Sunday, December 30, 2018

ISE IRANSE AWON OBINRIN


ISE IRANSE AWON OBINRIN
1 KOR 14:34
O han gbangba pe obinrin ki se ole ninu ise iranse, eko yi si fi ye w ape ti a ba wo bibeli wa daradara, a o ri opo awon obinrin ti Olorun lo gidigidi, ti a o ko ni pa won ti o ba  to akoko, gege bi a ti n tesiwaju ninu eko, opo ise iranse ni obinrin ndasi tabi ti o le se ni ona kan tabi omiran, sugbon ise iranse akoko ti a ri Oluwa ti o pe obinrin si ni ise iranse “iranlowo” Gen 2:18.
            A ko pe obinrin nitori fun ise iranse ohun akoko ti a pe obinrin fun ni ki o je iranlowo fun idile re.
            Gbogbo ise iranse ti a ban se ti o ba tin pa ile wa lara ki se ise iranse ara wa ni a nsise fun.  Obinrin gbodo ri wipe gbogbo nnkan ko ni ohun le se ninu ise iranse oko re gbogbo nnkan ko ni ohun le so.
            Emi iye ni “zoe” ni ede Giriki,
Eda alaaye ni eni ti o ni emi eranko
Alaaye okan ti o ni iye
Niwonba igba ti a ti yo okan lara egungun okunrin o ti di alabuku.  Alaabo ara si ni awa obinrin nitori ayo egungun wa kuro lara okunrin Jh 1:1
KINI A NPE NI IDILE?
Oro idile tobi ju oro ile lo.
Idile (Home) – Idile ni ibi ti ife ngbe, ti baba ati iya ati omo  ti ife gbe won ro, tabi ti ife sowon papo.
Ile (House) – Ile ni ibi ti a fi owo ko, ile ni ibi ti baba ati iya ati omo wa ti o si le ma si ife laarin won.
IYATO TI O WA LAARIN ILE ATI IDILE
IDILE
1.        Awon obi (the parent) – Baba ati iya yen won o dabi tegbon taburo ti won a si gbo ara won ye.
2.        Ise won (their attitude) – Nnkan kan naa ni won o ma se papo.
3.        Oju iwoye won (opinion) – Won a jo ni oju iwoye kanna nigba na ni won to di idile.
4.        Igbe aye tara (moral standard) – Imura won  gbodo dogba
5.        Ifisise won (action) – Ifisise won gbodo lo bakanna
6.        Iwa Omoluabi (character) – Iwa won gbodo je bakanna,iwa won gbodo je iwa omoluabi
7.        Idile Kristieni (a Christian home)
            Idile Kristieni ni ibi ti Baba ti ni iberu Olorun, ti iya ti ni iberu Olorun ti awon omo na ti ni iberu Olorun, o sit un je ibi idasile ti ife Kristeni so won papo, nibi  ti a ti fi aaye gba awon omo fun itoni ti Emi, ti Jesu Oluwa si ti je opo ti ki se ori lasan, nibi ti obi ati awon omo ti ma npejo po fun isin ebi lararo, idile Kristeni je ibi ti eru Olorun ti nsakoso. Owe 14:1, Owe 9:13.
AWON OHUN META TO SE PATAKI NINU AYE OBINRIN OLOGBON
1.        INU TI O JIN – O gbodo je eni ti ile inu re jin, ti o ri ibi gba oro si, ko gbodo je alara gbigbona.
2.        OKUTA – O duro bi oruko Jesu, iyato wa ninu mimo Jesu ati nini Jesu.  Nini Jesu gege bi ohun ini ti ko se mani, ko le mu ipinnu Olorun se ninu aye yi.  O gbodo ni Jesu gege bi ogun ko se mani.
            Oruko Jesu oju bi awon eniyan ti  pe, gbogbo ibikibi ti a ban lo a gbodo ma fi oruko yi yangan, a gbodo ni oruko yi ju oko ati omo wa lo. Bi a se ma nran oko wa lowo lati mu ki idi ti o fi was aye wa si imuse, tabi bi a se ma nran omo wa lowo lati mu ki idi ti awon omo yi fi was aye wa si imuse.
3.        ERUPE (Oro Olorun) – Nigba ti iyawo iranse Olorun ko ba le ye oro Olorun wo fun bi (30 mins) si (1hr), ki ni o fe mu rinrin ajo ninu aye yi tabi ki ni o fe fi ko awon eniyan.   Mt 7:24 – 27 – Oro Olorun nikan ni a nilo ni akoko ti a wayi.
OJUSE OBINRIN NINU ILE – Owe 31:11 – 30
Ojuse obinrin ninu ile, ti a ba je olotito si
1.        O gbodo je eni ti o se gbekele ti o si se sinmi le, Owe 31:11 – Iyawo Kristi se sinmile fun isoji igba ikeyin. I Kor 7:10, Rom 7:2.  Obinrin gbodo fi ara sile fun oko re titi ti iku yoo fiya won.
2.        O gbodo je oluranlowo fun oko re Owe 31:12
3.        O gbodo je orison ibukun fun idile re Owe 31:14
4.        O gbodo je obinrin oro na – Eni ti ko ni duro de igba ti oko re ba ni adura ya, ko ni duro de oko re igba ti oro Olorun baya, a ati pin oro Olorun fun awon omo re Owe 31:15
5.        O gbodo je obinrin ti o ma gba imoran lowo oko ki o to se ohunkohun, ko gbodo je eni ti o nse asiri ikoko – Owe 31:16
6.        O gbodo je eni ti o mu ojuse temi ni okunkundun – Owe 31:17.  Iru obinrin be gbodo je eni oro na, o gbodo je oluko ile eko ojo isinmi, o gbodo je eni ti o nrin deedee, ti o si nko awon omo re, o gbodo je eni ti o nka oro Olorun lemo lemo.
7.        Owe 31:18 – O gbodo je obinrin adura na ki oja re ti se Emi mimo ki o lagbara, ki Fitila re ti ise igbe aye adura ma si ku, ti o ba ri pe nnkan nsele si oko re tabi awon omo re o gbodo dide ki o gbe ohun adura soke.  O gbodo je eni ti o le fi adura jagun ona to jin lori omo, lori oko, igbe aye adura ma nje ki eniyan da ohun Olorun mo ni gbogbo igba, adura ni o ma nje ki a mo okan Olorun ni gbogbo igba.
8.        Titu 2:5 – O gbodo je osise ninu ile, eni ti ko ya obun, eni ti o moju tonu ile toto, omo re gbodo mo, o gbodo je obinrin to nsise takuntakun.
9.        O gbodo je eni to lawo, eni to nfi funni eni ti ko lahun, eni ti Olorun ma lo ti won ma fi se ategun fun gbogbo agbaye gbodo je obinrin ti o lawo.
10.      O gbodo le se itoju oko re ki o seri.
11.      O gbodo je obinrin ti o mu ki idile re duro girigiri.
12.      Owe 31:26, Jak 3:2 – 6 – O gbodo je eni ti o ko ahon re ni ijanu, o gbodo je eni ti o le sakoso ahon re, eni ti Olorun ma lo fun isojji igba ikeyin o gbodo le pa asiri mo.
13.      Owe 31:27 – O gbodo je obinrin ti o ni gbagbo nipa ojo ola, ko gbodo je eni ti nro oni nikan, ko je eni ti now ojo ola, mo mo wipe bi oni o ba dara, ojo ola yoo dara.
14.      O gbodo je aso ibora fun oko re, iru iyawo be duro bi aso aabo fun oko re we 31:21, I Kor 7:1 – 5, 10, 16.
AWON OBINRIN TI WON MU ISOJU WA NIGBA TI WON
            Ani opolopo obinrin ti Olorun lo fun ise re nigba aye ti won, eyi ti a lo se agbeyewo won ninu majemu laelae ati titun, eyi ti a lo ma gbeyewo ni kookan.
            Oluwa ki kanju lati lo enikan sa tabi lati mu eni ti a ko pese aye re sile, eni ti ko leko, eni ti a ko ti ge aye re si ipele ti o le wu Oluwa, Oluwa ko le mu iru eniyan be se ojuse re ninu ijo re.  Isoji ni idasi Olorun tabi ipakusi Olorun ninu aye enikan, isoji ni mimu aye kan tondaku lo pada wa si iye.  Fun apeere, isoji ma nfi opin si igbe aye ti ko dara ti eniyan ngbe, isoji ni isele kan ti Olorun fi aaye gba lati fi opin si igbe aye ese.
SIPPORA – Eks 4:24 - 26
            Gbogbo enikeni ti Olorun ba ma lo fun isoji ikeyin gbodo je eni ti o ni igboya.    Nitori aigboran ni Olorun se fe pa Mose, Sippora iyawo re ni o ni igboya ti Olorun lo fun lati mu ki iku ye lori re, eni ti o le se ikawo ile re girigiri, iru eni be ni Olorun gbodo gbekele.  Ina isoji wa gbodo bere lati inu ile wa wa, leyin na ni ijo Olorun.
DEBORA – Oni 4:1 – 24
1.        Obinrin ti o ba sise iranse ko le da ise se laisi oko re, bi okunrin na ko se le da ise se ni obinrin ko le da ise se.
2.        O je eni ti o da Olorun re mo, ki se Olorun oko re ni o gbekele, o je eni ti o ni idile, Debora je oluko, o je onidajo o je eni ti o ni amuye tooto ki won to le yan gege bi onidajo gbogbo ilu, bibeli pe ni Oluko, gbogbo eni ti Olorun ba ma lo fun ina isoji igba ikeyin gbodo je Oluko, ohun to nko, si ntele bi o ti nko won, Debora ni igbe aye ti o  ni ihoho, ko si eni ti o ma wa ba fun ife ikoko, eni ti Olorun ma lo fun isoji ikeyin gbodo je eni tii ko ni asiri ikoko, eni ti Olorun o lo fun ise iranse igba ikeyin ko ni se ohun ti awon eniyan nse. Onid 5:7.
IGBE AYE RUTU – Rutu 1:1 –
            Ipokipo ti eniyan ba wa loni, ki a ni iforiti, ki a si le duro de opin.  Ohunkohun to wu to nla koja, ma wo, wo wipe idojuko na ko nip e pari latari sise fun isoro, eniyan le padanu oko o si le padanu omo, ti eniyan ko ba ti le duro de Oluwa yoo padanu opolopo nnkan pupo.
            Ni opolopo igba ni sisa ninu ogun o tun ma nti wa lo sinu ogun.  Asonidomoleyin wa duro bi Naomi fun wa ti yoo ma juwe ona abayo fun aye wa, Rutu ni o duro bi omoleyin ninu eko yi.  Opolopo ohun ti a ba se fun asonidomoleyin wa ni akosile re wa, opo ohun ti a nse fun Jesu ni a ni akosile re.
            Ninu jije omoleyin eniyan gbodo ni iforiti, nitori gbogbo akosile aye wa ni won nko sile.
IGBE AYE FASTI AYABA
            Asise akoko ti Fasti se ni wi pe ko ye ki o da ni ise iranse tire, o ye ki o mo wi pe ise iranse oko ohun naa ni ise iranse ti ohun, ise iranse akoko ti a ni ni oko tabi aya wa, ekeji ni omo won ki o to kan ise iranse.
            Ti awon oko wa ba fun wa ni oore ofe lati sin Olorun koye ki a si lo.
IGBE AYE ESTERI – Est 2
            Nigba ti inu re bar u ko bi a ti nsakoso, nigba ti inu Asiwerusi ru, oko iyawo re, nigba ti inu re role, o ranti Fasti, sugbon epa ko boro mo, opolopo oko tabi aya ni o ma njiya ni ikorita yi nitori nigba ti oju won ba role, ko ni si atunse mo ti ki ba se asise Fasti, Aswerusi ko ba ma ni iyawo meji.  Nitori Esteri ni asonidomoleyin eleyi je ki o ri ojurere lodo Oba, nitori ki se ohunkohun funrare, gbogbo ohun ti asonidomoleyin re so fun ni o nse, ko se ohun ti olodi si ohun ti asonidomoleyin re ni ki o se.
            Esteri je eni  ti o ni irele ti o si dunwo, o si je arewa obinrin, nnkan keji ni wipe o je eni ti o npa asiri mo, o sit un ti wa laba isaba fun odidi odun kan, o ni eko ki se alaileko omo wiwa labe isaba ki se ohun ti o rorun, omoleyin ti ko ba gboran si asonidomoleyin re lenu aye re ko ni se ri, aye re ko ni yanju, nse ni aye re ma dobu.
            Ohun miran ti a tun ri ko ninu aye re ni wi pe ko fi aye re ko ba Modekai, nnkan miran ti atun ri ti Esteri se ni wi pe o fi Emi re wewu nitori awon ara Juu, nitori o ni ibasepo to dara pelu Olorun re.
            Nnkan miran tun ni wi pe o la ipa ninu gbogbo aye awon ti won wa ni ibe, ti aye wa ko ba la ipa ninu idile wa, Olorun ko le lo wa fun ihinrere ikeyin.  A ko leda rinrin ajo yi afi ki a koko la ipa ninu aye awon eniyan miran, gbogbo akoko ti a fi sile fun awon omo wa lati je ki oye oro Olorun ye won, a ko fi akoko na sofo, ti eniyan ko ba re ara re sile, Olorun ko le lo, ti eniyan ko ba je eni to ngboran Olorun ko le lo.
AWON OBINRIN TI OLORUN LO NINU MAJEMU TITUN FUN ISOJI ATI ISE WON
1.     IYA JESU IGBE AYE MARIA – Lk 1:28 – 38
            Igbe aye Maria wa di ohun to ngbe iyanu kiri sinu aye elomiran, ti yoo mu ki ipinnu Olorun ninu aye elomiran wa si imuse.  Aye Maria te olorun lorun lati mu iyanu jade, nitori ki se ohun nikan ni wundia  to wa nibe nigba naa.  
            Awon nnkan meji ti Maria sonu ninu igbeyawo re ki o to le ye.
1.        O so eye idana nu (Engagement)
2.        O so igbeyawo nu ati adun leyin isopo nu (Wedding & Honeymoon)
            Maria so gbogbo ohun to ni eto si nu nitori emi ati iwo, ti awa na ko ba le so ohun ti a ni nu nitori isoji igba ikeyin yi, ki elomiran le ni iye ayeraye, iru eni be ko ye fun isoji igba ikeyin yi.  Ti a ko ba gbagbe eto wa ki a ko sile aye elomiran ko le ni iyipada, fifi aye wa sile fun Olorun yoo mu ekun ati ose dani, dandan na ni ki a fi aye wa sile fun elomiran. 
Ko rorun fun Jesu lati fi Emi re lele, sugbon o na ni nnkan kan, sibe o fi ara da, ki a ba le ni iye ainipekun.   Ireti Olorun fun aye eni ti o mu isoji jade iru aye be gbodo mu iyipada ba won.
2.        IGBE AYE MARIA MAGDALENE – Jh 20:1 – 18
            Maria Magdalene je omoleyin Jesu ti o de gbeyin, bi o ti je wipe ohun ni o de gbeyin gbogbo ohun ti Jesu so fun won wi pe o ma sele ti ohun ba ku ni o nfi okan si ju ti awon to ba ni be lo.
            Gbogbo eni ti ko ba ni igboya, Olorun ko le lo fun isoji igba ikeyin.   Ti o ba fe ri nnkan tuntun ninu oro Olorun o gbodo duro pepe titi ki o le ri ohun titun, iyato wa ninu kika bibeli ati sisaro oro Olorun.   Igbe aye ti Maria gbe yi ni o tumo si sisaro oro Olorun pipe titi, iru eni bi Maria yi ni o le wulo fun isoji igba ikeyin.
            Iru iwa ti Peteru ati omo eyin keji wu ninu eko yi ni o tumo si awon to nka bibeli ni erefe ti ko le duro pe titi.  Irin ajo jije omoleyin ki se irin ajo ajorin o je irin ajo ti a ma da rin.  Ireti Olorun lori aye wa ni wi pe ki gbogbo aye je alabapin iku re nipase wa, ki se wi pe ki awon eniyan di eni itanu nipase wa.  Olorun lo Maria lati ba iroyin buburu ti awon omo eyin mu lo je lori Jesu, sugbon opolopo onigbagbo lo je wi pe aye won ko polongo Jesu mo ni akoko yi, sugbon ko ye ki awa tun pelu won, o ye ki aye tiwa bere si ni polongo Jesu fun ihinrere igba ikeyin yi.
LARA AWON OBINRIN BUBURU
IGBE AYE EFA – Gen 3:1 – 7
1.        Ohun akoko ninu aye Efa ni wipe o fi alakoba se ore re, ko fi oko re se ore re.
2.        Opo nnkan ni Efa nse ti ki so fun oko re, o tumo si wi pe ki a ma fi nnkan pamo fun oko eleyi ma nse okunfa wahala wa sinu ebi
3.        O silekun sile lati ba majemu Olorun je lori oko re.
            Efa ati Adamu je alawawi eniyan, Efa ni o ko ba iran eniyan.  Kaini na sit un ni (higher killer) akoko ninu bibeli fun iran eniyan, nitori ohun ti Efa se yi, Olorun ko le lo fun isoji igba ikeyin.
IGBE AYE IYAWO POTIFERI– Gen 39:7 – 18

            Awon ohun to pana isoji ni akoko iyawo Potiferi ni wi pe o je opuro, o tun je pansaga.  Iyawo iranse Olorun ko gbodo ma (poision) okan oko re ti o ba fe ki Olorun lo ohun fun ina isoji igba ikeyin Ps 37:32 – 33.

IGBE AYE DELILA – Onid 16:4 – 19
            Obinrin ti Olorun fe lo fun isoji igba ikeyin ko gbodo ma tu gbogbo asiri oko re.   Gbogbo ohun ti a ban la koja a ko gbodo je ki asiri idile wa tu sita fun awon eniyan.
IGBE AYE PENINA – I Sam 1:6
            Nitori Penina ma nto Hana orogun re, ti o si nfi omo yo, nitori eyi a ko gbo oruko Penina mo ninu bibeli ati awon omo re, eni ti Olorun yoo ba lo fun isoji ti igba ikeyin, ko gbodo ma kegan eniyan.
IGBE AYE JESEBELI – I Awon Oba 21:1
               Jesebeli naa tun je opuro ati olojukokoro lati gba ohun ini Naboti, Jesebeli je iyawo Oba, sugbon iro ati ojukokoro ko je ki o wulo fun ise iranse igba ikeyin, aini itelorun ko ye ki o ti orun ise iranse.  Ti a ba fe ki ina isoji igba ikeyin ma jo ninu aye wa ki a ma je ki enikeni gba igbala sonu ninu aye wa.
IGBE AYE ATALIAH – 2 Awon Oba 11 – 1
            Ohun akoko ti a ri ninu aye Ataliah ni wipe o je olote obinrin, o si je agbode gba okunkun, ko ni eru Olorun ninu rara, o tun je eni ti o ni imotara re nikan.  Ataliah ko ni ero rere ninu aye re, gbogbo aye re ero ibi ni.
            Ataliah je eni ti o ma nfa owo Olorun male ti ki fe ki ileri Olorun se, ni gbogbo irin ajo wa, a gbodo ma sora ki a ma dabi Ataliah.   Ataliah ni emi esan gbigba, awon Ataliah ni ki tete dariji boro.
IGBE AYE HERODIA – Mt 14:1 – 12
Herodia ni emi esen, beni ko ni emi idariji, Horia wa lara awon ti ki gbebe, won ma nse ise  aje, eni  ti Olorun yoo ba lo fun isoji ti igba ikeyin yoo sa fun ise aje.
Iru awon eniyan bi ti Herodia yi ni o ma nde ogo eniyan, tabi ki won fi opin si irin ajo temi ninu aye eniyan, awon eniyan kan wa ti o je pe oro enu won obe ni, ti won ki si beere boya eni na se aseyori.
Awopoko je awo to se iyebiye tabi ohun to se iyebiye, awopoko je ohun to nse iyebiye tabi nnkan to seyebiye, tabi aye to se iyebiye.  A gbodo ko bi a ti ma so oro oko tabi aya wa loju awon eniyan, ki oro tiwa na ma ba dabi ti Herodia ati iya re ti won seku pa iranse Olorun Johannu.
Gbogbo oore ofe ti Oluwa ba fi fun wa tabi ti o fi sinu wa, tabi talenti re bi o ti hu kop o to Oluwa nreti wa lati fit un aye oko wa ati aya wa se, ati lati mu debi ti Olorun fe mu de ati lati mu ipe orun se lori aye iru oko be, Oluwa mu wa si aye ki se lati ba aye je abi lati mu idi ife Olorun se, ye aye re wo, nje igbe aye re mu aye oko/aya re ye lati je adari fun Oluwa larin awon eniyan tabi ni awujo tabi se o fi aaye gba ikeji re lati le gbe oju si ohun ti Olorun ran o waye wase, se o je aye, mo obinrin abi eni eegun ti o ma nmu itiju ba oko re tabi aya re, se o je eni ti o nfi ade de oko re lori abi oyn ninu egungun ki Oluwa o ran wa lowo Amin).






No comments: