Tuesday, August 1, 2017

AWON OMODE NI ILE IWOSAN

                   AWON OMODE NI ILE IWOSAN
TANI AWON OMODE? Awon ti a mo gegebi omode ni, omo oojo si omo odun merinla. Awon omo ni ini OLUWA O.D. 127:3. Awon ni ogo idile kookan. Awon ni gbongbo ogo iran ojo ola. Awon ni owon pataki iran ti o mbo.
Bi o tile je wipe won je awon ohun ti a soke yi, bakan na, won je ilepa esu. Ogun orun apadi mo wipe  bi awon ba le mu awon omode, awon ti segun ojo iwaju iran omo eniyan
Esu gegebi olori ota Olorun, ti jade pelu owo ijade ti o l'agbara, pelu ipinnu, ete, ipa ati ni idakeje pelu. Ki oun tan, baje, daru, bori, ge won lege, parun, darupapo, so di omoleyin, mu kuro l'oju ona, fi emi aimo kun, dojuko, dari fiyaje ki o si pa awon ini OLUWA. Eyi ni ise ijoba okunkun ti owa lowo won ni kiakia.
Opolopo awon obi ni l'owa ti awon omo won kun fun emi aimo, di omoleyin gege bi asoju eniyan fun esu. (Bi o ti le je wipe won maa wa si ile ijosin deede bii awon olujoko). Sibe won ko mo. Eyi je oun itiju . Bi esu ba le rapala wo inu ijo Olorun to bee, o ye ki awa pelu le mo ki a si so bi nkan yoo ti ri lawujo awon alaigbagbo. Looto, esu nni akoko ti o dara ni ibugbe awon alaigbagbo ni biba awon omo won je ki o si tun gba won si ise pelu.
Nje ona abayo wa fun awon omo wonyii ti won ti wa ninu ide ati okun emi aimo bi? BEENI! Ireti wa fun won. Eyi si ni idakoro agbara Jesu ti n ja ajaga ti a pese fun gbogbo Ijo Olorun kookan nipase emi mimo. Isaiah 10:27
Loni, ale ba gbogbo ise esu je, ki a tu awon onde sile, le emi aimo jade, ki a si fa gbogbo gbongbo irugbin esu tu kuro ninu aye awon ini Oluwa wonyii si ijoba okunkun ti baje. A ko gbodo gboju f won da. idi niyi ti Olorun fifun ijo ni ise iranse itusile  Isaiah 61:1-4. Gbogbo eyi ti esu ti se ninu aye awon omde yii ni ale fo danu pelu ami ororo Olorun. Awon kristeni kun oju osunwon ti won ba fe tele Bibeli.
BI EMI AIMO SE NWONU AWON OMODE
Ni igba miran awon obi won ta won fun esu nipase jije ope won. Emi aimo je emi ti ko ni ara ti won si buru pupo. A kole ri won pelu oju lasan won si maa n fe lati gbe ninu eniyan. Enikan wipe: Ilepa won ti ju ni pe won fe ara gege bi ibugbe aye lati le maa sise nipase re.
Emi aimo gegebi ohun abemi, maa nwole nipase ilekun ti o ba si sile. Won le wo'nu awon omode nitori awon pelu gegebi agbalagba ni emi, okan at ara. Paapa emi aimo now'nu oyun inu.
Odomobirin kan jewo pe, ojuse oun si joba okukun nipe ki oun maa mu awon omobirin lati inu oyun wo egbe okunkun. Bakana ni a ti se alabapade emi aimo ti osi so wipe oun wo inu ago ti oun wa lati inu oyun ni.
Bayi, niwon bi o ti han gbangba pa emi aimo le raaye wole sinu omo ti owa ninu, o se pataki fun wa lati se agbeyewo awon ona ti won maa n gba rapala wole sinu awon omode wonyii.
1.   IMU W'EGBE LATI OWO OBI:  Opolopo omo ni won ni emi aimo nigbati awon obi won jowo fun orisa   
       boya ni mimo tabi ninu ope. Ni opo igab, iru awon bee maa n ni emi aimo ti m be lleyin irufe orisa
       bee.

2.   ISELE IGBEAYE: Iriri igbeaye obi ti ko ladun le silekun fun emiaimo lati ko won l'eru. Awon obi ti won       
       ni idaduro omobibi ti won sii n lo kaakiri fun apeere: ile wooli eke, babalawo, ile egbe okunkun, ibile   
       ki won to beere sii biimo le ti silekun sile fun emi aimo lati wo inu emi awon omo won.

3.   AKOKO AILERA: Emi aimo maa n lo anfaani akoko ailera. Okan omo kookan tabi aye si sile fun
       ohunkohun ti owa ayee lati wole . Aye omo kookan lo sofo, ti ko ba si si aabo ti o peye lati odo obi
       wa won yio di ije fun emi okunkun ni.

4.    OPE OBI: Aaye maa n si sile fun emi aimo lati wo'nu awon omo nipase ope awon obi. Lopo nitori jije
        ope si arekereke esu, opo obi ati alagbato maa n fi aye sile fun emi aimo ninu aye awon omo won.  
        Eyi le waye nipa gbeere sinsin, gbigbewon lo si odo awon woli eke tabi si ojubo babalawo, fifun won
        ni ounje ti a fi rubo si orisa ati fun emi oku-emi orisa idile.
        Esu kii kuna gbogbo anfaani ti o  ni pase awon ayeye ti a se ninu jije ope wa lati si aye awon omo wa    
        sile fun aye emi aimo.

         Bibeli ninu iwe Deutaronomi 18:10-14 kilo lodi si iru awon ayeye bee ti ole fun sataani ni aaye (eto)     
         ni ile wa. A le ri ni igba miiran awon obi maa n fun esu ni eto lati sise ninu aye awon omo won.
         Efesu 4:27. Dajudaju kii si anfaani ti o ba ni lo boya ni mimo tabi aimo.
         Idi niyi ti Bibeli fi g ba wa ni yanju pe " E mase fun esu ni aye". Osi ti di mimo fun wa esu yio gba
          gbogbo ile ti a ba fun un. Eyi si ni o n maa se late ipase awon emi aimo. II Korinti 2:11.

   5.   AYIKA TI O LEWU: Awon omo ti a to dagba ni agbegbe ti won ti maa nb orisa ni gbangban, emi omi   
          ati orisa idile rorun pupo fun emi esu lati ni ipa ki osi ni awon omo naa.

   6.   IDILE ALAWO: Awon omo ti a bi ti a si to nibi ti ale pe ni ijo emi tabi ti won ti maa n borisa ti won si   
          maa n se irubo l'oorekoore. Eyi le mu awon omo wonyii wa larowoto emi aimo lati ni won tabi nipa
          lori won.

   7.   OUNJE EMI AIMO: jije ounje ti a fi rubo si orisa nipase awon asoju esu paapa julo se akoba. IFIHAN  
          2:14b

   8.    ETO EMI AIMO: Eyi maa n sele nipa eto isodomoleyin ijoba okun. Loni ona ti o ga ni awon omo
          keeke maa n gba mu ara won wo inu egbe. Ifagagbaga nla mbe. Awon omo ti o ti wonu egbe
          nipase ojuse ta bi omiran paapa se akitiyan lai sinmi lati rii daju pe awon pelu mu elomiran wo ibe .
           Ogbon ewe won si ni pe " iwo fun mi, emi pelu yio fun elomiran". O si dabi esu n so fun awon
           omo ti oni emi aimo wonyii pe, " a ti fi ororo yan lati awon miiran wa, ere nla sibe lati se bee"

    9.    NIPASE AJOGUNBA: Oni saamu soro Olorun wipe "oun yoo yan ini wa fun wa" O.D. 47:4a. Oro ti a     
            fe fi han kedere. Esu ni baba elese nitori a ti koo pe "eniti o ba dese ti esu ni".
            Loni, opolopo ise lo ro mo bi emi aimo se n gbe inu eniya nipase ajogunba. Fun apeere, ti won ba            
            so fun omo kan pe ojo obi re osese ki o jogun awon ailera won ki osi ti pase bee di wahala si l'aya.
            Loni, a ti ri akoko ti ailera ati aisan obi ti wo'nu aye awon omo won. Eyi see se nipase emi
            ajogunba. Bakanna pelu awon isele die wa ti emi aimo le fi di sisowo si awon omo. ko si si hun ti
            omo naa le se ju pe ki o gba iru emi bee lo. Emi aimo bee di "emi ibinimo" ti o maa nfi aisan tabi
               ailera sowo ti yoo si wa fun ebi ohun nikan si irin won ti o mbo.

     10.    AIBIKITA OBI: Aibikita awon obi ni bibojuto awon omo won le silekun sile fun emi aimo. Awon     
               obi ti won ko ni obi ti won ko ni obi ti emi lati dabobo awon omo won le dara won lebi. Awon
               obi ti won ko omo won lati jeun laibikita nibikibi, yoo ta awon omo won fun asoju esu laipe.

OHUN TI A O SE FUN WON
Awon ibeere ti a nilo bi ara wa ti a o si dahun re niwonyi:
1.      Se ki afi aye gba esu lati di awon omo wonyii titi lae sinu okunkun re-koto?  Isaiah 61:1c.
2.      Se ki a gbaaye fun ota Olorun ki o fi awon ini Olorun pamo si abe ide nla titi lae ni akoko ti wa yi?  
         Isaiah 61:1b.
3.      A ko ha le ja won gba kuro lowo emi aimo bi? O.D 54:1-4.
4.      A ko ha le gbo igbe ekun awon omo alainireti yi ninu ewon esu bi? Isa 61:3a.
5.      Se a o le dide ninu agbara Olorun lati wo ogba ewon esu ki a si tu won sile bi? O.D 125:3.

Ha! Gbingbin, ekun, igbe ati ijiya won mu ki okan Olorun maa s'eje. A gbodo mura giri bayi ki a si wo'nu ise ki o to pe ju. Eyi tumo si pe o gbodo gbe ise iranse itusile laruge ki a si bere si fi si ise. A gbodo yi imo ijinle ati asa wa pada. Ise iranse itusile ba Bibeli mu a si gbodo se ni ibamu pelu bibeli.

IDI FUN ISE IRANSE TI PE
                                                ".........Jesu si emi aimo na wi, o si mu OMO na lara da,
                                                          O si fa le baba re lowo". Luku 9:42b.
Gegebi osise ninu papa ti o l'eso (ijere-okan awon omode), lopo igba, a ko le ni ise iranse ti o pe bi oko ba mo nipa bi a o se le se ise iranse itusile fun awon omode. O to ki a so wipe ise iranse itusile ni ohun elo pataki lati mu ojulowo omo jade wa tii se gbungbun ise iranse Bibeli ti o peye. Ewe, eyi tumo si pe ti o ko ba mo bi a se nse itusile fun awon omode ni ona ti Bibeli la kale, ona lati ni ise iranse ti o pe yoo mo niwon. Nitorina, a nilo lati farabale daada si eko yi niwon bi o tile je pe ilepa wa lati ojulowo ise iranse.
Bakanna pelu,  a nilo lati wo ijere-okan awon omode finifini pelu oju'woye wooli ki a ba le se awari awon ohun elo ti o ti sonu ninu ise iranse awon omode l'ode oni. Bikosepe a ba se awari awon ohun elo wonyi, a ko ni le munadoko, je alagbara, ninu ise iranse itusile awon omode. Awon ohun elo ijere-okan awon omode l'ode oni lati inu awon aseyori ati gbungbun Bibeli- ise itusile.
BI A SE LE SE ISE IRANSE ITUSILE AWON OMODE
Ise iranse itusile je ise iranse awon "eniyan ti o to". Lotito, o je ise iranse fun awon ti o ye . Ibeere ti mo ni fun o ni pe nje iwo ye? Iwo ko le je eni ti o ye lai je wipe o lowo si ijere-okan awon omode. Ti o ba si lowo si lai je eni ti o ye, ko ni si abajade ti o danmoran fun o.
Bakanna, ti o ba ni amuye lati je eni ti o to fun ise iranse itusile lai ni ogbon ewe ti o to, ilana ti o to imo ijinle ti o ye ati ifororoyan ti o to, iwo ko ni le se aseyori ninu ise iranse yi.
Ngo gbiyanju lati ko awon koko ti ise otito yi lati fi gbe oro mi ti mo ti so nidi fun oye ti o gbooro.
Opolopo osise awon omode tabi iranse Olorun ni won ni ohun gbogbo sugbon agbara ti nje ajaga. Lotito, opo ni ohun elo (aworan ikoni) agbara, ogbon sugbon won ko ni imo ijinle ti o to ko si si atunda ifororoyan, won gba jugbaja sugbon won ko ni igbe aye otun ninu Bibeli.
ITOJU ILE IWOSAN PELU AWON OMODE
Ninu ise iranse itusile, paapa pelu awon omode, ipele-ipele eniyan (omode) ni a o pade ti o si beere fun awon akose-mose ti o nye (specialist). Nitorina, o se pataki lati da awon oniruuru eniyan (omode) ti yoo wa fun itusile ni ile iwosan emi wa mo.
1.   AWON OMO TI WON KERE PUPO: Gbogbo awon omode ti o ba kere si odun meta (under 3) sugbon  
       ti won ni emi aimo tabi ti emi aimo ti ko leru ni a wipe kere pupo. Awon wonyi ko le alaye ohun ti o
       nse won. Sibe, won nilo ogbon ti o po rekoja ati itusile ti o gbongbon pelu.

      Sise ise iranse itusile pelu awon wonyi beere fun akanse ifamiororoyan ati liloye ase ti a ni nipase  
      Jesu. Iranse binrin kan fun ijere-okan awon omode wipe iru ise iranse itusile bee beere fun
      ifamiororoyan ti o le.

2.    AWON TI WON KERE DIE: Awon wonyi ni omo ti o wa labe ide emi aimo sugbon won je omo odun
       merin si mefa (4-6). Bi o tile jepe won le soro, won ko ni oye ti o to lati se alaye ohun gbogbo lai se
        asise. A ni lati sora pelu awon wonyi. Ninu imurasile fun itusile- igbani ni iyanju, a ni lati kiyesi ailera
        won nigbati won ba ndahun awon ibeere wa.

3.    AWON TI OJO ORI WON KO TO: Awon wonyi je omo odun meje si mokanla (7-11) ti won si wa labe    
        ide emi aimo. Bi o tile jepe ojo ori won ko to nkan, won le salaye lekunrere iriri won ajoji ti won ni bi
         won ba fe see bee, nigba ti won ti won ko ba si labe ideruba. A nilo ogbon Olorun, suuru ati oye ti o
         peye nipa ihuwasi awon omode ki a ba le ni ifitoni leti ti o wulo lati odo awon eniyan ni ipele awon
         omo yi ki a baa le mo bi itusile won yoo se ri.

 4.     AWON TI WON KO SI NINU OYE WON: Awon wonyi ko si ninu oye won latari ise emi aimo ninu   
          won. A ko le lo ilana itusile lati fi se itusile fun iru awon wonyi. A nilo ifororoyan ti o tayo lati tu
          awon wonyi sile (Lk 9:38-42). Jesu sise iranse si iru won lai so wipe ki won tele ilana itusile rara.

5.      AWON TI WON WA NI OYE WON TI WON SI FE BO: Awon wonyi ni won wa labe ide esu ti won si fe  
          jade kuro labe ide bee. Won maa nfi ife jijade won han nipa siso gbogbo otito ati ohun gbogbo ti  
          yoo le mu won la awon igbese itusile koja. Bakanna, o nilo lati fun won ni idaniloju aabo won ti o  
          peye fun titu asiri ise esu ninu aye won.

 6.      AWON TI WON KO FE BO: Awon omo miran wa ti won ni emi aimo sugbon ti won ko pinnu tabi   
          setan lati di ominira nitori irufe ideruba ti emi aimo nfun won pe, ti won ba le jewo, won yoo pa
          won. Bakanna, eyi le ri bee latari ohun ti won je lohun, ninu oye emi. Opo won le wa ni ipo giga
          ninu oniruuru egbe ti won wa. Won si nro ninu ope won pe awon yoo wa nibe titilae. Iru adanu nla  
          wo leyi? Ohun ti a nilo lati ni pe ki a mu da won loju idi ti won ni lati fi jade kuro ninu idekun esu, ki  
          a si mu won ri wipe o lewu lati wa lawujo ati ogo awon ota.

             
             ITOPASE LEYIN ITUSILE: BAWO NI AWON OMODE SE LE DAABOBO ITUSILE WON?
A ti so gbangba pe o rorun lati gba itusile ju lati daboobo lo. Ati pelu ni ti awon omo owo ati awon omode, bawo ni won se le pa ara won mo kuro lowo emi aimo niwon bi a ti tu won sile, niwon bi won ko ti kun oju osuwon lati daboobo ara won?
Ojuse awon obi ni. Ninu Bibeli, akiyesi pe nigbati Jesu ba tu omo kan sile okan ninuawon obi omo naa tabi awon mejeeji ni yoo wa nibe. Ojuse abi ni lati je atona emi fun awon omo won. Jesu fi otito yi han wa nigbati O fa omo kan le baba re lowo leyin ti O ti le emi aimo jade kuro laye re tan.     
                                                 ".....Jesu si ba emi aimo na wi, o si mu omo na larada,
                                                                o si faa le BABA re lowo". Lk 9:42b.
Eyi ni wahala ti a ni loni, opolopo obi ni won kii se Kristeni, ti won ba tile tun je Kristeni, opo ni won ko dagba ta, won ko ni itara, beeni won ko si ni iberu. Ise nile waye nitori oniruuru oruko adamodi ti won maa npe awon omo won paapa leyin itusile. Opolopo Tomasi oniyemeji ni awon obi je. Awon miran tile le yo omo na laarin awon yoku ki o si fun ni oruko bii "irugbin esu", "esu kekere" "arekereke" abbl. Esekeli 35:5. Eyi lewu pupo, o le mu ibinu Olorun wa sori wa ti a ko ba sora.

     

No comments: