Monday, November 5, 2018

HANDOUT EKO APEERE


GROUND OF TRUTH BIBLE INSTITUTE
       Bible Palace, Aba-Ibeji Road, Ayetoro, Odo-Ona Kekere, Ibadan                                        E-mail; groundoftruth2@yahoo.com.  Website- www.groundoftruth.net.ms
                                           MOBILE: 08056008526 & 07031821386
HANDOUT
EKO APEERE

   





 ADVANCED CHRISTIAN LEADERSHIP (200 LEVEL)
EKO APEERE

IFIHAN: Eko yi, yio ran wa lowo gege bi akeko bibeli, oniwasu ati osise ati paapaa ogbologbo oniwasu oro Olorun lati mo erongba Olorun nipa irapada omo eniyan kuro ninu isubu won.  Olorun ni erongba to dara fun eniyan lori isubu re to be ti o fi ni ero irapada ati idapada gbogbo ohun ti o ti sonu nipase sisubu yi.  Sugbon erongba Olorun ni awon nkan miran “ohun ti TYPOLOGY dale” ni lati wa idagbasoke erongba yi ni ese se laarin awon omo eniyan.  Bi a ti nko omode leko, ti a si nfi nkan ti o je apeere ti  nwon ti da mo layika ko won; be na ni  Olorun ti fi apeere lati inu majemu ti lailai han, ti o si lo orisirisi ona bi eniyan, ohun kan ati ayika, lati je ki a mo Olorun ati ijoba re ti yio mu wa.  Olorun nreti o si npale mo fun IHINRERE (GOSPEL).  Nipa fifi ko ijo ti majemu lailai, Olorun ma nmu itoni wa nipase Iru (type), Apejuwe ati afijo awon nkan ti o nbo.
                                         Alaye Itumo  (DEFINITION)
I (A)    IRU (TYPE):- Je ohun kan ti Olorun ti fi se Apeere, akawe tabi afijo kini kan ti o joju daadaa.
(B)       Majemu lailai dabi dingi ti oun fi eda aworan han, ti majemu tuntun si je aworan gidi.  Eyi dabi arabinrin ti o fi aworan re ranse si olufe re, ti olufe re ti o fe fe yi si nreti ojo ti yio fi oju kan afesona na. Typology nipase iru yo tan imole si fun awon ti yio fi tokantokan wa oro ti o sa pamo sinu iwe mimo.
II.        ILODI SI IRU (ANTI TYPE):- Je imuse tabi otito ti a ti so tele ninu iwe mimo.  Eyi jasi wipe iru je ojiji tabi ofefe ti ojulowo.
Akiyesi: Iru gege bi apeere yo sise nigbati ojulowo ko ba tii han (farahan).  Nitori idi eyi, ti ogidi tabi ojulowo ba de, iru re ko ni wulo mo rara. Nitori pe ohun ti afise apeere re ti de asi ti ri lojukoju
(Bi o ti ri).
ORISI OUNJE MEJI
            Iwe mimo fi yewa pe orisi ounje meji lo wa ti o se koko
i.                 Otito ti o duro bi Wara:- Eyi wa fun awon onigbagbo titun.  Awon titun yi to si ounje ti o roo ti o si fun gege bi Wara, ! Kor 3:12.
ii.               Otito ti o duro bi  ounje gidi:- Eyi je ojulowo, otito ti o to si okan onigbagbo ti o dagba, eyi yi ni ounje gidi tabi eran ti on pe lenu ju wara lo.   Nitooto, ounje gidi iru eyi le ma ye eniyan, sugbon bi o ba ye wa tan ninu iwe mimo yio tubo tobi si ni.  Yio ti le jeki imo wa ninu bibeli sun siwaju si.  I Kor 3:2

KINNI IRU LEE JE?
Bi a ti sotele ninu afiwe ohun ti iru je ati wipe, kii se ojulowo.  Wipe ofeefe ni, be ni a o ti ri wo ni ipele ti o kan yi.
(i)              ENIYAN:-  Adamu je iru Kristi (Roman 5:13) gege bi aworan eni ti o nbo.
(ii)            AYEYE TABI ISELE:- Iru eyi ni ti isele inu Ekisodu (I Kor 10:11)
(iii)           NKAN:-  Gege bi iboju ti o wa ninu tempili ti o je iru ti ara Kristi (Heb 10:20).
(iv)           IBI IMO ATI EKO:- Imo ati Eko ati Alufa ti awon Juu, ti o je Iru Alufa giga ti Jesu Kristi (Heb 9:11).
(v)            AYEYE SISE:- Ajo irekoja je iru ifi rubo ti Kristi (I Kor 5:7 A ma nsaba ri awon Iru (type) ninu PENTATEUCH, a ma nri okokan ni ibo miran pelu.  Ogidi, iru tabi ojulowo ni a o ri ninu majemu tuntun.  Iwe Heberu je eyi to o gbajugbaja ninu iru ni majemu tuntun, be gege ni iwe Ekisodu ati Lefitiku.

ITUMO IRU (TYPES)
Iru ni o tumo si Apeere, iru tabi eda kii se ohunti a le lo fun liana Esin a mo lati fi se apejuwe tabi alaye kedere tabi ilana ni ibomiran (Jh 3:14, I Kor 5:7). Isa 66:3, Heb 8:7 – 8. Ko bojumu lati pe ohun kan ni iru lai je wi pe a fihan bee ninu iwe mimo.  O je ooto to damiloju gbangba pe iru pupo lo wa ti ko ba ilana yi mu, amo ti dida won mo je lati ipa emi mimo, yato sipe bayi ni a tin se lati ojo to tipe.  Apeere ni ti Josefu ti gbogbo aye fere gba bi iru Kristi.
      Ki eniyan, ayeye tabi ibi eko to le je iru, o ni lati ni ohun meji to ni ipa.                Ni akoko o ni lati ni afijo ni iru (form) tabi ti Emi si oun ti afi we ojulowo re.
Ekeji – Olorun gbodo ti seto awon nkan lati pe ko je awo ojiji fun ohun ti o dara gidigidi ninu ihinrere.  Ati iru ati ojulowo ni Olorun ti seto re lati ko ni ni ohun ti Emi ododo.  Iru yio je ohun ti a leri paapaa fun igba die ni igba ti ojulowo yio je ohun ti a ko le ri ti yio si je ohun Emi.  Iru je ohun ti isinsinyi, o han, o si je ti aye, nigbati ogidi je ohun ti o fi ara sin, ti ojo iwaju o si ni ipa ti orun.
KOKORO SI ITUMO IRU
      Jesu je oro ipada waye eni ti a nsin, amo o lai si akosile oro na nibe, a ko le mo eni ti a nsin.  Bibeli ko lo fi aponle fun Kristi, bikose pe Kristi lo fi aponle fun Bibeli.
·       Bibeli menu ba aimoye ogorun ise ti o je ipele akoko ti o wulo julo
·       Ipilese Aye
·       Dida awon eda eniyan
·       Itan ese
·       Imo mimo nipa idajo
·       Di dide ati itan awon omo Israeli
·       Ipadawaye Olorun
·       Igbe aye ati iku Jesu Kristi
·       Imo Eko itesiwaju ijo Kristieni
·       Gbigbe ihinrere kale fun gbogbo aye
·       Nipa ijakadi laarin imole ati okunkun
·       Otito ti o gbehin lori akoko (igba).
Kini asiri ilana, itan igbekale ati iwe emi ti oun ti asopo ti o gbaladun.
Idahun kan soso lo wa nibe KRISITI ni.  Bibeli lati Genesisi de ifihan lo nso nipa Jesu Kristi.  Iwe Luku 24:27, 44 ni o jeri eyi o si bamu regi.
            Jesu lo gba gbogbo inu majemu ti lailai kan.  Majemu naa fere ma ye eniyan bi kose nipa Jesu Kristi.  On ni kokoro si ongbifo ohun ti a npe ni iru – TYPOLOGY – ti nse imo nipa “Asotele” Aworan Jesu Kristi ti a ya ni aimoye ona.   Akeko gidi yio ri opolopo anfani ti o wa ninu aworan wonyi.
IRU NINU IWE GENESISI
            Eko kekere kan wa ninu iwe Genensisi ti o je ti Ase pipa.  A si fi otito ko ni nipase iru, ileri ati ise.  Eko na wa fun fifi oju ri ju eti lo, ati awon nkan eelo tin won le rii tabi mu dani.  A ri opolopo ohun itesiwaju ti a ri ninu ihuwasi Olorun nipase oruko re. A si menu ba die ni isale yi.
(i)         GENESISI 1.1 – OLORUN Alagbara.  Oruko yi Ia lo ni ibamu fun ipilese eda eniyan.
(ii)       GENESISI 2:4- OLUWA OLORUN – Jehofa, the “self – existent ONE” Eni ti o fun rare wa ti o sipe ara re ni Emi ti nje Emi.  Eyi yi ni irapada oruko eni mimo.  Oruko yi ni eda ti nsubu gbodo mo ki Olorun to lee fun ni ireti.
(iii) GENESISI 14:18 – OLORUN TI O GAJU LO – Eyi tumo si wi pe oun lo ni gbogbo aye ati orun.  Akawe yi jo Abrahamu loju jojo, to be ti o fi je wipe oun nsan idamewa re patapata fun Melkisedeki.
(iv) GENESISI 15:2 – OLUWA OLORUN OGA – Nigba ti Abrahamu fe ri ojurere, iranlowo ati igbani ni imoran lati odo Ouwa ni o lo eyi.
(v)       GENESIS 17:1 – OLORUN ATOBIJU – EL-Shaddai. Eni ti oni agbara “Eni to le ni aya”, A fun ni je, A fun ni okun, A te ni lorun (eyi ni gbogbo ohun ti iya je si omo re) Eni ti o mu ni bi si ati rire si.
Oruko yi ni Olorun lo nigba ti oun tun ileri re se fun Abraham nipa pe oun yo fun ni omokunrin kan.  Okunrin na “san ni kiku”.
ADEHUN ABRAHAMU: - ni a tunse fun Isaaki ati Jakobi Gen 12:1 – 37, Gen 13:14 – 17, 15:1 – 6, 17:2 – 22; 22:15 – 18; 28:10  -14.  Ileri ti a se fun Abrahamu nipa pe yo jogun aye je apeere jije ogun orun awon eso (omo).
Abrahamu ni ti Emi (Heberu 11:16).  Kini idi ti won ko fi jogun ile na logan?  Eese ti won fi rin irin aare kiri fun ojo pipe, ti won si ri ileri na gba? Idi nipe ki iriri nwon le je aworan, apeere ti ijo ti o ga, ti a si nse igbaradi re sile fun ijogun ti orun nipa wiwa ni bakanna ati kikoja ninu iriri bayi.
Ni sisentlele Adehun Abrahamu ni eyi:-
a.     Ibukun ti ile Aye:- Ile, oro Aabo ati bebe lo.
b.    Ibisi ti ile Aye:- Ti yio po bi iyanrin ile (Gen 15:5).  Eyi ti afihan ni orile ede Juu; ati nipase Ismaeli (Johanu 8:33, 37).
d.  Eso ti Orun:- Eyi ti o po repete bi “irawo oju orun” (Gen 15:5) Eyi ti a muse ninu            Juu ti o gbagbo ati omo lehin Jesu ti o gbagbo (Romu 2:28 – 29) 9:6 – 8, Gal         3:29).
e.   Ileri ti Emi:- Bi “Emi yo bukun o” – “iwo yo si je Olubukun”.
f.    Ileri ti mimo Olugbala wa – Eleyi ni iwe mimo fihan ni ibasepo meji ti aye ni   pase Abrahamu legbe kan ati Eso ti Emi legbe keji.
APEERE KRISTI NINU IWE GENESISI
IRU (EYA) KRISTI

      Oluwa funra re ti fun wa ni apeere tabi ojutu ninu iwe mimo, nipa ara re ninu majemu lailai.  NInu eko Emmausi re (Lk 24:26, 27, 44) Nihin ni o ti pin “Ohun ti o so nipa Ara re” si ipa meji”- Awon ohun ti o so nipa IJIYA re ati ti eyi ti ba ti “OGO RE” mu.  Peteru fi ye wa pe Emi mimo ti Kristi wa ninu awon onkowe ti majemu ti lailai, to be ge ti won “fi nso eri saaju ati ti ijiya Kristi ati ogo ti yoo tele (I Pet 1:11).
             Ni idi eyi a le reti “ni inu gbogbo iwe mimo” – “Kristi ti o njiya”, ti o ni ogo julo, ti a fi se eleya, ti a ko sile ati Kristi ti a gbega, ti a si da lola.
KINNI A FI KRISTI WE
       Ni hin a o joka, a o si se awari awon imo yi ninu majemu tuntun.
1.    KRISTI, Imole Aye (Gen 1:3
2.    KRISTI, Oorun ododo ti ise mimo (Gen 1:16, Mal 4:2)
                         AKIYESI:- Yio mu ise re lo ni ipada bo re.  Bayi ile aye wa ni aarin meji (Gen 1:3 ati 1:6)A ko ri oorun sugbon imole wa.  Bi eto ijo wa ni ipo “imole die” nigba ti a ri osupa ti on fi imole ti orun ti a ko ri han.  Ni atetekose (Gen 1:6) ni olukuluku onigbagbo je “imole”.  Wayi o ile ti su.
3.   KRISTI apeere Adamu ti iru Adamu akoko (Gen 1:27 – 29, 2:7 – 15).  Nipa eyi ti Kristi fi je olori awon Eda tuntun bi okunrin akoko se je ti “Adamu” tabi ti “Kristi” – I Kor. 15:22, 45 -7; Romu 5:12 – 19.
                         AKIYESI:- Kosi ibi ti ati pe Kristi ni Adamu keji sugbon a pe ni Adamu ti o kehin.  Nitori ti o gbe gbogbo ese iran Adamu, idajo gbogbo iran Adamu le Kristi lori – O le wa so bayi pe “Mo se tan patapata pelu Adamu”.  Adamu miran ko ni si mo.  Kristi ni ADAMU IKEHIN kiyesi Adamu kan mu Ese wa, Ekeji mu IYE wa.
4.   KRISTI ni oko ijo (Gen 2:18 – 24). Igbeyawo  ti akoko je apeere igbeyawo mimo (ti                                
      Emi mimo) isopo laarin Adamu ikehin ati ijo.
5.    KRISTI –Ododo ti Olorun (Gen 3:21).  Ninu iwe mimo aso tabi ewu nfi igbakugba             nfi ami iwa mimo han.
6.     KRISTI Odo aguntan Olorun (Gen 4:4).  Eyi ni apeere ti o nfi olugbala ti o njiya han ninu gbogbo awon akosile iwe ti a n ri Odo aguntan ni iru “Aguntan ti o ko gbogbo ese aye lo” (Jh 1:29, 36) Aguntan nfi aisinmi, alaise ati alainika ti Jesu Oluwa je han (Isa 53:7, Lk 23:9; Mt 26:53,54).  Iru apeere yi ni a mu wa ti o lodi si ti ebo Kaini ti ko ni eje ti eso ise owo re ati ikede ibere iran na ti ko le sele lai si itaje sile fun idariji (Heb 9:22; 11:4).
7.    KRISTI, Aabo fun awon eniyan lowo idajo, Gen 6:1 si 8L16, Heb 11:7; fun ibamu,
         eleyi soro nipa ipamo kuro ninu iponju nla (Mt 24:21 – 22) ti awon Israeli ti o seku  ti yio si yi pada si Olorun ni ikehin ojo.  Afihan eyi ni ti Enoku, ti a mu lo si orun ki o  to di igba idajo ti ekun omi) A gbe lo si oke lati lo pade Oluwa Gen 5:22 – 24; 1 Thes 4:15 – 17; Heb 11:5, Isa 2:10 – 11; 26: 20 – 21) sugbon iru eyi na ni itokasi   tode oni,  nipa iduro onigbagbo ninu Kristi (Efe 1).
8.    KRISTI, Alufa nipa itokasi ti Melkisedeki, Gen 14:18 – 20, Heb 7.  Iru eyi fihan pato ise Alufa ti Kristi nse nipa ajinde, ni iwon igba ti Melkisedeki fi iranti irubo “Akara     ati Waini” han.  Lehin ti ipa Melkisedeki (Heb 6:20) mu wa lo si igba ailopin ti ise Alufa ti Kristi (Heb 7:23:24) A se akiyesi pe iku fi opin si ise Alufa ti Aaroni.
9.     KRISTI, Olugboran omo gege bi ifihan nipa Isaaki, Gen 21, 22 etc.  A kori Isaaki ki o se ife inu re ri.  Gbogbo igbese re lowo Baba re lo ti nwa (Jh 5:30, 6:38).  Awon ti o yo gbangba ninu iru yi ni:-
a.         Isaaki je omo ileri (Gen 15:3,4) o je iru eso ti emi ti ijo.
b.        O se igboran titi de oju iku (looto a kopa) Gen 22.
d.        A ji dide kuro ninu ipo oku (Ni ago ara) Heb 11:19
e.         Lehin na, o gba iyawo keferi (Gen 24)
10.      IRU TI JOSEFU:  Eleyi menu baa won ojulowo ibagbe Kristi ati eniyan lori ile aye. 
A ko le menu ba eyi ni ranpe rara.  Ni idi eyi ki awon akeko lo se iwadi ninu majemu titun lati se afihan Kristi ni ipa meje yi.
(i)        Josefu je omo ti Baba re feran (Gen 37:3)
(ii)       Awon egbon re nbinu, korira re won si ko (Gen 37: 4 – 8)
 (iii)     Awo egbon re dite mo lati pa, eyi ti erongba won se (Gen 37:18 – 22)
(iv)      A fa Josefu jade kuro lati inu koto (Gen 37:28)
(v)       Josefu lo bo si odo awon Egipiti, nibi ti o ti je iya die, ki a to gbaa ti a si fi ojurere wo (Gen 39:41 – 44)
(vi)      O fe aya ni ile Egipiti nigba ti awon egbon re Israeli ko sile (Gen 41:45)
(vii)     Josefu pari ija nipa atunse pelu awon egbon re.  Eyi si mu nwon ni opolopo oro (Gen 42 si 49:11).
                          ORISI APEERE IJO TI ANRI NINU GENESISI

1.        Awon “imole kinkin lati joba ale” (Gen 1:16) ijo ntan nipase ti imole oorun ti ko si (II Kor 3:18), Ifi , at 5:14
2.        Efa (Gen 2:18 – 23; Jh 3:28 – 29, II Kor 11:2; Efe 5:25 – 32; Ifi 19: 7 – 8).
3.        Enoku (Egn 5: 22 – 24, Heb 11:5) “A mu Enoku lo sorun ki o ma ba ri iku”.  Ki idajo ekun omi to sele si aye, isele akoko ti o pari igba na siwaju idajo ti wahala nla (Dan 12:1; Mt 24:21) ti yio je imulosoke awon eni mimo (I The 4:14 – 17).
4.        Isaaki – Nitori bibi re ti o je iyanu ati wipe o je omo igbagbo, eyi mu je iru ijo eso emi ti Abrahamu.
5.        Rebeka:- Ti nse aya ti omo (Gen 24) ninu iru eyi ari aya ti a fe lai si oko nibe, nipa ijeri igbagbo omo odo  ti ko soro fun ara re sugbon fun oro oga re ti o si ti fun omo re.  “Iyawo na si fi tokantokan gba oko re lai ti ri ri paapaa fun oro re.  Elieseri je iru Emi mimo yi.
6.        Asenati:- Iyawo alaigbagbo (Egipiti) ti Joseofu fe lehin ti awon egbon re ko, se afihan igba ti Kristi nwa iyawo fun ara re lehin ti awon Israeli koo (Gen 41:45).
7.        Ofin ati Oore Ofe – Isedaa ti atijo ati tuntun (Gen 16:21, Gal 4:21 – 31) Hagari je iru oke Sinai nibi ti ipapo ti mu ofin wa, Sarah si je iru Jerusalemu nibi ti ipapo ti mu ofin wa.  Sarah si je iru Jerusalemu nibi ti ipati ti mu oore ofe wa.  Hagari situn je bi iru ti ijo ti aye ti o wa ni abe akamo ti ohun aye yi. Sarah ni ti ijo ti emi ti o ye ko gbadun ati ekun rere ibukun Olorun.
AWON ORISIRISI IRU NINU GENESISI
   Gen 4 (Kaini ati Aneli ti Sethi tele) a ni iru eso meji to o nta gbogbo ti o sin so eso ninu aye yi.  Ore Kaini fi igberaga han ati be be lo, sugbon ti Abeli je iru eyi ti Olorun fe nitori oni eje Gen 5.  Nipa igbagbo otito Enoku sunmo Olorun ni ona ti o yato.  Gen 5:23 – a ka wi pe “Enoku ba Olorun rin” ninu irin igbagbo yi lai f'ota pe o je iru Kristi ati aworan fun wa “ijo ti Kristi” ati awon igbese ti Olorun fe ka ma gbe.
AWON ‘IRU TI O WA NINU EKISODU
           
            Iwe Ekisodu kun fun awon iru ti o joju ninu Bibeli, ti akeko le ri opolopo ogbon mu.  Ranti pe iwe Genesisi fi ye wa nipa Josefu.  Eleyi tun bo si oye wa si iwe Ekiosdu nibi ti a o ti koko ri iran eya Abrahamu nipase Josefu.
            Bakanna a ko gbodo gbagbe bi nwon se de ibe (Gen 15:9 – 14) okan awon iran Abrahamu yi bale daadaa ni ile “Egipiti”.  Gegebi okan opolopo eda se bale ninu aye yi paapaa.
            Iwe Ekisodu kun fun aimoye iru apeere yi ti o dun mo ni.  Bi iwe na ti si, o fi iran Abrahamu han ninu igbadun ni ile Egipiti.  Nwon tile ti fe so imo nwon nu ninu Olorun otito (Ranti ibere Mose yi “When they shall say what is his name? What shall I say unto them?”. (Ek 3:13) ko da opolopo tin sin Olorun awon Egipit.
            “Kinni idi ti Olorun fi fun awon ara Egipit ni aaye lati fi iya je awon omo Israeli?”.  Idi ni pe a ni lati run nwon soke kuro ninu ibarele won, fun ipongbe ile Kenani tin se ogun nwon.  Olorun ti ri ijiya nwon, nigbati won ro pe enikan ko mo o si se ti se tan lati gba nwon la, se bi bayi ni Olorun nse fun awon elese nipa mimu aibale okan fun igbe aye ese nwon, ki won si ni ifi ojusona fun ogun rere ti Olorun ti pese fun nwon; eyi yi ni igbala, iyo kuro lowo ibi ese ati awon ibukun miran.
ILE GOSHENI:- ti a fun Josefu ati ebi re lati owo Farao je ile olora ni Egipiti titi di oni oloni.  Ko ni pakanleke Kankan rara, nwon o kan si ma gbe ibe, sugbon ki se ibi ti Olorun yan fun won nipa se ileri ti Olorun se fun Abrahamu.  Bi ko ba je be ni, akitiyan Mose lati mu ki awon omo Israeli lo si Kenani ko ba jasi asan.  Paapaa o je asiko ti Olorun fe ki won di orile ede, olominira laarin awon orile ede miran ni ojo iwaju.  Nwon je alaimokan ati darandaran ni ile olaju ti Egipiti.  Ase asiko niyi fun won lati mo oniruru ise ati owo.  (Kiyesi awon orisirisi ebun ati imo ni o wulo fun opo ohun elo Tabanaku).  A fi agbara mu won, paapaa nipa ise lile fun anfani awon Egipit.  O ye ki a ranti pe Olorun ologbon julo a ma je ki nkan sele si wa lati mu wa gbaradi fun abojuto ojo iwaju, isinsinyi ati ayeraye.  Ojogbon bibeli kan a ma so pe “ile aye yi je ile eko fun ayeraiye”.  Olorun mnu ijo re gbaradi fun amuye ati abojuto ojo iwaju.
            A o ri awon iru afiwe die ti a le fi se agbeyewo ile Egipit ati Kenani.  Egpiti je aworan ile aye, igbe aye igbekele ara eni.  Egipit ni o ri ominira ti Naili ti kun koja bebe rer, o si fun ile na ni ora.  Nwon ko ni wahala ati ma wa omi kiri fun lilo.  A le so pe ko si ohun ti won wo oju orun fun.  O di keji re ni ti Kenani nitoripe o duro fun igbe aye igbagbo ati isegun.  Kenani ngba omi ojo otun lato'do Olorun, o si je ile ti o nsan fun wara ati oyin nitori Olorun bukun nipa ojo.  Nwon ni lati woke – won a si gba igbekele won ninu Olorun.  Aimoye igba ni a se nse bi awon omo Egipiti ti won ko gbekele Olorun nitori won ko mo opolopo ibukun ti o wa lati odo re.
            Kanran ki Abrahamu duro si Kenani o si sokale lo si Egipit (Gen 12:10).  Ni igbakigba ti a ba nrin jinna si Olorun, o ja si rinrin ona ti ko to rara, Jonah se eyi, o ri wipe ko ba ojumu rara.
KENANI:-  je ilu ti o san fun wara ati oyin, wara nfun ni ohun elo (calcium) fun egungun.  Ago ara wa nfe egungun ehin ti ogbo daadaa lati mu wa duro gboin.  A fe ohun elo ti Emi (spiritual calcium).  A nilo oyin paapa nitori nigba miran a ma mnu lara tabi ki a so ohun ti o koro ti a le kabamo ti o baya.  Olorun fe mu wa lo si Kenani ti Emi ti o ni wara ati oyin fun lilo wa.

NISINSINYI JE KI A WO DIE NINU AWON IRU TI INU EKISODU
1.        FARAO:- je apeere satani, ogbologbo oloote ti o njoba aye yi.  O nfi gbogbo igba dena ati ri igbala kuro ninu ese awon elese ti ese ti mu leru.
2.        MOSE:- Iru apeere Kristi ti o je agbanila (Deut 18:15; Luke 4:18, I Thes 1:10)
a.         Mose je olugbala ti Olorun yan (Ex 3; Act 7:25)
b.        A koo ni gba akoko, ni oba koju si awon alaigbagbo (Act 7:23 – 29)
d.        Ni asiko ti a koo o ri iyawo alaigbagbo (Ex 2:13 – 21)
e.         Lehin eyi o tun pada fi ara han gege bi olugbala fun Israeli asi gbagbo (Ex 4:31)
e.         O wa di woli, alagbawi ati asiwaju awon eniyan ti a gbala (Deut 18:15; Num 11:12).

OPA MOSE – EX 4:1 – 4:-  ni awon eko kan fun wa, opa yi je ohun iranwo fun adaran ti o ba nri ona ti ko gun rege, o je ohun ikunpa fun nigba  ti o ba ree, o je ohun aabo fun ni igba eewu, o fi han wa pe ore ofe Olorun ni a le gboju le fun iranlowo ati aabo, ohun ni a le gbe ara le paapa nigbati Mose gbe kale, o di ejo ti oun paapa sa fun.
Heb 10:35 so fun wa pe ki a ma pa igbekele wa ti, sugbon ki a gbekele opa yi ti nse agbara ati oore ofe Olorun.
IREKOJA:- Ex 12:1 – 28, I Kor 5:6 – 8, I Pet 1:18 – 19) Odo aguntan ti irekoja gba gbogbo akobi Israeli la, o si je irufe Kristi ti o ngba akobi ijo lati oruko won yio si wa ni orun.
1.        Odo Aguntan na yio je alailabawon – (Ex 12:5, Lef 22:20 – 22) Fun idaniloju a fi pamo fumo fun ojo merin.  A o yan ni ojo kewa osu, a o fi pamo di ojo kerinla lasiko ti a o ma boju to daadaa – ni idi eyi ijade si gbangba Oluwa wa nfe abojuto gidi ni iyewo ati lati fi mimo re han (Luke 11:53 – 54; Jh 8:45, 18:38).
2.        Dandan ni ki a pa – (Ek 12:6, Jh 12:24, Heb 9:22) A ni lati gbe iku yewo nipa wi pe tani o ye fun, eni ti o se ni tabi alaise ti a fi ropo.  Jeki a wo lilo oro “on” ni ese kefa (vs 6).   Aimoye egberun odo aguntan ni yio ku ni ale ojo na, kini idi  ti Olorun fi so pe “on”?  Nitori pe gbogbo awon odo aguntan wonyii ntoka si eyo kansoso, odo aguntan Olorun ti irekoja ti a ni lati pa.  Tun se akiyesi “odo aguntan kan” (vs 3) “odo aguntan na” (vs 4) ati si “odo aguntan re” (vs 5).  Jesu ki kan se “odo aguntan kan” ti Olorun, oni lati je “odo aguntan re” ati eni ti o ra o pada (se ayewo Johanu 9 nibi ti okunrin afoju yen tit un bo ni oye – nipa Jesu si).
3.        A ni lati mu eje na lo – (Ex 12:7) o so nipa igbala ara eni ati pe ki se gbogbo eniyan ni a o gbala bi ko se awon ti o je wi pe nipa igbagbo gba ifirubo Jesu Kristi (Jh 3:36) Olorun ko wo iru ile wo ni ebi kan ngbe, o kere ni tabi o tobi, won lowo ni tabi won talaka “O now Eje”, ko wo ohun ti enikeni je.  Nwon le je iran Abrahamu o, ki won si kola sugbon ti won ko ba lo eje, gbogbo re ja si asan.
4.        A pa odo aguntan naa ki o le je ounje fun won – Nitori ale ojo na, ni won yio fi ile Egpiti sile won yio si ni lo okun fun irin ajo won (Ex 12:18, 11,14 – 15.  Nwon ko gbodo fi nkankan sofo, ninu eran na nipa bibo ninu omi, afi ki won yan.  Eyi ni ti o ti ri iriri iku ati ina wa di ounje.  Aworan Oluwa to re wa leyi nitori lehin igba ti o ni iriri ina kafari o wa di ounje fun awon ti o gbagbo (Mt 26:26).  Ise ati eto wa ni lati je nibe sugbon ki se eyi ni yio fun wa ni igbala, ki a sora ki o ma je ariya asan.  Ranti pe won ko gbodo fi ikankan sile di owuro ojo keji.  A sin Kristi ni koko ki ile to su nitori o je odo aguntan irekoja Olorun.
5.        A ko gbodo fo egungun re Kankan – (Ex 12:46, Num 9:12) Iku odo aguntan ni a bere fun ki se si salogbe.  Olorun ti seto pe lehin igbati Kristi ba ti san gbese iku tan ki a toju ara re bi ohun mimo ni, ki se bi ogbe.  Iru apeere yi lari ninu Jh 19:36.
6.        Ki won fi ewe kikoro je odo aguntan na – (Ex 12:8) Eyi duro fun bi isin lu nwon ni ile Egipiti ti koro to.  A mo ju bee lo eko gidi lo je fun w ape o fi ibanuje ati ironupiwada lori ese wa ti o fa iku odo aguntan Olorun wa, se kan pa.
7.        Akara aiwu ati ewe kikoru ni nwon yo fi je odo aguntan na – (Ex 12:15) Wiwa je iru apeere ibi iwa buburu, eke a si ma ba gbogbo ohun ti o dara je ti o ba ti fi ara kan, (Lk 12:1; I Kor 5:6 – 8).  Ninu Mt 16:16 ikilo Jesu da lori iwukara ti awon Farisi (Eyi ti o duro fun fifi asa siwaju oro Olorun) ati ti awon Sadusi (Eko odi). O ni ohun aye ni awon Sadusi tin won si lodi si emi ati ajinde.  Ninu Mk 8:15, o kilo lori iwukara  ti Herodu (ohun ti aye, ore pelu aye).
8.        Jije nso nipa ibasepo – Ko lesi ibasepo Pataki pelu Oluwa ti iwukara die ba wa (Ese) ninu okan wa.  Awon ogbologbo Ju ti o de oni paapaa wa inu ile won daadaa fun iwukara ki o to di igba irekoja, nitorina o ye ki a wo okan wa fun iwukara ki a si gbogbo nnkan ti o le di ibasepo wa pelu Olorun sonu siwaju.
9.        Nwon yio je akara alaiwu yi fun ojo meje – Eeeje je nomba ti o pe ti o nfi iyipo igba han (Lehin ojo meje ose mi bere) Olorun fi ojo meje tin se ose le le, opo ohun ni a fihan ni meje meje ninu iwe ifihan.  O so nipa ese, o sigbe gbogbo asiko wa lori ile aye si egbe kan.  Jawo kuro ninu iwukara ko dara to ki a bojuto ibalopo wa pelu Olorun.  Olorun fa oju ro si awon eniyan re ti o ndese, se akiyesi oro yi “A o ge kuro” ninu (Ex 12:15) nipa eni yowu ti o ba je iwukara.
ADALU ENIYAN – (Ex 12:38) Awon iran miran sese ki won ti fe awon omo Israeli, ti won ko ni fe pinya pelu awon molebi won.  Awon miran tele won nigba ti won ri owo nla Olorun.  Ti won nri gbangba bi Olorun ti bukun awon omo Israeli, won yara fara mo won lati wa “ina rerer Olorun sugbon lai ni ironupiwada okan.  Awon wonyi ni gbogbo nkan koko nsu.  Ijoba ota yi ko le sa dede fi awon omo Israeli sile bee ki won ma lo, nidi eyi won fi awon omo Egipiti die se alabarin won lo si ile Kenani.
IKUUKU AWOSANMO ATI INA (Ex 12:21 – 22; 40:34 – 38) opo yi wa ba won lehin igba ti a fie je se aabo won.  Wo iwe Efe 1:13,14.  O je apeere pe Olorun wa nibe, apeere Emi mimo, o nfun won ni aabo kuro lowo awon omo ogun Egipiti.  Opolopo igba ni Emi mimo nje aabo fun wa.  A fun won ni ikuuku yi lati ma  to won ninu aginju.  Be na ni baba ran Emi mimo lati ma to wa (Jh 16:13; Rom 8:14).
MARAH ATI ELIMU (Ex 15:22 – 27) won rin irin ajo won lai ronu, nigba ti won si ri ikan o koro bi iwo, kanran ki won gboju wo Olorun se ni won tun nkun si Mose, lai bikita pe ikuuku yi lo se atona won de ibe.  Eyi ni igba miran ti a ba ndebi fun awon elomiran lori ohun ti o ba sele si wa, ti ore ba jawa kule.  A nda won lebi nipa gbigba gbe “Ikuuku” ti o to wa lo si ibe.  Omi Marah koro ko si le tan ongbe won, bi omi ti aye nfun ni ti ri niyi.  Awon onigbagbo titun ma nro wi pe ni iwon igba ti awon ti gbagbo ninu Jesu gbogbo nnkan yio rorun ati pe Olorun yio gba won lowo wahala ati inunibini be ko o.  Ni iwon igba ti a ba wa ninu aye ti o ko Olorun yi, hen, wahala yow a ki eni ti o ba sese gba Jesu gbo mura sile fun eyi.
            Ki ni o woo mi na san?  Igi ti a so sinu re ti apeere Kristi fun rara re (ye orin Solomoni 2:3) ti o le ba wa so ikoro aye wa yi di dundun.  Paapaa o tun je iru apeere agbelebu (I Pet 2:24; Fil 3:10) Paulu ati Sila ti o wa ninu ogba ewon ni iriri marah, sugbon bi won ti npin ni “ibasepo ijiya re” a ri “igi ti o mu omi kikoro dun.  Bi Mose ti lo igi na ni o ye ka ma lo agbelebu lojojumo, ki a si se akiyesi iponju ati inira ti o wa ni aye onigbagbo bi anfani lati je alabapin ninu ijiya Kristi.
            Se akiyesi ohun ti Mose se “o kigbe be Oluwa” idi ti “Marah” wa ni lati mu wa sun mo Olorun.  Ps 107 fi eyi han lera lera bayi pe “Nigbana ni won kigbe pe Oluwa ninu isoro won” se ni a nti won ba Olorun.  Be naa ni awa na ni igba miran.
            Nigbawo ni Olorun se igbese? Nigba ti alagbawi kan be ke pe Olorun – Mose je iru alagbawi wa (Heb 7:25).  Mose ni eko nipa ipese Olorun ni kete ti Olorun lati fi ipese oore ofe fun wa ni igba ti o wulo fun wa.
            Lehin marah Olorun mu won losi Elimu nibi ti won ti ri kanga mejila ti o ni omi ati adorin igi ope, o je ibi ti o gba oorun ti o si tutu.  Kanga kan soso ti o koro ni kanga mejila ti o dun daadaa tele ati adorin igi ope.  Ki a ma se aponle pupo lori aye kikoro kanga na.  Fi okan re si ti kanga mejila yi.
AGINJU NA (Ex 13:17) - “Lehin igba ti won rekoja okun pupa, awon omo Israeli tesiwaju ni ojo meta sinu aginju”.  Ki se erongba Olorun lati pe ki won fi ibe se ile won, onirin ajo ni won ti won nrekoja lo.  Elerlan ara a ma ri opo nkan ti o nfa ni mora ninu aye, sugbon si eni Emi o je “Asan ati ohun ibinu fun Emi”.  Aginju yi nwasu “ife eran ara” “ife oju” ati “igberaga aye” lai wulo fun…….tuntun.  Irorun ese dida ko te ni lorun mo.  Ni won  igbati a ba ti jeun pelu Kristi aye ti a ngbe ko ni nkan se pelu ongbe okan wa.
MANNA NA (Ex 16:14 – 35) Je iru apeere Kristi, iyipada oro ati bibeli paapaa, oro ti a ko, ounje awon onigbagbo ninu aginju (Jh 6:31 -35).
            Ounje ti won mu wa lati Egipiti tan leyin igba ti won fi Elimu sile, nwon sin kun si Mose.  Mose fi ye won pe kikun won ko ni nkan se pelu won bikose si Olorun (vs 6).  Ni igba miran ti a ban kun si awon olori wa, o ye ki a se ayewo okan wa daadaa.  A o se akiyesi pe kikun si Olorun ni.  Nitori iberu ti a ni si Olorun a kuku wan fu ikanra mo awon iranse re.
Eje ki a wo die ninu eko ti Emi ti Manna ko wa:
a.         Ese 4 wipe “A ni lati gbaajo” Olorun ko kan ma ko da si nwon lenu.  Eni kan ni Olorun nbo awon eye sugbon nwon se laala fun gbogbo ohun ti won nri je ni.  Eyi ko wa ni akikanju, ko si aaye fun isole ninu eto Olorun.
b.        A fun nwon ni Manna “nitoripe won nfe” se bi nitori eyi ni Olorun fi fun wa ni omo re nitori pe ohun ti a fe ju ni?  Bakanna o fun wa ni oro re lati je ounje ni ojojumo.
d.        O je ipese agbara nla Olorun (vs 4) Bibeli je iwe agbara nla Olorun fun wa.
e.         “Ojojumo ni nwon yio ma ko” a fi ni ojo isinmi nkan.  Iranti ohun tin won je lana ko le ran nwon lowo loni.  Mo ni lati ni iwon titun fun toni.  Eyi ti yio pese okun si ara wa.  Ki ise ki a kan ka oro na lasan bikose pe ki Oluka kookan mu lo daadaa fun ara won.  Opolopo gbekele ounje Emi tin won ngbo ni ojo isinmi ni oso ose.
e.         Manna je jije ki se wiwo lasan tabi gbigbadun lasan.  Ai kobi ara si tabi ijekuje le ba ago ara je, bakanna ni aikobiara si ounje Emi le fa okan to rewesi ati aare Emi.  Opo gbadun Kristi sugbon eyi ko to bi ki a feran ounje sugbon ki a koko pa ninu sise re.
              Ani lati ma se ijiroro lori oro Olorun “Jije ni” bi a ti run ounje lenu fun mimu ohun elo inu re.  Ma kanju ka rara.  Ma si oju iwe itan na ninu okan re, ro jinle gege bi Maria ti se (Luke 2:19) ati bi alabukun nni nini (Psalm 1).  Mu ono na tabi alaye lototo, ro jinle lati fa itumo re yo ati ohun ti o le fi we, se akiyesi bi ewure ti nje koriko tan ti yoo si dobale pese lati ma run daadaa lenu.  Eyi gba asiko, ki a ma sare ka oro Olorun tabi gbigbo re lasan ko to pin.
Gbe Kristi ye wo daadaa gege bi o ti ri ninu awon iwe (gospels) to nrin laarin awon eniyan, ti o sin se erongba baba re yato si ti eje jije manna.  Eyi je idahun si “wara” bi ounje fun awon odo ninu igbagbo.  Wo siwaju bi a se fihan ninu Episteli ti a o ti ri “Eran” oro na (Heb 5:13, 14).
f.         Manna sunmo won tabi………….nwon.  Ni idi eyi Kristi sunmo wa ati wi pe oro Olorun yi wa ni arowoto wa.
g.         On njabo lojojumo.  A ni lati ni igbagbo gidi ti a o fi gba pe a o ri won ko.  Ranti “fun mi ni ounje ojo mi loni”.
APATA TI A LU (Ex 17:1 – 6) Eyi je iru ti Kristi ti a sa logbe fun wa (I Kor. 10:4) omi ti nro jade lara apata yi je irufe igbala nipase oore ofe fun awon eniyan  ti ko to si rara.

APEERE IGBALA NIPA OORE OFE
a.         Ofe ni (Jh 4:10, Rom 3:23, Efe 2:8)
b.        O po repete (Rom 5:20; Ps 105:41, Jh 3:16)
d.        O wa nitosi (Rom 10:8)
e.         Ki awon eniyan kan nowo mu ni (Isa 55:1)
            Iriri awon omo Israeli yi je iru apeere elese ti o nmu mi tooto ti o njade lara kristeni ti o wa nfi ipa eyi wo inu atunbi lo, to si ntubo nmu omi na fun itura ojojumo.

IJAGUN NWON PELU AMALEKI NI REPHIDIMU (Ex 17:8 – 15)
            O sese ki o je pe nitori omi ti awon Israeli ri mu ni awon Amaleki se gbe ogun wa ba won nitori wi pe omi won pupo ni asale si ma da ija sile laarin awon ara atijo.
            Amaleki je iru apeere iwa wa atijo, ki o to di wi pe a ni igbala ni a ti ni awon iwa atijo yi.  Sugbon nipa atunbi a gba iwa otun, Emi Olorun (Jh 3:5,6)>  Ti a ko ba mu iwa atijo kuro Kristieni tuntun yio mani iporuru okan ti ko mori, iwa ti atijo ni o nfa ijangbon pelu ti tuntun ti o mo (Gal 5:17, Rom 7).  Gbogbo Kristieni ni o ni iwa meji yi, okana ti o kun fun ese, ekeji ti ko ni ese.  Awon iwa yato si ara won, won tako ara won.
            Amaleki gbe ogun de lehin igbati awon omo Israeli ti nmu omi agbara Emi ti o nya lati apata na, ti a sin se agbeyewo iru ogun ti iwa atijo ti o nbere ni kete ti a ba ti mu omi iye na.  Awon omo Israeli o ja ogun Kankan ni ile Egipiti o, okun pupa paapaa, ko je nnkankan, sugbon nig ere ti a fun nwon ni ohun kan ti o duro fun Emi mimo Amaleki dide lati ta ko won.
AARONI IRU APEERE ALUFA AGBA WA (EX 28)
Akiyesi:-  Kristieni je alufa lehin Melksedeki (Eyi ti o fi je wi pe “ O nse amuse re lera lera” Jije Alufa tire je  ti ayeraye, ki se bi  ti Alufa  ti Aaroni je ti iku da lowo ko.  Bi o ti wu kori o tele ipa ti Aaroni nfi nse ise re nipa rirubo fun ese.
a.         Aaroni je alufa nipa yiyan ati orun wa (Ex 28:1).  Bi o se je be wa ninu iwe (Heb 5:4 – 6)
b.        Nigbana on ni alufa ti o le se irubo (Lef 16:1 – 3) Be ni pelu Kristi ti nse odi iru apeere na (Heb 9:7 – 12).
TABANAKU NA –  (Ex 25:31, 35 – 42) Ni iwon igbati ekun rere ikeko yio waye lori Tabanaku lai pe awon ori kokan ni a o gbe yewo laipe bakanna.
ISE ALUFA TI LEFITIKU – (Ex 28, Rev 5:10) Eyi wa fun awon eniyan kan tin won jinna si Olorun ti o nfe enikan ti yio mu nwon sunmo Olorun, eni yi yio ma fi ara han niwaju Olorun nitori awon eniyan yi.  Nipato ise Alufa yi je ijiroro (tabi alarina) laarin Olorun mimo ati awon eniyan elese yi.  Ise Alufa yi bojuto irorun otun ati osi – Olorun ati eniyan, nwon nse abojuto awon ti o nse, nwon mu won ni ibi kan, nwon duro fun Olorun si awon eniyan nipa kiko won ni ofin Olorun (Deut 33: 8 – 11).
a.         Awon ipele:- (1) Awon Lefi (2) Awon Alufa ati (3) Olori Alufa.  Olorun yan iran Lefi ni Pataki fun ihinrere re (Num 8: 11, 16, 19).  Ni arin iran Lefi ni a ti yan ebi kan laayo, eyi ni ebi Aaroni, lati ma sun mo Olorun ati lati soju awon miran.  O si fi Aaroni ni se Olori Alufa.
b.        Ise iranse tabi ise nwon – (Num 4:1 – 33)
1.        Awon Lefi wa lati inu eya meta: Gershorinti, Kohathiti ati Merariti.  Nwon ni lati je oluranlowo Pataki fun Aaroni ati awon Alufa (Num 8:19).  Ise nwon lati ma bojuto Tabanaku, nwon ma to ni gbogbo ibi tin won ba ti duro, nwon a ma tu, nwon o ma gbe gbogbo awon ohun elo nwon.  Ebi kookan ninu meta yi ni Olorun ti fun ni ohun ti nwon o ma se.  Ise nwon yi je iirufe isesi awa Kristeni.  Olorun ni ise fun eni kookan wa lati se.  E jeki a wa aaye ti o ni fun wa, ki a ma jowo ipo ti enikeni tabi ise nwon.  Awon omo Lefi nse iranwo ni pipa ati gige awon eran fun irubo.  Lefi je iranwo fun awon alufa ati nipa kiko awon eniyan ni eko Olorun, kin won fi mo Olorun, erongba re ati awon ona re (Lef 10:11) o se se ko je pe idi niyi ti Olorun fi fon nwon kakiri ile Israeli kin won le wa ni arowoto gbogbo awon eniyan.
2.        Awon Alufa (ati olori Alufa) – nba awon eniyan se irubo.  Nwon nse oju awon eniyan ti won ba ti wo inu Tabanaku lati josin fun Olorun nwon je irufe apeere awa onigbagbo nitoripe a je ijoba awon alufa ti yio ma kede fun awon miran ti a o sit un ma josin fun Olorun (I Pet 2:5, 9; Ifi 1:6, 5:10; Heb 13:15)
3.        Olori Alufa nikan ni o le se irubo fun awon eniyan.
d.        Awon Amuye fun Alufa sise
1.        Nwon ni lati je eya Lefi ati idile Aaroni.  A yan nwon lati inu omo Israeli (Ex 28:1), ijoba awon Alufa – ti Olorun fi awon omo Israeli se  (Ex 19:6) ni idi eyi okan na ni won, won si duro fun nwon, Kristi di eniyan o si di ara wa ati wi pe o duro fun wa pelu, niwaju Olorun (Heb 5:1)
2.        Nwon ko gbodo ni abawon lara.  Gege bi asoju Olorun ati eniyaan o di dandan ki nwon wa ni pipe iru iwa mimo ti ko ni abawon ti Olorun nfe ninu awon ojise re.
3.        Nwon ni lati yara won kuro si ohun idibaje (Lefi 22) wo Isa 52:11 na.
e.         Gbedeke Nwon:- Ki ni idi ti a se mu nwon ta kete siwaju? Kini idi ti a fid a awon omo Lefi lowoko lati wo “Ibi mimo” ati awon Alufa paapaa ko fi ni anfaani pupo?  Ati Olori Alufa paapaa ko fi le wo “Ibi mimo julo” ju eekan lodun lo? Awon gbedeke tabi idalowoko yi ti o kan eniyan ati awon Alufa ni Olorun gbe kale ni lati fi iberu ati owo fun Olorun ti o ga julo, mimo julo ti a nsin.
e.         Igba ti Nwon yio fi sise:- Awon Lefi sise lati ooooooogbon (30 years) odun si adota odun (50 years) (Num 4:22, 23, 29,30; 8:25, 26).  Awon Alufa ati Oloru Alufa yio sise titi yio fi ku ni.
f.         Ipese Won:- Awon Lefi ngba idamewa lati owo awon eniyan (Num 18:13, 15:17 – 21, 2 Kro 31:5,6).  Nwon a sit un ma fun nwon ni idamewa ikogun (Num 18:27 – 30) Nwon tile ya awon ilu kan soto fun awon Lefi, ninu awon ilu wonyi ni ilu aabo mefa” (Num 35:2 – 4).  Awon Lefi paapaa ma nya idamewa ohun ti o ba wole si owo won sile fun itoju awon alufa ati olori alufa (Num 18:26).
ORO ITASORI: - Ex 30:23 – 33 – Awon ohun elo merin ni a o fi sinu ororo olifi.  Gbogbo won wa lati ara igi ti a ba nsoro eniyan ninu aye.  Nwon je ohun oloorun didun, ti o so nipa oorun didun Kristi bi eniyan lori ile aye.  Myrrh je gomu ti a ri ni ara igi kan ni ile Arabia.  O ni oorun didun sugbon o koro lenu.  A menuba Myrrh yi ninu “Orin Solomoni, o so nipa oorun didun ti o ntu jade niti ife Kristi ati paapaa ti ikoro ti iku re (Jh 19:39).  Goomu myrry ma ntu jade lara, epo igi na, ti a ba t sa logbe.  Ife Kristi fun Baba re a ma tu jade googo ati paapaa nigbati a sa logbe lori agbelebu.  “Sinamoni” ni a nri lati epo odo asese yo igi kan ti o ma ntutu yipo odun (itumo eya iru “Sinamoni” yi ko iti ye ni).
            Oorun re ni a ma nri yo lehin igba ti a ba gun igi kalamusi.  Kristi ju ara re sile fun awon owo ibi ti o gun (fi iya je) o si wa fi oorun re kun orun on aye nipa eyi (irufe itumo “kassia ko iti yewa).
            Ohun kan ti o se pataki nipa ororo ifiyan yi nip e ki a ma daba lati se iru re rara (vs 31).  Ororo na yio wa fun ifiyan, ki se fun isogo tabi igbadun omo eniyan.  A ri ninu iwe 2 Kor. 1:22 Olorun fi Emi mimo yan eniyan.  Wo iwe Gal 4:6 na.  Eran ara ko le mu ore ofe ti Emi jade.  Awon Alufa ni a nya pelu ororo ti o nfi yiyan awon Alufa ti ode oni han, to je wipe looto ni nwon je atunbi onigbagbo.  Ko gbodo si eda re nitori ti ororo yi fi mimo alailabawon ti Kristi je han.  Ko gbodo si afiwe ise igbagbo wa.   Anania ati Safira (Ise A. Ap 5) ti won se afarawe igbese Emi mimo a sir o ori odajo ti o sele si nwon, (tun wo ikilo nipa turari ajoji ni v 37) eyi  ti a o gbe yewo nigba  ti a ban ka nipa pepe turari ti a ba nko nipa Tabanaku.
            Eko miran ti o se koko ninu “oro” na ni “Enikeni ti o ba fi ninu re si ori alejo” (Ex 30:38).  Ki ise wi pe ki o ma si eda Emi mimo nipa igberage nikan sugbon alainigbala (Alejo) ni a ko gbodo gba fun tabi ki oni lowo lati ni pin ninu awon nkan mimo Olorun, laisi ironupiwada to gbamuse siwaju igbese yi.  Bi be ko, nwon o ma ro wi pea won ti se ojuse nwon ni nidi eyi nwon o wa foju si ohun ti o nse eto nwon lati se nipa rire ara nwon sile ati ironupiwada.  A ko gbodo je kin won ro pe ko si isoro Kankan fun nwon.

AWON IRUFE TI O WA NINU LEFITIKU
            Awon irufe yi po gan ni.  A gba akeko niyanju kin won fi ara bale, kin won gbadura daadaa fun imo iyanu ti yio ma je sisi nipa Kristi
1.        Awon irubo ti Lefitiku (Chapters 1 – 7) Eyi je marun a sit un pin si ona meji.

                            Oorun didun
                    Alaidun
             Jije Chapter 1
            Ounje Chapter 2
            Alafia Chapter 3
            Eyi je ti o ba wun     
            Iwa mimo so wi pe                                        
     (Sin) Ese Chapter 4
     Irekoja Chapter 5         

                       Eyi  yi je dandan

·       Ki a ma dese
·       Ki a ma se ohun rere gbogbo.
            Ninu irubo oloorun didun a ri Kristi bi eni ti o pe ju fun itewogba fun Olorun, ki ise nitori wi pe ko da ese Kankan, bikose pe ko kuna ri lati ma se rere.  Igbe aye re nte siwaju ninu ore oloorun didun si Olorun.  Ore oloorun didun wan so nipa bi ifirubo Kristi ti je si Olorun.  Eyi ti ko ni oorun didun fihan bi ifirubo Kristi ti je si wa.  Se akiyesi atenumo awon oro yi “A o dariji” ninu 4:20, 26, 31, 35, 5:10, 13, 16, 18, 6:7.
            Bi a se se agbekale oruko irubo wonyi ko wa ni eko.  Olorun bere lati odo ara re ki o  to gbede odo wa ninu irubo ese ati irukoja.  Heb 9:14 so fun w ape Kristi fi ara re rubo lailabawon.  Eyi ni irubo ti oorun didun ti o fi Kristi han bi o ti mu erongba Olorun se.
            Wayi o eje ki a wo bi ikokan irubo na ti je irufe abi apeere ise Kristi fun wa.
(a)       IRUBO OORUN DIDUN (Chaps 1 – 3)
1.        EBO OHUN SISUN – A npe eleyi be nitori pe gbogbo eran na ni a o sun lori pepe aya fi eje irun ara re vs 9.  O gbodo je ebo atinuwa bi iru eyi ti Kristi finu findo ku fun wa.  Idi niyi ti o fi je ebo Oloorun didun si Olorun.  Ero ati je ni yak o muna doko rara.  Eni ti o nrubo ti o mo ara re ni elese (eyi ti o tokasi igbowo leni lori) ko ni emi ijebi ni okan re nipa awon koko irekoja.  Bi o ti nranti ohun ti o sele na lo ngbero ifi okan sin Olorun ti o le sele na lo ngbero ifi okan sin Olorun ti o ye ko wa ti o si nbo.
            Awon eran ti o ye fun irubo yi je okan ninu awon wonyi.  “MALU (EGBORO)” apeere pe Kristi je alagbara ati oni suru iranse ti o ngba ipo awa tin se omo odo (iranse) alailere.  “Aguntan tabi odo aguntan” ni apeere Kristi ti ko janpata ti o jowo ara re titi de ori igi Agbelenu “Ewure” apeere elese ti Kristi gba ipo re “koko laarin awon irekoja”.  Odere koko tabi eyele ni iru apeere pe “O titori tiwa di talaka ki a le tipase eyi di olowo”.  Gbogbo awon ohun irubo wonyi ko gbodo ni abawon Kankan vs 3).  A nda ebo ati ohun irubo mo nipa igbowole olurubo si ori ohun irubo na ni ifihan pe o ti fi ropo ara re.
            Ina ori pepe je itewogba ohun irubo elese na.
            Ebo sisun odo aguntan olodun kan (Ex 29:39 – 40) omo Israeli fun irubo ni owuro nigba ti ekeji rubo ni asale ni ojojumo.  Nwon ni lati se bayi lojojumo lera lera.  Eyi tin won yio fi rubo ni asale nigba ti ko si pajawiri lori pepe yi yio jina ni were ni gbogbo ala ni.  Eyi legbekan ni o duro fun iwalaye irubo ti o nduro fun bi Israeli awon eniyan ileri Olorun se ni lati ma se ife ti Olorun.  Kristi fi apeere yi han.  A ni lati fi ara wa han gege bi irubo aaye fun Olorun, nipa wiwa ti mo ife re tooto.
 2.       IRUBO TI OUNJE Chapter 2 (Eyi ki se eran ara eranko gege bi iwe mimo (king James) tipe a mo awon nnkan bi iresi tabi baba) irubo atinuwa miran ni eyi ti o nse apejuwe Kristi bi omo eniyan ti ope ni iye lori ile aye.   O je ebo ti ko ni eje, fun idi eyi awon ma nse pelu ebo sisun ni (Lef 23:18).  Yio je iye fun ti o kunna daadaa, itumo wi pe a o lo iresi, baba tabi witi na kunna eyi ti o nfi ise Kristi han.  A o fi oi pelu re, eyi ti o fihan pe lehin igba ti a bi Kristi a se iribomi ti Emi mimo fun.  Turari “frankincense” fi iru oorun didun ti igbe aye Kristi si Olorun ati eniyan.  “IYO” vs 13 ko gbodo nwon ni rara.  Ohun elo daadaa ni fun ki nkan (Eran) ma tete di baje.  Iyo tun je apeere iwa ati esin ti o mon.  Iwukara ati oyin ni a mu kuro lara awon nnkan wonyi.  A ti mo nipa iwukara ni isiwaju.  Oyin lo je ohun  ti odun ju ti o si wulo fun ago ara.  Olorun fe ki a mo wi pe gbogbo ohun ti o ban je ago ara wa logun ko ba ohun lara mu rara.  Oyin duro fun nkan elo eniyan ti o dun ti o si fa ni mora ki a to dan wo (pelu ina) ki se pe Olorun ko fe ohun eran ara nikan, sugbon o nfe ohun ti o le gba idanwo ina sara duro.  Ki ni ise wa si awon eniyan ti a nba pade – se ni ti oyin ati turari frankincense ni? O di dandan ki ina subu.  Nigba ti isoro ba gbogun ti wa, ti awon eniyan nse inunibini si wa, ti ojo iwaju paapaa ko daju nje a nlayo (se inu wan dun)? 2 Kor 2:15.
3.        EBO ALAAFIA Lef 3 – Eyi na je atinuwa, a o sun ora ebo yi lori pepe, aya ati ayika apa otun ni alufa yio ju belebele niwaju Olorun lati fihan wi pe a nse irubo si, awon eka yi ni yio je ti alufa ti o nse ise irubo na (7:14, 31, 34).  Alufa yio pe omo Lefi ti o ba je alaini, opo ati omo alaini baba (Deut 16:11).  Sugbon o kan dandan ki nowon je “niwaju Oluwa” nibi ti Oluwa ti fi oruko re si ti o si je ogba Tabanaku.  To ba se ku di ojo keji a ni lati sun ni (Lef 7:15 – 17).  Ni pase ebo yi, olurubo ni anfani ajose pelu Olorun ati awon Alufa re ni ibi tabili re ati awon miran ti o je mimo ninu eto na.  Niti wa, o so nipa ajosepo awon onigbagbo pelu Olorun nipase Krisiti.  Awon ibi (eka) ti a fi sile fun awon alufa ko wa ni eko daradara: Aya apeere ife; ejika ibi agbara ati okun.  Bi Kristi ti fi gbogbo ife re ati agbara fun baba re, be na ni awa na se ye ki a fi gbogbo ohun fun Olorun
            Gege bi ounje ti je baraku fun wa, be gege ti a ba nfi igbe aye Kristi se ounje wa, be na ni awon iwa re yio di baraku fun wa.
EBO ALAILORUN DIDUN: Lef 4 – 6:  Eyi duro fun gbogbo ijakule tabi iwa kuwa elese ti o ko le Kristi lori ti on sig be lo ba Olorun ko da pelu aito si itewogba elese lodo Olorun.  Ni idi eyi Olorun onidajo ba Jesu Kristi wi dipo elese gangan.  Dandan ni irubo yi.
1.        IRUBE ESE: Lef 4:1, 6:13 – Awon wonyi tokasi orisirisi ese si Olorun.  Awon ese yi ki se ti aimokan bikose ti aimomoda, ti asise ti aigboran tabi afojufo.  Oro yi kanna ni a nlo fun eni ti ko momo paniyan (Num 35:11).
            Fun awon ese ti a momo da, akanse ese, bi eyi ti a fi ntako ase Olorun ko ni irubo ti a gba laaye fun eyi (Num 15:28 – 30).
            Irubo ese ni apeere Kristi ti o die se fun wa, ti o ku dipo wa (I Kor 5:21, Heb 13:12, Isa 53, Ps 22).  O yi ofin pada fun wa.
            Gbogbo eko eran irubo na ni yio di jijo ni eyin ago (Lef 4:12) ki se lori pepe ni Tabanaku.  Eje re nikan ni a o mu wo inu Tabanaku, ti a o si won ni emeje siwaju iboju ti inu lohun.  A o tun fi si ori iwo pepe ifi turari.  A o si da eyi ti o ku si ese pepe ina.  Ranti pe a mu Krisiti lo jade si ehin ago (Jerusalemu) a si fi rubo (Heb 13:10, 13).
Ore irekoja Lef 5:14 si 6:7:- A le pin eyi si ona meji, akoko awon eyi ti a se si “ohun mimo Oluwa” (5:15) bi o ti wa ninu idamewa ati eso akoko ati ilodi irekoja si as Olorun ti a nse laimo ati laini ironu (5:17 – 19).  Ipa keji (6:1 – 7) to awon irekoja oniruru si awon omo enikeji wa.  Sugbon ese na lodi si eda Olorun ti a sa logbe, ni idi eyi dandan ni irubo.  Sugbon a ti je gbese kan si eni ti a se, ki a le san oju owo pada ati afikun marun pelu.  Wonyi yi ni awon ese ti a se laimo, tabi labe adanwo gidi.  Elese ni lati ronupiwada, ki o si se atunse niwaju Olorun nikan ko ati niwaju eni ti o se paapaa.
            Irubo yi tokasi Kristi ti o ru gbogbo iwa ese wa (Mt 1:21; I Pet 2:24, I Jh 2:2, Psa 51).   Isatunse je koko ninu irekoja.  Eni na yio da gbogbo ohun  ti o ti gba (lona eru) pada tabi ki o se idiwon iye won ki o si fi idamarun kun 5:15.  Ese yin so nipa “ohun mimo” asi le fi we idamewa ti o to si Oluwa, se akiyesi Lef 7:25 ni ibi ti a  tin mu ohun ti o je ti Olorun pato lo fun ara wa, kanran ki a fi fun Olorun.
IYASIMIMO AWON ALUFA: Lef 8:1 si 9:25; Ex 28:41 si 29:24).  Nwon o ya ara won si mimo nwon kan jowo ara won fun ise ni (Rom 6:13, 12:1).  Mose ti o nsoju Olorun ni o nboju to gbogbo re fun un.
            A le pin ayeye iyasimimo si aimoye ipa:
i.          IFAMI ORORO YAN OLORUN ALUFA (8:10 – 12).  Ti Aaroni ya to gidi si ti awon Alufa toku nitori wipe a yan ki o to di wipe a bere awon irubo ni, awon Alufa toku yi o koko fi owo ba eje.  Yiyan ti Aaroni kun pupo niye, se ni a da ororo ifiyan le Aaroni lori repete (Psa 133:2) sugbon nse ni a won si awon Alufa toku.  Kristi alaidese, ti Aaroni nse apeere re ko ni se pelu ororo ifiyan rara ohun ni ami Emi mimo.  Ni afikun, dida ororo ifiyan le Aaroni lori je bi Kristi ti gba ainiye Emi mimo (Jh 3:34; Heb 1:9).  Aaroni duro gboin lori eleyi titi di igba itaje sile (Eyi ni iku Krisiti ni Kalfari) Aaroni ati awon omo re ko le duro papo.
ii.         EWU AWON ALUFA (Lef 8:13):- Bi Aaron se je apeere iru Kristi ni awon omo re je iru onigbagbo alufa.  Aso nwon je aala funfun gboo ti o nfi iwa mimo han.
iii.        ORE WON (Lef 8:14 – 22):- Se akiyesi eto irubo na: ekinni ni (1) irubo ese, lehin ti se iwenu ese yi ni o kan (2) Ebo Sisun ti o duro fun ijowo ara wa sile fun Olorun patapata; eyi ti o kanyin (3) agbo iyasimimo.  Ninu igbese kookan ni Aaroni ati awon omo re ni lati fi owo nwon le irubo na lati fihan pen won lowo sip e ohun ni iropo na fun nwon.
iv.        LILO EJE IYASIMIMO (Lef 8:23 – 26):- Lehin irubo ese ati ebo sisun, ni a o to pa agbo irubo iyasimimo na.  A o fie je si (1) eti re otun, eyi ni lati ma fi eti si oro Olorun;  A o tun (2) fi si atanpako owo otun re, eyi fihan pe o ni lati ma sise fun Olorun;  A o kan si (3) atanpako ese otun re pe ki o ma rin ni ona mimo ati ki o ma sise fun Olorun.  Ni koko a o tun fie je won pepe (8:15, 19,24) eje ti a ta yi ni ipilese gbogbo nnkan.
v.         “EKUN WO” AWON ALUFA (Lef. 8:27 – 29):- Iwon ti Mose ba ko si owo re ni won yoo fi se irubo si Olorun fun mimo pe ohun loni ohun gbogbo ti o sin fun ni ki yo si ohun Kankan lowo nwon titi Mosey o fi de ti yo si duro siwaju Oluwa (Olorun) ti yio si fun won ni nnkan tin won yio fi rubo bakanna ni pelu wa.  Ohunkohun ti a ba fe fi fun Olorun wa lati odo re, o fi fun wa ni.  E wo Oba  oloore ofe ti Olorun je, ti o nbere ore (irubo) lowo wa ohun na ni o tun npese ohun ti a o fi se irubo na.  Bawo ni o se wa to si wa lati hawo ohun ti o fun wa si?
vi.        YIYAN PELU EJE ATI ORORO (Lef 8:30 – 33):- Ofin Olorun si won ni yin so wipe kin won duro ojo meje ati ale meje ninu Tabanaku kin won lo yara simimo fun Olorun (Oluwa).  Eeje je nomba ti ope ti o si daniloju nitori na o ye ki a ya ara wa soto fun odindin “ose kan”, fun esin wa nibi lori ile aye yi, nitori wipe awa na ni ifi ami ororo yan bi  ti awon alufa lati wulo fun Olorun.  Nse lo ye ki a ma gbe ninu iwalaye re (Psa 91:1).  Se akiyesi oro yi “A fi igba ti ojo yi yan re ba sunmole (vs 33).  Ni igba wo ni eleyi yio sele?  Wo ikilo miran si ninu iwe Lef 21:12.
vii.       INA NA (Lef 9:23 – 24):- Lehin ti a ya nwon si mimo tan awon Alufa nab ere ise ijosin won.  Nitori wipe a ti se gbogbo nnkan bi Oluwa  ti palase fun nwon (8:36).  Ogo Olorun farahan si gbogbo awon eniyan, ina si jade siwaju Oluwa o si jo gbogbo ebon a.  Ninu Lef 6:13 Olorun so fun nwon pen won ko gbodo je ki ina ori pepe ku rara.  Isedale awon Juu fihan wipe nwon ko je ki ina yi ku titi di akoko ijoba Manasseh.  Nihin ina yi je apeere ojulowo ifi arajin Kristi si ife          Baba re ti o si je arikose fun wa.  Ina ti Olorun tan si okan wa nikete ti a di Kristieni je ohun ti a ko gbodo je ko kuu.  Ti ina yi ba ku ami yiyan na ku niyen.  A ni lati boju to ki o ma ku nipa ki ama keko bibeli wa lai sinmi, gbigba adura lemolemo, ibasepo pelu Olorun ati awon ebi Olorun ati nipa ki a ma jewo re (Lef 6:13).
viii.      INA AJEJI NADABU ATI ABIHU (Lef 10:1 – 3)
a.         Awon wonyi fi erongba okan tin won dipo ti Olorun nipa mimu ina ti nwon dipo ina ti Olorun ti o fun nwon (Lef 9:24).  Igberaga pe a ti gbe won de ipo Alufa sese ki o ti ko wo okan won (sakiyesi wipe Paulu kilo nipa lilo ope si ipo ( I Tim 3:6).  Awon mejeji wa ro wipe awon ti mo bi awon yio ti ma fin turari lai ti fi idi re han nwon.  Nwon ro lokan won pe iru awon ti koja eni ti yio ma gbase lodo Mose mo.  Ni idi eyi won pa agbakale ofin Olorun ti.  Itumo Naanu ni “Bi o ba se wa”.  Abihu je “Olorun ni Baba”.  Nadabu ti o ni okan igboran “kini o le fa aapon?  Ona wa dara.  Abihu yi je apeere awon eniyan kan ti nma fie nu won yo irin, tin won yoo si se ife okan nwon (Kol 2:23).
                        Awon wonyi lodi si ohun ti Olorun pese fun nwon nipa riro pe ina ti ara nwon na dogba pelu ti Olorun ti o fun nwon.  Satani a ma se eda gbogbo ohun ti Olorun ba se.  Ranti eda ti inu Ananaya ati Safira.
b.        O tun je iru ife itiraka lati ru oro esin soke nipase eran ara lasan bi ki a fe mu igberu ba ijosin ati iyin nipa ara lasan.  Oorun turari kii ru soke lai je wi pe a mu ina lo si.  Bo tile wu ki a ni itara ati aanu bi eleran ara to “ina ajoji” ni yio je.  Enu eke to dun moroyin, itara etan ati ariwo pipa ki yio je itewogba fun Olorun.  Iwe I Sam 4:5 a ri bi awon omo Israeli ti pariwo nla sugbon ti Olorun di ti sin won.  Ilakaka eran ara lasan ni yi je.  Ina a ti oke wa nikan, to wa lati owo Emi mimo lo le mu ijosin ati iyin to to fun Olorun.
ix.        OJO ETUTU (Lef 16:1):- Ki a tie gbe ti ebo ruru ti, olori Alufa se fun ara re si egbe kan na (6:11 – 14) eyi ti ko ni hun se pelu Kristi (Heb 7:26 – 27), koko akolekan ni tie ran ewure meji ati okan Alufa gangan.  Gbogbo eto wonyi ni olori Alufa yio se.  Awon eniyan ko ni nkankan se rara.  Kristi “fun rara re” ni o fa ese wa jade (Heb 1:3).  A kole se ohun Kankan bi etutu fun ese wa.
                        Ninu awon ewure meji ni a ri irubo etutu orisi meji.  Eyi ti a se ami si “fun Oluwa” (vs 8) ati ami eniyan fun “isapere ijiya”.
a.         Ewure ti a pa (je ti Jehofa) eyi ni ipa akoko sise etutu na, ti o nfi han wa bi Oluwa ti fi ara re fun iya je nitori ese wa, ti o tun ku dipo wa; olori Alufa yio gbe eje ebo ese wa, ti o tun ku dipo wa; olori Alufa yio gbe eje ebo ese na lati fi won ibori                 ti o wa ni ibi mimo julo.  Eje yi so di ijoko aanu dipo ti idajo.  Wiwon eje fihan pee to mimo ti ofin nbere fun ni a ti fun, Olorun na yio wa fi aanu re han.  Oro awon Heberu tin won lo ni ibi ti a ti lo oyinbo re “Etutu” tu mo si “ki a bo nkan”, “fi nkan bo” “Bibo” o fi han wa gbangba pe irubo Llelfitiku gboingboin fun bibo ese awon nitori wipe ko si ebo eranko Kankan ti o le mu kuro.  O sese ki Olorun “rekoja” (Rom 3:25) ese nwon nitori pe igbakugba ni agbelebu nwa niwaju re.  Lef 17:11 – Oro Heberu ti o tumo si “Aye” ni o tumo si “Emi”.  Ese yi ni “Emi eran ara wa ninu eje           nitori pee je nse irubo nipase Emi” Isa 53:12 ni Kristi po emi re jade si iku.
b.        Ewure keji ti a pe ni “Isapere ijiya” yi ni awon ese ti awon eniyan njewo bi Alufa ti gbowo te ori ewure na, bi o ti nse eyi o ndan eni na si ori alailese eran irubo na.  Lehin eyi nwon yi o ma lo si aginju, ko si gbodo pada mo.  Ninu ewure yi a ri apeere bi Kristi ti ko gbogbo ese ru sinu ago ara re, ti o si ko nwon lo patapata, a ko si le nwon mo (2 Kor 5:21, I Pet 2:24, Isa 53:6, 44:22; Psa 103:12).

IKEKO INU TABANAKU
IBUGBE OLORUN PELU AWON OMO ISRAELI

            Iwe Bibeli ko lo to ori meji lati se apejuwe didara orun ati ti ile aye ati awon ohun inu re.  Sugbon adota (50) ori ni a fi se apejuwe Tabanaku ati awon ise re.  Kini idi eyi?  Idi ni wipe Tabanaku ni lati je aworan o ni lati kun fofo, nipa omo re ati ise irapada re.
IBUGBE OLORUN (Ex 25:1 – 9)
            Erongba Olorun ni lati ma gbe laarin awon eda owo re (Isa 57:15; 66:1 – 2).  Se ranti pe ese lo da ibasepo tinu ogba Edeni ru nipase satani.  Ibasepo yi ni lati je ohun ti o wulo si Olorun gidi nitori kete ti o da ni, ni Olorun fi eto miran fun atunto liana a je ma nkun si ni ogo, ewa ati isunmo ra eni.

DIAGRAM OF THE CAMP

TANI OLORUN MBA GBE?
a.         Awon ti a ti fie je rapada (Ex 12:12 – 13)
b.        Awon ti a ti yo ninu abode, kuro lowo satani (Farao) ati aye (Egipit) Ex 14:21,22; 15:13)
d.        Awon ti a sa yan fun igboran nipase eje (Ex 20:1 – 3)
e.         Awon ti a bo ti a si da si nigba ti irin ajo ati arinka inu aginju (Ex 16:16 – 18)
e.         Awon ti a gba kuro lowo ese ati iwa ji jinna si Olorun (Ex 33:12 – 14)
f.         Awon ti a gba sinu erongba isinmi Olorun (Ex 35:1 – 3)
ERONGBA FUN TABANAKU
a.         Lati ko awon omo Israeli nipa mimo re – ni di eyi gbogbo ogiri di mo nwon mo ta.
b.        Lati ko nwon nipa ese dida nwon – Ti o mu ki a le nwon jinna si Olorun.
d.        Lati ko nwon pe ona kan soso tin won fi le sun moni nipase irubo.
ETO FUN TABANAKU
            Olorun se eto fun Tabanaku o sig be le Mose lowo lori oke Sinai.  Kosi ohun ti o fi sile fun imo ti eniyan.  Olorun kilo fun Mose pe o gbodo mu gbogbo ese bi a ti seto (Ex 24:1,2; 25 – 28).
            Bi a ti ri itenumo nomba keje ninu Lefitiku ni a ri itenumo “Eeta”.  Eeta je ohun mimo ti o peye.  Eka meta lo wa ninu Tabanaku (ibi gbangba, ibi mimo ati ibi mimo julo) ona tabi ilekun meta (ilekun nla, ti a ba wole ti aarin ati ti inu lohun, orisi ina meta (ti oorun, ti igi olora itanna, ati ogo ti shekina), ibi meta ti a o fie je si (pepe didan, pepe isun turari ati pepe ijoko………….) irorin meta (Wura, oje ati ide) orisi awo meta (………..pupa,…………).  Awo funfun na tun han daadaa.
ASO IBO OGBA NA (Ex 27:9 – 15)
            Igbelewon ogba na 100 kubiti si 50 kubiti (150ft si 75ft), kubiti kan je bi 11/2ft.  Ilekun nla ogba na je 20 kubiti (30 feet) nifife.  Aso ibo abawole ni a fi ko lati opo kan si ekeji lori iko oni oje lori awon opo onide.
            Awon oke tabi ori (ti ape ni olu ilu) ni a………….se.  Agbara wa fun awon opo na nipa se okun ti owa lalti oke de ile ti a fi ko ide oje ti a kan mole ni inu ati leyin aso na.  Awon opo na simile iho inu oje ti a ki bo inu ile iyanrin.
EKO EMI MIMO
a.         Ibugbe Olorun:- ni a yasoto jinna si ohunkohun ti o le je idiwo.  A ko le ku giri lo ba Olorun, a fi lehin irubo iku Kristi, eni Kankan ko le sunmo Apoti Eri Olorun ni ibi igbadura (pepe turara), lati se ijeri fun Olorun (opa igi itanna) tabi ni asepo pelu Olorun ati ayeraye (jije akara).  Aso on nwonyi bon won patapata.  Nitori wi pen won ga ni iwon 7 ½ feet ko si eni ti o le no orun wo ohun ti o nlo lodi keji, koda o tun bole daadaa to be ti ko si eni to tun le rakoro wo abe re.  Iku ni ere ese enikeni tabi alejo ti o ba fi owo kan (Num 3:38).
b.        Aso ti o dara:- Eyi duro fun iwa mimo ninu eniyan ati Olorun, iwa mimo ti a le se akiyesi re lojojumo.  O je ami ailafiwe iwa Olorun, ki kun Emi mimo, ailabawon, igbe aye ti ko leeri, ero, ise ati oro.  Olori Alufa ma now aso funfun nini yi niwaju Olorun nigbati o ba fe se irubo ese (Lef 16:4).
d.        Oje:- ti a fin se iko ati olulu yi ni a nri lati “owo irapada, ti olukuluku eniyan san” fun emi re fun Oluwa. (Ex 30:11 – 16; 38: 25 – 29).  Iye kanna ni olukuluku san iba je olowo tabi talaka.  Eleyi tokasi wipe agbawa la, pe nitoooto ni a raw a pada pelu eje iyebiye odo aguntan tin se Kristi.  Je ki a ranti pe irin mimo Kankan ko si ti o yato si irapada.  Iko oje yi (irapada) ni o ngbe aso ibo ona duro bi iwa Emi mimo ni jojumo aye (I Pet 1:18- 19; Titu 2:11 – 14).
e.         Ide ma nso ti idajo:-  Iwa mimo Olorun bere fun ijiya fun ese, Kristi ru eru ese wonyi, o si wa fun wa ni iwa mimo re.  O ye ki a gbekele lati gbe war o ki o sit un toju wa (I Kor. 10:12; I Pet 1:5).
ABAWOLE ATI BI A TI SOKE (Ex 27:16, 17)
            Ni ipekun ila oorun gba gede na ni ona kansoso ti a le fi de odo Olorun wa.  Isoko ilekun abawole na je ihunpo awon ageku aso, ti a ti se ara orisi ti o dara si ni awo bi__________,_____________,_____________,___________.  Opo ide merin lo mu eyi dani si po, tin won tun joko si inu iho  ti a se sinu ide, a fin won ko iko ti oje bii ti aso ibo ona funfun.
EKO EMI MIMO
A.        ONA IGBAWOLE KAN SOSO LO WA:- Fi we oro Jh 12:6, 6:10; Ise A. Ap 4:12.  Eyi han gbangba ona kan soso lo wa ti o si tokasi iwalaye mimo ati oju rere Olorun eyi si ni nipase Oluwa wa Jesu Krisiti.  Abawole na wa ni ila oorun tin won ba tin mu ore irubo bo ni owuro, nitori opolopo awon ara igbaani ma nsin yiyo oorun.  Ti o ba se wipe yiyo oorun ni nwon koju si ni bi nwon ti now inu ogba Tabanaku o sese kin won ro wipe oorun ni awon nbo ki se Olorun.  Eko miran ni nipa ti ibu ati wole ogba na ti o je 20 kubiti tabi 30 feet.  O fi ye w ape o fe kan lati gba ogunlogo eniyan o fanimora fun gbogbo eni ti o wa lona ti o to.  Wo iwe Isaiah 55:1, 2; 2 Pet 3:9; I Jh 2:2, eko iwe mimo yip e ko si ruju.  Ipe ihinrere pe ki a wa si odo Olorun nipa gbigba ewu ona (Kristi) je ofe fun gbogbo eniyan.
B.        GBIGBE KO:-  Kristi bi omo eniyan, ninu olanla re ati irubo etutu ti awon awo yi duro fun: Bulu nso nipa Kristi bi eni orun.  Bulu yi ni awon eni ipo ma nwo.  Wo iwe Ezek 23:6.  Bi nwon ti ni eniyan gbodo wo aso Bulu ti o gbooro si isale ason nwon fihan pe o ye kin won je eni orun, ti o gboran si ofin Olorun (Num 15:37 – 41).  O ba Kristi mu regi paapaa ihinrere ti Johanu ni a ti ri ti o gbera ninu olanla re wiwa lati orirun re ti nse  orun ati ti igbe aye.  Wo iwe John 3:13; 6:57, 58; 16:28……..je awon ti awon oba ati awon molebi nwon maa now.  Ki a kuku pe ni awon awon lobaloba.  Ti a bar anti awon omo ogun fi aso ti o ni awo yi si ara Jesu lati fi se yeye pe Oba awon Ju ni (Jh 19:2, Mt 27:28).  Wo awon itokasi awo yi fun aso awon oba ninu iwe onidajo 8:26 ati Esteri 8:15.  Eyi fi ye wa pe iwa ati ami Oba ti Kristi nse ni a fihan wa ninu ihinrere ti Matiu, nibi ti o ti fihan ninu ipo Oba ti o je (ao yi ni oyo pelu iwa aro kan (Ti ara eni nikan)………………….yi ni a fa jade lara akolo ti o ni awo na, ti o je wipe ti  nwon ba tin gun ni o nyo awo jade fun sise aro na.  Ni orin Dafidi 22:6 Kristi so nipa ara re gege bi ekolo yi, a mo pe labe eru ese wa a gun a sis a, aaye eje ti awo yi si nda jade lara re, eyi si ni ohun ti o we ese wa nu.
D.        OPO MERIN NA:- Iwonyi duro fun iwe ihinrere merin ni inu ibi ti a ti fi Kristi han wa (1) gege bi obe (Matiu), (2) gege bi iranse (Maku), (3) gege bi eni kan ti o njiya sugbon ti yio je gbogo ogo aye yi, omo eniyan (Luku),ati (4) Eni mimo ti orun, omo kan soso Olorun ayeraye (Johannu)
PEPE IDE (Ex 27:1 – 8)
            Eleyi ko jinna si abawole sinu ogba Tabanaku yi sugbon ni ita Tabanaku nibi ti Olorun ngbe ni, ti o fi han wa gbangba pe ifi eje rubo se Pataki ki a to ni gbolohun pelu Olorun.  Igi shittimu (acacia) ti a fi ide le lori ni afise.  Laarin, labe awon eti pepe ni a se ide mo ti o je alalafo ti igi ati ohun irubo yio simi le lori ti eru yio ma ri aaye jabo sile.  O je 7 ½ si 7 ½ feet o si je 4 ½ feet ni giga.  Ni igun kookan ni iwo kookan wa ti o je ide ti o si ntokasi sita ati si oke.  Bakanna ni a ri oruka kookan ni igun kookan ti a ma ti opa igi bo lati ma gbee.

DIAGRAM

DIAGRAM
EKO EMI MIMO
A.        IDE:- Eyi tun nso fun wa nipa aiyipada Olorun lori idajo______a ni lati se idajo .  A mo o nibi yi o nso nipa ti idajo ara eni, bi Alufa ba ti teriba si agbada irubo ni yo ti ri bi eje ba fonka oju on ti o si lati fo.  Yio wa lo omi lati fo ara re, nitori a ko gba ki eni ti o doti wo inu Tabanaku.  Apostle Paulu ko wa ninu I Kor 11:31; 31 -32 wipe ti a ko ba da wa lejo ki a da ara wa lejo.
            Gbogbo ohun eto ti o wa ninu gbagede ogba Tabanaku yi ni a fi ide se eyi ti o fi ye wa pe dandan ni idajo.  Aworan Kristi ni atunwa oro Olorun (Jh 1:1) ti o ni gbogbo idajo (Jh 5:22) 2 Kor 5:10, 11).
            “Ninu pepe ide ni idajo ese wa – Ese wa.  Ninu agbada ide idajo ara eni wa – awa ara wa”.
B.        DINGI OJU:- Iwulo dingi ni lati fi ara han wa.  Igba miran ewe a ma fun ni igberage ati gaaru aye eyi ti agbada ide je wiwe mo ati biba Olorun soro.  Ni Luku 18 a ri ojulowo lilo dingi ni asehan awon Farisi, ki a gbe yewo ohun ti oselu ri ati obinrin ara samaria (Jh 4) ri nigba tin won wo dingi Olorun.  Jak 1:23 – 25 fi ohun ti itumo Emi ti dingi je oro Olorun “ofin idand ti oniye” ni a ri bi dingi mimo ti o nfi otito iwa wa han.  Gbogbo ohun irira pata ni oro yi nfo danu.  “Idara eni mo ohun ibanileru nitori ti o nmu wa mo gbogbo aimo wa.  Bi Isaiah (Isa 6) ti mo aimo re, ni a pa lara mo sile fun atunse, ki se fun ibaje.  A nilo oro atunse ki a to ni iriri iwemo omi.
D.        OMI INU OPON AGBADA:- Dingi nfi eeri han sugbon ko le foo.  Agbada tabi opon yi ma nfi a ti foo agbada tabi opon yi ma nfi ati foo han sugbon o tun ni omi fun fifo okan.  Wo Psalm 119:9 ati John 15:3 fun ikede oro ihinrere si awon onigbagbo o je itoka wa si orison ti nse Kristi.  O di dandan lati lo omi ki a to se iwe mo.  Opo kiko ni oro Olorun ati kika ko le mu iwa mimo wa a mo die ninu amulo re ni a mo.  Ihinrere ti Kristi wa je ti afomo ati irubo ijo re pelu fifi omi se afomo nipase oro ki o le fi ara re han ijo tiyi teye (Efe 5:25 – 27).  Awon alufa ti o gbagbo ti ki saba fo ara nwon ninu omi oro Olorun sese kin won gbagbe ese nwon.  Nigba ti omi oro Olorun yi ba de si ori ohun ti o sese ki o ma di baje, opo eri wa fun eleyi ninu aye.  Afi igba ti a ba sun mo opon oro Olorun fun iwe mo ni a o fi mo ese ati egbin inu aye wa.
E.         AFOMO:- John 13:10 pe oro meji ni a tumo si “fifo” ti o si yato ni itumo.  Ese yi se alaye daadaa siwaju bayi.  “Eni ti a fo” (wiwe) ko gbodo ja npata lati (fo) “ese sugbon o fo gbogbo eka ara”.  Ni awon orile ede ti o wa ni ila oorun tin won lati ile iwe yi de ile, ti o sese ki o tun ti keeri ba ese nwon dele.  Ohun ti o ku nip e ki a foe se wa nikan bi a ba dele.
                        “Ninu pepe ide ti o je irufe afomo ti ijebi ese wa labe ese tin sun jade ni  Kalfari.  (Eyi ni yio je iwe ti a daruko loke).  Inu agbada yi ni afihan wiwe mo kuro ninu eri ese.  Nibi agbada yi ti nse (Dingi) a o fie se wa ti a mo ati atyi ti a ko ranti han wa, nipase oro Olorun.  Ni idi eyi a ni lati ma we loorekore ninu agbada oro Olorun, ki a le ri gbogbo ese aye wa.
EKO EMI MIMO
A.        SHITTIMU (AKOTUN ORUKO RE NJE ACACIA) “Igi Shittimu”:- Ni asale ni igi ti ma nhu (Isa 41:19, 20) ti o fi irele ipile, aisi irole keke ti aye, ati iteriba ti Kristi han.  Awon ota re ko ri esun Kankan ka si lorun bikose esun alainidi, iru igi yi miran a ma sun oje ti o dara fun iwosan. A si ma nlo odo igi na fun itun eje se.  Kristi wa lati wo gbogbo okan to gbogbe san ati lati ri si aini ti ara ati okan awon eniyan.
B.        IDE:- Duro fun idajo mimo.  Pepe yi nse ijeri si idajo fun ese ti a da ati idajo  ti o ni iterun bi “Oorun didun” ti fi han nipa ifihan awon ebo kan.  Bi ide ti roku, be ni Kristi paapaa ni idajo re fun agbeyewo aanu yi to si irubo (Lef 26:19, Jer 1:18, Psa 107:16).  Awon iwe wonyi toka si ami ti ide duro fun o roku, o ni agbara, okun ati wipe o ni alope o fi Olorun han fun aileyipada re, agbara re aini le bo lowo idajo re ati ifokanbale labe aabo re”.
D.        ASE:-  Niwon igba ti o wa laarin meji pepe o le bawa soro nipa aarin gbungbun ago ara wa ti nse okan.  Ori ase yi ni a ma ngbe ohun irubo le.
E.         AWON IWO NSO NIPA AGBARA (Dan 8:3,4):- Nwon nso nipa agbara Olorun ti o jeyo ninu ajinde ti Kristi (Efe 1:19 – 21).  Nwon je ide nwon si ntoka si igun mererin aye ti o si nfihan pe gbogbo aye lo dese ti o si wa labe idajo Olorun.  A mo o bi a ba ti fi eje si ori awon iwo yi (Lef 4:25) ni nwon yio jise ibebe fun idariji, irapada to wa fun gbogbo eda, tie tutu Kristi ti o to fun gbogbo eniyan.
E.         INA:- Je iru idajo Olorun ti o gbodo kan sori gbogbo ese.  Ina ni orisirisi ami bii:
            (1)       Idajo (Gen 19:24, Psa 11:6)
            (2)       Mimo (Ex 3:2. Ezek 1:4, 27)
            (3)       Iwenumo (Mal 3:23, I Pet 1:7) nibo ni ina inu pepe ide ti wa, wo Lef 9:24.  A ko gbodo jeki ina na ta jade (Lef 6:13), Olorun lo tan ina na sugbon eniyan ni lati boju to daadaa.
(F).     EBO SISUN (Lef 6:8 – 13):- Eran irubo ni a o gbe sori pepe ni owuro ati ni asale a ko si gbodo je ki ina ku rara.  Kristi ni ebo sisun na ti o di eeru.  Ti a ba nsoro kikun ati pipe nipe ni jijo tan re ti o fi Kristi han fun iyori igbala wa niwaju Olorun ti nse Baba re.
(G)      EERU:- Nwon yio gbe eeru yi kuro ninu gbagede ogba lo si ibi ti o mo (Lef 6:10, 11) A gbe ara Oluwa wa lo sinu iboji tuntun.  Ni Ex 29:42 – 46 ese Bibeli to dara kan se akojopo eko lori pepe ide ati irubo ti “ebo sisun bi a ti mu sese lati ba Olorun soro, iso di mimo alufa ati eniyan, wiwa Olorun laarin nwon, ti yoo si ma je iranti ileri Olorun nipa mimu nwon jade kuro ni ile Egipit, ibi imunileru.
OPON IDE (Ex 30:17 – 21, 38:8)
            O wa laarin pepe ide ati ilekun ile Tabanaku.  O kun fun omi ti awon alufa ma nfi fo owo nwon ti won ti won ba ti jise ori pepe ide tan.  Kosi idiwon fun ide dingi awon obinrin ni a fi dan mirin-miran.  A ko bo bi awon ohun elo miran ti a ba fe si nipo.
IBI MIMO – Ti Nwon ti Nse Ise Alufa
            Ago tabi Tabanaku ni a pin si yara meji akoko ni a pe ni ibi mimo, ekeji ni a npe ni ibi mimo julo.  Ibi mimo ni a le fi we bi orun ni Efe 1:3 ati ni 2:4 – 6.
            Ni ibi mimo ni a tiri awon ohun elo ti o nfi idagba ninu ore ofe han; tabili ti akara jije – ti nse kika ati jijiroro lori oro na (Jh 6:48).  Igi ijoko opa itanna  - to nse ijeri nipa oro ati aye (Mt 5:14 – 16; Ise A. Ap 1:8) pepe turari – ti o ntoka si adura (I Pet 2:5; Ifi 8:3 – 4).  Ti a ba  ti wo inu ibi mimo yi a ni lati fi awon nkankan sile sibe.  A ko le ma dagba ninu igbagbo ki a tun ma darapo  ma ba araye dese.  Opo Kristeni ni nwon ngbe gbangba ogba na.  Koko eko ibi mimo yi ni ijosin lorekore si Olorun, lati odo ayanfe Alufa (I Pet 2:5. Ifi 1:6).
A.        ASO IBO ONA TI ITA GBANGBE (Ex 26:36, 37)
Ni iwaju ibi mimo ni ni a so aso ona na ko si ti o nse apeere Kristi gege bi ona si ise Alufa.  Awon ara Israeli ko gbodo koja pepe ide sugbon nwon mo pe asoju nwon tin se Alufa le wo ibe lati se ojuse ti awon Alufa (Ex 19:6).  Aso ona na ni a fi ko lori opo marun tin won nsimi sinu iho inu ide.  Ide ti o kehin nse ikilo fun awon Alufa lati koko se idajo ara nwon kin won to gbiyanju ati wo inu ibi mimo.
B.        OPO ITANNA ONIWURA TABI OPA INA (Ex 25:31 – 40)
O duro fun imole mimo ati ijeri.  Ti a fi ogidi wura se, o si sese ko je pe ohun ni o won ju ninu gbogbo ohun ti o wa ninu Tabanaku ti o fihan ojulowo ohun ti o duro fun.
            Opo itannna olopa meje ni nse, ti a sit e yo lati inu ogidi wura.  Ogidi wura ni o gbodo je.  Ninu oro Olorun wura nso ti ogo Olorun.  “Opo Kristieni ni nwon fe ni ohun didara yi bi iriri onigbagbo tin won je sugbon ti nwon d aide die irin die aye yimo.  Opo onigbagbo paapaa o ti wo inu iriri yi ti opa wura itanna duro fun nitoripe won da ijora eniloju/isogo ara eni po mo ogo ti Olorun.  Wo iwe Isa 42:8.  Ko si ohun ti o nba eri awa omo Olorun je ju igba ti a ba nwa ogo fun ara wa nikan ninu ise ihinrere”.
            Ise oolu ni ki se igba omo ni a lo, se awon opa na nwon lu won jade lati ara eyo wura kan ni.  Igbese yi ko rorun sugbon ko si ona miran.  Oluwa wa je iru iya yi.  Be na ni Mose, Dafidi, Josefu, Paulu ati awon miran kin won to le ri ohun ti Olorun ran nwon lati se.  Wo iwe I Pet 4:12 – 14, Rom 8:18; Psa 66:10 – 12.  Ma je ko ya o lenu ti isoro ba koo loju.  Ise oolu Olorun nsele ninu aye re niyi nitori pe ko si ona miran ti a le fi se awon opa itanna oni wura yi.  Bezaleel mo ibi ti o ye lati lu, iye igba ti o ye ati bi yo ti fi okun si lilu na.  Jesu ni Bezaleel wa, ti o mo ohun  ti a nilo (Heb 4:15; I Kor 10:13).

D.        TABILI AKARA JIJE (Ex 25:23 – 29)
                                     
DIAGRAM

              O nso nipa ajosepo pelu itelorun Olorun.  Igi Acacia ni a fi se, a bo pelu wura, ti o nfi iteriba/irele ati eni mimo ti Kristi je han.  Ni ojo Sabath kookan ni nwon fi ise akara mejila sese se sori tabili yin won yio si ko ajeku titele jade ohun ti o daju nipe, awon eya omo Israeli kookan ni o nse abojuto ipese akara na ni sisentele (Lef 24:5 – 9).  Nipase akara yi ni a ri Kristi bi alabaro ati ounje fun onigbagbo (Jh 6:32, 33:50 – 51) nwon fi turari si eka ila kookan.  Kristi te Baba re lorun (oorun didun ti frankecense) ati ipese fun ise Alufa amo ti a ba fehinti ni, o ni ibi iyasoto nitoripe ibi mimo ni Aaroni ati awon omo re yi o ti ma je akara na.  (fun alaye kikun lori akara yi lo wo asaro ninu (Lef 24).
              Tabili akara yi je tabili ti Olorun ti ngba awon eniyan re lalejo, tin won yio si jeun po ni isokan (Ifi 3:20).  Iye nomba akara wa fun iye awon ti o ba ni adehun ti o pe lati kopa ninu apeje mimo na.  O ni pupo fun gbogbo eniyan.  O ran wa leti tabili ajosepo ileri tuntun nibi ti awon Kristieni korajo lati kopa ninu akara ati waini na.
E.         PEPE TURARI:-  Adura ati ibannibe (Ex 30:1 – 10, Psa 141:2) Eyi duro looro pelu pepe ide agbada ati Apoti eri pelu ijoko aanu ti o nso ipese mimo ti a file ba Olorun soro.  Igi acacia ni a fi se ti a si bo pelu wura.  O duro gboin niwaju aga aanu lori Apoti eri ninu ibi mimo julo ti aso iboju se pin lati ibi ti iwalaye re wa.  Lekan lodun ni olori Alufa yio won eje irubo si ori awon iwo ti o wa lori pepe ide.  Olorun ngba turari nitoripe eje Kalfari wa sibe (Ex 30:10) ki alufa kankan to sunmo pepe turari o ni lati duro nibi agbada ide fun iwemo, ti o nko w ape a ni lati yanju ara wa pelu ese ki a to sunmo Olorun.  Awon alufa nikan lo le sise ni idi pepe turari oba Uzziah ro wipe on le rubo turari sugbon Olorun so di adete.  A fi igbati Kristi di ipo meji ti (Oba ati Alufa) mu, apapo si owo enikan Kristi wa duro bi Oba ati Alufa ti o si nse alagbawi fun wa.  Awa paapaa ninu Kristi je Oba ati Alufa fun Olorun.
                          Aaro ati irole daju  ti yio fi kun turari sugbon oorun yio ma ja fikan titi.  O ni lati je pelu adura wa.  Laarin adura wa okan wa gbodo se irubo aponle pelu iyin – adura ti o ga ju. (I Thes 5:16 – 18) onigbagbo ti o ba nbere ohun aye lowo Olorun ti si anfani adura – idagba ninu emi nipa fifi ara wa jin fun Olorun ko le mu ohun ti ko dun mo kuro, ati lati fi aaye fun ara re, bi turari nati fi ara re fun ina.
A FI ARA BALE JUWE TURARI LATI ENU OLORUN (Ex 30:34 – 38):- Eyi ti o juwe yi ni o ntewo gba.  Gege bi a ko  ti ni fe ti a si nko owo ti ko dara be na ni Olorun ko fe eda.  Ko si ohun ti a le fi ropo esin NI TI EMI ATI NITI OTO (Jh 4:24).  Turari otito ni eyi ti o jeyo lati okan onigbagbo ti o si goke to pepe Olorun nipase olori Alufa nla ni ti tise Jesu (Psa 141:2; Ifi 5:8).  Ko gbodo wa lati ete wa rara bikose lati okan ibasepo ti o dara laarin okan ati Olorun.
            Ki idunnu ti Turari nfun Olorun?  A peelo re pelu ijosin toto lati okan wa, iyin, igbagbo, ipa mo ife Olorun, iteriba ati ife (Heb 13:15; Ifi 8:3) sa kiyesi ikilo lori “Ajeji turari (Ex 30:9).  “Ajeji turari je ijosin laslana ti o kan je aniyan lasan.  O kilo fun nwon lati ma se iru.  “Eyi ti yio je oorun be” (Ex 30:38) ohun ti Olorun fib u nihin yi nip e ki nwon ma so esin di igbadun lasan si eniyan ibaje pelu orin/ilu ti o dara lati gbo seti tabi mimo oro so kan wulo fun itelorun okan lasan tabi pipatewo ti o kan mu inu eran ara dun lasan.  Ti a ba ni ki a wo daadaa, sisin ni tooto ki saba se ohun ti o dun mo okan tabi opolo.  Ijosin tooto ni eyi ti o ba pe Jesu Oluwa wa.  A ri iyato yi ninu vs 37 ti oro kan ni “iwo ko gbodo so ara re di “mimo fun Oluwa”.
ASO IBO ONA TI INU LOHUN (Ex 26:31 – 33):- je irufe ara Kristi.  A se pelu owu aso ati awon awo ti o dara fun ibori ti ita ati wi pe o ni aworan awon kerubu ti a fi owu ti o dara hun.  Kerubu je awon eso ti Olorun fin le awon ti Olorun ko fe Gen 3:24.  A mo ni ibi yi awon kerubu ara aso yi ma ndi awon eniyan lodo Olorun.  Nwon ni lati nise pelu mimo Olorun: pe rirubo nikan ni elese fi le ni iwalaaye mimo ti yo se awemo fun pipe Olorun.  Aso yi lo nfi ipinya si ajosepo eniyan ati Olorun.  O tun dabobo awon alufa kuro ninu wiwa re ni ibi mimo julo.
Nigbati a kan Kristi mo agbelwnu, Aso ipele tempili fa ya (Mt 27:45 – 52).  Eyi fihan pe gbogbo irubo ti inu majemu lailai ni a ti pa ti, ti a si ti gbe liana otun ti o wa laaye lo nipase fifo si wewe ara Kristi (Heb 10:20).  O ya lati oke wa, ti o fihan pe Olorun lo se, o ya de ile ti o nfihan pe ase pari ni ise na, o si fihan pe ko si ohun eniyan elese tun fe se tabi fi kun ati sumo Olorun.  Ko da o tun “ya laarin” (Lk 23:45) ti o nfihan pe elese ti o ngbagbo bayi ko ni lati gba ona egbe tabi ma yi obiripo Kankan ju pe ki o ni anfani taara si Olorun.
“O je ijoniloju gidi pe o sese ki awon alufa ti ran aso ibo ona ti Olorun ya papo nitori wi pe isin inu Tempili tun nte siwaju fun odindi ogoji (40yrs) odun, aso ibo ona ati a ran yi ni Galatianism – itiraka lati fi eni Olorun tabi elese pada si abe ofin, Wo Gal 1: 6 – 9.  Ohunkohun ti o ba  ti yato si ore ofe Kristi je ihinrere miran o si wa labe Anathema” .  Ijeni niya tabi ibinu si ni, ko wulo aawe ati adura lati wa oju rere Olorun tabi lati ni anfani sisunmo ibi ti Olorun wa.  Iru igbese be ko woye aso ibo ona ti o ya, ko tun gba ekun rere anito ti o wa ninu iku Kristi!.
“Aso ileke ti o ya yi je apeere eran ara ebo Olorun ti a ya.   Nipase yiya yi ni ona fi si fun awon alufa (tin won o ba ma sise isin nwon ninu ibi mimo ni wakati na) ati paapaa gbogbo onigbagbo lati wo ibi mimo julo.  Edu ti a fi nda’na turari_________gbogbo eti so iyi nwon nu.  Nwon ti di oku ise.  Awon miran bori nwon.  Nigba kan won je ona ti a fi nri ojurere Olorun, ni igba miran nwon kan je aiwulo iranti ileri ti o  ti ku lai mo, awon alufa ti fi oju nwon ri iku ti majemu lailai ati ibere majemu tuntun.
Efesu 3:12; 2:18; Heb 4:16; 10:19 ti nwon nso nipa nini anfani si Olorun, a si le wa pelu igboya ati ifokan le (igbokanle).  Nwon wa lafiwe oto inu Tabanaku nibi ti iwonna aaye lo wa wa ko da fun awon alufa.  Ni igba atijo si sunmo ibi aaye Olorun ni a ma nse pelu iberu ati egbonriri.  Bawo ni o se yato ni ode oni, ise alufa ti Emi tuntun, ti o nwole sinu lohun si odo Olorun pelu ifokanbale.

IBI MIMO JULO (Ex 25:10 -22).
            Ibi yi ni ibi iyasimimo julo ninu Tabanaku.  Ibi ni Olorun ngbe laarin awon eniyan re.  A ko gba enikankan laye ni be afi Mose ati olori Alufa.  Olori alufa paapaa now ibe lekan lodun, Sugbon ki ise lai mu nnkan irubo dani (Lef 16:4) Eje ti yo mu wo ibe ni eje maalu fun irubo ese tire (vs 11) ati eje ti ewure fun irubo fun ese ti orile ede Israeli (vs 16).
            Ibi mimo julo je apeere orun awon orun ibugbe Olorun (laarin awon eniyan re) ti ko se de labe ofin, fun awon onigbagbo wo, wayi o ni ti Emi ati ipese ni ti iwalaaye ni a gba bi ibi mimo ti mo julo je okan fun wa, ni iwon igba ti aso igbeleke ti ya.
            Ni inu ibi mimo julo, gege bi o ti ye ibi mimo, ko si iru ifipile (alainiye) ni a nri nibe.  Lehin ti a ba ti se idajo ese tan, a o bere si ri wura ogo Olorun.  “Ko si imotara eni nikan tabi isogo ara eni, yinyin eniyan, a fi erongba ti ogo Olorun le fihan”.
            Ni inu ibi ti a nwi yi, ko si ohun ti a le gbo ju ti Olorun lo.  Ni ibi ko si ina Kankan, Olorun ni imole ibe.  Ohun elo kan soso na lo wa nibe ti nse Apoti eri ti nse ite Olorun.  Ibi yi ni Olorun.  Ibi yi ni Olorun ti ma nba Mose ni gbolohun lati ori ite aanu wa (vs 22).
APOTI ERI (Ex 25:10 -21)

DIAGRAM

            Eyi je apoti pooro ti a fi igi Acacia se ti a sib o pelu wura ninu ati ni ita re.  Ogidi wura ni a fib o, ijoko aanu, nibiti awon kerubu meji ti a fi ogidi wura se duro tabi kunle si, Apoti eri yi duro fun ite Olorun, ite ogo re fun isejoba lori Israeli.
            Mu aye ti o yato ni ibase pelu ago awon omo Israeli.  Nigbati awon omo Israeli ba nyan lo Apoti eri ma nwa ni iwaju nwon ni, ti yio o ma wa ibi isinmi fun won (Num 10:33), iru bi eni mimo ti ma nsiwaju wa.  Ti nwon ba si duro fun isinmi ni apoti eri yio wa laarin nwon bi Kristi ni aarin wa, paapaa bo ti le je eni meji tabi meta ni nwon pejo ni oruko re.





No comments: