Tuesday, August 1, 2017

ITOKASI EKO GIGBE IHAMORA FUN KRISTI (ITUSILE)

               ITOKASI EKO GIGBE IHAMORA FUN KRISTI (ITUSILE)
ORUKO NAA
Oro naa, "Gigbe ohun ija tabi ihamora fun Kristi" le dabi ede ajoji leti opolopo sugbon, otito ti o wa nibe ni pe o ba Bibeli mu ati pe o je oro ti a npeni si akiyesi wipe ogun nbe ni ibikan. Beni ogun nlo nigba gbogbo ninu aye ti Emi. Ninu Efesu 6:10-12 Iwe Mimo "Lakotan ara mi, e je alagbara ninu Oluwa ati inu agbara ipa re. E gbe gbogbo ihamora Olorun wo ki e ba le ko oju ija si arekereke esu. Nitori pe ki i se eje ati aran ara ni awa ba nla ja, sugbon awon ijoye, awon alagbara, awon alase ibi okunkun aye yi ati awon emi buburu ni oju orun". Bi a ba wo ohun ti a ka yi, a o ri daju wipe lati gbe gbogbo ihamora Olorun wo, je ase ti o wa lati odo Olorun gangan. Ohun ti o si fa ipe yi ni ti awon emi kan ti a ko fi oju ri sugbon ti oje wipe awon onigbagbo ni ilepa won. Efesu 6:1-13a so wipe "Nitori baa e gbe gbogbo ihamora Olorun wo" Oro ti o wipe "Nitori naa" tumo si wipe nitori idi eyi, iyen nipe gbogbo awon ohun ti a ka ni oke yi ni idi ti a gbodo fi gbe ihamora Olorun wo. Bakanna oro ti o wipe "Gbe" tumosi gberu lati mu lo, lati gba, tabi lati je eni ti o ngbe ihamora fun Olorun.
     Nitori idi eyi, oruko ti a fi fun idanileko yi je eyi ti o ba mu gan. Gbogbo wa ni a mo wipe Olorun wa ni "OLUWA AWON OMO OGUN" Eks 15:3, O.D 34:8. Nitori idi eyi a ri wipe kiki awon ti o ba gba pe Olorun ni Balogun won ati wipe awon kan je eru ohun ija ni awon ni yoo maa ni isegun igba gbogbo lori gbogbo ogun ti won ba ni. Apeere iru awon eniyan bee ni:  (1) Mose   (2) Joshua   (3) Gideoni   (4) Samueli ati bebelo. Lati je aru ihamora yio fun o ni awon orisirisi anfani gegebi:
(1)   Lati je ki owo re di fun un.
(2)   Ki a ni ibale okan loju ija.
(3)   Lati ni agbara lati fi tele Oga wa.
(4)   Lati mu ki aye re ni abo ati bebelo.
                                    IFI IDI MULE RIRU IHAMORA NINU BIBELI
1Sam 14:1-7; 17:6-7; 41; 31:4-6, Efesu 6:10-13. Nitori idi eyi Kristi ni Balogun wa, gbogbo igba ni o ma nwa loju ogun, ohun ti a nilo lati se ni ki a je eni ti o nru ihamora fun Kristi, bakanna ohun ija wa ki i se ti ara, sugbon o ni agbara ninu Olorun lati wo ibi giga pale. 11Kor 10:3-5. Niwon igbati Kristi ko le ku mo, awa pelu ni idianiloju aabo.
                                                            ERO AWON IJO
Oniruru ero, akiyesi ati igbagbo nipa ise iranse itusile ninu awon ijo ni aye ode oni. Awon kan gbagbo, awon kan si ni idi tiwon ko fi gbagbo tabi ti won ko fi gbiyanju lati fi si ise nigbati awon miran ko tile gbagbo lai si idi fun igbagbo won. Awon ero ati akiyesi wonyi ni a o pin si ona marun, ti a o si fi ijo se apejuwe won gegebi:
(1)     AWON IJO AKOKO ko gba itusile gbo, won si pari ero ti won si pe eko awon emi esu ni, sugbon ise iranse itusile kii se eko emi esu bikose eko nipa awon emi esu ati wipe oro ti o wipe "nipa" tunmo si eko bi a se le doju ija ko won, ki a si ba ise awon emi aimo je.
(2)     AWON IJO KEJI gbagbo wipe otito ni ise iranse itusile ati pe o si ba Bibeli mu ati pelu won tun gbagbo pe a da sile lati owo Jesu Oluwa ni Mk 16:17 sugbon won pari ero tiwon si pe o ti lo pelu awon Aposteli akoko, ko si si ni enu ise mo. Awon die tile gbagbo wipe leyin awon mejila ti Oluwa yan ko tile si Aposteli mo sugbon won gbagbe Efesu 4:11-15. Nitori awon ohun ti a ri wonyi, a wa le fi gbogbo enu so wipe won ko gba itusile gbo.
(3)     AWON IJO KETA wonyi jewo pe awon gbagbo sugbon isoro tiwon ni pe won ko se ohun kohun nipa re, won a ma gba awon eniyan ni iyanju wipe e mase fi owo kan esu. Won je ojo onigbagbo ti o ma nsa fun esu, won ko mo wipe esu a ma sa fun awon ti o ba ko oju ija si, a si ma bu ramuramu mo awon ti o ba beru re.Won yio ma be Olorun pe ki o sokale wa ba won le emi esu jade, sugbon ohun kan ti a mo daju nipe lati duro de Olorun ki o wa ba wa le emi esu jade, yio je diduro titi aye.
 Awon nkan wonyi tabi ju bee lo ni ami lati mo iru awon ijo bee:
(i)    Won a ma jewo wipe awon nwasu ihinrere, sugbon ijadelo won ko o ti ni aseyori ri nitori esu ko ni je                          ki awon eniyan fi eti bale gbo oro Olorun.
(ii)    Won a ma se eto won ni ibi ti ko si eso. Ko si si apeja ti yoo ma de iwo ipeja re ni baluwe, tabi agbe                                   ti yoo ma kore oko nibi tabili ijeun.
(iii)    Iru awon omo ijo be a ma ja lori awon oro keekeeke, titi de bi pe won yio si bere si tuka diedie.
(iv)    Won ko ni gbaaye fun Emi Olorun lati rin dipo be won yoo pana Emi ni.
(v)     Won  a ma gba ipo mo Emi Mimo lowo ati aye oro Olorun, iru ijo be ibinu Olorun nbe lori won.
          Ninu iru ijo yi ida marun din ni ogorin (75%), awon olori won ni o ni emi esu Esk 13:3-7. Ida ogorin                    (80%) isoro ti awon onigbagbo ni loni ni o wa lati owo esu.
(4)     A le fi won we awon omo eyin ti Paulu ba pade ni Efesu ti won ko mo boya Emi Mimo kan tile wa tabi Baptisimu Emi Mimo kan tile wa Ise Aposteli 19:1-4. Iru awon onigbagbo bayii ni awon onigbagbo ti ko mo iyebiye agbara Olorun nigbati esu ba doju ija ko won, won yoo ma be Olorun ki o wa ba awon le emi esu jade, nitori pe won gbagbo pe ohunkohun ti o ba nsele si won wa lati owo Olorun boya rere tabi buburu sugbon won gbagbe oro Olorun ninu Jak 1:13-18.
(5)     AWON IJO TI O KEYIN yi ni awon ti o gbagbo ti won si fi si ise. Awon wonyi mo ase won ninu Jesu Kristi, won fi igba gbogbo doju ija ko esu nigbakugba ti o ba gbiyanju lati fi owo ka won, won ko fi aye gba eran ara ninu aye won, won fi aye gba asotele ti o ba wa esu ko ni agbara lati fi owo kan ise iranse won.
                              AWON OHUN TI ITUSILE KO JE   
Opo ijo ati opo awon olori ninu ijo ni ko ni inu didun tabi lo ti so inu didun won nu nipa ise iranse itusile tabi lile emi aimo jade kii kuku se wipe won ko mo oro Olorun tabi won je ojo sugbon nitori pe awon kan se ni isekise, won ti fi owo omo ale mu, won si ti pe ni oruko ti kii se tire. Idi niyi ti a ni lati jo kiyesi papo "Awon ohun ti itusile ko je".
(1).   Kii se ise iranse ti o da duro. Mk 16:15-17.
(2).   Kii se eso ti Emi. Matt 7:15-23.
(3).    Ko wa fun asehan tabi ifagagbaga. Lk 4:1-13.
(4).    Kii se ona fun ati kowo jo. Acts 8:18-23.
(5).    Kii se fifun ni ni "koffee", "tea", ororo, tabi omi mu, wipe ki o ba le bi emi aimo.
(6).    Kii se wiwe eni naa ninu omi gbigbono tabi tutu gegebi ona lati mu ki emi aimo.
(7).    Kii se siso eni naa mo igi, ki a si maa na legba tabi igbale lati mu ki emi aimo jade.
(8).    Kii se lati fi eni na se eleya tabi yeye leyin ise iranse itusile.
(9).    Kii se lati ba eni na ja ni o ba tile se agidi pelu wa.
(10).  Kii se anfaani lati ma so mo ni tabi lati ma fi owo pa eni na lara, paapa julo eya to je odikeji tiwa.
NI IPARI
O gbodo ma fi gbogbo igba wa ni imurasile si arekereke Satani, nitori pe esu ko ni wa gege bi esu, sugbon yio wa ni awo aguntan. Nitori idi eyi, mo ro yin lati ma ja ija ti Emi, ki e si tu onde sile. Olorun so fun Joshua pe "Se giri ki o si mu aya le; nitori iwo ni yio pin ile na fun awon eniyan yi, ile ti mo ti bura fun awon baba won lati fi fun won. Joshua 1:6 mo le so wipe idahun re yio dabi ti awon omo Israeli ti won wipe " Gbogbo ohun ti iwo palase fun wa ni awa yio se, ibikibi ti iwo ba ran wa lo, ni awa yio lo "Joshua 1:6.
                                                            OHUN TI ITUSILE JE
Leyin ti ati ko awon ohun ti ise iranse itusile ko je, a nilo lati wo awon ohun ti o je. Opo onigbagbo ni o nsa fun, opo tile ko ki a pe awon ni osise ise itusile, gbogbo eyi je nitori pe won ko mo ohun ti itusile je ati ohun ti o je. Iwe Mimo salaye re yekeyeke pe owo onigbagbo gbodo di fun lile emi aimo jade. Matt 10:1.
                                                                EKO ISE ITUSILE
Oro yii "Itusile" ni ale ma ba pade ninu Majemu Lailai, sugbon a le ri awon ise ati afiwe re ninu Majemu Lailai. Ise iranse itusile ni a mo gegebi ise iranse lile emi aimo jade, sugbon lode oni oun na ni a mo ti a si npe ni ise ITUSILE.
Itusile funrare lati inu majemu laelae ati tuntun je oro ti o loyun tabi akojopo oro ti a lo lati fi salaye ominira lowo oniruru isoro gegebi: iwosan, igbala, ominira kuro lowo emi esu. Iwe Woli Isaiah 61:1-4 so yekeyeke awon ohun ti itusile tunmo si:
(1)    Ihinrere fun awon otosi.
(2)    Lati se awotan awon onirobinuje okan.
(3)    Idasile fun awon igbekun (ti Emi ati ti Ara).
(4)    Lati tu awon ti o nsofo ninu.
(5)    Isisile tubu fun awon onde.
(6)    Lati fi oso dipo eeru.
(7)    Ororo ayo dipo ofo
(8)    Aso iyin dipo emi ibanuje.
          Lakotan
Lati salaye awon oro wonyi: A ri wipe No 1 tumosi lati waasu ihinrere fun awon elese, nigbati elese ba ronupiwada kuro ninu ide ese 1Jn 3:8, bakanna No 2 ati 5 nsoro nipa ise iranse igbaniyanju iyen ni lati gbani-niyanju tabi lati tuni ninu eni na ti o ni eru wuwo ninu okan re, sugbon bi o ba gba niniyanju ti okan re si pada soji a ti tu iru eni bee sile kuro ninu ide iberu ati erokero. Nigbati N0 3 ati 4 nsoro nipa titu awon ti aye ati esu ti de sile lati je agbara okunkun ati majemu esu ati lati tu iru eni bee sile kuro ninu iru ide eyikeyi.
Bakanna No 6 titi de No 8 je lati tu ni sile kuro ninu ide osi bakanna ni o tun tumosi lati si eniyan nipo kuro ninu osi si oro. Bakanna a o eo awon isele meji miran, ki a ba le ni oye kikun nipa ohun ti a nse.
(1)   Mose eni ti Olorun ran lati tu awon omo Israeli sile
(2)   Jesu Oluwa wa eni ti ise Messaiah eyi ni olugbala tabi olutusile wa.
                              IFIDIMULE ISE IRANSE ITUSILE NINU BIBELI
Niwon igba ti a ti mo ohun ti itusile je, o wa se dandan fun wa lati wo agbara ti o nbe leyin re. Ni ibi pupo ni Bibeli Mimo ti fi idi re mule paapaa julo lile emi esu jade, Bibeli pelu tun fi idi re mule wipe o je eto fun gbogbo onigbagbo fun apeere: Matt 10:7-8, Lk 9:1, Mk 16:17, bakanna Mk 7:24-30, Lk 13:10-17, Ise Aposteli 19:11-17.
Itusile ni a fi dogba pelu awon ise iranse ti o ku ninu Matt 10:7 ati Isa 61:1-4. Itusile ni a fi si ipo akoko ninu Ase Jesu ninu awon iwe ihinrere meji, paapaa siwaju imularada Lk 9:1 ati Mk 16:17.
                                                       
                                                             PATAKI ISE IRANSE ITUSILE
Ise iranse itusile je ise dandab fun gbogbo onigbagbo nitori awon ohun ti a fe gbe yewo yi, fun apeere:
(1)    O je ase Jesu. Matt 10:1-8, Lk 9:1
   Jesu mo wipe isoro ti o ndoju ko aye loni da lori awon agbara okunkun lati igba ti a ti le esu da sori ile aye ni aye ti ni idojuko nla lati odo won wa. Ifihan 12: 7-10. Jesu mo wipe lati waasu ihinrere lai le emi esu jade eyi ti ko ni je ki won fetisi tabi fokan si iwaasu ti won ngbo, yio kan yori si laala asedanu, idi niyi ti o koko pase lile emi esu jade siwaju awon ohun miran eyi ti o je awon ohun ipilese fun ise iranse.
Omiran nipe leyin ti awon eniyan gbagbo ti won ko si di ominira patapata lowo ijegaba emi esu, bo pe bo ya won yio tun pada sinu ese won tabi (ise won) Jn 8:32. Nitori idi eyi bi enikeni ba di atunbi ti ko si gba itusile lowo oluponiloju, ko iti di ominira patapata. Nitori idi eyi Jesu kan naa yi o pase fun awon onigbagbo lati waasu ihinrere ati lati mu alaisan larada na ni Oluwa ti o pase pe ki a le awon emi esu jade. 1Jn 3:8.
(2)    A maa ran iduro sinsin ninu igbagbo lowo
Eyi ri be nitori eni ti yio le duro sinsin ninu Oluwa ni eni naa ti esu ko di lowo ni oniruru ona re fun apeere:
i.   Nipase erokero tabi ikoro okan
ii.   Nipa aiko le gbadura
iii.  Aiko le gba oye ninu Bibeli.
Satani ninu ogbon arekereke re yio mu ki eniyan maa se sin re si Olorun lai ko si ni ri ere gba. Opo onigbagbo ni o ti pada seyin loni nitori ti esu mu ki o nira fun won lati fi Bibeli si ise. Mase reti wipe esu yio bu ola fun o, esu ti ko tile fi ola fun Olorun sugbon o beru Olorun, nitori bi o ba fi ola fun Olorun gegebi owe Jesu ninu Matt 13:18-39 ko ni gboju gboya ki o wa lo loru lati lo gbin nkan miran, iyen ni eepo sinu ogba Olorun, nitori idi eyi iwo eniyan Olorun, o ye ki o mo wipe ko ni bu ola fun o, o kan le beru oruko Oluwa ninu aye re ki o si salo.
(3)    A ma mu ki igbe aye onigbagbo lojutu
Opo ijo ati opo onigbagbo ni aye won ti kan ti ko si wulo, nitori ti aye won ko lojutu mo, fun apeere:
Ki o so wipe o fe gbadura fun enikan ti o nse aisan, ti aisan na ko si lo nitori emi aimo nbe leyin re, ti eni na ati iwo si ti so wipe oun yio gba Olorun re gbo bi o ba le wo oun san, ti iwo na si ti se ileri pe Olorun yio se ohun kan ninu aye re, sugbon ti o wa je wipe ayafi ki o wo inu adura itusile ko to le ri iyanu yi. Jesu wipe "Ijoba Olorun di afagbara wo awon alagbara si nfi ipa gbaa. Matt 11:12. Olusoaguntan ti o nwasu alafia ninu ebi sugbon ti ko ni alafia ninu ile re.
Tabi oniwasu ti o ko awon eniyan jo ni papa isoji ti o si gba ofa bi o se nsise iranse lowo ti ko si mo ohun ti oun yio se si, yio subu laipe lati ori pepe ti awon eniyan yio si fon ka. Opo awon onigbagbo ni won ko gbadun igbe aye onigbagbo won nitori won wipe "eyi ko se nkan kan" sugbon itusile yio mu ki o le se ohun ti o ba waasu re.
(4)    O ntun aye se ninu Emi
               Itusile yio ran o lowo lati gbe igbe aye ti Olorun yan fun o siwaju ipilese aye. Opo onigbagbo ni Olorun fe lati lo, opo won ni awon ebun emi ti o je iyebiye sugbon esu ko ni gba ki won rin ninu Emi. Won ni ojuse agbayanu sugbon esu yio gbegi dina fun ise iranse won. Won le ni iran fun iranse ile okere ki Olorun tun fidi re mule pelu asotele sugbon sibe won le ku lai je wipe ati owo won jere okan kan fun Oluwa ati lai je wipe ileri Olorun wa si imuse ninu aye won nitori idi eyi aye won i ba mu lati pe Olorun ni opuro sugbon beeko Olorun je Olotito esu ni o pagidina iran aye won.
Nitori idi eyi won di ariran dipo ojise ti o nso iran di ise won ni iran ti o lagbara sugbon won ko le yii pada ki o di ise tabi lati so di ise iranse. Jesu soro nipa iru awon eniyan bi eyi pe "Iba san fun okunrin na bi o ba se pe a ko bi". Matt 26:24.
Bibeli wipe "Emi ni Olorun ati awon ti o nsin ko le sai ma sin ninu Emi" Iyen ni lati gba aye fun Emi Mimo lati se ise iranse si o ati ki o lema gba oro lati odo re wa. Bakanna lati gbaye fun lati segun gbogbo aye ati ohun ti o je, iyen ni Emi, Okan ati Ara. 1Thess 5:23. Nibi ti itusile ba wa, yio ru awon eniyan soke lati gbe igbe aye ti o kun fun Emi Mimo nitori ti Emi Mimo ni ominira lati sise nigbakugba ninu iru aye bee ati pelu ebun emi yio dagba soke.
(5)     O nran itara ti Emi lowo
               Opo onigbagbo ni awon emi aimo nje gaba le lori, debi pe won ko le se ohunkohun ninu ijo tabi fun Olorun yori, idi nipe Satani ti gbe owo le won nipa ti ara ati ti emi. Awon ti o ku ti o wa ninu Emi re yio sare jade awon kan yio farapamo sinu okan awon die ninu ara, awon die yio si jade tan patapata.
                                                            ISE ATI OJUSE WON
1.   Awon ti won jade patapata yio mu ohun ti a npe ni ayo igba die wa
2.   Awon ti o fi ara pamo sinu eran ara yio ma mu oniruru aisan wa
3.   Awon ti inu okan yio ma mu erokero wa.
Awon wonyi ni ogbon esu lati mu ki irin ajo onigbagbo su ni, ki o si pehinda sugbon bi ko ba si emi aimo lati mu aisan wa fun o, bakan na ko si emi aimo lati mu inu re baje tabi ero kero, oko ni irinmole tabi ijegaba, o sun kosi ogun ti o nle o kiri, kosi ohun ti nyo aye ti Emi lenu, o gbadura, o si ri esi gba, iwo yio sin Olorun pelu itara nitori idi eyi itusile nran itara ti Emi lowo.

(6)     A ma ran idagbasoke kankan lowo: Ohun akoko ti a nwo ni pe ise itusile ma nsi oju eniyan si aye keji ni, iwo yio wa dabi pe Angeli ni iwo, sugbon bi o ko ba kiyesara iwo pelu yio ro wipe be lo je. Otito ibe nipe iwo ki i se Angeli sugbon eniyan ni iwo, o kan ma nmu ki eniyan tete dagba ninu Oluwa. Bakanna ni Jesu lo opo asiko leyin ajinde re ti o fi nse itusile pelu awon omo eyin re nipa lile emi aigbagbo, iyemeji ati iberu jade kuro ninu aye won. Ni kete leyin eyi won dagba soke ninu Olorun kankan. Lk 24:47, Jn                                                                                                                                                                              20:19-29; 21:1-7. Nitori idi eyi itusile nran idagba soke kankan lowo.  

No comments: