbodo je iranse, ati pe
enikeni ti o ba fe lati je eni ti o se pataki julo ati eni ti yio wa ni ipo
akoko larin yin gbodo je eru won. Omo eniyan ko wa ki a le ma sin, sugbon lati
sin elomiran, ati fi aye re sile fun irapada opo eniyan. Mk 10:42-45 (AMP)
Awon ese Bibeli ti oke yi fi ilana ti gbogbo wa gbodo
tele ninu sise awujo to ye fun ijo Re. Jesu pase pe Isakoso ijo tabi didari ijo
ko gbodo wa ni ibamu pelu asa ti aye. Isakoso ijo ko ni erongba lati mu oselu
wo inu ijo, ki a ma ri. Awon olusakoso ninu ijo ko ye ki won lo agbara, ase
tabi ijegaba gege bi oti wopo lode oni . Won wa lati sin tabi lati se ise
iranse, won ki ise Oluwa, eru ni won nse!
Ohun ti a nri ninu ijo ode oni yato si ohun ti oro
Olorun la sile. Awon olori ijo ko sin ni mo, sugbon awon ni a nsin, nse ni won
nse bi eni pe awon ni o ni ijo. Sugbon eyi ki yio ri be larin yin.
AWON ENIYAN TI A YAN LATI SIN NINU IJO “Nitori na o wipe, nigbati o goke lo sibi giga, O di
igbekun ni igbekun O si fi ebun fun eniyan. O si ti fi awon kan funni bi
Aposteli, ati awon miran bi woli, ati awon miran bi Efangelist, ati awon miran
bi Olusoaguntan ati Olukoni. Fun asepe awon eniyan mimo, fun ise iranse, fun
imudagba ara Kristi” Efesu 4:8,11-12.
AWON TI A YA SAPAKAN FUN ISAKOSO NINU ARA KRISTI
Awon
miran tun wa ninu ijo gegebi a ti se ri ninu Bibeli ti won ko ni oju ile ise
iranse bi iru eyi, sugbon won wa lara awon ti se Isakoso ijo fun apeere iru
awon eniyan bee ni awon okunrin meje ti ni iroyin rere. Ti a yan ninu awon
eniyan (Ise A. Aposteli 6:3, 5-6). Eyi ni awon Diakoni akoko ninu ijo akoko.
Paalu ru Titun soke lati yan awon eniyan gge bi Bisobu lati ma se abojuto agbo
awon aguntan, ti o ba je pe iru eni be koju osunwon ti a la sile.
ILANA JESU NIPA ISAKOSO IJO
IGBIMO MAJE O BAJE
IGBIMO TO GA JULO AKOWE IJO
IGBIMO AWON AGBA
LAGBAYE
AGBAJOPO AWON IRASE OLORUN
IPEJOPO GBOGBO OSISE

IPEJOPO GBOGBO AWON
ENIYAN
OLORI
IRANSE:
Jesu Kristi ni o wa ni ipo yi gege
bi ori ijo . Gbogbo eniyan ni o gboju
soke si odo re fun itoni. O ni ojuse taara taara si baba Re, Jesu so
wipe omo (Jesu) ko le se ohun kohun ninu ara re, ayafi ohun ti o ba ri ti baba
ba nse (Jn 5:19 ) O wa lati mu ife baba re se.
Jesu Kristi ni o wa ni ipo yi gege
bi ori ijo . Gbogbo eniyan ni o gboju
soke si odo re fun itoni. O ni ojuse taara taara si baba Re, Jesu so
wipe omo (Jesu) ko le se ohun kohun ninu ara re, ayafi ohun ti o ba ri ti baba
ba nse (Jn
IGBIMO
MAJE O BAJE: ; 
Nibe ni a ti ri Mose ati Elijah ti
won nba Jesu jiroro nipa iku re. Bi o tile je wipe Jesu so fun awon Aposteli
idi ti a fi bii. Sibe ko si eyi ti o ni igboya tabi ni lankaye toto lati ba
jiroro ninu oro to gbongbon yi bikose Mose ati Elijah nikan ni o se be ni ori
oke Ipalarada (Lk 9:28 -31).

Nibe ni a ti ri Mose ati Elijah ti
won nba Jesu jiroro nipa iku re. Bi o tile je wipe Jesu so fun awon Aposteli
idi ti a fi bii. Sibe ko si eyi ti o ni igboya tabi ni lankaye toto lati ba
jiroro ninu oro to gbongbon yi bikose Mose ati Elijah nikan ni o se be ni ori
oke Ipalarada (Lk
Igbimo
maje o baje yi awon ni o ma nlana eto kale fun ijo. Awon ni o ma ngbaruku ti
imuse iran
ise iranse. Awon ni o ma ngba Olori iranse ni imoran lori gbogbo ise iranse.
Awon iru eniyan be gbodo je eni ti a ti wo fini fini ti won ni oruko rere ninu
Oluwa.
Won
gbodo je agba ninu iriri ninu ise iranse. Nigba miran, odara lati ni awon eni
ti o dagba ju olori iranse lo ninu ise iranse gege bi igbimo yi, ki o ba le see
se fun awon igbimo yi lati je ijanu fun asoju eyi ti olori iranse le fe se
nigba miran.
IGBIMO
TI O GA
JULO:
Peteru, Jakobu, Johanu ati Jesu
Kristi ni awon ti o wa ninu igbimo ti o gajulo ninu ise iranse Jesu. Awon
eniyan wonyi na pelu Jesu lori oke Ipa larada (Lk 9:28 -31, Matt 12:1).
Peteru, Jakobu, Johanu ati Jesu
Kristi ni awon ti o wa ninu igbimo ti o gajulo ninu ise iranse Jesu. Awon
eniyan wonyi na pelu Jesu lori oke Ipa larada (Lk
Ni
ogba Gestemani, Jesu fi awon ti o wulo nipa ise iranse Re han. O mu awon mokanla wa pelu ara re wa sinu ogba.
Laarin awon mokanla o yan awon meta, Peteru, Jakobu ati Johanu o si so fun won pe ki won duro ni ibikan. Oun funra
re sun siwaju bi opo ina kan
si won lati gbadura. Gbogbo ise ti o gbopon ti o si jemo ise ijadelo ma nkan
awon eniyan yii. Nigbati Jesu nlo lati wo omo obinrin Jairu san o mu awon
eniyan meta yi lo sibe.
AKOWE
IJO:
Enikan wa ninu awon omo eyin, eni
ti o sun mo Jesu ti o ma nrogun si aya re. Omo eyin yi mo gbogbo ero okan Jesu
ju gbogbo awon ti o ku lo. A si mo omo eyin yi gege bi Johanu olufe. (Jhn
13:22-26;21:30).
Enikan wa ninu awon omo eyin, eni
ti o sun mo Jesu ti o ma nrogun si aya re. Omo eyin yi mo gbogbo ero okan Jesu
ju gbogbo awon ti o ku lo. A si mo omo eyin yi gege bi Johanu olufe. (Jhn
13:22-26;21:30).
Ko
le yani lenu pupo pe nigba ti Jesu de enu bebe iku Re, o so fun un pe ki o se
alabojuto iya ti o bi oun nipa ti ara.
Jesu
yan Johanu olufe gege bi akowe Re si ijo ninu iwe ifihan (Ifihan 1:1,4-3:22)
IGBIMO
AWON AGBA LAGBAYE:
(Mk
3:13-15) Jesu yan awon mejila ki won le wa pelu Re, ki o le ran won jade lo
wasu. Awon mejila yi je opo-mulero ise iranse Jesu
lagbaye,
ijo gbodo ni awon iranse ti a fi ororo yan fun ise iranse ti yio wa ni ipo lati
tan ihinrere Jesu Kristi Oluwa kaakiri koja ibode ilu won.
AGBARIJOPO
AWON IRANSE OLUWA:
Lk
10:1-12, 16-20 Igbimo agbarijopo awon iranse Olorun je awon aadorin ti Jesu
yan, awon ti Jesu ran jade lati wasu. Gbogbo awon eniyan wonyi ni won ti gba
ise iranse ni ekun rere, ti won si n tele itoni ti oga won fun won. O pa lase
lati ma mu ohunkohun pelu won ni irin ajo won. O ye ki ijo gbe iru igbimo bee
kale ninu ijo fun ise ijere okan.
AKOWE ABENU:
Lk 1:1-4; Ise A. A 1:1 Onisegun Luku ni o nko
akosile ohun gbogbo ti Jesu ko, ati ohun ti o nse. O to gbogbo itan leselese
lati ibeere aye Jesu titi Jesu fi goke lo si orun ati bakannaa nipa ibeere ijo.
Awon ero awujo ko mo pe o se akosile ohun gbogbo ti o nsele.
Lk 1:1-4; Ise A. A 1:1 Onisegun Luku ni o nko
akosile ohun gbogbo ti Jesu ko, ati ohun ti o nse. O to gbogbo itan leselese
lati ibeere aye Jesu titi Jesu fi goke lo si orun ati bakannaa nipa ibeere ijo.
Awon ero awujo ko mo pe o se akosile ohun gbogbo ti o nsele.
Akowe ti a le gbeke le gbodo je, eni
ti yio ma wa ni amojuto bi ise iranse yio se le se deede, iru eni be yio sise
ni taara pelu Olusoaguntan ti ile ise iranse bee.
IPEJOPO
GBOGBO OSISE:
Ipejopo
gbogbo osise ni awon ti o nsise lati igba ti ijo ti bere. Awon ni awon ti won
gba bamutisi Emi Mimo ni ojo Pentikosti, ti iye won je (120) ogofa eniyan. Lati
inu awon ogofa yi ni Stefanu ati Filipi ti jade wa.
Ipejopo awon osise ni o gbodo kan gbogbo eniyan ti o
nse ohun kan
tabi omiran ninu ise iranse, gege bi:- Asona, Akorin, Oluko ile eko ojo isinmi,
Afi adura segun, Gbogbo asiwaju, Gbogbo iranse Olorun ati gbogbo osise miran
ati beebe lo.


IPIEJOPO
GBOGBO AWON ENIYAN:
Ipejopo
gbogbo agbarijo awon omoleyin. Awon eniyan yi se pataki ninu ise iranse Jesu,
bakan na ni o dawon mo. Ni opo igba, aini awon opo eniyan wonyi ti o maa ntii
lati wasu ati lati se awon ise iyanu.
Ninu
ijo akoko, nigba ti won nkun, ni awon Aposteli pe awon ogoro omo eyin ti won si
ba won soro, won si pase fun awon ogooro awon eniyan lati yan awon okunrin meje
laarin won, awon eni ti won ya soto gege bi Diakoni (Act 6:1-6) Ise iranse ti o
ba kuna lati da ohun awon ipejopo awon eniyan mo, a ni iriri idarudapo ati wipe
iru ise iranse be ko ni dagba soke
No comments:
Post a Comment