EKO
IMO IJINLE NIPA EMI AIMO
(Theology of
Demonology)
ILANA ETO EKO NAA
1. Oro Asosaaju
2. Orisun awon emi aimo
3. Wiwa laye awon emi mimo loni
4. Iparun awon emi aimo
5. Akosile nipa awon ti emi aimo fi iya je
6. Awon ohun aigbodomani fun ise iranse itusile
ORO ASOSAJU:
Kini Theology? Kini Demonology?
THEO- Je Olorun, LOGY- Je Eko
THEOLOGY je Eko nipa Olorun tabi akiyesi Olorun
DEMON je emi aimo, LOGY
je eko
DEMONOLOGY je Eko nipa awon emi mimo.
IMO IJINLE NIPA EMI
AIMO: je awon idanileko Bibeli nipa awon emi aimo, iyen ni pe
ohun ti iwe Mimo ko wa nipa awon emi aimo paapa julo wiwa laye won, orisun won
ohun ti won je, ise won tabi awon ojuse won. Bi Olorun se si won ni ipo ati
ireti Olorun lori wa lati si won ni ipo pelu.
KINI IDI TI A FI NKO
NIPA EMI AIMO
O ni awon idi pataki ti a fi nko
eko yi, awon idi na niwonyi:
1. Lati fi han fun wa isodi pupo aye, bi aye
tabi awon aye se wa ti o yato si ti eniyan bii aye ti emi.
2. Lati mo orisun won, boya lati odo Olorun ni
tabi won wa nipa ti ara won ni.
3. Lati kilo fun wa nipa ewu ti o yi wa ka ati
bi a se ni lati sora.
4. Lati gba awon ohun ini eyi ti Olorun fi fun
wa, tabi ti o ti pese fun wa awon ohun ijagun paapa julo
ohun awon ija isegun gege bi oruko Jesu,
Eje Jesu ati bebelo, ohun ti o wa ni ikawo wa ni lati se lodi si
ati lati ja won kule ati bakana lati pa
awon ise won run.
5. Lati mo aabo Olorun ti o wa fun wa.
6. Ki ise Olorun le te siwaju.
7. ki a le mo arekereke esu.
8. Lati le mo ipele (odiwon) won ati bi won ti
nsise.
9. Lati mo bi won se nsise ninu eniyan yala
awon onigbagbo tabi awon alaigbagbo
10. Lati mo iru awon eniyan ti
emi aimo ko le dari tabi je gaba lori re.
11. Lati mo ogbon ati ona ti a
le fi doju ija ko awon emi aimo.
ORISUN WON
Awon Emi Aimo wonyi ni o koko ti
wa ni orun ki o to di wipe won subu pelu Lusiferi (Satani), ninu eyi ti a le
won jade sinu aye lehin ote aisase yori ti Lusiferi di si Olorun ti o subu dele
(Ifihan 12:7-10; 12:3-4, Isa 14:12-14).
WIWA LAAYE WON
Won po niye ti o yi wa ka, ti
won nfo kiri ni idakeje lati maa se ise won lodi si eniyan. Ifihan 12:2-4, 1Pet
5:8.
IRISI WON TABI OUN
TI WON JE
a. Won je emi- angeli ti o subu
b. Won je aiku
ISE ATI OJUSE WON
Lapapo won je emi buburu si
Olorun ati si eniyan eyi ni pe won je asodi si Olorun ati si eniyan pelu paapa
julo awon ti o setan lati sin Olorun.
a. NIPA TI OLORUN
Won pinu lati ba eniyan je, resile,
titako ati si eniyan nipo eyi ti se ise Olorun.
b. SE ENIYAN
Won nba ti eniyan je, ri rin mole,
irewesi okan, gbigba iro gbo, itanje, fifa sinu awon, ifiyaje, idewo,
nini eniyan ati lati pa (John 10:10, Job 2:2)
ASE TI KRISTENI NI
LATI NI
1John 3:8. Omo Olorun ti farahan
lati pa ise Satani run, Olorun nfe ki a doju ija ko awon emi aimo, ki a si pa
ise won run. Jakobu 4:7 so wipe Teriba fun Olorun ki o si doju ija ko esu...................Olorun
nfe ki a koju ija si gbogbo akamo ati ikolu awon emi aimo ti ndoju ija ko wa. (Matt 10:7-8, Mk 16:17 pelu Lk 9:1).
ORISUN AWON EMI AIMO
Bibeli ko jafara lati dahun
ibere yi, opolopo idahun ni o wa fun ayewo, ikan lara awon idahun ibere yi, ni
awon eniyan ti gba lapapo bayi.
1. Nigbati
Satani se si Olorun ninu iwe Isa
14:12-20, Ezek 28:11-19, awon kan wipe ko da dese ni oun
nikan sugbon oun ni asiwaju awon
angeli. Nigbati Satani subu ati oun ati awon angeli re ni Olorun le
jade, awon angeli to subu yi ni won
pada di awon emi aimo. Ninu iwe Matt
12:26. Satani la le ri
nibe gegebi oba lori ijoba awon emi
aimo oje wewe ti o tumo si wipe o ni awon emi aimo ti o wa
labe re ti o nsise fun.
2. Awon eniyan rii ni Gen 6:1-6 wipe awon
angeli nsokale lati wa ma ba awon obinrin lo po. Omo ti
won bi nigbanna ni won di Omiran.
Opo eniyan si so pe awon wonyi ni odi awon emi aimo lehin
iku. Awon elomiran wipe isele yi je
ti igbeyawo larin eniyan Olorun nipase "Seti" pelu ti aiwa bi
Olorun nipase ti (Kaini). Bi eyi ba
ri bee, kini o mu ki awon omode igba naa di omiran awon eniti kii
se eniyan lasan sugbon ti won
sigbonle. Gen 6:2.
Bakanna ni a ri wipe Jobu 1:6 so nipa
"Awon omo Olorun ti won wa nfi ara han niwaju Oluwa.
Awon omo seti ni won ko ni anfani
lati wo inu awon orun, a fi awon angeli nikan.
3. Alaye keta nipe awon emi buburu yi ni
awon emi ti o wa ki o to di akoko Adamu ni ese meji akoko
iwe Gen 1, a si se apejuwe won ni
Jer 4:23-26 bi igbati a wipe ".....ko si eniyan...." Eyi ti o tumo
si
pe awon eniyan ti wa nigba kan ri.
IWA LAAYE AWON EMI
AIMO LONI
Opolopo awon eri ni o wa ninu iwe
mimo pe awon emi aimo ti o po ni iye wa ni akoko ti Olugbala wa ninu aye yi.
Sugbon awon eniyan nhale loni pelu ijinle nipa (science) ati awon eko miran
wipe oro ti Bibeli so nipa emi aimo je igbagbo ofege tabi ohun isefe. Awon ti o
ko majemu Titun ni won ni igbagbo ti o muna doko nipa emi aimo Johannu ninu iwe
Ifihan 9:20 so nipa isele kan lojo
iwaju, iyen akoko iponju nla, nigbati awon eniyan yoo bere si sin (bo) emi esu,
eyiti opolopo awon aborisa je Olusin won lode oni. Gege bi eleri ode oni, nipa
awon emi aimo opolopo awon to ngbe ilu Manila ti nse Olu ilu Philipire ni won
ni anfani lati ri awon ti o ni emi esu ati bi won ti ngba enu awon eniyan naa
soro.
IPARUN AWON EMI AIMO
Iparun awon emi buburu yi, gege
bi ti Satani, ni Kristi ti pari lori igi agbelebu. Ogun aini sale ni ibi ti a
yan fun ijiya awon emi aimo ni ikehin. Ifihan 9:11. Awon emi buburu yi ti mo
wipe iparun won nbo. Matt 8:29. Kini se tawa tire, Jesu, Omo Olorun/ Iwo ha wa
lati da wa loro ki o to akoko/ Opin awon emi aimo ati ti Satani ni orun apadi.
Matt 25:41.............Ina ajooku, ti a ti pese sile fun esu ati awon angeli
re.
AKOSILE AWON TI EMI
AIMO FI IYA JE
1. Antoni Ara Egypiti, ba
awon emi aimo ja ijakadi lojukoju
2. Marita Luther so iriri
tire nipa bi Satani se nwa ba oun loorekore lati ba oun ati ise iranse oun ja
nipase awon emi aimo (poltergeist
phehomen) ati bebeli. Esu paapa fi ara han okunrin naa lati ba ja.
3. Awon Ebi John Wesley ni
won ni idojuko pelu awon emi ariwo yi; ti won kii jeki won sun loru, nipa
kikanlekun, fifi nkan didun sara ibusun
tabi ogiri ile, gigbo iro ese bi ti eniyan ati awon emi buburu ti
won nfo kiri yika ile ni ona iyanu.
4. St. Teresa, ri opolopo
ifiya je lati odo Satani, idojuko Satani ninu emi, opolo ati lojukoju. bee naa
ni
awon iranse Olorun bi Cured Arts J. Dean, Marie-Vianney, A.B.
Simpson, ati awon akogun miran
ninu ihinrere. Gegebi ati mo ipo wa
ninu Kristi ati ise etutu fun ese. Efesu
2:6, Kol 12-15, a si ni lati
mo.
1. Awon ota wa
2. Ogbon ewe won
3. Agbara won
4. Ati ise won.
Ninu awon iwe bi "Awon nkan pataki nipa emi
aimo" lati owo Langton, Igbekele
Bibeli nipa emi aimo lati owo Uger ati eko nipa awon angeli ati emi aimo lati owo Nedham. Igbagbo pe awon
emi aimo wa lo ti di mimo laarin awon eniyan ninu aye lati igbati omo eniyan ti
ni oye re. Laarin awon eni atijo ati awon ti ko laju ni won ri awon emi wonyi
gege bi awon ebora ti o lo ti won si tun pada lati wa ba awon alaye ja.
Awon ti won ri awon emi wonyi ni won
ri won ni iri eniyan gege bi eranko ati bebelo sugbon awon emi aimo gan je
airi. Jesu gba wipe awon emi aimo wa, ihinrere maku paapa so opolopo itan bi
Jesu se le awon emi aimo wonyi jade. Awon elomiran nbere boya awon emi aimo wa
ninu aye yi, idahun nipa re ni wipe a gbagbo pe won wa.
AWON OHUN AIGBODO MA
NI FUN ISE IRANSE ITUSILE
1. IGBALA
Eniti yoo gba eniyan ni lati ko gba ara
sile. Igbala je iriri eniyan nipa igbe aye titun atunbi, ti nse bibi ti emi.
Jesu Kristi je Olugbala eniti yoo gba elomiran yoo koko gba ase lowo Re. Awon
keferi kan dibon pe won lagbara lati le emi esu jade, Jesu wipe Satani ko le le
Satani jade, ijoba re ki yoo duro. Ise
Aposteli 19:13-16 ni a ti ri awon aborisa ti won nle emi aimo jade loruko
Jesu ati Paulu nwasu kii se pe awon emi aimo ko dahun nikan, sugbon won je won
niya. Awon keferi maa ntu emi aimo loju, iyen ni pe won o bee tabi ki won paa
lenu mo eyi ti o si le tumo si alaafia igba die kii si se bi Jesu ti nfun ni.
2. ASE
Ase yi wa fun gbogbo Kristeni ti o ba
ti di atunbi, ko si le sise titi di igbati eniyan ba fi sinu ise (Jakobu 4:7)
so fun wa pe awon emi esu yoo sa fun wa ti a ba fi ase doju ija ko won. Satani
nbu ramuramu fun eniti o beru re sugbon o maa nsa fun awon ti won ba doju ija
koo.
3. ORO OLORUN
Oro Olorun ni ida ti a fi njagun, o si
tun je aabo kuro lowo ofa eni buburu "..........Jesu
si le emi buburu naa jade pelu oro........." Matt 8:16. Ninu iwe Efesu
6:17b, a ka nipa "ida ti emi,
ti nse oro Olorun" Eniyan gbodo
ni ifiamin ororo yan ti Emi Mimo ninu oro Olorun lati gba awon eniyan kuro lowo
agbara esu.
4. IFAMI ORORO YAN
Ifami ororo yan ni nja gbogbo ajaga
tabi pa agbara Satani run ninu aye eniyan (Isa 10:27). Jesu wipe (Luku 4:18, 19) "Emi Oluwa nbe lara mi, nitori o ti fi ami ororo yan
mi........lati kede odun itewogba Oluwa" o tun wipe (Matt 12:28) "........Emi nle emi esu
jade nipa Emi Olorun......" Ifami ororo yan ti Emi Mimo nsise po pelu
wa bi a se nlo ase wa ninu Jesu Kristi. Iru eko wo ni eyi? pelu ase ati agbara
ni o npase fun awon emi esu lati jade! (Luku
4:36).
5. IGBAGBO
Maku 11:22 nipa igbagbo la o ti wonu
isegun
6. IMO EMI YATO
Imo emi yato wa laarin awon ebun Emi Mimo
mesan yi kii se lati fi mo emi buburu nikan, sugbon lati mo ipo tabi agbara
won, boya alase kekeke tabi awon olori won ninu eyi ti itusile re le soro nigba
miran lati se bi a ko ba mo eyi.
7. ORO IMO TABI ORO OYE
Eyi je okan lara ebun ti Emi Mimo
mesan ti o nran ni lowo lati ni oye tabi lati gba itoni Emi Mimo ninu eyiti yoo
soro fun eniyan lati mo bawo tabi bi Olorun se soro. Imo emi yato nfi emi aimo
han, nigbati oro imo nfi ona lati segun won han wa.
8. AAWE ATI ADURA
Matt. 17:21, Maku 9:29. Loruko Jesu ki
gbogbo eekun ki o wole, sugbon awon emi buburu kan wa (iyen ni pe) awon emi
aimo oloye kan wa ti won ko ni iteriba bikose pe a ba da oruko Jesu ninu aawe
ati adura nigba na ni won to le gboran si ase Olorun ninu Jesu. Iru Aawe yi pin
si ipa meji.
a. Eni ti yio sise iranse itusile fun
eniyan
b. Eni ti a o se ise itusile fun
9. SISIRO OHUN TI YOO NAA WA
Luku 14:28-32. Jesu
so fun awon omo ehin re pe ki won siro ohun ti yoo na won ki won to lo si oju
ogun kogun. itusile tii se lile emi esu jade je ise ti o doju ko esu lojukoju,
o je idojuko pelu awon emi Satani nigbangba. O je ise ti Satani fi gbogbo emi
re tako ti o si korira nitori ti o yara ba ijoba re je ju awon ise iranse ti o
ku lo. Nitori idi eyi, Satani yoo sa ipa wonyi:
a. Pipa tabi apa-ipatan, fun eni ti o
ba nse iru ise be.
b. Yoo mu irewesi tabi ijakunle ba
iru eni bee bi ko ba see pa
d. Satani yoo maa mu airoju ati
airaye ba iriju yi bi o ba ri pe irewesi ko sise.
e. Satani yoo lo awon eniyan lati
dojuko iru eni bee, bi airoju ko ba sise.
e. Ada nikan wa yoo sele si, awon
eniyan yoo yera fun iru eni na
f. Nigbehin, emi igberaga yoo wole
lati rii pe tabi lati je ki iriju naa ma sogo nipa aseyori re lai fi
gbogbo ogo fun Olorun. Sora,
igberaga npa alagbara.
No comments:
Post a Comment