LIBERTY
CAMPUS OGBOMOSO OYO STATE
Liberty Hall, Opposite Blind Centre, Ayetoro area Ogbomoso, Oyo State, Nigeria
MOBILE; 08056008526 & 07031821386
HANDOUT
ISE ETUTU
Eko kkiko: Matiu.1:18-25,Rom.3:23-26, 1 John
1:9
“Yio si bi
omokunrin kan, Jesu ni iwo o pe oruko re; nitori on ni yio gba enia re la kuro ninu ese won. Matiu 1:21 (KJV)
IFAARA: Anilo lati ko ki a si loye iru eniti Kristi Jesu nse, ise re
lori ile aye ati idi iku re lori agbelebu ni kalfari. Bi ohun nla kan tabi
eredi ti o fi ta eje re sile yio ba jamo nkankan ninu aye wa.
Eese ti o fi
wa, ti o ku lori igi agbelebu, ti o sita eje re sile, bi ise-etutu, kilode?
Nitori wipe “gbogbo enia lo sa ti se, ti won si kuna ogo Olorun” ati pe ko si
eniti o le rii tabi mu ogo wa fun Olorun ayafi bi a ba mu ese kuro (1
John.1:8-10) nitorina ni o fi pondandan fun un lati wa ati lati ku iku ti ko
buyi kunni lati gba wa la kuro ninu iku ayeraye, nipa mimu ese kuro nipa
idariji re, ti o si gba wa sile kuro ninu ide ese patapata, pe ki a ma ba sin
ese mo.
LILOYE
ENITI JESU NSE
Isa.7:14, Jh.1:21, Matt.16:16, Jh.4:25-26.
O se Pataki fun
wa lati mo Olugbala okan wa yi, mase je eniyan bii obirin ara Samaria eni ti o
duro pelu olugbala, sibe ti ko mo eni ti olugbala ise,(Jh. 4:22) Jesu ko kan
gboruko lori bi eran araara, bikose fun
eredi ati gba awon eniyan re la, (Heb.2:14-15, Gal.6:16) kuro lowo agbara ati
ijegaba ese.
WAHALA
TI ESE DA SILE
ISUBU ADAMU ATI EFA
kiise
didun inu Olorun fun adamu lati subu kuro ninu ojurere ati ipese Re, sugbon,
esu ti o ti je ota eniyan lati ipile aye lose eyi.
Ninu
arekereke ti ejo ni lowo ni esu fi ri gege bi ohun elo ti o wa ni arowoto.
Nigba ti ejo wo inu ogba, o soro fun eniyan lati gbagbo wipe esu ti kajo sinu
re. Ogba Edeni wa ni alafia titit di igba ti esu wo inu re wa. Nigba ti o wo
inu ogba na tan nse ni o lo taara sodo obinrin naa, nitori o mo wipe okunrin na
yio le ju fun ohun lati tete bori.
Sugbon
oje iyalenu lati ri wipe okunrin na wa nile bi alaisi ni, nitoripe ni oju re ni
esu ti nduna-dura pelu iyawo re lori ohun ti oun gangan mo wipe o lodi si ase
ti Olorun pa fun oun.
Ibeere
ni wipe, nibo lowa ti esu fi ndunadura lori omo, iyawo tabi ise iranse re? Ohun
elo pataki meta ni esu lo fun Efa, titi di oni ni esu si nlo awon ohun elo
wonyi, nitoripe onsise fun:
1. Odara fun jije.
2. Odara fun oju.
3. Igi ti nfe lati munni gbon.
Ohun
elo kan ti o lo fun isubu Adamu ati Efa yi na ni o lo fun Akanni ninu Joshua 7:
21-25. Bakan na ni o tun loo fun Jesu
Oluwa leyin iribomi re. Luku 4: 1-14.
Esu
yio jare opolopo eniyan ni orun apadi nitoripe imoran ni o ma nmu wa, eniyan si
agbara lati yi imoran re danu
AWON
ABAJADE ISUBU ENIYAN
1. Ese gba ijoba aye eniyan
2. Eniyan jogun iku nipase ese.
3. Alafo nla ni ese da sile laarin eniyan
ati Olorun.
4. Eniyan si di eni egun niwaju Olorun.
Romu
3:25; Rome 6:23; Rome 5:12.
Bawo ni
ibasepo pelu re sele pada sipo? Ayafi ki a mu oun ti o fa iyapa kuro. Eniyan ko
lagbara lati se ohunkohun nipa re (Rom.5:6) ayafi Olorun tikarare nikan soso lo
le mu wahala naa kuro, eyi je idi Pataki ti o fi ran omo bibi re nikan soso ti
o je aworan Olorun tikarare lati ku lori agbelebu, ati lati ta eje re sile fun
irapada wa. (Jh.3:16-21)
ISE
ETUTU
Ise etutu je dandan, nitori a gbodo
setutu ese gbogbo.
Ise
etutu tumo sipe ki a duro ni ona kan lati sipe fun asise tabi aisedede igba
kan. (Rom.3:25)
Oro etutu yi
ni a le fi se apejuwe omo oba kan to sesi se alabapade ebo kan ni ikorita kan
lati wo ilu won. Leyin eyi ni o wa bo sinu aisan nla kan, eyi ti iwadi fihan
wipe won gbodo se etutu irorun fun, nitori bikose bee, omo oba yi yio ku ni.
Rom. 3:25; Rom. 5:6.
Bi
ko ba si igbese kiakia, omo oba yi yio pada ku ni o:
- Ogbon ori tabi imo iwe kuna, yio pada
mu iku ba omo oba na ni.
- Bi itiju ko ba gba won laaye lati se
etutu na, omo oba yi yio ku ni.
- Bi ko ba si eni ti yio gbe etutu na
fun omo oba yi, yio pada ku na ni.
1. Mimo riri oore pelu okan ope nigba
gbogbo
2. Gbigboran si eni na lenu titi lailai
3. Jijowo ara eni lati tele itoni re nigba
gbogbo
OPIN
EBO LORI OMO OBA NAA Heb. 10:26-27;
Rome 6:1-2
Bi
omo oba yi ba tun monmon lo fi oju ko ebo miran, ohan gbangba wipe omo oba yi
yio papa ku na ni. (Iku ina orun apadi)
Ise
etutu ti Jesu ti se nipa eje re mu idande ba gbogbo eniti o ba jewo ese re
gbogbo ti o si ko won sile, lojukanna, a we nu ninu eje, o si di mimo, pelupelu
o mura tan lati igbe-aye ododo gbogbo (1.Jh.1:9) eyi si seese nipa igbagbo.
IGBAGBO NINU EJE RE Rom.3:24-25, Rom.5:1-2,
Heb.11:5-6
BAWO
NI ASE LE MO WIPE ETUTU TI GBA?
Oje otito
wipe kiise gbogbo ebo ti awon eniyan gbe nitori enikan ni etutu re ma ngba lori
eni na
Bi etutu na
ba si gba, oni awon ona ti won yio fi mo wipe etutu na ti gba. Bakan na ni o ri
nipa ti Emi, bi etutu eje Jesu ba gba lori enikan, yio ni awon ona ti awon eni
Emi yio fi mo, fun apeere, ti a ba wo aye Poolu ao ri eko ti o po ko, paapa
julo nipa ona lati mo wipe etutu ti gba
lori re. Ise A. A. 9: 1-9
* Imole nla mole yiika
* Osubu kuro lori esin to ngun bo
* Afi awon asise re han fun
* Awon alajorin re pada leyin re
* Leyin ti oju re la, ko si ri awon nkan
atijo mo
* Won fa lowo, osi ntele eni to nfa lo
si Damasku
* Ko jeun fun ojo meta, a se akoso
ipongbe re.
AGBARA AGBELEBU NINU ISE
ETUTU
KINI AGBELEBU? Lati inu itumo
nipa ti ara:
i. Agbelebu
je igi kan ti o ge omiran ti o duro loju ona re si meji ki oun ba le koja lo.
ii. Ibi
ti ife Olorun ti ge ife okan Jesu si meji, ti ife Olorun si wa si imuse
iii. Atun
mo gege bi ona ijiya to gaju ti awon
ijoba Romu fi nje eni ti won da lebi iku.
iv. O
je ona lati mo eni egun tabi eni ifibu
v. Agbelebu
ni igi na ti a fi Jesu ko si ki o baa le ru egun, ese, idalebi ati iku aye wa.
vi. Lori
agbelebu ni Jesu ti mu aago ikoro ati asepe ise igbala wa
vii. Jesu
duro gege bi aropo wa lori agbelebu. e.t.c Eksodu 12:3-7; Heb. 9:12-14; 1Pet.2:2-4.
Leyin gbogbo ise igbala ti a ti ri nipase agbelebu
yi, koye ki a tun ri enikan ti yio tun je ota fun agbelebu. Sugbon oje ohun to
yani lenu wipe awon kan wa ti won ti so ara won di ota fun agbelebu. Filipi 3:
17-21 E je ki a wo awon ona ti a le gba da iru won mo:
1. Igbeyin
won ni iparu lowo
2. Ikun
won ni Olorun won
3. Won a
ma sogo ninu itiju won
4. Awon
ohun aye yi ni gbogbo ero won
IDELARE NIPA EJE RE. Rom.5:1-9
Idalare ni
ona ti Olorun ngba lati kede eniyan elese gege bi Olododo, ese ikesan (9) so
wipe a nda o lare nipa eje re: eyi ni ipe Olorun ninu idalare yi.
Ese akoko so
wipe a dawa lare nipa igbagbo, eyi ni ipa tire ninu re ti a si gbodo wa aye fun
bi a ti nkeko nipa ise asepo irubo nipa etutu eyi ti o mu itusile wa kuro lowo
agbara ese fun enikonkan ti o ba gbogbo. “Nitori okan ni a fi ngbagbo si ododo
ati pe enu ni a fi njewo si igbala” Rom.10:9. KJV
No comments:
Post a Comment