Tuesday, August 1, 2017

KRISTENI ATI EMI AIMO

                                           KRISTENI ATI EMI AIMO
ILANA ETO EKO NAA
(1)   Nje kristeni leni Emi Mimo?
(2)   Ifiyaje awon emi aimo ninu majemu titun
(3)   Satani Ndena awon onigbagbo
(4)   Awon oun tio mu ki emi aimo teriba

Eko Naa
(1)   Nje Kristeni leni emi aimo? IJEGABA ATI NINI Kristeni le ni emi aimo (Nipa ifiyaje). Sugbon emi aimo ko leni kristeni (11 Cor. 4:4; Eph. 2:2)

Lati ni emi aimo tumosi, pe, eniyan  wa labe ifiyaje tabi pe, emi aimo npon eniyan loju.Iru eyi ti  o le je idojuko ti ara tabi ti emi, fun apere aisan tabi rire (Rom 6:14).

Olorun nipase Jesu Kristi ti fun wa ni ase ati agbara  papa Ipa lati joba iori awon emi aimo ,Nigbati a ba si pase fun won ni Oruko Jesu, won o teriba.  Nigbati okun fa iponju, tabi aisan naa tii se emi aimo ba ti lo, nigba naa ni eniti o wa labe ijiya tabi ide yio di ominira (Mk 16:17; Lk 10:17-19;Rom 6:14 James 4:7, James 5:14-17, Matt 16:23, Lk 22:21, 22, Matt 26:46-50)
      
       Nje omo Olorun nitoto ti a ti gbala lokunrin tabi lobinrin lr ni emi aimo bi?
       Nje kristeni ti o kun fun emi mimo le ni emi aimo bi?

IDAHUN
(a)    BEKO Kristeni; ti o ti di atunbi, ti Jesu si ngbe inu re gege bi Oluwa ti o kun fun Emi ti a baptisi re
         nipa omi ati emi, awon Emi aimo ko le ni.
(b)     BENI! Kristeni kan ti o di atunbi ti a ti baptisi re ninu emi-mimo, ti Jesu ngbe inu re gege bi Oluwa
          ati Olugbala re, o le wa labe ifiyaje/irin mole emi aimo awon emi aimo sile nipase re.
(d)     Eniti kise Kristeni a le fiya je lati ofo awon emi-aimo, mo eyi pe oruko Emi aimo, Emi buburu, Esu a
          nlo won dipo ara won.
               Idahun beni ati beko ti o wa loke yii ni opolopo igba nru awon akeko loju won ti pada wa pelu opolopo ibere ati ariyanjiyan ti o dara, ti o da bi pe awon emi aimo ni won seto re. O han gbangba si gbogbo eniyan labe orun pe imole ati okunkun kole gbe papo nibikan 2Kor 6:14 nigba kanna. Awon ariyanjiyan wonyi ni o jeyo lati inu aini imo nipa eniti eniyan nse, won wa lati inu asiro pe eniyan dabi ile-gbe ti o le gba Jesu nipase emi mimo tabi Satani lekanna. Eniyan kise ile ti o ni iyara kan soso, eniyan je meta lokan tii se emi, okan ati ara. Eniyan je ile ti o ni iyara meta tii se Emi, Okan ati Ara. 1Thess 5:23.

             METALOKAN TI ENIYAN ROMU 8:5-16
(1)        Emi:- Jn 17:22;  10:38, 11Kor 5:19, 1Jn 4:4, Zech 12:1 Emi eniyan ni o wa ni inu iyara tinu lohun,
             nipa eyi ni eniyan fin nmo iwalaye Olorun, eyi ni pe oun nba Olorun soro ninu emi. Nitoripe ati 
             tun emi yi bii, Emi Olorun yio si kun emi eniyan. Romu 8:16. Lojukanna ti a ba ti tun eniyan bi, 
             awon emi aimo ninu emi re yio folo, nitori pe emi Olorun tabi Kristi yio kun eniyan naa, awon  
             miran le sa sinu okan tabi Ara nigbati awon miran yio sa jade patapata.

             ISE WON
(A)       Awon emi aimo ti o wo inu ara ma nfa aisan, ailera ati bebelo.
(B)        Awon emi aimo ti o wo inu okan yio ma fa ero buburu tabi ero ti o lodi ati bebelo.
(C)        Ijade lo patapata ipa keta awon emi aimo wonyi ni omu ayo ati oju rere igba die ba okan igbala  
             bee.

(1)         Emi eniyan ni agbara lati moye ati imo ijinle nipa ohun ti emi, Ede Giriki (Greek) yi ni a npe ni 
              PNEUMA. Emi ni ijinle imoye fun oun ti Olorun, awon ti kosi ti di atunbi je oku ninu ese tabi 
              irekoja gegebi iwe mimo ti wi (Efesu 2:1-4). Je ki awon oku ma sin ara won (Lk 9:29). E o kiyesi pe
              won je oku nigbati okan ati ara won nsise sibe ti o tunmosi pe emi ni o ma n mu eniyan wa laye,
              emi ni o nilo atunbi ti eyi yio si farahan ninu okan ati ara. Eniti ati tunbi yio wa laaye nipa ti emi
              ati oku si ise ti ara ati oun ti ara. Nitori idi eyi eniyan le walaye nipa ti ara ati ninu oye sugbon ki o
              je oku nipa ti emi nitoripe ki se atunbi.

(2)         OKAN: Okan (Soul) ni eniyan funrare, eyi si nise pelu oye, ife (will) re ati irorun ti o lo pelu  
               ogbon re. Oro Giriki fun imoye (okan) ni "PSYCHE" 1Thess 5:23 so fun wa pe eniyan je ipa meta:  
               Okan, Emi ati Ara. Nipa Okan (Soul) ni eniyan ni agbara ninu oye lati yan eyi ti o fe ninu rere     
               (good) tabi buburu (bad/evil). Bibeli so nipa okan (Heart) eniyan Jer 17:9-10 Bikosepe a tun
               eniyan bi, okan re ko le moye ohun rere 1Kor 2:9-16.

(3)        ARA: Ara je eya miran ninu eniyan ti a nri lode, ti o ni awon eya ara ninu ati lode. Oro Giriki fun 
              ara ni "SOMA". Oro yi SOMA fi ARA we eyin (egg) adiye. Eyin (egg) pin si ipa meta ninu eyi ti 
              eepo eyin (shell) bo funfun ati pupa inu eyin lohun gege bi ARA (body) se je aabo fun OKAN   
              (Soul) ati EMI (Spirit), ARA ni a fi we:
                                (a)   Ile (House), Ago (Terbanacle) 11kor 5:1.
                                 (b)   Tempili. 1Oba 8:17-18, Daniel 7:15.

AKIYESI: Ara ni ile (house) tabi tempili ninu eyi ti Emi tabi Okan (Soul) yoo maa gbe titi ayeraye (eternity). Ale fi Ara we oko ofurufu ti o ngbe eniyan yala lati orile-ede kan si ekeji. Eyi ni pe awon eniyan nilati wa ninu re titi won o fi de ibi ti won nlo bee gege ni Okan (soul) ati Emi (Spirit) nilati maa gbe ninu Ara (body) titi iku (death) yoo fi pin won niya. Isa 38:12, 2Pet 1:13. Okan (soul) ni a mo gegebi eniyan gan. Ko si opin fun okan eniyan ati Emi Kristi bi iru eni bee ba je atunbi. Bee gege ni ipele alaigbagbo, okan ati Emi won yoo lailopin (Lasaru ati okunrin oloro).

               Nigbati Jesu ba wo inu aye enikan, o wo inu re gege bi emi, ki ise bi eniyan ti a le ri lojukoju nitoripe oun je Emi (Jn 4:24, 11Cor 3:17, 1Pet 1:4, Rom 8:29, 11Kor 5:19). Okunrin titun yii ni a bi nipa ti emi nigbati Kristi wole taara sinu emi re (Kolose 3:10, Efesu 4:24). Eyi ni Bibeli so ninu Jn 1:12-13. Emi aimo ko lee ni (possess) eniyan titun yii nitoripe Emi-mimo wa ni inu re bayii. Emi-mimo ti ni Emi bayi o si di atunbi, o di eda titun ti a ti gbala. Emi (spirit) re ni iyipada ba Ara (body) ati okan (soul) re si wa bi o ti wa tele. Idi  niyi ti o fi se pataki ati dandan lati dide sise karakara fun igbala awon miran. Lojukanna ti a bi okunrin titun yii ni Emi-mimo yoo fi edidi dii. Gal 3:28, Efe 1:13-14 (mo wipe eda tuntun yii ni a ti fi edidi dii.

OKAN (MIND) ATI ARA (BODY): Okan ati Ara ni ipa meji ninu aye eniyan ti igbala ko kan (inulator/shield). Nitori idi eyi awon emi aimo si ni anfani lori okan (soul) ati Ara (body) onigbagbo. Ore mi won ninu Kristi, opolopo ni ero (thoughts) ati ihumo (imaginations) ti ko mo (pure) ninu re ti o ti nwa isegun le lori lati opolopo odun wa ti o ko tii segun won. Bi o tile je pe o jewo opolopo ileri Olorun gbogbo, oko tii bo lowo awon isoro wonyi nitoripe isoro naa ko rorun bee bi o ti ro pe won ri ti emi esu nii won, ko sile isegun lee titi ti a o si le won jade. Ara (flesh) mo agbelebu. Awon emi-aimo wonyi ngbogun ti Emi (spirit) Okan (soul) ati Ara (Body) alaigbagbo, sugbon okan (soul) ati Ara (body) ni won le gbogun ti ninu onigbagbo (okan) soul, inu (mind) ise (emotion) ati ife (will), nigbati won ba si yori igbogunti won, won yoo pa ago (tents) won yoo si maa dari tabi joba nibe.

Awon apeere die ni wonyii:
Isele- Peteru ati esu (Matt 16:13-25); Anania ati Saphira (Ise Aposteli 5:1-10). Bi awon emi-aimo ba lee wo. Inu Olori awon Aposteli, Peteru, ti won soro lati inu re, ti ko si mo rara, ti won kun inu re ti won si nsise lati inu re, a woye pe arakunrin Anania ati arabinrin Saphira je omo ijo nibiti Bisobu Peteru ti je oluso aguntan agba. A si tun woye pelu pe won ti gba iribomi ti Emi mimo ni igba Pentikosti laarin awon ogofa omo ehin ni iyara oke (Ise Aposteli 2:1-4).

           Ni akoko isin ti Bisobu Peteru dari, ko si enikan ti a ko se iribomi fun (Ise Aposteli 8:14-17). Won je alabapin ninu eko bibeli lori idagbasoke Kristeni ati isegun lati owo eni owo julo (Reverend) (kefa) Simoni Peteru ati awon Aposteli yoku (Ise Aposteli 1:41-42). Sibe, okan (mind) tokotaya wonyi kun fun emi-aimo ti ireje, ojukokoro, iro pipa ati itanje ati bebelo. Awon Kristeni ti Korinti, ti won ko se alaini ebun emi kankan paapa bi won ti nreti bibo Jesu Oluwa si wa ninu ara sibe pelu awon emi-aimo ti ilara,  aso ati iyapa. (1Kor 1:7; 3:3; 5:1). Wo ayika re, laarin awon omo igbala, iwo yio ri opo ti won si wa labe ifiyaje agbara awon emi-aimo. awon ailera ti a le foju ri miran wa ti won kii san (cured) titi eni naa yio fi gba itusile lowo awon emi-aimo ti o wa lehin isoro bee (Owe 26:2, Lk 13:11-13).
            Nigba ti a ba nse itusile fun eniyan, anfi tipatipa le awon emi aimo jade lati mu imoye (intellect) ise (emotion), ati ife (will) (soul man) nipa Emi Olorun ati ase ti Balogun igbala wa fun wa, ani Jesu Kristi (Mt 16:17), ki Jesu ba le joba lori gbogbo ibi ti emi aimo ti jade, ki o si je Oluwa lori aye (total man) bee. Idi niyi ti a fi ni lati jowo ara wa fun itusile, ki a je ki Jesu joba lori Emi (Spirit), Okan (Soul) ati Ara (Body) wa ni ijoba patapata. Eto Olorun ni pe ki Emi joba lori eniyan. Idi niyi ti Okan (soul) ati Ara (body) fi gbekele Emi (spirit) fun iwalaye. (1Thess 5:23).

2.      IFIYAJE NI EMI-AIMO NINU MAJEMU TITUN
          Ninu eko yii, a ti kiyesi pe awon emi-aimo lee gbogun ti Kristeni ati lati pon on loju, a ti kiyesi pelu bi awon emi-aimo ti nsise ninu aye awon onigbagbo: Ninu gbogbo (soul) aye awon alaigbagbo ati Okan ati Ara (body) onigbagbo nibi ti agbara won pin si. Bawo ni awon emi-aimo se pon awon Kristeni majemu titun loju?. Awon apeere:
1.       Won pon awon omo obinrin Abrahamu loju nipa emi ailera (Lk 13:11-23).
2.        Egun ninu ara Paulu. 2Kor 12:7-10
3.        Satani dena Paulu lati ma lo be ijo Tessalonika wo (1Thess 2:18) Eyi ni nipa isele

3.        SATANI NDE ONIGBAGBO LONA: Satani lee dena (hinder) onigbagbo ni opolopo ona:
1.        Satani le fi emi ailera de eniyan, eyi ti o le je iponju ti a foju ri gege bi awon aisan, awon isoro owo   
            ati bebelo. Nitoripe Satani/esu fe ri daju pe aye onigbagbo ko se dede ni ona Oluwa Olorun (Lk
             4:39; 6:17, 18).
2.         Sisoro lati inu onigbagbo. Awon emi aimo le so oro odi si o tabi lati inu re nipa lilo ohun (voice)
            elomiran bii Peteru (Mt 16:23) ati lati kun okan eniyan (Ise Aposteli 5:1-10).
3.         Satani le dena onigbagbo nipa awon isele ayika. 1Thess 2:18.
4:        Satani le se idena nipa fifi ohun kan dipo ekeji, fifi buburu dipo ire (good).
5.         Nipa iyiriwo (trials), idanwo (temptations) Mt 4:1 ati iporuru okan (discouragement) Heb 3:6, 10.
6.         Satani maa ndena awon emi ise iranse (ministering spirit) tabi awon angeli. Dan 10:12-13.
7.       Satani maa ndena nipa pipa ara (flesh) awon onigbagbo run. 1Kor 5:1-14
8.       Satani maa nse idena nipa pipa awon ohun ini awon onigbagbo run. Jn 10;10, Job 1.
9.       Satani ndi awon onigbagbo lowo nipa kiku won danu bi alikama. Lk 22:3-32.
10.     nipa kikoran onigbagbo. Jakobu  3:14-15.

4.      AWON OHUN TI O MU KI EMI AIMO TERIBA
         Lati je iranse itusile, awon ilana kan pato wa ti awon emi-aimo ati esu baba awon maa n teriba fun. Kii se lati ma bebe pe ki emi-aimo jade, dipo eyi, a maa npase ni oruko Jesu ki won jade. Lk 10:17-19. Jesu pelu ase re doju ija ko ota yi (emi aimo) ninu aye awon eniyan re. Ninu iru awon isele bayi, awon emi aimo le mu ki iru eniyan bee kigbe, pariwo, tabi se agidi nigbati awon emi naa ba fe jade (Mk 9:20, Lk 4:33-36, 41). Awon omo eyin pelu lo iru ona yii kanna nipa pipe oruko Jesu lati fun won ni ase lati le awon emi aimo jade (Lk 10:17-18).

AWON ILANA NAA
1.    IGBAGBO: "Igbagbo" yi pin si ona meji
        (a)  Igbagbo ti igbala: ko see se fun elese (eni ti ko tii ni igbala) lati le emi esu jade. O di dandan ki a  
               tun e bi, igbala re ni lati daju, a ni lati mo o ninu ijoba Olorun, ninu aye ati ni orun apadi pe Omo
               Olorun ni o (Ise Aposteli 19:1-11, 14-17, Jn 1:10-12, 1Jn 5:11-12, Mk 16:15-20, Ise Aposteli 4:12).
       
         (b)  Gbagbo, ni igbagbo ninu Jesu Kristi: ko si oruko miran ti awon emi-aimo ati Satani baba won
                nteriba fun yato si oruko Jesu Kristi. O ni lati gba oruko naa gbo, ki o ni igbagbo ati igbekele ninu   
                re pelu. Isa 61:1-4, Mk 16:17-18, Fillippi 2:5-10.

2.     ORUKO JESU FILLIPI 2:8-10

3     IFAMIOROROYAN (Ifamiororoyan ni o nja ajaga) Isa 10:27. Emi mimo nsise ninu aye wa nipa    
        ifamiororoyan, nipa re si ni awon ajaga ifiyajeni emi aimo ninu aye awon eniyan nje sonu. Eniyan le
        kiyesi ifamiororoyan yi lojokojo tabi moye re ninu emi. Nigbakigba ti eyi ba sele, ki i se akoko lati ma
         gbadura bikose lati maa pase ati lati pede (pronouncements) ti yoo wa ni imuse ninu isele aye re.   
         Apere eyi ni ari ninu Esikeli ni afonifoji egungun gbigbe Esikeli 37:1-10. O kiyesi ifarahan Olorun ni  
         ona ti o yato, o si bere sii so awon asotele. Nigba ti o ba kiyesi ifamiororoyan Emi mimo; o le bere
         sii pase itusile, ibukun, isegun lori ara re ati idajo lori awon ota re (Isa 54:17, 15,16,14, 1Jn 2:20, 27).

4.      ORO OLORUN: awon emi-aimo miran ti won maa nse ariyanjiyan maa nbere fun eri (proof) lati  
          inu oro Olorun ki won to jade. Lk 4:4,8,10,12.

5.     AWE ATI ADURA: Awe ati adura ti o ba bibeli mu se dandan gegebi ilana ti awon emi esu maa  
          nwariri (tremble) niwaju re. Matt 17:21.

6.     IJOWO ARA ENI FUN OLORUN. Jakobu 4:7, 11Kor 10:6.

7.     AGBARA ATI IFOWOSI (APPROVAL) OLORUN: Olorun ni alagbara julo o si lagbara lati ran   
         enikeni ti o ba fe lowo nigbakugba. Agbara Re ko ni odiwon nitoripe o ni gbogbo ini orun ati aye ni
         ikawo Re. Neh 1:7.

8       IWA MIMO: Olorun je mimo; awa iranse re pelu gbodo je mimo. Iwa mimo ni sisa fun ese ati lati     
         maa gboran si Olorun lenu. Jn 15:10, 1Pet 1:13,14,15,16,17-19.

9       ASE (AUTHORITY): Ase Olorun lenu yoo le emi-aimo jade bi o ti wu ki ipo re ga to bi o ba gbekele    
          Emi mimo nikan. Ase Olorun lenu re gbodo ni atilehin iwa mimo. Mt 7:29, Prov 29:2, Mt 8:9,20;   
          25:21-23, Mk 1:27; 13:34, Lk 9:1; 19:17, Jn 5:27.

Akiyesi: Oniruru ni awon emi esu awon emi aimo ojewere emi aimo oloye. Awon ligioni (Legions) Balogun awon egbegberun (Batalioni) bi won se gbarun yala si ara won.
          A ko jiyan pe ise iranse itusile nikan ni ona iwosan tabi pe ki o je olori awon ona iwosan yoku sugbon ireti wa ni pe a o fi aye gba gege bi alabasisepo pelu awon ise iranse yoku. A si tun nwona fun ojo na fun apeere ti awon iranse Olorun ni ibasisepo pelu awon onisegun oyinbo ati awon Dokita arun opolo yoo parapo ninu isokan ati igbekele lati ri bi adura itusile se lee se iranwo. Eyi yoo nilo isipaya okan lati samulo re gege bi ona iwosan pipe.



No comments: