Monday, November 5, 2018

ITAN IJO


CHURCH HISTORY
ITAN IJO
AFIHAN/ORO AKOSO:- ijo Kristi ni a bi sinu aye ti o ti di ogbo, oniruru awon ijoba gbaye ni o ti lale wu, ti o si ti kogba sile ni ara won ni wonyi: Egipiti, Babloni, Asria, Persia ati Giriki ki o to kan Romu ti o je wi pe ohun ni o ndari ijoba agbaye, nigba ti a fi se idasile ijo ninu idasile ijoba Romu yi kan na ni o ti lo edegbeta odun re akoko.
            Ki a to bere si ni so oro nipa ijo, o se Pataki ki a loye awon isele ti nsele ninu aye eyi ti ijo dagba ninu re, ti a ba soro nipa ijo a gbodo ri awon eni ipe jade, eyi ti o tumo si ijo je awon eni ti a pe jade lati inu aye, esu, ese ara ti a sir a won pada nipa eje Kristi Jesu ti o ta sile ni ori Oke Kalfari.  Ijo Jesu Kristi ni o beresi ndagba ti o si ngberu lati ofofa eniyan (120 peoples) ti a ni ki o duro ninu yara oke ni Jerusalemu.  Ijo je awujo awon eniyan to po ti owo ja re si de oniruru ilu ninu aye.
            Ijo dabi irugbin eyi ti a gbin ti o dagba lati idi igi nla ti awon eye oju orun ati oniruru ohun abemi nlo fun ibi aabo, ibi isadi ati oniruru awon anfani miran.  Ijo Kristi wa di ibi aabo fun gbogbo awon onigbagbo bi Ijo Kristi se ngberu yi ni o ndojuko oniruru inunibini lati odo awon ijoba, awon Ju ati awon Keferi pelu.
            Empire ni an pe ni isakoso gbogbo agbaye.
            Awon 120 ni o wa ni yara oke, Awon 3000 ni won koko yan kun won, Awon 5000 ni won tun pada yan kun won lekeji, apapo re ni 8120 ni gbogbowon diedie ni ijo Olorun npo si.  Awon ti o ko ijo ti ku sugbon ise won nfohun sibe.
A BI IJO JESU KRISTI
IPILE IJO NAA: Gege bi itan majemu laelae nibe ni a ti ri nipa ileri mesaya awon akosile nipa igbe aye Jesu Kristi gege bi awon iwe ihinrere se ko ati akosile iwe Ise Awon Aposteli ni o fun wa ni ekun rere nipa itan ti ijo Jesu Kristi – Isa 9:6 – 7, Isa 11:1, Ise A. Ap 2:1 – 4, Mt 16:18, Ise A. Ap 1:8 – 14, Gen 12:1 – 4, Gen 3:15 – 16 nigba ti akoko to fun Olorun lati se afihan ara re fun iran eniyana o yan Abrahamu ki o ba le bere pelu re lati inu eya awon Heberu lati ipase Abrahamu yi niOlorun ti pinnu re pe a o bi ijo majemu titun. Gal 3:8.  Bi iwe mimo si ti ri tele pe, Olorun yoo da awon keferi lare nipa igbagbo, o si ti waasu ihinrere saaju fun Abrahamu, o hun wi pe, ninu re ni a o bukun fun gbogbo orile ede.  Pelu ese oro Olorun a mo pea won Heberu gbagbo ninu otito ti majemu laelae, a si fi Jesu han fun won gege bi isipaya Olorun ti o ga ju lo – Heb 1:1 – 2.  Jesu Kristi yi naa ni o wa awon eniyan re ti se Ju, won si ko eyi ti o fun awa keferi ni anfani nipa ihinrere ti a si gbagbo Jh 1:11 – 12.
IJOBA AGBAYE ROMU
            Ninu ijoba Romu ni a bi ijoba ti Kristi si, Ijoba Romi yi ni o je ijoba ti oni agbara, ti owoja rre si san de opolopo ilu ati England si Pewrsia, lati Sahara de iwo oorun Gamani (Germany).  Okun meditariania nigba naa ko da bi o ti se wa loni, nitori owoja re san de opolopo orile ede o si je omi eyi ti o so ekun ati elekunjekun mora won, opolopo ilu tabi orile ede ti o ni itan ti o saju ti Romu, ni Romu nsakoso won pelu gbungbun isejoba agbaye yi ni ilu Romu, ni ile Romu yi bakanna agbara isejoba nbe ni owo eni ti a npe ni “Emperor” eyi ti o tumo si Aare gbogbo agbaye.
ISEJOBA TI IJO
            Ki o to di 27BC gbogbo elekunjekun Romu ni a nse ijoba re nipase liana ijoba ti a npe ni Republic ti o tumo si olominira.  Ni inu re ni awo asofin ti ni agbara lati yan Emperor ko si enikan ti o le da se ijoba laisi owo igun miran nibe ni 27BC ewe leyin ogun abele ti o gbona janjan fun bi ogorun odun, agbara isakoso Romu ni o bo si owo “GIUS OCTAVIANUS.  Gius Octavianus yi ni a mo ninu itan gege bi Kesari Augustus 1, ohun ni o si ti ni agbara ti o po ju laarin awon asejoba agbaye odo re ni Republic pari si o si je Aare agbaye lati 27BC si 14BC.
LATI DAFIDI SI ALESANDA
            Ijoba ti Israeli ti a ti owo Dafidi omo Jese se agbekale re 1000BC ti Dafidi si joba lori re fun ogoji odun, ijoba yi ni Dafidi ko fi owo degree mu rara nitori ohun ni o je ami Israeli eyi ti o ni ireti nla mesaya.
            Leyin omo Dafidi ti a pe ni Solomoni nnkan bi 930BC ijoba ti a ti owo Dafidi se agbekale re ni a pin si ipa meji
1.              IPA ATI ARIWA – NORTHERN KINGDOM:- Awon ni a npe oruko won ni Israeli awon ni ese gogo ninu aye won, won je eya ti o ba Jeroboamu lo, opolopo ise ore ofe ni a ran si won, ti o ye ki o mu won ronupiwada, nitori opolopo woli ni a ran si won fun ironupiwada ati iparun ti o nbo laipe, sugbon won ko gbo ti won.  Leyin oreyin awon Asria wa won ko won lo sinu igbekun Asria ni 72 1BC ni inu igbekun yi ni won si segbe si ti won ko si pada wale mo titi di oni.
2.              AWON TI GUSU:- Awon ni a npeni Juda, awon wonyi ni won je olooto si ile Juda won si ni igba ati akoko togun ju ti awon ile Israeli, awon wonyi sin Olorun die nitori ariwa oba to mo Olorun laarin won, Josiah, Hesekiah, ati be be lo.  Nigba ti odi 586BC Juda naa ni a ko lo si ile igbekun Babloni ni 539BC oba kan je ni Persia ti a pe oruko re ni Kirusi oba yi ni o fun Juda ni oore ofe pe eni ti o ba fe pada sile ninu won, won le pada si Jerusalemu eni ti o ba si fe duro ninu won le duro ni Persia, sugbon ko fi ide de won.
            Leyin ipada wale awon omo Israeli lati ile ajeji, okan Pataki gbogi ti o pada wale ni a pe ni Ezra, olori won tabi adari won ni Alufa si ni pelu eni ti o fi ojo aye re jin si ofin Mose ti o si n lakaka ki ofin le di apakan liana awon omo Israeli.
            Awon Farisi ti a nba pade ninu awon iwe ihinrere ati ninu iwe Ise A. Aposteli ni won dagba lati inu liana lati da awon omo Israeli pada sinu ofin Mose laarin 334 ati 323BC iyen nip e fun ofun mokanla ni Alesanda ti o je odomokunrin Makedonia ni o gba ijoba mo awon ara Kirusi lowo, Alesanda yi ni o ku ni odun 323BC ni eni odun metalelogbon (33yrs).
AWON MAKABIOSI
            Leyin igba ti awon omo Israeli ti pada de lati inu igbekun Babiloni, ni awon Ju ti n tele ofin Mose gege bi Ezra se nko won.  O to akoko kan nigba ti awon Giriki fe fi tipatipa mu won lati tele liana ati asa ase awon ara Giriki olori awon to fe mu won tele ase miran ni a npe ni oba Anti Chusi IV.  Anti Chursi IV ni o gori oye ni 175BC, nigbati awon Ju ko tele ase ati asa ti o gbekale wahala ati ija igbooro ni o  tele.
AWON OHUN TI OFA WAHALA NA
1.        Se ni won gbe awon asewo wa si inu tempili lati ba ibi mimo je.
2.        Ofin atowodowo awon Ju ni won gbese le wi pe won ko gbodo se ikola mo.
3.        Eyi ti o buru ju ti o si bani lokan je ni wipe gbogbo iwe ofin Oluwa ni a dana sun ni gbangba.
            Wahala laarin Makabiosi ati Oba Antichusi IV yi ni o bureke ni 168BC nigba ti Olori awon Ju ti o si je Alufa agba ti a pe oruko re ni “Mattatias” eni ti o ni awon omokunrin marun ti a npe oruko won ni Makabiosi, itumo Makabiosi ni awon to nja takuntakun tabi Oolu.
            Ni 141BC ni awon Ju gba ominira patapata lowo awon ara Siria ti se ota won fun igba akoko lati 586BC ni Israeli di orile ede olominira odun mejo pere ni won si fi lo ominira yi. 
            Ni 63BC ija abele ni Jerusalemu ni ofi aaye gba awon ara Romu lati gbe ase won kale nibe fun bi ogota odun to tele ni Israeli fi wa ni ominira laabo.
            Ni 37BC ni Herodu akoko tabi Herodu agba ti o di Aare apase akoko pelu ifowosi awon ara Romu, Herodu akoko naa ni o si njoba nigba ti a bi Jesu ni 4BC.  Leyin iku Herodu ijoba re ni a pin laarin awon omo re mejeji omo re akobi ti a pe ni “Archelaus” ohun ni a fun ni awon agbegbe Juda, Samaria ati Idumea, omo re keji ti a pe ni “Amtipas” ni a fun ni agbegbe Galili.
            Ni 6AD Archelaus ni a ro loye nitori awon iwa toyato si alaafia ati imuduro ofin naa aro loba alekuro, nigba naa ni won mu lo si ile ajoji agbegbe re ni o wa di agbegbe awon ara Romu ti a si yan ajele si ibe.   Lati AD26 – AD36 ajele ti a yan si agbegbe Judia ni a npe ni Pontiu Pilatu.
AWON SINAGOGUE ATI SAHENDRI
SINAGOGUE:- Ki awon Ju to lo si ile igbekun ni 586BC ibi ijosin awon Ju ninu tempili nla ti Jerusalemu leyin ile igbekun ibi ijosin awon Ju ni synagogue ti a si nri kakiri ni gbogbo ayika ati ayida won.
            Ni Babiloni ni a ko ti fi aaye gba, awon Ju lati wa si Jerusalemu lati wa join ohun ni won se ni awon ile ijosin kereje kereje lati wa josin, fun adura gbigba, a nlo fun oro Olorun ati fun idanileko.
SAHENDRI:- Igbimoto gaju ti awon ju ni a npe ni Sahendri igbimo yi je igbimo Alaadorin (70 men) igbimo yi ti a pe ni Sahendri ni a pe ni “jijoko papo” bi o tile je ijoko papo won yi abe ase awon Romu ni igbimo aladorin ni won nse akoso nipa oro esin ati isakoso ilu igbimo alaadorin yi ni a ti ri awon Farisi ati Sadusi won njoko papo labe Alufa agba.
FARISI ATI SADUSI
            Awon Farisi ati Sadusi ni Olori awon Ju lati igba Makabiosi wa.
AWON SADUSI
            Awon Sadusi yi ni won wa lati idile Alufa won si je gbaju gbaja agbejoro, ona tijo ni won ntele, won ko si fi aaye gba ohun ti won npe ni ayipada, bi o tile je pe won tele ilakaka awon Makabiosi, wo inu ilana awon Ju.
BI A SE NMO AWON SADUSI
1.        A mo won nipa liana esin gege bi awon ti ko gba eko, won gba pe ko si eko yato si ohun ti ofin ba so.
2.        Won ko gba ohunkohun ti a pe ni angeli tabi emi gbo.
3.        Won gbogbo wi pe ko si ajinde, iyeni nip e ti eniyan ba ti ku emi re segbe pelu re, leyin aye ti a wa yi ko si aye miran, awon Sadusi yi ni a ko gburo won mo leyin isubu Jerusalemu ni 70AD
AWON FARISI
            Ni gbogbo ona ni awon Farisi fi yato si awon Sadusi
1.        Awon Farisi won ko wa lati idile Alufa.
2.        Agbejoro ni awon Farisi sugbon won gbagbo pe a le se atungbeyewo ofin.
3.        Won ko fi aye gba esin ati asa atohun rinwa, iba je ti Giriki tabi ti Romu..
4.        Won gbagbo ninu ajinde, aye titun ere fun ise wa ati idajo fun ise buburu.
5.        Won gbagbo ninu ofin atowodowo lai nani igbe aye temi.
6.        Ilana ofin atowodowo ni won gbe igbe aye won le, won ko gba pe eniyan le gba imisi tabi isipaya tie mi.  Abala yi ni o nfa atako nipa igbe aye won ati ti Jesu Kristi.  Awon Farisi yi naa ni a ko gburo won mo leyin isubu Ju bakanna pelu.
IMURASILE FUN IJO
            Ninu Galatia 4:4 – “Sugbon nigbati akoko kikun naa de, Olorun ran omo re jade wa, eni ti a bi ninu obinrin, ti a bi labe ofin”.   Lati inu oro Olorun oke yi o se afihan pe Olorun ti se awon imurasile ti o dara ki a to ran omo re tise Jesu Kristi si aye, Olorun ni lati baa won liana kan nipa ti ara ati nipa ti Emi pade ki o to di wi pe ijo bere, awon liana ti Olorun ba pade naa ni wonyii:
1.        Ijoba Romu lonse akoso gbogbo agbaye – Lk 2: 1 – 4
2.        Sise atunse awon oju ona ati ori afara Mt 3:3
3.        Sise akoso awon ole oju omi – Mt 3:3
4.        Didabo bo awuju lowo awon adigunjale ati awon elewu eniyan
5.        Awon Giriki ni won ntan kakiri agbaye
6.        Ede Giriki ni o die de to gbaju-gbaja kakiri agbaye.
IBERE IJO
            Ni Jerusalemu ni a ti ko gbo nipa itan ijo majemu titun Ise A. Ap 2:1 – 4, 2:8, o soro lati so wi pe ojo kan pato ni itan ijo bere, nitori ti a ba ni ijo bere ni ojo pentikositi a je wi pe a gboju fo igbe aye, eko ati igbe aye Jesu Kristi.
            Ti a ba wa so pe ijo bere pelu Jesu Kristi a ko gbodo gbagbe wi pe, igbe aye, eko ati igbe aye Jesu Kristi wi pe o dagba lati inu liana awon Ju ni, nitorinaa ni wipe ohun ti o dara ju fun wa lati so ni wi pe ijo hu jade lati inu igbe aye eko ati ise iranse Jesu Kristi ti o si di ohun ti gbogbo aye je eleri re ni ojo pentikositi – Mt 16:18 siwaju si Ise A. Ap 1:47, Ise A. Ap 2:1 – 4.
BI IJO SE NGBORO SI
            Leyin iriri ibujade ti Emi mimo ni ojo nla ti Pentikositi ijo ti Kristi bere si ni gberu, a ko gbodo gbagbe wi pe titi dioni ni ijo ngboro si.  Awon nnkan to nmu ijo gbooro tabi gberu si ni wonyii:
1.        Peteru wasu ogooro awon eniyan ni o si yipada ti ise ami ati ise iyanu si tele iwaasu na.
2.        Afihan Olorun taara si Peteru nipa ki awon keferi o darapo mo ijo – Ise A. Ap 10:1 – 48
3.        Siso lokuta ti a so Stfanu lokuta ati inunibi Saulu ti o dide si eniyan ninu ijo akoko oun lo fa ti a fin mu ihinrere lo si odo awon kereri ati aladugbo won Ise. A. Ap 6, 7 8.
4.        Awon Ju ti a tu kaakiri ti won ni oye iriri isele ojo pentikositi ni won mu ihinrere Jes Kristi lo si odo ore ati aladugbo won.  Ise A. Ap 8: 5 – 6, 26 – 40.
5.        Awon Ajinhinrere ti a pe naa ni won mu ihinrere lo si odo awon keferi ati awon aladugbo won. Ise A. Ap 9:1 – 43.
IJO NDANGBA SINU
            Lati 33 – 325AD ni io fi ndagba sinu idagbsoke ijo ni se pelu eko ati awon liana re.  Eko ati liana agbekale to dara nitori ninu won ni a ti nloye otito Olorun ni a n wipe eko agbekale to dara ni a n mo nipa liana to dara.  O ti mu oniruru ede aiyede ati ikolukogba wonu ijo Olorun.  Bakanna ni jo ti ko ba ni eko ni won yoo je ope si awon otito ti o si igbagbo mu.
            Ni inu itan ijo awon merin kan se Pataki a npe won ni awon Baba Aposteli nitori wi pea won Aposteli fun ra won ni won ko won leko, awon merin na ni wonyi:
1.        Clement ati Hermas ti Romu
2.        Ignatius ti Antioku
3.        Polycarp ti Syria
4.        Barnabas ti Alexandria
            Nigba ti ijo yoo fi ni ifidimule oniruru awon eko ni o ti fidimule kakiri ni inu awon eko wonyi awon miran je ojulowo awon miran ko si je ojulowo eyi ni awon ijo fi fie nu ko si awon nnkan meta yi.
1.        Creed – ijewo igbagbo
2.        Cannon – Iwon tabi tito
3.        Method – Eto
IJEWO IGBAGBO
            Oro yi Creed ni a mu lati inu ede Latin. 
Latin – “Credo” – Creed – Ijewo igbagbo eyi ti o tumo si “mo gbagbo” (“I belief”)
IWON TABI TITO
            Oro yi ta mo si “Cannon” ti a mo si Iwon tabi tito” tabi osuwon.
METHOD – ETO
            Ni abe eto yi ni ijo ti gbagbo wi pe o ye ki eto o wa fun ohun gbogbo ti won ban se ninu ijo Olorun ti si fi agbara ati ase adari se atileyin rre awon adari ninu ijo ni a gbe ase yi le lowo lati se eto hun gbogbo bi o ba ti ye.  Adari yi le je olusoaguntan tabi oludasile ti a fun ni ase lati seto ohun gbogbo.  Ni ii ti a ba ti seto ohun gbogbo bi o ti to ati bi o ti ye, awon ayipada ati awon atunto ti o to ati ayipada ohun rere ma nfi ara han nibe.
IJO TI JERUSALEMU
            Ni Jerusalemu ni a ti ko gbo nipa ebi onigbagbo ni ibi ase ajo irekoja (feast of Passover) ti o pada wa di ase ajo isokale Emi mimo (feast of pentecoast).  Ose meje leyin ikanmo agbelebu Jesu Kristi tabi ojo kewa leyin igoke re orun Jesu Kristi.  Ijo ni ibere pepe je awujo awon eniyan kereje ti won ngbe igbe aye won ni idapo ati iran ra eni lowo ti a si nyan kun won lojoojumo iye awon okan ti a ngbala Ise A. Ap. 2:42 – 47, iwaasu won oje iwaasu ti ko le rara ohun ti o si dale lori ni ironupiwada kuro ninu ese ti won sig be iku ati ajinde Jesu Kristi laruge, ti won si tempele mo ajinde ati iribomi.  Iwaasu won ni o duro lori awon nnkan wonyii:
1.        Ibi Jesu lati odo wundia
2.        Igbe aye Jesu ati eko re
3.        Ijiya ati ikanmo agbelebu re
4.        Ajinde Jesu
5.        Igoke re orun Jesu Kristi
            Ifitoni leti wonyi ni ise ami ati ise iyanu si ntele eyi ti o sin mu iyipada okan fun awon keferi ti opolopo awon woli (Alufa) si nyipada pelu.
AWON ONIGBAGBO HELENI ATI HEBERU
            Ni kop e ko jinna leyin ibere to ni ileri to dara yi iwe Ise Awon Apositeli se akosile awon isele meji ti o fe ba ibasepo ijo akoko je, awon isele naa ni wonyi
1.        Ese Ananaya ati Safira ti a se akosile re ninu Ise Awon Aposteli ori karun ese ikinni de Ikokanla Act 5:1 – 11.
2.        Aidunnu awon Helene si awon Heberu arakunrin won eyi ti a se akosile re ni Ise A. Ap 6:6.
                        Isele Ananaya ati Safira je isele ti o de bani lojiji, sele yi ko sele si aarin awujo awon Kristieni o sele labe abala kan. Ifisun tabi ifitoni leti awon Helene si awon arakunrin won je isele ti o yato patapata, o je isele ti o sele lati fi iyato han laarin ijo Olorun funrare, o je isele to nise pelu ede aiyede ti o sele laarin awon Kristieni Ju ti Jerusalemu ati awon Kristeni miran awon ti o wa leyin ikolo si ile igbekun (Helene) a gbodo loye itumo awon oro wonyi “Heleni” “Heberu”.
            Oro yi Heberu ni a lo ni ibi meji ninu majemu titun ninu itokasi awon Juu.  Awon ti a npe ni Heberu ni awon ti o je pe ni gbogbo ona ni won fi ntele ofin Mose, won gbagbo ninu re won si ngbe igbe aye won gege bi liana asa awon baba won.
            Awon Heleni ni awon Ju ti won pada wa nigba ti won kuro ni ile igbekun ti won si gba asa ati ise awon ara Giriki gbo.   Oro yi “Heleni” ohun ni a mu jade lati inu ede Giriki “Hellas: ti itumo re je Giriki.
            Aidunnu ti o wa laarin awon Giriki ati Heberu ni o je afihan iyato laarin awon Ju ti a ko ko lo si ile igbekun ati awon Ju ti a ko lo si ile igbekun ti won pada wale.  Awon ohun ti o sese ki o fi aaye aidapo laarin awon Ju ati Heleni nibi ipinfunni ori tabili ohun ni awon nnkan meji yi.
1.        Ofin nipa ti ase
2.        Iyato laarin asa
            Aini idapo nibi ipinfunni ounje yi ounn ni o si mu iyapa wa laarin won.
IKEDE IHINRERE KOJA JERUSALEMU
            Itu kaakiri opo Kristieni lo si awon agbegbe miran ohun ni o se okunfa bi ijo se ngberu ti o koja lati Jerusalemu lo si ekun ibomiran, Filipi ni o koja lo si Samaria ti o lo wasu nibe, eyi ti o mu ki ijo ti Jerusalemu ran Peteru ati Johannu lo si Samaria lati lo se ayewo awon ilu kereje kereje ti ekun Samaria.
            Filipi ni a pe lati lo si Gasa ni apa Gusu ti Jerusalemu nibi ti o ti salaba pade iwefa ara etopia ti o wasu fun ti o si se iribomi fun pelu – Ise A. Ap 8: 5 – 6, 26 – 40.
            Peteru ni o lo si ekun Joppa ati Kesaria ti o lo wasu nibe, awon abewo si awon ilu wonyi ni o se okunfa ti o fi loye isele ojo nla ti pentikositi nibe ni o ti loye wi pe ati keferi ati awon Ju ni won le di omoleyin Kristi ti a si le gba won bi omo Ijo – Ise A. Ap 10:44 – 48.
            Nitori idi eyi ni o se se iribomi fun eni ti ki se Ju ti o je keferi ti a pe oruko re ni Konieliu, Konieliu yi ni a pe ni balogun orun ti o si je ti egbe omo ogun Romu, nitori isele to sele nile Konieliu ijo ti Jerusalemu yi ni won ranse pe Peteru ohun tori lobe ti o fi gaaru owo, eyi ti o fun Peteru ni anfani lati salaye ohun ti o sele nile Konieliu Ise A. Ap 11:1 – 18.
IJO NI JERUSALEMU NDINKU
            Pelu gbogbo ilakaka ti Filip, Peteru ati Johannu ati awon akegbe won lati waasu ohun ti a pe ni ihinrere ponnbele, ijo Jerusalemu ndinku ko gberu.
AWON IDI TI O FI NDINKU
1.        Ijo Jerusalemu di ijo eleyameya – won so ijo di ti awon Heberu nikan.
2.        Awon Heleni ti won pada wa si Jerusalemu leying igba ti innibini ti koja won ko pada dara po mo won, awon Ju ko fe ki awon Heleni ba won se, eleyameya si le to be ge ti Peteru fi nberu lati jeun pelu awon Kristieni keferi ti o ku ni Antioku, nigba ti awon ara lati ijo Jerusalemu wa se abewo si won ni Antioku – Ise A. Ap 11:   , Gal 2:11 – 14.
BI IJO SE WA TIITI DI 313AD
            Ogbon odun leyin igba ti ijo Kristi bere inunibini ti awon Empire awon isejoba agbaye ni o dipo ti inunibini ti awon Ju.
            Inunibini yi ma nwa o si ma nlo ni awon akoko kookan ti o si ntesiwaju titi di 313AD. 
            Ni 313AD, ni Emperor Constantaine pase. Ominira ni ti  esin, bi oodunrun odun ti ijo fin la akoko iyiriwo ati inunibini koja, opolopo ayipada ni o ti farahan ninu ijo.
            Pupo ninu awon ayipada ni o waye nipase okan tabi omiran ninu awon nnkan wonyii.
1.        Inunibini
2.        Idagbasoke ijo
3.        Ariyanjiyan nipa ti eko
4.        Iyato nipa ti iri laarin ijo ti ila oorun ati ti iwo oorun.
ISEJOBA IJO – CHURCH GOVERNMENT
            Nigba ti ijo bere ni Jerusalemu awon igbimo Aposteli lo nse akoso ijo nipa emi ogbon ati agbara Emi mimo Ise A. Ap 14.
            Ko si alagba, ko si Diakoni, ko si awon Bisobu, ko si awon igbimo miran, ko si elekunjekun, ko si egbe miran, ko si ikorajopo tabi asoju enikeni, awon ohun ti  a menuba loke yi ni o nsuyo tabi farahan ni bi idagbasoke ti nfarahan ni elekun jekun tabi elekanka.
            Apeere ti o dara nipa eyi ni ari ninu iyansipo ti ayan awon mejeji ti a pe ni Diakoni lati se itoju awon opo Heleni nibi ipinfunni tabili Ise A. Ap 6.  Ijo ni o yan won ti awon Aposteli ti won si fi ase fun won lati fi won si ojuse.
IBAWI NINU IJO
            Igbe aye ninu ijo akoko ohun ni o da lori igbe aye iwa mimo, majemu titun funrare oun lo fi idi igbe aye iwa mimo mule ti awon baba igbagbo eyi ti o fi eko ihinrerre tabi oye yi mule gege bi ofin lati tele – Owe 29:13 – 19, Owe 29:1, I Kor 5:1 – 13, Ise A. Ap. 5:1 – 11 ti a ba kiyesi awon ese oro Olorun wonyii gbogbo won ni o fi idi ibawi mule.  Igbe aye iwa mimo yi ni o fi idi igbagbo Kristieni mule, yato si ki a ma gbe oko re tabi si ori lasan.  Abala ti igbe aye mimo yi oun ni o fi idi Kristieni mule, gege bi ohun ti o yato si awon esin miran ati awon keferi laarin igbe aye esin Kristieni ati awon keferi ni o fi igbe aye Kristieni mule.
            Eyi ni o mu ki ijo fi idi ibawi mule pelu gbogbo liana ati agbara ase tin be ni owo re, nitorina awon ti o bar u ofin ti a la kale ni a nbawi ti a si nfi iya ti o dopin je won.  Nigba ti Kristi wa ninu ikan ninu awon eko Kristi, Kristi ko w ape a gbodo dariji ara wa ni igba adorin meje, eko Johannu ori kinni si ese kejo, ohun ni Johannu fi ipile si ibawi mule, oro yi ti a pe ni “penance” ti o wa lati inu ede Latine “peonitentia” ti o tumo si ifiya jeni ni o gbodo fi idi ibanuje fun igbe aye ese ki elese to le ri idariji ese gba – I Jh 1:8 – 10.
Nitori na awon idi fun ifiyajeni ni wonyi:
1.        A gbodo fi iya je eni ti o se ni abala kan ki a le re eran ara elese sile, ki a ba le gba okan elese yen la – I Kor 5:5.
2.        Ki a ba le fi idi igbe aye mimo mule ninu agbo ijo Olorun – Ise A. Ap 5:11 – 14
            Ona kan gbogi ti a gba nbaniwi ni ijewo ni gbangba gege bi oro ti a lo loke ti a pe ni poenitentia ti o tumo si jijewo ese patapata.
IJO DOJUKO INUNIBINI
            Jesu Kristi ti so tele fun ijo pe gege bi won se se inunibini si mi be ni won o se inunibini si yin pelu.
            Ijo ti lo oodunrun odun (300yrs) ti won ti nfi oju wina inunibibi, akoko inunibini ni a npe ni akoko awon akoni, ohun ti o je kape ni igba awon akoni ni wi pe nigba iponju la mo ore, ni akoko inunibini ni a mo ojulowo omo Olorun, ni akoko inunibini yi, pupo ninu awon baba igbagbo, opolopo awon adari ati awon miran lara awon omo ijo majemu titun ni won ni lati jiya nitori igbagbo won.
            Gege bi akosile iwe mimo ninu Peteru kinni ori kerin (I Pet 4:1 – 2, 12 – 16) Peteru ati Johannu ni a ti gbe ti mole, ti a si ti se inunibini si ogoro eniyan, Stefanu ati Johannu ni won ti ku iku ajeriku (Ise A. Ap. 7:58 – 59) Ise A. Ap. 12:1 – 2.  Bi awon Kristieni se ndojuko inunibini lati odo awon Ju, be na ni awon ijoba orile ede Romu nlo agbara won lati pon won loju.
            Ni AD64 nigba isejoba Aare Agbaye Nero ina kan seyo ni Romu fun odidi ose kan gbako ni ina yi fi njo lati aro di asale fun odidi ose kan, Aare isejoba agbaye yi ni o fie sun kana won Kristeni pea won ni won da ina yi, ti awon Kristieni si di eni atimole ti a si nfi iya je opolopo, opolopo awon obinrin ni a so mo eranko ti awon eranko si fa won ya perepere, ni nnkan bi ogorun ni AD64 – 164AD ti o je Ogorun odun ko si igbogunti gbogbo gbo, sugbon ti elekunjekun ni akoko igbogunti tabi inunibini yi awon baba kan wa ti won ku iku ajeriku.
1.        Ignatius Bisobu ni Antioku
2.        Polycap Bisobu ni Symna
3.        Justin Martyr – eni ti o ko opolopo iwe lati dab obo igbagbo.
            Laarin 161 – 180AD Aare agbaye kan wa ti a pe oruko re ni Marcus Aurelius, aare agbaye yi ni o pase pe gbogbo awon Kristieni ti a ba ti fie sun kan ni a gbodo ma ko eru won, eyi lo fa ti awon olufisun fi dide si Krsitieni ki won ba le lo ko dukia awon Kristieni, nitori idi eyi opolopo Kristieni ni a mu lo si idajo ti a dawon lebi ti a si ko awon eru ati dukia won fun awon olufisun won.
Die ninu awon baba igbagbo ti won jiya nitori isele yi ni wonyi:
1.        Ambros (Bisobu) 340 – 397AD
2.        Jerome 345 – 420AD
3.        John Chrysostom 347 – 406AD
4.        Augustine 354 – 430AD
5.        Athenagoruso
6.        Hege Sippus
7.        Theophilus ara Antioku
8.        Clement ara Alexandria
9.        Ireneus
10.      Jerti;;oam
11.      Eusebius
AWON IGBOGUNTI NA
            Fun bi Oodunrun odun (300yrs) leyin igba ti a ti bi ijo, ni ijo ti ndojuko inunibini tabi igbogunti.  Laarin awon oodunrun odun ti ijo fin la inunibini tabi igbogunti koja yin a ni ijo fi gba gbogbo ile Romu.  Eje awon ajeriku ni won so pe o je irugbin ti o mu ijo dagba, eyi ki si se oro aheso lasan nitori inunibini tabi igbogunti ti ijo la koja ni akoko yi, ni o je eyi ti o mu irora lowo lopolopo bakanna ni o je eyi ti o mu ere tabi eso wa lopo yanturu.
            Gbogbo inunibini tabi igbogunti ohun ti o ma nmu ere wa lati odo Olorun.  Ni inu gungun igbogunti tabi inunibini yi ni jo ndagba si ti o si ngberu si bakanna, nigba ti o di opin inunibini tabi igbogunti yi awon Kristieni ni won ti da ijo won si oniruru ilu ni ijoba Romu, nitori nigba ti inunibini aa fe pari, aare agbaye kan ti o je Kristieni ni o gba akoso Costantine eyi ni o wa je ohun ti Kristieni ko ni ewu mo rara, ko da a ti je Kristieni o je eyi ti o ni aabo ti ko si eni to dun koko mo won mo, o tun wa je ohun ti o mu ewu lowo lati ma je Kristieni nitori oore ofe ati igbadun to nbe ninu jije Kristieni.
            Igbogunti tabi inunibini ti o de ba ijo ohun ni a le pin si abe isori meji.
1.        Ohun ni o je inunibini ti o bere nigba ti isejoba agbaye Nero ni AD64 titi di igba isejoba agbaye Decius ni AD 250
2.        Ni o je igbogunti tabi inunibini nigba isejoba agbaye Constantine ni 313AD ni apa iwo oorun ati 323AD ni apa ila oorun.
KRISTIENI ESIN TI KO BA OFIN MU
(RELIGIO ILLICITA)
            Ni bi Kristieni se ngberu ti o nfe si ni awon Ju je ko di mimo fun ijoba Romu pea won  atele Mose ati awon to hun tele Jesu Kristi won ki se okan naa ati pe won yato si ara won.  Eyi ni o farahan ninu otito naa pe ni opolopo tabi ni yanturu ni awon keferi ndarapo mo esin igbagbo ju awon ti won ndarapo mo awon Ju.  Ni eyin o reyin ni awon ijoba wa loye re pe iyato nbe laarin awon Ju ati awon Kristieni.  Bakanna ni o tun ye won gbangba pea won Ju po lopolopo, won je eni ola, ilumoka, ati gbajumo ti won si mo ato ohun gbogbo se, nigba ti awon Kristieni si je awon kereje, awon ti ko lowo lowo, ti won ki se ilumoka, ti won ko si je gbajumo.
AWON NNKAN TO FA INUNIBINI TABI IGBOGUNTI TI WON FI NI ESIN
KRISTIENI KO BA OFIN MU
1.        Kiko ti won ko lati se irubo si aare agbeye Emperor je idi kan gbogi ti ijoba Romu se gba pee sin Kristieni ko ba ofin mu “Religio illicita”.
2.        Kiko pa ti awon Kristieni ma nkopa ninu isin idapo ounje ale Oluwa.
3.        Awon isin abele ti won ma nse ti won ma nti ilekun mori je idi miran ti won fi gba pe Kristieni ko ba ofin mu (Religio illicita).
AWON AKOJOPO IWE MAJEMU TITUN
            Iku awon aposteli ni oti mu ohun ase kuro lori ohun ti a pe ni ihinrere ati ohun ti ihinrere ko je, gbogbo eko awon Aposteli ni o ti di eyi ti ko ni akosile mo eyi lo fa ti akojopo iwe majemu titun se waye.  Oro yi kanoni ni a mu lati inu ede Giriki ti o tumo si osuwon, opa iwon tito tabi gigun ninu itesiwaju kanoni ni o wa tumosi awon akojopo akosile awon eniyan mimo, eyi ti a nlo otito lati se osuwon re.
ASE AWON KANONI
            Nigba ti o fi di 200AD gbogbo awon iwe majemu titun ni awon ijo akoko ti gba wole gege bi awon iwe ti o ba ife Olorun mu.  Awon nnkan wonyi ti a fee bere si ni so yi, ni o ye ni afiyesi nipa awon kanoni.
1.        Osunwon ti awon ijo igbani tabi awon baba igbagbo lo lati se ayewo awon iwe ti o ye lati gba wole ati eyi ti a ko ni gba wole ohun ni ase onkowe.  Ase onkowe ni “Apostolicity” eyi ni ase tabi agbara ti o ti iwe yen leyin.
2.        Athamasious 367AD ni o ko se akosile ti majemu titun di bi o ti se wa titi di oni yi.
Ibi ipade igbimo meji ni o wa ye
1.        Hipo Regius 393AD
2.        Carthage 397AD eyi ti o waye ni (North Africa) Ariwa Afrika ni abe isakoso Augustine ohun ni o fi owo si akojopo majemu titun ti o fi je ojulowo ti ijo ti ila oorun ati ti iwo oorun si tele Afrika gege bi apeere.
3.        Awon kanoni yi ni won gba bi Oodunrun odun lati fohun sokan lori akojopo awon kanoni nitori awon iwe ti a pada wa gba wole je awon iwe ti a fowo si, ti gbogbo ijo si gba be pe o je ojulowo.
4.        Ni akoko awon kanoni, ijo duro ni ifesemule lori igbagbo ati iwaasu re, awon kanoni lo paa wa di gbajugbaja nitori awon adamodi eko ti o w ape igbagbo ijo nija.
IJEWO IGBAGBO AWON APOSTELI
            Oro oyinbo ti a pe ni “creed” ohun ni a mu jade lati inu ede Latine ti o je “credo” ti o tumo si – mo gbagbo.
            Ni inu ede ti ijo “creed” je oro ijewo igbagbo ti o tumosi mo gbagbo, oro ijewo igbagbo ti o lojo lori ju ti a sin lo ninu ijo ode oni ohun ni a npe ni oro ijewo igbagbo ti awon Aposteli, ki se awon Aposteli ni o ko oro igbagbo, oro yi ti a pe ni ijewo igbagbo, leyin igba ti awon aposteli ti ku ni a to gbe jade ki se igba kan ni a ko oro ijewo igbagbo, se ni won ntesiwaju titi di akoko yi.
            A pe ni ijewo igbagbo ti awon Aposteli nitori o fi otito igbagbo ati eko awon Aposteli mule.
BI IJEWO IGBAGBO AWON APOSTELI SE BERE
            Awon oro kan wa ninu majemu titun, won je oro ijewo igbagbo ti a ko kasi ti a ko si nani, awon oro yi je oro ti o kere to be ge ti a le gboju fo da ti a ko si nani won, awon oro yi ni awon oro ti a ma nlo nibi ipejopo Kristieni, nibi iwaasu itagbangba tabi isin awon omo Olorun.
Die ninu awon oro be ni wonyi:
Ise A. Ap. 8:37, Ise A. Ap 16:31, Rom 10:9, I Kor 8:6, I Kor 15:3 – 4, Fil 2:8 – 11, I Tim 3:16, I Tim 2:5 – 6, I Tim 6:13 – 14 ati II Tim 2:8.
ILANA ISIN NINU IJO
            Iyato ti o de ba igbe aye ijo leyin iyipada Constatine ti o di aare agbaye, ohun to mu awon ayipada gbogi ba eto iyipada laarin ijo, laarin akoko ti ijo fin la inunibini tabi wahala koja ohun loje ki won ma se akiyesi igbe aye won nipa ti Emi eyi ti o fi ara sin.  Fun bi igba odun (200yrs) ni ijo ko ti ni owo lowo ni won ko si ni anfani lati ko ile ijosin nla, nibi ti won yoo ti ma se liana ijosin to larinrin, ni ogoji odun to saaju ijobaDeoclatan and Kristieni ni anfani lati ko ibi ti o tobi fun ipejopo, ti won si ti ro pea won iya ti o tin je won bo lati igba isejoba Decius ati Valeria ni 251 si 259AD se ni won ro pe akoko ifiya jeni ti dopin, sugbon gbogbo awon ile ijosin nlanla ati amusewa ni won ti baje ti won si dana sun.
AWON ODUN IJO
            Gege bi awon odun ti ara se wa, ni awon odun ijo na wa, awon odun ijo ni awon Kristieni gba lati fi se ajoyo ti Emi, a npe awon odun yi ni odun ijo nitori o nmu war ranti awon anfani ti a nje gbadun re lodo Jesu, awon odun yi ni o ti bere lati igba ti ijo ti bere, awon odun ijo yi ni o nse afihan ati ise irapada nla ti oore ofe Jesu Kristi ti se afihan ofun ijo Olorun.
Awon odun na ni wonyi:
1.        The Incarnation (Christmas) – odun Keresimesi
2.        The death and resurrection of Christ (Odun Ajinde)
3.        The coming of the Holy Spirity (Odun Pentikositi)
ODUN KERESIMESI
            Odun Keresimesi yi je eyi ti a ma nse ni Pataki ni ojo isinmi, eyi ti a ma fi nsori ibi Jesu Kristi, keresimesi je igba ti a nse ajoyo araye eyi ti a bi fun iran eniyan, o je akoko ti a ma nfi ayo ati idunnu wa han fun eni ti o fi ite ogo re sile si orun lati wa si aye nitori ti awa eda.
ODUN AJINDE
            Akoko aawe lenti ni o ma nsaaju ki odun ajinde to kade re nile, ohun ni o je ose mefa ti a fi nni isera eni, gbogbo akoko lenti yi ni o ma nmu war anti akoko ijiya Jesu Kristi, asi ma nlo awon akoko naa fun aawe gbigba, akoko aawe yi ni a ma npari si ojo ti a mo si Good Friday (Jimoh rere).  Jimoh rere yi ni o je iranti ojo ti a kan Jesu Kristi mo agbelebu.  A pe ni Jimoh rere nitori ni ojo Jimoh ti a kan Jesu mo agbelebe yi ni ipa agbara, ijoba esu ati ese ni o di alailagbara lori aye wa.
ODUN PENTIKOSITI
            Ayeye ti pentikositi yi ni o je ayeye asekagba ti ibi Jesu ati ajinde re, pentikositi ni o tumo si adota ojo ti se ose meje ti o wa laarin ajinde ati isokale Emi mimo, nigba ti o pe ogoji ojo ti Jesu jinde ni ijo nse ajoyo igoke re orun ti Jesu Kristi, nitori o pari ise re ti Olorun sinu aye wa se, gbogbo awon odun wonyi ni awon ijo akoko nkiyesi ti won sin se ajoyo won, ti won si ntele awon odun naa.  Odun ti Pentikositi yi ni odun to gbeyin ninu awon odun ore ofe ti ibi ati ti ajinde eyi ti Olorun fu iran eniyan, odun pentikositi yi ni o wa pada wa dipo odun ase irekoja (feast of Passover) ti a lana sile fun awon omo Israeli ninu majemu laelae.
OJO SUNDAY ATI ISIN OJO SUNDAY
            Ni ibere tabi lati ibere ni awon Kristieni ti a ranti ti won sin lo ojo akoko ninu ose lati se ajoyo ajinde Jesu Kristi ni abe aare ase joba agbaye “Constantine” lati igba aare agbaye Constantine bakanna jijosin ni ojo isinmi ni ohun ti a fi ase tabi opa ijoba si ti o si ni itumo fun awa Kristieni bakanna pelu.
            A gbodo loye re pea are agbaye Constantine ko se agbekale afowo si ijoba yi nitori awon Kristieni tabi ki o se agbekale re gege bi ofin kerin ofin Oluwa, o se agbekale re ojo isinmi gege bi ojo ti a maa maa josin lati so oruko re ni Sunday ti o je oruko aarin ti o si je oruko orisa re, o se agbekale (Sunday) ojo isinmi Sunday ti o tumo si (ojo oorun).  Bi se won se wa fowo si wipe ki won ma josin ni ojo Sunday gbogbo agbaye ti wa fowosi wipe ki won ma josin ni ojo Sunday yato si ojo Sunday ninu afowosi yi ni awon Kristieni ti mu itumo miran fun oorun (sun) ti won ti gba Jesu gege bi oorun itansan ododo (sun of righteousness).  Nitorinaa are agbaye Constantine ati awon are agbaye miran ti o je leyin re ati awon igbimo miran ti o ni se pelu liana esin ni won jo fi owosi gege bi ofin tuntun ti a pe ni ofin ijosin ni ojo isinmi ase aare agbaye Constantine ti odun 321AD ohun ni o fi ipinle igba wole ojo isinmi gege bi ti ojo ti gbogbo agbaye yoo ma josin ti won si fi owo si bakanna pelu tabi ti won si gba gege bi ojo isinmi.
            Laarin awujo awon Kristieni ijosin si Olorun ni ohun  ti a nfi ojo isinmi se, idi ni yen titi di oni ti ojo isinmi je ojo  ti aya soto, ni ojo ti o kun fun iseju fun awon gbogbo omo Olorun.
            Isin ti a nso nipa ojo isinmi (Sunday) pin si ipa meji
1.        Eyi ni eyi ti o ko gbogbo eniyan papo, iru wa ogiri wa, a pe ni isin (Missa-Cathecumenus) isin gbogbo eyi ti ko gbogbo eniyanpa papo.
2.        Ekeji ni (Missa Fidelium) – Eyi ni isin awon olooto, isin yi si ma nbeere lehin igba ti a ba tit u gbogbo eniyan ka.  Ninu isin Fidelum ni won se (workers meeting) ibe ni won ti so awon oro ti o se Pataki eleyi ni esin olooto ti o ma nwaye ni eyin igba ti aba tit u awon Cathecumenus sile.
            Oro ti a pe ni Missa yi ni a mu jade lati inu ede Latin (awon Fidelium ni won ni eto si ounje ale Oluwa awon ni o nsan idamewa awon ni o nsan ore.
            Missa ti a mu lati inu ede Latin ohun ni a pe ni Missus ni ibi ti a mu mass jade lati inu ede oyinbo ni o tumo si idapo mimo, tabi kikopa, o le je ojojumo tabi ojo isinmi tabi ojo ti won ba fi ipade si tabi o le je ekan lodun, opolopo igbimo ni o ma nwa ninu ijo omiran  le je ekan lodun omiran le je emeji lodun, sugbon ni igba ti o fi di 500 – 600AD ti ijo bere naa ni a tin se gege bi isin gbogbo bi o tile je pe awon ti won ti ni igbala lo wa fun.
SAKIRAMENTI (SACRAMENT)
            Sakiramenti ni awon isin ti o se Pataki eyi a ntele ni awujo awon omo Olorun, o je eyi ti Kristi lana re tabi eyi ti a pase fun wa ki o to goke re orun, awon isin na ni iribomi ati ounje ale Oluwa, awon isin miran wa ti won gbe ni isin Pataki teletele ni igba ti ijo sese bere bi o tile je pe Jesu ko pase fun wa, pupo awon isin ti a pe ni dandan wonyi ni won pada wa kuro ni isin dandan nitoripe won o pa lase fun wa.  Ni nnkan bi 500AD ti ijo bere ni won gba (confirmation) fun ijo Pataki ni igbati awon alatunto won ko gba (ordination) ati confirmation) gege bi isin Pataki mo.  Iribomi ati ounje ale Oluwa gege bi isin Pataki.  Ilana kan gbogi ti won si gba ni iribomi gege bi majemu titun, iyen ni iribomi patapata labe iribo patapata yyi ni abe omi ti o nsun ni won ma nse, won kin se iribomi fun awon ti ko gbagbo ati awon ti ko loye re, ju gbogbo re lo won ki se iribomi fun omo kekere, agbalagba nikan ni won ma nse fun.
            Oro ti a pe ni iribomi ni a mu jade lati inu ede Giriki oro na ni (baptiso) ti o tumo si riri nnkan bo inu nnkan tabi gbigbe nnkan kan bo inu omi ki omi san lori re.  Enikeni ti o ba je pe ko se iribomi won ko leto lati je ounje ale Oluwa.




No comments: